Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí
“KÍ Ẹ ní inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Baba wa Ọlọ́run àti Jésù Kristi Olúwa.” Báyìí ni Pọ́ọ̀lù ṣe kí àwọn ìjọ nínú ọ̀pọ̀ lára lẹ́tà tó kọ sí wọn. Àwa náà ń kí yín bẹ́ẹ̀, nítorí pé à ń ṣàníyàn nípa gbogbo yín pátá.—Éfé. 1:2.
A mà dúpẹ́ fún inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí Jèhófà fún wa nípasẹ̀ ẹbọ ìràpadà Kristi Jésù o! Ìràpadà yẹn ló jẹ́ ká lè rí ojú rere Ọlọ́run. Kò sí bí àwa fúnra wa ṣe lè ṣe é láé tá a fi lè rí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí yẹn, bó ṣe wù ká kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì dáadáa, ká wàásù ìhìn rere tàbí ká ṣe àwọn iṣẹ́ rere mìíràn tó. Ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ tá à ń rí gbà àti ìyè àìnípẹ̀kun tá à ń retí kì í ṣe nítorí mímọ̀ọ́ṣe wa, bí kò ṣe nítorí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí Jèhófà fún wa nípasẹ̀ Jésù Kristi.—Róòmù 11:6.
Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sáwọn onígbàgbọ́ bíi tiẹ̀ pé: “Àwa ń pàrọwà fún yín . . . pé kí ẹ má ṣe tẹ́wọ́ gba inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run kí ẹ sì tàsé ète rẹ̀. Nítorí ó wí pé: ‘Ní àkókò ìtẹ́wọ́gbà, mo gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ, àti ní ọjọ́ ìgbàlà, mo ràn ọ́ lọ́wọ́.’ Wò ó! Ìsinsìnyí gan-an ni àkókò ìtẹ́wọ́gbà. Wò ó! Ìsinsìnyí ni ọjọ́ ìgbàlà.” Àkókò kan wà tó jẹ́ “àkókò ìtẹ́wọ́gbà” nígbà tó kù díẹ̀ kí Jerúsálẹ́mù pa run ní ọ̀rúndún kìíní. Àwọn èèyàn ọlọ́kàn rere tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà rí ojúure rẹ̀. Ìyẹn ni gbogbo àwọn olóòótọ́ tó sá kúrò ní Jerúsálẹ́mù nígbà tó kù díẹ̀ kí ìparun rẹ̀ dé lọ́dún 70 Sànmánì Kristẹni fi bọ́ lọ́wọ́ ìparun yẹn.—2 Kọ́r. 6:1, 2.
Bákan náà, “àkókò ìtẹ́wọ́gbà” tó tún jẹ́ “ọjọ́ ìgbàlà” là ń gbé lónìí. Àwọn tí Jèhófà tẹ́wọ́ gbà láti jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n sì ti rí ojúure rẹ̀ yóò rí ìgbàlà nígbà tí “ọjọ́ ńlá Jèhófà,” tó sún mọ́lé yìí bá dé.—Sef. 1:14.
Iṣẹ́ ńlá ni ọjọ́ Jèhófà tó ń bọ́ yìí gbé lé wa lọ́wọ́. A gbọ́dọ̀ kìlọ̀ fáwọn èèyàn nípa rẹ̀ ká sì tún ran àwọn ọlọ́kàn rere lọ́wọ́ kí wọ́n bàa lè jàǹfààní inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jèhófà káwọn náà lè rí ìgbàlà. Ọwọ́ pàtàkì ni Pọ́ọ̀lù fi mú ojúṣe yìí. Ó sọ pé: “Ní ti gidi, mo gbé bí èmi kò bá polongo ìhìn rere!” Ó tún sọ bí ọ̀rọ̀ ọ̀hún ṣe rí lára rẹ̀, ó ní: “Èmi jẹ́ ajigbèsè sí . . . àwọn ọlọ́gbọ́n àti àwọn òpònú: nítorí náà, ìháragàgà wà ní ìhà ọ̀dọ̀ mi láti polongo ìhìn rere.”—1 Kọ́r. 9:16; Róòmù 1:14, 15.
Bá a bá pa iṣẹ́ pàtàkì tí Jèhófà gbé lé wa lọ́wọ́ pé ká kìlọ̀ fáwọn èèyàn tì, a máa dáhùn níwájú Jèhófà. A kúkú mọ ohun tí Jèhófà sọ fún wòlíì Ìsíkíẹ́lì pé: “Ọmọ ènìyàn, olùṣọ́ ni mo fi ọ́ ṣe fún ilé Ísírẹ́lì, kí o sì gbọ́ ọ̀rọ̀ láti ẹnu mi, kí o sì kìlọ̀ fún wọn láti ọ̀dọ̀ mi. Nígbà tí mo bá sọ fún ẹni burúkú pé, ‘Dájúdájú ìwọ yóò kú,’ tí ìwọ kò sì kìlọ̀ fún un ní tòótọ́, kí o sì sọ̀rọ̀ láti kìlọ̀ fún ẹni burúkú náà pé kí ó kúrò ní ọ̀nà burúkú rẹ̀ láti pa á mọ́ láàyè, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ ẹni burúkú, yóò kú nínú ìṣìnà rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ni èmi yóò béèrè padà ní ọwọ́ rẹ.”—Ìsík. 3:17, 18.
Àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí nira láti bá lò. Kò rọrùn láti ṣe gbogbo ohun tó yẹ nínú ìdílé, níbi iṣẹ́, nínú ìjọ àti lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù kí ọ̀kan má sì pa òmíì lára. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ lára yín ni àìsàn, àárẹ̀ ọkàn àti ọjọ́ ogbó ń yọ lẹ́nu, kódà àwọn kan ń kojú àtakò. Èyí tó pọ̀ lára yín lẹrù sì “wọ̀ lọ́rùn.” À ń ṣàníyàn nípa yín, gẹ́gẹ́ bí Jésù ti sọ pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá, tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, dájúdájú, èmi yóò sì tù yín lára.” (Mát. 11:28) A gbóṣùbà fún gbogbo ẹ̀yin tẹ́ ẹ̀ ń sapá láti máa sin Jèhófà nìṣó láìka ìṣòro ńlá àti kéékèèké tó ń dojú kọ yín sí.
Gẹ́gẹ́ bí àbájáde iṣẹ́ ìwàásù tẹ́ ẹ̀ ń fìtara ṣe pa pọ̀ mọ́ ìbùkún Jèhófà, ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé ọ̀tàlélẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin àti méjì [4,762] làwọn tó ń ṣèrìbọmi lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Ìjọ tuntun egbèje ó dín mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [1,375] la dá sílẹ̀ lọ́dún iṣẹ́ ìsìn tó kọjá yìí. A nírètí, a sì ń gbà á ládùúrà pé kí ìwé tuntun náà, Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?, tó ti jáde lédè ọgọ́fà [120], ran àìmọye ọ̀kẹ́ èèyàn lọ́wọ́ sí i láti jàǹfààní inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti àlàáfíà látọ̀dọ̀ Jèhófà lásìkò “ọjọ́ ìgbàlà yìí.”
A fẹ́ kẹ́ ẹ mọ̀ pé Ìgbìmọ̀ Olùdarí nífẹ̀ẹ́ yín, a sì ń gbàdúrà fún yín. Bẹ́ẹ̀ náà là ń dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún àdúrà tẹ́yin náà ń gbà fún wa.
Àwa arákùnrin yín,
Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà