Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí
Ẹ̀yin Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ẹlẹgbẹ́ Wa Ọ̀wọ́n:
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lo àǹfààní èyíkéyìí tó bá ní láti fi hàn pé òun mọrírì àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ òun, òún sì nífẹ̀ẹ́ wọn. Nínú lẹ́tà tó kọ sáwọn ará nílùú Róòmù, ó sọ pé: “Mo fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run mi nípasẹ̀ Jésù Kristi nítorí gbogbo yín, nítorí a ń sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ yín jákèjádò ayé.” (Róòmù 1:8) Bọ́ràn ṣe rí gan-an nìyẹn, torí pé gbogbo ibi tí ilẹ̀ Róòmù ti ń ṣàkóso ni wọ́n ti mọ̀ pé ìgbàgbọ́ àwọn Kristẹni tó wà nígbà yẹn lágbára gan-an, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ń fìtara wàásù. (1 Tẹs. 1:8) Abájọ tí Pọ́ọ̀lù fi nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin rẹ̀ dénú!
Bíi ti Pọ́ọ̀lù làwa náà ń ṣe, torí gbogbo ìgbà tá a bá rántí yín la máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà. Gbogbo yín la fẹ́ràn dénúdénú! Ẹ sì jẹ́ kó dá a yín lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ yín lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Àwọn kan lára yín ń fojú winá inúnibíni tó gbóná janjan, síbẹ̀ ẹ̀ ń bá a lọ láti wàásù. Ẹ ò rí bí ẹ̀mí àìṣojo àti ìgboyà yín ṣe máa múnú Jèhófà dùn tó!—Òwe 27:11.
A fi àpilẹ̀kọ kan ṣàlàyé iṣẹ́ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe lóde òní sínú ìwé ọdọọdún wa, ìyẹn Yearbook, tá a ṣe lọ́nà tó gbádùn mọ́ni tó sì fún ìgbàgbọ́ ẹni lókun, àkòrí àpilẹ̀kọ náà ní “Acts of Jehovah’s Witnesses in Modern Times.” Tẹ́ ẹ bá ka àpilẹ̀kọ náà tẹ́ ẹ sì ronú lórí rẹ̀, ẹ máa rí ẹ̀rí pé Jésù Kristi Olúwa ṣì ń bá a lọ láti ‘ṣẹ́gun àti láti parí ìṣẹ́gun rẹ̀,’ ẹ sì tún máa rí i pé kò sóhun ìjà èyíkéyìí táwọn èèyàn bá ṣe torí àwọn tó ń tẹ̀ lé Kristi tó máa ṣàṣeyọrí.—Ìṣí. 6:2; Aísá. 54:17.
Nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará ní Fílípì, ó sọ pé: “Mo . . . dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run mi nítorí ìrànlọ́wọ́ fún ìtìlẹyìn tí ẹ ti ṣe fún ìhìn rere.” (Fílí. 1:3-5) Bí àwa Ìgbìmọ̀ Olùdarí ṣe ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nítorí ohun tẹ́ ẹ ti ṣe gan-an nìyẹn. Lọ́dún iṣẹ́ ìsìn 2007, àròpọ̀ bílíọ̀nù kan, mílíọ̀nù ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé mọ́kànlélọ́gbọ̀n, ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún méje ó lé mọ́kànlélọ́gọ́ta àti ọgọ́rùn-ún márùn-ún ó lé mẹ́rìnléláàádọ́ta wákàtí [1,431,761,554] làwa akéde mílíọ̀nù mẹ́fà, ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ó lé mọ́kànléláàádọ́rùn-ún, ọgọ́rùn-ún méje àti àádọ́rùn-ún [6,691,790] fi wàásù ìhìn rere ní igba ó lé mẹ́rìndínlógójì [236] ilẹ̀ lágbàáyé. Ẹ ò rí i pé iṣẹ́ takuntakun lẹ̀ ń ṣe fún ìtẹ̀síwájú ìhìn rere! Ẹ wo ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn táyé wọn ti túbọ̀ nítumọ̀ látàrí ìsapá tá a jọ ń ṣe láti fògo fún Jèhófà!
