ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Kí Ni Ọlọ́run Ń Fẹ́?
    Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
    • Kí Ni Ọlọ́run Ń Fẹ́?

      Ọlọ́run fẹ́ ká máa gbé ní àlàáfíà àti ayọ̀ nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé títí láé!

      Àmọ́, o lè máa wò ó pé, ‘Ǹjẹ́ ìyẹn lè ṣẹlẹ̀ láé?’ Bíbélì sọ pé Ìjọba Ọlọ́run máa mú kó ṣeé ṣe, Ọlọ́run sì fẹ́ kí gbogbo èèyàn mọ̀ nípa Ìjọba yẹn àti ohun tí òun fẹ́ ṣe fún aráyé.​—Sáàmù 37:11, 29; Àìsáyà 9:7.

      Ọlọ́run fẹ́ ká ṣe ara wa láǹfààní.

      Bó ṣe jẹ́ pé bàbá rere máa ń fẹ́ ohun tó dára jù lọ fún àwọn ọmọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe wu Bàbá wa ọ̀run pé ká máa láyọ̀ títí lọ. (Àìsáyà 48:17, 18) Ó ti ṣèlérí pé “ẹni tó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ló máa wà títí láé.”​—1 Jòhánù 2:17.

      Ọlọ́run fẹ́ ká máa rìn ní àwọn ọ̀nà rẹ̀.

      Bíbélì sọ pé Ẹlẹ́dàá wa fẹ́ “kọ́ wa ní àwọn ọ̀nà rẹ̀” ká lè “máa rìn ní àwọn ọ̀nà rẹ̀.” (Àìsáyà 2:2, 3) Ó ti ṣètò ‘àwọn èèyàn kan fún orúkọ rẹ̀,’ kí wọ́n lè máa sọ ohun tó fẹ́ fún àwọn èèyàn kárí ayé.​—Ìṣe 15:14.

      Ọlọ́run ń fẹ́ ká máa sin òun ní ìṣọ̀kan.

      Ìjọsìn mímọ́ Jèhófà kì í pín àwọn èèyàn níyà, ńṣe ló ń mú kí wọ́n wà níṣọ̀kan kí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ ara wọn dénú. (Jòhánù 13:35) Lónìí, àwọn wo ló ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ lọ́kùnrin àti lóbìnrin níbi gbogbo kí wọ́n lè mọ bí wọ́n á ṣe máa sin Ọlọ́run níṣọ̀kan? A fẹ́ kó o ka ìwé yìí kó o lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè náà.

      ṢE ÌWÁDÌÍ SÍ I

      Jẹ́ ká jọ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ṣé o ti bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà? Tí o ò bá tíì bẹ̀rẹ̀, ṣé o fẹ́ ká máa kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Ọ̀fẹ́ ni. Wàá rí i pé ó máa jẹ́ kó o túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run.

      Béèrè ìwé lọ́fẹ̀ẹ́. O lè lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nítòsí rẹ tàbí kó o bá Ẹlẹ́rìí Jèhófà èyíkéyìí sọ̀rọ̀, kó o lè béèrè ìwé tá a kọ ní èdè rẹ tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti lóye Bíbélì.

      Lọ wo ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì kó o lè mọ̀ nípa wa. Lọ wo ìkànnì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. O lè ka Bíbélì àti ọ̀pọ̀ lára àwọn ìwé wa níbẹ̀ ní èdè tó lé ní ọgọ́rùn-ún méje àti àádọ́ta (750), o sì lè tẹ̀ wọ́n jáde.

  • Irú Èèyàn Wo Ni Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
    Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
    • Ẹ̀KỌ́ 1

      Irú Èèyàn Wo Ni Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

      Ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní orílẹ̀-èdè Denmark

      Orílẹ̀-èdè Denmark

      Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní orílẹ̀-èdè Taiwan

      Orílẹ̀-èdè Taiwan

      Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní orílẹ̀-èdè Fẹnẹsúélà

      Orílẹ̀-èdè Fẹnẹsúélà

      Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní orílẹ̀-èdè Íńdíà

      Orílẹ̀-èdè Íńdíà

      Mélòó lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lo mọ̀? Ó ṣeé ṣe kí àwọn kan lára wa máa gbé ní àdúgbò rẹ, ìwọ àtàwọn kan sì lè jọ máa ṣiṣẹ́ tàbí kí ẹ jọ máa lọ sí ilé ìwé. Ó sì lè jẹ́ pé wọ́n ti bá ẹ sọ̀rọ̀ látinú Bíbélì rí. Irú èèyàn wo ni wá, kí nìdí tá a fi máa ń sọ ohun tá a gbà gbọ́ fún àwọn èèyàn?

      Èèyàn bíi tiyín ni wá. Látinú oríṣiríṣi ẹ̀yà àti àwùjọ la ti wá. Ẹ̀sìn míì ni àwọn kan lára wa ń ṣe tẹ́lẹ̀, àwọn kan lára wa ò sì gbà tẹ́lẹ̀ pé Ọlọ́run wà. Àmọ́, ká tó di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, gbogbo wa la fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. (Ìṣe 17:11) A gbà pé òótọ́ ni ẹ̀kọ́ tá a kọ́, fúnra wa la sì pinnu pé Jèhófà Ọlọ́run la máa sìn.

      À ń jàǹfààní látinú ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bíi ti gbogbo èèyàn, àwa náà ní àwọn ìṣòro àti àwọn ibi tá a kù sí. Àmọ́ bá a ṣe ń sapá láti fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò lójoojúmọ́, à ń rí i pé ìgbé ayé wa ń dáa sí i. (Sáàmù 128:1, 2) Ọ̀kan lára ìdí tá a fi ń sọ àwọn ohun rere tá a ti kọ́ látinú Bíbélì fún àwọn èèyàn nìyẹn.

