Káàbọ̀ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Ó JU igba orílẹ̀-èdè lọ káàkiri ayé tí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ti ń jàǹfààní nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Àwọn kan ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni. Àwọn mìíràn sì ti ń lọ sí ilé ẹ̀kọ́ ọ̀hún láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn. A ń darí ilé ẹ̀kọ́ yìí ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ilé ìpàdé. Ibikíbi tó o bá ń gbé lórí ilẹ̀ ayé, ètò ẹ̀kọ́ kan náà yìí wà fún ọ. Tọmọdé tàgbà, gbogbo ẹ̀yà àti ìran, àtọ̀mọ̀wé àti púrúǹtù ló jùmọ̀ ń gba ìtọ́ni Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run yìí lọ́fẹ̀ẹ́.
Nígbà tí a fi ilé ẹ̀kọ́ yìí lọ́lẹ̀ nínú àwọn ìjọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́dún 1943, a ṣàlàyé pé ète tó wà fún ni: “Láti múra gbogbo ‘àwọn olóòótọ́ èèyàn’ sílẹ̀, àwọn tí wọ́n ti gbọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí wọ́n sì ti fi hàn pé àwọn gbà á gbọ́, ‘kí wọ́n lè kọ́ àwọn ẹlòmíràn‘ . . . fún ète pàtàkì pé kí olúkúlùkù wọn . . . lè túbọ̀ já fáfá nínú sísọ ìrètí tí ń bẹ nínú wọn jáde fáyé gbọ́.” (Course in Theocratic Ministry, ojú ewé 4) Ète ilé ẹ̀kọ́ yìí kò yí padà títí dòní.
Kí ni ohun tó dára jù lọ tí kálukú wa lè fi ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ sísọ tí Ọlọ́run fún wa ṣe ná? Bíbélì dáhùn rẹ̀ pé: “Gbogbo ohun eléèémí—kí ó yin Jáà.” (Sm. 150:6) Bí a bá ṣe ìyẹn, a óò mú inú Baba wa ọ̀run dùn. A óò jẹ́ kí ó hàn sí i láti ọkàn wa wá pé a mọrírì oore rẹ̀ àti ìfẹ́ tó fi hàn sí wa. Abájọ tá a fi gba àwọn Kristẹni níyànjú pé kí wọ́n máa “rú ẹbọ ìyìn sí Ọlọ́run nígbà gbogbo, èyíinì ni, èso ètè tí ń ṣe ìpolongo ní gbangba sí orúkọ rẹ̀”! (Héb. 13:15) A tẹ́wọ́ gbà ọ́ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí akẹ́kọ̀ọ́ kí á lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti lo àwọn ẹ̀bùn tó o ní láti fi yin Jèhófà.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé bí a ṣe ń kàwé fún àwùjọ àti bí a ṣe ń mọ ọ̀nà tí à ń gbà báni sọ̀rọ̀ àti bí a ṣe ń kọ́ni ló gbàfiyèsí púpọ̀ nínú ilé ẹ̀kọ́ yìí, àǹfààní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run kò mọ síbẹ̀ nìkan. Bí o ṣe ń kópa nínú rẹ̀, a ó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti di ẹni tó ń kàwé, ẹni tó mọ bá a ṣe ń fetí sílẹ̀ àti bá a ṣe ń rántí nǹkan, tó mọ bá a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ àti bá a ṣe ń ṣe ìwádìí, bá a ṣe ń ṣe àyẹ̀wò fínnífínní àti bá a ṣe ń ṣàkójọ ọ̀rọ̀, bá a ṣe ń fọ̀rọ̀ wérọ̀ àti bá a ṣe ń dáhùn àwọn ìbéèrè, àti bí a ṣe ń kọ èrò ọkàn ẹni sílẹ̀. Inú Bíbélì fúnra rẹ̀ àti àwọn ìtẹ̀jáde tí a gbé karí Bíbélì ni ẹ̀kọ́ àti àwọn àlàyé àti àwọn ìjíròrò ní ilé ẹ̀kọ́ yìí yóò ti wá. Bí o ṣe ń gba òtítọ́ ṣíṣeyebíye tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sínú ọkàn rẹ, wàá dẹni tó mọ bí a ṣe ń ronú lọ́nà ti Ọlọ́run. Èyí yóò sì ṣàǹfààní lọ́nà kíkọyọyọ nínú gbogbo apá ìgbésí ayé rẹ! Nípa bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe níye lórí tó, ọ̀gbẹ́ni William Lyon Phelps, tó jẹ́ olùkọ́ni ní yunifásítì ní ọ̀rúndún ogún kọ̀wé pé: “Olúkúlùkù ẹni tó bá mọ Bíbélì ní àmọ̀dájú la lè pè ní ọ̀mọ̀wé. . . . Mo gbà gbọ́ pé bí èèyàn bá ní ìmọ̀ Bíbélì ṣùgbọ́n tí kò lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga, ìyẹn ṣì wúlò ju pé kó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga láìní ìmọ̀ Bíbélì.”
