“Lọ Káàkiri La Ilẹ̀ Náà Já”
“Lọ káàkiri la ilẹ̀ náà já ní gígùn rẹ̀ àti ní ìbú rẹ̀.”—Jẹ́nẹ́sísì 13:17.
1. Ìtọ́ni wo ni Ọlọ́run fún Ábúráhámù?
ǸJẸ́ o máa ń gbádùn gbígbafẹ́ kiri, bóyá kó o máa wa ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rẹ láti ibì kan dé ibòmíràn ní òpin ọ̀sẹ̀? Kẹ̀kẹ́ láwọn ẹlòmíràn máa ń gùn láti fi dára yá, kí wọ́n lè rí gbogbo ohun tó wà ní àyíká wọn dáadáa. Àwọn ẹlòmíràn sì wà tó jẹ́ pé ìrìn fàájì làwọn máa ń fẹ́ rìn káàkiri kí wọ́n lè mọ àgbègbè kan dáadáa. Irú ìrìn afẹ́ bẹ́ẹ̀ kì í sábà jẹ́ èyí tó gùn lọ títí. Àmọ́ fojú inú wo ohun tó ní láti wá sọ́kàn Ábúráhámù lẹ́yìn tí Ọlọ́run sọ fún un pé: “Dìde, lọ káàkiri la ilẹ̀ náà já ní gígùn rẹ̀ àti ní ìbú rẹ̀, nítorí pé ìwọ ni èmi yóò fi í fún”!—Jẹ́nẹ́sísì 13:17.
2. Ibo ni Ábúráhámù lọ lẹ́yìn tó kúrò ní Íjíbítì?
2 Gbé àyíká àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn yẹ̀ wò. Ábúráhámù àti ìyàwó rẹ̀ àtàwọn yòókù gbé ní Íjíbítì fúngbà díẹ̀. Jẹ́nẹ́sísì orí kẹtàlá sọ fún wa pé wọ́n kúrò ní Íjíbítì, wọ́n sì kó agbo ẹran wọn lọ sí “Négébù.” Ẹ̀yìn ìyẹn ni Ábúráhámù wá “mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n lọ láti ibùdó sí ibùdó jáde kúrò ní Négébù àti sí Bẹ́tẹ́lì.” Nígbà tí awuyewuye kan wáyé láàárín àwọn darandaran tirẹ̀ àti ti Lọ́ọ̀tì ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀, tí wọ́n sì wá rí i pé àwọn méjèèjì ní láti wá pápá ìjẹko ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ fún àwọn ẹran ọ̀sìn wọn, ẹ̀mí ọ̀làwọ́ tí Ábúráhámù ní ló mú kó sọ fún Lọ́ọ̀tì pé kó yan ibi tó wù ú. Lọ́ọ̀tì yan “Àgbègbè Jọ́dánì,” ìyẹn àfonífojì ọlọ́ràá tó dà “bí ọgbà Jèhófà,” nígbà tó sì yá ó lọ ń gbé ní Sódómù. Ọlọ́run sọ fún Ábúráhámù pé: “Gbé ojú rẹ sókè, jọ̀wọ́, kí o sì wo ìhà àríwá àti ìhà gúúsù àti ìhà ìlà-oòrùn àti ìhà ìwọ̀-oòrùn, láti ibi tí o wà.” Ó lè jẹ́ pé ibi gíga kan ní Bẹ́tẹ́lì ni Ábúráhámù dúró sí tó fi rí àwọn ibi tó kù lára ilẹ̀ náà. Síbẹ̀, ohun tó máa ṣe ṣì kù. Ọlọ́run sọ fún un pé kó “lọ káàkiri la ilẹ̀ náà já,” kó lè mọ bí ilẹ̀ náà àtàwọn àgbègbè rẹ̀ ṣe rí.
3. Kí nìdí tó fi lè ṣòro fún wa láti fọkàn yàwòrán àwọn ibi tí Ábúráhámù rìnrìn àjò dé?
3 Ibi yòówù kí Ábúráhámù rìn dé ní ilẹ̀ náà kó tó dé Hébúrónì, ó dájú pé ó mọ Ilẹ̀ Ìlérí náà dáadáa ju bí ọ̀pọ̀ ju lọ wa ṣe mọ̀ ọ́n. Ronú nípa àwọn ibi tí àkọsílẹ̀ náà mẹ́nu kan—Négébù, Bẹ́tẹ́lì, Àgbègbè Jọ́dánì, Sódómù, àti Hébúrónì. Ǹjẹ́ ó ṣòro fún ọ láti fọkàn yàwòrán ibi tí àwọn àgbègbè yẹn wà? Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ṣòro fún láti ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí pé ìwọ̀nba díẹ̀ lára àwọn èèyàn Jèhófà ló tíì lọ sáwọn ibi tí wọ́n ń kà nípa rẹ̀ nínú Bíbélì, kí wọ́n rin ìbú àtòòró ilẹ̀ náà já. Síbẹ̀síbẹ̀, ìdí wà fún wa láti fẹ́ mọ̀ nípa àwọn ibi tí Bíbélì mẹ́nu kan. Kí nìdí?
4, 5. (a) Báwo ni Òwe 18:15 ṣe wé mọ́ ìmọ̀ àti òye nípa àwọn ilẹ̀ tí Bíbélì mẹ́nu kàn? (b) Kí ni Sefanáyà orí kejì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀?
