ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • yb13 ojú ìwé 78-173
  • Myanmar (Burma)

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Myanmar (Burma)
  • Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2013
  • Ìsọ̀rí
  • Bí Iṣẹ́ Ìwàásù Ṣe Bẹ̀rẹ̀
  • “Rachel, Mo Ti Rí Òtítọ́!”
  • Àwọn Aṣáájú-Ọ̀nà Onígboyà
  • Àpéjọ Àgbègbè Tí A Kò Lè Gbàgbé
  • Àwọn Kayin Tó Kọ́kọ́ Di Ẹlẹ́rìí Jèhófà
  • Àwọn Ohun Tójú Rí Nígbà Ogun Àgbáyé Kejì
  • Inú Wa Dùn Pé Ojú Túnra Rí
  • Àwọn Míṣọ́nnárì Tó Kọ́kọ́ Wá Láti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì
  • Ogun Abẹ́lé Bẹ́ Sílẹ̀!
  • A Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Wàásù, A sì Ń Kọ́ni Lédè Burmese
  • Iṣẹ́ Ìwàásù So Èso Rere ní Ìlú Mandalay
  • Wọ́n Lé Àwọn Míṣọ́nnárì Kúrò Nílùú!
  • A Wàásù Dé Ìpínlẹ̀ Chin
  • A Lọ sí Àwọn Ìlú Tó Wà Lórí Òkè
  • “Àwọn Ará Myitkyina Kì Í Fẹ́ Gbọ́ Ìwàásù”
  • Àwọn Apá Kan Lára Ọkọ̀ Rélùwéè Dàwátì
  • Bá A Ṣe Kọ́ Àwọn Ẹ̀yà Naga Lẹ́kọ̀ọ́ Òtítọ́
  • Àtakò Gbígbóná Janjan Bẹ̀rẹ̀ Níbi Tí Ohun Àmúṣọrọ̀ Wà Tẹ́lẹ̀
  • Wọn Kò Lọ́wọ́ sí Òṣèlú àti Ogun
  • Àwọn Ológun Di Kristẹni
  • Wọ́n Fèrò Wérò Pẹ̀lú “Onírúurú Ènìyàn”
  • A Ṣe Àwọn Àpéjọ Àgbègbè Nígbà Rògbòdìyàn
  • Wọn Ò Kọ Ìpéjọpọ̀ Kristẹni Sílẹ̀
  • A Mú Ọ̀nà Tá À Ń Gbà Tẹ̀wé Dára Sí I
  • A Nílò Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Tuntun
  • ‘Kì Í Ṣe Nípasẹ̀ Agbára, Bí Kò Ṣe Nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mi’
  • A Kọ́ Àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba Tuntun
  • Àwọn Míṣọ́nnárì Dé
  • Ọ̀pọ̀ Jàǹfààní Látinú Àpẹẹrẹ Rere Wọn
  • Wọ́n Ń Jàǹfààní Látinú Ìtumọ̀ Èdè Tó Dára Sí I
  • Ìjì Nargis
  • Ìṣẹ̀lẹ̀ Tí A Kò Lè Gbàgbé
  • “Funfun fún Kíkórè”
Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2013
yb13 ojú ìwé 78-173
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 78, 79]

Myanmar (Burma)

ORÍLẸ̀-ÈDÈ Myanmar wà láàárín orílẹ̀-èdè Ṣáínà àti Íńdíà tí wọ́n jẹ́ orílẹ̀-èdè tó tóbi jù lọ nílẹ̀ Éṣíà. Oríṣiríṣi nǹkan ló mú kí orílẹ̀-èdè yìí fani mọ́ra gan-an.a Ìlú Yangon (tó ń jẹ́ Rangoon tẹ́lẹ̀) ló tóbi jù níbẹ̀. Téèyàn bá dé ìlú yìí, ó máa rí àwọn ilé àwòṣífìlà, àwọn ṣọ́ọ̀bù ìtajà tó kún fọ́fọ́ àtàwọn ọkọ̀ ìrìnnà tó ń lọ tó ń bọ̀ lójú pópó. Yàtọ̀ sí ìlú Yangon, àwọn abúlé tún wà káàkiri níbi téèyàn ti lè rí àwọn ẹfọ̀n ti ń túlẹ̀ létí omi. Àwòyanu làwọn ará ìgbèríko máa ń wo àwọn àlejò, èèyàn jẹ́jẹ́ sì ni wọ́n.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 78]

Bí orílẹ̀-èdè Myanmar ṣe rí lóde òní máa ń rán wa létí bí ilẹ̀ Éṣíà ṣe rí láyé àtijọ́. Tó o bá ń lọ lójú ọ̀nà, wàá rí àwọn bọ́ọ̀sì tó rí hẹ́gẹhẹ̀gẹ tó ń gba àwọn ọ̀nà págunpàgun kọjá àtàwọn kẹ̀kẹ́ akẹ́rù tí wọ́n fi ń kó irè oko lọ sí ọjà. Wàá tún rí àwọn darandaran tí wọ́n ń da ẹran nínú pápá. Ọ̀pọ̀ àwọn ọkùnrin wọn ló máa ń wọ aṣọ ìbílẹ̀, ìyẹn ìró tí wọ́n ń pè ní lungi. Àwọn obìnrin máa ń kun thanaka (tàbí àtíkè tí wọ́n fi èèpo igi ṣe) láti fi ṣe oge. Àwọn èèyàn ilẹ̀ Myanmar kì í fi ẹ̀sìn wọn ṣeré rárá. Àwọn ẹlẹ́sìn Búdà ka àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé sí ju àwọn èèyàn jàǹkànjàǹkàn tó wà láwùjọ wọn lọ. Kódà, ojoojúmọ́ ni wọ́n máa ń lọ rúbọ nídìí ère Búdà.

Èèyàn jẹ́jẹ́ làwọn ọmọ ilẹ̀ Myanmar, wọ́n máa ń gba tàwọn ẹlòmíì rò, wọ́n sì máa ń ṣe ìwádìí gan-an. Ẹ̀yà ńlá mẹ́jọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló wà lórílẹ̀-èdè náà, àtàwọn mẹ́tàdínlàáádóje [127] míì tí wọ́n jẹ́ àwọn ẹ̀yà kéékèèké. Ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan ló ní èdè tiẹ̀, títí kan oúnjẹ, ìmúra àti àṣà tó yàtọ̀ sí tàwọn yòókù. Ọ̀pọ̀ àwọn ará ibẹ̀ ló ń gbé lórí pẹ̀tẹ́lẹ̀ tó tẹ́jú, níbi tí odò Ayeyarwady (ìyẹn odò Irrawaddy) gbà kọjá. Odò náà gùn tó ẹgbẹ̀rún méjì àti àádọ́sàn-án [2,170] kìlómítà, ó sì ṣàn gba ẹ̀gbẹ́ àwọn òkè Himalayas (tí yìnyín ti bò) wọnú òkun Andaman tí kò fi bẹ́ẹ̀ tutù. Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló ń gbé láwọn etíkun tí odò ti ṣàn wọnú òkun àti láwọn ilẹ̀ olókè níbi tí orílẹ̀-èdè náà ti pààlà pẹ̀lú orílẹ̀-èdè Bangladesh, Ṣáínà, Íńdíà, Laos àti orílẹ̀-èdè Thailand.

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 81

Ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́rùn-ún [100] ọdún báyìí táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhofà lórílẹ̀-èdè Myanmar ti ń fi hàn pé àwọn ní ìgbàgbọ́ tó lágbára, àwọn sì ń lo ìfaradà. Wọn ò fìgbà kankan dá sí òṣèlú, pàápàá ní gbogbo àkókò tí ìwà jàgídíjàgan àti rògbòdìyàn òṣèlú gbòde kan. (Jòh. 17:14) Pẹ̀lú bí ipò nǹkan ò ṣe rọgbọ fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wọ̀nyí, àwọn onísìn tún ń gbógun tì wọ́n, kò sì rọrùn fún wọn láti kàn sí àwọn ará wọn láwọn orílẹ̀-èdè míì. Síbẹ̀, wọn kò ṣàárẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run. Ìtàn wọn yìí máa wú wa lórí gan-an.

Ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́rùn-ún [100] ọdún báyìí tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhofà lórílẹ̀-èdè Myanmar ti fi hàn pé àwọn ní ìgbàgbọ́ tó lágbára, àwọn sì ń lo ìfaradà

Bí Iṣẹ́ Ìwàásù Ṣe Bẹ̀rẹ̀

Lọ́dún 1914, tó jẹ́ ọdún pàtàkì, àwọn ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì méjì kan, ìyẹn Arákùnrin Hendry Carmichael àti alábàáṣiṣẹ́pọ̀ rẹ̀ tí wọ́n jọ jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà sọ̀ kalẹ̀ látinú ọkọ̀ òkun sí èbúté ìlú Yangon tó móoru gan-an. Ilẹ̀ Íńdíà ni wọ́n ti gbéra láti wá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù lórílẹ̀-èdè Burma. Iṣẹ́ ńlá ni iṣẹ́ tí wọ́n wá ṣe yìí torí pé gbogbo orílẹ̀-èdè yẹn látòkè délẹ̀ ló máa jẹ́ ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn.

“O lè ṣe bẹ́ẹ̀ tó o bá fẹ́ kí àwọn aṣáájú-ọ̀nà yẹn wọnú ayé tuntun dípò rẹ”

[Graph tó wà ní ojú ìwé 84]

Ìlú Yangon ni Arákùnrin Carmichael àti alábàáṣiṣẹ́pọ̀ rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù wọn. Kò pẹ́ rárá tí wọ́n fi pàdé Bertram Marcelline àti Vernon French tí wọ́n jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Íńdíà tó tan mọ́ àwọn ará ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.b Tọkàntọkàn làwọn ọkùnrin yìí fi fẹ́ gbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Kíá làwọn méjèèjì pa ṣọ́ọ̀ṣì tì, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù láìjẹ́ bí àṣà fún àwọn ọ̀rẹ́ wọn. Kò pẹ́ púpọ̀ lẹ́yìn ìgbà yẹn tí nǹkan bí ogún [20] èèyàn fi bẹ̀rẹ̀ sí í ṣèpàdé déédéé ní ilé Arákùnrin Bertram.c Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ ni wọ́n fi máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

[Àwòrán]

Àwọn akéde tó wà ní ìlú Yangon, lọ́dún 1932

Lọ́dún 1928, Arákùnrin George Wright tí òun náà jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, tó sì jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì wá láti ilẹ̀ Íńdíà sí Burma. Láàárín oṣù márùn-ún, ó lọ yíká orílẹ̀-èdè náà, ó sì ń fúnrúgbìn òtítọ́ bó ṣe ń pín ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fún àwọn èèyàn. Àkòrí ọ̀kan lára àwọn ìwé náà ni Àràádọ́ta Ọ̀kẹ́ Tó Wà Láàyè Nísinsìnyí Kò Ní Kú Láé! Ìwé yìí ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ́kọ́ túmọ̀ sí èdè Burmese.

Ọdún méjì lẹ́yìn náà, Arákùnrin Claude Goodman àti Ronald Tippin tí wọ́n jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà dé sí ìlú Yangon. Nígbà tí wọ́n dé, wọ́n rí i pé àwọn ará kan wà níbẹ̀ tí wọ́n ń ṣèpàdé déédéé, àmọ́ wọn kì í wàásù. Arákùnrin Claude sọ pé àwọ́n gba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n máa wá sóde ẹ̀rí láwọn ọjọ́ Sunday. Arákùnrin kan tiẹ̀ béèrè bóyá òun lè bẹ àwọn aṣáájú-ọ̀nà pé kí wọ́n máa bá òun wàásù, kí òun sì máa sanwó fún wọn. Arákùnrin Ronald wá sọ fún un pé: “Kò burú, o lè ṣe bẹ́ẹ̀ tó o bá fẹ́ kí àwọn aṣáájú-ọ̀nà yẹn wọnú ayé tuntun dípò rẹ.” Bí Arákùnrin Ronald ṣe sọjú abẹ níkòó yìí ló fún àwọn ará yẹn ní ìṣírí láti tẹ̀ síwájú. Kò pẹ́ rárá tí ọ̀pọ̀ àwọn ará fi bẹ̀rẹ̀ sí í bá Arákùnrin Claude àti Ronald lọ sóde ẹ̀rí.

“Rachel, Mo Ti Rí Òtítọ́!”

Lọ́dún 1930, Arákùnrin Ronald àti Claude pàdé Ọ̀gbẹ́ni Sydney Coote, tó jẹ́ ọ̀gá iléeṣẹ́ ọkọ̀ rélùwéè ní ìlú Yangon. Ọ̀gbẹ́ni Sydney gba ìdìpọ̀ àwọn ìwé aláwọ̀ mèremère táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde. Lẹ́yìn tí Sydney ka apá kan nínú ọ̀kan lára àwọn ìwé náà, ṣe ló pe ìyàwó rẹ̀, ó ní: “Rachel, mo ti rí òtítọ́!” Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn tí gbogbo ìdílé Coote fi di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Arákùnrin Sydney máa ń fi tọkàntara kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́. Ọmọ rẹ̀ obìnrin tó ń jẹ́ Norma Barber, tó jẹ́ míṣọ́nnárì tẹ́lẹ̀, tó sì ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì báyìí sọ pé: “Bàbá mi ṣe ìwé atọ́ka àwọn ẹsẹ Bíbélì fún ara rẹ̀. Tó bá ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tó ṣàlàyé ẹ̀kọ́ Bíbélì, ó máa ń kọ ọ́ sí abẹ́ àkọlé tó bá yẹ nínú ìwé atọ́ka náà. Ó pe orúkọ ìwé náà ní Where is it? [Ibo ló wà?]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 87]

Sydney Coote (ní àárín) máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gan-an. Òun àti Rachel ìyàwó rẹ̀ (lápá òsì), máa ń wàásù fáwọn èèyàn

Kì í ṣe pé Arákùnrin Sydney fẹ́ràn láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìkan, ó tún fẹ́ kọ́ àwọn ẹlòmíì lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Torí náà, ó kọ lẹ́tà sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó wà lórílẹ̀-èdè Íńdíà láti béèrè bóyá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà ní Burma. Kò pẹ́ tó fi rí èsì gbà, wọ́n sì tún fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ àti orúkọ àwọn èèyàn kan ránṣẹ́ sí i. Norma sọ pé: “Ṣe ni bàbá mi kọ̀wé sí gbogbo ẹni tí orúkọ̀ rẹ̀ wà lórí ìwé náà pé kí wọ́n wá sílé wa. Arákùnrin bíi márùn-ún sí mẹ́fà ló wá sílé wa, wọ́n sì sọ bá a ṣe lè máa jẹ́rìí lọ́nà àìjẹ́-bí-àṣà fún wa. Kíá làwọn òbí mi ti bẹ̀rẹ̀ sí í pín àwọn ìwé ìròyìn yẹn fún àwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn aládùúgbò wọn. Wọ́n tún fi lẹ́tà àti àwọn ìwé náà ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn mọ̀lẹ́bí wa pátá.”

Nígbà tí ẹ̀gbọ́n Sydney kan, ìyẹn Daisy D’Souza, tó ń gbé ní ìlú Mandalay, rí lẹ́tà Sydney gbà, àti ìwé tó fi ránṣẹ́, ìyẹn ìwé The Kingdom, the Hope of the World, kíá ló fèsì lẹ́tà náà, ó sì ní kí wọ́n tún fi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ àti Bíbélì ránṣẹ́ sí òun. Ó ka gbogbo ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ yẹn láti òru mọ́jú. Ohun tó sì kà wọ̀ ọ́ lọ́kàn tó bẹ́ẹ̀ tó fi pe àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́fẹ̀ẹ̀fà jọ, tó sì sọ fún wọn pé àwọn ò lọ sí Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì mọ́ torí pé àwọn ti rí òtítọ́. Ìyàlẹ́nu ńlá ló jẹ́ fún wọn! Nígbà tó yá, ọkọ rẹ̀ àtàwọn ọmọ rẹ̀ náà kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Ní báyìí, ìran mẹ́rin nínú ìdílé D’Souza ló ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Àwọn Aṣáájú-Ọ̀nà Onígboyà

Láti ọdún 1930 sí 1933, àwọn aṣáájú-ọ̀nà fi ìtara wàásù ìhìn rere láwọn ọ̀nà ojú irin tó wá láti ìlú Yangon sí Myitkyina, nítòsí ààlà ilẹ̀ Ṣáínà. Wọ́n tún wàásù dé ìlú Mawlamyine (ìyẹn Moulmein) àti ìlú Sittwe (ìyẹn Akyab), ní etíkun tó wà lápá ìlà oòrùn àti ìwọ̀ oòrùn ìlú Yangon. Èyí mú kí wọ́n dá àwọn ìjọ kéékèèké sílẹ̀ ní ìlú Mawlamyine àti Mandalay.

Nígbà tó di ọdún 1938, orílẹ̀-èdè Ọsirélíà bẹ̀rẹ̀ sí í bójú tó iṣẹ́ ìwáàsù lórílẹ̀-èdè Burma dípò orílẹ̀-èdè Íńdíà. Torí náà, àwọn aṣáájú-ọ̀nà láti orílẹ̀-èdè Ọsirélíà àti New Zealand bẹ̀rẹ̀ sí í ya wọ Burma. Lára àwọn tí wọ́n wá síbẹ̀, tí wọ́n sì ṣiṣẹ́ tọkàntọkàn nígbà yẹn ni Fred Paton, Hector Oates, Frank Dewar, Mick Engel àti Stuart Keltie. Ògbóṣáṣá aṣáájú-ọ̀nà làwọn arákùnrin ọ̀wọ́n yìí.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 89]

Frank Dewar

Arákùnrin Fred Paton sọ pé: “Láàárín ọdún márùn-ún tí mo lò ní orílẹ̀-èdè Burma, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ìlú tó wà níbẹ̀ ni mo wàásù dé. Nígbà yẹn, oríṣiríṣi àìsàn ló bá mi fínra. Lára rẹ̀ ni àìsàn ibà, ibà jẹ̀funjẹ̀fun, ìgbẹ́ ọ̀rìn àtàwọn àìsàn míì. Lọ́pọ̀ ìgbà, lẹ́yìn tí mo bá ti wàásù káàkiri látàárọ̀, kò ní sí ibi tí màá sùn lálẹ́. Àmọ́, Jèhófà máa ń pèsè àwọn ohun tí mo nílò, ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ sì ń fún mi lókun.” Arákùnrin Frank Dewar tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ New Zealand fara da onírúurú ìṣoro. Ó sọ pé: “Mo máa ń pàdé àwọn jàǹdùkú àtàwọn oníjàgídíjàgan, títí kan àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba tí wọ́n ń halẹ̀ mọ́ni. Àmọ́ mo ti wá mọ̀ pé bí mo bá fara balẹ̀, tí mo hùwà ọmọlúwàbí, tí mo lo ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tí mo sì fi ọgbọ́n bá wọn sọ̀rọ̀, wẹ́rẹ́ báyìí ni ohun tó dà bíi pé kò ṣeé ṣe máa ń bọ́ sí i. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe èèyànkéèyàn rárá.”

Gbọ̀ọ̀rọ̀gbọọrọ làwọn aṣáájú-ọ̀nà yìí fi yàtọ̀ sí àwọn míì tí wọ́n jẹ́ ọmọ ilẹ̀ òkèèrè tó kórìíra àwọn ará ìlú yẹn gan-an. Àwọn aṣáájú-ọ̀nà yìí nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, wọ́n sì máa ń bọ̀wọ̀ fáwọn aráàlú. Onírẹ̀lẹ̀ làwọn ọmọ ilẹ̀ Burma, wọ́n fẹ́ràn kéèyàn máa ṣe jẹ́jẹ́ kó sì fi ọgbọ́n àti òye hùwà dípò kó máa ṣàtakò tàbí kó kàn máa sọ̀rọ̀ ṣàkàṣàkà. Ìdí nìyen tí wọ́n fi fẹ́ràn àwọn aṣáájú-ọ̀nà wa yìí gan-an torí pé wọ́n jẹ́ ọmọlúwàbí. Àwọn aṣáájú-ọ̀nà yìí fi hàn nínú ìwà àti ìṣe wọn pé Kristẹni tòótọ́ ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.—Jòh.13:35.

Àpéjọ Àgbègbè Tí A Kò Lè Gbàgbé

Lẹ́yìn oṣù mélòó kan táwọn aṣáájú-ọ̀nà yẹn dé sílẹ̀ Burma, ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní ilẹ̀ Ọsirélíà ṣètò pé ká ṣe àpéjọ àgbègbè ní ìlú Yangon. Gbọ̀ngàn ìlú Yangon ni àpéjọ náà ti wáyé. Ìrísí gbọ̀ngàn yẹn fani mọ́ra gan-an, òkúta mábìlì ni wọ́n fi ṣe àtẹ̀gùn rẹ̀, idẹ sì ni wọ́n fi ṣe àwọn ìlẹ̀kùn ńláńlá tó wà níbẹ̀. Àwọn ará wá sí àpéjọ náà láti orílẹ̀-èdè Thailand, Malaysia àti Singapore. Arákùnrin Alex MacGillivray, tó jẹ́ ìránṣẹ́ ẹ̀ka láti ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní ilẹ̀ Ọsirélíà tún mú àwọn ará kan wá láti ìlú Sydney.

Àsọyé fún gbogbo ènìyàn, tá a pe àkòrí rẹ̀ ní “Ogun Kárí Ayé Kù sí Dẹ̀dẹ̀,” ta àwọn èèyàn náà kìjí torí ó jọ pé ogun ti fẹ́ bẹ́ sílẹ̀ ní ìlú yẹn. Arákùnrin Fred Paton sọ pé: “Mi ò tíì rí i káwọn èèyàn tètè kún inú gbọ̀ngàn bíi tọjọ́ yẹn rí. Nígbà tí mo ṣí àwọn ilẹ̀kùn àbáwọlé, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn ló rọ́ wìtìwìtì gun orí àwọn àtẹ̀gùn inú gbọ̀ngàn náà. Kò tó ìṣẹ́jú mẹ́wàá tí àwọn èèyàn tó lé ní ẹgbẹ̀rún [1000] kan ti rún ara wọ́n mọ́ orí àga tí kò ju ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ àti àádọ́ta [850] lọ.” Arákùnrin Frank Dewar sọ pé: “Ṣe la ti àwọn ilẹ̀kùn àbáwọlé torí inú ilé ti kún, ìta ò sì gba àwọn èrò mọ́. Kódà, ẹgbẹ̀rún [1,000] kan èèyàn ló tún ṣì wà níta. Síbẹ̀, àwọn ọ̀dọ́ kan tún dọ́gbọ́n rá pálá gba àwọn ọ̀nà kéékèèké tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ wọlé.”

Yàtọ̀ sí pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló wá sí àpéjọ yẹn, nǹkan míì tó tún wú àwọn ará wa lórí ni bó ṣe jẹ́ pé oríṣiríṣi èèyàn ló wá síbẹ̀, títí kan àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Burma tí wọ́n jẹ́ ẹ̀yà ọ̀tọ̀ọ̀tọ. Ìdí ni pé títí dìgbà tá à ń wí yìí, ìwọ̀nba làwọn ọmọ ìbílẹ̀ Burma tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Èyí tó pọ̀ jù nínú wọn ti jingíri sínú ẹ̀sìn Búdà. Àwọn ọmọ ìbílẹ̀ tí wọ́n ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì kò gbé nítòsí, àwọn ẹ̀yà Kayin, Karen, Kachin àtàwọn Chin ló sì pọ̀ jù lára wọn. A ò tíì fi bẹ́ẹ̀ wàásù ìhìn rere débi tí wọ́n wà, tó fi hàn pé iṣẹ́ ṣì ń bẹ fún wa láwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù tí wọ́n ti ń sọ èdè ìbílẹ̀. Àmọ́ ó dá wa lójú pé láìpẹ́, àwọn ará Burma látinú oríṣiríṣi ẹ̀yà máa wà lára “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tó wá láti inú gbogbo orílẹ̀-èdè.—Ìṣí. 7:9.

Àwọn Kayin Tó Kọ́kọ́ Di Ẹlẹ́rìí Jèhófà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 92]

Arábìnrin Chu May, “Daisy” (lápá òsì) tó kọ́kọ́ di Ẹlẹ́rìí Jèhófà lára àwọn Kayin àti Hnin May, “Lily” (lápá ọ̀tún)

Lọ́dún 1940, Arábìnrin Ruby Goff, tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, wàásù ní ìlú kékeré kan tó ń jẹ́ Insein, nítòsí ìlú Yangon. Nígbà tó wà lóde ẹ̀rí lọ́jọ́ kan, àwọn èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ gbọ́ ìwàásù. Ni Ruby bá bẹ Jèhófà, ó ní: “Jèhófà jọ̀ọ́, jẹ́ kí n rí ẹnì kan tó máa gbọ́ ìwàásù kí n tó pa dà sílé.” Nígbà tí Ruby wọ ilé tó kàn, ó rí obìnrin kan tó ń jẹ́ Hmwe Kyaing, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Kayin. Ṣọ́ọ̀ṣì Onítẹ̀bọmi ni obìnrin náà ń lọ, àmọ́ ó fetí sí ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run lọ́jọ́ yẹn. Kò pẹ́ rárá tí òun àtàwọn ọmọbìnrin rẹ̀ méjì, ìyẹn Chu May (tó tún ń jẹ́ Daisy) àti Hnin May (tó tún ń jẹ́ Lily), fi bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n sì tẹ̀ síwájú dáadáa nípa tẹ̀mí. Kò pẹ́ sígbà yẹn tí obìnrin náà kú. Lily, tó kéré jù lára àwọn ọmọ rẹ̀ ló wá di ẹni àkọ́kọ́ lára àwọn ẹ̀yà Kayin tó ṣèrìbọmi, tó sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbà tó yá, Daisy náà ṣèrìbọmi.

Lily àti Daisy di aṣáájú-ọ̀nà onítara, wọ́n sì fi àpẹẹrẹ àtàtà lélẹ̀. Ní báyìí, ọgọ́rọ̀ọ̀rún àtọmọdọ́mọ wọn àtàwọn tí wọ́n kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Myanmar àti nílẹ̀ òkèèrè.

Àwọn Ohun Tójú Rí Nígbà Ogun Àgbáyé Kejì

Nígbà tó fi máa di ọdún 1939, Ogun Àgbáyé Kejì ti bẹ̀rẹ̀ nílẹ̀ Yúróòpù, èyí sì da jìnnìjìnnì bo àwọn èèyàn kárí ayé. Bí ogun yẹn ṣe ń kó àwọn èèyàn láyà sókè làwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì túbọ̀ ń fúngun mọ́ ìjọba pé kí wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé àwọn ìwé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Arákùnrin Mick Engel, tó ń bójú tó ibi tí à ń kó àwọn ìwé wa sí ní ìlú Yangon, lọ bá ọ̀kan lára àwọn aláṣẹ tó wá láti ilẹ̀ Amẹ́ríkà. Ó sì gba ìwé àṣẹ láti fi ọkọ̀ àwọn ọmọ ogun kó nǹkan bíi tọ́ọ̀nù méjì lára àwọn ìwé wa láti orílẹ̀-èdè Burma kọjá lọ sí ilẹ̀ Ṣáínà.

Arákùnrin Fred Paton àti Hector Oates ló kó àwọn ìwé náà lọ sọ́dọ̀ ọ̀gá ilé iṣẹ́ ọkọ̀ rélùwéè tó wà ní ìlú Lashio, nítòsí ààlà ilẹ̀ Ṣáínà. Nígbà tí wọ́n rí ọ̀gá àwọn tó ń bójú tó àwọn ọkọ̀ tó ń lọ sílẹ̀ Ṣáínà, ó fìbínú jágbe mọ́ wọn. Ó ní: “Àbí ẹ ò mọ nǹkan tẹ́ ẹ̀ ń sọ ni? Báwo ni mo ṣe lè fún yín láyè láti kó àwọn ìwé ọ̀ràn tí ẹ̀ ń kó kiri yìí sínú ọkọ̀ akẹ́rù wa, nígbà táwa gan-an ò tíì ríbi kó àwọn ẹrù ogun àtàwọn oògùn tá a fẹ́ fi tọ́jú àwọn aláìsàn sí?” Ni Arákùnrin Fred bá dákẹ́, ó sì fa ìwé àṣẹ tó gbà látọ̀dọ̀ aṣojú ilẹ̀ Amẹ́ríkà yọ látinú báàgì rẹ̀. Ó sọ fún ọkùnrin yẹn pé ọ̀ràn ńlá ló máa dá tó bá kọ̀ láti tẹ̀ lé àṣẹ tí wọ́n pa láti ìlú Yangon. Bí ọkùnrin náà ṣe gbọ́ ohun tí Arákùnrin Fred sọ yìí, ó ní kí ọ̀kan lára àwọn awakọ̀ wọn gbé ọkọ̀ akẹ́rù kékeré kan tẹ̀ lé àwọn arákùnrin náà, kí wọ́n sì fi kó àwọn ìwé tí wọ́n fẹ́ kó. Wọ́n rin ìrìn ẹgbẹ̀rún méjì àti irinwó [2,400] kìlómítà lọ sí ilú Chongqing (ìyẹn Chungking), ní àárín gbùngbùn gúúsù ilẹ̀ Ṣáínà. Ibẹ̀ ni wọ́n ti pín àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tó ṣeyebíye yẹn. Wọ́n sì tún láǹfààní láti wàásù fún Ọ̀gbẹ́ni Chiang Kai-shek, tó jẹ́ ààrẹ ilẹ̀ Ṣáínà nígbà yẹn.

