Ojú Ìwòye Bíbélì
Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Kò Fi Pa Èṣù Run?
TÓ O bá lágbára láti ṣèrànwọ́ fún ẹnì kan tó ń jìyà, ṣé wàá ràn án lọ́wọ́? Àwọn tó ń ṣèrànwọ́ fún àwọn tí àjálù dé bá sábà máa ń yára lọ sáwọn ibi tí àjálù bá ti ṣẹlẹ̀ kí wọ́n lè lọ ran àwọn tó ń jìyà lọ́wọ́, kí wọ́n sì gba ẹ̀mí àwọn èèyàn là bí wọn kò tiẹ̀ mọ̀ wọ́n rí. Èyí lè mú ká béèrè pé, ‘Kí wá nìdí tí Ọlọ́run kò fi tètè pa Èṣù run, ẹni tó fa gbogbo ìyà tó ń jẹ aráyé?’
Ká bàa lè dáhùn ìbéèrè yìí, jẹ́ ká wo àpèjúwe kan. Ká sọ pé ẹjọ́ pàtàkì kan ń lọ lọ́wọ́ nílé ẹjọ́. Àmọ́, torí pé apààyàn tí wọ́n gbé wá sílé ẹjọ́ náà fẹ́ da ẹjọ́ yẹn rú, ó bẹ̀rẹ̀ sí í sọ pé adájọ́ yẹn máa ń ṣe èrú nínú ẹjọ́ tó máa ń dá nílé ẹjọ́ rẹ̀, ó tiẹ̀ tún sọ pé ìgbìmọ̀ tó ń gbẹ́jọ́ nílé ẹjọ́ yẹn máa ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀. Torí èyí, wọ́n ní kí ọ̀pọ̀ èèyàn wá jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ yìí.
Adájọ́ náà mọ̀ pé nǹkan ò ní rọrùn rárá bó ṣe di pé ẹjọ́ yẹn ti bẹ̀rẹ̀ sí í fẹjú báyìí, kò sì fẹ́ kí ẹjọ́ yẹn falẹ̀ rárá. Síbẹ̀, ó tún mọ̀ pé tóun bá fẹ́ dá ẹjọ́ tó máa jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ torí ẹjọ́ tó tún lè wáyé nígbà míì, àfi kí òun fún àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn ní àkókò tí ó pọ̀ tó kí wọ́n lè sọ tẹnu wọn nípa ọ̀ràn náà.
Báwo ni àpèjúwe yìí ṣe jọra pẹ̀lú ẹ̀sùn tí Èṣù, tá a tún ń pè ní “dírágónì,” “ejò” àti “Sátánì” fi kan Jèhófà, “Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé”? (Ìṣípayá 12:9; Sáàmù 83:18) Ta ni Èṣù yìí gan-an? Ẹ̀sùn wo ló fi kan Jèhófà Ọlọ́run? Ìgbà wo sì ni Ọlọ́run máa pa á run?
Idi Tá A Fi Nílò Àpẹẹrẹ Irú Ìwà Tó Yẹ Ká Máa Hù
Ọ̀kan lára àwọn áńgẹ́lì tí Ọlọ́run dá gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí pípé ló di Èṣù. (Jóòbù 1:6, 7) Ó sọ ara rẹ̀ di Èṣù nígbà tó jẹ́ kí ìmọtara-ẹni-nìkan gba òun lọ́kàn débi tó fi fẹ́ káwọn èèyàn máa sin òun. Ó wá fẹ̀sùn kan Ọlọ́run pé kò lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso, ó tiẹ̀ tún sọ pé Ọlọ́run kò yẹ lẹ́ni tá à ń ṣègbọràn sí. Ó sọ pé tórí Ọlọ́run ń bù kún àwọn èèyàn ni wọ́n ṣe ń sìn ín. Sátánì tún sọ pé, gbogbo èèyàn ló máa “bú” Ẹlẹ́dàá wọ́n bí wọ́n bá ní ìṣòro.—Jóòbù 1:8-11; 2:4, 5.
Kì í ṣe ọ̀ràn pé kí Ọlọ́run fi hàn Sátánì pé òun lágbára jù ú lọ ló máa yanjú ọ̀rọ̀ yìí. Ká sòótọ́, bí Ọlọ́run bá ti pa Èṣù run nínú ọgbà Édẹ́nì, èyí lè jẹ́ kí àwọn kan rò pé òótọ́ ni ohun tí Èṣù ń sọ. Torí náà, Ọlọ́run tó jẹ́ Ọba Aláṣẹ Láyé Àtọ̀run, bẹ̀rẹ̀ ìgbẹ́jọ́ tó máa mú àwọn ẹ̀sùn tí Sátánì fi kàn án kúrò lọ́kàn gbogbo àwọn òǹwòran.
Ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà àti ìdájọ́ òdodo Jèhófà Ọlọ́run tó pé pérépéré, Ọlọ́run fi hàn pé àwọn tí ọ̀ràn kàn máa ní àwọn ẹlẹ́rìí tó máa wá sọ tẹnu wọn nípa ẹ̀yìn ẹni tí wọ́n wà. Àkókò tí Ọlọ́run ti fi sílẹ̀ ti mú kí Ádámù ní àwọn àtọmọdọ́mọ, kí àwọn àtọmọdọ́mọ náà sì lè máa pa ìwà títọ́ wọn mọ́, láìka ìṣòro èyíkéyìí sí, torí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run.
Báwo Ló Ṣe Máa Pẹ́ Tó?
Jèhófà Ọlọ́run mọ̀ dáadáa pé, lásìkò tí ìgbẹ́jọ́ yẹn ń lọ lọ́wọ́, ojú á máa pọ́n àwa èèyàn. Síbẹ̀, ó ti pinnu láti parí ẹjọ́ yẹn lásìkò. Bíbélì sọ pé Ọlọ́run jẹ́ “Baba àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo.” (2 Kọ́ríńtì 1:3) Ó dájú pé “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo” kò ní gba Èṣù láyè láti máa wà nìṣó kọjá àkókò tó yẹ, kò sì ní jẹ́ kí ìyà tó ń jẹ aráyé máa báa lọ bẹ́ẹ̀. Lọ́wọ́ kejì, Ọlọ́run kò ní pa Èṣù run láìjẹ́ pé àkókò ti tó láti ṣe bẹ́ẹ̀, ó dìgbà tí ẹjọ́ tó kan gbogbo ẹ̀dá láyé àtọ̀run yẹn bá parí pátápátá kí Ọlọ́run tó pa èṣù run.
Tí ọ̀ràn yẹn bá yanjú pátápátá, á wá ṣe kedere pé Jèhófà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ Ọba Aláṣẹ láyé àti ọ̀run. Ìdájọ́ tí Ọlọ́run máa ṣe fún Èṣù yìí á jẹ́ ẹ̀rí títí láé. Bí ẹnikẹ́ni bá tún ń gbèrò láti ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà, ohun tí Ọlọ́run ṣe fún Sátánì yìí á jẹ́ àríkọ́gbọ́n tí irú rẹ̀ kò ní wáyé mọ́.
Bí àsìkò bá tó lójú Jèhófà, ó máa fún Ọmọ rẹ̀ tó ti jíǹde láṣẹ láti pa Èṣù àtàwọn iṣẹ́ rẹ̀ run. Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ìgbà kan tí Jésù máa “fi ìjọba lé Ọlọ́run àti Baba rẹ̀ lọ́wọ́, nígbà tí ó bá ti sọ gbogbo ìjọba àti gbogbo ọlá àṣẹ àti agbára di asán. Nítorí òun gbọ́dọ̀ ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba títí Ọlọ́run yóò fi fi gbogbo àwọn ọ̀tá sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀tá ìkẹyìn, ikú ni a ó sọ di asán.”—1 Kọ́ríńtì15:24-26.
Inú wa dùn pé Bíbélì ṣèlérí pé gbogbo ayé máa di Párádísè! Àwọn èèyàn á máa gbé nínú ayé tuntun, wọ́n á sì wà ní àlàáfíà gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ kí nǹkan rí láti ìbẹ̀rẹ̀. “Àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.” Bẹ́ẹ̀ ni o, “àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.”—Sáàmù 37:11, 29.
Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ìrètí àgbàyanu kan ń dúró de àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run, ó ní: “Wò ó! Àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú aráyé, yóò sì máa bá wọn gbé, wọn yóò sì máa jẹ́ ènìyàn rẹ̀. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yóò sì wà pẹ̀lú wọn. Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”—Ìṣípayá 21:3, 4.
KÍ LÈRÒ Ẹ?
● Báwo ni Èṣù ṣe fi ẹ̀sùn èké kan Ọlọ́run àti àwa èèyàn?—Jóòbù 1:8-11.
● Èwo nínú àwọn ànímọ́ Ọlọ́run ló mú kó dá wa lójú pé ó ṣì máa pa Èṣù run?—2 Kọ́ríńtì 1:3.
● Ìrètí wo ni Bíbélì fún wa?—Ìṣípayá 21:3, 4.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Kí ẹjọ́ yìí bàa lè jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ, adájọ́ yìí gbọ́dọ̀ fún àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn ní àkókò tó pọ̀ tó kí wọ́n lè sọ tẹnu wọn nípa ọ̀ràn náà