Bí O Ṣe Lè Jàǹfààní ní Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́
Ó dájú pé, ìwọ, tó o jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́, ní láti sapá kí o tó lè jàǹfààní lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ Tímótì tó jẹ́ Kristẹni alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ pé: “Máa fẹ̀sọ̀ ronú lórí nǹkan wọ̀nyí; fi ara rẹ fún wọn pátápátá, kí ìlọsíwájú rẹ lè fara hàn kedere fún gbogbo ènìyàn.” (1 Tím. 4:15) Àwọn ọ̀nà gbígbéṣẹ́ wo lo lè gbà ṣakitiyan?
Bó bá ṣeé ṣe, rí i dájú pé o kì í pa Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run jẹ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Lo ìwé yìí, Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ. Kọ orúkọ rẹ sí àyè tá a pèsè sí ojú ewé tá a kọ orúkọ ìwé yìí sí. Máa mú ìwé yìí dání wá sí ilé ẹ̀kọ́ yìí nígbà gbogbo. O tún lè kọ nǹkan sínú ìwé yìí. Bí o bá ka kókó pàtàkì kan nínú rẹ̀ tí o ronú pé á ràn ọ́ lọ́wọ́, fa ìlà sídìí rẹ̀. Lo àyè fẹ̀rẹ̀gẹ̀dẹ̀ tó wà létí ìwé yìí fún ṣíṣàkọsílẹ̀ àwọn kókó tó wúlò tí o bá kọ́ nígbà ìjíròrò ilé ẹ̀kọ́ yìí.
A pèsè ẹ̀dà ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí a tẹ̀, tí a ó tẹ̀ lé nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run lọ́tọ̀. Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìsọfúnni nípa bí ètò ilé ẹ̀kọ́ ṣe máa rí yóò wà nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọ̀hún pẹ̀lú. O lè rí i pé yóò dára bó o bá fi ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà sínú ìwé yìí, kó lè wà lárọ̀ọ́wọ́tó rẹ.
Bí o ṣe ń múra iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ ti ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ sílẹ̀, fi í sọ́kàn pé Bíbélì ni lájorí ìwé tí à ń lò. Kíka apá ibi tí a yàn nínú Bíbélì fún kíkà lọ́sẹ̀ ni kó gba iwájú o. Bí o bá sì lè ka àwọn ibi tí a ṣètò fún àwọn apá yòókù nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ṣáájú, ìyẹn pẹ̀lú yóò ṣàǹfààní gan-an ni.
Lásìkò ilé ẹ̀kọ́ náà, àyè lè ṣí sílẹ̀ fún àwùjọ láti kópa níbẹ̀. Lo àǹfààní yẹn ní kíkún. Lílóhùn sí irú àwọn ìjíròrò bẹ́ẹ̀ jẹ́ ara nǹkan pàtàkì tí yóò mú ọ rántí ohun tó o gbọ́ tí yóò sì jẹ́ kí o lè fi í sílò nínú ìgbésí ayé rẹ.
