-
Ṣé Oṣù December Ni Wọ́n Bí Jésù?Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
-
-
ÀFIKÚN
Ṣé Oṣù December Ni Wọ́n Bí Jésù?
BÍBÉLÌ ò sọ ìgbà tí wọ́n bí Jésù fún wa. Àmọ́, ó sọ àwọn ohun kan tó jẹ́ ká mọ̀ pé wọn ò bí Jésù ní oṣù December.
Ìwọ wo bí ojú ọjọ́ ṣe máa ń rí ní oṣù December ní ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù tí wọ́n bí Jésù sí. Nínú kàlẹ́ńdà àwọn Júù, oṣù Chislev (tó jẹ́ apá kan November àti apá kan December nínú kàlẹ́ńdà tiwa) jẹ́ oṣù tí òjò máa ń rọ̀ tí òtútù sì máa ń mú ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Oṣù tó máa ń tẹ̀ lé ìyẹn ni oṣù Tebeth (tó jẹ́ apá kan December àti apá kan January nínú kàlẹ́ńdà tiwa). Oṣù yìí ni òtútù ti máa ń mú jù nínú ọdún, kódà yìnyín máa ń já bọ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan láwọn ibi tó jẹ́ ilẹ̀ olókè. Jẹ́ ká wo ohun tí Bíbélì sọ fún wa nípa bí ojú ọjọ́ àgbègbè Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ṣe máa ń rí.
Ẹ́sírà tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì fi hàn pé òótọ́ ni òjò máa ń rọ̀ tí òtútù sì máa ń mú ní oṣù Chislev. Lẹ́yìn tí Ẹ́sírà sọ pé ọ̀pọ̀ èèyàn pé jọ ní Jerúsálẹ́mù “ní oṣù kẹsàn-án [ìyẹn oṣù Chislev] ní ogúnjọ́ oṣù náà,” ó wá ròyìn pé àwọn èèyàn náà “ń gbọ̀n nítorí . . . ọ̀wààrà òjò.” Kódà àwọn èèyàn tó pé jọ náà sọ nípa bí ojú ọjọ́ ṣe rí lákòókò yẹn, wọ́n ní: ‘Àsìkò ọ̀wààrà òjò ni, kò sì ṣeé ṣe láti dúró lóde.’ (Ẹ́sírà 10:9, 13; Jeremáyà 36:22) Abájọ tó fi jẹ́ pé àwọn olùṣọ́ àgùntàn tó wà lágbègbè Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ò lè ṣe kí wọ́n máà kó àwọn àgùntàn wọn wọlé lálẹ́ ní oṣù December!
Àmọ́, Bíbélì sọ pé àwọn olùṣọ́ àgùntàn ń tọ́jú àwọn àgùntàn wọn ní ìta lálẹ́ ọjọ́ tí wọ́n bí Jésù. Kódà, Lúùkù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì fi hàn pé lákòókò náà, àwọn olùṣọ́ àgùntàn ‘ń gbé ní ìta, wọ́n sì ń ṣọ́ àwọn agbo ẹran wọn ní òru’ nítòsí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. (Lúùkù 2:8-12) Kíyè sí i pé ńṣe làwọn olùṣọ́ àgùntàn ń gbé ní ìta, kì í kàn án ṣe pé wọ́n ǹ rìn kiri níta lọ́sàn-án. Àwọn àgùntàn wọn wà lọ́dọ̀ wọn ní pápá ní òru. Tó bá jẹ́ pé oṣù December tí òtútù máa ń mú gan-an tí òjò sì máa ń rọ̀ ni, ǹjẹ́ àwọn olùṣọ́ àgùntàn á lè wà níta lóru? Rárá. Nítorí náà, bí ipò ojú ọjọ́ ṣe rí lákòókò tí wọ́n bí Jésù fi hàn pé kì í ṣe oṣù December ni wọ́n bí i.a
Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ ìgbà tí Jésù kú gan-an fún wa, àmọ́ kò sọ ìgbà náà gan-an tí wọ́n bí i, ńṣe ló kàn sọ àwọn nǹkan tá a lè gùn lé láti mọ ìgbà tí wọ́n bí i. Èyí mú ká rántí ohun tí Ọba Sólómọ́nì sọ, pé: “Orúkọ sàn ju òróró dáradára, ọjọ́ ikú sì sàn ju ọjọ́ tí a bíni lọ.” (Oníwàásù 7:1) Nítorí náà, kò yà wá lẹ́nu pé Bíbélì sọ ọ̀pọ̀ nǹkan fún wa nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù àti ikú rẹ̀, nígbà tó sì jẹ́ pé nǹkan díẹ̀ ló sọ fún wa nípa ìgbà tí wọ́n bí i.
Nígbà tí wọ́n bí Jésù, àwọn olùṣọ́ àgùntàn àtàwọn àgùntàn wọn wà ní pápá ní òru
-
-
Ǹjẹ́ Ó Yẹ Ká Máa Ṣe Ọdún àti Àwọn Ayẹyẹ Kan?Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
-
-
ÀFIKÚN
Ǹjẹ́ Ó Yẹ Ká Máa Ṣe Ọdún àti Àwọn Ayẹyẹ Kan?
