Ẹ̀KỌ́ 45
Àpèjúwe àti Àpẹẹrẹ Tí Ń Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́
LÍLO àpèjúwe àti àpẹẹrẹ jẹ́ ọ̀nà tí a lè gbà kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà tó múná dóko. Kì í sábà jẹ́ kí ọkàn olùgbọ́ kúrò lórí ọ̀rọ̀ tí ò ń sọ. Ó máa ń jẹ́ kéèyàn ronú jinlẹ̀. Ó ń tani jí, fún ìdí yìí ó lè gún ọkàn àti ẹ̀rí ọkàn ní kẹ́sẹ́. Nígbà mìíràn, àpèjúwe lè mú ẹ̀tanú kúrò. Kì í sì í jẹ́ kéèyàn gbàgbé ọ̀rọ̀. Ǹjẹ́ o máa ń lò ó nígbà tó o bá ń kọ́ni?
Àkànlò èdè jẹ́ àkàwe tó sábà máa ń ṣe ṣókí; àmọ́ ó máa ń jẹ́ kí èèyàn fojú inú rí ohun tí à ń sọ kedere. Nígbà tó bá ṣe rẹ́gí, ìtumọ̀ rẹ̀ kì í mù. Àmọ́ olùkọ́ lè jẹ́ kó túbọ̀ gbéṣẹ́ nípa fífi àlàyé ráńpẹ́ gbé e jókòó. Àpẹẹrẹ irú rẹ̀ pọ̀ nínú Bíbélì tó o lè tẹ̀ lé.
Fi Àfiwé Tààrà àti Àfiwé Ẹlẹ́lọ̀ọ́ Bẹ̀rẹ̀. Àfiwé tààrà ni àkànlò èdè tó rọrùn jù lọ. Bó bá jẹ́ pé ńṣe lo ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kọ́ bá a ṣe ń lo àpèjúwe, á dáa kó o fi àfiwé tààrà bẹ̀rẹ̀. Àwọn ọ̀rọ̀ tá a sábà máa ń lò láti fi gbé e yọ ni “bíi” tàbí “gẹ́gẹ́ bí.” Àfiwé tààrà máa ń mú ọ̀rọ̀ méjì tó yàtọ̀ síra pátápátá pa pọ̀, á sì wá fi ibi tí wọ́n ti jọra hàn. Bíbélì lo ọ̀pọ̀ èdè àpèjúwe tó dá lórí àwọn nǹkan tí a dá, bí irúgbìn, ẹranko àtàwọn ohun tí ń bẹ lójú ọ̀run, àti ìrírí àwọn ènìyàn pẹ̀lú. Sáàmù 1:3 sọ pé ẹni tó bá ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé “dà bí igi tí a gbìn sẹ́bàá àwọn ìṣàn omi,” tí ń so èso, tí kì í sì í rọ. Sáàmù tún sọ pé ẹni ibi dà “bí kìnnìún” tó ba de ẹran tó fẹ́ pa jẹ. (Sm. 10:9) Jèhófà ṣèlérí fún Ábúráhámù pé irú ọmọ rẹ̀ yóò dà “bí àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run” ní iye àti “bí àwọn egunrín iyanrìn tí ó wà ní etíkun.” (Jẹ́n. 22:17) Nígbà tí Jèhófà ń sọ̀rọ̀ nípa àjọṣe tí òun mú kí ó wà láàárín òun àti orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, Ọlọ́run sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí ìgbànú ti ń lẹ̀ mọ́ ìgbáròkó ènìyàn,” bẹ́ẹ̀ lòun ṣe jẹ́ kí Ísírẹ́lì àti Júdà lẹ̀ mọ́ Òun.—Jer. 13:11.
Àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́ náà máa ń fi ibi tí àwọn nǹkan méjì tó yàtọ̀ síra gan-an ti jọra hàn pẹ̀lú. Ṣùgbọ́n àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́ túbọ̀ máa ń ṣe ṣàkó ní tirẹ̀. Ó máa ń sọ̀rọ̀ bíi pé ohun tibí ni tọ̀hún, ó sì máa ń tipa báyìí gbé ànímọ́ ìkínní wọ ìkejì. Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin ni ìmọ́lẹ̀ ayé.” (Mát. 5:14) Nígbà tí ọmọ ẹ̀yìn náà Jákọ́bù ń ṣàlàyé wàhálà tí sísọ̀rọ̀ láìkóra-ẹni-níjàánu lè dá sílẹ̀, ó kọ̀wé pé: “Ahọ́n jẹ́ iná.” (Ják. 3:6) Dáfídì kọ ọ́ lórin sí Jèhófà pé: “Ìwọ ni àpáta gàǹgà mi àti ibi odi agbára mi.” (Sm. 31:3) Àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́ tó bá ṣe rẹ́gí kì í sábàá béèrè àlàyé púpọ̀. Bó bá ṣe ṣe ṣókí tó ló ṣe máa ń lágbára tó. Àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́ lè jẹ́ kí àwùjọ rántí kókó tí wọn ì bá gbàgbé tó bá jẹ́ pé ńṣe la sọ̀rọ̀ náà ṣákálá.
