Àtúnṣe Lórí Ìlànà Tó Wà fún Lílo Gbọ̀ngàn Ìjọba fún Ṣíṣe Ìgbéyàwó ní Nàìjíríà
1 Ìgbéyàwó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn nǹkan pàtàkì tá à ń ṣe nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. (Jẹ́n. 2:24) Yàtọ̀ sí kéèyàn ṣe gbogbo ohun tí òfin béèrè, àwọn ìlànà kan tún wà nínú ètò Jèhófà tẹ́ni tó bá fẹ́ ṣègbéyàwó nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba ní láti tẹ̀ lé. Àwọn àtúnṣe tá a ṣe sí ìlànà táwọn kan lè ti máa tẹ̀ lé nígbà kan rí la là lẹ́sẹẹsẹ sínú àpilẹ̀kọ yìí.
2 Lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà láǹfààní láti yan ọ̀kan nínú ìṣètò méjì tó wà fún ṣíṣe ìgbéyàwó: bóyá Ìgbéyàwó Lọ́nà ti Àṣà Ìbílẹ̀ tàbí Ìgbéyàwó Níbàámu Pẹ̀lú Òfin Ìgbéyàwó. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé oríṣi ìgbéyàwó méjèèjì ló bófin mu tó sì bá Ìwé Mímọ́ mu, ó ṣe pàtàkì ká mọ̀ pé wọ́n yàtọ̀ síra, bẹ́ẹ̀ sì ni ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ló dá dúró gedegbe. Ọ̀nà wo ni wọ́n gbà yàtọ̀ síra?
3 Ìgbéyàwó Lọ́nà ti Àṣà Ìbílẹ̀: Bí wọ́n ṣe ń ṣe Ìgbéyàwó Lọ́nà ti Àṣà Ìbílẹ̀ níbì kan lè yàtọ̀ sí bí wọ́n ṣe ń ṣe é níbòmíì. Síbẹ̀, lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà níbí, ilé ẹjọ́ ti fọwọ́ sí àwọn nǹkan kan tó ṣe pàtàkì kí Ìgbéyàwó Lọ́nà ti Àṣà Ìbílẹ̀ lè lẹ́sẹ̀ nílẹ̀. Níwọ̀n bí irú ìgbéyàwó yìí ti fìdí múlẹ̀ nípa sísan owó orí ìyàwó àti fífa ìyàwó lé ọkọ lọ́wọ́, ọkùnrin àti obìnrin náà ti di tọkọtaya lábẹ́ òfin àti níbàámu pẹ̀lú Ìwé Mímọ́.
4 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ìgbéyàwó Lọ́nà ti Àṣà Ìbílẹ̀ lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ láìfi orúkọ ẹ̀ sílẹ̀ lábẹ́ òfin, kí tọkọtaya bàa lè ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn, dandan ni kí wọ́n forúkọ ìgbéyàwó wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin. Bí wọ́n bá forúkọ ìgbéyàwó wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin, òfin á dáàbò bò wọ́n á sì dáàbò bo àwọn ọmọ wọn. Nítorí náà, kí àwọn alàgbà rí i pé àwọn tẹnu mọ́ ọn fáwọn Kristẹni tó ṣe Ìgbéyàwó Lọ́nà ti Àṣà Ìbílẹ̀ pé kí wọ́n forúkọ ìgbéyàwó náà sílẹ̀ lábẹ́ òfin ní gbàrà tí ìgbéyàwó náà bá ti parí. Káńsù ìjọba ìbílẹ̀ tó bá ní ìṣètò fíforúkọ Ìgbéyàwó Lọ́nà ti Àṣà Ìbílẹ̀ sílẹ̀ lábẹ́ òfin lèèyàn ti lè ṣe irú ìforúkọsílẹ̀ bẹ́ẹ̀.