Nígbà míì ẹ̀wẹ̀, Pọ́ọ̀lù fi hàn pé òún máa ń fọ̀ràn àwọn arákùnrin òun ro ara òun wò. Ó kọ̀wé sáwọn ará ní Tẹsalóníkà pé: ‘Láìdabọ̀ ni a ń rántí ìfaradà yín nítorí ìrètí yín nínú Olúwa wa Jésù Kristi níwájú Ọlọ́run àti Baba wa.’ (1 Tẹs. 1:2, 3) Bẹ́ẹ̀ ni, ìgbésí ayé ẹ̀dá èèyàn ò lè ṣe kó má níṣòro. Ìṣòro á jẹyọ lóòótọ́, àmọ́ ó ṣe pàtàkì pé ká fara dà á. Àwọn ìṣòro wo lò ń dojú kọ báyìí? Ṣé àìsàn tó le koko tó ń ṣe ẹ́ tí kò jẹ́ kó o lè ṣe tó bó o ṣe fẹ́ nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ló mú kó o sorí kọ́? Àbí olólùfẹ́ rẹ tẹ́ ẹ ti jọ wà tipẹ́tipẹ́ ló ti di èrò Ṣìọ́ọ̀lù, ìyẹn ọ̀tá tí ò ṣeé tẹ́ lọ́rùn táráyé ní? (Òwe 30:15, 16) Ṣó dà bíi pé gbogbo ìsapá rẹ láti wa ẹni tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà bíi tìẹ fi ṣaya tàbí ṣọkọ ló ń já sí pàbó bó o ti ń fòótọ́ inú ṣègbọràn sí ìlànà Ìwé Mímọ́ pé kó o fẹ́ ọkọ tàbí aya kìkì nínú Olúwa? (1 Kọ́r. 7:39) Ṣé ńṣe lò ń gbìyànjú láti tọ́ àwọn ọmọ rẹ nínú ayé tí ipò ìṣúnná owó ò ti fi bẹ́ẹ̀ rọgbọ yìí? Ìṣòro yòówù kó o ní, tó o bá ti ń fi ire Ìjọba Ọlọ́run sí ipò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé rẹ, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà kò ní “gbàgbé iṣẹ́ [rẹ] àti ìfẹ́ tí [o] fi hàn fún orúkọ rẹ̀.” Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, ẹ jọ̀wọ́ “ẹ má ṣe . . . juwọ́ sílẹ̀ ní ṣíṣe ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀”!—Héb. 6:10; Gál. 6:9.
Kí ló lè ràn yín lọ́wọ́ láti fara da ìṣòro? Bíi tàwọn ará tó wà ní Tẹsalóníkà, “ìrètí yín nínú Olúwa wa Jésù Kristi” ló lè ràn yín lọ́wọ́. Pọ́ọ̀lù ní ìdí tó lágbára láti fi “ìrètí ìgbàlà” wé àṣíborí tó lágbára tó lè dáàbò bo àwọn Kristẹni kúrò lọ́wọ́ èròkérò àti iyèméjì tí kì í kúrò lọ́pọlọ bọ̀rọ̀.—1 Tẹs. 5:8.
Ká sòótọ́, tẹ́ ẹ bá ń fi tayọ̀tayọ̀ fara da àdánwò ńṣe lẹ̀ ń fún Sátánì lésì lórí ọ̀ràn ẹni tó yẹ kó jẹ́ ọba aláṣẹ ayé òun ọ̀run. Sátánì sọ pé onímọtara-ẹni-nìkan kúkú làwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run, bí wọ́n bá tiẹ̀ fẹ́ sìn ín, fún àkókò díẹ̀ ni, torí tí ìṣòro tó pọ̀ bá dé bá wọn tàbí tí òpin ètò àwọn nǹkan yìí bá pẹ́ ju bí wọ́n ti rò lọ, ńṣe ni wọ́n máa dẹwọ́ nínú ìjọsìn wọn sí Ọlọ́run. O láǹfààní láti fi èṣù hàn bí òpùrọ́ tó yẹ lẹ́ni ẹ̀gàn! Bójúmọ́ ṣe ń mọ́ lò ń sún mọ́ ìgbà táwọn ohun tó o ti ń retí máa nímùúṣẹ.
Bí Pọ́ọ̀lù ṣe lo àwọn àǹfààní tó ní láti gbóríyìn fáwọn arákùnrin rẹ̀ torí ìgbàgbọ́ wọn tó lágbára, ìtìlẹyìn àtọkànwá tí wọ́n ń ṣe fún iṣẹ́ ìwàásù àti ìfaradà wọn làwa náà ṣe lo àǹfààní yìí láti gbóríyìn fún yín tá a sì ń jẹ́ kẹ́ ẹ mọ̀ pé a nífẹ̀ẹ́ yín gan-an. Ẹ má ṣe dẹwọ́ nínú iṣẹ́ rere yín o!
Ìfẹ́ wa ni pé kí ọdún tó ń bọ̀ yìí kún fún àwọn ìbùkún tẹ̀mí ní àkúnwọ́sílẹ̀. A ní ire yín lọ́kàn gan-an ni.
Àwa arákùnrin yín,
Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà