Agbára Ọ̀rọ̀ Onínúure
“Ọkàn-àyà tí ó rẹ̀wẹ̀sì nitori àníyàn, ẹ wo bí ọ̀rọ̀ onínúure yoo ti tù ú lára tó!”—Owe 12:25, Knox.
AWỌN Kristian kò ní àjẹsára lòdìsí ìpọ́njú. Nígbà mìíràn wọn máa ń nírìírí àníyàn nitori pé wọn ń gbé ní “awọn àkókò lílekoko tí ó nira lati bálò” yii.—2 Timoteu 3:1, NW.
Nígbà tí wọn bá ń jìyà lọ́wọ́ irú ìdààmú bẹ́ẹ̀, ẹ wo irú ìbùkún tí ó jẹ́ lati gbọ́ awọn ọ̀rọ̀ onínúure lati ẹnu ọ̀rẹ́ adúróṣinṣin kan! Bibeli wí pé, “Ọ̀rẹ́ a máa fẹ́ni nígbà gbogbo, ṣugbọn arákùnrin ni a bí fún ìgbà ìpọ́njú.” (Owe 17:17) Ọkùnrin olóòótọ́ naa Jobu ni a mọ̀ fún jíjẹ́ irú ọ̀rẹ́ yii. Elifasi tilẹ̀ sọ nipa rẹ̀ pé: “Nígbà tí ẹnìkan bá kọsẹ̀, tí ó rẹ̀wẹ̀sì tabi káàárẹ̀, ọ̀rọ̀ rẹ fún un ní ìṣírí lati dúró.”—Jobu 4:4, Today’s English Version.
Ṣugbọn, nígbà tí Jobu fúnraarẹ̀ nílò ìṣírí, Elifasi ati awọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kò sọ awọn ọ̀rọ̀ onínúure jáde. Wọn dá Jobu lẹ́bi fún ìdààmú rẹ̀, ní fífọgbọ́n sọ pé ó ti níláti ṣe awọn àṣìṣe kan ní bòókẹ́lẹ́. (Jobu 4:8) The Intrepreter’s Bible ṣàlàyé pé: “Ohun tí Jobu nílò ni ìyọ́nú tí ń bẹ ninu ọkàn-àyà ènìyàn. Ohun tí ó rígbà ni ọ̀wọ́ awọn ọ̀rọ̀ tí ó jẹ́ ‘òtítọ́’ délẹ̀délẹ̀ ati awọn ọ̀rọ̀ tí ó dùn-ún gbọ́ dáradára tí ó ti ṣá tí ó nííṣe pẹlu ìsìn ati awọn òbu-ọ̀rọ̀ tí ó nííṣe pẹlu ọ̀nà-ìwàhíhù.” Orí Jobu gbóná tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ lati gbọ́ awọn ọ̀rọ̀ Elifasi ati awọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tí a fi sún un lati kígbe jáde pé: “Yoo ti pẹ́ tó tí ẹ̀yin ó fi máa bà mí ninu jẹ́, tí ẹ̀yin o fi máa fi ọ̀rọ̀ kun mi ní ìjàǹjá?”—Jobu 19:2.
Ǹjẹ́ kí a máṣe mú kí ìránṣẹ́ Ọlọrun ẹlẹgbẹ́ wa sọkún ninu ìpọ́njú láé nitori awọn ọ̀rọ̀ aláìnírònú, aláìnínúure tí a bá sọ. (Fiwé Deuteronomi 24:15.) Owe Bibeli kan kìlọ̀ pé: “Ohun tí o sọ lè pa ìwàláàyè mọ́ tabi kí ó pa á run; nitori naa o gbọ́dọ̀ gba àbájáde awọn ọ̀rọ̀ rẹ.”—Owe 18:21, TEV.
Ẹ jẹ́ kí a tẹ̀lé àpẹẹrẹ aposteli Paulu, ní fífi ìmọrírì hàn fún agbára ọ̀rọ̀ sísọ. Nígbà tí ó wà ní Makedonia, ó “fi ọ̀rọ̀ pupọ gbà wọn ní ìyànjú.”—Iṣe 20:2.