Láyé àtijọ́, ìrìn àjò orí ilẹ̀ kì í yá, ó máa ń tánni lókun, ó sì máa ń náni lówó ju kéèyàn wọ́ ọkọ̀ ojú omi lọ. Àmọ́ o, ọ̀pọ̀ ibi lèèyàn ò lè dé nígbà yẹn láìjẹ́ pé ó fẹsẹ̀ rìn.
Èèyàn lè fẹsẹ̀ rin nǹkan bí ọgbọ̀n (30) kìlómítà lóòjọ́. Ẹni náà máa ní láti fara da àwọn nǹkan bí oòrùn, òjò, ooru àti òtútù. Ó sì ṣeé ṣe kó pàdé àwọn dánàdánà lójú ọ̀nà. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé òun wà “nínú ìrìn àjò lọ́pọ̀ ìgbà, nínú ewu odò, nínú ewu dánàdánà.”—2 Kọ́r. 11:26.
Àwọn ọ̀nà tó dáa wà lọ́pọ̀ ibi káàkiri Ilẹ̀ Ọba Róòmù. Láwọn òpópónà térò sábà máa ń gbà, wọ́n máa ń ṣe ilé ìgbàlejò táwọn arìnrìn-àjò ti lè sùn mọ́jú lẹ́yìn ìrìn àjò ọjọ́ kan. Àwọn ilé ìgbàlejò náà tún máa ń ní ilé ìtajà táwọn arìnrìn àjò ti lè ra àwọn nǹkan pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ tí wọ́n nílò. Àwọn òǹkọ̀wé kan sọ pé àwọn ilé ìgbàlejò àti ilé ìtajà yẹn máa ń kún fọ́fọ́, ó máa ń dọ̀tí, ó máa ń móoru, ẹ̀fọn sì máa ń pọ̀ níbẹ̀. Àwọn èèyànkéèyàn ló sì máa ń kúnbẹ̀. Àwọn tó ń bójú tó àwọn ilé ìgbàlejò náà sábà máa ń ja àwọn arìnrìn-àjò lólè, wọ́n sì tún láwọn aṣẹ́wó tó ń ṣiṣẹ́ fún wọn.
Ó dájú pé àwọn Kristẹni máa ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe kí wọ́n má bàa máa dé sáwọn ilé ìgbàlejò yẹn. Àmọ́, tí wọ́n bá ń rìnrìn àjò láwọn ìlú tí wọn ò ti ní mọ̀lẹ́bí tàbí ọ̀rẹ́, wọ́n máa ní láti sùn síbẹ̀.