Nígbà táwọn aláṣẹ náà máa fi dé ibi tí à ń kó ìwé wa sí, wọn ò bá ìwé kankan níbẹ̀

Lóṣù May, ọdún 1941, ìjọba tó ń gbókèèrè ṣàkóso láti ilẹ̀ Íńdíà kọ̀wé ránṣẹ́ sí ìlú Yangon. Wọ́n sì pàṣẹ pé káwọn aláṣẹ gbẹ́sẹ̀ lé àwọn ìwé wa. Gbàrà tí àwọn arákùnrin méjì tó ń ṣiṣẹ́ ní ilé iṣẹ́ ìfìwéránṣẹ́ ti gbọ́ ni wọ́n ti sọ fún Arákùnrin Mick Engel. Ni Arákùnrin Mick bá pe Arábìnrin Lily àti Daisy, kí wọ́n lè tètè jọ lọ síbi tí à ń kó àwọn ìwé wa sí. Wọ́n yára kó ogójì [40] páálí tó ṣẹ́ kù, tí ìwé kún inú wọn fọ́fọ́, wọ́n sì lọ tọ́jú wọn sí àwọn ilé káàkiri ìlú Yangon níbi tí àwọn aláṣẹ kò ti lè rí i. Nígbà táwọn aláṣẹ náà máa fi dé ibi tí à ń kó ìwé wa sí, wọn ò bá ìwé kankan níbẹ̀.

Ní December 11, ọdún 1941, ọjọ́ mẹ́rin péré lẹ́yìn tí ilẹ̀ Japan ju bọ́ǹbù sí Pearl Harbor, àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Japan tún bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀jò àdó olóró sí ilẹ̀ Burma. Ní òpin ọ̀sẹ̀ yẹn, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bíi mélòó kan kóra jọ sínú ilé kékeré kan tó wà lókè ibùdókọ̀ rélùwéè ti ìlú Yangon. Lẹ́yìn tí wọ́n fara balẹ̀ gbọ́ àsọyé Bíbélì tán, Lily ṣèrìbọmi nínú bàsíà ńlá kan níbẹ̀.

Ọ̀sẹ̀ méjìlá lẹ́yìn èyí làwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Japan ya wọ ìlú Yangon, àmọ́ àwọn èèyàn kéréje ni wọ́n bá ní ìlú náà. Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń gbé níbẹ̀ ló ti sá lọ sílẹ̀ Íńdíà. Àìmọye èèyàn ló kú sójú ọ̀nà nítorí ebi, àárẹ̀ àti àìsàn. Arákùnrin Sydney Coote àti ìdílé rẹ̀ náà sá kúrò nílùú Yangon, àmọ́ àìsàn ibà tó máa ń ṣàkóbá fún ọpọlọ ló pa arákùnrin náà nítòsí ẹnubode ilẹ̀ Íńdíà. Àwọn sójà ilẹ̀ Japan yìnbọn pa arákùnrin kan. Arákùnrin míì sì pàdánù ìyàwó àtàwọn ọmọ rẹ̀ nígbà tí wọ́n ju bọ́ǹbù sílé wọn.

Àwọn ará tó ṣẹ́ kù sí orílẹ̀-èdè náà kò pọ̀ rárá. Arábìnrin Lily àti Daisy kó lọ sí ìlú Pyin Oo Lwin (ìyẹn Maymyo), nítòsí ìlú Mandalay. Ìlú yẹn pa rọ́rọ́, ó sì wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn òkè kan. Ibẹ̀ làwọn arábìnrin yìí ti ń fúnrúgbìn òtítọ́ nìṣó, èyí sì méso jáde nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Ẹnì kẹta wọn ni Arákùnrin Cyri Gay, tó kó lọ sí abúlé Thayarwaddy, tó wà ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún [100] kìlómítà níhà gúúsù ìlú Yangon. Ibẹ̀ ló fara pa mọ́ sí títí ogun fi parí.

Inú Wa Dùn Pé Ojú Túnra Rí

Nígbà tí ogun parí, èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ará tí wọ́n sá lọ sílẹ̀ Íńdíà bẹ̀rẹ̀ sí í pa dà sí Burma. Ní oṣù April, ọdún 1946, akéde mẹ́jọ péré ló ń ròyìn déédéé ní Ìjọ Yangon. Àmọ́ nígbà tí ọdún náà fi máa parí, akéde mẹ́rìnlélógún [24] ló ti wà ní ìjọ náà. Ìgbà yẹn ni wọ́n ṣe àpéjọ kan.

Inú ọgbà iléèwé kan ní ìlú Insein ni wọ́n ti ṣe àpéjọ náà fún ọjọ́ méjì gbáko. Arákùnrin Theo Syriopoulos, tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ní ìlú Yangon lọ́dún 1932 sọ pé: “Nígbà tí mo dé láti ilẹ̀ Íńdíà, wọ́n sọ fún mi pé èmi ni màá sọ àsọyé fún gbogbo ènìyàn ní àpéjọ náà. Mi ò sì tíì sọ irú àsọyé yẹn rí. Kódà, ẹ̀ẹ̀mejì péré ni mo tíì ṣe iṣẹ́ oníṣẹ̀ẹ́jú márùn-ún nípàdé. Àmọ́ a dúpẹ́ pé àpéjọ yẹn kẹ́sẹ járí, àwọn èèyàn tó ju ọgọ́rùn-ún [100] ló wá síbẹ̀.”

Ọ̀sẹ̀ mélòó kan lẹ́yìn náà, ọkùnrin kan tó jẹ́ olóyè lááàrín àwọn ẹ̀yà Kayin tó sì tún nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ Bíbélì, fún ìjọ wa ní ilẹ̀ kan sí abúlé Ahlone lẹ́gbẹ̀ẹ́ odò nítòsí ìlú Yangon. Orí ilẹ̀ náà làwọn ará fi ọparun kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kan tó lè gba nǹkan bí ọgọ́rùn-ún [100] èèyàn sí. Ìdùnnú wá ṣubú lu ayọ̀ fún àwọn ará ní ìjọ náà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ogun jà kárí ilẹ̀ náà, wọn ò jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wọn yingin. Wọ́n sì ti múra tán láti máa bá iṣẹ́ ìwàásù nìṣó ní pẹrẹu.

Àwọn Míṣọ́nnárì Tó Kọ́kọ́ Wá Láti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 97]

Lókè: Àwọn míṣọ́nnárì tó kọ́kọ́ dé láti Gílíádì, Hubert Smedstad, Robert Kirk, Norman Barber àti Robert Richards Nísàlẹ̀: (lọ́wọ́ ẹ̀yìn) Nancy D’Souza, Milton Henschel, Nathan Knorr, Robert Kirk àti Terence D’Souza, (lọ́wọ́ iwájú) Russell Mobley, Penelope Jarvis-Vagg, Phyllis Tsatos, Daisy D’Souza àti Basil Tsatos

Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1947, tayọ̀tayọ̀ làwọn arákùnrin bíi mélòó kan fi lọ sí etíkun ìlú Yangon láti lọ pàde Arákùnrin Robert Kirk. Òun ni míṣọ́nnárì àkọ́kọ́ tí wọ́n rán wá sí orílẹ̀-èdè Burma láti ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì. Kò pẹ́ sígbà yẹn táwọn míṣọ́nnárì mẹ́ta míì tún dé. Orúkọ wọn ni Norman Barber, Robert Richards àti Hubert Smedstad. Wọ́n jọ dé pẹ̀lú Arákùnrin Frank Dewar, òun náà ti ṣe aṣáájú-ọ̀nà rí nílẹ̀ Íńdíà nígbà ogun.

Inú ìlú tí ogun ti bàjẹ́ làwọn míṣọ́nnárì yìí dé sí. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ilé tó wà ní ìlú náà ni wọ́n ti dáná sun. Inú àwọn ilé ẹgẹrẹmìtì tí wọ́n fi ọparun kọ́ sí ẹ̀gbẹ́ títì ni ọ̀pọ̀ èèyàn ń gbé. Ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ títì làwọn èèyàn ti ń dáná, tí wọ́n ti ń fọṣọ, tí wọ́n sì ti ń ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan. Síbẹ̀, àwọn èèyàn yìí làwọn míṣọ́nnárì fẹ́ wá kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Torí náà, wọ́n mú ara wọn bá ipò táwọn èèyàn náà wà mu, wọ́n sì gbájú mọ́ iṣẹ́ ìwàású wọn.

Ní September 1, ọdún 1947, a ṣí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí ilé táwọn míṣọ́nnárì ń gbé ní òpópónà Signal Pagora, tí kò fi bẹ́ẹ̀ jìnnà sí àárín gbùngbùn ìlú Yangon. Arákùnrin Robert Kirk ni wọ́n fi ṣe alábòójútó ẹ̀ka. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni ìjọ Yangon kúrò ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tí wọ́n fi ọparun kọ́ sí abúlé Ahlone, wọ́n kó lọ sí ilé pẹ̀tẹ́ẹ̀sì kan ní òpópónà Bogalay Zay. Kò jìnnà rárá síbi tí ọ́fíìsì ìjọba wà, ìyẹn ilé ńlá kan tó lẹ́wà gan-an tí ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì fi ṣe ọ́fíìsì wọn nígbà tí wọ́n ṣì ń ṣàkóso ìlú yẹn. Kété lẹ́yìn náà ni ìjọba yìí kúrò lórílẹ̀-èdè Burma.

Ogun Abẹ́lé Bẹ́ Sílẹ̀!

Ní January 4, ọdún 1948, orílẹ̀-èdè Burma gba òmìnira lẹ́yìn ọgọ́ta [60] ọdún tí ìjọba Gẹ̀ẹ́sì ti ń ṣàkóso wọn. Àmọ́, ṣe ni ogun abẹ́lé tún bẹ́ sílẹ̀ lórílẹ̀-èdè náà.

[Graph tó wà ní ojú ìwé 100]

Onírúurú ẹ̀yà ń bára wọn jà torí pé kálukú ló fẹ́ ní ìpínlẹ̀ tiẹ̀. Àwọn ọmọ ogun táwọn èèyàn kó jọ àtàwọn jàǹdùkú sì ń figa gbága torí kí wọ́n lè ṣàkóso àwọn ìpínlẹ̀ náà. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1949, àwọn ọlọ̀tẹ̀ tó kóra wọn jọ ti ń ṣàkóso ọ̀pọ̀ ibi tó pọ̀ jù lórílẹ̀-èdè náà. Bí ìjà ṣe bẹ́ sílẹ̀ láwọn ìgbèríko ìlú Yangon nìyẹn.

Nígbà míì ogun yẹn máa ń le, á sì tún rọlẹ̀ nígbà míì, àmọ́ àwọn ará ń bá iṣẹ́ ìwàásù wọn lọ tìṣọ́ratìṣọ́ra. Nígbà tó yá, a kó ẹ̀ka ọ́fíìsì wa kúrò ní òpópónà Signal Pagoda lọ sí ilé pẹ̀tẹ́ẹ̀sì kan ní òpópónà 39th Street níbi tí kò ti sí rògbòdìyàn. Ibẹ̀ ni ọ́fíìsì àwọn aṣojú ìjọba ilẹ̀ òkèèrè pọ̀ sí. Kò sì jìnnà rárá sí ilé iṣẹ́ ìfìwéránṣẹ́.

Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, agbára àwọn ọmọ ogun orílẹ̀-èdè Burma ń pọ̀ sí i, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í lé àwọn ọlọ̀tẹ̀ yẹn lọ sáwọn apá ibi tí òkè wà ní orílẹ̀-èdè náà. Nígbà tó máa fi di nǹkan bí ọdún 1955, apá ìjọba orílẹ̀-èdè náà ti bẹ̀rẹ̀ sí í ká ibi tó pọ̀ dáadáa nílẹ̀ náà. Àmọ́ ogun abẹ́lé kò tán nílẹ̀ yẹn bọ̀rọ̀. Ó ṣì máa ń ṣẹ́ yọ lọ́nà kan tàbí òmíràn títí di òní olónìí.

A Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Wàásù, A sì Ń Kọ́ni Lédè Burmese

Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé èdè Gẹ̀ẹ́sì nìkan làwọn ará fi ń wàásù lórílẹ̀-èdè Burma títí di nǹkan bí ọdún 1955. Àwọn èèyàn tó kàwé tí wọ́n ń gbé nígboro àtàwọn ìlú ńláńlá nìkan ló sì gbọ́ èdè yìí. Àmọ́ ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn lórílẹ̀-èdè náà ló jẹ́ pé èdè Burmese (ìyẹn Myanmar), Kayin, Kachin, Chin àtàwọn èdè ìbílẹ̀ míì ni wọ́n ń sọ. Báwo ni wọ́n ṣe máa wá gbọ́ ìhìn rere tí à ń wàásù?

Lọ́dún 1934, Arákùnrin Sydney Coote sọ fún ọkùnrin kan tó jẹ́ olùkọ́ èdè Kayin pé kó bá wa túmọ̀ àwọn ìwé kéékèèké kan sí èdè Burmese àti èdè Kayin. Lẹ́yìn náà, àwọn ará wa kan túmọ̀ ìwé Jẹki Ọlọrun Jẹ Olõtọ àtàwọn ìwé kéékèèké míì sí èdè Burmese. Lọ́dún 1950, Arákùnrin Robert Kirk sọ fún Arákùnrin Ba Oo pé kó túmọ̀ àwọn àpilẹ̀kọ tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ sí èdè Burmese. Tí arákùnrin náà bá ti fi ọwọ́ kọ ìtúmọ̀ náà sí orí ìwé, àwọn ilé iṣẹ́ ìtẹ̀wé kan ní ìlú Yangon máa ń bá wa tẹ̀ ẹ́ jáde. A sì máa ń pín in fáwọn tó bá wá sí ìpàdé. Nígbà tó yá, ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ra ẹ̀rọ ìtẹ̀wé tó ṣeé fi tẹ èdè Burmese, kí iṣẹ́ ìtúmọ̀ èdè náà lè túbọ̀ yá.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 101]

Ba Oo (lápá òsì) máa ń túmọ̀ àwọn àpilẹ̀kọ tó wà fún ìkẹ́kòọ́ nínú Ilé Ìṣọ́ sí èdè Burmese

Nǹkan ò rọrùn rárá fún àwọn tó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìtúmọ̀ èdè nígbà yẹn. Arákùnrin Naygar Po Han ló ń bá iṣẹ́ náà lọ nígbà tí Arákùnrin Ba Oo kò lè ṣe é mọ́. Ó sọ pé: “Tójúmọ́ bá ti mọ́, màá gba ìdí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ mi lọ kí n lè rí ohun tí màá fi gbọ́ bùkátà ìdílé mi. Tó bá sì di alẹ́, mo máa ń lo iná mànàmáná tí kò fi bẹ́ẹ̀ mọ́lẹ̀ dáadáa kí n lè ríran túmọ̀ àwọn àpilẹ̀kọ wa títí wọ ààjìn òru. Mi ò fi bẹ́ẹ̀ gbọ́ Gẹ̀ẹ́sì dáadáa, torí náà ìtúmọ̀ yẹn kò fi bẹ́ẹ̀ péye nígbà náà. Ohun tó ṣáà jẹ wá lógún ni pé kí ọ̀pọ̀ èèyàn rí ìwé wa kà bó bá ti lè ṣeé ṣe tó.” Nígbà tí Arákùnrin Robert Kirk sọ fún Arábìnrin Doris Raj pé kó túmọ̀ Ilé Ìṣọ́ sí èdè Burmese, ṣe ni arábìnrin yìí bú sẹ́kún torí ó ti ro ara rẹ̀ pin pé òun ò lè ṣe iṣẹ́ náà. Ó ní: “Mi ò fi bẹ́ẹ̀ kàwé púpọ̀, mi ò sì ṣe iṣẹ́ ìtúmọ̀ èdè rí. Àmọ́ Arákùnrin Kirk sọ fún mi pé kí n gbìyànjú ẹ̀ wò. Torí náà mo gbàdúrà sí Jèhófà, mo sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà.” Ó ti tó nǹkan bí àádọ́ta [50] ọdún báyìí tí Arábìnrin Doris ti wà lẹ́nu iṣẹ́ ìtúmọ̀ èdè ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní ìlú Yangon. Arákùnrin Naygar Po Han náà ti di ẹni ọdún mẹ́tàléláàádọ́rùn-ún [93] báyìí. Bẹ́tẹ́lì ló wà báyìí, iná ìtara rẹ̀ kò jó rẹ̀yìn rárá bó ṣe ń bá iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀ lọ ní rabidun.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 103]

Lọ́dún 1956, Nathan Knorr mú Ilé Ìṣọ́ jáde ní èdè Burmese

Lọ́dún 1956, Arákùnrin Nathan Knorr láti oríléeṣẹ́ wa wá sí orílẹ̀-èdè Burma, ó sì kéde pé a máa bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ Ilé Ìṣọ́ jáde ní èdè Burmese. Ó tún gba àwọn míṣọ́nnárì níyànjú pé kí wọ́n kọ́ èdè náà kí ìwàásù wọn lè túbọ̀ máa wọ àwọn èèyàn lọ́kàn. Ọ̀rọ̀ ìyànjú tí Arákùnrin Knorr sọ fún àwọn míṣọ́nnárì mú kí wọ́n túbọ̀ tẹra mọ́ kíkọ́ èdè Burmese. Lọ́dún 1957, Arákùnrin Frederick Franz láti oríléeṣẹ wa ló sọ lájorí àsọyé ní àpéjọ ọlọ́jọ́ márùn-ún tí wọ́n ṣe nínú gbọ̀ngàn Ilé Ẹ̀kọ́ Rélùwéè ní ìlú Yangon. Ó gba àwọn tó ń múpò iwájú níyànjú pé kí wọ́n rán àwọn aṣáájú-ọ̀nà lọ sí àwọn ìlú àtàwọn àgbègbè tó wà káàkiri orílẹ̀-èdè náà kí wọ́n lè mú iṣẹ́ ìwàásù gbòòrò sí i. Ilú Mandalay, tó jẹ́ olú ìlú orílẹ̀-èdè Burma tẹ́lẹ̀, tó sì tún jẹ́ ìlú kejì tó tóbi jù lórílẹ̀-èdè náà, ni wọ́n kọ́kọ́ rán àwọn aṣáájú-ọ̀nà yẹn lọ láti wàásù.

Iṣẹ́ Ìwàásù So Èso Rere ní Ìlú Mandalay

Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1957, àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe mẹ́fà dé sí ìlú Mandalay. Wọ́n sì dara pọ̀ mọ́ Arákùnrin Robert Richards, tó jẹ́ míṣọ́nnárì àti Baby, ìyàwó rẹ̀. Kò rọrùn fún àwọn aṣáájú-ọ̀nà yìí láti wàásù ní ìlú náà torí pé ibẹ̀ làwọn ẹlẹ́sìn Búdà pọ̀ sí jù. Ibẹ̀ sì ni nǹkan bí ìdajì àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé tó wà lórílẹ̀-èdè Burma ń gbé. Àmọ́ nígbà tó yá, àwọn aṣáájú-ọ̀nà yìí wá rí i pe, Jèhófà ní “ọ̀pọ̀ ènìyàn ní ìlú ńlá yìí,” bíi ti ìlú Kọ́ríǹtì àtijọ́.—Ìṣe 18:10.

Ọ̀kan lára irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ ni ọmọléèwé kan tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kànlélógún [21] lára àwọn ẹ̀yà Kachin. Orúkọ rẹ̀ ni Robin Zauja. Ó sọ pé: “Láàárọ̀ ọjọ́ kan, Arákùnrin Robert àti ìyàwó rẹ̀ wá sílé mi. Wọ́n sọ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn. Wọ́n ní àwọn ń wàásù ìhìn rere láti ilé dé ilé bí Jésù ṣe pa á láṣẹ. (Mát. 10:11-13) Lẹ́yìn tí wọ́n wàásù fún mi, wọ́n sọ àdírẹ́sì wọn, wọ́n sì fún mi ní àwọn ìwé ìròyìn àtàwọn ìwé míì. Lálẹ́ ọjọ́ yẹn, mo ka ọ̀kan lára àwọn ìwé náà lóru mọ́jú. Ni mo bá gba ilé Arákùnrin Robert lọ. Ọ̀pọ̀ wákàtí ni mo fi ń da ìbéèrè bò ó. Ó sì fi Bíbélì dáhùn gbogbo ìbéèrè mi.” Kò pẹ́ sígbà yẹn ni Robin Zauja di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Òun ló kọ́kọ́ di Ẹlẹ́rìí lára àwọn Kachin. Lẹ́yìn náà, ó di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, ọ̀pọ̀ ọdún ló sì fi ṣiṣẹ́ ìsìn ní àríwá orílẹ̀-èdè Burma. Ó ti ran nǹkan bí ọgọ́rùn-ún [100] èèyàn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Méjì lára àwọn ọmọ rẹ̀ ti wà ní Bẹ́tẹ́lì ti ìlú Yangon bàyìí.

Ẹlòmíì tó tún fi ìtara wàásù ni ọmọbìnrin ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17] kan tó ń jẹ́ Pramila Galliara. Kò pẹ́ rárá tí òun náà kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ní ìlú Yangon. Pramila sọ pé: “Ẹ̀sìn Jain ni bàbá mi ń ṣe, wọ́n sì ṣe àtakò tó gbóná gan-an sí mi nígbà tí mò ń kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Ẹ̀ẹ̀mejì ni wọ́n dáná sun Bíbélì mi àtàwọn ìwé tí mo fi ń kẹ́kọ̀ọ́. Àìmọye ìgbà ni wọ́n sì ti nà mí níta gbangba. Ọjọ́ kan tiẹ̀ wà tí wọ́n tì mí mọ́ inú ilé, kí n má bàa lọ sípàdé. Wọ́n tiẹ̀ láwọn máa dáná sun ilé Arákùnrin Richards! Àmọ́ nígbà tí wọ́n rí i pé mi ò jáwọ́, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í dẹwọ́ àtakò yẹn díẹ̀díẹ̀.” Arábìnrin Pramila fi ilé ìwé yunifásítì tó ń lọ sílẹ̀, ó sì di aṣáájú-ọ̀nà onítara. Nígbà tó yá, ó di ìyàwó alábòójútó àyíká kan, ìyẹn Arákùnrin Dunstan O’Neill. Ní báyìí, ó ti ran ẹni márùndínláàádọ́ta [45] lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.

Bí iṣẹ́ ìwàásù ṣe túbọ̀ ń tẹ̀ síwájú ní ìlú Mandalay, ẹ̀ka ọ́fíìsì tún rán àwọn míṣọ́nnárì àtàwọn aṣáájú-ọ̀nà jáde lọ sí àwọn àgbègbè míì. Lára àwọn àgbègbè ọ̀hún ni ìlú Pathein (ìyẹn Bassein), Kalaymyo, Bhamaw, Myitkyina, Mawlamyine àti Myeik (ìyẹn Mergui). Ẹ̀rí fi hàn pé Jèhófà bù kún iṣẹ́ táwọn ará yìí ṣe torí pé àwọn ìjọ ń lágbára sí i bí wọ́n ti ń fìdí múlẹ̀ láwọn ìlú náà.

Wọ́n Lé Àwọn Míṣọ́nnárì Kúrò Nílùú!

Bí iṣẹ́ ìwàásù ṣe túbọ̀ ń tẹ̀ síwájú, rògbòdìyàn òṣèlú àti ìjà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà kò jẹ́ kí ìlú fara rọ rárá. Nígbà tó fi máa di oṣù March, ọdún 1962, àwọn ológun fipá gbàjọba. Àìmọ̀ye àwọn ọmọ ilẹ̀ Íńdíà àtàwọn tí wọ́n jẹ́ apá kan ọmọ ilẹ̀ Íńdíà àti apá kan ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ni wọ́n fipá lé pa dà lọ sílẹ̀ Íńdíà àti Bangladesh (tí wọ́n ń pè ní East Pakistan nígbà yẹn). Wọn ò sì gbà pé kí àlejò tó bá jẹ́ ọmọ ilẹ̀ òkèèrè lò ju wákàtí mẹ́rìnlélógún [24] lọ. Bí orílẹ̀-èdè Burma ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ara rẹ̀ di ọ̀tá gbogbo ayé nìyẹn.

Inú àwọn ará kò dùn rárá sí gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí. Ìjọba ológun sọ pé àwọn máa fún àwọn èèyàn ní òmìnira ẹ̀sìn bí àwọn onísìn bá lè jáwọ́ pátápátá nínú ọ̀ràn òṣèlú. Àmọ́ àwọn míṣọ́nnárì ṣọ́ọ̀ṣì kò yé tojú bọ ọ̀ràn òṣèlú. Nígbà tó di oṣù May, ọdún 1966, ìjọba ológun yarí pátápátá. Wọ́n sì pàṣẹ pé kí gbogbo miṣọ́nnárì tó bá jẹ́ ọmọ ilẹ̀ òkèèrè fi orílẹ̀-èdè náà sílẹ̀ ní wàràǹṣeṣà! Àwọn míṣọ́nnárì tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò lọ́wọ́ nínú òṣèlú rárá, àmọ́ ó ṣeni láàánú pé wọ́n lé àwọn náà kúrò nílùú.

Ọ̀rọ̀ yìí bá àwọn ará wa tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Burma lójijì, àmọ́ wọn ò sọ̀rètí nù. Wọ́n mọ̀ pé Jèhofà kò ní fi àwọn sílẹ̀. (Diu. 31:6) Síbẹ̀, àwọn ará kan ṣàníyàn nípa bí iṣẹ́ ìwáàsù ṣe máa tẹ̀ síwájú.

Kò pẹ́ rárá sígbà yẹn tí wọ́n fi rí ẹ̀rí pé Jèhófà kò fi àwọn sílẹ̀. Wọ́n yan Arákùnrin Maurice Raj, tó ti jẹ́ alábòójútó àyíká tẹ́lẹ̀, tí wọ́n sì ti dá lẹ́kọ̀ọ́ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì, pé kó máa bójú tó ẹ̀ka ọ́fíìsì. Ìjọba kò lé Arákùnrin Maurice kúrò nílùú láìka pé ó jẹ́ ọmọ bíbí ilẹ̀ Íńdíà. Ó sọ pé: “Lọ́dún mélòó kan sẹ́yìn, mo kọ̀wé béèrè fún ìwé àṣẹ láti di ọmọ ìbílẹ̀ orílẹ̀-èdè Burma. Àmọ́ mi ò ní àádọ́ta lé nírinwó [450] kyats,d ìyẹn iye owó tí ìjọba béèrè pé kí n san nígbà yẹn. Ni mo bá mọ́kàn kúrò níbẹ̀. Àmọ́ bí mo ṣe ń kọjá lọ níwájú ọ́fíìsì tí mo ti ń ṣiṣẹ́ tẹ́lẹ̀, ọ̀gá tí mò ń bá ṣiṣẹ́ nígbà yẹn rí mi. Ló bá pariwo pé: ‘Raj, wá ńbí o! Wá gbowó ẹ. O ò dúró gbowó àjẹmọ́nú tó yẹ kó o gbà nígbà tó o fiṣẹ́ sílẹ̀.’ Nígbà tí mo yẹ̀ ẹ́ wò, ló bá di àádọ́ta lé nírinwó [450] kyats.

“Bí mo ṣe ń kúrò ní ọ́fíìsì yẹn, mò ń ronú oríṣiríṣi nǹkan tí mo lè fi owó yẹn ṣe. Àmọ́ bó ṣe jẹ́ iye owó tí mo nílò gẹ́lẹ́ láti fi gba ìwé àṣẹ pé mo ti di ọmọ onílùú, mo ronú pé ó ní láti jẹ́ pé ohun tí Jèhófà fẹ́ kí n fi owó náà ṣe nìyẹn. Àǹfààní kékeré kọ́ ni ìpinnu tí mo ṣe yẹn ṣe fún mi o. Nígbà tí ìjọba orílẹ̀-èdè Burma lé gbogbo ọmọ ilẹ̀ Íńdíà kúrò nílùú, àwòmọ́jú ni wọ́n ń wò mí. Ibi tó bá wù mí ni mo lè rìnrìn-àjò lọ. Mo lè kó ìwé wọ̀lú, kí n sì tún ṣe àwọn òjúṣe pàtàkì míì tó jẹ mọ́ iṣẹ́ ìwàásù torí pé mo ti gba ìwé àṣẹ ọmọ onílùú.”

Arákùnrin Maurice àti Dunstan O’Neill bẹ̀rẹ̀ sí í lọ káàkiri orílẹ̀-èdè náà láti lọ fi àwọn ará lọ́kàn balẹ̀ láwọn ìjọ àtàwọn àwùjọ tó wà ní àdádó. Arákùnrin Maurice sọ pé: “A sọ fún àwọn ará pé: ‘Ẹ fọkàn balẹ̀, Jèhófà wà pẹ̀lú wa. Tí àwa náà bá dúró tì í, ó máa ràn wá lọ́wọ́.’ Jèhófà sì ràn wá lọ́wọ́ lóòótọ́! Kò pẹ́ sígbà yẹn làwọn àṣáájú-ọ̀nà àkànṣe tún pọ̀ sí i. Iṣẹ́ ìwàásù sì wá ń gbóòrò lọ́nà tó bùáyà.”

Ní báyìí, ọdún mẹ́rìndínláàádọ́ta [46] ti kọ́já, síbẹ̀ Arákùnrin Maurice tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka lórílẹ̀-èdè náà ṣì máa ń rìnrìn-àjò káàkiri orílẹ̀-èdè Myanmar láti lọ gbé àwọn ará ró nínú ìjọ. Bíi ti Kálébú ní Ísírẹ́lì àtijọ́, ìtara tó ní fún iṣẹ́ Ọlọ́run kò dín kù rárá.—Jóṣ. 14:11.

A Wàásù Dé Ìpínlẹ̀ Chin

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 111]

Ìpínlẹ̀ Chin wà lárá àwọn ibi táwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe ti kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ìwàásù. Ààlà ilẹ̀ Íńdíà àti Bangladesh ni ìpínlẹ̀ náà wà, àwọn òkè sì pọ̀ níbẹ̀. Àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì pọ̀ gan-an ní ìpínlẹ̀ yìí, ìyẹn àwọn tó gbaṣẹ́ lọ́wọ́ àwọn míṣọ́nnárì Ṣọ́ọ̀ṣì Onítẹ̀bọmi nígbà tí ìjọba Gẹ̀ẹ́sì ṣì ń ṣàkóso Burma. Torí náà, ọ̀pọ̀ èèyàn ní ìpínlẹ̀ náà ka Bíbélì sí ìwé pàtàkì, wọ́n sì máa ń bọ̀wọ̀ fún àwọn tó bá ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Bí ọdún 1966 ṣe ń parí lọ, Arákùnrin Lal Chhana, wá sí ìlú Falam tó jẹ́ ìlú tó tóbi jù ní ìpínlẹ̀ náà. Iṣẹ́ ológun ni arákùnrin yìí ń ṣe tẹ́lẹ̀, àmọ́ ó ti di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe báyìí. Àwọn míì tó tún lọ síbẹ̀ ni Arákùnrin àti Arábìnrin O’Neill àti Arákùnrin Than Tum, tóun náà jẹ́ sójà tẹ́lẹ̀, àmọ́ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi nígbà yẹn. Àwọn ará yìí fìtara wàásù, wọ́n sì rí àwọn ìdílé mélòó kan kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Kò pẹ́ rárá tí wọ́n fi dá ìjọ tuntun sílẹ̀ níbẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìjọ náà kéré, ó lágbára nípa tẹ̀mí.

Lọ́dún 1967, Arákùnrin Than Tum lọ sí ìlú Hakha, tó wà níhà gúùsù ìlú Falam. Ó ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà níbẹ̀, wọ́n sì dá àwùjọ kékeré kan sílẹ̀ níbẹ̀. Nígbà tó yá, ó tún lọ sáwọn ìlú míì ní Ìpínlẹ̀ Chin, irú bíi Surkhua, Gangaw, abúlé Vanhna àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, wọ́n sì dá àwọn ìjọ sílẹ̀ níbẹ̀ pẹ̀lú. Ọdún márùndínláàádọ́ta [45] ti kọjá lọ, síbẹ̀ Arákùnrin Than Tum ń fìtara ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe nìṣó ní abúlé Vanhna tí wọ́n bí i sí.

Nígbà tí Arákunrin Than Tum kúrò ní ìlú Hakha, ọ̀dọ́kùnrin ọmọ ogún [20] ọdún kan tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, ìyẹn Donald Dewar, ló wá rọ́pò rẹ̀. Torí pé àwọn òbí Donald, ìyẹn Frank àti Lily Dewar (tó ń jẹ́ Lily May tẹ́lẹ̀), kò sí lórílẹ̀-èdè náà mọ́, Samuel, àbúrò rẹ̀ tó jẹ́ ọmọ ọdún méjìdínlógún [18], ló wá ṣìkejì Donald ní ìlú náà. Donald sọ pé: “Inú ahéré kéreré kan là ń gbé, ó máa ń móoru gan-an nígbà ẹ̀ẹ̀rùn, ó sì máa ń tutù nini nígbà òtútù. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń ṣe wá bíi pé a dá nìkan wà. Àìmọye ìgbà ni mo máa ń dá ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí, mi ò sì fi bẹ́ẹ̀ gbọ́ èdè Hakha Chin, tí wọ́n ń sọ níbẹ̀. Èmi àti Samuel pẹ̀lú akéde kan tàbí méjì la jọ máa ń ṣèpàdé. Èyí mú kí n rẹ̀wẹ̀sì, kódà mo rò ó pé bóyá kí n kúkú kúrò ní ìlú náà.”

“Nínú Ìwé Ọdọọdún wa, mo ka ìrírí kan tó wọ̀ mí lọ́kàn nípa bí àwọn ará wa lórílẹ̀-èdè Màláwì ṣe fara da inúnibíni tó le koko.e Mo bi ara mi pé, ‘Tí mi ò bá lè fara da ìdánìkanwà, ṣé màá lè fara da inúnibíni báyìí?’ Mo sọ ohun tó wà lọ́kàn mi fún Jèhófà, ọkàn mi sì bẹ̀rẹ̀ sí í fúyẹ́. Nígbà tí mo ka Bíbélì àtàwọn àpilẹ̀kọ inú Ilé Ìṣọ́, tí mo sì ṣàṣàro lórí wọn, ìyẹn náà fún mi lókun. Láìrò tẹ́lẹ̀, Arákùnrin Maurice Raj àti Dunstan O’Neill wá bẹ̀ mí wò, ṣe ló dà bíi pé àwọn áńgẹ́lì méjì ló wọlé tọ̀ mí wá! Bí mo tún ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ náà nìyẹn.”

Nígbà tí Arákùnrin Donald di alábòójútó àyíká, ìrírí tó ní yìí jẹ́ kó lè fún àwọn ará tó wà ní àdádó ní ìṣírí. Iṣẹ́ tó ṣe ní ìlú Hakha sì méso jáde. Ìjọ ti wá fìdí múlẹ̀ níbẹ̀ báyìí, àwọn ará sì máa ń ṣe àwọn àpéjọ ní ìlú náà. Méjì lára àwọn tí arákùnrin yìí kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìyẹn Johnson Lal Vung àti Daniel Sang Kha, di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe tó ń fìtara wàásù. Wọ́n sì wà lára àwọn tó mú ìhìn rere lọ sí ibi tó pọ̀ jù ní Ìpínlẹ̀ Chin.

A Lọ sí Àwọn Ìlú Tó Wà Lórí Òkè

Ìpínlẹ̀ Chin wà ní orí òkè tó ga tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000] sí ẹgbẹ̀rún mẹ́fà [6,000] ẹsẹ̀ bàtà, ó sì tún ní àwọn òkè gàgàrà míì tó ga tó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá [10,000] ẹsẹ̀ bàtà. Igbó kìjikìji tó kún fún àwọn igi teak, àtàwọn igi tó ga fíofío, tó dúró digbí àtàwọn tó ní àwọn òdòdó tó fani mọ́ra ló bo ọ̀pọ̀ àwọn òkè náà mọ́lẹ̀. Ewéko pọ̀ níbẹ̀, ó dùn-ún wò. Àmọ́ kò rọrùn láti rìnrìn-àjò níbẹ̀. Àwọn ọ̀nà tó wà níbẹ̀ rí kọ́lọkọ̀lọ, wọ́n sì dọ̀tí. Wọn kì í ṣeé gbà nígbà míì tí òjò bá rọ̀. Àwọn òkè tó wà níbẹ̀ sì máa ń ya wálẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà. Ọ̀nà ẹlẹ́sẹ̀ nìkan ló dé ọ̀pọ̀ àwọn abúlé tó wà níbẹ̀. Àmọ́ gbogbo èyí kò dí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lọ́wọ́. Wọ́n ti pinnu pé bí iná ń jó bí ìjì ń jà, àwọn máa mú ìhìn rere dé ọ̀dọ̀ ọ̀pọ̀ èèyàn bó bá ti lè ṣeé ṣe tó.

Arábìnrin Aye Aye Thit, tó jẹ́ ìyàwó alábòójútó àyíká kan ní Ìpínlẹ̀ Chin, sọ pé: “Pẹ̀tẹ́lẹ̀ ni mo dàgbà sí láwọn bèbè tí odò ti ya wọ òkun ní Ayeyarwady, torí náà àwọn òkè Chin yẹn máa ń fà mí mọ́ra gan-an. Inú mi dùn gan-an lọ́jọ́ tí mo kọ́kọ́ gun orí òkè kan, àmọ́ ṣe ni mo dákú nígbà tí mo dórí òkè náà torí pé mi ò lè mí délẹ̀ mọ́. Nígbà tí mo tún gun orí òkè míì lẹ́yìn ìgbà yẹn, ó rẹ̀ mí gan-an, àfi bíi pé mo fẹ́ kú. Nígbà tó yá, mo wá kọ́ béèyàn ṣe ń rọra gun orí òkè láìlo gbogbo okun inú rẹ̀ tán. Mo sì wá ń rin ìrìn kìlómítà méjìlélọ́gbọ̀n [32] lójúmọ́ tá a bá ń rìnrìn-àjò ọlọ́jọ mẹ́fà tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 114]

Apá òsì: Àwọn ará ìjọ Matupi máa ń rin ìrìn àádọ́rin-lé-rúgba [270] kìlómítà lọ sí àpéjọ ní ìlú Hakha

Bí ọdún ti ń gorí ọdún, oríṣiríṣi ohun ìrìnnà làwọn ará ní Ìpínlẹ̀ Chin ti lò. Lára wọn ni kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ẹṣin àti kẹ̀kẹ́. Nígbà tí ọ̀làjú dé, wọ́n lo alùpùpù, ọkọ̀ akẹ́rù àti ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́. Àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, ẹsẹ̀ ni wọ́n máa fi ń rìn. Bí àpẹẹrẹ, tí Arákùnrin Kyaw Win àti David Zama, tí wọ́n jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe bá fẹ́ lọ sí àwọn abúlé tó wà nítòsí ìlú Matupi, ẹsẹ̀ ni wọ́n máa fi ń rìn. Tí àwọn ará ìjọ Matupi bá sì fẹ́ lọ sí àpéjọ àgbègbè ní ìlú Hakha, tó lé ní àádọ́rin-lé-rúgba [270] kìlómítà sí wọn, ọjọ́ mẹ́fà sí mẹ́jọ ni wọ́n fi máa ń rìn, wọ́n sì tún máa rin ìrìn ọjọ́ mẹ́fà sí mẹ́jọ pa dà. Wọ́n máa ń kọ orin Ìjọba Ọlọ́run lójú ọ̀nà, ohùn wọn sì máa ń ròkè lala lẹ́bàá àwọn òkè tó fani mọ́ra yẹn.

Ojú àwọn ará máa ń rí nǹkan lẹ́nu àwọn ìrìn àjò náà, wọ́n máa ń fara da ojú ọjọ́ tí kò bára dé àti ẹ̀fọn, oríṣiríṣi kòkòrò sì jẹ pásapàsa sí wọn lára, pàápàá lásìkò òjò. Alábòójútó àyíká kan tó ń jẹ́ Myint Lwin sọ pé: “Lọ́jọ́ kan tí mò ń lọ nínú igbó, ṣàdédé ni mo rí àwọn kòkòrò mùjẹ̀mùjẹ̀ lórí ẹsẹ̀ mi, mo sì já wọn dà nù. Ká tó wí ká tó fọ̀, mo tún rí méjì míì lára mi. Ni mo bá fò sórí igi kan tó ṣubú sí ẹ̀bá ọ̀nà nírètí pé mo ti bọ́, bí mo tún ṣe rí wọn nìyẹn. Wọ́n pọ̀ bí eéṣú, wọ́n sì ń sáré tọ orí igi náà bọ̀ lọ́dọ̀ mi. Ẹ̀rù bà mí, ni mo bá kán lugbó. Nígbà tí mo fi máa dé ẹ̀bá ọ̀nà, gbogbo ara mi ti lé pátipàti, àwọn kòkòrò mùjẹ̀mùjẹ̀ yẹn ti jẹ kísà sí mi lára.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 115]

Apá ọ̀tún: Gumja Naw, tó jẹ́ alábòójútó àgbègbè àti Nan Lu, ìyàwó rẹ̀, máa ń rìnrìn àjò lórí àwọn òkè lọ sí àwọn ìjọ tó wà ní Ìpínlẹ̀ Chin

Àmọ́ kékeré ni kòkòrò mùjẹ̀mùjẹ̀ lára ohun tí àwọn arìnrìn-àjò ní Ìpínlẹ̀ Chin ní láti fara da. Àwọn àkòtagìrì ẹranko bí ìmàdò, béárì, àmọ̀tẹ́kùn àti ẹkùn tún kún inú àwọn igbó yẹn. A tiẹ̀ gbọ́ pé orílẹ̀-èdè Myanmar làwọn ejò olóró pọ̀ sí jù lọ lágbàáyé. Nígbà tí alábòójútó àgbègbè kan tó ń jẹ́ Gumja Naw àti Nan Lu, ìyàwó rẹ̀, ń rìnrìn àjò gba àwọn òkè náà kọjá lọ sí àwọn ìjọ tó wà ní Ìpínlẹ̀ Chin, ṣe ni wọ́n dá iná yíká ibi tí wọ́n sùn lálẹ́, kí àwọn ẹranko búburú yẹn má bàa hàn wọ́n léèmọ̀!

Títí láé la ó máa rántí àpẹẹrẹ àtàtà táwọn ará wa yìí fi lélẹ̀. Arákùnrin Maurice Raj sọ pé: “Gbogbo okun wọn ni wọ́n fi sin Jèhófà. Kódà, lẹ́yìn tí wọ́n kúrò ní Ìpínlẹ̀ Chin, wọ́n ṣì tún fẹ́ láti pa dà wá. Gbogbo iṣẹ́ tí wọ́n ṣe fìyìn fún Jèhófà!” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ ní ìpínlẹ̀ yìí, ìjọ méje àti àwùjọ mélòó kan ló wà níbẹ̀ báyìí.

“Àwọn Ará Myitkyina Kì Í Fẹ́ Gbọ́ Ìwàásù”

Lọ́dún 1966, àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe bíi mélòó kan dé sí ìlú Myitkyina, ní ẹ̀bá Odò Ayeyarwady ní Ìpínlẹ̀ Kachin tó wà nítòsí ilẹ̀ Ṣáínà. Arákùnrin àti Arábìnrin Richards ti wàásù níbẹ̀ tẹ́lẹ̀ ní ọdún mẹ́fà sẹ́yìn. Wọ́n ní: “Àwọn ará Myitkyina kì í fẹ́ gbọ́ ìwàásù.” Síbẹ̀, àwọn aṣáájú-ọ̀nà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé yìí rí i pé àwọn èèyàn tó hára gàgà láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ wà níbẹ̀.

Ọ̀kan lára irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ ni ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19] kan tó ń jẹ́ Mya Maung. Ṣọ́ọ̀ṣì Onítẹ̀bọmi ló ń lọ, ó sì ń bẹ Ọlọ́run pé kó ran òun lọ́wọ́ kí òun lè lóye Bíbélì. Ó ní: “Inú mi dùn gan-an nígbà tí aṣáájú-ọ̀nà kan wá síbi iṣẹ́ mi tó sì ní òun fẹ́ máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Mo wò ó pé òun ni Ọlọ́run fi dáhùn àdúrà mi. Ẹ̀ẹ̀mejì ni èmi àti San Aye, àbúrò mi máa ń ṣèkẹ́kọ̀ọ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. A sì yára tẹ̀ síwájú gan-an nípa tẹ̀mí.

“Arákùnrin Wilson Thein tó ń kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ nígbà yẹn ràn wá lọ́wọ́ lọ́pọ̀lọpọ̀. Ó máa ń fi ohun tó yẹ ká ṣe hàn wá, dípò kó kàn sọ ọ́ fún wa. Nínú àwọn àṣefihàn àti ìfidánrawò tó máa ń ṣe fún wa, ó kọ́ wa bá a ṣe lè máa lo Bíbélì lọ́ná tó wúlò, bá a ṣe lè máa fi ìgboyà wàásù, ohun tá a lè ṣe táwọn èèyàn bá ta kò wá àti bá a ṣe lè múra iṣẹ́ tá a bá ní nínú ìjọ sílẹ̀ ká sì ṣé e lọ́nà tó fi máa wọni lọ́kàn. A máa ń ṣe ìfidánrawò iṣẹ́ tá a bá ní fún un, ó sì máa ń sọ àwọn àtúnṣe tó yẹ ká ṣe fún wa. Bó ṣe máa ń fi sùúrù kọ́ wa ti jẹ́ kí àwa náà ní àwọn àfojúsùn tẹ̀mí.

“Ní báyìí ìjọ ti fìdí múlẹ̀ láwọn ìlú tí ọkọ̀ rélùwéè ti máa ń dúró, irú bíi Namti, Hopin, Mohnyin àti Katha”

“Lọ́dún 1968, èmi àti àbúrò mi bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, èyí mú kí iye aṣáájú-ọ̀nà tó wà ní ìlú Myitkyina di mẹ́jọ. Ìyá mi àtàwọn àbúrò mi méje wà lára àwọn tá a kọ́kọ́ kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, gbogbo wọn di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. A tún máa ń fi ọjọ́ kan sí mẹ́ta wàásù láwọn ìlú àtàwọn abúlé tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà ọkọ̀ rélùwéè tó lọ láti ìlú Myitkyina sí Mandalay. Iṣẹ́ ìwàású wa sì méso jáde nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Ní báyìí àwọn ìjọ ti fìdí múlẹ̀ láwọn ìlú tí ọkọ̀ rélùwéè ti máa ń dúró, irú bíi Namti, Hopin, Mohnyin àti Katha.”

Nígbà tí San Aye ń wàásù ní ìpínlẹ̀ ìwàásù táwọn èèyàn ti ń ṣiṣẹ́ ajé, ó rí Phum Ram, tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yà Kachin tó ń lọ sí Ṣọ́ọ̀ṣì Onítẹ̀bọmi, tó sì ń ṣiṣẹ́ ìjọba. Phum Ram fi ìtara kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ó sì kó lọ sí ìlú Putao, lẹ́bàá àwọn òkè Himalayas. Ó wàásù fún ọ̀pọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ níbẹ̀, kò sì pẹ́ rárá tí èèyàn mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] fi bẹ̀rẹ̀ sí í wá sípàdé. Nígbà tó di aṣáájú-ọ̀nà, ó kọ́ ìyàwó rẹ̀ àtàwọn ọmọ rẹ̀ méjèèje lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ títí kan ọ̀pọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀. Alàgbà àti aṣáájú-ọ̀nà ni báyìí nílùú Myitkyina.

Àwọn Apá Kan Lára Ọkọ̀ Rélùwéè Dàwátì

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 119]

Àwọn ará wọ ọkọ̀ rélùwéè tá a dìídì gbà láti ìlú Yangon lọ sí Myitkyina lọ́dún 1969, láti lọ ṣe àpéjọ àgbègbè

Ìbísí tẹ̀mí tó gbèrú ní Ìpínlẹ̀ Kachin ló mú kí ẹ̀ka ọ́fíìsì ṣe Àpéjọ kan tá a pe akọlé rẹ̀ ní “Àlàáfíà Lórí Ilẹ̀ Ayé” ní ìlú Myitkyina dípò ìlú Yangon tí wọ́n ti máa ń ṣe é tẹ́lẹ̀. Ẹ̀ka ọ́fíìsì tọrọ àyè lọ́wọ́ àwọn aláṣẹ ilé iṣẹ́ ọkọ̀ rélùwéè ti orílẹ̀-èdè Burma pé kí wọ́n fi apá mẹ́fà lára ọkọ̀ wọn gbé àwọn ará láti ìlú Yangon lọ́ sí ìlú Myitkyina. Ìrìn-àjò yẹn lé ní ẹgbẹ̀rún kan [1,000] kìlómítà. Àwọn èèyàn kì í sábà béèrè fún irú ohun táwọn ará béèrè fún yẹn. Ìdí ni pé àwọn tó ń dìtẹ̀ ìjọba pọ̀ ní Ìpínlẹ̀ Kachin, àwọn aláṣẹ sì máa ń ṣọ́ báwọn èèyàn ṣe ń lọ àti bí wọ́n ṣe ń bọ̀ ní àgbègbè náà. Èyí mú kó ya àwọn ará lẹ́nu nígbà táwọn aláṣẹ ilé iṣẹ́ náà fọwọ́ sí ohun tí wọ́n béèrè.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 125]

Àwọn alàgbà kan ní Àpéjọ Àgbáyé “Àlàáfíà Lórí Ilẹ̀ Ayé” ti ọdún 1969 tó wáyé ní ìlú Myitkyina. (Ilà ẹ̀yìn) Francis Vaidopau, Maurice Raj, Tin Pei Than, Mya Maung, (ilà àárín) Dunstan O’Neill, Charlie Aung Thein, Aung Tin Shwe, Wilson Thein, San Aye, (ilà iwájú) Maung Khar, Donald Dewar, David Abraham àti Robin Zauja

Lọ́jọ́ tí wọ́n retí pé ọkọ̀ rélùwéè náà máa dé sí ìlú Myitkyina, Arákùnrin Maurice Raj àtàwọn ará bíi mélòó kan lọ sí ibùdókọ̀ rélùwéè náà láti lọ pàdé àwọn ará. Arákùnrin Maurice sọ pé: “Níbi tá a dúró sí ni ọ̀ga ibùdókọ̀ yẹn ti sáré wá bá wa pé àwọn ti gbọ́ pé àwọn aláṣẹ yọ apá ibi táwọn ará wà sílẹ̀ lára ọkọ̀ náà torí pé ẹ́ńjìnì ọkọ̀ náà kò lè fà á gùnkè. Wọ́n sì ti fi wọ́n sílẹ̀ sí ojú ọ̀nà.

“À wá bẹ̀rẹ̀ sí í ronú ohun tá a lè ṣe. A kọ́kọ́ ń ronú láti yí ọjọ́ àpéjọ náà pa dà. Àmọ́ ìyẹn máa gba pé ká tún ṣẹ̀ṣẹ̀ lọ gbàṣẹ, èyí sì lè gba ọ̀sẹ̀ bíi mélòó kan. Bá a ṣe ń gbàdúrà tá a sì ń ronú ohun tá a lè ṣe ni ọkọ̀ náà dé. Ohun tá a rí yà wá lẹ́nu gan-an, àwọn ará wa kún inú ọkọ̀ rélùwéè náà bámúbámú! Wọ́n ń rẹ́rìn-ín músẹ́, wọ́n sì ń juwọ́ sí wa. Nígbà tá a bi wọn pé, ‘Báwo ni wọ́n ṣe ṣe é?’ Ọ̀kan nínú wọn sọ pé, ‘Lóòótọ́ ni wọ́n já àwọn apá kan lára ọkọ̀ náà sílẹ̀, àmọ́ kì í ṣe apá ibi tá a wà!’”

‘Lóòótọ́ ni wọ́n já àwọn apá kan lára ọkọ̀ náà sílẹ̀, àmọ́ kì í ṣe apá ibi tá a wà!’

Àpéjọ tá a ṣe ní ìlú Myitkyina yẹn lárinrin, ó sì yọrí sí rere. Ìwé tuntun mẹ́ta ló jáde lédè Burmese, márùn-ún sì jáde lédè Gẹ̀ẹ́sì. Ọdún mẹ́ta lẹ́yìn tí ìjọba lé àwọn míṣọ́nnárì kúrò nílùú, oúnjẹ tẹ̀mí díẹ̀díẹ̀ là ń rí jẹ, àmọ́ ní báyìí oúnjẹ tẹ̀mí ti yamùrá!

Bá A Ṣe Kọ́ Àwọn Ẹ̀yà Naga Lẹ́kọ̀ọ́ Òtítọ́

Oṣù mẹ́rin lẹ́yìn àpéjọ tá a ṣe ní ìlú Myitkyina, ẹ̀ka ọ́fíìsì wa rí lẹ́tà kan gbà látọ̀dọ̀ ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Ba Yee. Ó ń ṣiṣẹ́ ní ilé iṣẹ́ ìfìwéránṣẹ́ tó wà ní ìlú Khamti, nítòsí odò tó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ àwọn òkè tó wà ní ààlà orílẹ̀-èdè Burma àti Íńdíà. Àgbègbè yìí ni àwọn Naga ń gbé, oríṣiríṣi ẹ̀yà sì làwọn tó parapọ̀ di àwọn Naga. Láyé ìgbà kan, ṣe ni wọ́n máa ń bẹ́ àwọn èèyàn lórí níbẹ̀. Ṣọ́ọ̀ṣì Seventh Day Adventist ni Ba Yee ń lọ tẹ́lẹ̀, àmọ́ nínú lẹ́tà tó kọ, ó ní òun túbọ̀ fẹ́ mọ Ọlọ́run. Láìjáfara, ẹ̀ka ọ́fíìsì ní kí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe méjì, ìyẹn Arákùnrin Aung Naing àti Win Pe tètè lọ síbẹ̀.

Arákùnrin Win Pe sọ pé: “Níbi tí ọkọ̀ òfurufú ti máa ń balẹ̀ nílùú Khamti, ẹ̀rù bà wá nígbà tá a rí àwọn ọmọ ogun Naga tí ojú wọn le koko tí wọ́n sì sán bàǹtẹ́. Àmọ́ Ba Yee sáré wá pàdé wa, ó sì yára mú wa lọ sọ́dọ̀ àwọn tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kò pẹ́ rárá tá a fi bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ẹni márùn-ún lẹ́kọ̀ọ́.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 121]

Biak Mawia (apá ọ̀tún, lọ́wọ́ ẹ̀yìn) pẹ̀lú Ìjọ Khamti, nígbà tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù ní àgbègbè àwọn Naga

“Àmọ́ àwọn aláṣẹ àgbègbè náà rò pé ara àwọn pásítọ̀ Ṣọ́ọ̀ṣì Onítẹ̀bọmi tí wọ́n jẹ́ baba ìsàlẹ̀ fún àwọn jàǹdùkú tó ń dìtẹ̀ sí ìjọba ni wá. Láìka gbogbo àlàyé tá a ṣe fún wọn pé àwa kì í dá sọ́rọ̀ òṣèlú, a ò lò tó oṣù kan níbẹ̀ tí wọ́n fi pàṣẹ pé ká fi àgbègbè náà sílẹ̀.”

Nígbà tó fi máa di ọdún mẹ́ta lẹ́yìn ìgbà yẹn, wọ́n ti gbé àwọn òṣìṣẹ́ míì wá sí àgbègbè yẹn. Arákùnrin Biak Mawia, tó jẹ́ ọmọ ọdún méjìdínlógún [18], tó sì jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà sì tún bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù níbẹ̀. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni Ba Yee kọ̀wé fiṣẹ́ sílẹ̀, tó sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Lẹ́yìn náà, àwọn aṣáájú-ọ̀nà míì tún dé sí àgbègbè náà. Gbogbo wọn jọ ń fi ìtara wàásù, kò sì pẹ́ tí wọ́n fi dá ìjọ tuntun sílẹ̀ níbẹ̀, tí wọ́n sì dá àwùjọ̀ kéékèèké sílẹ̀ láwọn abúlé tó wà nítòsí. Arákùnrin Biak Mawia sọ pé: “Àwọn ará tí wọ́n jẹ́ Naga kò mọ̀wé, wọn ò sì lè kàwé. Àmọ́ wọ́n fẹ́ràn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n sì máa ń fi ìtara lo àwọn àwòrán inú ìwé wa láti wàásù. Ọ̀pọ̀ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ àtàwọn orin Ìjọba Ọlọ́run ni wọ́n ti há sórí.”

Ní báyìí, a máa ń ṣe àpéjọ àgbègbè ní ìlú Khamti. Àwọn èèyàn sì máa ń wá láti ibi tó jìnnà, títí kan ìlú Homalin, tó gba ìrìn wákàtí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] nínú ọkọ̀ ojú omi.

Àtakò Gbígbóná Janjan Bẹ̀rẹ̀ Níbi Tí Ohun Àmúṣọrọ̀ Wà Tẹ́lẹ̀

Iṣẹ́ ìwàásù tún ń tẹ̀ síwájú láwọn apá ibòmíì lórílẹ̀-èdè náà, pàápàá láwọn ilẹ̀ olókè tó wà ní ààlà orílẹ̀-èdè Ṣáínà, Laos àti Thailand. Ibẹ̀ ni àwọn orílẹ̀-èdè yìí ti ń rí àwọn ohun àmúṣọrọ̀ tẹ́lẹ̀. Àwọn òkè tó wà ní àgbègbè yìí fani mọ́ra, ilẹ̀ ọlọ́ràá sì làwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ tó wà níbẹ̀. Ibẹ̀ ni wọ́n ti ń gbin igi tí wọ́n fi ń ṣe oògùn olóró tí wọ́n ń pè ní opium. Àwọn jàǹdùkú tó ń dìtẹ̀ sí ìjọba pọ̀ níbẹ̀, wọ́n sì ń hu onírúurú ìwà tí kò bófin mu. Torí náà, àwọn aṣáájú-ọ̀nà tó ń wàásù ní àgbègbè eléwu yìí máa ń ṣọ́ra, wọ́n sì ń fi ọgbọ́n hùwà. (Mát. 10:16) Síbẹ̀ àwọn aṣáájú nínú ṣọ́ọ̀ṣì kò yéé ta kò wọ́n.