      Àwọn ìlànà Ọlọ́run là ń tẹ̀ lé. Àwọn ìlànà Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì ń ṣe wá láǹfààní, ó ń mú ká bọ̀wọ̀ fún àwọn èèyàn, ó sì ń mú ká jẹ́ olóòótọ́ àti onínúure. Àwọn ìlànà yìí ń mú kí ìlera àwọn èèyàn dáa sí i, ó ń mú kí wọ́n wúlò láwùjọ, ó ń mú kí ìdílé wà ní ìṣọ̀kan, kí wọ́n sì máa hùwà rere. Nítorí a gbà pé “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú,” ìdí nìyẹn tí a fi jẹ́ ìdílé kan ṣoṣo kárí ayé, tí ìgbàgbọ́ wa sì ṣọ̀kan, ìyẹn ló fà á tí a kì í gbé ẹ̀yà kan ga ju òmíì lọ, tí a kì í sì í lọ́wọ́ sí ìṣèlú. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé lẹ́nì kọ̀ọ̀kan a ò yàtọ̀ sí àwọn èèyàn yòókù, àmọ́ lápapọ̀ èèyàn tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ni wá.​—Ìṣe 4:13; 10:34, 35.

      • Ọ̀nà wo ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò fi yàtọ̀ sí àwọn èèyàn yòókù?

      • Àwọn ìlànà wo ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ́ látinú Bíbélì?

  • Kí Nìdí Tí Wọ́n Fi Ń Pè Wá Ní Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
    Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
    • Ẹ̀KỌ́ 2

      Kí Nìdí Tí Wọ́n Fi Ń Pè Wá Ní Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

      Nóà

      Nóà

      Ábúráhámù àti Sérà

      Ábúráhámù àti Sérà

      Mósè

      Mósè

      Jésù Kristi

      Jésù Kristi

      Ọ̀pọ̀ èèyàn rò pé ẹ̀sìn tuntun ni ẹ̀sìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àmọ́, ṣáájú ẹgbẹ̀rún méjì ó lé ọgọ́rùn-ún méje (2,700) ọdún sẹ́yìn ni Bíbélì ti pe àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà ní “ẹlẹ́rìí” rẹ̀. (Àìsáyà 43:10-12) Ṣáájú ọdún 1931, orúkọ tí wọ́n ń pè wá ni àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kí nìdí tí a fi wá ń jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

      Orúkọ náà ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ Ọlọ́run wa. Àwọn ìwé àfọwọ́kọ àtijọ́ fi hàn pé orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà, fara hàn ní ọ̀pọ̀ ẹgbẹ̀rún ìgbà nínú Bíbélì. Nínú ọ̀pọ̀ Bíbélì, wọ́n ti fi orúkọ oyè bí Olúwa tàbí Ọlọ́run rọ́pò orúkọ yìí. Síbẹ̀, nígbà tí Ọlọ́run tòótọ́ fara han Mósè, ó lo orúkọ tó ń jẹ́ gangan, ìyẹn Jèhófà, ó sì sọ pé: “Èyí ni orúkọ mi títí láé.” (Ẹ́kísódù 3:15) Ọ̀nà yìí ni Ọlọ́run gbà fi hàn pé òun yàtọ̀ sí gbogbo àwọn ọlọ́run èké. Inú wa dùn pé wọ́n ń fi orúkọ mímọ́ ti Ọlọ́run pè wá.

      Orúkọ náà ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ iṣẹ́ wa. Ọ̀pọ̀ èèyàn nígbà àtijọ́ fi ẹ̀rí hàn pé àwọn ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà, èyí sì bẹ̀rẹ̀ látọ̀dọ̀ ọkùnrin olóòótọ́ náà Ébẹ́lì. Láti ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún ni àwọn èèyàn bíi Nóà, Ábúráhámù, Sérà, Mósè, Dáfídì àti àwọn míì ti wà lára ọ̀pọ̀ “àwọsánmà àwọn ẹlẹ́rìí” yìí. (Hébérù 11:4–12:1) Bíi ti ẹni tó ń ṣe ẹlẹ́rìí nílé ẹjọ́ fún ẹni tí kò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án, a fẹ́ kí àwọn èèyàn mọ òtítọ́ nípa Ọlọ́run wa.

      À ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. Bíbélì pe Jésù ní ‘ẹlẹ́rìí olóòótọ́ tó ṣeé gbára lé.’ (Ìfihàn 3:14) Jésù fúnra rẹ̀ sọ pé òun ‘jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ orúkọ Ọlọ́rùn’ òun sì ń “jẹ́rìí sí òtítọ́” nípa Ọlọ́run. (Jòhánù 17:26; 18:37) Nítorí náà, àwọn ojúlówó ọmọlẹ́yìn Kristi gbọ́dọ̀ máa jẹ́ orúkọ mọ́ Jèhófà kí wọ́n sì jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ orúkọ náà. Ohun tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe nìyẹn.

      • Kí nìdí tí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fi wá ń jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

      • Ìgbà wo ni Jèhófà ti bẹ̀rẹ̀ sí í ní àwọn ẹlẹ́rìí lórí ilẹ̀ ayé?

      • Ta ni Ẹlẹ́rìí tó ga jù lọ tí Jèhófà ní?

      ṢE ÌWÁDÌÍ SÍ I

      Tó o bá rí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ, gbìyànjú láti mọ̀ wọ́n dáadáa. Bi wọ́n léèrè pé: “Kí nìdí tí wọ́n fi di Ẹlẹ́rìí Jèhófà?”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́