ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Apá Kẹjọ: Bí A Ṣe Lè Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Tí Yóò Máa Tẹ̀ Síwájú
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba—2005 | April
    • Apá Kẹjọ: Bí A Ṣe Lè Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Tí Yóò Máa Tẹ̀ Síwájú

      Bá A Ṣe Lè Máa Darí Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Sínú Ètò Ọlọ́run

      1. Kí nìdí tó fi ṣàǹfààní pé kó o máa kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ohun kan nípa ètò Jèhófà lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ nígbà tó o bá ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

      1 Kì í ṣe nítorí káwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lè mọ ẹ̀kọ́ ìsìn nìkan la ṣe ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bí kò ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́ káwọn pẹ̀lú lè di ara ìjọ Kristẹni. (Sek. 8:23) Ìwé pẹlẹbẹ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà—Ta Ni Wọ́n? Kí Ni Wọ́n Gbà Gbọ́? ló dáa jù láti lò. Fún àwọn tó o ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ẹ̀dà kan ìwé yìí, kó o sì gbà wọ́n níyànjú láti kà á. Láfikún sí i, máa fi àkókò díẹ̀ sílẹ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ nígbà tó o bá ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láti fi kọ́ wọn ní ohun kan nípa ètò Jèhófà.

      2. Báwo lo ṣe lè rọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pé kí wọ́n máa wá sí ìpàdé?

      2 Ìpàdé Ìjọ: Ọ̀nà kan tó dáa jù táwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fi lè mọrírì ètò Ọlọ́run ni pé kí wọ́n máa wá sí ìpàdé ìjọ. (1 Kọ́r. 14:24, 25) Nítorí náà, o lè máa ṣàlàyé ìpàdé márààrún tá à ń ṣe lọ́sẹ̀ fún wọn níkọ̀ọ̀kan kí wọ́n bàa lè mọ̀ nípa àwọn ìpàdé wa. Jẹ́ kí wọ́n mọ àkòrí àsọyé fún gbogbo èèyàn tẹ́ ẹ máa gbọ́ nípàdé lọ́sẹ̀ yẹn. Fi àpilẹ̀kọ tá a máa kà lọ́sẹ̀ náà nígbà Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ àti ibi tá a máa kà nínú ìwé tá à ń lò ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ hàn wọ́n. Ṣàlàyé fún wọn nípa Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run àti Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn. Tó o bá ní iṣẹ́ nínú ìpàdé ilé ẹ̀kọ́, kò burú tó o bá fi dánra wò lójú wọn. Sọ àwọn kókó pàtàkì tó o gbọ́ rí láwọn ìpàdé fún wọn. Fi àwòrán tó wà nínú àwọn ìwé wa hàn wọ́n kó lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fọkàn yàwòrán bí ìpàdé wa ṣe máa ń rí. Ọjọ́ tó o bá kọ́kọ́ kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ ni kó o ti fi ìpàdé lọ̀ wọ́n.

      3. Kí làwọn nǹkan tó ń lọ nínú ètò yìí tó yẹ ká jíròrò?

      3 Ìgbà tí ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó ṣe pàtàkì bá ṣì wà lọ́nà ni kó o ti fi ìṣẹ́jú díẹ̀ ṣàlàyé fún wọn nípa rẹ̀ lọ́nà tí wọ́n á fi túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ sí i. Irú ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì bẹ́ẹ̀ sì lè jẹ́ Ìrántí Ikú Kristi, àpéjọ àyíká, àpéjọ àkànṣe, àpéjọ àgbègbè, tàbí ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká. Ṣàlàyé ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀ lé sáwọn ìbéèrè bíi, Kí nìdí tá a fi ń jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà? Kí ló fà á tó fi jẹ́ pé Gbọ̀ngàn Ìjọba là ń pe ibi tá a ti ń ṣèpàdé? Kí ni ojúṣe àwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́? Ọ̀nà wo la gbà ṣètò iṣẹ́ ìwàásù àti ìpínlẹ̀ ìwàásù? Báwo la ṣe ń tẹ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́? Ibo lowó tí ètò yìí ń lò ti ń wá? Kí ni ẹ̀ka ọ́fíìsì àti Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ń ṣe láti bójú tó iṣẹ́ náà?