Nígbà tí Arákùnrin Robin Zauja àti David Abraham, tí wọ́n jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà dé sí ìlú Lashio, tí èèyàn pọ̀ sí ní Ìpínlẹ̀ Shan, àwọn aṣáájú ìsìn fẹ̀sùn kàn wọ́n pé ọlọ̀tẹ̀ ni wọ́n. Arákùnrin Robin sọ pe: “Wọ́n fàṣẹ ọba mú wa, wọ́n sì tì wá mọ́lé, ibẹ̀ la ti fi ìwé tí ìjọba fún wa han àwọn ọlọ́pàá. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni ọ̀gá ológun kan wọlé wá. Ó sì sọ pé, ‘Ọ̀gbẹ́ni Zauja, ojú ẹ rèé. Ẹ̀yin Ajẹ́rìí Jèhófà tún ti wá sí ìlú Lashio!’ Ilé ìwé kan náà lèmi àti ọ̀gá ológun yìí jọ lọ, ó sì ní kí wọ́n fi wá sílẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.”

Báwọn aṣáájú-ọ̀nà méjèèjì yìí ṣe bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ nìyẹn, kò sì pẹ́ tí wọ́n fi dá ìjọ kan sílẹ̀ níbẹ̀. Lẹ́yìn náà, wọ́n kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kan. Lẹ́yìn ọdún méjì, ìjọba pè wọ́n wá sí ọ́fíìsì ìjọba ìbílẹ̀ láti wá pàdé àwọn ọ̀gá ológun tó lé ní àádọ́rin [70], àwọn olórí àwọn ẹ̀yà àtàwọn aṣáájú ẹ̀sìn. Arákùnrin Robin sọ pé: “Inú ń bí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn yẹn, wọ́n sì fẹ̀sùn kàn wá pé ṣe là ń fipá fa àwọn èèyàn kúrò nínú ẹ̀sìn wọn. Nígbà tí alága ìjókòó yẹn ní kí á sọ tẹnu wa, mo bẹ̀ ẹ́ bóyá ó lè jẹ́ kí n lo Bíbélì láti fi gbèjà ara mi. Ó sì gbà. Mo yára gba àdúrà ìdákẹ́jẹ́ẹ́. Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàlàyé ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn àṣà ẹ̀sìn èké, iṣẹ́ ológun àtàwọn ètò tó ń gbé orílẹ̀-èdè ẹni lárugẹ. Nígbà tí mo sọ̀rọ̀ tán, alága ìjókòó yẹn dìde, ó sì sọ pé òfin orílẹ̀-èdè Burma gba gbogbo èèyàn láyè láti ṣe ẹ̀sìn tó bá wù ú. Bí wọ́n ṣe fi wá sílẹ̀ nìyẹn, tá a sì ń bá iṣẹ́ ìwàásù wa nìṣó! Ǹṣe lara ń ta àwọn aṣáájú ẹ̀sìn wọ̀nyẹn, àmọ́ wọ́n pa dà gba kámú náà ni.”

Kò pẹ́ sígbà yẹn táwọn ọmọ ìjọ Ṣọ́ọ̀ṣì Onítẹ̀bọmi kan tínú ń bí lọ dáná sun Gbọ̀ngàn Ìjọba ní abúlé Mongpaw, nítòsí ààlà orílẹ̀-èdè Ṣáínà. Nígbà tí wọ́n rí i pé Gbọ̀ngàn Ìjọba tí wọ́n dáná sun yẹn kò dín ìtara àwọn ará kù, wọ́n tún lọ dáná sun ilé aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe kan, wọ́n sì ń fòòró ẹ̀mí àwọn ará. Ni àwọn ará bá mú ẹjọ́ lọ sọ́dọ̀ aláṣẹ àgbègbè náà, àmọ́ ẹ̀yìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ló gbè sí. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ìjọba dá sí ọ̀rọ̀ náà, wọ́n sì fún àwọn ará láṣẹ láti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun. Àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, àárín gbùngbùn ìlú ni ìjọba fún wọn láṣẹ pé kí wọ́n lọ kọ́ gbọ̀ngàn náà sí, kì í ṣe sápá ẹ̀yìn abúlé níbi tó wà tẹ́lẹ̀.

Àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ṣe àtakò tó gbóná janjan sí Arákùnrin Gregory Sarilo ní abúlé Leiktho tí òkè pọ̀ sí, ní Ìpínlẹ̀ Kayin, lápá gúùsù orílẹ̀-èdè náà, nítòsí ibi tí wọ́n ti ń wa ohun àmúṣọrọ̀ tẹ́lẹ̀. Arákùnrin Gregory sọ pé: “Aṣááju ẹ̀sìn abúlé náà pàṣẹ pé kí àwọn ọmọ ìjọ rẹ̀ lọ ba oko ẹ̀fọ́ mi jẹ́, kí wọ́n sì kó ẹ̀bùn oúnjẹ rẹpẹtẹ wá fún mi. Àmọ́ ọ̀rẹ́ mi kan ta mí lólobó pé wọ́n ti fi májèlé sínú oúnjẹ náà. Lọ́jọ́ kan, àwọn ọmọ ẹ̀yìn àlùfáà wọn béèrè ọ̀nà ibi tí mo máa gbà kọjá lọ́jọ́ kejì. Nígbà tílẹ̀ mọ́, mo ya gba ọ̀nà ibòmíì torí pé wọ́n ti lọ dènà dè mí kí wọ́n lè pa mí. Nígbà tí mo lọ fi ẹjọ́ wọn sun àwọn aláṣẹ, wọ́n pàṣẹ pé wọn kò gbọ́dọ̀ fọwọ́ kàn mí. Bí Jèhófà ṣe gbà mí lọ́wọ́ ‘àwọn tí ń dọdẹ ọkàn mi’ nìyẹn.”—Sm. 35:4.

Wọn Kò Lọ́wọ́ sí Òṣèlú àti Ogun

Láti ọ̀pọ̀ ọdún ni wọ́n ti ń dán ìwà títọ́ àwọn ará wa nílẹ̀ Burma wò lọ́nà míì tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Nítorí pé wọ́n jẹ́ Kristẹni tí wọn kì í sì í dá sí ọ̀ràn òṣèlú àti ogun, ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n dojú kọ àdánwò nígbà tí ogun ẹ̀yà àti rògbòdìyàn òṣèlú bẹ́ sílẹ̀.—Jòh. 18:36.

Ìlú Thanbyuzayat wà ní gúúsù orílẹ̀-èdè Burma, wọ́n kọ́ ibùdó ọkọ̀ ojú irin kan síbẹ̀ nígbà Ogun Àgbáyé Kejì. Ìlú yìí ni ogun láàárín àwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ àtàwọn sójà ìjọba ká Arákùnrin Hla Aung tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe mọ́. Ó sọ pé: “Àwọn sójà máa ń wá sínú àwọn abúlé lóru, wọ́n á fi ìbọn halẹ̀ mọ́ àwọn ọkùnrin kí wọ́n lè lọ máa bá wọn ru ẹrù lójú ogun. Ọ̀pọ̀ ló ṣe bẹ́ẹ̀ dàwátì. Lálẹ́ ọjọ́ kan, bí èmi àti Donald Dewar ṣe ń sọ̀rọ̀ nílé wa làwọn sójà ya wọ abúlé wa. Ariwo tí ìyàwó mi tètè pa ló jẹ́ ká ráyè sá wọgbó. Lẹ́yìn tí mo bọ́ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, mo ṣe ibi kọ́lọ́fín kan sílé wa tí mo lè tètè sá pamọ́ sí tó bá ṣẹlẹ̀ pé àwọn sójà tún wá sí abúlé wa.”

Nígbà tí Rajan Pandit tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe dé ìlú Dawei tó wà ní gúúsù ìlú Thanbyuzayat, kò pẹ́ tó fi bẹ̀rẹ̀ ọ̀pọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú abúlé kan táwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ pọ̀ sí nítòsí Dawei. Ó sọ pé: “Lọ́jọ́ kan tí mò ń bọ̀ láti abúlé náà, àwọn sójà mú mi, wọ́n fẹ̀sùn kàn mí pé mò ń ran àwọn ọlọ̀tẹ̀ lọ́wọ́, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í lù mí. Nígbà tí mo sọ fún wọn pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mí, wọ́n béèrè bí mo ṣe dé ìlú Dawei. Mo wá fi tíkẹ́ẹ̀tì ọkọ̀ òfuurufú tí mo tọ́jú hàn wọ́n. Wọ́n rí i pé ọkọ̀ òfuurufú ni mo wọ̀ wá síbẹ̀, àwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ kì í sì í wọkọ̀ òfuurufú. Wọn ò lù mí mọ́, nígbà tó yá wọ́n dá mi sílẹ̀. Àmọ́, wọ́n kọ́kọ́ wádìí ọ̀rọ̀ lẹ́nu ẹnì kan tí mò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, òun ló sọ fún wọn pé ẹ̀kọ́ Bíbélì nìkan la jọ ń kọ́. Lẹ́yìn èyí, àwọn sójà náà fi mí sílẹ̀, àwọn kan lára wọn tiẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í gba ìwé ìròyìn lọ́wọ́ mi déédéé.”

Nígbà míì àwọn aláṣẹ ìlú máa ń fẹ́ kí àwọn arákùnrin wa lọ́wọ́ sí òṣèlú, wọ́n lè sọ pé kí wọ́n dìbò tàbí kí wọ́n kópa nínú àwọn ayẹyẹ tó ń gbé ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni lárugẹ. Nígbà táwọn aláṣẹ ìlú Zalun, tó wà létí odò ní nǹkan bí àádóje [130] kìlómítà sí àríwá ìlú Yangon fẹ́ fipá mú àwọn ará wa dìbò, àwọn ará sọ pé àwọn ò dìbò, wọ́n sì jẹ́ kí àwọn aláṣẹ yẹn mọ̀ pé ohun tí Bíbélì sọ làwọn ń ṣe. (Jòh. 6:15) Àwọn aláṣẹ náà lọ fẹjọ́ wa sun àwọn aláṣẹ àgbègbè. Àmọ́ àwọn aláṣẹ àgbègbè ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í dá sí ọ̀ràn òṣèlú. Kíá làwọn aláṣẹ náà fara mọ́ ọn pé ká má dìbò.

Ní ìlú Khampat tó wà ní ààlà orílẹ̀-èdè Burma àti Íńdíà, obìnrin kan tó jẹ́ ọ̀gá iléèwé lé àwọn ọmọ mẹ́tàlélógún [23] tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà kúrò níléèwé torí wọ́n kọ̀ láti kí àsíá. Ó pe àwọn méjì lára alàgbà ìjọ láti fara hàn níwájú àwùjọ àwọn aláṣẹ, adájọ́ àti ọ̀gá sójà sì wà lára wọn. Paul Khai Khan Thang, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn alàgbà náà sọ pé: “Bá a ṣe ń fi Bíbélì ṣàlàyé ìdí tí a kì í fi í kí àsíá, ó hàn gbangba pé àwọn kan nínú àwọn aláṣẹ náà kórìíra wa. A fi ẹ̀dà ìwé àṣẹ ìjọba hàn wọ́n, ìwé náà sọ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè ‘dúró tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, kí wọ́n sì dákẹ́ nígbà tí wọ́n bá ń kí àsíá lọ́wọ́.’ Ẹnú yà wọ́n débi pé kò sẹ́ni tó lè sọ nǹkan kan mọ́. Lẹ́yìn náà, ọ̀gá sójà náà pàṣẹ pé kí ọ̀gá iléèwé náà gba àwọn ọmọ tó lé pa dà. Ọ̀gá iléèwé náà tún pín ẹ̀dà ìwé àṣẹ náà fún gbogbo ẹ̀ka iléèwé náà.”

Lóde òní, àwọn aláṣẹ gíga jù lọ nínú ìjọba Myanmar ti mọ̀ dáadáa pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í lọ́wọ́ sí òṣèlú àti ogun. Bí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ṣe ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì lójú méjèèjì ti jẹ́ ẹ̀rí fún àwọn èèyàn gẹ́gẹ́ bí Jésù Kristi ti sọ tẹ́lẹ̀.—Lúùkù 21:13.

Àwọn Ológun Di Kristẹni

Ìtàn ilẹ̀ Myanmar òde òní, fi hàn pé ọ̀pọ̀ èèyàn ibẹ̀ ló ti jagun rí, yálà gẹ́gẹ́ bí sójà ìjọba tàbí ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀. Àwọn kan nínú wọn jẹ́ ‘olùfọkànsìn àti ẹnì kan tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run’ bíi Kọ̀nílíù, ọ̀gá ẹgbẹ́ ọmọ ogun Róòmù ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. (Ìṣe 10:2) Tí wọ́n bá ti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, wọ́n máa ń sapá láti mú kí ìgbésí ayé wọn bá ìlànà Jèhófà mu.

Ọpẹ́lọpẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó tú wọn sílẹ̀ kúrò nínú ìdè ìkórìíra, ìfẹ́ ti wá so wọ́n pọ̀

Ọ̀kan lára wọn ni Hlawn Mang, sójà ojú omi onípò kékeré tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nígbà tó wà lẹ́nu iṣẹ́ ní ìlú Mawlamyine. Ó sọ pé: “Ó wù mí pé kí n bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù lójú ẹsẹ̀. Àmọ́ bí mo ṣe fẹ́ fiṣẹ́ ológun sílẹ̀, mo gbọ́ pé wọ́n máa tó gbé mi ga lẹ́nu iṣẹ́, wọ́n á sì fún mi ní ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ ní orílẹ̀-èdè ọlọ́rọ̀ kan ní Ìwọ̀ Oòrùn ayé! Síbẹ̀, mi ò yí ìpinnu mi láti ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run pa dà. Ó ya àwọn ọ̀gá mi lẹ́nu gan-an nígbà tí mo kọ̀wé fiṣẹ́ sílẹ̀ tí mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í sin Jèhófà. Ọgbọ̀n [30] ọdún ti kọjá báyìí, àmọ́ ó ṣì dá mi lójú pé ìpinnu tó tọ̀nà ni mo ṣe. Àbí kí ló dára tó kéèyàn láǹfààní láti máa sin Ọlọ́run tòótọ́?”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 132]

Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Aik Lin (lápá òsì) àti Sa Than Htun Aung (lápá ọ̀tún) dojú ìjà kọ ara wọn nínú àwọn ogun àjàkú akátá nínú igbó

Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ La Bang Gam ń gba ìtọ́jú nílé ìwòsàn ológun kan nígbà tí Arákùnrin Robin Zauja fi ìwé Lati Paradise T’a Sọnu Si Paradise T’a Jere-Padaf hàn án. Ìwé yìí wu La Bang Gam gan-an débi tó fi sọ pé kí Robin fún òun. Àmọ́, Robin gbà láti yá a fún ọjọ́ kan péré tórí ẹ̀dà kan ṣoṣo tó ní nìyẹn. Nígbà tí Robin dé lọ́jọ́ kejì, La Bang Gam sọ pé: “Gba ìwé ẹ. Mo ti ní ẹ̀dà tèmi!” Gbogbo òru ló fi da ìwé náà kọ, kò sì fojú ba oorun títí tó fi parí gbogbo ojú ewé àádọ́talénígba [250] tí ìwé náà ní! Láìpẹ́ sígbà yẹn, La Bang Gam fi iṣẹ́ ológun sílẹ̀, ó sì fi ìwé tó dà kọ yìí kọ́ ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.

Ní Ìpínlẹ̀ Shan tí òkè pọ̀ sí, ọ̀pọ̀ ìgbà ni Sa Than Htun Aung, tó jẹ́ ọ̀gá nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun ilẹ̀ Burma, dojú ìjà kọ Aik Lin, ọ̀kan lára àwọn olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Ìpínlẹ̀ United Wa, nínú àwọn ogun àjàkú akátá nínú igbó. Nígbà tí ẹgbẹ́ méjèèjì fòpin sí ìjà wọn, àwọn ọkùnrin méjèèjì yìí wá ń gbé ní Ìpínlẹ̀ Shan. Nígbà tó yá, kálukú wọn kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, wọ́n kọ̀wé fiṣẹ́ ológun sílẹ̀, wọ́n sì ṣèrìbọmi. Àwọn méjì tó jẹ́ ọ̀tá ara wọn tẹ́lẹ̀ yìí pàdé ní àpéjọ àyíká kan, ni àwọn arákùnrin méjèèjì bá fi ayọ̀ gbá ara wọn mọ́ra! Ọpẹ́lọpẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó tú wọn sílẹ̀ kúrò nínú ìdè ìkórìíra, ìfẹ́ ti wá so wọ́n pọ̀.—Jòh. 8:32; 13:35.

Wọ́n Fèrò Wérò Pẹ̀lú “Onírúurú Ènìyàn”

Iye àwọn akéde tó wà ní Burma fi ohun tó ju ìlọ́po mẹ́ta pọ̀ sí i láàárín ọdún 1965 sí 1976. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó di Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló jẹ́ pé oníṣọ́ọ̀ṣì ni wọ́n nígbà tá a wàásù fún wọn. Síbẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yẹn mọ̀ pé ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé “kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (1 Tím. 2:4) Nítorí náà, láti ọdún 1975, wọ́n túbọ̀ fi kún ìsapá wọn láti wàásù fún ọ̀pọ̀ àwọn tó ń ṣe ẹ̀sìn míì nílẹ̀ Burma, bí àwọn ẹlẹ́sìn Búdà, Híńdù àtàwọn abọgibọ̀pẹ̀.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 134]

A máa ń rí àwọn ẹlẹ́sìn Búdà tó jẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé tí wọ́n wọṣọ ẹ̀sìn wọn

Ọ̀pọ̀ ìṣòro ni wọ́n dojú kọ. Àwọn ẹlẹ́sìn Búdà kò gbà pé ẹnì kan wà tó jẹ́ Ọlọ́run tàbí Ẹlẹ́dàá, àwọn Híńdù ń jọ́sìn àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ọlọ́run, àwọn abọgibọ̀pẹ̀ ń jọ́sìn àwọn ẹ̀mí àìrí, wọ́n sì gbà pé wọ́n lágbára gan-an. Ìgbàgbọ́ nínú ohun asán, wíwoṣẹ́ àti bíbá ẹ̀mí lò wọ́pọ̀ nínú àwọn ẹ̀sìn náà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ẹlẹ́sìn yìí gbà pé Bíbélì jẹ́ ìwé mímọ́ kan, wọn kò fi bẹ́ẹ̀ mọ nǹkan kan nípa ohun tí Bíbélì sọ àti àwọn èèyàn, ìtàn àti àṣà inú rẹ̀.

Síbẹ̀, àwọn ará mọ̀ pé kò sẹ́ni tí Bíbélì kò lè yí lọ́kàn pa dà. (Héb. 4:12) Wọ́n ní láti gbára lé ẹ̀mí Ọlọ́run, kí wọ́n sì lo “ọnà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́,” ìyẹn ni pé kí wọ́n fèrò wérò pẹ̀lú àwọn èèyàn lọ́nà tí òtítọ́ á fi wọ̀ wọ́n lọ́kàn, táá sì mú kí wọ́n yí ìgbésí ayé wọn pa dà.—2 Tím. 4:2.

Bí àpẹẹrẹ, ṣàgbéyẹ̀wò bí Arábìnrin Rosaline, tó ti pẹ́ nínú iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe ṣe máa ń fèrò wérò pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́sìn Búdà. Ó sọ pé: “Nígbà tá a bá kọ́ àwọn ẹlẹ́sìn Búdà pé ẹnì kan wà tó jẹ́ Ẹlẹ́dàá, wọ́n sábà máa ń béèrè pé, ‘Ta ló wá dá Ẹlẹ́dàá náà?’ Nítorí pé àwọn ẹlẹ́sìn Búdà gbà gbọ́ pé àwọn èèyàn máa ń tún ayé wá, wọ́n á sì di ẹranko, mo máa ń fi àwọn ẹran ọ̀sìn wọn ṣàpèjúwe fún wọn.

“Màá béèrè pé: ‘Ṣé ẹranko kan mọ̀ pé olówó òun wà?’

“‘Bẹ́ẹ̀ ni.’

“‘Ṣùgbọ́n ṣé ó mọ̀ nípa iṣẹ́ olówó rẹ̀, ìdílé rẹ̀ àti ibi tó ti wá?’

“‘Rárá o.’

“‘Lọ́nà kan náà, àwa èèyàn ò rí Ọlọ́run torí Ẹ̀mí ni Ọlọ́run. Ṣé ó wá yẹ ká rò pé a lè mọ ohun gbogbo nípa Ọlọ́run àti ibi tí Ọlọ́run ti wá?’

“‘Rárá.’”

“Ìfẹ́ tí àwọn ará fi hàn sí mi tù mí lára gan-an”

Fífi èrò wérò lọ́nà yìí ti mú kí ọ̀pọ̀ ẹlẹ́sìn Búdà tó jẹ́ olóòótọ́ ọkàn ṣàyẹ̀wò àwọn ẹ̀rí míì tó fi hàn pé Ọlọ́run wà. Tá a bá fi ojúlówó ìfẹ́ Kristẹni kún ìfèròwérò wa, ọ̀rọ̀ wa á lè wọ àwọn èèyàn lọ́kàn gan-an. Ohn Thwin tó jẹ́ ẹlẹ́sìn Búdà tẹ́lẹ̀ sọ pé: “Nígbà tí mo fi Nirvana tí mo gbà gbọ́ nínú ẹ̀sìn Búdà wé ìlérí tí Bíbélì ṣe pé ayé máa di Párádísè, Párádísè ló wù mí jù. Àmọ́ mi ò ṣe ohunkóhun nípa ohun tí mo kọ́ torí mo gbà gbọ́ pé kì í ṣe ọ̀nà kan ṣoṣo lèèyàn lè gbà mọ òtítọ́. Nígbà tó yá, mo bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ìfẹ́ tí àwọn ará fi hàn sí mi tù mí lára gan-an. Ìfẹ́ yìí ló mú kí n ṣe ohun tó bá òtítọ́ tí mo mọ̀ mu.”

[Àwòrán]

Lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Burma lọ́dún 1987

Ká sòótọ́, a nílò ọgbọ́n àti sùúrù ká tó lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè yí èrò wọn nípa ẹ̀sìn wọn pa dà. Ọmọ ọdún mẹ́wàá ni Kumar Chakarabani nígbà tí bàbá rẹ̀ tó jẹ́ ẹlẹ́sìn Híńdù paraku gbà kí Jimmy Xavier tó jẹ́ ọ̀kan lára ìdílé Bẹ́tẹ́lì máa kọ́ ọ ní ìwé kíkà. Ó sọ pé: “Bàbá mi kìlọ̀ fún un pé ìwé kíkà nìkan ni kó kọ́ mi, kò gbọ́dọ̀ kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ ìsìn. Jimmy sọ fún bàbá mi pé Ìwé Ìtàn Bíbélì dára gan-an fún kíkọ́ ọmọdé ní ìwé kíkà. Bakàn náà, tí Jimmy bá ti kọ́ mi tán, ó tún máa ń bá bàbá mi sọ̀rọ̀, ó sì máa ń ṣe ohun tó fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wọn. Nígbà tí bàbá mi wá bẹ̀rẹ̀ sí í béèrè àwọn ìbéèrè nípa ẹ̀sìn, ṣe ni Jimmy fi ọgbọ́n sọ fún wọn pé: ‘Inú Bíbélì làwọn ìdáhùn náà wà. Ẹ jẹ́ ká jọ wò ó.’ Níkẹyìn, yàtọ̀ sí pé bàbá mi tẹ́wọ́ gba òtítọ́, àwọn mẹ́tàlélọ́gọ́ta [63] nínú ìdílé wa ló tún di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.”

A Ṣe Àwọn Àpéjọ Àgbègbè Nígbà Rògbòdìyàn

Láti nǹkan bí ọdún 1985, ọ̀ràn òṣèlú túbọ̀ ń dá rògbòdìyàn sílẹ̀ lórílẹ̀-èdè Burma. Nígbà tó wá di ọdún 1988, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ ìwọ́de láti fi ẹ̀hónú wọn hàn sí ìjọba. Àmọ́ kíá ni àwọn sójà paná ìwọ́de náà, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í lo òfin ológun níbi púpọ̀ lórílẹ̀-èdè náà.

Arákùnrin Kyaw Win tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì sọ pé: “Àwọn aláṣẹ fi òfin kónílé-gbélé ká àwọn èèyàn lọ́wọ́ kò, wọn ò sì gbà kéèyàn tó ju márùn-ún lọ kóra jọ pọ̀. A wá bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé bóyá la ò ní wọ́gi lé àwọn àpéjọ àgbègbè tá a fẹ́ ṣe. Àmọ́ a lo ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà, a sì lọ bá ọ̀gá ológun tó ń ṣàkóso àgbègbè Yangon pé kó jọ̀wọ́ gbà wá láyè láti ṣe àpéjọ tí ẹgbẹ̀rún kan èèyàn máa wá. Lẹ́yìn ọjọ́ méjì a rí ìwé àṣẹ gbà! Nígbà tá a fi ìwé àṣẹ yìí han àwọn aláṣẹ láwọn àgbègbè míì, ó mú kí àwọn náà gbà pé ká ṣe àpéjọ àgbègbè ní ìpínlẹ̀ wọn. Jèhófà sì mú kí gbogbo àwọn àpéjọ àgbègbè tá a ṣe náà yọrí sí rere!”

Wọn Ò Kọ Ìpéjọpọ̀ Kristẹni Sílẹ̀

Lẹ́yìn rògbòdìyàn ọdún 1988, ipò ọrọ̀ ajé lórílẹ̀-èdè Burma túbọ̀ ń burú sí i. Síbẹ̀, ìgbàgbọ́ táwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ní nínú Ọlọ́run kò yingin, wọ́n ń fi àwọn ohun tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́ ní ìgbésí ayé wọn.—Mát. 6:33.

Ẹ wo àpẹẹrẹ Cin Khan Dal, tí òun àti ìdílé rẹ̀ ń gbé abúlé Sagaing tó jìnnà sí ìgboro. Ó sọ pé: “A fẹ́ lọ sí àpéjọ àgbègbè ní ìlú Tahan, a máa rin ìrìn àjò lórí ilẹ̀ àti lójú omi fún ọjọ́ méjì. Àmọ́ kò sẹ́ni tó máa bá wa tọ́jú àwọn adìyẹ wa tá ò bá sí nílé. Síbẹ̀, a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, a sì lọ sí àpéjọ náà. Nígbà tá a pa dà dé, a rí i pé adìyẹ mọ́kàndínlógún [19] ló ti kú. Àdánù ńlá lèyí jẹ́. Síbẹ̀, lẹ́yìn ọdún kan, ìwọ̀nba adìyẹ tó ṣẹ́ kù ti pọ̀ sí i, wọ́n ju ọgọ́ta [60] lọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé lọ́dún yẹn náà, àìsàn pa ọ̀pọ̀ adìyẹ àwọn tá a jọ ń gbé abúlé yẹn, kò sí èyí tó kú lára adìyẹ tiwa.”

Àwọn míì tí ìjọsìn Ọlọ́run tún jẹ lógún ni Aung Tin Nyunt àti ìyàwó rẹ̀, Nyein Mya. Àwọn pẹ̀lú ọmọ wọn mẹ́sàn-án ń gbé ní Kyonsha, abúlé kékeré kan tó wà ní kìlómítà mẹ́rìnlélọ́gọ́ta [64] lápá àríwá ìwọ oòrùn ìlú Yangon. Arákùnrin Aung sọ pé: “Lọ́pọ̀ ìgbà ìrẹsì àti ewébẹ̀ nìkan ni ìdílé wa máa ń jẹ. A kò lówó, a kò sì ní nǹkan tá a lè tà. Síbẹ̀, a ò jẹ́ kí ìrònú dorí wa kodò. Mo sọ fún ìdílé mi pé: ‘Jésù ò nílé tara ẹ̀. Nítorí náà, tó bá tiẹ̀ le débi pé kí n máa gbé abẹ́ igi tàbí kí ebi pa mí kú, mi ò ní yé sin Ọlọ́run tọkàntọkàn.’

“Jèhófà ni olùrànlọ́wọ́ mi; èmi kì yóò fòyà. Kí ni ènìyàn lè fi mí ṣe?”—Héb. 13:6

“Àmọ́, lọ́jọ́ kan, kò sí oúnjẹ kankan nílé wa. Ìyàwó mi àtàwọn ọmọ mi wá bẹ̀rẹ̀ sí í wojú mi, ebi hàn lójú wọn. Mo sọ fún wọn pé: ‘Ẹ má mikàn, Ọlọ́run máa pèsè.’ Lẹ́yìn tí mo parí iṣẹ́ lóde ẹ̀rí láàárọ̀ ọjọ́ yẹn, èmi àtàwọn ọmọkùnrin mi lọ pẹja. Ṣùgbọ́n ìwọ̀n ẹja tá a máa jẹ ní ìjókòó ẹ̀ẹ̀kan la rí pa. Ni a bá kó àwọn apẹ̀rẹ̀ tá a fi ń pẹja sí tòsí àwọn òṣíbàtà kan tó ṣù pọ̀ nínú odò náà, mo sì sọ fáwọn ọmọ mi pé: ‘A máa pa dà wá nírọ̀lẹ́ lẹ́yìn ìpàdé.’ Ẹ̀fúùfù pọ̀ gan-an lọ́sàn-án ọjọ́ yẹn. Nígbà tá a pa dà dé, a rí i pé ọ̀pọ̀ ẹja ti sá pamọ́ sábẹ́ àwọn òṣíbàtà náà torí ẹ̀fúùfù tó ń fẹ́. Bá a ṣe fi àwọn apẹ̀rẹ̀ wa kó ẹja tó pọ̀ gan-an nìyẹn, tá a sì tà wọ́n láti ra oúnjẹ tó máa tó wa jẹ fún odindi ọ̀sẹ̀ kan.”