4 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Ọkàn-àyà olóye ń jèrè ìmọ̀, etí àwọn ọlọ́gbọ́n sì ń wá ọ̀nà láti rí ìmọ̀.” (Òwe 18:15) Èèyàn lè nímọ̀ ọ̀pọ̀ nǹkan, àmọ́ ìmọ̀ pípéye nípa Jèhófà Ọlọ́run àti bó ṣe ń ṣe àwọn nǹkan rẹ̀ ni ìmọ̀ tó ṣe pàtàkì jù lọ. Ó sì dájú pé ohun tí àwọn nǹkan tá a ń kà nínú Bíbélì dá lé lórí gan-an nìyẹn. (2 Tímótì 3:16) Àmọ́ o, tún kíyè sí i pé ó gba pé kéèyàn ní òye. Ìyẹn ni pé kéèyàn lágbára láti mọ bí ohun kan ṣe rí, kó lè fòye mọ ìsopọ̀ tó wà láàárín apá kọ̀ọ̀kan rẹ̀ àti gbogbo rẹ̀ lódindi. Bí ọ̀rọ̀ àwọn ibi tí Bíbélì mẹ́nu kan ṣe rí gan-an nìyẹn. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ jù lọ wa ló mọ ibi tí Íjíbítì wà, àmọ́ ǹjẹ́ a fi bẹ́ẹ̀ lóye ọ̀rọ̀ tí Bíbélì sọ pé Ábúráhámù kúrò ní Íjíbítì “lọ sí Négébù,” lẹ́yìn náà ó lọ sí Bẹ́tẹ́lì, kó tó wá forí lé Hébúrónì? Ǹjẹ́ o mọ bí àwọn ilẹ̀ wọ̀nyẹn ṣe jìnnà sí ara wọn tó?
5 Ó ṣeé ṣe kó o ti ka Sefanáyà orí kejì nínu ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bíbélì kíkà rẹ. Ibẹ̀ lo ti kà nípa orúkọ àwọn ìlú, àwọn èèyàn, àtàwọn ilẹ̀. Orí kan ṣoṣo yìí dárúkọ àwọn ìlú bíi Gásà, Áṣíkẹ́lónì, Áṣídódì, Ékírónì, Sódómù, àti Nínéfè, títí kan Kénáánì, Móábù, Ámónì, àti Asíríà. Mélòó nínú ibi táwọn èèyàn ayé ìgbà yẹn gbé wọ̀nyí lo lè fọkàn yàwòrán rẹ̀, ìyẹn àwọn èèyàn tí àsọtẹ́lẹ̀ tí Ọlọ́run sọ ṣẹ sí lára?
6. Kí ló mú kí àwọn Kristẹni kan ka àwòrán ilẹ̀ sí pàtàkì? (Wo àpótí.)
6 Ọ̀pọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló ti jàǹfààní púpọ̀ nípa yíyẹ àwòrán àwọn ilẹ̀ tí Bíbélì mẹ́nu kàn wò. Kì í ṣe pé ìfẹ́ tí wọ́n ní sí wíwo àwòrán ilẹ̀ ló fà á tí wọ́n fi ń ṣe bẹ́ẹ̀ o, bí kò ṣe nítorí rírí tí wọ́n rí i pé lílo àwòrán ilẹ̀ á fi kún ìmọ̀ táwọn ní nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àwọn àwòrán ilẹ̀ tún lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fi kún òye wọn, nígbà tí wọ́n bá rí i bí àwọn ohun tí wọ́n mọ̀ tẹ́lẹ̀ ṣe wé mọ́ àwọn ìsọfúnni mìíràn. Bá a bá ṣe ń gbé àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò, ó ṣeé ṣe kí ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà túbọ̀ pọ̀ sí i, kó o sì túbọ̀ ní òye kíkún nípa àwọn ohun tó wà nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀.—Wo àpótí tó wà ní ojú ìwé 14.
Mímọ Bí Àwọn Ilẹ̀ Náà Ṣe Jìnnà Síra Tó Lè Mú Kí Òye Rẹ Pọ̀ Sí I
7, 8. (a) Ohun àgbàyanu wo ni Sámúsìnì ṣe tó kan Gásà? (b) Ìsọfúnni wo ló jẹ́ ká túbọ̀ mọ̀ pé itú ńlá ni Sámúsìnì pa? (d) Báwo ni ìmọ̀ àti òye àkọsílẹ̀ yìí nípa Sámúsìnì ṣe lè ràn wá lọ́wọ́?
7 O lè kà nípa ìgbà tí Sámúsìnì Onídàájọ́ wà ní Gásà nínú ìwé Àwọn Onídàájọ́ 16:2. Lónìí, orúkọ ìlú Gásà ò ṣàjèjì nínú àwọn ìròyìn, ìyẹn lè jẹ́ kó o mọ apá ibi tí Sámúsìnì wà ní ilẹ̀ àwọn ará Filísínì nítòsí Etíkun Mẹditaréníà. [gl 11] Wàyí o, kíyè sí ohun tí Àwọn Onídàájọ́ 16:3 sọ, ó ní: “Sámúsìnì ń bá a nìṣó ní dídùbúlẹ̀ títí di ọ̀gànjọ́ òru, ó sì wá dìde ní ọ̀gànjọ́ òru, ó sì gbá àwọn ilẹ̀kùn ẹnubodè ìlú ńlá náà mú àti àwọn arópòódògiri ẹ̀gbẹ́ méjèèjì, ó sì fà wọ́n tu pa pọ̀ pẹ̀lú ọ̀pá ìdábùú rẹ̀, ó sì gbé wọn sórí èjìká rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé wọn gòkè lọ sí orí òkè ńlá tí ó wà níwájú Hébúrónì.”