INÚ Bíbélì kọ́ ni ọ̀pọ̀ ayẹyẹ àti ọdún táwọn èèyàn ń ṣe jákèjádò ayé lónìí ti wá. Ibo wá nirú àwọn ọdún àti ayẹyẹ bẹ́ẹ̀ ti wá? Tó o bá láǹfààní láti lọ ṣe ìwádìí ní ilé ìkówèésí kan, wàá rí i pé àwọn ìwé kan tọ́ka sí ibi tí àwọn ọdún àti ayẹyẹ tó gbajúmọ̀ lágbègbè rẹ ti wá. Wo àpẹẹrẹ díẹ̀.
Ọdún Àjíǹde. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Britannica sọ pé: “Nínú Májẹ̀mú Tuntun, kò sóhun tó fi hàn pé ẹnikẹ́ni kan ṣe Ọdún Àjíǹde.” Báwo wá ni Ọdún Àjíǹde ṣe bẹ̀rẹ̀? Inú ìjọsìn àwọn Kèfèrí ló ti bẹ̀rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tó ń ṣe Ọdún Àjíǹde máa ń sọ pé àjíǹde Jésù làwọn fi ń rántí, inú ìsìn Kristẹni kọ́ làwọn àṣà tó máa ń bá Ọdún náà rìn ti wá. Bí àpẹẹrẹ, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Catholic Encyclopedia sọ nípa àṣà “Ehoro ìgbà ọdún Àjíǹde” tó gbajúmọ̀ láwọn ibì kan, ó ní: “Àwọn Kèfèrí ló máa ń lo ehoro nínú ìsìn wọn, tipẹ́tipẹ́ ni wọ́n sì ti máa ń lo ehoro gẹ́gẹ́ bí àmì ìbímọlémọ.”
Ayẹyẹ Ọdún Tuntun. Ọjọ́ tí orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan máa ń ṣe ọdún tuntun kì í dọ́gba, bẹ́ẹ̀ ni àwọn àṣà tó máa ń bá ọdún náà rìn ní orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan máa ń yàtọ̀ síra wọn. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia sọ̀rọ̀ nípa bí Ọdún tuntun ṣe bẹ̀rẹ̀, ó ní: “Ní ọdún 46 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, alákòóso Róòmù tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Julius Caesar yan ọjọ́ kìíní oṣù kìíní ọdún gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí wọ́n á máa ṣe ayẹyẹ Ọdún Tuntun. Janus tó jẹ́ ọlọ́run ibodè, ọlọ́run ilẹ̀kùn àti ọlọ́run ìbẹ̀rẹ̀ làwọn ará Róòmù ń fi ọjọ́ ọdún tuntun júbà. Janus ní orí méjì, ọ̀kan kọjú síwájú, èkejì sì kọjú sí ẹ̀yìn. Inú orúkọ Janus tí wọ́n kà sí ọlọ́run yìí sì ni wọ́n ti mú orúkọ oṣù kìíní ọdún, tá à ń pè ní January, jáde.” Nítorí náà, inú àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn Kèfèrí ni ayẹyẹ Ọdún Tuntun ti wá.
Halloween. Ayẹyẹ yìí ló dà bí ayẹyẹ ọdún eégún tí wọ́n fi ń ṣèrántí àwọn tó ti kú, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopedia Americana sì sọ nípa rẹ̀ pé: “A lè tọpasẹ̀ àwọn ohun tó wà nínú àṣà ayẹyẹ Halloween lọ sí ayẹyẹ Druid [tó jẹ́ àlùfáà ìsìn àwọn ẹ̀yà Celt ayé àtijọ́] tí wọ́n máa ń ṣe ṣáájú àkókò Kristẹni. Àwọn ẹ̀yà Celt máa ń fi ayẹyẹ yìí júbà ọlọ́run méjì, ìyẹn ọlọ́run oòrùn àti ọlọ́run àwọn òkú . . . , tí àwọn ẹ̀yà Celt máa ń ṣe ayẹyẹ rẹ̀ ní ọjọ́ kìíní oṣù November tó jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ọdún tuntun tiwọn. Díẹ̀díẹ̀ ni ayẹyẹ tí wọ́n fi ń rántí àwọn tó ti kú wọnú àwọn ayẹyẹ Kristẹni.”
Àwọn Ayẹyẹ àti Ọdún Mìíràn. Kò ṣeé ṣe láti sọ gbogbo ọdún àti ayẹyẹ táwọn èèyàn máa ń ṣe jákèjádò ayé. Àmọ́, Jèhófà ò lè tẹ́wọ́ gba ọdún àti ayẹyẹ èyíkéyìí tó jẹ́ pé èèyàn tàbí àjọ kan ni wọ́n fi ń gbé ga o. (Jeremáyà 17:5-7; Ìṣe 10:25, 26) Sì fi sọ́kàn pé, ibi tí ayẹyẹ ìsìn kan bá ti wá ló máa pinnu, bóyá Ọlọ́run á tẹ́wọ́ gbà á tàbí kò ní tẹ́wọ́ gbà á. (Aísáyà 52:11; Ìṣípayá 18:4) Àwọn ìlànà Bíbélì tó wà ní Orí Kẹrìndínlógún ìwé yìí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ kó o lè mọ irú ojú tí Ọlọ́run fi ń wo àwọn ayẹyẹ tí kì í ṣe ti ìsìn pẹ̀lú.
-