-
Ǹjẹ́ Ilẹ̀ Júdà Dahoro?Ilé Ìṣọ́—2006 | November 15
-
-
Ǹjẹ́ Ilẹ̀ Júdà Dahoro?
BÍBÉLÌ sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn ará Bábílónì á pa ilẹ̀ Júdà run, ilẹ̀ náà á sì wà láhoro títí táwọn Júù tí wọ́n kó nígbèkùn á fi darí walé. (Jeremáyà 25:8-11) Ẹ̀rí tó fìdí múlẹ̀ jù lọ tá a fi lè gbà gbọ́ pé àsọtẹ́lẹ̀ yìí nímùúṣẹ wà nínú ìtàn tí Ọlọ́run mí sí, tó sì ti wà lákọọ́lẹ̀ láti nǹkan bí ọdún márùndínlọ́gọ́rin lẹ́yìn táwọn Júù tó kọ́kọ́ dé láti ìgbèkùn padà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn. Ìtàn náà sọ pé ọba Bábílónì “kó àwọn tí ó ṣẹ́ kù lọ́wọ́ idà lọ sí Bábílónì ní òǹdè, wọ́n sì wá di ìránṣẹ́ fún òun àtàwọn ọmọ rẹ̀ títí di ìgbà tí àwọn ará Páṣíà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso.” Ó sì sọ nípa ilẹ̀ Júdà pé: “Ní gbogbo ọjọ́ tí ó fi wà ní ahoro, ó ń pa sábáàtì mọ́.” (2 Kíróníkà 36:20, 21) Ǹjẹ́ ẹ̀rí èyíkéyìí wà látọ̀dọ̀ àwọn awalẹ̀pìtàn tá a lè fi ti èyí lẹ́yìn?
Nínú ìwé ìròyìn Biblical Archaeology Review tó ń sọ nípa ìwalẹ̀pìtàn, Ọ̀jọ̀gbọ́n Ephraim Stern, tó ń ṣiṣẹ́ olùkọ́ nílé ìwé gíga Hebrew University tó sì ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ ìwalẹ̀pìtàn nípa àgbègbè Palẹ́sìnì, ṣàlàyé pé: “Àwọn ará Ásíríà àtàwọn ará Bábílónì pa àgbègbè tó pọ̀ lára ilẹ̀ Ísírẹ́lì ìgbàanì run, síbẹ̀ ohun méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ la rí kọ́ látinú ohun táwọn awalẹ̀pìtàn hú jáde lẹ́yìn ogun kọ̀ọ̀kan tí wọ́n bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jà.” Ó ṣàlàyé pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn awalẹ̀pìtàn rí ẹ̀rí tó ṣe kedere pé àwọn ará Ásíríà ti bá àwọn ará Palẹ́sínì jagun rí, síbẹ̀ ìyàlẹ́nu ló jẹ́ pé lẹ́yìn táwọn ara Bábílónì pa ìlú náà run, kò sí ẹ̀rí kankan tá a fi lè mọ̀ pé wọ́n ti jagun níbẹ̀ rí. . . . Kò sí ẹ̀rí kankan tó fi hàn pé ẹnì kan gbé nílùú náà títí dìgbà tí àkóso fi bọ́ sọ́wọ́ àwọn ará Páṣíà . . . Kò tiẹ̀ sí ohunkóhun tó fi hàn pé ẹnikẹ́ni gbé nínú ìlú náà rí. Ní gbogbo àkókò náà, kò sí ẹyọ hóró kan lára ìlú táwọn ará Bábílónì pa run tí ẹnikẹ́ni tún padà gbé.”
Ọ̀jọ̀gbọ́n Lawrence E. Stager, ti ilé ẹ̀kọ́ gíga Harvard University náà gbà pé bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn. Ó sọ pé: “Jákèjádò ilẹ̀ Filíṣíà, ńṣe ni” àwọn ọba ilẹ̀ Bábílónì “tó ti mọ́ lára láti máa pa ilé àti ọ̀nà run, kí wọ́n sì máa ba dúkìá jẹ́ sọ gbogbo àgbègbè ìwọ̀ oòrùn Odò Jọ́dánì di ahoro pátápátá. Bákan náà ni wọ́n sì ṣe jákèjádò gbogbo ilẹ̀ Júdà lẹ́yìn náà.” Ọ̀jọ̀gbọ́n náà tún wá fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé àkọsílẹ̀ àwọn awalẹ̀pìtàn fi hàn pé àwọn èèyàn tún padà bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ní Jerúsálẹ́mù àti Júdà, níbi tí ọ̀pọ̀ àwọn Júù tó padà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn láti ìgbèkùn dé sí, nígbà ìṣàkóso Kírúsì Ńlá, ará Páṣíà tó gbàjọba lọ́wọ́ àwọn ará Bábílónì.
Dájúdájú, ọ̀rọ̀ Jèhófà pé ilẹ̀ Júdà máa dahoro ní ìmúṣẹ. Gbogbo ọ̀rọ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run bá sọ tẹ́lẹ̀ ló máa ń ní ìmúṣẹ. (Aísáyà 55:10, 11) A lè ní ìgbọ́kànlé kíkún nínú Jèhófà àtàwọn ìlérí tó wà nínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀.—2 Tímótì 3:16.
-
-
Ṣé Wàá Fẹ́ Ká Wá Ọ Wá?Ilé Ìṣọ́—2006 | November 15
-
-
Ṣé Wàá Fẹ́ Ká Wá Ọ Wá?
Àní nínú ayé onídààmú yìí, ìmọ̀ pípéye látinú Bíbélì nípa Ọlọ́run, Ìjọba rẹ̀, àti ohun àgbàyanu tó fẹ́ ṣe fún aráyé lè fún ọ láyọ̀. Bó o bá fẹ́ ìsọfúnni síwájú sí i tàbí tó o fẹ́ kí ẹnì kan kàn sí ọ nílé láti kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́, jọ̀wọ́ kọ̀wé sí Jehovah’s Witnesses, P.M.B. 1090, Benin City 300001, Edo State, Nigeria, tàbí sí àdírẹ́sì tó bá yẹ lára èyí tí a tò sí ojú ìwé 2.
-