8 Láìsí àní-àní, àwọn ilẹ̀kùn ẹnubodè àtàwọn arópòódògiri ìlú olódi bíi Gásà tóbi ó sì wúwo. Bí wọ́n ṣe tóbi tó yẹn, kí ẹnì kan wá lóun fẹ́ gbé wọn! Sámúsìnì ṣe bẹ́ẹ̀ o, àmọ́ ibo ló ti gbé wọn, àti pé irú ìrìn àjò wo gan-an ló rìn? Ṣé o rí i, etíkun ni Gásà wà ní dédé ìtẹ́jú òkun. [15] Àmọ́, Hébúrónì wà ní ìhà ìlà oòrùn tó gá tó ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án mítà—ó dájú pé ìyẹn á gba pé kéèyàn pọ́nkè gan-an! A ò mọ ọ̀gangan ibi tí “òkè ńlá tí ó wà níwájú Hébúrónì” wà, àmọ́ ìlú Hébúrónì fúnra rẹ̀ wà ní nǹkan bí ọgọ́ta kìlómítà sí Gásà. Ibi tí ìlú yẹn wà mà ga sókè gan-an o! Ǹjẹ́ bá a ṣe mọ bó ṣe jìnnà tó yẹn ò jẹ́ kó túbọ̀ yé wa pé itú ńlá gidi ni Sámúsìnì pa? Rántí pé ohun tó mú kí Sámúsìnì lè ṣe ohun tó ṣe yẹn ni pé, “Ẹ̀mí Jèhófà . . . bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ lára rẹ̀.” (Àwọn Onídàájọ́ 14:6,19; 15:14) Àwa tá a jẹ́ Kristẹni lóde òní ò retí pé kí ẹ̀mí Ọlọ́run fún wa ní agbára àrà ọ̀tọ̀ kan. Àmọ́, ẹ̀mí tó lágbára kan náà yẹn lè mú ká túbọ̀ ní òye nípa àwọn nǹkan tẹ̀mí kó sì sọ wá di alágbára ńlá ní ìbámu pẹ̀lú ẹni tá a jẹ́ ní inú. (1 Kọ́ríńtì 2:10-16; 13:8; Éfésù 3:16; Kólósè 1:9, 10) Bẹ́ẹ̀ ni o, tá a bá lóye ìtàn Sámúsìnì, yóò dá wa lójú pé ẹ̀mí Ọlọ́run lè ran àwa náà lọ́wọ́.
9, 10. (a) Kí làwọn nǹkan tó wé mọ́ ìṣẹ́gun Gídíónì lórí àwọn ará Mídíánì? (b) Báwo ni ìmọ̀ tá a ní nípa bí àwọn ilẹ̀ náà ṣe rí ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ lóye ìtàn yìí dáadáa?
9 Ìṣẹ́gun Gídíónì lórí àwọn ará Mídíánì tún jẹ́ àkọsílẹ̀ mìíràn tó jẹ́ ká rí ìjẹ́pàtàkì mímọ bí ilẹ̀ kan ṣe jìnnà sí òmíràn tó. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó ń ka Bíbélì ló mọ̀ pé Gídíónì Onídàájọ́ àtàwọn ọ̀ọ́dúnrún ẹmẹ̀wà rẹ̀ ṣẹ́gun àwọn ọmọ ogun tó para pọ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́fà ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàájọ [135,000], ìyẹn àwọn ará Mídíánì, àwọn ọmọ Ámálékì àtàwọn mìíràn tí wọ́n jùmọ̀ pabùdó sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jésíréélì nítòsí òkè Mórè. [18] Àwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú Gídíónì fun ìwo, wọ́n fọ́ àwọn ìṣà omi túútúú káwọn èèyàn lè rí àwọn ògùṣọ̀ wọn, wọ́n sì kígbe pé: “Idà Jèhófà àti ti Gídíónì!” Èyí kó ṣìbáṣìbo àti ìjayà bá àwọn ọ̀tá tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi idà pa ara wọn. (Àwọn Onídàájọ́ 6:33; 7:1-22) Ṣé gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ náà nìyẹn, tí wọ́n kàn sáré ṣe lóru ọjọ́ náà? Máa ka ìtàn náà lọ nínú Àwọn Onídàájọ́ orí keje àti ìkẹjọ. Wàá rí i pé Gídíónì ò padà lẹ́yìn àwọn ọ̀tá náà. Àwọn kan lára ọ̀pọ̀ ibi tí Bíbélì mẹ́nu kàn yẹn la ò lè mọ ọ̀gangan ibi tí wọ́n wà mọ́ lóde òní, nítorí náà, a lè máà rí wọ́n nínú àwòrán àwọn ilẹ̀ tí Bíbélì mẹ́nu kàn. Síbẹ̀ náà, àwọn ilẹ̀ tá a fi hàn níbẹ̀ pọ̀ tó fún wa láti mọ àwọn ohun tí Gídíónì ṣe.