Ọlọ́run ṣèlérí tó ń mọ́kàn ẹni yọ̀ pé: “Dájúdájú, èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà.” Àìmọye ìgbà làwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lórílẹ̀-èdè Myanmar ti rí bí ìlérí náà ṣe ṣẹ. Nítorí náà, wọ́n ń sọ pé: “Jèhófà ni olùrànlọ́wọ́ mi; èmi kì yóò fòyà. Kí ni ènìyàn lè fi mí ṣe?”—Héb. 13:5, 6.

A Mú Ọ̀nà Tá À Ń Gbà Tẹ̀wé Dára Sí I

[Graph tó wà ní ojú ìwé 146]

Láti ọdún 1956 làwọn èèyàn orílẹ̀-èdè Myanmar ti ń gbádùn oúnjẹ tẹ̀mí déédéé nínú Ilé Ìṣọ́ lédè Myanmar (Burmese). Lójú gbogbo ìjà tó ń wáyé láàárín àwọn ẹ̀yà ibẹ̀ àti rògbòdìyàn nínú ìlú pẹ̀lú ọrọ̀ ajé tó ń ṣe ségesège, kò sí ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ kan tó jáde tí wọn kò rí. Ọ̀nà wo ni wọ́n ń gbà tẹ ìwé ìròyìn yìí jáde?

Fún ọ̀pọ̀ ọdún, ẹ̀ka ọ́fíìsì wa máa ń fi àwọn ẹ̀dà ìwé ìròyìn wa tá a túmọ̀ ránṣẹ́ sí ilé iṣẹ́ ìjọba tó máa yẹ̀ ẹ́ wò bóyá ó léwu fún ààbò ilẹ̀ Myanmar. Tí ìjọba bá ti fọwọ́ sí i, ẹ̀ka ọ́fíìsì wa á gba àṣẹ láti ra bébà tí wọ́n á fi tẹ̀ ẹ́ jáde. Tí wọ́n bá ti ra bébà tán, arákùnrin kan á kó bébà náà àtàwọn ọ̀rọ̀ tá a fẹ́ tẹ̀ sí i lọ sí ilé iṣẹ́ tó máa tẹ̀ ẹ́. Òǹtẹ̀wé náà á wá fi ọwọ́ to lẹ́tà ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan lédè Myanmar sójú ìwé tí wọ́n fẹ́ tẹ̀. Lẹ́yìn tí arákùnrin náà bá ti yẹ àwọn ọ̀rọ̀ náà wò tí kò sì sí àṣìṣe kankan, òǹtẹ̀wé náà á wá fi ẹ̀rọ kan tó ti gbó tẹ̀ ẹ́ jáde. Wọ́n á fi àwọn ẹ̀dà ìwé ìròyìn náà ránṣẹ́ sí ilé iṣẹ́ ìjọba kí wọ́n lè fún wọn ní ìwé ẹ̀rí tó ní nọ́ńbà láti fi hàn pé wọ́n ti fọwọ́ sí i. Kò yani lẹ́nu pé iṣẹ́ aláápọn yìí máa ń gba ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀, ìwé ìròyìn náà kì í sì í fi bẹ́ẹ̀ fani mọ́ra.

[Àwòrán]

Ní ọdún 1989, ẹ̀ka ọ́fíìsì wa gba ètò ìtẹ̀wé tuntun kan, tó yí bí wọ́n ṣe ń tẹ̀wé pa dà pátápátá. Orílé-iṣẹ́ wa lágbàáyé la ti ṣe ètò ìtẹ̀wé náà, ìyẹn Multilanguage Electronic Phototypesetting System, tàbí MEPS. Ó ń lo kọ̀ǹpútà, ètò ìṣiṣẹ́ kọ̀ǹpútà àti ètò tí a fi ń tẹ ọ̀rọ̀ láti tẹ ìwé jáde lédè ọgọ́sàn-án ó lé mẹ́fà [186], títí kan èdè Myanmar!g

Arákùnrin Mya Maung tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì nígbà yẹn sọ pé: “Kò sí àní-àní pé, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la kọ́kọ́ lo kọ̀ǹpútà láti ṣe ìwé, ká sì fi tẹ̀ ẹ́ jáde lórílẹ̀-èdè Myanmar. Bí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ṣe ń lo MEPS láti gbé àwọn lẹ́tà èdè Myanmar jáde lọ́nà tó fani mọ́ra ti mú kí àyípadà ńlá bá ọ̀nà tí àwọn ilé iṣẹ́ ìtẹ̀wé gbà ń tẹ̀wé. Ó máa ń ya àwọn èèyàn lẹ́nu gan-an bí àwọn lẹ́tà ọ̀rọ̀ inú ìwé wa ṣe máa ń wà nigín-nigín!” Dípò ká máa fi ọwọ́ to ọ̀rọ̀ sórí ẹ̀rọ ká tó tẹ̀ ẹ́, MEPS mú ká lè máa tẹ ọ̀rọ̀ sórí ìwé ní tààràtà, ìtẹ̀síwájú ńlá lèyí sì jẹ́. MEPS tún jẹ́ ká lè ya àwọn àwòrán mèremère, èyí sì mú kí Ilé Ìṣọ́ túbọ̀ fani mọ́ra.

Lọ́dún 1991, ìjọba Myanmar fọwọ́ sí i pé ká máa tẹ ìwé ìròyìn Jí! jáde, inú àwọn ará sì dùn jọjọ. Inú àwọn ará ìlú náà sì dùn pẹ̀lú! Ọ̀gá àgbà kan ní Ilé Iṣẹ́ Ìsọfúnni ti Ìjọba sọ ohun tí ọ̀pọ̀ àwọn òǹkàwé wa sọ, ó ní: “Ìwé ìròyìn Jí! yàtọ̀ sí gbogbo ìwé àwọn ẹ̀sìn yòókù. Ó máa ń sọ̀rọ̀ nípa oríṣiríṣi nǹkan, ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì yéni dáadáa. Mo fẹ́ràn rẹ̀ gan-an.”

Iye ìwé ìròyìn tí wọ́n ń tẹ̀ jáde ti fi ìlọ́po mẹ́sàn-án pọ̀ sí i ju èyí tí wọ́n ń tẹ̀ lóhun tó lé ní ogún ọdún sẹ́yìn!

Ní ohun tó lé ní ogún ọdún sẹ́yìn, ìwé ìròyìn ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15,000] ni ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Myanmar ń tẹ̀ jáde lóṣooṣù, àmọ́ ní báyìí ó ti di ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbẹ̀rún [141,000], èyí fi ìlọ́po mẹ́sàn-án pọ̀ sí i! Tọmọdé tàgbà ló ti wá mọ Ilé Ìṣọ́ àti Jí! nílùú Yangon, àwọn èèyàn sì ń kà á níbi gbogbo lórílẹ̀-èdè yìí.

A Nílò Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Tuntun

Lẹ́yìn rògbòdìyàn ọdún 1988, àwọn aláṣẹ ológun ní káwọn ẹ̀sìn àti àwọn ẹgbẹ́ tó wà ní Myanmar wá forúkọ sílẹ̀ lọ́dọ̀ ìjọba. Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa sì ṣe bẹ́ẹ̀. Ọdún méjì lẹ́yìn náà, ní January 5, 1990, ìjọba fi orúkọ ẹ̀sìn wa sílẹ̀ pé à ń jẹ́ “Jehovah’s Witnesses (Watch Tower) Society” ní orílẹ̀-èdè Myanmar.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 149]

Ilé Bẹ́tẹ́lì náà kò gbà wọ́n mọ́. Ilẹ̀ ni arábìnrin kan jókòó sí tó ń lọ aṣọ

Lákòókò yẹn, àwọn ará ti gbé ẹ̀ka ọ́fíìsì wa kúrò ní 39th Street tó wà tẹ́lẹ̀, lọ sí ilé alájà méjì kan tó wà lórí ìdajì sarè ilẹ̀ kan ní òpópónà Inya. Ibi tí wọ́n kó lọ yìí wà ní àríwá ìlú náà, ó sì jẹ́ àdúgbò táwọn ọlọ́rọ̀ wà. Àmọ́ ilé ọ̀hún kò gbà wọ́n mọ́. Arákùnrin Viv Mouritz, tó bẹ orílẹ̀-èdè Myanmar wò gẹ́gẹ́ bí alábòójútó láti ilẹ̀ òkèèrè sọ pé: “Inú ìnira ni àwọn mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] tó wà nínú ìdílé Bẹ́tẹ́lì náà ti ń ṣiṣẹ́. Wọn kò ní ẹ̀rọ ìdáná ìgbàlóde ní ilé ìdáná wọn, ẹ̀rọ ìdáná kékeré kan ni arábìnrin kan fi ń dáná fún wọn. Kò sí ẹ̀rọ ìfọṣọ, torí náà arábìnrin kan ń bá wọn fọṣọ nínú agbada kan tí a rì mọ́lẹ̀ nínú ilé náà. Wọn ì bá ra ẹ̀rọ ìdáná ìgbàlódé àti ẹ̀rọ ìfọṣọ, àmọ́ ọjà ò ṣeé kó wọlé láti òkè òkun.”

Ó ṣe kedere pé àwọn ará wa nílò ẹ̀ka ọ́fíìsì tó tóbi ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Ìgbìmọ̀ Olùdarí fọwọ́ sí i pé kí wọ́n wó ilé alájà méjì tí wọ́n ń lò, kí wọ́n sì kọ́ ilé gbígbé alájà mẹ́rin àti ọ́fíìsì sórí ilẹ̀ náà. Síbẹ̀, káwọn ará náà tó lè bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, wọ́n gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ borí àwọn ìṣòro ńlá kan. Àkọ́kọ́ ni pé wọ́n gbọ́dọ̀ gba àṣẹ láti ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀gá mẹ́fà kan tí ipò wọn yàtọ̀ síra nínú iṣẹ́ ìjọba. Ìkejì, àwọn agbaṣẹ́ṣe ilẹ̀ Myanmar kò lè ṣe iṣẹ́ náà, torí wọn kò mọ bí wọ́n ṣe ń fi irin kọ́lé. Ìkẹta, àwọn Ẹlẹ́rìí tó fẹ́ yọ̀ǹda ara wọn láti ilẹ̀ òkèèrè kò lè wọ orílẹ̀-èdè Myanmar. Paríparí rẹ̀ ni pé wọn ò lè rí àwọn ohun tí wọ́n fẹ́ fi kọ́lé rà ní orílẹ̀-èdè náà, wọn kò sì lè kó wọn wọlé láti ilẹ̀ òkèèrè. Ṣe ló dà bíi pé iṣẹ́ náà ò lè ṣeé ṣe. Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn ará gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé tó bá jẹ́ ìfẹ́ rẹ̀, wọ́n máa kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì tuntun náà!—Sm. 127:1.

‘Kì Í Ṣe Nípasẹ̀ Agbára, Bí Kò Ṣe Nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mi’

Arákùnrin Kyaw Win tó ń sìn ní Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ọ̀ràn Òfin ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ń bá ìtàn náà lọ, ó ní: “Márùn-ún nínú àwọn ọ̀gá mẹ́fà náà, títí kan ti Ilé Iṣẹ́ Ìjọba fún Ọ̀ràn Ẹ̀sìn, fún wa láṣẹ láti kọ́lé náà. Àmọ́ Ìgbìmọ̀ Tó Ń Bójú Tó Ìdàgbàsókè Ìlú Yangon sọ pé ilé alájà mẹ́rin ti máa ga jù, wọn kò sì fọwọ́ sí ìwé wa. Nígbà tá a pa dà mú ìwé náà lọ, wọn ò tún fọwọ́ sí i. Àmọ́ Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka sọ pé kí n máà jẹ́ kó sú mi. Nítorí náà, mo gbàdúrà sí Jèhófà tọkàntọkàn, mo wá mú un lọ lẹ́ẹ̀kẹta. Wọ́n sì fọwọ́ sí i!

“Lẹ́yìn náà, a lọ sí Ilé Iṣẹ́ Ìjọba Tó Ń Rí sí Ìwọ̀lú. Wọ́n sọ fún wa pé àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè tó wá ṣèbẹ̀wò sí ìlú wa nìkan ló lè gba ìwé àṣẹ ìwọ̀lú, wọn ò sì lè lo ju ọjọ́ méje lọ. Àmọ́, nígbà tá a ṣàlàyé pé àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ tó yọ̀ǹda ara wọn láti ilẹ̀ òkèèrè yìí máa kọ́ àwọn aráàlú ní bí a ṣe ń kọ́lé ìgbàlódé, wọ́n gbà pé kí wọ́n lo oṣù mẹ́fà!

“Nígbà tá a dé Ilé Iṣẹ́ Ìjọba Tó Ń Bójú Tó Ìṣòwò, wọ́n ní ìjọba ti fòfin de kíkó ọjà wọlé. Àmọ́ nígbà tá a ṣàlàyé irú iṣẹ́ ìkọ́lé tá a fẹ́ ṣe, wọ́n fún wa láṣẹ láti kó ọjà tí iye rẹ̀ lé ní mílíọ̀nù márùnléláàádọ́jọ́ [155,000,000] náírà wọ̀lú. Owó orí tá a máa san lórí ọjà tá a kó wọlé ńkọ́? A lọ sí Ilé Iṣẹ́ Ìjọba Tó Ń Bójú Tó Ọ̀ràn Ìnáwó, wọ́n sì gbà pé ká kó ẹrù náà wọlé láìsan owó orí kankan! Nítorí àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí àtàwọn nǹkan míì, a ti wá rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run sọ pé: ‘“Kì í ṣe nípasẹ̀ ẹgbẹ́ ológun, tàbí nípasẹ̀ agbára, bí kò ṣe nípasẹ̀ ẹ̀mí mi,” ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí.’”—Sek. 4:6.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 151]

Àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè àti àwọn ọmọ ìbílẹ̀ ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀

Lọ́dún 1997, àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn bẹ̀rẹ̀ sí í dé síbi tá a fẹ́ kọ́ ilé náà sí. Àwọn ará nílẹ̀ Ọsirélíà ló fi èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn nǹkan tá a máa fi kọ́lé náà ránṣẹ́, àwọn ará nílẹ̀ Malaysia, Singapore àti Thailand fi àwọn nǹkan yòókù ránṣẹ́. Arákùnrin Bruce Pickering, tó jẹ́ alábòójútó iṣẹ́ ìkọ́lé náà sọ pé: “Àwọn ará láti ilẹ̀ Ọsirélíà ṣe gbogbo irin tá a máa fi kọ́lé náà, wọ́n sì wá ń dè wọ́n pa pọ̀ níkọ̀ọ̀kan lórílẹ̀-èdè Myanmar níbí. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ pé gbogbo irin ọ̀hún ló bára wọn mu wẹ́kú!” Àwọn ará tún yọ̀ǹda ara wọn láti ilẹ̀ Amẹ́ríkà, Fíjì, Gẹ̀ẹ́sì, Gíríìsì, Jámánì àti New Zealand.

Láti ọgbọ̀n [30] ọdún, ìgbà àkọ́kọ́ rèé tó máa ṣeé ṣe fún àwọn Ẹlẹ́rìí ní Myanmar láti ṣe nǹkan pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ará wọn tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ òkèèrè. Donald Dewar sọ pé: “Inú wa dùn gan-an, ṣe ló dà bí àlá. Bí àwọn àlejò yìí ṣe nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wọn, tí wọ́n sì lo okun àti owó wọn lẹ́nu iṣẹ́ náà jẹ́ ìṣírí ńláǹlà fún wa.” Arákùnrin mìíràn fi kún un pé: “A tún kọ́ àwọn ohun tó wúlò nípa iṣẹ́ ìkọ́lé. Àwọn akéde tó jẹ́ pé kìkì iná àbẹ́là ni wọ́n ń lò wá mọ bá a ṣe ń so wáyà iná mànàmáná. Àwọn míì tó jẹ́ pé abẹ̀bẹ̀ ni wọ́n fi ń fẹ́ra wá mọ bá a ṣe ń gbé ẹ̀rọ amúlétutù sínú ilé. A tún kọ́ bí wọ́n ṣe ń lo àwọn irinṣẹ́ tó ń bá iná ṣiṣẹ́!”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 152]

Bẹ́tẹ́lì orílẹ̀-èdè Myanmar

Bákan náà, ìfẹ́ àti ìgbàgbọ́ àwọn ará lórílẹ̀-èdè Myanmar wú àwọn tó wá láti ilẹ̀ òkèèrè lórí gan-an. Bruce Pickering sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé aláìní làwọn ará wa yìí, wọ́n lawọ́ gan-an. Púpọ̀ nínú wọn ló ní ká wá jẹun nílé wọn, tí wọ́n sì fi oúnjẹ tí ìdílé wọn lè jẹ fún ọjọ́ mélòó kan ṣe wá lálejò. Àpẹẹrẹ wọn rán wa létí pé àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù ní ìgbésí ayé ni ìdílé, àjọṣe tó dára pẹ̀lú Jèhófà, ẹgbẹ́ ará wa àti ìbùkún Jèhófà.”

Ní January 22, 2000 la ya ẹ̀ka ọ́fíìsì tuntun náà sí mímọ́ ní ìpàdé pàtàkì kan tá a ṣe ní gbọ̀ngàn National Theatre. Inú àwọn ará wa ní Myanmar dùn gan-an pé arákùnrin John E. Barr tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí ló wá sọ àsọyé ìyàsímímọ́ náà.

A Kọ́ Àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba Tuntun

Nígbà tí wọ́n ti fẹ́rẹ̀ẹ́ parí ẹ̀ka ọ́fíìsì tuntun náà, àwọn ará yíjú sí nǹkan míì tí wọ́n tún nílò lójú méjèèjì, ìyẹn Gbọ̀ngàn Ìjọba. Lọ́dún 1999, tọkọtaya Nobuhiko àti Aya Koyama dé láti orílẹ̀-èdè Japan. Arákùnrin Nobuhiko bá ẹ̀ka ọ́fíìsì dá Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba sílẹ̀. Ó sọ ohun tó ṣẹlẹ̀, ó ní: “A kọ́kọ́ lọ ṣàyẹ̀wò àwọn ibi tí àwọn ará wa ń lò fún ìpàdé ìjọ káàkiri orílẹ̀-èdè náà, a lo bọ́ọ̀sì, ọkọ̀ òfuurufú, ọ̀kadà, kẹ̀kẹ́, ọkọ̀ ojú omi, a sì tún fẹsẹ̀ rìn. Lọ́pọ̀ ìgbà, ó pọn dandan pé ká gba ìwé àṣẹ ìrìn-àjò lọ́wọ́ ìjọba torí ibi tí wọn ò fẹ́ káwọn àlejò dé pọ̀ gan-an. Lẹ́yìn tá a ti mọ àwọn ibi tí wọ́n ti nílò Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun, Ìgbìmọ̀ Olùdarí pèsè owó ìkọ́lé náà láti ara owó tá a fi ń ṣèrànwọ́ fún àwọn ilẹ̀ tí kò fi bẹ́ẹ̀ lówó.

“Lẹ́yìn tá a kó àwọn tó fi tọkàntọkàn yọ̀ǹda ara wọn jọ, àwọn òṣìṣẹ́ náà lọ sí ìgbèríko Shwepyitha, ní ìlú Yangon, ibẹ̀ ni wọ́n kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun àkọ́kọ́ sí. Àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè àti àwọn ọmọ ìbílẹ̀ ló jọ ṣiṣẹ́ náà. Èyí ya àwọn ọlọ́pàá àgbègbè náà lẹ́nu débi pé wọ́n dá iṣẹ́ ìkọ́lé náà dúró nígbà mélòó kan láti ṣèwádìí lọ́dọ̀ ọ̀gá wọn bóyá ó yẹ káwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè máa bá àwọn ọmọ ìbílẹ̀ ṣiṣẹ́. Àwọn míì tó kíyè sí iṣẹ́ náà yin àwọn ará wa. Ọkùnrin kan sọ pé: ‘Mo rí ọmọ ilẹ̀ òkèèrè kan tó ń fọ ilé ìgbọ̀nsẹ̀! Mi ò tíì rí i kí ọmọ ilẹ̀ òkèèrè máa ṣe irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ rí. Ẹ̀yin èèyàn yìí yàtọ̀ lóòótọ́!’

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 156]

Ọkọ̀ ojú omí ni wọ́n ń gbé lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun kan

“Lákòókò kan náà, àwùjọ àwọn kọ́lékọ́lé míì tún bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun sí ìlú Tachileik, tó wà ní ààlà orílẹ̀-èdè Myanmar àti Thailand. Ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti orílẹ̀-èdè Thailand máa ń kọjá ní ibodè lójoojúmọ́ kí wọ́n lè bá àwọn ará wọn ní orílẹ̀-èdè Myanmar ṣe iṣẹ́ náà. Gbogbo wọn ṣiṣẹ́ pa pọ̀ bó tilẹ̀ jẹ́ pé èdè wọn yàtọ̀ síra. Ohun tó yàtọ̀ pátápátá ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba náà parí. Àwọn ọmọ ogun tó wà ní ààlà orílẹ̀-èdè Myanmar àti Thailand bẹ̀rẹ̀ sí í bá ara wọn jà. Bí wọ́n ṣe ń ju bọ́ǹbù ni ìbọn ń ró láyìíká Gbọ̀ngàn Ìjọba náà, àmọ́ kò kan Gbọ̀ngàn Ìjọba. Nígbà tí ìjà náà parí, àwọn èèyàn méjìléláàádọ́rin [72] ló péjọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba náà láti yà á sí mímọ́ fún Jèhófà, Ọlọ́run àlàáfíà.”

Láti ọdún 1999, àwọn ẹgbẹ́ tó ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba ti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tó lé ní márùndínláàádọ́rin [65] káàkiri orílẹ̀-èdè yìí

Láti ọdún 1999, àwọn ẹgbẹ́ tó ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba ti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tó lé ní márùndínláàádọ́rin [65] káàkiri lórílẹ̀-èdè yìí. Báwo ló ṣe rí lára àwọn akéde tó máa lo àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba náà? Ọ̀pọ̀ nínú wọn ló sọ irú ọ̀rọ̀ tí arábìnrin kan tó mọyì iṣẹ́ náà sọ, omijé ayọ̀ ń bọ́ lójú ẹ̀ bó ṣe sọ pé: “Mi ò ronú pé a máa ní irú Gbọ̀ngàn Ìjọba tó rẹwà báyìí! Ní báyìí o, màá túbọ̀ sapá láti máa pe àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wá sáwọn ìpàdé ìjọ. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà àti ètò rẹ̀ fún inúure tí wọ́n fi hàn sí wa!”

Àwọn Míṣọ́nnárì Dé

Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tí orílẹ̀-èdè Myanmar kò gbà káwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè wọ ìlú wọn, àǹfààní bẹ̀rẹ̀ sí í ṣí sílẹ̀ láàárín ọdún 1990 sí 1999 fún àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè láti wọ orílẹ̀-èdè náà. Torí náà, ẹ̀ka ọ́fíìsì wa béèrè pé kí ìjọba fàyè gba àwọn míṣọ́nnárì láti wọ orílẹ̀-èdè náà lẹ́ẹ̀kan sí i. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ní oṣù January ọdún 2003, tọkọtaya Hiroshi àti Junko Aoki tí wọ́n ti kẹ́kọ̀ọ́ yege nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì dé sí Myanmar láti orílẹ̀-èdè Japan. Àwọn ní míṣọ́nnárì tó kọ́kọ́ wọ orílẹ̀-èdè náà lẹ́yìn nǹkan bí ọdún mẹ́tàdínlógójì [37] tí míṣọ́nnárì ti wọbẹ̀ gbẹ̀yìn.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 158]

Hiroshi àti Junko Aoki rèé, àwọn ni míṣọ́nnárì tó kọ́kọ́ wọ orílẹ̀-èdè Myanmar lẹ́yìn nǹkan bí ọdún mẹ́tàdínlógójì [37] tí míṣọ́nnárì ti wọbẹ̀ gbẹ̀yìn

Arákùnrin Hiroshi sọ pé: “Àwa tá a wá láti ilẹ̀ òkèèrè ò tó nǹkan, a ò sì fẹ́ káwọn aláṣẹ máa ro nǹkan míì nípa iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe, torí bẹ́ẹ̀ ó gba pé ká fọgbọ́n ṣe é. Nítorí náà, a kọ́kọ́ ń bá àwọn ará tó jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ lọ sọ́dọ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti ìpadàbẹ̀wò wọn. Kò pẹ́ tá a fi mọ̀ pé àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè Myanmar fẹ́ràn láti máa sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run. Ní àárọ̀ ọjọ́ tá a kọ́kọ́ lọ wàásù, a bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì márùn-ún!”

Arábìnrin Junko fi ọ̀rọ̀ tiẹ̀ kún un pé: “Lọ́pọ̀ ìgbà, a máa ń rí bí Jèhófà ṣe ń tọ́ wa sọ́nà. Lọ́jọ́ kan, nígbà tá à ń bọ̀ látọ̀dọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan nítòsí ìlú Mandalay, táyà alùpùpù wa jò. A ti alùpùpù náà lọ sí ilé iṣẹ́ kan tó wà nítòsí, a sì ní kí wọ́n bá wa tún táyà náà ṣe. Ẹ̀ṣọ́ tó wà níbẹ̀ jẹ́ kí Hiroshi ti alùpùpù náà wọlé, àmọ́ èmi dúró sí ilé kótópó tí wọ́n kọ́ fún àwọn ẹ̀ṣọ́. Ẹ̀ṣọ́ náà bẹ̀rẹ̀ sí í bi mí ní ìbéèrè.

Ó ní: “‘Kí lẹ wá ṣe níbí?’

Mo sọ fún un pé: “‘A wá kí àwọn ọ̀rẹ́ wa kan ni.’

Ló bá tún sọ pé: “‘Ṣé ò sí? Àbí ẹ wá ṣèpàdé ẹ̀sìn ni?’

“Torí mi ò mọ ìdí tó fi ń béèrè, mo ṣe bíi pé mi ò gbọ́ ohun tó sọ.

Ó wá sọ pé: “‘Má purọ́ fún mi o, àwọn wo lẹ̀ ń ṣiṣẹ́ fún?’

“Mo mú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ kan nínú báàgì mi, mo sì fi hàn án.

Inú rẹ̀ dùn, ó sọ pé: “‘Ọkàn mi sọ fún mi bẹ́ẹ̀!’ Ó yíjú sí àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́, ó sì kígbe pé: ‘Ẹ wò ó! Áńgẹ́lì kan ló jo táyà àwọn Ajẹ́rìí yìí, kí wọ́n lè wá sọ́dọ̀ wa!’

“Ọkùnrin náà yọ Bíbélì kan àti ìwé àṣàrò kúkurú wa kan jáde látinú báàgì rẹ̀. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì níbi tó ń gbé tẹ́lẹ̀, àmọ́ kò tíì rí Ẹlẹ́rìí kankan látìgbà tó ti dé ìlú Mandalay. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ la bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tó yá, àwọn kan lára àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.”

Lọ́dún 2005, àwọn míṣọ́nnárì mẹ́rin míì dé sí orílẹ̀-èdè Myanmar, wọ́n wá láti orílẹ̀-èdè Philippines lẹ́yìn tí wọ́n jáde ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ (ní báyìí, à ń pè é ní Ilé Ẹ̀kọ́ Bíbélì fún Àwọn Àpọ́n). Ọ̀kan lára àwọn arákùnrin náà, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Nelson Junio, ní ìṣòro tí ọpọ̀ míṣọ́nnárì máa ń ní. Àárò ilé ń sọ ọ́. Ó sọ pé: “Mo sábà máa ń sunkún, mo sì máa ń gbàdúrà kí oorun tó gbé mi lọ. Arákùnrin kan tó jẹ́ onínúure wá fi ohun tó wà nínú ìwé Hébérù 11:15, 16 hàn mí. Tó sọ nípa bí Ábúráhámù àti Sárà ò ṣe jẹ́ kí àárò ilé wọn nílùú Úrì máa sọ wọ́n, àmọ́ tí wọ́n ń sin Jèhófà nìṣó. Lẹ́yìn tí mo ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn, mi ò sunkún mọ́. Mo wá ń wo àwọn tí mò ń wàásù fún bí àwọn èèyàn mi.”