      4, 5. Báwo làwọn fídíò wa ṣe lè jẹ́ káwọn èèyàn túbọ̀ mọyì ètò Ọlọ́run?

      4 Àwọn Fídíò Tó Ń Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́: A tún lè lo àwọn fídíò wa láti jẹ́ kí àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ̀ nípa ètò Jèhófà tó jẹ́ àgbàyanu yìí. Fídíò tá a pè ní To the Ends of the Earth, fi bá a ṣe ń ṣíṣẹ ìwàásù káàkiri ayé hàn, bí ẹgbẹ́ ará kárí ayé ṣe rí ló wà nínú fídíò Our Whole Association of Brothers, nígbà tí èyí tá a pè ní United by Divine Teaching gbé ìṣọ̀kan tó wà láàárín àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà yọ rekete. Nígbà tí obìnrin kan tó ti máa ń gba àwọn ìwé ìròyìn àtàwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa mìíràn wo fídíò Jehovah’s Witnesses—The Organization Behind the Name, kò mọ̀gbà tó bú sẹ́kún. Tẹ́lẹ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí tó ń lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ nìkan ló fọkàn tán, àmọ́ lẹ́yìn tó wo fídíò yìí tán, ó wá yé e pé ó tún yẹ kóun fọkàn tán ètò Ọlọ́run. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, nígbà tó sì di ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, òun náà lọ sí ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba.

      5 Tá a bá ń lo ìwọ̀nba ìṣẹ́jú díẹ̀ lọ́sẹ̀ pẹ̀lú àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá a sì tún ń lo àwọn irin iṣẹ́ tó wà lọ́wọ́, ní kẹ̀rẹ̀ kẹ̀rẹ̀, a ó lè máa darí wọn wá sínú ètò kan ṣoṣo tí Jèhófà ń lò lónìí.

  • Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba—2005 | April
    • Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn

      Ile Iṣọ Apr. 15

      “Ǹjẹ́ kò dà bíi pé ẹ̀kọ́ kíkọ́ ò lópin láyé òde òní? [Jẹ́ kó fèsì.] Àmọ́, kò sóhun tó wúlò tó ohun tí ẹsẹ Bíbélì yìí sọ. [Ka Jòhánù 17:3.] Ìwé ìròyìn yìí sọ ohun tí gbólóhùn náà, ‘ìyè àìnípẹ̀kun’ túmọ̀ sí àti béèyàn ṣe lè ní ìmọ̀ tó máa jẹ́ kéèyàn ní ìyè àìnípẹ̀kun.”

      Ile Iṣọ May 1

      “Nígbà téèyàn wa bá kú, ohun tó máa ń wu àwa ẹ̀dá èèyàn ni pé ká tún padà rí onítọ̀hún. Àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? [Jẹ́ kó fèsì.] Ọ̀pọ̀ èèyàn ni ìlérí tó wà nínú Bíbélì pé àwọn òkú yóò jíǹde ti tù nínú. [Ka Jòhánù 5:28, 29.] Ìwé ìròyìn yìí sọ ìgbà tí àjíǹde yóò wáyé àti àwọn tí àjíǹde máa ṣe láǹfààní.”

      Jí May 8

      “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sẹ́ni táwọn èèyàn mọ̀ nípa rẹ̀ tó Jésù Kristi nínú gbogbo àwọn tó ti gbé ayé rí, síbẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń ṣe kàyéfì nípa ẹni tí Jésù jẹ́ gan-an. Ǹjẹ́ o mọ̀ pé àwọn àpọ́sítélì Jésù pàápàá ṣe kàyéfì bẹ́ẹ̀? [Jẹ́ kó fèsì, lẹ́yìn náà ka Máàkù 4:41.] Ìwé ìròyìn yìí ṣe àlàyé nípa ẹni tí Jésù jẹ́ gan-an.”

      “Ọ̀pọ̀ òbí ló máa ń fòye yan irú fíìmù tí wọ́n fàyè gba àwọn ọmọ wọn láti máa wò. Ǹjẹ́ ó máa ń ṣòro fún ọ láti mọ irú fíìmù tó bójú mu pé kí ìdílé rẹ wò? [Jẹ́ kó fèsì, lẹ́yìn náà ka Éfésù 4:17.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé bí àwọn òbí ṣe lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ irú fíìmù tàbí eré sinimá tó bójú mu fún wọn.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́