10 Gídíónì lé ìyókù ẹgbẹ́ ọmọ ogun náà kọjá Bẹti-ṣítà, ẹ̀yìn ìyẹn ló lé wọn gba ìhà gúúsù lọ sí Ebẹli-Méhólà, nítòsí Jọ́dánì. (Àwọn Onídàájọ́ 7:22-25) Àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Gídíónì wá sí Jọ́dánì, wọ́n sọdá rẹ̀, òun àti ọ̀ọ́dúnrún ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, ó ti rẹ̀ wọ́n ṣùgbọ́n wọ́n ń bá ìlépa náà nìṣó.” Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọdá odò Jọ́dánì, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í lépa àwọn ọ̀tá náà gba ìhà gúúsù lọ sí Súkótù àti Pénúélì, nítòsí Jábókù, wọ́n tún wá lé wọn gba orí òkè lọ sí Jógíbéhà (nítòsí ìlú Ámánì, ní orílẹ̀-èdè Jọ́dánì òde òní). Ìyẹn ni pé ibi tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́rin kìlómítà ni wọ́n lépa àwọn ọ̀tá náà dé tí wọ́n sì ń bá wọn jà. Ọwọ́ Gídíónì tẹ àwọn ọba Mídíánì méjèèjì; ó sì pa wọ́n, ẹ̀yìn ìyẹn ló wá padà sí Ọ́fírà, ìlú rẹ̀, nítòsí ibi tí ìjà náà ti bẹ̀rẹ̀. (Àwọn Onídàájọ́ 8:4-12, 21-27) Ó hàn gbangba pé itú tí Gídíónì pa kọjá fífun ìwo, jíju àwọn ògùṣọ̀, àti kíkígbe, fún ìṣẹ́jú díẹ̀. Tún ronú lórí bó ṣe jẹ́ kí ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ọkùnrin ìgbàgbọ́ túbọ̀ wọni lọ́kàn sí i, Bíbélì ní: “Àkókò kì yóò tó fún mi bí mo bá ń bá a lọ láti ṣèròyìn nípa Gídíónì [àtàwọn mìíràn tó jẹ́ pé] láti ipò àìlera, a sọ wọ́n di alágbára, wọ́n di akíkanjú nínú ogun.” (Hébérù 11:32-34) Ó lè rẹ àwa Kristẹni náà, àmọ́ ǹjẹ́ kò ṣe pàtàkì pé ká máa bá ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run nìṣó?—2 Kọ́ríńtì 4:1, 16; Gálátíà 6:9.
Báwo ni Èrò àti Ìṣe Àwọn Èèyàn Ṣe Máa Ń Rí?
11. Ìrìn àjò wo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì rìn kí wọ́n tó dé Kádéṣì àti lẹ́yìn tí wọ́n kúrò níbẹ̀?
11 Àwọn kan lè ṣí ìwé àwòrán àwọn ilẹ̀ tó wà nínú Bíbélì kí wọ́n lè mọ ibi tí àwọn ilẹ̀ náà wà, àmọ́ ǹjẹ́ o rò pé àwòrán ilẹ̀ lè mú ká mọ bí àwọn èèyàn ṣe ń ronú? Fi ọ̀ràn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣàpẹẹrẹ, wọ́n gbéra láti Òkè Sínáì wọ́n sì kọrí sí Ilẹ̀ Ìlérí. Wọ́n tẹsẹ̀ dúró láwọn ibi kan lójú ọ̀nà, lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn wọ́n dé Kádéṣì (tàbí Kadeṣi-báníà). [gl 9] Diutarónómì 1:2 sọ pé ìrìn ọjọ́ mọ́kànlá gbáko lèyí, ó sì jẹ́ nǹkan bíi igba ó lé àádọ́rin [270] kìlómítà. Àtibẹ̀ ni Mósè ti rán àwọn amí méjìlá lọ sí Ilẹ̀ Ìlérí. (Númérì 10:12, 33; 11:34, 35; 12:16; 13:1-3, 25, 26) Àwọn amí náà gba Négébù lọ sí ìhà àríwá, ó sì ṣeé ṣe kí wọ́n gba Bíá-ṣébà, kí wọ́n tún gba Hébúrónì, títí wọ́n fi dé ibi tí Ilẹ̀ Ìlérí náà parí sí ní ìhà àríwá. (Númérì 13:21-24) Nítorí pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fara mọ́ ìròyìn búburú tí mẹ́wàá lára àwọn amí náà mú wá ni wọ́n ṣe fi ogójì ọdún rìn gbéregbère kiri nínú aginjù. (Númérì 14:1-34) Kí lèyí fi hàn nípa ìgbàgbọ́ wọn àti bí wọ́n ṣe múra tán láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà?—Diutarónómì 1:19-33; Sáàmù 78:22, 32-43; Júúdà 5.
12. Kí la lè sọ nípa ìgbàgbọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí sì nìdí tíyẹn fi jẹ́ ohun kan tó yẹ ká ronú lé lórí?