Ọ̀pọ̀ Jàǹfààní Látinú Àpẹẹrẹ Rere Wọn

Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba Tímótì nímọ̀ràn pé: “Àwọn nǹkan tí ìwọ . . . ti gbọ́ lọ́dọ̀ mi . . . ni kí o fi lé àwọn olùṣòtítọ́ lọ́wọ́, tí àwọn, ẹ̀wẹ̀, yóò tóótun tẹ́rùntẹ́rùn láti kọ́ àwọn ẹlòmíràn.” (2 Tím. 2:2) Ìlànà yìí ni àwọn míṣọ́nnárì fi sọ́kàn, tí wọ́n fi ran àwọn ìjọ tó wà ní orílẹ̀-èdè Myanmar lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni kan náà tí ètò Ọlọ́run ń fún gbogbo ẹgbẹ́ ará kárí ayé.

Bí àpẹẹrẹ, àwọn míṣọ́nnárì náà kíyè sí i pé ọ̀pọ̀ lára àwọn akéde ló máa ń ní kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọn máa sọ ìdáhùn wọn bó ṣe wà nínú ìwé tí wọ́n fi ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́. Ọ̀nà yìí ni wọ́n fi ń kọ́ àwọn ọmọ lẹ́kọ̀ọ́ ní ọ̀pọ̀ jù lọ ilé ìwé ní Myanmar. Arákùnrin Joemar Ubiña sọ pé: “A ní sùúrù fún wọn, a sì gba àwọn akéde yẹn níyànjú pé kí wọ́n máa lo àwọn ìbéèrè tó máa jẹ́ kí àwọn tí wọ́n ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ sọ èrò wọn àti bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára wọn. Nígbà tí àwọn akéde náà ṣe bí a ti sọ, wọ́n di olùkọ́ tó gbéṣẹ́ gan-an.”

Àwọn míṣọ́nnárì náà tún kíyè sí i pé alàgbà kan ṣoṣo tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan ṣoṣo ló wà nínú ọ̀pọ̀ ìjọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn arákùnrin yẹn jẹ́ olóòótọ́ tí wọ́n sì ń ṣisẹ́ kára, àwọn kan lára wọn sábà máa ń pàṣẹ lé agbo Ọlọ́run lórí. Kò sí àní-àní pé irú ìwà kan náà ló wà nínú ìjọ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, nígbà tí àpọ́sítélì Pétérù gba àwọn alàgbà níyànjú pé: “Ẹ máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run tí ń bẹ lábẹ́ àbójútó yín, . . . kì í ṣe bí ẹní ń jẹ olúwa lé àwọn tí í ṣe ogún Ọlọ́run lórí, ṣùgbọ́n kí ẹ di àpẹẹrẹ fún agbo.” (1 Pét. 5:2, 3) Ọ̀nà wo làwọn míṣọ́nnárì yìí lè gbà ran àwọn arákùnrin wọn lọ́wọ́? Arákùnrin Benjamin Reyes sọ pé: “A sapá gidigidi láti fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ nípa jíjẹ́ onínúure, ẹni pẹ̀lẹ́ àti ẹni tó ṣeé sún mọ́.” Nígbà tó yá, àwọn alàgbà bẹ̀rẹ̀ sí í fara wé àpẹẹrẹ àtàtà wọn. Ọ̀pọ̀ lára àwọn alàgbà náà yí ọ̀nà tí wọ́n gbà ń ṣe nǹkan pa dà, wọ́n sì túbọ̀ ń fìfẹ́ bójú tó àwọn ará.

Wọ́n Ń Jàǹfààní Látinú Ìtumọ̀ Èdè Tó Dára Sí I

Láti ọ̀pọ̀ ọdún wá ni àwọn ará wa ní Myanmar ti ń lo Bíbélì kan tí wọ́n túmọ̀ sí èdè ìbílẹ̀ ní nǹkan bí igba [200] ọdún sẹ́yìn. Ọ̀kan lára àwọn míṣọ́nnárì oníṣọ́ọ̀ṣì ló túmọ̀ Bíbélì náà pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn ẹlẹ́sìn Búdà tó jẹ́ ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé. Ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ èdè Pali táwọn èèyàn kì í lò mọ́ tó sì ṣòro lóye ló wà nínú ìtumọ̀ yìí. Nítorí náà, ìdùnnú ṣubú layọ̀ nígbà tá a mú Bíbélì Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde ní èdè Myanmar lọ́dún 2008. Arákùnrin Maurice Raj sọ ohun tó ṣẹlẹ̀, ó ní: “Ńṣe ni ìró àtẹ́wọ́ dún lọ, inú àwọn kan dùn débi pé wọ́n sunkún ayọ̀ nígbà tí wọ́n gba ẹ̀dà Bíbélì tiwọn. Ìtumọ̀ Bíbélì náà ṣe kedere, ó rọrùn, ó sì péye. Àwọn ẹlẹ́sìn Búdà pàápàá rí i pé ó tètè yé èèyàn!” Lẹ́yìn tí a mú Bíbélì yìí jáde, iye ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá à ń ṣe lórílẹ̀-èdè Myanmar fi ìdá mẹ́rin nínú mẹ́wàá lọ sókè.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 102]

Ó ti tó nǹkan bí àádọ́ta [50] ọdún báyìí tí Doris Raj ti ń ṣiṣẹ́ atúmọ̀ èdè ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní ìlú Yangon

Bó ṣe rí nínú ọ̀pọ̀ èdè, oríṣi méjì ni èdè Myanmar. Ọ̀kan ní àwọn òfin, ó sì wá látinú èdè Pali àti Sanskrit. Èkejì lèyí tí wọ́n máa ń sọ lójoojúmọ́, tí kò sì ní òfin. Méjèèjì ni wọ́n máa ń sọ tí wọ́n sì máa ń kọ sílẹ̀. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ìwé wa àtijọ́ ló jẹ́ pé èdè àkọ́kọ́ yẹn ni wọ́n fi kọ ọ́, ó sì ṣòro fún ọ̀pọ̀ láti lóye. Nítorí náà, ẹ̀ka ọ́fíìsì bẹ̀rẹ̀ sí í túmọ̀ àwọn ìwé wa sí èdè tí àwọn èèyàn Myanmar ń sọ lójoojúmọ́, tí ọ̀pọ̀ sì lóye.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 162]

Àwọn atúmọ̀ èdè ní ẹ̀ka ọ́fíìsì orílẹ̀-èdè Myanmar

Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ làwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í jàǹfààní látinú àwọn ìwé náà. Arákùnrin Than Htwe Oo, tó jẹ́ alábòójútó Ẹ̀ka Ìtumọ̀ Èdè ṣàlàyé pé: “Ohun táwọn èèyàn máa ń sọ tẹ́lẹ̀ ni pé: ‘Ojúlówó bébà lẹ fi ń ṣe ìwé yín, àmọ́ àwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ kò yé mi.’ Nísinsìnyí, tí wọ́n bá ti gba ìwé wa, inú wọn máa ń dùn gan-an, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n á ti bẹ̀rẹ̀ sí í kà á. Ọ̀pọ̀ máa ń sọ pé, ‘Ìwé yìí yé èèyàn dáadáa!’” Kódà ìdáhùn àwọn ará nípàdé ti wá ń dára sí i torí ohun tó wà nínú àwọn ìwé wa máa ń yé wọn kedere.

Ní báyìí, àwọn atúmọ̀ èdè mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n [26] ló ń ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Ìtumọ̀ èdè. Èdè mẹ́ta tí wọ́n sì ń túmọ̀ sí ni èdè Myanmar, èdè Hakha Chin àti èdè Sgaw Kayin. Wọ́n tún ti túmọ̀ àwọn ìwé wa sí èdè ìbílẹ̀ mọ́kànlá míì.

Ìjì Nargis

Ní May 2, ọdún 2008, ìjì Nargis, wáyé ní orílẹ̀-èdè Myanmar. Ọwọ́ọ̀jà ìjì yìí le gan-an, ó ń yára tó ìrìn òjìlénígba [240] kìlómítà ní wákàtí kan. Ó ba ọ̀pọ̀ dúkìá jẹ́ ó sì pa ọ̀pọ̀ èèyàn láti agbègbè Ayeyarwady Delta lọ dé ẹnu ààlà orílẹ̀-èdè Thailand. Ìjì yìí ṣàkóbá fún àwọn èèyàn tó lé ní mílíọ̀nù méjì, àwọn tó sì pa tàbí tí wọ́n sọnù tó ọ̀kẹ́ méje [140,000].

Ẹgbẹgbẹ̀rún lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló wà lágbègbè tí ìjì náà ti wáyé, àmọ́ ó yani lẹ́nu pé kò sẹ́nì kankan lára wọn tó fara pa. Ohun tó sì mú kí wọ́n yè bọ́ ni pé ọ̀pọ̀ wọn fara pa mọ́ sínú àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́. Ní abúlé Bothingone, tó sún mọ́ odò kan lágbègbè Ayeyarwady Delta, àwọn ogún [20] Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti àwọn ọgọ́rin [80] ará abúlé náà ló kóra wọn sí òkè àjà Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn fún wákàtí mẹ́sàn-án. Bí ọ̀gbàrá náà ṣe ń pọ̀ sí i, tó sì ń sún mọ́ àjà ilé náà, ló bá dáwọ́ dúró, ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sílẹ̀.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 165]

May Sin Oo rèé ní ìta ilé rẹ̀ nígbà tí wọ́n ń tún un kọ́

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 165]

Àwọn tó wá ṣèrànwọ́ dúró pẹ̀lú Arákùnrin àti Arábìrin Htun Khin níwájú ilé wọn tí wọ́n tún kọ́ lẹ́yìn tí Ìji Nargis bà á jẹ́

Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni ẹ̀ka ọ́fíìsì rán àwọn ará kan láti lọ ṣèrànwọ́ fún àwọn tó ń gbé níbi tí ìjì náà ti ṣọṣẹ́ jù lọ, ìyẹn ibi tí omi ti ya wọnú òkun. Kí wọ́n lè kó oúnjẹ, omi àti oògùn lọ síbẹ̀, wọ́n gba ọ̀nà tó dá páropáro tí àwọn òkú ti sùn lọ bí ilẹ̀ bí ẹni. Àwọn ni wọ́n kọ́kọ́ débẹ̀ láti ṣèrànwọ́. Lẹ́yìn tí wọ́n fún àwọn ará náà ní ohun tí wọ́n kó wá, wọ́n sọ àsọyé Bíbélì tó fún wọn lókun, wọ́n sì pín Bíbélì àtàwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fún wọn, torí ìjì náà tí gbé gbogbo ohun ìní wọn lọ.

Ẹ̀ka ọ́fíìsì dá Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù sílẹ̀ ní ìlú Yangon àti nílùú Pathein. Àwọn ìgbìmọ̀ yìí ṣètò àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn, kí wọ́n lè pín omi, ìrẹsì àtàwọn nǹkan míì fún àwọn tí ìjì náà bá. Wọ́n tún ṣètò pé káwọn kan tó mọ̀ nípa iṣẹ́ ìkọ́lé máa lọ káàkiri láti ṣàtúnṣe ilé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ìjì náà bà jẹ́, tàbí kí wọ́n tún un kọ́.

Ọ̀kan lára àwọn tó yọ̀ǹda láti ṣèrànwọ́, tó ń jẹ́ Tobias Lund sọ pé: “Èmi àti ìyàwó mi, Sofia, rí May Sin Oo, ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún kan, tó jẹ́ pé òun nìkan ni akéde nínú ìdílé rẹ̀, ó ń sá Bíbélì rẹ̀ sóòrùn lórí àwókù ilé wọn. Ó rẹ́rìn-ín nígbà tó rí wa, omijé sì bẹ̀rẹ̀ sí í dà lójú rẹ̀. Láìpẹ́, ọ̀kan lára ẹgbẹ́ tó ń bá àwọn ará wa kọ́lé dé, wọ́n kó akoto, irinṣẹ́ tó ń lo iná mànàmáná àtàwọn ohun èlò ìkọ́lé wá síbẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ilé míì fún ìdílé náà. Ó ya àwọn aládùúgbò lẹ́nu gan-an! Ọ̀pọ̀ ọjọ́ làwọn èèyàn fi lóṣòó yí ibẹ̀ ká, ó wá di ìran àpéwò pàtàkì ládùúgbò yẹn. Àwọn èèyàn tó ń ṣàkíyèsí ìṣẹ́ náà sọ pé: ‘A ò tíì rí irú eléyìí rí o! Ètò yín wà níṣọ̀kan, ẹ sì nífẹ̀ẹ́ ara yín. Àwa náà á fẹ́ láti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.’ Àwọn òbí May Sin Oo àtàwọn ọmọ wọn yòókù ti ń wá sípàdé báyìí, gbogbo wọ́n sì ń ṣe àwọn ìyípadà tó yẹ kí wọ́n lè máa sin Jèhófà.”

Ọ̀pọ̀ oṣù la fi ṣèrànwọ́ fún àwọn tí àjálù náà bá. Àwọn ará fi ọ̀pọ̀ tọ́ọ̀nù ẹrù ránṣẹ́ sí àwọn tí ìjì náà bá, ilé tí wọ́n tún ṣe tàbí tí wọ́n tún kọ́ jẹ́ ọgọ́jọ [160], Gbọ̀ngàn Ìjọba sì jẹ́ mẹ́jọ. Ìjì Nargis fa àjálù àti ìnira bá àwọn èèyàn lórílẹ̀-èdè Myanmar, àmọ́ ìjì yẹn tún jẹ́ ká rí ohun kan tó ṣeyebíye. Ó jẹ́ ká rí ìfẹ́ tó mú káwọn èèyàn Ọlọ́run wà níṣọ̀kan, tó sì ń gbé orúkọ Jèhófà ga.

Ìṣẹ̀lẹ̀ Tí A Kò Lè Gbàgbé

Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2007, ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní orílẹ̀-èdè Myanmar gba lẹ́tà amóríyá kan. Arákùnrin Jon Sharp tí òun àti ìyàwó rẹ̀, Janet, dé sí ẹ̀ka ọ́fíìsì náà lọ́dún 2006, sọ pé: “Ìgbìmọ̀ Olùdarí ní kí a ṣètò àpéjọ àgbáyé kan ní Yangon. Ọ̀pọ̀ àwọn ará láti orílẹ̀-èdè mẹ́wàá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló máa wá sí àpéjọ àgbáyé yẹn lọ́dún 2009, irú ẹ̀ ò sì tíì ṣẹlẹ̀ rí ní orílẹ̀-èdè wa!”

Arákùnrin Jon ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “Ọ̀pọ̀ ìbéèrè ló wá sọ́kàn wa: ‘Ibo ló máa lè gba àwọn èèyàn tó pọ̀ tó yìí? Ṣé àwọn akéde tó ń gbé láwọn abúlé tó jìnnà máa lè wá síbẹ̀? Ibo ni wọ́n máa dé sí? Báwo ni wọ́n á ṣe débẹ̀? Ṣé wọ́n á lè bọ́ ìdílé wọn? Bákan náà, àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Myanmar ńkọ́? Ṣé wọ́n á tiẹ̀ fàyè gba irú àpéjọ bẹ́ẹ̀?’ Àwọn ìṣòro ọ̀hún wá ga bí òkè. Àmọ́, a rántí ọ̀rọ̀ Jésù pé: ‘Àwọn ohun tí kò ṣeé ṣe fún ènìyàn ṣeé ṣe fún Ọlọ́run.’ (Lúùkù 18:27) Torí náà, a gbára lé Ọlọ́run, ìmúrasílẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹu.

“Kò pẹ́ tá a fi rí ibi tó ṣeé lò, ìyẹn pápá ìṣeré Myanmar, tó sún mọ́ àárín ìlú náà. Ó lè gba èèyàn tó tó ẹgbẹ̀rún mọ́kànlá [11,000], ó sì ní àwọn ẹ̀rọ amúlétutu. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ la kọ̀wé sí àwọn aláṣẹ láti sọ fún wọn pé a fẹ́ lo ibẹ̀. Àmọ́, lẹ́yìn ọ̀pọ̀ oṣù a ò gbọ́ nǹkan kan, kódà nígbà tó ku ọ̀sẹ̀ mélòó kan kí àpejọ náà bẹ̀rẹ̀, wọn ò tíì fún wa lésì pé ká lò ó. A wá gbọ́ ìròyìn kan tó dà wá lọ́kàn rú: Àwọn tó ń bójú tó pápá náà ti ṣètò ìdíje fún àwọn tó ń fi ìpá àti ìkúùkù jà sí àwọn ọjọ́ tá a fẹ́ ṣe àpéjọ wa! Nítorí a kò ní àkókò tó pọ̀ tó láti wá ibòmíì tá a lè lò, a bá ẹni tó ṣètò ìdíje náà àtàwọn aláṣẹ tọ́ràn kàn sọ̀rọ̀ ká lè yanjú ẹ̀ ní ìtùnbí ìnùbí. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ẹni tó ṣètò ìdíje náà gbà pé òun lè sún ìdíje náà síwájú, tí àwọn mẹ́rìndínlógún tó fẹ́ kópa nínú ìdíje náà bá gbà láti yí àdéhùn tí wọ́n ti fọwọ́ sí pa dà. Nígbà tí àwọn tó fẹ́ kópa nínú ìdíje náà gbọ́ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló fẹ́ lo pápá náà fún àpéjọ àgbègbè pàtàkì kan, gbogbo wọn ló gbà láti yí àdéhùn tí wọ́n ti fọwọ́ sí pa dà.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 167]

Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka, láti apá òsì sí apá ọ̀tún: Kyaw Win, Hla Aung, Jon Sharp, Donald Dewar àti Maurice Raj

Arákùnrin Kyaw Win tí òun pẹ̀lú jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka sọ pé: “Síbẹ̀, a ṣì nílò àṣẹ ìjọba láti lè lo pápá náà, ẹ̀ẹ̀mẹrin ni wọ́n sì ti fagi lé ìwé tá a kọ! Lẹ́yìn tá a gbàdúrà sí Jèhófà, a lọ bá ọ̀gágun tó ń bójú tó gbogbo pápá tó wà ní Myanmar. Ọ̀sẹ̀ méjì péré ló kù kí àpéjọ náà bẹ̀rẹ̀, èyí sì ni ìgbà àkọ́kọ́ tí wọ́n máa jẹ́ ká bá onípò àṣẹ tó ga bẹ́ẹ̀ sọ̀rọ̀. Inú wá dùn pé ó fọwọ́ sí ìwé wa!”

Lákòókò yìí, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tó fẹ́ wá sí àpéjọ náà láti ibi gbogbo lórílẹ̀-èdè Myanmar àti láti ilẹ̀ òkèèrè ti bẹ̀rẹ̀ sí í dé sí ìlú Yangon, wọn ò tiẹ̀ mọ gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀. Oríṣiríṣi ohun ìrìnnà ni wọ́n sì lò, bí ọkọ̀ òfuurufú, ọkọ̀ ojú irin, ọkọ̀ ojú omi, bọ́ọ̀sì, ọkọ̀ akẹ́rù, àwọn míì sì fẹsẹ̀ rìn. Ọ̀pọ̀ ìdílé lórílẹ̀-èdè Myanmar ló fowó pa mọ́ fún ọ̀pọ̀ oṣù kí wọ́n lè lọ sí àpéjọ náà. Ọ̀pọ̀ àwọn ará ló dá oko, àwọn kan sin ẹlẹ́dẹ̀, àwọn míì rán aṣọ, àwọn mìíràn sì lọ wa góòlù nínú odò. Ọ̀pọ̀ wọn ni kò dé ìlú ńlá rí tàbí tí wọn ò tíì rí ọmọ orílẹ̀-èdè míì rí.

Àwọn tó wá láti àríwá orílẹ̀-èdè Myanmar lé ní ẹgbẹ̀rún kan àti ọ̀ọ́dúnrún [1,300], wọ́n kóra jọ sí ibùdókọ̀ ìlú Mandalay láti wọ ọkọ̀ ojú irin tá a dìídì gbà pé kó gbé wọn lọ sí ìlú Yangon. Àwùjọ kan tó wá láti àgbègbè Naga Hills rin ìrìn àjò ọlọ́jọ́ mẹ́fà, wọ́n sì gbé àkéde méjì pọ̀n torí kò pẹ́ tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò wọn ni kẹ̀kẹ́ arọ tí wọ́n ṣe fún wọn ti bà jẹ́. Ọgọ́rùn-ún mélòó kan lára àwọn ará ló ti dé sí ibùdókọ̀, wọ́n ń sọ̀rọ̀, wọ́n ń rẹ́rìn-ín, wọ́n sì ń kọrin Ìjọba Ọlọ́run. Arákùnrin Pum Cin Khai, tó bá wọn ṣètò ọkọ̀ ìrìnnà sọ pé: “Inú gbogbo àwọn ará dùn. A fún wọn ní oúnjẹ, omi àti ẹní tí wọ́n máa fi sùn. Nígbà tí ọkọ̀ ojú irin náà dé lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, àwọn alàgbà ṣèrànwọ́ kí àwùjọ kọ̀ọ̀kan lè mọ ibi tí wọ́n máa wà nínú ọkọ̀ náà. Lẹ́yìn náà, wọ́n gbọ́ ìkéde kan lórí ẹ̀rọ gbohùngbohùn pé: ‘Ọkọ̀ ojú irin àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti fẹ́ gbéra o!’ Mo wò yíká bóyá màá rí ẹni tí ò tíì wọlé, lèmi náà bá tètè wọnú ọkọ̀!”

Lákòókò yẹn náà, ní ìlú Yangon, a fi àwọn àlejò láti ilẹ̀ òkèèrè tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin [700] wọ̀ sí òtẹ́lì. Ibo wá ni àwọn tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000] tó wá láti orílẹ̀-èdè Myanmar máa dé sí? Arákùnrin Myint Lwin tó ṣiṣẹ́ ni Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé sọ pé: “Jèhófà mú kí ọkàn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní ìlú Yangon fẹ́ láti ran àwọn arákùnrin àti arábìnrin wọn lọ́wọ́. Àwọn ìdílé kan ní kí àwọn àlejò tí ó tó mẹ́ẹ̀ẹ́dógún dé sílé àwọn. Wọ́n san owó tí wọ́n fi forúkọ wọn sílẹ̀ lọ́dọ̀ ìjọba, wọ́n pèsè oúnjẹ àárọ̀ fún wọn, wọ́n sì ṣètò ọkọ̀ táá máa gbé wọn lọ sí àpéjọ náà, táá sì tún gbé wọn pa dà. Àwọn kan dé sí àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà ládùúgbò; àwọn ọgọ́rùn-ún míì sùn sí ilé iṣẹ́ ńlá kan. Síbẹ̀, pẹ̀lú gbogbo ètò tá a ṣe yìí, ó ṣì ku àwọn ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] míì tí wọn ò níbi tí wọ́n máa dé sí. A ṣàlàyé ìṣòro yìí fún àwọn tó ń bójú tó pápá ìṣere náà, wọ́n sì gbà pé kí àwọn ará wa sùn síbẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sẹ́ni tó sun pápá ìṣeré náà rí.”

“Jèhófà mú kí ọkàn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní ìlú Yangon fẹ́ láti ran àwọn arákùnrin àti arábìnrin wọn lọ́wọ́”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 169]

Ní ọdún 2009 Àpéjọ Àgbáyé “Ẹ Máa Ṣọ́nà!” gbé ìgbàgbọ́ àwọn ará ró, ó sì jẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn ní ìlú Yangon mọ̀ nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 170]

Nítorí pé ipò tí pápá ìṣeré náà wà kò bójú mu, ọjọ́ mẹ́wàá ni àwọn tó lé ní àádọ́ta dín nírinwó [350] fi yọ̀ǹda ara wọn láti tún un ṣe fún àpéjọ náà. Arákùnrin Htay Win tó jẹ́ alábòójútó àpéjọ náà sọ pé: “A ṣe àtúnṣe sí àwọn páìpù omi, iná mànàmáná àti ẹ̀rọ amúlétutù, lẹ́yìn náà a kun gbogbo ibẹ̀, a sì gbá a. Iṣẹ́ rẹpẹtẹ yìí jẹ́ káwọn èèyàn sọ̀rọ̀ tó dáa nípa wa. Ọ̀gá ológun tó ń bójú tó pápá ìṣeré náà sọ pé: ‘Ẹ ṣeun! Ẹ ṣé gan-an! Mò ń bẹ Ọlọ́run pé kí ẹ̀yin èèyàn yìí wá máa lo pápá ìṣeré yìí lọ́dọọdún!’”

Àwọn èèyàn tó lé ní ẹgbẹ̀rún márùn-ún [5,000] ló wá sí àpéjọ àgbáyé náà ní December 3 sí 6, ọdún 2009. Ní ọjọ́ tó gbẹ̀yìn àpéjọ náà, àwọn ará wọ aṣọ ìbílẹ̀ wọn, ẹwà àwọn aṣọ aláwọ̀ mèremère náà sì fani mọ́ra gan-an. Arábìnrin kan sọ pé: “Kí ìpàdé tó bẹ̀rẹ̀ rárá làwọn èèyàn ti ń dì mọ́ ara wọn, tí wọ́n sì ń sunkún.” Lẹ́yìn tí Arákùnrin Gerrit Lösch tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí gbàdúrà ìparí, àwọn èèyàn náà ń pàtẹ́wọ́, wọ́n sì ń juwọ́ fún ọ̀pọ̀ ìṣẹ́jú. Arábìnrin kan tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìndínláàádọ́rùn-ún [86] sọ bí ọ̀ràn náà ṣe rí lára gbogbo èèyàn, ó ní, “Ńṣe ló dà bíi pé mo ti wà nínú ayé tuntun!”

Àpéjọ náà tún mú orí ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀gá lẹ́nu iṣẹ́ ìjọba wú gan-an. Ọ̀gá kan sọ pé: “Àwọn èèyàn tó kóra jọ yìí yàtọ̀ gan-an. Kò sẹ́ni tó ń ṣépè, kò sẹ́ni tó ń mu sìgá tàbí ẹni tó ń jẹ ẹ̀pà betel. Àwọn èèyàn láti onírúurú èdè wà níṣọ̀kan. Mi ò tíì rí irú àwùjọ èèyàn bí èyí ri!” Arákùnrin Maurice Raj sọ pé: “Kódà ọ̀gágun àgbà ìlú Yangon sọ fún wa pé òun àtàwọn ẹlẹgbẹ́ òun kò tíì rí irú ohun tó wúni lórí bí èyí rí.”

Àwọn ará tó wá sí àpéjọ náà gbà pé ohun tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ló ṣẹlẹ̀ níbẹ̀. Arákùnrin kan ní Yangon sọ pé: “Ká tó ṣe àpéjọ yìí, a kàn máa ń gbọ́ nípa ẹgbẹ́ ará wa kárí ayé ni. Àmọ́ ní báyìí a ti fojú ara wa rí i! A kò lè gbàgbé ìfẹ́ táwọn ará fi hàn sí wa.”

“Ká tó ṣe àpéjọ yìí, a kàn máa ń gbọ́ nípa ẹgbẹ́ ará wa kárí ayé ni. Àmọ́ ní báyìí a ti fojú ara wa rí i!”

“Funfun fún Kíkórè”

Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún méjì [2,000] sẹ́yìn, Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ gbé ojú yín sókè, kí ẹ sì wo àwọn pápá, pé wọ́n ti funfun fún kíkórè.” (Jòh. 4:35) Bí ọ̀ràn ṣe rí lórílẹ̀-èdè Myanmar lóde òní náà nìyẹn. Ní báyìí, orílẹ̀-èdè yìí ní akéde ẹgbọ̀kàndínlógún ó dín mẹ́wàá [3,790], ìyẹn ni pé akéde kan máa wàásù fún ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlógún ó dín ọgọ́ta àti mẹ́sàn-án [15,931] èèyàn. Ẹ ò rí i pé iṣẹ́ ìkórè pọ̀ gan-an láti ṣe nílẹ̀ yìí! Bó sì ṣe jẹ́ pé àwọn èèyàn ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ ó lé márùn-ún [8,005] ló wá sí Ìrántí Ikú Kristi lọ́dún 2012, ọ̀pọ̀ ló ṣì lè wá sin Jèhófà!

Ẹ jẹ́ ká gbé ẹ̀rí mìíràn yẹ̀ wò. Àwọn èèyàn tó wà ní Ìpínlẹ̀ Rakhine, ìyẹn àgbègbè etíkun tó wà ní ààlà orílẹ̀-èdè Bangladesh, fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù mẹ́rin [4,000,000], àmọ́ kò sí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan níbẹ̀. Arákùnrin Maurice Raj sọ pé: “Lóṣooṣù, à ń gba ọ̀pọ̀ lẹ́tà látọ̀dọ̀ àwọn èèyàn lágbègbè yìí tí wọ́n ní ká fi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ránṣẹ́, ká sì wá kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bákan náà, iye àwọn onísìn Búdà lórílẹ̀-èdè Myanmar, pàápàá àwọn ọ̀dọ́, tó ń sọ pé àwọn nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́ ń pọ̀ sí i. Nítorí náà, à ń bẹ Ọ̀gá náà láti rán àwọn òṣìṣẹ́ púpọ̀ sí i jáde fún iṣẹ́ ìkórè náà.”—Mát. 9:37, 38.

