ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Báwo Ni A Ṣe Wá Mọ Òtítọ́ Tí Bíbélì Fi Kọ́ni?
    Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
    • Ẹ̀KỌ́ 3

      Báwo Ni A Ṣe Wá Mọ Òtítọ́ Tí Bíbélì Fi Kọ́ni?

      Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ọdún 1870 sí 1879

      Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ọdún 1870 sí 1879

      Ọkùnrin kan ń ka ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ tí wọ́n kọ́kọ́ tẹ̀ jáde

      Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ tí wọ́n kọ́kọ́ tẹ̀ jáde, ọdún 1879

      Obìnrin kan mú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! dání

      Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ rèé lónìí

      Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé lẹ́yìn tí Kristi bá kú, àwọn olùkọ́ èké máa dìde láàárín àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀, wọ́n á sì sọ òtítọ́ tí Bíbélì kọ́ni dìdàkudà. (Ìṣe 20:29, 30) Ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an nìyẹn nígbà tó yá. Wọ́n da ẹ̀kọ́ Jésù pọ̀ mọ́ ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn àwọn kèfèrí, ayédèrú ẹ̀sìn Kristẹni sì bẹ̀rẹ̀. (2 Tímótì 4:3, 4) Báwo ló ṣe dá wa lójú lóde òní pé a mọ ohun náà gan-an tí Bíbélì fi kọ́ni?

      Àkókò tó lójú Jèhófà láti jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ òtítọ́. Ọlọ́run sọ tẹ́lẹ̀ pé ‘ní àkókò òpin, ìmọ̀ tòótọ́ máa pọ̀ yanturu.’ (Dáníẹ́lì 12:4) Ní ọdún 1870, àwùjọ kékeré kan tó fẹ́ mọ òtítọ́ rí i pé ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì ni kò bá Ìwé Mímọ́ mu. Torí náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í wá bí wọ́n ṣe máa lóye ohun náà gan-an tí Bíbélì fi kọni, Jèhófà sì mú kí wọ́n lóye Ìwé Mímọ́.

      Àwọn ọkùnrin olóòótọ́ fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ọ̀nà tí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n ní ìtara, ìyẹn àwọn tó wà ṣáájú wa gbà kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni àwa náà ń gbà kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ lónìí. Wọ́n máa ń ṣàlàyé ẹ̀kọ́ Bíbélì lọ́kọ̀ọ̀kan. Tí wọ́n bá rí apá kan nínú Bíbélì tó ṣòro láti lóye, wọ́n máa ń wá àwọn ẹsẹ míì tó lè ṣàlàyé rẹ̀ nínú Bíbélì. Tí wọ́n bá ti fohùn ṣọ̀kan lórí ohun tó bá àwọn apá tó kù nínú Ìwé Mímọ́ mu, wọ́n á kọ ọ́ sílẹ̀. Bí wọ́n ṣe ń jẹ́ kí Bíbélì ṣàlàyé ara rẹ̀ yìí ni wọ́n fi wá mọ ohun tó jẹ́ òtítọ́ nípa orúkọ Ọlọ́run àti Ìjọba rẹ̀, ohun tó ní lọ́kàn fún aráyé àti ayé, ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn òkú àti ìrètí pé àwọn òkú máa jíǹde. Ìwádìí tí wọ́n ṣe yìí mú kí wọ́n bọ́ lọ́wọ́ ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ èké àtàwọn àṣà tínú Ọlọ́run kò dùn sí.​—Jòhánù 8:31, 32.

      Nígbà tó di ọdún 1879 àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rí i pé ó ti tó àkókò láti jẹ́ kí àwọn èèyàn níbi gbogbo mọ òtítọ́. Torí náà, lọ́dún yẹn wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ jáde lédè Gẹ̀ẹ́sì, ìyẹn The Watchtower Announcing Jehovah’s Kingdom, a ṣì ń tẹ̀ ẹ́ jáde títí dòní. Ní báyìí, à ń sọ òtítọ́ tí Bíbélì fi kọ́ni fún àwọn èèyàn ní igba ó lé ogójì (240) orílẹ̀-èdè ní èdè tó lé ní ọgọ́rùn-ún méje àti àádọ́ta (750). Ìmọ̀ òtítọ́ kò tíì pọ̀ tó yìí rí!

      • Lẹ́yìn tí Kristi kú, kí ló ṣẹlẹ̀ sí òtítọ́ tí Bíbélì fi kọ́ni?

      • Kí ló ràn wá lọ́wọ́ láti wá mọ òtítọ́ tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi kọ́ni?

  • Kí Nìdí Tí A Fi Ṣe Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun?
    Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
    • Ẹ̀KỌ́ 4

      Kí Nìdí Tí A Fi Ṣe Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun?