12 Wá fojú bí àwọn ilẹ̀ náà ṣe jìnnà tó síra wọn wò ó. Ǹjẹ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ì bá ti rìnrìn àjò tó jìnnà tó yẹn kí wọ́n tó dé Ilẹ̀ Ìlérí ká ní wọn ti lo ìgbàgbọ́ tí wọ́n sì tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Jóṣúà àti Kálébù? Nǹkan bíi kìlómítà mẹ́rìndínlógún ni Kádéṣì wà sí Bia-laháí-róì, níbi tí Ísákì àti Rèbékà gbé nígbà kan rí. [gl 7] Kádéṣì ò tó kìlómítà márùndínlọ́gọ́rùn-ún sí Bíá-ṣébà tó wà ní ìhà gúúsù Ilẹ̀ Ìlérí. (Jẹ́nẹ́sísì 24:62; 25:11; 2 Sámúẹ́lì 3:10) Lẹ́yìn tí wọ́n gbéra ní Íjíbítì tí wọ́n sì dé Òkè Sínáì, tí wọ́n tún rin ìrìn igba ó lé àádọ́rin [270] kìlómítà dé Kádéṣì, èyí tó kù kí wọ́n wọ Ilẹ̀ Ìlérí ò tó nǹkan mọ́. Ní tiwa, a ti wà ní bèbè àtiwọ Párádísè ilẹ̀ ayé tí Ọlọ́run ṣèlérí rẹ̀. Ẹ̀kọ́ wo la wá lè rí kọ́? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù so ipò tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà nígbà yẹn mọ́ ìmọ̀ràn tó fún wa, pé: “Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a sa gbogbo ipá wa láti wọnú ìsinmi yẹn, kí ẹnikẹ́ni má bàa ṣubú sínú àpẹẹrẹ ọ̀nà àìgbọràn kan náà.”—Hébérù 3:16–4:11.
13, 14. (a) Inú ipò wo làwọn ará Gíbíónì ti gbé ìgbésẹ̀ tó mọ́gbọ́n dání? (b) Kí ló fi irú ẹ̀mí táwọn ará Gíbíónì ní hàn, ẹ̀kọ́ wo ló sì yẹ ká kọ́ látinú èyí?
13 Ìtàn tí Bíbélì sọ nípa àwọn ará Gíbíónì fi hàn pé ẹ̀mí tó yàtọ̀ pátápátá ni wọ́n ní, ìyẹn ẹ̀mí tó fi ìgbẹ́kẹ̀lé téèyàn ní hàn pé Ọlọ́run yóò mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ. Lẹ́yìn tí Jóṣúà kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì la Odò Jọ́dánì já sínú ilẹ̀ tí Ọlọ́run ṣèlérí fún ìdílé Ábúráhámù, àkókò wá tó wàyí láti lé àwọn ará Kénáánì kúrò níbẹ̀. (Diutarónómì 7:1-3) Àwọn ará Gíbíónì sì wà lára wọn. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti ṣẹ́gun Jẹ́ríkò àti Áì, wọ́n sì pabùdó sítòsí ibẹ̀ ní Gílígálì. Àwọn ará Gíbíónì ò fẹ́ kú bíi tàwọn ará Kénáánì tó jẹ́ ẹni ègún, ìdí nìyẹn tí wọ́n fi rán aṣojú lọ bá Jóṣúà ní Gílígálì. Wọ́n díbọ́n bí ẹni pé ibì kan tó jìnnà sí ìpínlẹ̀ àwọn ọmọ Kénáánì làwọn ti wá, kí àwọn Hébérù náà lè bá wọn ṣe àdéhùn àlàáfíà.
14 Àwọn aṣojú wọ̀nyẹn sọ pé: “Láti ilẹ̀ jíjìnnàréré ni àwa ìránṣẹ́ rẹ ti wá ní tìtorí orúkọ Jèhófà Ọlọ́run rẹ.” (Jóṣúà 9:3-9) Aṣọ ọrùn wọn àti oúnjẹ tí wọ́n mú dání fi hàn pé ibi tí wọ́n ti wá jìnnà, bẹ́ẹ̀ Gíbíónì ò ju nǹkan bíi ọgbọ̀n kìlómítà lọ sí Gílígálì. [gl 19] Jóṣúà àtàwọn ìjòyè rẹ̀ gbà wọ́n gbọ́, wọ́n sì ṣe àdéhùn àlàáfíà pẹ̀lú Gíbíónì àtàwọn ìlú tó so pọ̀ mọ́ Gíbíónì. Ṣé káwọn ará Gíbíónì má bàa kú nìkan ni wọ́n ṣe dá ọgbọ́n arúmọjẹ yìí? Rárá o, ó fi hàn pé ó wù wọ́n láti rí ojú rere Ọlọ́run Ísírẹ́lì. Jèhófà gbà kí àwọn ará Gíbíónì di “aṣẹ́gi àti apọnmi fún àpéjọ náà àti fún pẹpẹ Jèhófà,” kí wọ́n sì máa kó igi ìdáná wá síbi pẹpẹ ìrúbọ. (Jóṣúà 9:11-27) Àwọn ará Gíbíónì ń bá a lọ ní fífi hàn pé àwọn múra tán láti ṣe àwọn iṣẹ́ tí kò fi bẹ́ẹ̀ jọjú yẹn nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Ó ṣeé ṣe kí díẹ̀ lára wọn wà lára àwọn Nétínímù tó padà wá láti Bábílónì tí wọ́n sì bá wọn lọ́wọ́ sí títún tẹ́ńpìlì kọ́. (Ẹ́sírà 2:1, 2, 43-54; 8:20) A lè fara wé irú ẹ̀mí tí wọ́n ní nípa sísapá láti máa wà ní àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run ká sì múra tán láti tẹ́wọ́ gba àwọn iṣẹ́ tí kò fi bẹ́ẹ̀ jọni lójú nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀.
