ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 1/11 ojú ìwé 30
  • Bá A Ṣe Lè Máa Sọ̀rọ̀ Tó Mọ́gbọ́n Dání

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bá A Ṣe Lè Máa Sọ̀rọ̀ Tó Mọ́gbọ́n Dání
  • Jí!—2011
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹ Máa Fi Ìfẹ́ Àti Ọ̀wọ̀ Hàn Fún Ara Yín Nípa Kíkó Ahọ́n Yín Níjàánu
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ìgbàgbọ́ Ń sún Wa Ṣiṣẹ́!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Kí Ló Dé Tó Jẹ́ Ọ̀rọ̀ Tí Ò Dáa Ló Máa Ń Jáde Lẹ́nu Mi Ṣáá?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • ‘Ètè Òtítọ́ Yóò Dúró Títí Láé’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
Àwọn Míì
Jí!—2011
g 1/11 ojú ìwé 30

Bá A Ṣe Lè Máa Sọ̀rọ̀ Tó Mọ́gbọ́n Dání

‘Ǹ BÁ mọ̀ kí n ti má sọ ohun tí mo sọ yẹn o!’ Ǹjẹ́ o ti sọ irú ọ̀rọ̀ yìí rí? Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, kò rọrùn láti kó ahọ́n wa níjàánu. Bíbélì sọ pé, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ẹranko ni àwa èèyàn lè rọ̀ lójú, “ṣùgbọ́n ahọ́n, kò sí ẹnì kan nínú aráyé tí ó lè rọ̀ ọ́ lójú.” (Jákọ́bù 3:7, 8) Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé kò ṣeé ṣe láti kó ahọ́n wa níjàánu ni? Rárá o! Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn ìlànà Bíbélì kan yẹ̀ wò tó máa jẹ́ ká lè túbọ̀ ṣàkóso ẹ̀yà ara wa tó kéré, àmọ́ tí agbára rẹ̀ pọ̀ jọjọ yìí.

● “Nínú ọ̀pọ̀ yanturu ọ̀rọ̀ kì í ṣàìsí ìrélànàkọjá, ṣùgbọ́n ẹni tí ń ṣàkóso ètè rẹ̀ ń hùwà tòyetòye.” (Òwe 10:19) Bí èèyàn bá ti ń sọ̀rọ̀ jù, onítọ̀hún kò ní ṣàìsọ ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ tàbí ọ̀rọ̀ tó lè ṣàkóbá fúnni pàápàá. Ká sòótọ́, bí èèyàn kò bá kó ahọ́n rẹ̀ níjàánu ńṣe ni ahọ́n rẹ̀ á dà bí iná, ní ti pé á máa yára tan òfófó tó ń pani lára kálẹ̀, a sì máa bani lórúkọ jẹ́. (Jákọ́bù 3:5, 6) Àmọ́, tá a bá ń ṣọ́ ọ̀rọ̀ sọ tàbí tá a bá ń ronú ká tó sọ̀rọ̀, èyí á fi hàn pé ṣe là ń ro ìgbẹ̀yìn ọ̀rọ̀ ká tó sọ ọ́. Èyí á jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ wá sí ọlọgbọ́n èèyàn, wọ́n á máa bọ̀wọ̀ fún wa, wọ́n á sì fọkàn tán wa.

● “Yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ, lọ́ra nípa ìrunú.” (Jákọ́bù 1:19) Àwọn èèyàn máa mọyì rẹ̀ bá a bá ń fetí sílẹ̀ dáadáa nígbà tí wọ́n bá ń bá wa sọ̀rọ̀, èyí máa fi hàn pé ọ̀rọ̀ wọn jẹ wá lógún, a sì bọ̀wọ̀ fún wọn. Àmọ́ kí ló yẹ ká ṣe bí ẹnì kan bá sọ̀rọ̀ tó dùn wá tàbí tó dìídì fẹ́ mú wa bínú? Ó yẹ ká “lọ́ra nípa ìrunú,” ká má ṣe gbẹ̀san. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé nǹkan kan ló ń bí onítọ̀hún nínú, ó sì lè tọrọ àforíjì bó bá yá. Ṣó máa ń ṣòro fún ẹ láti “lọ́ra nípa ìrunú”? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó jẹ́ kó o lè máa kó ara rẹ níjàánu. Ó dájú pé Ọlọ́run máa dáhùn àdúrà tó o bá gbà tọkàntọkàn.—Lúùkù 11:13.

● “Ahọ́n pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ . . . lè fọ́ egungun.” (Òwe 25:15) Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn gbà gbọ́, jíjẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ jẹ́ àmì pé èèyàn ní okun. Bí àpẹẹrẹ, ìdáhùn pẹ̀lẹ́ lè borí àtakò tó le bí egungun tí ẹnì kan ń ṣe sí wa bóyá torí pé inú ń bí i tàbí pé ó ń ṣe ẹ̀tanú. Ká sòótọ́, kò rọrùn rárá láti hùwà tútù, pàápàá jù lọ bí inú bá ń bí wa. Torí náà, ronú nípa àwọn àǹfààní tó wà nínú ṣíṣe ohun tí Bíbélì sọ àti ohun tó máa jẹ́ àbájáde rẹ̀ tó o bá kọ̀ láti ṣe ohun tí Bíbélì sọ.

Ní ti tòótọ́, àwọn ìlànà inú Bíbélì jẹ́ “ọgbọ́n tí ó wá láti òkè.” (Jákọ́bù 3:17) Bá a bá ń fi àwọn ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì sọ́kàn nígbà tá a bá ń sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ wa á máa buyì kún àwọn èèyàn, á máa fà wọ́n lọ́kàn mọ́ra, á máa fún wọn níṣìírí, á sì máa bọ́ sí àkókò bí “àwọn èso ápù ti wúrà nínú àwọn ohun gbígbẹ́ tí a fi fàdákà ṣe.”—Òwe 25:11.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́