5 Ìgbéyàwó Níbàámu Pẹ̀lú Òfin Ìgbéyàwó: Oríṣi ìgbéyàwó kejì tí òfin orílẹ̀-èdè Nàìjíríà fàṣẹ sí ni Ìgbéyàwó Níbàámu Pẹ̀lú Òfin Ìgbéyàwó. Oríṣi ìgbéyàwó kejì yìí béèrè pé kí ọkùnrin àti obìnrin náà ka ẹ̀jẹ́ níwájú ẹni tí òfin fún láṣẹ láti sọ wọ́n di tọkọtaya. Bákan náà, ó kéré tán, ìgbéyàwó náà gbọ́dọ̀ ṣojú ẹlẹ́rìí méjì, tọkọtaya àtàwọn ẹlẹ́rìí sì gbọ́dọ̀ buwọ́ lu ìwé ẹ̀rí. Kò dìgbà tí ẹbí tọkọtaya náà bá fọwọ́ sí irú ìgbéyàwó yìí, bẹ́ẹ̀ sì ni irú ìgbéyàwó yìí ò béèrè fún sísan owó orí. Àmọ́, lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ìjọba ti fọwọ́ sí lílo àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba kan fún ṣíṣe Ìgbéyàwó Níbàámu Pẹ̀lú Òfin Ìgbéyàwó.
6 Ṣíṣe Ìgbéyàwó Lọ́nà ti Àṣà Ìbílẹ̀ àti Níbàámu Pẹ̀lú Òfin Ìgbéyàwó Pa Pọ̀: Láti bí ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, ó ti wá wọ́pọ̀ láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí tó ń fẹ́ra pé lẹ́yìn tí wọ́n bá ti kọ́kọ́ ṣe Ìgbéyàwó Lọ́nà ti Àṣà Ìbílẹ̀, wọ́n á tún wá ṣe Ìgbéyàwó Níbàámu Pẹ̀lú Òfin Ìgbéyàwó ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ó ṣeé ṣe káwọn kan ti rí èyí bí ọ̀nà tí wọ́n lè gbà fi orúkọ ìgbéyàwó tí wọ́n ṣe lọ́nà ti àṣà ìbílẹ̀ sílẹ̀ lábẹ́ òfin. Síbẹ̀, ó ṣe pàtàkì láti rántí pé Ìgbéyàwó Lọ́nà ti Àṣà Ìbílẹ̀ àti Ìgbéyàwó Níbàámu Òfin Ìgbéyàwó yàtọ̀ síra gédégbé. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn bá Ìwé Mímọ́ mu, ó sì bá òfin mu, láìsí èkejì. Nítorí náà, bí ọkùnrin àti obìnrin kan bá ṣègbéyàwó Níbàámu Pẹ̀lú Òfin Ìgbéyàwó ní Gbọ̀ngàn Ìjọba lẹ́yìn tí wọ́n ti ṣe Ìgbéyàwó Lọ́nà ti Àṣà Ìbílẹ̀, ohun tó túmọ̀ sí ni pé wọ́n ti ṣègbéyàwó lẹ́ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.
7 Ìlànà tó wà níbẹ̀ ni pé bí àwọn méjì tí wọ́n lómìnira àtifẹ́ra bá ṣègbéyàwó níwájú adájọ́ tàbí ẹlòmíì tí òfin fún láṣẹ láti so tọkọtaya pọ̀, ìgbéyàwó náà lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ níwájú Ọlọ́run àti níwájú ìjọ Kristẹni. Bí wọ́n bá tún wá lọ ṣe ‘ìgbéyàwó nílànà ìsìn’ lóṣù mélòó kan tàbí lọ́dún mélòó kan lẹ́yìn náà, ṣe ló máa túmọ̀ sí pé ìgbéyàwó àkọ́kọ́ ò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀. Bákan náà, bí ẹni méjì bá ṣe Ìgbéyàwó Lọ́nà ti Àṣà Ìbílẹ̀, ìgbéyàwó náà ti fẹsẹ̀ múlẹ̀ níwájú Ọlọ́run àti níwájú ìjọ Kristẹni. Bó ṣe wá rí yìí, kò bójú mu, kò sì pọn dandan fún àwọn tó ti ṣe Ìgbéyàwó Lọ́nà ti Àṣà Ìbílẹ̀ láti tún ṣe Ìgbéyàwó Níbàámu Pẹ̀lú Òfin Ìgbéyàwó nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba tó níwèé àṣẹ láti so tọkọtaya pọ̀ nílànà òfin ìgbéyàwó.