Ẹ Jẹ́ Ká Máa Lo Ara Wa Fáwọn Ẹlòmíràn
15. Kí nìdí tó fi yẹ ká fẹ́ láti mọ̀ nípa àwọn ilẹ̀ tí Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀?
15 Ẹ̀kọ́ nípa àwòrán àwọn ilẹ̀ tí Bíbélì mẹ́nu kàn tún kan àwọn àkọsílẹ̀ tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, irú bí àwọn ìrìn àjò tí Jésù rìn àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ àti ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. (Máàkù 1:38; 7:24, 31; 10:1; Lúùkù 8:1; 13:22; 2 Kọ́ríńtì 11:25, 26) Gbìyànjú láti fojú inú wo ibi tí àwọn ìrìn àjò tá a fẹ́ dẹ́nu lé yìí nasẹ̀ dé.
16. Báwo làwọn Kristẹni tó wà ní Bèróà ṣe fi hàn pé àwọn mọyì Pọ́ọ̀lù?
16 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù rin ìrìn àjò míṣọ́nnárì ẹlẹ́ẹ̀kejì (ìyẹn ìlà aláwọ àlùkò lórí àwòrán ilẹ̀), ó dé sí Fílípì, tó ti di ara orílẹ̀-èdè Gíríìsì báyìí. [gl 33] Ó jẹ́rìí níbẹ̀, ó ṣẹ̀wọ̀n níbẹ̀ wọ́n sì dá a nídè, ó wá forí lé Tẹsalóníkà látibẹ̀. (Ìṣe 16:6–17:1) Nígbà táwọn Júù dá rògbòdìyàn sílẹ̀, àwọn ará tó wà ní Tẹsalóníkà rọ Pọ́ọ̀lù pé kó máa lọ sí Bèróà, tó jẹ́ nǹkan bíi kìlómítà márùnlélọ́gọ́ta sí ibẹ̀. Iṣẹ́ òjíṣẹ́ Pọ́ọ̀lù kẹ́sẹ járí gan-an ní Bèróà, àmọ́ àwọn Júù tún wá kó sí àwọn ará ibẹ̀ nínú. Nítorí èyí, “àwọn ará rán Pọ́ọ̀lù jáde lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ láti lọ jìnnà títí dé òkun . . . àwọn tí ń sin Pọ́ọ̀lù lọ [sì] mú un wá títí dé Áténì.” (Ìṣe 17:5-15) Ó ní láti jẹ́ pé àwọn kan lára àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ di onígbàgbọ́ múra tán láti rìnrìn ogójì kìlómítà dé Òkun Aegean, wọ́n san owó ọkọ tí wọ́n wọ̀, wọ́n sì rìnrìn àjò nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] kìlómítà. Irú ìrìn àjò yẹn léwu, àmọ́ àwọn ará forí la ewu náà, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ pẹ́ díẹ̀ lọ́dọ̀ arìnrìn-àjò tó jẹ́ aṣojú fún Ọlọ́run yìí.
17. Kí la lè túbọ̀ mọrírì rẹ̀ nígbà tá a bá lóye bí Mílétù ṣe jìnnà sí Éfésù tó?
17 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù rin ìrìn àjò ẹlẹ́ẹ̀kẹta (ìlà aláwọ̀ ewé lórí àwòrán ilẹ̀), ó gúnlẹ̀ sí èbúté Mílétù. Ó ránṣẹ́ pe àwọn àgbà ọkùnrin tó wà nínú ìjọ Éfésù, tó jẹ́ nǹkan bí àádọ́ta kìlómítà sí ibẹ̀. Ńṣe làwọn alàgbà wọ̀nyẹn pa àwọn nǹkan mìíràn tí wọ́n ń ṣe tì, wọ́n sì lọ bá Pọ́ọ̀lù. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé bí wọ́n ṣe ń rìn lọ yẹn ni inú wọ́n ń dùn tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ nípa ìpàdé tí wọ́n fẹ́ lọ ṣe náà. Lẹ́yìn tí wọ́n bá Pọ́ọ̀lù ṣèpàdé tí wọ́n sì tún gbọ́ bó ṣe gbàdúrà, “ẹkún sísun tí kò mọ níwọ̀n bẹ́ sílẹ̀ láàárín gbogbo wọn, wọ́n sì rọ̀ mọ́ ọrùn Pọ́ọ̀lù, wọ́n sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́.” Lẹ́yìn náà, “wọ́n tẹ̀ síwájú láti sìn ín dé ìdí ọkọ̀ ojú omi” kó lè lọ sí Jerúsálẹ́mù. (Ìṣe 20:14-38) Ọ̀pọ̀ nǹkan ló máa wà fún wọn láti ronú lé lórí àti láti sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nígbà tí wọ́n ń padà lọ sí Éfésù. Ǹjẹ́ orí rẹ ò wú sí ìfẹ́ àti ìmọrírì tí wọ́n fi hàn nígbà tí wọ́n rìnrìn àjò tó jìnnà tó yẹn kí wọ́n lè dé ọ̀dọ̀ òjíṣẹ́ arìnrìn-àjò tó lè bá wọn sọ̀rọ̀ kó sì fún wọn níṣìírí? Ǹjẹ́ o rí ohun kan nínú àkọsílẹ̀ yìí tó o lè fi sílò kó o sì máa ronú lé lórí?