“À ń bẹ Ọ̀gá náà láti rán àwọn òṣìṣẹ́ púpọ̀ sí i jáde fún iṣẹ́ ìkórè náà”

Ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún [100] ọdún sẹ́yìn làwọn aṣáájú-ọ̀nà méjì tí wọ́n jẹ́ onígboyà mú ìhìn rere wá sí ilẹ̀ tí ọ̀pọ̀ jù lọ ti jẹ́ onísìn Búdà yìí. Látìgbà yẹn, ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn láti onírúurú èdè ti gba òtítọ́, wọ́n sì dì í mú ṣinṣin. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Myanmar kojú àwọn ìṣòro bí ogun abẹ́lé, rògbòdìyàn òṣèlú, ipò òṣì, inúnibíni ẹ̀sìn, àwọn àjálù àti bí orílẹ̀-èdè wọn ò ṣe bá orílẹ̀-èdè míì ṣọ̀rẹ́, síbẹ̀ wọ́n ń fọkàn sin Jèhófà Ọlọ́run, wọ́n sì ń tẹ̀lé Jésù Kristi, Ọmọ rẹ̀ láìyẹsẹ̀. Wọ́n ti pinnu pé àwọn á máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, àwọn á sì máa “fara dà á ní kíkún” àti pé àwọn á “máa ní ìpamọ́ra pẹ̀lú ìdùnnú.”—Kól. 1:11.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 172, 173]

a Orúkọ tí orílẹ̀-èdè Myanmar ń jẹ́ tẹ́lẹ̀ ni Burma, torí pé ẹ̀yà Bamar (ìyẹn Burmese) làwọn tó pọ̀ jù níbẹ̀. Lọ́dún 1989, wọ́n yí orúkọ yẹn pa dà sí Union of Myanmar, láti fi hàn pé àwọn ẹ̀yà míì wà lórílẹ̀-èdè náà. Nínú ìwé yìí, Burma la ó pe orúkọ orílẹ̀-èdè yìí níbi tá a bá ti sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tó wáyé ṣáájú ọdún 1989. Àmọ́ tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọdún 1989, a ó pè é ní Myanmar.

b Nígbà tí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ń ṣàkóso ilẹ̀ Íńdíà, àwọn kan láti ilẹ̀ Íńdíà wá tẹ̀dó sí ìlú Burma, tó wà lábẹ́ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.

c Arákùnrin Bertram Marcelline ló kọ́kọ́ ṣèrìbọmi, tó sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Burma. Ó jẹ́ olóòótọ́ títí tó fi kú lórílẹ̀-èdè náà ní nǹkan bí ọdún 1970.

d Owó yìí tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15,000] náìrà, owó tó jọjú ni nígbà yẹn.

e Wo Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—1966 [Gẹ̀ẹ́sì], ojú ìwé 192.

f Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é, àmọ́ a kò tẹ̀ ẹ́ mọ́.

g Ní báyìí èdè tó lé ní ẹgbẹ̀ta [600] ti ń lo MEPS.

[Àwòrán]

Àlàyé Ṣókí Nípa Orílẹ̀-Èdè Myanmar

Ilẹ̀

Oríṣiríṣi nǹkan mèremère ló mú kí ilẹ̀ Myanmar wuni. Àwọn òkè tí yìnyín bò, àwọn igbó kìjikìji tó ń móoru fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́, àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ tó tẹ́jú, àwọn odò ńláńlá, àtàwọn ibi tí odò ti ya wọnú òkun. Ilẹ̀ Myanmar ni orílẹ̀-èdè kejì tó tóbi jù ní gúúsù ìlà oòrùn ilẹ̀ Éṣíà, ó sì fẹ̀ ju orílẹ̀-èdè Faransé lọ.

Àwọn Èèyàn

Wọ́n fojú bù ú pé ọgọ́ta [60] mílíọ̀nù èèyàn látinú ẹ̀yà tó lé ní márùndínlógóje [135] ló ń gbé Myanmar. Ìdá méjì nínú mẹ́ta wọn ló jẹ́ ẹ̀yà Bamar tàbí Burmese. Nǹkan bí ẹni mẹ́sàn-án nínú mẹ́wàá tó ń gbé lórílẹ̀-èdè náà ló jẹ́ ẹlẹ́sìn Búdà ti Theravada. Ọ̀pọ̀ àwọn tó jẹ́ ẹ̀yà Kayin, Chin àti Kachin ló jẹ́ oníṣọ́ọ̀ṣì.

Èdè

Myanmar (tí wọ́n tún ń pè ní Burmese) ni èdè àjùmọ̀lò tí wọ́n ń sọ jákèjádò orílẹ̀-èdè Myanmar. Àmọ́ ọ̀pọ̀ àwọn ẹ̀yà tó wà níbẹ̀ tún ní èdè ìbílẹ̀ tiwọn.

Iṣẹ́ Oúnjẹ Òòjọ́

Iṣẹ́ àgbẹ̀, gbígbin igi àti iṣẹ́ ẹja pípa ni iṣẹ́ táwọn èèyàn ń ṣe jù lórílẹ̀-èdè Myanmar. Ìrẹsì ni wọ́n kà sí pàtàkì jù lára àwọn irè oko wọn. Àwọn ohun àmúṣọrọ̀ tún pọ̀ gan-an níbẹ̀, irú bí igi teak, rọ́bà, òkúta jéèdì, rúbì, epo àti gáàsì.

Oúnjẹ

[Àwòrán]

Àwọn tí wọ́n jọ ń jẹ oúnjẹ ilẹ̀ Myanmar

Ìrẹsì ni oúnjẹ tí wọ́n sábà máa ń jẹ níbẹ̀. Ọbẹ̀ ngapi, ìyẹn ọbẹ̀ tó ki, tí wọ́n fi ẹja tàbí edé sè, ni wọ́n sì sábà máa ń fi jẹ ẹ́. Àwọn sàláàdì tí wọ́n fi oríṣiríṣi èròjà sí náà wọ́pọ̀. Wọ́n tún máa ń fi ẹja, ẹran adìyẹ àti edé díẹ̀díẹ̀ sínú oúnjẹ wọn. Ohun mímu táwọn èèyàn mọ̀ jù níbẹ̀ ni tíì dúdú àti tíì aláwọ̀ ewé.

Ojú Ọjọ́

Òjò wẹliwẹli ló pọ̀ jù nílẹ̀ Myanmar. Ooru máa ń mú nígbà ẹ̀rùn àti lásìkò òjò. Àmọ́ lápá àríwá níbi tí òkè pọ̀ sí, ojú ọjọ́ máa ń tutù.

Ọkùnrin Tí Kì Í Fọ̀rọ̀ Sábẹ́ Ahọ́n Sọ

[Àwòrán]

SYDNEY COOTE

WỌ́N BÍ I NÍ 1896

Ó ṢÈRÌBỌMI NÍ 1939

ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ Ó wà lára àwọn tó kọ́kọ́ di Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Myanmar. Phyllis Tsatos (tó ń jẹ́ D’Souza tẹ́lẹ̀), tó jẹ́ ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ló sọ ìtàn yìí.

◆ ÀBÚRÒ ìyá mi ló wàásù fún ìdílé wa.

Ó béèrè lọ́wọ́ mi pé, “Ǹjẹ́ o tiẹ̀ gbà gbọ́ pé Ọlọ́run máa ń dá àwọn èèyàn lóró nínú iná ọ̀run àpáàdì?”

Mo dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, ohun tí wọ́n kọ́ wa ní Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì nìyẹn.”

Ó nawọ́ sí ajá wa tó sùn sílẹ̀, ó sì bi mí pé, “Kí lo máa ṣe tí ajá yìí bá bù ẹ́ jẹ?”

Mo dá a lóhùn pé, “Màá gbá a lábàrá kó lè mọ̀ pé nǹkan tó ṣe ò dáa.”

Ó wá sọ pé, “O ò ṣe fi ìrù ajá yẹn gbé e kọ́ sórí igi, kó o wá máa fi irin tó gbóná jó o lára?”

Àyà mi já, ṣe ni mo dá a lóhùn pé, “Á-à-á! Ìwà ìkà nìyẹn kẹ̀!”

Ó ní, “Ìwọ náà gbà pé ìwà ìkà nìyẹn, àbí? Àmọ́, wọ́n sọ fún yín ní ṣọ́ọ̀ṣì pé Ọlọ́run máa dá àwọn èèyàn lóró títí ayé nínú iná ọ̀run àpáàdì!”

Bó ṣe dọ́gbọ́n sọjú abẹ níkòó yẹn mú kí n ronú jinlẹ̀ lórí ohun tí mo gbà gbọ́ tẹ́lẹ̀. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni ẹni mẹ́jọ nínú ìdílé wa di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí wọ́n sì ń fìtara wàásù.

Àṣà Ìbílẹ̀ Àwọn Ará Myanmar

Orúkọ

Ọ̀pọ̀ àwọn ará Myanmar kì í jẹ́ orúkọ bàbá tàbí orúkọ ìdílé wọn. Orúkọ wọn sì sábà máa ń gùn. Wọ́n tún máa ń fi orúkọ wọn ṣàlàyé àwọn ìwà tó fani mọ́ra, àwọn nǹkan tí kò lẹ́mìí tàbí ẹ̀yà tí ẹnì kan ti wá. Bí àpẹẹrẹ Cho Sandar Myint túmọ̀ sí “Òṣùpá Dùn-ún Wò Lókè,” Htet Aung Htun túmọ̀ sí “Ọgbọ́n Ju Ẹ̀yẹ Lọ,” Naw Say Wah Phaw sì túmọ̀ sí “Òdòdó Ẹlẹ́wà.”

Ìkíni

Oríṣiríṣi ọ̀nà làwọn ará Myanmar gbà ń kí ara wọn. Tí àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ tó ti rí ara wọn tipẹ́ bá fẹ́ kí ara wọn, wọ́n á sọ pé, “Ojú ẹ rèé! Ṣé pé o ò tíì kú?” Tó bá bọ́ sígbà tí wọ́n fẹ́ jẹun, wọ́n á ní, “Ṣé o ti jẹun?” Àwọn ará Myanmar kì í sọ pé, “Ó dàbọ̀.” Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n á sọ pé, “Mo ti fẹ́ máa lọ.” Ohun tí wọ́n máa ń fi dáhùn ni pé, “Ire o!” tàbí “Ṣe jẹ́jẹ́ o!”

Ìwà

[Àwòrán]

Àwọn ará Myanmar máa ń fẹ́ kéèyàn jẹ́ oníwà tútù kó sì ní sùúrù gan-an. Wọ́n máa ń bọ̀wọ̀ fún àgbàlagbà. Wọ́n máa ń pè wọ́n ní Bọ̀dá, Àǹtí tàbí Olùkọ́. Tí wọ́n bá ń fún ara wọn ní nǹkan tàbí tí wọ́n bá ń bọ ara wọn lọ́wọ́, wọ́n máa ń fi ọwọ́ òsì di ọrùn ọwọ́ ọ̀tún wọn mú láti fi hàn pé wọ́n bọ̀wọ̀ fún ẹni náà. Tọkọtaya àtàwọn tó ń fẹ́ ara wọn sọ́nà kì í fi ìfẹ́ hàn sí ara wọn ní gbangba. Àmọ́ ọkùnrin àtọkùnrin tàbí obìnrin àtobìnrin máa ń di ara wọn lọ́wọ́ mú ní gbangba.

Aṣọ

Àtọkùnrin àtobìnrin máa ń wọ aṣọ tí wọ́n ń pè ní lungi. Aṣọ náà gbayì, ó sì wuni gan-an. Ó máa ń gùn láti ìbàdí dé kókósẹ̀. Táwọn ọkùnrin bá ró lungi mọ́ra, wọ́n á ta kókó rẹ̀ síwájú ikùn wọn, àmọ́ àwọn obìnrin máa ń ṣẹ́ tiwọn po sínú níbi ìbàdí. Bí àwọn ẹ̀yà tó wà ní ilẹ̀ Myanmar ṣe máa ń rán aṣọ ọkùnrin àtobìnrin yàtọ̀ síra.

Ìmúra

[Àwòrán]

Ìyá tó ń kun thanaka sí ojú ọmọ rẹ̀

Ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin àtàwọn ọmọdé máa ń kun thanaka, ìyẹn àtíkè olóòrùn dídùn tí wọ́n fi èèpo igi thanaka ṣe. Wọ́n máa ń lò ó láti fi tọ́jú ara àti láti fi ṣe ara lóge. Thanaka máa ń mára jọ̀lọ̀, ó sì lè dáàbò bo ara lọ́wọ́ ìtànṣán oòrùn.

Jèhófà Sọ Mí Di Ẹni Tuntun

[Àwòrán]

WILSON THEIN

WỌ́N BÍ I NÍ 1924

Ó ṢÈRÌBỌMI NÍ 1955

ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ Ó máa ń jalè tẹ́lẹ̀, àmọ́ ó sapá gan-an láti yí ìwà rẹ̀ pa dà, ó sì fi ọdún mẹ́rìnléláàádọ́ta [54] ṣe aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe.

◆ NÍGBÀ tí mo wà lọ́dọ̀ọ́, mo kọ́ bí wọ́n ṣe ń kan ẹ̀ṣẹ́, bí wọ́n ṣe ń ja gídígbò àti ìjàkadì tí wọ́n ń pè ní Judo. Nítorí náà, mo di oníjàgídíjàgan, mo sì máa ń bínú sódì. Nígbà tí mo fi máa di ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19], mo ti wọ ẹgbẹ́ àwọn adigunjalè. Ọwọ́ ìjọba tẹ̀ mí, wọ́n sì sọ mí sí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́jọ. Ibẹ̀ ni mo ti ronú lórí ìgbésí ayé burúkú tí mò ń gbé, mo sì gbàdúrà gan-an. Nínú ọkàn mi lọ́hùn-ún, ó wù mí kí n túbọ̀ mọ Ọlọ́run.

Lẹ́yìn tí mo jáde lẹ́wọ̀n, mo gba ìlú Yangon lọ, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, mo kẹ́kọ̀ọ́, mo sì ṣe ìrìbọmi. Ọpẹ́lọpẹ́ àwọn ará tó fi sùúrù ràn mí lọ́wọ́.

Lẹ́yìn tí mo ṣèrìbọmi, kò rọrùn fún mi láti máa hùwà bíi Kristẹni. (Éfé. 4:24) Ṣe ni mo máa ń ṣàríwísí àwọn èèyàn, mo sì máa ń bínú sí wọn. Ó wù mí gan-an pé kí n níwà tó dáa, àmọ́ mo ṣì máa ń bínú sódì. Èyí mú kí n ro ara mi pin, ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo sì máa ń lọ sódò lọ sunkún fún ọ̀pọ̀ wákàtí.

Mo máa n ro ara mi pin, ọ̀pọ̀ ìgbà sì ni mo máa ń lọ sódò lọ sunkún fún ọ̀pọ̀ wákàtí

Mo di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe lọ́dún 1957. Ìlú Mandalay ni wọ́n kọ́kọ́ gbé mi lọ. Èmi àti míṣọ́nnárì tó ń jẹ́ Robert Richards la jọ ṣiṣẹ́ níbẹ̀. Arákùnrin Robert mú mi bí ọmọ rẹ̀. Ó sì kọ́ mi láti máa wo ibi táwọn èèyàn dáa sí dípò kí n máa wo ibi tí wọ́n kù sí. Ó jẹ́ kí n mọ̀ pé ó yẹ kí n máa rántí pé èmi náà láwọn kùdìẹ̀kudiẹ tèmi. (Gál. 5:22, 23) Ìgbàkigbà tínú bá fẹ́ bí mi, ṣe ni mo máa ń bẹ Jèhófà pé kó fún mi ní “ẹ̀mí tuntun, ọ̀kan tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin” kí n lè lẹ́mìí àlàáfíà. (Sm. 51:10) Jèhófà gbọ́ àdúrà mi. Nígbà tó yá, ìwà mi túbọ̀ sunwọ̀n sí i.

Lẹ́yìn ìgbà náà, mo kọ́ bàbá àgbàlagbà kan tó jẹ́ ẹni ọgọ́rin [80] ọdún lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ṣọ́ọ̀ṣì Onítẹ̀bọmi ni bàbá yìí ń lọ, àwọn ará ṣọ́ọ̀ṣì yẹn fẹ̀sùn kàn mí pé mo ti kó àwọn ọmọ ìjọ àwọn lọ. Ọ̀kan nínú wọn tiẹ̀ fi ọ̀bẹ halẹ̀ mọ́ mi, ó sọ pé: “Àbí ẹ̀ṣẹ̀ ni tí mo bá pa ẹ́ dànù?” Inú ti bí mi gan-an. Lójú ẹsẹ̀, mo fọkàn gbàdúrà sí Jèhófà, mo wá fohùn pẹ̀lẹ́ fèsì pé: “O ti dáhùn ìbéèrè yẹn fúnra ẹ.” Bí ọkùnrin náà ṣe wò mí, tó sì bá tiẹ̀ lọ nìyẹn. Mo dúpẹ́ pé Jèhófà jẹ́ kí n ní sùúrù. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, bàbá àgbàlagbà yẹn ṣe ìrìbọmi. Ó sì sin Jèhófà tọkàntọkàn títí tó fi kú.

Ọ̀pọ̀ ọdún ni mo fi ṣe aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe ní ìpínlẹ̀ ìwàásù mẹ́tàdínlógún [17] ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Mo sì ti ran ẹni mẹ́rìnlélọ́gọ́ta [64] lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Omijé ayọ̀ máa ń bọ́ lójú mi nígbàkigbà tí mo bá ń rántí àwọn ohun rere tí Jèhófà ti ṣe fún mi. Tẹ́lẹ̀ mo máa ń bínú sódì, mi ò láyọ̀, mo sì tún jẹ́ oníwà ipá. Àmọ́ ní báyìí, Jèhófà ti sọ mí di ẹni tuntun.

Jèhófà Ṣe Ọ̀nà Àbáyọ

[Àwòrán]

MAURICE RAJ

WỌ́N BÍ I NÍ 1933

Ó ṢÈRÌBỌMI NÍ 1949

ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ Ó ti lo ohun tó lé ní àádọ́ta [50] ọdún lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún lórílẹ̀-èdè Myanmar. Ọ̀pọ̀ ọdún yẹn ló sì fi ṣe alábòójútó ẹ̀ka. Ní báyìí, ó wà lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ni orílẹ̀-èdè náà.h

◆ LỌ́DÚN 1988, àwọn èèyàn tó ń ṣe ìwọ́de gba gbogbo ojú ọ̀nà kan ní ìlú Yangon. Wọn ò gba ti ìjọba tó ń ṣàkóso nígbà yẹn. Ìgbà táwọn ológun rí i pé ìlú ti fẹ́ pín sí méjì, ni wọ́n bá dìtẹ̀ gbàjọba. Wọ́n wá ń pàṣẹ bó ṣe wù wọ́n. Àìmọye àwọn èèyàn tó ń wọ́de ni wọ́n pa dà nù.

Oṣù yẹn gan-an ló sì yẹ ká fi ìròyìn ọdọọdún ti ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ránṣẹ́ sí orílé-iṣẹ́ wa ní ìlú New York. Ṣùgbọ́n kò sí ọ̀nà tá a fẹ́ gbé e gbà. Wọn ò jẹ́ kí gbogbo ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ ṣiṣẹ́ mọ́. Nígbà tí mo gbọ́ pé ọ́fíìsì aṣojú ìjọba orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà fẹ́ fi ọkọ̀ òfuurufú kó àwọn lẹ́tà ìjọba ránṣẹ́ sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, mo ronú pé ó máa bọ́gbọ́n mu tí mo bá lọ fún wọn ní ìròyìn wa, kí wọ́n lè bá wa fi ránṣẹ́. Mo bá wọ èyí tó dáa jù lára àwọn kóòtù àti táì mi, mo sì kọrí sí ọ́fíìsì aṣojú ìjọba orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.

Òjò ń ṣe wẹliwẹli bí mo ṣe ń wakọ̀ lọ lójú ọ̀nà. Mo sì kíyè sí i pé gbogbo ọ̀nà dá páropáro. Nígbà tó yá, mo rí i pé wọ́n ti gbégi dínà. Mo bá sọ̀ kalẹ̀ nínú ọkọ̀, mo sì fi ẹsẹ̀ rìn dé ọ́fíìsì náà.

Bí mo ṣe ń sún mọ́ ẹnu géètì, mo rí ọ̀pọ̀ èèyàn tí wọ́n fẹ́ láti wọlé, àmọ́ àwọn àkòtagìrì ọmọ ogun ojú omi tójú wọn le koko ló wà lẹ́nu ọ̀nà. Mo bá rọra gbàdúrà sínú. Nígbà tí ọ̀kan lára àwọn ọmọléèwé tó wà níbẹ̀ rí bí mo ṣe múra, ó bá pariwo pé: “Ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ wọn lọkùnrin yìí o!” Bí mo ṣe rún ara mi gba àárín àwọn èrò yẹn kọjá nìyẹn. Nígbà tí mo jàjà dé ẹnu géètì náà, ọ̀kan tó rí fìrìgbọ̀n lára àwọn ọmọ ogun yẹn wò mí tìfuratìfura, ó sì jágbe mọ́ mi.

Ó ní: “Ibo nìwọ ti wá, kí lo fẹ́?”

Mo dá a lóhùn pé, “Mo fẹ́ rí ọ̀gá, ọ̀rọ̀ pàtàkì kan wà tí mo fẹ́ fi ránṣẹ́ sí Amẹ́ríkà.”

Ó wò mí títí. Nígbà tó yá, ó ṣílẹ̀kùn fún mi lójijì, ó sì fà mí wọlé, ló bá yára ti ilẹ̀kùn pa dà kí èrò má bàa rọ́ wọlé.

Ó ní, “Tẹ̀ lé mi.”

Nígbà tá a dé ẹnu ọ̀nà, ó fà mí lé ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ wọn lọ́wọ́. Ìyẹn náà bá tún béèrè ohun tí mo bá wá.

Mo fara balẹ̀ ṣàlàyé fún un pé: “Ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mo ti wá. Mo sì ní ìsọfúnni pàtàkì kan tó gbọ́dọ̀ dé oríléeṣẹ́ wa nílùú New York lóṣù yìí. Ẹ jọ̀ọ́, ṣé ẹ lè bá mi fi ránṣẹ́ pẹ̀lú àwọn lẹ́tà tí ọ́fíìsì yín náà fẹ́ fi ránṣẹ́?” Mo bá fún un ní àpòòwé tí mo fi ìròyìn náà sí, mo sì sọ fún un pé, “Ẹ jọ̀ọ́, ẹ máà bínú o, mi ò ní sítáǹbù tí mo lè lẹ̀ mọ́ ọn.”

Mo fún un ní àpòòwé tí mo fi ìròyìn náà sí, mo sì sọ fún un pé, “Ẹ jọ̀ọ́, ẹ máà bínú o, mi ò ní sítáǹbù tí mo lè lẹ̀ mọ́ ọn”

Bí mo ṣe bá a sọ̀rọ̀ yẹn yà á lẹ́nu gan-an, ó bi mí láwọn ìbéèrè mélòó kan. Ó sì fi dá mi lójú pé òun máa fi ìwé náà ránṣẹ́. Mo gbọ́ pé ìròyìn náà dé oríléeṣẹ́ wa lásìkò.

h Ìtàn nípa Arákùnrin Raj wà nínú Ilé Ìṣọ́ December 1, 2010.

Adájọ́ Kan Kẹ́kọ̀ọ́ Òtítọ́

[Àwòrán]

MANG CUNG

WỌ́N BÍ I NÍ 1934

Ó ṢÈRÌBỌMI NÍ 1981

ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ Ọ̀gá àgbà iléèwé girama àti adájọ́ tó di aṣáájú-ọ̀nà onítara.

◆ NÍGBÀ tí aṣáájú ọ̀nà kan kọ́kọ́ fún mi ní Ilé Ìṣọ́, mo sọ fún un pé: “Ọwọ́ mi dí gan-an. Èmi ò lè ráyè ka ìwé tó o fún mi yìí o.” Àmọ́ torí pé mo máa ń mu tábà gan-an, mo ronú pé ìwé náà máa wúlò fún mi láti fi wé tábà nígbàkigbà tí mo bá fẹ́ mu ún. Torí náà, mo gba ìwé ìròyìn náà.

Bí mo ṣe fẹ́ ya abala kan níbẹ̀ láti fi wé tábà, mo ronú pé kò ní dáa kí n ya ìwé náà láì kọ́kọ́ kà á. Bí mo ṣe wá fẹ́ràn láti máa ka Ilé Ìṣọ́ nìyẹn. Ohun tí mo kà nínú ìwé yẹn ló jẹ́ kí n jáwọ́ nínú mímu tábà, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi ìlànà Ọlọ́run ṣèwà hù. Kò pẹ́ rárá tí mo ṣèrìbọmi.

Lẹ́yìn tí mo ṣèrìbọmi tí mo sì pa dà sí abúlé wa, pásítọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì abúlé wa àtàwọn àgbààgbà ibẹ̀ fi owó bẹ̀ mí pé kí n pa dà sí ẹ̀sìn tí mo ń ṣe tẹ́lẹ̀. Nígbà tí mo kọ̀ láti ṣe ohun tí wọ́n sọ, wọ́n parọ́ fún àwọn èèyàn pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti fún mi lówó kí n lè ṣèrìbọmi. Láìka gbogbo irọ́ tí wọ́n pa mọ́ mi yìí, mi ò jẹ́ kẹ́rù bà mí. Inú mi dùn pé mo mọ Ọlọ́run tòótọ́, mo sì ń sìn ín.

Jèhófà Bù Kún Mi Nítorí Ìfaradà Mi

[Àwòrán]

AH SHE

WỌ́N BÍ I NÍ 1952

Ó ṢÈRÌBỌMI NÍ 1998

ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ Ọkùnrin tó máa ń wàásù ní ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì tẹ́lẹ̀, tó wá di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

◆ Ọ̀PỌ̀ ọdún ni mo fi ṣe ẹ̀sìn Kátólíìkì ní àgbègbè ibi tí nǹkan àmúṣọrọ̀ wà tẹ́lẹ̀. Nígbà tí mo rí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí mo sì rí bí wọ́n ṣe ń fi Bíbélì kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́, mo gbà wọ́n láyè láti máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Kò pẹ́ tí mo fi bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù nínú ṣọ́ọ̀ṣì nígbà ìsìn òwúrọ̀ láwọn ọjọ́ Sunday, tí mo sì máa ń lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba lọ́sàn-án Sunday. Mi ò mọ ìgbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í fi àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tí mò ń kọ́ kún ìwàásù mi ní ṣọ́ọ̀ṣì. Ìyẹn bí àwọn tá a jọ ń ṣe ìsìn nínú, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ àwọn àlùfáà. Nígbà tí mo kọ̀wé fi iṣẹ́ ìwàásù nínú ṣọ́ọ̀ṣì sílẹ̀, wọ́n gbé mi lọ sílé ẹjọ́ kí wọ́n lè lé mi kúrò ní abúlé náà. Àmọ́, adájọ́ sọ fún wọn pé ẹ̀sìn tó bá wù mí ni mo lè ṣe. Ṣe ni ìyàwó mi fàáké kọ́rí pé òun ò gbà. Ó kígbe mọ́ mi pé: “Máa lọ! Gbé báàgì àti Bíbélì ẹ kó o máa lọ!” Pẹ̀lú gbogbo bó ṣe ń bínú sí mi, mi ò fìkanra mọ́ ọn. Mo máa ń tọ́jú òun àtàwọn ọmọ. Inú mi dùn gan-an pé Jèhófà bù kún ìfaradà mi. Ní báyìí, Cherry ìyàwó mi, àtàwọn ọmọ wa ti ń sin Jèhófà tayọ̀tayọ̀.

Gbogbo Ìfura Mi sí Wọn Pòórá

[Àwòrán]

GREGORY SARILO

WỌ́N BÍ I NÍ 1950

Ó ṢÈRÌBỌMI NÍ 1985

ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ Ṣọ́ọ̀ṣì ló ti ń ṣiṣẹ́ tẹ́lẹ̀, ó sì rò pé wòlíì èké ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

◆ Ọ̀PỌ̀ ọdún ni mo fi ṣe ẹ̀sìn Kátólíìkì tọkàntara, tí mo sì máa ń darí àwọn nǹkan tí ṣọ́ọ̀ṣì bá ń ṣe lábúlé wa. Ní gbogbo àkókò yẹn, mo rí i táwọn aṣáájú ṣọ́ọ̀ṣì ń gba ìṣekúṣe láyè, tí wọ́n ń rúbọ sáwọn ẹ̀mí àìrí, tí wọ́n sì ń lọ́wọ́ nínú ìbẹ́mìílò. Ìwà àgàbàgebè wọn kó mi nírìíra débi tí mo fi kọ̀wé fi ṣọ́ọ̀ṣì sílẹ̀, ṣùgbọ́n mo ṣì gba àwọn ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn Kátólíìkì gbọ́.

Lọ́dún 1981, mo pàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Òye tí wọ́n ní nípa Bíbélì ló wú mi lórí tí mo fi gbà pé kí wọ́n máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Síbẹ̀, mo fura sí àwọn ẹ̀kọ́ wọn gan-an, gbogbo ìgbà ni mo sì ń ta kò wọ́n. Wọ́n fara balẹ̀ lo Bíbélì láti dáhùn gbogbo ìbéèrè mi.