A tún máa ń lo àbùmọ́ kí ọ̀rọ̀ wa lè wọni lọ́kàn. Àmọ́ ìlò rẹ̀ gba ìṣọ́ra, kí àwọn èèyàn má bàa ṣì í lóye. Jésù lo àkànlò èdè yìí kí àwọn èèyàn má bàa gbàgbé ọ̀rọ̀ rẹ̀ nígbà tó béèrè pé: “Èé ṣe tí ìwọ fi wá ń wo èérún pòròpórò tí ó wà nínú ojú arákùnrin rẹ, ṣùgbọ́n tí o kò ronú nípa igi ìrólé tí ó wà nínú ojú ìwọ fúnra rẹ?” (Mát. 7:3) Kí o tó bẹ̀rẹ̀ sí lo àkànlò èdè yìí tàbí àwọn mìíràn, kọ́kọ́ rí i dájú pé o ti mọ àfiwé lò dáadáa.
Lo Àpẹẹrẹ. O lè lo àpẹẹrẹ, yálà ìtàn àròsọ tàbí ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣẹlẹ̀ ní ti gidi láti fi la ọ̀rọ̀ rẹ yéni dípò lílo àkànlò èdè. Àmọ́ téèyàn ò bá ṣọ́ra, àpẹẹrẹ lè dojú ọ̀rọ̀ rú. Àwọn kókó tó bá ṣe pàtàkì nìkan ló yẹ kí o kàn fi àpẹẹrẹ tì lẹ́yìn, ó sì yẹ kó o lò ó lọ́nà táwọn èèyàn á ṣì fi rántí ẹ̀kọ́ náà tó o fẹ́ kọ́ wọn, kí ó má kàn jẹ́ pé ìtàn yẹn nìkan ni wọ́n máa rántí.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe dandan pé kí gbogbo àpẹẹrẹ tó o bá lò jẹ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an, síbẹ̀ ó yẹ kí ó jẹ́ ohun tó lè ṣẹlẹ̀ ní ti gidi. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé nígbà tí Jésù ń kọ́ wa ní ojú tó yẹ ká fi wo àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó ronú pìwà dà, ó lo àpèjúwe ayọ̀ tó kún inú ọkùnrin kan tó rí àgùntàn rẹ̀ tó sọnù. (Lúùkù 15:1-7) Nígbà tí Jésù ń ṣàlàyé fún ọkùnrin kan tí òye Òfin tó sọ pé kéèyàn nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ̀ kò yé délẹ̀délẹ̀, Jésù sọ ìtàn ará Samáríà kan tó ran ọkùnrin tó fara pa lọ́wọ́, lẹ́yìn tí àlùfáà àti ọmọ Léfì kọ̀ láti ràn án lọ́wọ́. (Lúùkù 10:30-37) Bó o bá ń fara balẹ̀ wo ìwà àti ìṣesí àwọn èèyàn, wàá lè lo ọ̀nà ìgbàkọ́ni yìí lọ́nà tó múná dóko.
Nátánì wòlíì ronú ìtàn àlọ́ kan tó fi bá Dáfídì Ọba wí. Ìtàn náà gbéṣẹ́ nítorí pé kò jẹ́ kí Dáfídì lè wí àwíjàre. Ó jẹ́ ìtàn ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan tó ní ọ̀pọ̀ àgùntàn àti ọkùnrin aláìní kan tó jẹ́ pé abo ọ̀dọ́ àgùntàn kan ṣoṣo ló ní, kíkẹ́ ló sì ń kẹ́ ọ̀dọ́ àgùntàn náà. Olùṣọ́ àgùntàn kúkú ni Dáfídì tẹ́lẹ̀. Nítorí náà, ó mọ bí ọ̀ràn àgùntàn ṣe máa rí lára ẹni tó ni ín. Inú bí Dáfídì sí ọkùnrin ọlọ́rọ̀ tó lọ gbé ọ̀dọ́ àgùntàn tí tálákà náà ń kẹ́ bí ọmọ yìí. Nígbà náà ni Nátánì wá là á mọ́lẹ̀ fún Dáfídì pé: “Ìwọ fúnra rẹ ni ọkùnrin náà!” Ọ̀rọ̀ náà gún Dáfídì ní kẹ́sẹ́, ó sì ronú pìwà dà tọkàntọkàn. (2 Sám. 12:1-14) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé kíkọ́ ni mímọ̀, o lè kọ́ bá a ṣe ń fọgbọ́n yanjú àwọn ọ̀ràn tó gbẹgẹ́.
Ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ tí a lè fi kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ la lè rí nínú àwọn ìtàn tó wà nínú Ìwé Mímọ́. Jésù lo irú àpẹẹrẹ bẹ́ẹ̀ nígbà tó sọ ní ṣókí pé: “Ẹ rántí aya Lọ́ọ̀tì.” (Lúùkù 17:32) Nígbà tí Jésù ń sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ àmì wíwà níhìn-ín rẹ̀, ó tọ́ka sí “ọjọ́ Nóà.” (Mát. 24:37-39) Ní Hébérù orí kọkànlá, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù dárúkọ èèyàn mẹ́rìndínlógún, lọ́kùnrin àti lóbìnrin, tí wọ́n jẹ́ àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́. Bí o ṣe ń mọ Bíbélì sí i, wàá lè túbọ̀ máa lo ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa àwọn ìtàn àtàwọn èèyàn inú rẹ̀ láti fi ṣe àwọn àpẹẹrẹ tó kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ gidi.—Róòmù 15:4; 1 Kọ́r. 10:11.
Nígbà mìíràn, o lè rí i pé ó dáa láti fi ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣẹlẹ̀ lóde òní kín ọ̀rọ̀ rẹ lẹ́yìn. Àmọ́ nígbà tó o bá ń ṣe èyí, rí i dájú pé kìkì ìrírí tí o mọ̀ pé ó jóòótọ́ ni o lò, má sì lo ìrírí tó máa dójú ti ẹnì kan láwùjọ tàbí ìrírí tó máa lọ ta bá kókó ọ̀rọ̀ tí ń dá àríyànjiyàn sílẹ̀. Tún rántí pé ó yẹ kí ìrírí náà ṣe iṣẹ́ kan pàtó. Má kàn pìtàn lọ rẹrẹẹrẹ, tí kókó ọ̀rọ̀ ò fi ní lójú mọ́.
Ǹjẹ́ Ó Máa Yé Àwọn Èèyàn? Ó yẹ kí àpèjúwe tàbí àpẹẹrẹ yòówù tó o bá lò ní èrò kan pàtó tó fẹ́ gbé yọ. Ǹjẹ́ ó máa wúlò rárá bó ò bá fi bó ṣe tan mọ́ kókó ọ̀rọ̀ rẹ hàn?
Lẹ́yìn tí Jésù pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní “ìmọ́lẹ̀ ayé,” ó wá sọ ọ̀rọ̀ díẹ̀ nípa iṣẹ́ tí fìtílà ń ṣe àti ẹrù iṣẹ́ tí èyí fi hàn pé ó já lé wọn léjìká. (Mát. 5:15, 16) Lẹ́yìn tó sọ àpèjúwe àgùntàn tó sọnù, ó wá sọ nípa ayọ̀ tó máa ń wà ní ọ̀run nígbà tí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan bá ronú pìwà dà. (Lúùkù 15:7) Lẹ́yìn tí Jésù sì pa ìtàn ará Samáríà tó jẹ́ aládùúgbò rere, ó béèrè ìbéèrè kan tó sojú abẹ níkòó, ó wá fi ìmọ̀ràn tó ṣe tààràtà dé e ládé. (Lúùkù 10:36, 37) Ní ọwọ́ kejì, kìkì àwọn onírẹ̀lẹ̀ tó fẹ́ mọ̀dí ọ̀rọ̀ ni Jésù ṣàlàyé àpèjúwe ti onírúurú ilẹ̀ àti àpèjúwe ti èpò fún, kò ṣàlàyé náà fún gbogbo èèyàn. (Mát. 13:1-30, 36-43) Ọjọ́ mẹ́ta ṣáájú ikú Jésù, ó sọ ìtàn kan tó jẹ́ àpèjúwe, tó jẹ́ nípa àwọn aroko tí wọ́n gbé ọgbà àjàrà fún, ṣùgbọ́n tí wọ́n wá di apànìyàn. Kò fi àlàyé kankan kún un; kò sídìí fún àlàyé. Síbẹ̀, “àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisí . . . ṣàkíyèsí pé ó ń sọ̀rọ̀ nípa wọn.” (Mát. 21:33-45) Nítorí náà, irú àpèjúwe tó jẹ́, àti ìṣarasíhùwà olùgbọ́ àti ohun tó o ní lọ́kàn lo máa fi mọ̀ bóyá ó yẹ kó o ṣàlàyé àti bó ṣe yẹ kí àlàyé ọ̀hún gùn tó, ìyẹn bí àlàyé bá pọn dandan.
Ó máa ń gba àkókò láti mọ bá a ṣe ń lo àpèjúwe àti àpẹẹrẹ lọ́nà tó kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́, ṣùgbọ́n ìsapá tó o bá ṣe tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Àpèjúwe tó ṣe rẹ́gí ń múni ronú jinlẹ̀, ó ń mú kí ọ̀rọ̀ wọni lọ́kàn. Ó máa ń jẹ́ kí ọ̀rọ̀ túbọ̀ yéni yékéyéké ju bí òye ẹni ṣe máa mọ bó bá jẹ́ pé ńṣe la kàn sọ̀rọ̀ náà ṣákálá.