Kẹ́kọ̀ọ́ Nípa Ilẹ̀ Náà àti Ohun Tó Wà Níwájú
18. Kí la lè pinnu láti ṣe nípa àwọn ilẹ̀ tí Bíbélì mẹ́nu kàn?
18 Àwọn àpẹẹrẹ tá a gbé yẹ̀ wò wọ̀nyí fi hàn pé ó ṣe pàtàkì láti mọ ilẹ̀ tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yẹn ní àmọ̀dunjú, ó sì tún fi hàn pé mímọ àwọn ilẹ̀ ṣe pàtàkì gan-an láti lóye ọ̀pọ̀ àwọn àkọsílẹ̀ inú Bíbélì. (Á sì lè jẹ́ kí òye wa túbọ̀ gbòòrò sí i tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ilẹ̀ tí Bíbélì dárúkọ.) Bá a ṣe túbọ̀ ń fi kún ìmọ̀ àti òye wa nípa Ilẹ̀ Ìlérí náà ní pàtàkì, a ní láti rántí ohun pàtàkì kan táwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́dọ̀ ṣe kí wọ́n tó lè wọ ilẹ̀ tó kún fún “wàrà àti oyin” kí wọn sì gbádùn rẹ̀. Ohun pàtàkì náà ni pé kí wọ́n bẹ̀rù Jèhófà kí wọ́n sì máa pa àṣẹ rẹ̀ mọ́.—Diutarónómì 6:1, 2; 27:3.
19. Párádísè méjì wo ló yẹ ká máa ronú nípa rẹ̀ nígbà gbogbo?
19 Lónìí pẹ̀lú, a ní láti ṣe ipa tiwa, ká bẹ̀rù Jèhófà ká sì rọ̀ mọ́ àwọn ọ̀nà rẹ̀. Tá a bà ṣe bẹ́ẹ̀, a óò mú kí párádísè tẹ̀mí tó wà nínú ìjọ Kristẹni jákèjádò ayé nísinsìnyí túbọ̀ dára sí i kó sì túbọ̀ gbádùn mọ́ni. Ìmọ̀ wa nípa onírúurú ẹ̀ka párádísè tẹ̀mí yẹn àtàwọn ìbùkún inú rẹ̀ yóò sì túbọ̀ pọ̀ sí i. A sì tún mọ̀ pé ọ̀pọ̀ ìbùkún ṣì wà níwájú. Jóṣúà kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọdá odò Jọ́dánì, wọ́n sì dé ilẹ̀ ọlọ́ràá, tó dára gan-an náà. Ní báyìí, a ní ìdí tó ṣe gúnmọ́ láti máa fi ìdánilójú retí Párádísè nípa tara, ìyẹn ilẹ̀ dáradára náà tó wà níwájú fún wa.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Kí nìdí tó fi yẹ kó wù wá láti fi kún ìmọ̀ àti òye wa nípa àwọn ilẹ̀ tí Bíbélì mẹ́nu kàn?
• Nínú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ẹ̀kọ́ nípa àwọn ilẹ̀ tá a gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ yìí, èwo ló là ọ́ lóye jù lọ nínú wọn?
• Ẹ̀kọ́ wo lo túbọ̀ rí kọ́ bó o ṣe wá mọ bí àwọn ilẹ̀ tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan ti wáyé ṣe jìnnà síra wọn tó?
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
Wo “Ilẹ̀ Dáradára” Náà
Tayọ̀tayọ̀ ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi gba ìwé pẹlẹbẹ Wo “Ilẹ̀ Dáradára” Náà láwọn àpéjọ ti ọdún 2003 sí 2004. Ìwé tuntun yìí, tá a tẹ̀ jáde ní nǹkan bí ọgọ́rin èdè, kún fún àwọn àwòrán ilẹ̀ aláwọ̀ mèremère àti àtẹ ìsọfúnni tó ṣàpèjúwe onírúurú àgbègbè tí Bíbélì mẹ́nu kàn, àgàgà Ilẹ̀ Ìlérí náà láàárín àwọn àkókò tó yàtọ̀ síra.