Ó dájú pé gbogbo akẹ́kọ̀ọ́ ni yóò láǹfààní láti sọ ọ̀rọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ tàbí kí wọ́n ṣe àṣefihàn níwájú ìjọ. Ṣe èyíkéyìí tí a bá yàn fún ọ nínú méjèèjì dáadáa. Sapá gidigidi láti rí i pé o túbọ̀ ṣe dáadáa sí i lórí ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ tí wọ́n bá yàn fún ọ. Wọn yóò fún ọ nímọ̀ràn táá lè túbọ̀ mú ọ tẹ̀ síwájú. Má ṣe kọ ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n bá fún ọ o. Kọ ìmọ̀ràn pàtó lórí ohun tí ìwọ fúnra rẹ lè ṣe láti tẹ̀ síwájú sínú ìwé rẹ. Nígbà tó sì jẹ́ pé ìpàkọ́ onípàkọ́ làá rí, ẹni ẹlẹ́ni ló ń báni rí tẹni, àbá onífẹ̀ẹ́, tí a gbé karí Bíbélì àti ìmọ̀ràn tí a óò fún ọ lè ràn ọ́ lọ́wọ́ gan-an láti tẹ̀ síwájú. Àní bó o bá tiẹ̀ ti wà nínú ilé ẹ̀kọ́ yìí láti ọ̀pọ̀ ọdún wá, kò yọ ẹ́ sílẹ̀.—Òwe 1:5.
Ṣé wàá fẹ́ láti tètè tẹ̀ síwájú? Bí o bá lo ìdánúṣe, ìyẹn lè ṣeé ṣe. Ka àwọn ibi tí a ti fa ọ̀rọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan yọ ṣáájú. Bó bá wá di pé a nílò olùbánisọ̀rọ̀ mìíràn dípò ẹni tí a yàn tẹ́lẹ̀, ìwọ yóò lè yọ̀ǹda ara rẹ, ìyẹn á sì tún jẹ́ kó o túbọ̀ nírìírí sí i. Bí àwọn ẹlòmíràn bá ń sọ̀rọ̀, tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ sí bí wọ́n ṣe ń sọ ọ̀rọ̀ wọn. Èèyàn a máa kẹ́kọ̀ọ́ lára ọmọnìkejì rẹ̀.
Ní àfikún sí i, bí àyè rẹ̀ bá yọ, o tún lè mú kí ìtẹ̀síwájú rẹ yá kánkán bó o bá ń ka ìwé yìí ṣáájú fúnra rẹ. Lẹ́yìn tó o bá ti mọ ohun tó wà nínú ẹ̀kọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún àkọ́kọ́ dáadáa, bẹ̀rẹ̀ sí í fúnra rẹ kọ́ ohun tó wà nínú “Ètò Sísọni Di Sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ àti Olùkọ́ni” tó bẹ̀rẹ̀ látojú ewé 78. Lákọ̀ọ́kọ́, ka ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan kí o sì ṣe iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ tí a gbé karí rẹ̀. Kí o wá fi ohun tó ò ń kọ́ sílò nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ. Èyí lè túbọ̀ mú kó o tẹ̀ síwájú dáadáa gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ń sọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó sì ń fi í kọ́ni.
Ẹ̀kọ́ tí ò ń kọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run yóò mú ọ gbára dì fún ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé rẹ. Nígbà tó sì jẹ́ pé nítorí ìfẹ́ Ọlọ́run la fi wà láàyè, tí a bá ń yìn ín, á jẹ́ pé a lóye ète pàtàkì tí a fi ń bẹ láàyè nìyẹn. Ìyìn tó ga lọ́lá jù lọ ló sì yẹ Jèhófà Ọlọ́run. (Ìṣí. 4:11) Ẹ̀kọ́ tí à ń kọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ yìí jẹ́ ọ̀nà kan tí a lè gbà yìn ín. Yóò jẹ́ ká lè ronú lọ́nà tó já gaara, ká hùwà ọlọgbọ́n, ká sì lè sọ àwọn àgbàyanu òtítọ́ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí fáwọn èèyàn lọ́nà tí yóò fi wọ̀ wọ́n lọ́kàn.