Mo lọ sí àpéjọ àgbègbè wọn kan kí n lè mọ̀ bóyá ohun kan náà ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọ́ àwọn èèyàn níbi gbogbo. Ní àkókò ìsinmi kan ní àpéjọ náà, mo gbàgbé báàgì mi sí abẹ́ àga, káàdì ìdánimọ̀ mi, owó àtàwọn ohun iyebíye míì ló sì wà nínú rẹ̀. Gbogbo èrò mi ni pé wọ́n á tí jí i gbé. Àmọ́ àwọn ará náà sọ fún mi pé: “Fọkàn ẹ balẹ̀. Bó o ṣe fi í sílẹ̀ ni wàá ṣe bá a.” Mo sáré pa dà síbi tí mo jókòó sí, mo sì bá a níbẹ̀ lóòótọ́! Gbogbo ìfura tí mo ní sáwọn Ẹlẹ́rìí pòórá lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.

Mo Rí ‘Ọrọ̀ Tí Ó Ta Yọ’

SA THAN HTUN AUNG

WỌ́N BÍ I NÍ 1954

Ó ṢÈRÌBỌMI NÍ 1993

ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ Ẹlẹ́sìn Búdà tó jẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé ni tẹ́lẹ̀, ó sì tún jẹ́ sójà. Lẹ́yìn tó rí òtítọ́, ó ṣe aṣáájú-ọ̀nà fún ọ̀pọ̀ ọdún.

◆ INÚ ÌDÍLÉ ẹlẹ́sìn Búdà ni wọ́n bí mi sí, ìgbà kan sì wà tí mo jẹ́ ẹlẹ́sìn Búdà tó jẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé. Mi ò gbà gbọ́ pé ẹnì kan wà tó jẹ́ Ọlọ́run tàbí Ẹlẹ́dàá. Lọ́jọ́ kan, ọ̀rẹ́ mi kan ní kí n wá sí ṣọ́ọ̀ṣì àwọn, ibẹ̀ sì ni mo ti gbọ́ pé àwa èèyàn ní Bàbá kan ní ọ̀run. Ó wù mí gan-an pé kí n mọ Bàbá wa ọ̀run yìí, kí n sì sún mọ́ ọn.

[Àwòrán]

Nígbà tí mo parí àkókò tí mo fẹ́ lò lẹ́nu iṣẹ́ ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé, mo wọ iṣẹ́ ológun. Mo máa ń ṣàkọsílẹ̀ ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan tí mo bá wà lẹ́nu iṣẹ́. Ọ̀rọ̀ tí mo sì máa ń kọ́kọ́ kọ ni “Bàbá, Ọlọ́run ọ̀run.” Nígbà tó yá, mo fẹ́ fi iṣẹ́ ológun sílẹ̀, kí n lè di pásítọ̀, àmọ́ àwọn ọ̀gá mi kò gbà. Láìpẹ́, mo dé ipò ọ̀gágun, èyí sì jẹ́ kí n di alágbára, mo lókìkí, mo sì lówó lọ́wọ́ gan-an. Síbẹ̀, ó ṣì ń wù mí pé kí n sún mọ́ Ọlọ́run.

Lọ́dún 1982, mo gbé Htu Aung níyàwó. Ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obìnrin tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún wa ní ìwé Lati Paradise T’a Sọnu Si Paradise T’a Jere-Pada. Ìwé náà sọ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run, àmọ́ mi ò gbà pé òótọ́ ni. Mo sọ fún ìyàwó mi pé, “Tó o bá lè fi orúkọ náà, Jèhófà, hàn mí nínú Bíbélì lédè Myanmar, màá di Ẹlẹ́rìí Jèhófà!” Ó wá a nínú Bíbélì rẹ̀, ṣùgbọ́n kò rí i. Àmọ́ bí ẹní fẹran jẹ̀kọ ló rí fún Mary, ọ̀rẹ́ rẹ̀ tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí. Ojú ẹsẹ̀ ló fi orúkọ náà, Jèhófà, hàn mí! Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, mo bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pẹ̀lú ìyàwó àtàwọn ọmọ mi, mo sì gbà kí wọ́n máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Bí mo ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sí i ló túbọ̀ ń wù mí láti sin Ọlọ́run. Ní ọdún 1991, mo tún kọ̀wé láti fi iṣẹ́ ológun sílẹ̀, àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí ó jẹ́ nítorí pé mo fẹ́ di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wọ́n yọ̀ǹda mi pátápátá lọ́dún 1993. Ọdún yẹn náà ni èmi àti Htu Aung ṣèrìbọmi.

Mo bẹ̀rẹ̀ sí í ta oúnjẹ lọ́jà kí n lè gbọ́ bùkátà ìdílé mi. Àwọn mọ̀lẹ́bí mi àtàwọn ọ̀rẹ́ mi sọ fún mi pé orí mi ti yí, torí pé mo fi iṣẹ́ ológun tó lè sọ mí di èèyàn ńlá sílẹ̀, mo wá ń ṣiṣẹ́ tí ò yẹ mí. Àmọ́ mo rántí pé Mósè fi ipò rẹ̀ láàfin Fáráò sílẹ̀, ó sì di olùṣọ́ àgùntàn, nítorí pé ó fẹ́ sin Ọlọ́run. (Ẹ́kís. 3:1; Héb. 11:24-27) Láìpẹ́, ọwọ́ mi ba àfojúsùn kan tó jẹ mí lógún, mo di aṣáájú-ọ̀nà déédéé.

Ọ̀pọ̀ àwọn tó jẹ́ ọ̀rẹ́ mi nínú iṣẹ́ ológun ló di ọ̀gá tó gbajúmọ̀, tí wọ́n sì rí ọrọ̀ kó jọ. Àmọ́ mo ti rí “ọrọ̀ títayọ ré kọjá,” ìyẹn àwọn ìbùkún tí mo rí gbà nítorí mo mọ bàbá mi ọ̀run, mo sì ń sìn ín. (Éfé. 2:7) Lónìí, àwọn ọmọ ẹ̀gbọ́n mi àtàwọn ọmọ àbúrò mi mélòó kan wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, ọmọkùnrin mi àgbà sì ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì ti orílẹ̀-èdè Myanmar.

Inú Rere Wọn Ló Jẹ́ Kí N Di Ẹlẹ́rìí Jèhófà

ZAW BAWM

WỌ́N BÍ I NÍ 1954

Ó ṢÈRÌBỌMI NÍ 1998

ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ Oògùn olóró ló ń tà tẹ́lẹ̀, ó sì kórìíra àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àmọ́ inú rere tí wọ́n fi hàn sí i wọ̀ ọ́ lọ́kàn gan-an.

[Àwòrán]

◆ NÍGBÀ tí Lu Mai, ìyàwó mi bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ńṣe ni mo fi ìbínú ta kò ó. Mo sọ ìwé tó fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sínú ṣáláńgá, mo sì lé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà kúrò nílé wa.

[Àwòrán]

Títí dòní, mi ò tíì yẹsẹ̀ lórí ìpinnu mi, mo ṣì ń fi gbogbo agbára mi sin Jèhófà

Nígbà tó yá, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ta oògùn olóró, èyí sì sọ mí dèrò ẹ̀wọ̀n. Lọ́jọ́ kejì, Lu Mai fi Bíbélì kan àti lẹ́tà tó kún fún ọ̀pọ̀ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ránṣẹ́ sí mi, èyí sì tù mí nínú. Ó tún fi àwọn lẹ́tà míì tó ń ṣàlàyé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ránṣẹ́ sí mi. Kò sì pẹ́ rárá tí mo fi mọ̀ pé ká ní mo ti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì ni, mi ò ní di ẹlẹ́wọ̀n.

Nígbà tí mo wà lẹ́wọ̀n, àwọn ọkùnrin méjì kan wá mi wá. Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n, wọ́n sì sọ fún mi pé ìyàwó mi ló ní kí àwọn wá wò mí, kí àwọn sì sọ̀rọ̀ ìṣírí fún mi. Ọjọ́ méjì ni wọ́n fi rin ìrìn àjò kí wọ́n tó dé ọ̀dọ̀ mi. Ìbẹ̀wò wọn wọ̀ mí lọ́kàn gan-an. Bí àwọn ìbátan mi ṣe pọ̀ tó, kò sí ìkankan nínú wọn tó wá wò mí. Àwọn èèyàn tí mo fi ìbínú ta kò nìkan ló wá mi wá.

Kò pẹ́ lẹ́yìn náà tí ibà táífọ́ọ̀dù gbé mi ṣánlẹ̀, wọ́n gbé mi lọ sí ilé ìwòsàn àmọ́ mi ò rówó san. Àkókò yẹn náà ni mo tún gbàlejò míì, ìyẹn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tí ìyàwó mi rán sí mi. Àánú ṣe é nígbà tó rí mi, ó sì sanwó ìtọ́jú mi. Ojú gbà mí tì, mo sì pinnu pé màá di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ọdún márùn-ún lẹ́yìn náà ni mo jáde lẹ́wọ̀n, mo sì ṣe bí mo ti pinnu.

Màá Gun Òkè bí Akọ Àgbọ̀nrín

[Àwòrán]

LIAN SANG

WỌ́N BÍ I NÍ 1950

Ó ṢÈRÌBỌMI NÍ 1991

ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ Sójà ni tẹ́lẹ̀, ogun ló sọ ọ́ dẹni tí kò lẹ́sẹ̀ mọ́. Ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ni báyìí.

◆ ABÚLÉ MATUPI, tó wà lórí òkè àdádó kan ní ìpínlẹ̀ Chin ni wọ́n bí mi sí, ibẹ̀ ni mo sì gbé dàgbà. Àwọn ẹ̀mí àìrí alágbára ni ìdílé wa ń jọ́sìn, wọ́n sì gbà gbọ́ pé inú àwọn igbó tàbí àwọn òkè kan ní àgbègbè wa ni àwọn ẹ̀mí náà wà. Bí ẹnì kan bá ṣàìsàn nínú ìdílé wa, a máa gbé oúnjẹ sí ojúbọ ilé wa, a sì máa gbàdúrà pé kí ẹ̀mí àìrí kan wá jẹ ẹbọ náà. A gbà gbọ́ pé ẹ̀mí àìrí yẹn á jẹ́ kí ara onítọ̀hún yá.

Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mọ́kànlélógún [21], mo wọṣẹ́ ológun. Lẹ́yìn ìgbà náà, ó tó ogún [20] ìgbà tí mo lọ sójú ogun. Ní ọdún 1977 àwọn ajàjàgbara Kọ́múníìsì gbéjà ko àgọ́ wa nítòsí ìlú Muse tó wà ní Ìpínlẹ̀ Shan. Ogúnjọ́ ni wọ́n fi bá wa jà. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, àwa náà bẹ̀rẹ̀ sí í gbéjà kò wọ́n kíkankíkan, bí mo ṣe tẹ àdó olóró kan mọ́lẹ̀ nìyẹn. Ìgbà tí mo wo ẹsẹ̀ mi, egungun nìkan ló kù. Ẹsẹ̀ mi ń gbóná, òùngbẹ sì ń gbẹ mí burúkú burúkú, àmọ́ mi ò bẹ̀rù rárá. Wọ́n sáré gbé mi lọ sí ilé ìwòsàn, ibẹ̀ ni wọ́n ti gé ẹsẹ̀ mi méjèèjì. Lẹ́yìn oṣù mẹ́rin, mo kúrò nílé ìwòsàn, wọ́n ní kí n kúrò lẹ́nu iṣẹ́ ológun, mo wá pa dà sílé.

Nínú Párádísè, màá gun òkè bí akọ àgbọ̀nrín, màá sáré, màá sì tún fò sókè tayọ̀tayọ̀!

Emi àti Sein Aye, ìyàwó mi kó lọ sí ìlú Sagaing, nítòsí ìpínlẹ̀ Mandalay. Nígbà tá a débẹ̀, mo bẹ̀rẹ̀ sí í fi ọparun hun àga kí n lè máa rówó gbọ́ bùkátà. Ibẹ̀ ni mo ti pàdé pásítọ̀ ìjọ Onítẹ̀bọmi kan tó sọ fún mi pé Ọlọ́run ló fẹ́ kí wọ́n gé ẹsẹ̀ mi. Nígbà tó yá, èmi àti ìyàwó mi pàdé aṣáájú-ọ̀nà kan tó ń jẹ́ Rebecca. Ó sì sọ fún wa pé ìrètí ṣì wà pé màá pa dà ní ẹsẹ̀ nígbà tí ayé bá di Párádísè lọ́jọ́ iwájú. Láìpẹ́, a bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tọkàntọkàn lọ́dọ̀ Rebecca dípò pásítọ̀ yẹn!

[Àwòrán]

Ọgbọ̀n [30] ọdún ti kọjá báyìí, èmi àti ìyàwó mi àtàwọn ọmọ wa méje tó ti ṣèrìbọmi ń gbé ní abúlé kékeré kan nítòsí Pyin Oo Lwin. Abúlé náà rẹwà, ó sì wà lórí òkè ní nǹkan bíi kìlómítà márùndínláàádọ́rin [65] sí ìlú Mandalay. Ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ni mí ní ìjọ Pyin Oo Lwin, mẹ́ta lára àwọn ọmọ mi sì jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Èmi àti ìyàwó mi ti sapá gan-an láti kọ́ àwọn ọmọ wa nípa Jèhófà, inú wa sì dùn pé wọ́n ń sin Jèhófà bá a ṣe fẹ́.

Mo máa ń fi kẹ̀kẹ́ arọ wàásù déédéé ní abúlé wa, wọ́n sì máa ń fi alùpùpù gbé mi lọ sí ìpàdé ìjọ. Mo tún ní igi pẹlẹbẹ méjì tí mo máa fi ń rìn.

Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí mo fẹ́ràn jù ni Aísáyà 35:6, tó sọ pé: “Ní àkókò yẹn, ẹni tí ó yarọ yóò gun òkè gan-an gẹ́gẹ́ bí akọ àgbọ̀nrín ti ń ṣe.” Mò ń fojú sọ́nà gan-an fún ọjọ́ tí àwọn ẹsẹ̀ mi máa pa dà bọ̀ sípò! Nígbà tó bá ṣẹlẹ̀, máa gun òkè bí akọ àgbọ̀nrín, màá sáré, màá sì tún fò sókè tayọ̀tayọ̀!

Àwọn Alábòójútó Arìnrìn-Àjò Ń Ṣiṣẹ́ Kára

[Àwòrán ilẹ̀]
[Àwòrán]

Àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò ń ṣiṣẹ́ takuntakun láti fún àwọn arákùnrin àti arábìnrin wọn lókun jákèjádò orílẹ̀-èdè tó gbòòrò yìí. Báwo ni wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́ wọn? Ẹ jẹ́ ká máa fọkàn bá alábòójútó arìnrìn-àjò kan lọ bó ṣe ń ṣèbẹ̀wò sáwọn ìjọ tó wà lágbègbè Naga Hills tó jìnnà réré. Orúkọ rẹ̀ ni Myint Lwin pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀, Lal Lun Mawmi. Ó sọ pé: “Ní nǹkan bí aago mẹ́sàn-án àárọ̀ ni èmi àti ìyàwó mi gbéra ní ìlú Kalaymyo nínú ọkọ̀ akẹ́rù kan tó há gádígádí. Àárín àwọn páálí tí wọ́n fi di ẹrù àti ewébẹ̀ la ki ẹsẹ̀ sí. Àwọn kan lára èrò jókòó sórí ọkọ̀, àwọn míì sì rọ̀ mọ́ ilẹ̀kùn ẹ̀yìn ọkọ̀ náà. Bá a ṣe ń lọ lójú ọ̀nà tó rí gbágungbàgun náà ni eruku ń fẹ́ wọlé. A máa ń da aṣọ bo imú àti ẹnu wa kí eruku má bàa kó sí wa lọ́fun.

“Lẹ́yìn wákàtí méjì, a dé Kalaywa, ìlú kan tó wà létí odò. Ibẹ̀ la ti máa wọ ọkọ̀ ojú omi. Bá a ṣe ń dúró de ọkọ̀, à ń fi àkókò yẹn wàásù fáwọn tá a jọ ń dúró àtàwọn tó ń tajà, tí ọ̀pọ̀ jù lọ wọn ò gbọ́ nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà rí. Bí ọkọ̀ náà ṣe dé, táwọn èrò inú rẹ̀ sì ń sọ̀ kalẹ̀, làwọn èrò tó wà nílẹ̀ ń sáré láti jókòó sáwọn àyè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣí sílẹ̀. Àwa tá a fún ara wa mọ́ inú ọkọ̀ náà máa tó ọgọ́rùn-ún [100], èyí sì lè mú kí ọkọ̀ náà dojú dé. A ri àwọn ìgò oníke bọ inú àwọn báàgì wa, kí wọ́n lè léfòó tí ọkọ̀ bá dojú dé.

“Lẹ́yìn wákàtí márùn-ún, a gúnlẹ̀ sí ìlú Mawlaik, níbi tá a ti máa sùn mọ́jú ní ilé èrò kékeré kan. Aago márùn-ún ìdájí la tún bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò wa lọ́jọ́ kejì. Ẹ̀ẹ̀mẹrin ni ọkọ̀ wa rì sínú ẹrẹ̀ nítorí pé omi odò náà ti fà nígbà ọ̀gbẹlẹ̀ yẹn. Ṣe lèmi àtàwọn ọkùnrin tó kù máa ń sọ̀ kalẹ̀, ká lè ti ọkọ̀ náà jáde. Ó ti rẹ̀ wá tẹnutẹnu nígbà tá a dé Homalin lẹ́yìn wákàtí mẹ́rìnlá, àmọ́ àwọn ará ìjọ tó wà níbẹ̀ wá pà dé wa. Ṣe ni ara wa yá gágá nígbà tá a rí ayọ̀ tó hàn lójú wọn. A máa gbádùn ìbákẹ́gbẹ́ alárinrin pẹ̀lú wọn lálẹ́ òní. Tílẹ̀ bá mọ́, a máa rin ìrìn àjò wákàtí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lọ sí ìlú Khamti.

“A tún tètè gbéra lónìí. Àmọ́ ọkọ̀ wa ò kún dẹ́nu bíi ti tẹ́lẹ̀, àwọn ibi tá a sì ń gbà kọjá ti yàtọ̀ pẹ̀lú. Bá a ṣe rọra ń lọ là ń kọjá àwọn ará abúlé tó ń wa góòlù nínú odò. Níkẹyìn, a dé ìlú Khamti, gbogbo ara ló ń kan wá gógó, àmọ́ kò sí ẹni tó wá pà dé wa. Bóyá lẹ́tà ìbẹ̀wò tá a kọ sí wọn ò dé ọ̀dọ̀ wọn. A yáa ní kí ọlọ́kadà kan gbé wa lọ sí ilé tí wọ́n kọ́ mọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba, tààrà la sì lọ sùn.

“Láàárọ̀ ọjọ́ kejì, a dara pọ̀ mọ́ àwọn akéde mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] tó wá pàdé fún iṣẹ́ ìwàásù ní Gbọ̀ngàn Ìjọba náà. Ọ̀pọ̀ wọn wá látinú ẹ̀yà Naga, tó ń gbé àárín àwọn òkè ńlá tó wọnú orílẹ̀-èdè Íńdíà. A gbéra lọ sí ibi tá a ti fẹ́ wàásù. Ìlú tá a ti fẹ́ wàásù wà láàárín ibi tí odò ti yí àwọn òkè gíga fíofío po. Èmi àti ẹni tá a jọ ṣiṣẹ́ nahùn sí àwọn tó ń gbé inú ilé onígi kan tá a dé. Ọkùnrin kan tó jẹ́ ẹ̀yà Naga kan yọjú sí wa, ó sì ní ká wọlé. Òun àti ìyàwó rẹ̀ fara balẹ̀ gbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, wọ́n sì fayọ̀ gba àwọn ìwé wa. Ọ̀pọ̀ àwọn Naga ló sọ pé Kristẹni làwọn, wọ́n sì máa ń fi ìfẹ́ hàn sí ìhìn rere. Nírọ̀lẹ́, a lọ sí ìpàdé ìjọ, tó jẹ́ àkọ́kọ́ nínú àwọn ìpàdé tá a ṣe lọ́sẹ̀ yẹn.

Ṣe ni ara wa yá gágá nígbà tá a rí ayọ̀ tó hàn lójú wọn

[Àwòrán]

“Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan, a ré kọjá odò lọ sí Sinthe. Ìlú kékeré kan ni, akéde méjìlá ló sì wà níbẹ̀. A tún bẹ àwùjọ mẹ́ta tó wà ní àdádó wò, èyí tó jìnnà jù lọ síbi tá a wà jẹ́ kìlómítà mọ́kànlá. Ẹsẹ̀ la máa fi rìn dé ọ̀dọ̀ wọn fún iṣẹ́ ìwàásù, màá sì sọ àsọyé Bíbélì kan fún wọn. Aláìní ni ọ̀pọ̀ àwọn akéde yìí, àìsàn ibà àti ikọ́ ẹ̀gbẹ sì ń bá ọ̀pọ̀ wọn fínra. Wọ́n tún ń fojú winá àtakò nítorí ẹ̀sìn wọn. Síbẹ̀, wọ́n ń fi ìtara wàásù. Inú wa dùn láti rí àwọn èèyàn mẹ́rìndínlọ́gọ́rin [76] tó wá gbọ́ àsọyé fún gbogbo èèyàn lọ́jọ́ Sunday, púpọ̀ nínú wọn rìn fún ọ̀pọ̀ wákàtí kí wọ́n tó débẹ̀.

“Ṣe ló dà bíi pé ká má lọ mọ́ nígbà tí ìbẹ̀wò wa parí. A ò fẹ́ fi àwọn arákùnrin àti arábìnrin ọ̀wọ́n yìí sílẹ̀, wọ́n ti fi hàn láìmọye ìgbà pé àwọn fẹ́ràn Jèhófà. Bí ọkọ̀ wa ṣe ń darí bọ̀ sí gúúsù Myanmar, ṣe là ń ronú nípa ìgbàgbọ́ wọn tó lágbára. Bí wọn ò tiẹ̀ ní àwọn nǹkan tara, wọ́n lọ́rọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run! A ń wọ̀nà fún ìgbà tá a tún máa bẹ̀ wọ́n wò.”

Mo Fẹ́ Wàásù fún Gbogbo Ayé!

[Àwòrán]

SAGAR RAI

WỌ́N BÍ I NÍ 1928

Ó ṢÈRÌBỌMI NÍ 1968

ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ Sójà tí ìjọba dá lọ́lá ni, ó rí òtítọ́, ó sì ń wàásù láìka àtakò líle láti ọ̀dọ̀ àwọn aládùúgbò sí.

◆ ÀGBÈGBÈ tí òkè pọ̀ sí ní Ìpínlẹ̀ Shan ní apá àríwá ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè Myanmar ni wọ́n ti bí mi. Inú ẹ̀yà Gurkha lórílẹ̀-èdè Nepal la ti wá, ẹlẹ́sìn Híńdù sì ni wá. A sì tún jẹ́ abọgibọ̀pẹ̀. Iṣẹ́ ológun ni ẹ̀yà Gurkha sábà máa ń ṣe, torí náà bíi ti bàbá mi àtàwọn ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin mẹ́rẹ̀ẹ̀rin èmi náà wọṣẹ́ ológun. Mo ṣiṣẹ́ ológun ní orílẹ̀-èdè Myanmar fún ogún [20] ọdún, mo sì lọ jagun láìmọye ìgbà. Síbẹ̀ ìyàlẹ́nu ló jẹ́ pé mi ò fi bẹ́ẹ̀ fara pa.

Ìgbà tí mo kọ́kọ́ ka ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ ni mo mọ̀ pé Bíbélì sọ pé Ọlọ́run kan ṣoṣo ló wà, orúkọ rẹ̀ sì ni Jèhófà. Ó jọ mí lójú gan-an ni. Nítorí ẹlẹ́sìn Híńdù ni mí, mo gbà pé ọ̀kẹ́ àìmọye ọlọ́run ló wà! Mo wá orúkọ náà Jèhófà nínú àwọn ìwé atúmọ̀ èdè ti èdè Nepali, Hindi, Burmese àti Gẹ̀ẹ́sì. Gbogbo wọn ló sọ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run tó ni Bíbélì.

Nígbà tó yá, èmi àti Jyoti, ìyàwó mi ṣí lọ sí ìlú Pathein, ibẹ̀ sì ni Frank Dewar ti bi mí bóyá màá fẹ́ kóun máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Mo gbà pé kó máa kọ́ mi, Jyoti náà sì gbà. Kò pẹ́ rárá tó fi dá wa lójú pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo, a sì pinnu pé Òun nìkan la ó máa sìn. A da gbogbo ère tá a fi ń jọ́sìn tẹ́lẹ̀ sínú Odò Pathein kí ẹnikẹ́ni má bàa rí wọn lò.—Diu. 7:25; Ìṣí. 4:11.

Kò pẹ́ sígbà yẹn ni mo fi iṣẹ́ ológun sílẹ̀. Èmi, ìyàwó mi àtàwọn ọmọ sì pa dà sí ìlú tí wọ́n ti bí mi. Nígbà tá a débẹ̀ a dara pọ̀ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mélòó kan tó wà níbẹ̀, wọ́n sì kọ́ wa bá a ṣe ń wàásù. Nígbà tó yá, a fi igi àti ewé kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kékeré kan síwájú ilé mi. Èyí múnú bí ìgbìmọ̀ kan ní àdúgbò tí àwọn Gurkha pọ̀ sí yìí, wọ́n fìbínú sọ pé: “Ta ló fún yín láṣẹ láti kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì Kristẹni síbi táwọn ẹlẹ́sìn Híńdù wà? Kò yẹ kẹ́ ẹ máa wàásù fún àwọn tó ti ní ẹ̀sìn tiwọn.”

Ìgbìmọ̀ ẹ̀yà Gurkha náà lọ fẹjọ́ wa sun àwọn aláṣẹ àdúgbò náà, wọ́n sì bi mí pé: “Ọ̀gbẹ́ni Rai, ṣé lóòótọ́ lo ń wàásù ní àdúgbò ẹ, tó o sì ń yí àwọn èèyàn lọ́kàn pa dà di Kristẹni?”

Mo sọ fún wọn pé: “Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mí. Kì í sì í ṣe pé mo fẹ́ wàásù ni àdúgbò mi nìkan, ṣùgbọ́n mo fẹ́ wàásù fún gbogbo ayé! Àmọ́ ṣá, kálukú ló máa pinnu bóyá òun fẹ́ yí ẹ̀sìn òun pa dà tàbí òun ò fẹ́.”

Ní ogójì [40] ọdún tó ti kọjá, èmi àti ìyàwó mi ti kọ́ àwọn èèyàn tó lé ní ọgọ́rùn-ún [100] lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́

Inú wa dùn pé, àwọn aláṣẹ ní ká máa bá iṣẹ́ ìwàásù wa lọ fàlàlà. Ní ogójì [40] ọdún tó ti kọjá, èmi àti ìyàwó mi ti kọ́ àwọn èèyàn tó lé ní ọgọ́rùn-ún [100] lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Púpọ̀ lára wọn ń sìn báyìí gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, alábòójútó arìnrìn-àjò, àwọn mìíràn sì ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì. Inú wa sì tún dùn pé èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ọmọ wa àti ìdílé wọn ló ń fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà.

Mo Fẹ́ Mọ Ibi Tí “Ìjọba Jèhófà” Wà!

[Àwòrán]

SOE LWIN

WỌ́N BÍ I NÍ 1960

Ó ṢÈRÌBỌMI NÍ 2000

ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ Ẹlẹ́sìn Búdà ni tẹ́lẹ̀, ó kà nípa “Ìjọba Jèhófà,” ó sì fẹ́ lọ síbi tó wà.

◆ NÍGBÀ tí mò ń rìn lọ sí ibi iṣẹ́ ní ìlú Tachileik, tó sún mọ́ ààlà orílẹ̀-èdè Thailand, mo rí àwọn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ mélòó kan tí wọ́n sọ sẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà, mo sì mú wọn. Àwọn ìwé ìròyìn náà sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìbùkún àgbàyanu tá a máa rí gbà lábẹ́ Ìjọba Jèhófà. Nítorí pé ẹlẹ́sìn Búdà ni mí, tí mi ò sì tíì gbọ́ nípa Jèhófà rí, mo rò pé orílẹ̀-èdè kan ní Áfíríkà ló ń jẹ́ “Ìjọba Jèhófà.” Mo wá “Ìjọba Jèhófà” nínú ìwé àwòrán ilẹ̀, àmọ́ mi ò rí i. Mo bi àwọn míì, síbẹ̀ àwọn náà ò mọ̀ ọ́n.

Lẹ́yìn náà, mo wá mọ̀ pé ọ̀dọ́kùnrin kan níbi iṣẹ́ mi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Mo bi í pé, “Ṣé o lè júwe fún mi, ibi tí Ìjọba Jèhófà wà?” Ó yà mí lẹ́nu láti mọ̀ pé ọ̀run ni Ìjọba Jèhófà wà, ó sì máa mú Párádísè wá sí ayé, èyí jọ mi lójú, ó sì múnú mi dùn gan-an. Mo gé irun mi, mi ò jẹ ẹ̀pà betel mọ́, mi ò lo oògùn nílòkulò mọ́, mo sì fi àwọn àṣà ẹ̀sìn Búdà sílẹ̀. Ní báyìí, ó wá ń wù mí ju ti tẹ́lẹ̀ lọ láti gbé lábẹ́ Ìjọba Jèhófà.—Mát. 25:34.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́