      Ẹ̀rọ ìtẹ̀wé àtijọ́
      Ẹ̀dà àkọ́kọ́ Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tí wọ́n mú jáde
      Àwọn èèyàn ń wo Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ní orílẹ̀-èdè Kóńgò (Kinshasa)

      Orílẹ̀-èdè Kóńgò (Kinshasa)

      Wọ́n mú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde ní Orílẹ̀-èdè Rùwáńdà

      Orílẹ̀-èdè Rùwáńdà

      Àjákù ìwé Symmachus níbi tí orúkọ Ọlọ́run ti fara hàn

      Àjákù ìwé Symmachus rèé tó ní Sáàmù 69:31, níbi tí orúkọ Ọlọ́run ti fara hàn, ọgọ́rùn-ún ọdún kẹta tàbí ìkẹrin Sànmánì Kristẹni

      Ọ̀pọ̀ ọdún ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi lo oríṣiríṣi ìtumọ̀ Bíbélì, tí a tẹ̀ wọ́n jáde tí a sì pín wọn káàkiri. Àmọ́ nígbà tó yá, a rí i pé ó yẹ ká ṣe ìtumọ̀ míì tó máa túbọ̀ ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti ní “ìmọ̀ tó péye nípa òtítọ́” bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ kí gbogbo èèyàn ní in. (1 Tímótì 2:3, 4) Torí náà, ní ọdún 1950 a bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde lápá kọ̀ọ̀kan ní èdè tó bóde mu. A ti túmọ̀ rẹ̀ lọ́nà tó péye tí kò sì lábùkù sí èdè tó lé ní àádóje (130).

      A nílò Bíbélì kan tó máa tètè yé àwọn èèyàn. Èdè máa ń yí pa dà, ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ Bíbélì ló sì ṣòro láti lóye torí wọ́n lo àwọn ọ̀rọ̀ tí kò ye àwọn èèyàn tàbí àwọn ọ̀rọ̀ àtijọ́. Bákan náà, a ti ṣàwárí àwọn Ìwé Mímọ́ àtijọ́ tí wọ́n fọwọ́ kọ, èyí tó túbọ̀ péye, tó sì sún mọ́ Bíbélì tí wọ́n kọ níbẹ̀rẹ̀. Èyí ti jẹ́ ká túbọ̀ lóye èdè Hébérù, Árámáíkì àti èdè Gíríìkì tí wọ́n fi kọ Bíbélì.

      A nílò ìtumọ̀ Bíbélì tí kò bomi la ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àwọn atúmọ̀ Bíbélì kò gbọ́dọ̀ yí ohun tó wà nínú Ìwé Mímọ́ tí Ọlọ́run mí sí pa dà, ńṣe ló yẹ kí wọ́n ṣe ìtumọ̀ tí kò lábùkù tó sì bá Bíbélì tí wọ́n kọ níbẹ̀rẹ̀ mu. Àmọ́, èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ìtumọ̀ Bíbélì ni kò lo Jèhófà, tó jẹ́ orúkọ Ọlọ́run.

      A nílò Bíbélì kan tó fi ògo fún Ẹni tó ni ín. (2 Sámúẹ́lì 23:2) Bó ṣe wà nínú àwòrán ìsàlẹ̀ yìí, a ti dá orúkọ náà, Jèhófà pa dà sínú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, bó ṣe wà ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méje (7,000) ìgbà nínú Bíbélì tí wọ́n kọ́kọ́ fọwọ́ kọ. (Sáàmù 83:18) Nítorí a ti fara balẹ̀ ṣe ìwádìí fún ọ̀pọ̀ ọdún ká tó mú Bíbélì yìí jáde, ó dùn-ún kà, ó sì jẹ́ ká mọ èrò Ọlọ́run lọ́nà tó ṣe kedere. Bóyá Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun wà ní èdè rẹ tàbí kò sí, jẹ́ kó mọ́ ẹ lára láti máa ka Ọ̀rọ̀ Jèhófà lójoojúmọ́.​—Jóṣúà 1:8; Sáàmù 1:2, 3.

      • Kí nìdí tá a fi pinnu pé a nílò ìtumọ̀ Bíbélì míì?

      • Kí ló yẹ kí gbogbo ẹni tó bá fẹ́ mọ ìfẹ́ Ọlọ́run máa ṣe lójoojúmọ́?

      ṢE ÌWÁDÌÍ SÍ I

      Ka ọ̀rọ̀ ìṣáájú nínú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, kó o sì dáhùn ìbéèrè yìí: “Kí ni ojúṣe tí ìgbìmọ̀ tó túmọ̀ Bíbélì yìí gbà pé àwọn ní?” Wá fi bí wọ́n ṣe túmọ̀ àwọn ẹsẹ Bíbélì tó tẹ̀ lé e yìí wé ti àwọn ìtumọ̀ Bíbélì míì tó o ní lọ́wọ́: Jẹ́nẹ́sísì 25:29; Àìsáyà 14:23; Mátíù 5:3; 11:12; 1 Kọ́ríńtì 10:24, 25; Fílípì 1:8.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́