Àpilẹ̀kọ tí àpótí yìí wà nínú rẹ̀ tọ́ka sí àwọn àwòrán ilẹ̀ pàtó kan nípa lílo àwọn nọ́ńbà ojú ewé tá a fi lẹ́tà dúdú kirikiri kọ, bíi [gl 15]. Tó o bá ní ìwé pẹlẹbẹ tuntun yìí, rí i pé ò ń kà á kó o lè mọ àwọn apá fífanimọ́ra inú rẹ̀ dunjú, èyí tó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti túbọ̀ fi kún ìmọ̀ àti òye rẹ nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
(1) Ọ̀pọ̀ àwòrán ilẹ̀ náà ló ní àkámọ́ kan tàbí àpótí tó ṣàlàyé àwọn àmì pàtàkì kan nínú àwòrán ilẹ̀ náà [gl 18]. (2) Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn àwòrán ilẹ̀ náà ló ni ìwọ̀n kan tó fi iye ibùsọ̀ àti kìlómítà tó máa jẹ́ kó o mọ bí àwọn ìlú náà ṣe tóbi tó hàn àti bí wọ́n ṣe jìnnà síra wọn tó [gl 26]. (3) Àmì ẹlẹ́nu ṣóńṣó kan wà níbẹ̀ tó tọ́ka sí àríwá, ìyẹn á jẹ́ kó o mọ ìhà tó o dojú kọ bó o ṣe ń wo àwòrán náà [gl 19]. (4) A kun àwọn àwòrán ilẹ̀ náà ní àwọ̀ mèremère láti fi bí ibi táwọn ilẹ̀ náà wà ṣe ga tó hàn [gl 12]. (5) Àwòrán ilẹ̀ kan lè ní álífábẹ́ẹ̀tì àti nọ́ńbà ní eteetí rẹ̀ kó o lè mọ bó o ṣe máa rí ibi tí àwọn ìlú kan àti orúkọ wọn wà [gl 23]. (6) Nínú ojú ewé méjì tí atọ́ka àwọn ibi tó wà nínú àwòrán ilẹ̀ náà wà [gl 34-35], wàá rí àwọn nọ́ńbà ojú ewé tá a fi lẹ́tà dúdú kirikiri kọ, tí álífábẹ́ẹ̀tì àti nọ́ńbà tá a kọ sẹ́gbẹ̀ẹ́ ara wọn tá a fi ń mọ ibi tí ìlú náà wà gan-an sì tẹ̀ lé e, bíi Ẹ2. Lẹ́yìn tó o bá lo ìwé yìí bá a ṣe ṣàlàyé rẹ̀ yìí fúngbà bíi mélòó kan, wàá rí i pe wọ́n lè ràn ọ́ lọ́wọ́ gan-an láti fi kún ìmọ̀ rẹ, òye rẹ nípa Bíbélì yóò sì túbọ̀ jinlẹ̀ sí i.
[Àtẹ Ìsọfúnnni/Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
ÀTẸ ÌSỌFÚNNI NÍPA ÀWỌN ÀGBÈGBÈ ILẸ̀ ÌLÉRÍ
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
A. Etí Òkun Ńlá
B. Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ìwọ̀ Oòrùn Jọ́dánì
1. Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Áṣérì
2. Ilẹ̀ Etíkun Dórì
3. Pápá Ìjẹko Ṣárónì
4. Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Filísíà
5. Àfonífojì Tó Bẹ̀rẹ̀ Láti Ìlà Oòrùn Lọ sí Ìwọ̀ Oòrùn
a. Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Mẹ́gídò
b. Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Rírẹlẹ̀ Jésíréélì
D. Àwọn Òkè Tó Wà ní Ìwọ̀ Oòrùn Jọ́dánì
1. Òkè Gálílì
2. Òkè Kámẹ́lì
3. Òkè Samáríà
4. Ṣẹ́fẹ́là (òkè kékeré)
5. Ilẹ̀ Olókè ti Júdà
6. Aginjù Júdà
7. Négébù
8. Aginjù Páránì
E. Árábà (Àfonífojì Ńlá)
1. Adágún Omi Húlà
2. Àgbègbè Òkun Gálílì
3. Àfonífojì Jọ́dánì
4. Òkun Iyọ̀ (Òkun Òkú)
5. Árábà (gúúsù Òkun Iyọ̀)
Ẹ. Àwọn Òkè àti Ilẹ̀ Títẹ́jú ní Ìlà Oòrùn Jọ́dánì
1. Báṣánì
2. Gílíádì
3. Ámónì àti Móábù
4. Òkè Olórí Pẹrẹsẹ ti Édómù
F. Àwọn Òkè Ńlá Lẹ́bánónì
[Àwòrán ilẹ̀]
Òkè Hámónì
Mórè
Ebẹli-méhólà
Súkótù
Jógíbéhà
Bẹ́tẹ́lì
Gílígálì
Gíbéónì
Jerúsálẹ́mù
Hébúrónì
Gásà
Bíá-ṣébà
Sódómù?
Kádéṣì
[Àwòrán ilẹ̀/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
KÉNÁÁNÌ
Mẹ́gídò
GÍLÍÁDÌ
Dótánì
Ṣékémù
Bẹ́tẹ́lì (Lúsì)
Áì
Jerúsálẹ́mù (Sálẹ́mù)
Bẹ́tílẹ́hẹ́mù (Éfúrátì)
Mámúrè
Hébúrónì (Mákípẹ́là)
Gérárì
Bíá-ṣébà
Sódómù?
NÉGÉBÙ
Réhóbótì?
[Àwọn òkè]
Móráyà
[Àwọn omi ńlá]
Òkun Iyọ̀
[Odò]
Jọ́dánì
[Àwòrán]
Ábúráhámù rin ilẹ̀ náà
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 18]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Tíróásì
SÁMÓTÍRÁSÌ
Neapólísì
Fílípì
Áńfípólì
Tẹsalóníkà
Bèróà
Áténì
Kọ́ríńtì
Éfésù
Mílétù
RÓDÉSÌ