8 Ọ̀nà Tó Tọ́ Láti Gbà Ṣe Ìgbéyàwó Níbàámu Pẹ̀lú Òfin Ìgbéyàwó Nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba: Pẹ̀lú ohun tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ yìí, kò ní bójú mu fáwọn tó ṣe Ìgbéyàwó Lọ́nà ti Àṣà Ìbílẹ̀ láti tún lọ ṣe Ìgbéyàwó Níbàámu Pẹ̀lú Òfin Ìgbéyàwó nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba. Bó bá wu tọkọtaya tó ṣe Ìgbéyàwó Lọ́nà ti Àṣà Ìbílẹ̀ láti sọ àsọyé ìgbéyàwó nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba, wọ́n lè sọ ọ́, kìkì pé kò gbọ́dọ̀ sí àwọn ètò míì tó máa ń wáyé nígbà Ìgbéyàwó Níbàámu Pẹ̀lú Òfin Ìgbéyàwó, irú bíi bíbuwọ́ lu ìwé ẹ̀rí. Àwọn méjì tó fẹ́ fẹ́ra wọn ló máa pinnu irú ìgbéyàwó tí wọ́n fẹ́ ṣe, bóyá Ìgbéyàwó Lọ́nà ti Àṣà Ìbílẹ̀ ni o tàbí Ìgbéyàwó Níbàámu Pẹ̀lú Òfin Ìgbéyàwó. Kókó pàtàkì tá a gbọ́dọ̀ máa fi sọ́kàn ni pé èyíkéyìí téèyàn bá ṣe nínú irú ìgbéyàwó méjèèjì yìí ló lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ tó bá dọ̀rọ̀ òfin àti níbàámu pẹ̀lú Ìwé Mímọ́.
9 Pẹ̀lú àlàyé tá a ti ṣe yìí, kò ní sí ààyè mọ́ fún tọkọtaya tó bá ti ṣe Ìgbéyàwó Lọ́nà ti Àṣà Ìbílẹ̀ láti tún ṣe Ìgbéyàwó Níbàámu Pẹ̀lú Òfin Ìgbéyàwó nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba èyíkéyìí ní Nàìjíríà. Bí tọkọtaya kan bá sì ti ṣe Ìgbéyàwó Lọ́nà ti Àṣà Ìbílẹ̀, kò tún ní pé wọ́n ń lọ ṣe Ìgbéyàwó Níbàámu Pẹ̀lú Òfin Ìgbéyàwó níbi ìforúkọsílẹ̀ Ìgbéyàwó mọ́. Bí tọkọtaya Kristẹni kan bá tún yàn láti ṣe Ìgbéyàwó Níbàámu Pẹ̀lú Òfin Ìgbéyàwó níbi ìforúkọsílẹ̀ ìgbéyàwó (kì í ṣe ní Gbọ̀ngàn Ìjọba), ọ̀ràn tí ara ẹni nìyẹn. Ìgbésẹ̀ kejì yìí kọ́ ló máa ṣẹ̀ṣẹ̀ fìdí ìgbéyàwó náà múlẹ̀. Ẹ má sì ṣe wá tìtorí ìyẹn ṣètò fún àsọyé ìgbéyàwó tàbí àpèjẹ. Bákan náà, kò sídìí fún tọkọtaya kan láti lọ ṣe Ìgbéyàwó Lọ́nà ti Àṣà Ìbílẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n bá ti ṣe Ìgbéyàwó Níbàámu Pẹ̀lú Òfin Ìgbéyàwó, bẹ́ẹ̀ sì ni kó bójú mu pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀.
10 Àsọyé Ìgbéyàwó: Bó bá ṣẹlẹ̀ pé lẹ́yìn tí tọkọtaya Kristẹni kan ti ṣe Ìgbéyàwó Lọ́nà ti Àṣà Ìbílẹ̀ tàbí Ìgbéyàwó Níbàámu Pẹ̀lú Òfin Ìgbéyàwó, ó tún wù wọ́n kí wọ́n gbọ́ àsọyé ìgbéyàwó ṣókí, wọ́n lè kàn sí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà ìjọ tó ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba tí wọ́n ti fẹ́ gbọ́ àsọyé ìgbéyàwó náà láti tọrọ ààyè, ì báà jẹ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tó níwèé àṣẹ láti so tọkọtaya pọ̀ tàbí èyí tí ò ní. Bí wọ́n bá ti fún wọn láṣẹ láti lo Gbọ̀ngàn Ìjọba, “yóò bọ́gbọ́n mu láti má ṣe jẹ́ kí ọjọ́ púpọ̀” wà láàárín ìgbéyàwó àti àsọyé ìgbéyàwó. (w97-YR 4/15 ojú ìwé 24, ìpínrọ̀ 1) Ọjọ́ kan náà tàbí ọjọ́ kejì tí Ìgbéyàwó Lọ́nà ti Àṣà Ìbílẹ̀ tàbí Ìgbéyàwó Níbàámu Pẹ̀lú Òfin Ìgbéyàwó bá wáyé ló máa dáa jù kí àsọyé tẹ̀ lé e nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba. Bí ọ̀pọ̀ ọjọ́ bá ti gùn ún lẹ́yìn ìgbéyàwó kí wọ́n tó sọ àsọyé Bíbélì, àsọyé yẹn ò ní fi bẹ́ẹ̀ nítumọ̀. Àsọyé Bíbélì gbọ́dọ̀ buyì kún ìṣètò náà, kó bu ọ̀wọ̀ fún Jèhófà kó sì fi bí ìgbéyàwó ṣe ṣe pàtàkì tó hàn. Ìwé Mímọ́ ló gbọ́dọ̀ dá lé lórí, kó tura kó sì gbé ìgbàgbọ́ àwọn tó pésẹ̀ síbẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú tọkọtaya ọjọ́ náà ró. Láfikún sí i, gbogbo ìṣètò tó bá rọ̀ mọ́ àsọyé náà ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí àwọn tó pésẹ̀ máa rò pé ìgbéyàwó ẹlẹ́ẹ̀kejì ni wọ́n ń ṣe.
11 Gbogbo Kristẹni tó wà nínú ìjọ ló gbà pé Ọlọ́run ló ṣètò ìgbéyàwó. Nítorí náà, ìyówù káwọn méjì tó ń fẹ́ra wọn yàn, ì báà jẹ́ Ìgbéyàwó Níbàámu Pẹ̀lú Òfin Ìgbéyàwó tàbí Ìgbéyàwó Lọ́nà ti Àṣà Ìbílẹ̀, wọ́n gbọ́dọ̀ sa gbogbo ipa wọn láti rí i pé ‘bẹ́ẹ̀ ni àwọn jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni’ nípa ṣíṣe ojúṣe wọn nínú àdéhùn ìgbéyàwó tí wọ́n jọ bára wọn ṣe. (Mát. 5:37; 19:6) Bá a bá jẹ́ kí ìgbéyàwó ní “ọlá” nírú ọ̀nà yìí, ṣe là ń fìyìn fún orúkọ Jèhófà, tá a sì ń rí i pé àwọn ìlànà rẹ̀ ò yingin.—Héb. 13:4.