-
Kí Lo Máa Gbádùn Láwọn Ìpàdé Wa?Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
-
-
Ẹ̀KỌ́ 5
Kí Lo Máa Gbádùn Láwọn Ìpàdé Wa?
Orílẹ̀-èdè Ajẹntínà
Orílẹ̀-èdè Sierra Leone
Orílẹ̀-èdè Belgium
Orílẹ̀-èdè Malaysia
Ọ̀pọ̀ èèyàn ni kì í lọ sí ilé ìjọsìn mọ́ torí wọn ò rí ìtọ́sọ́nà tàbí ìtùnú tí wọ́n fẹ́ níbẹ̀. Kí wá nìdí tó fi yẹ kó o lọ sí àwọn ìpàdé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà? Kí lo máa rí níbẹ̀?
Wàá láyọ̀ pé o dara pọ̀ mọ́ àwọn èèyàn tó ní ìfẹ́ àti aájò. Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àwọn Kristẹni ṣètò ara wọn sí àwọn ìjọ, wọ́n sì ń ṣe àwọn ìpàdé láti jọ́sìn Ọlọ́run, láti kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ àti láti gbé ara wọn ró. (Hébérù 10:24, 25) Ìfẹ́ gbilẹ̀ gan-an láàárín wọn, wọ́n sì mọ̀ pé àwọn wà láàárín àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́, ìyẹn àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí wọ́n jọ ń sin Ọlọ́run. (2 Tẹsalóníkà 1:3; 3 Jòhánù 14) Àpẹẹrẹ wọn là ń tẹ̀ lé, a sì ń láyọ̀ bíi tiwọn.
Wàá rí àǹfààní tó wà nínú kéèyàn mọ bá a ṣe lè fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò. Àwọn ọkùnrin, obìnrin àtàwọn ọmọdé máa ń pàdé pọ̀ bíi ti ayé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì. Àwọn olùkọ́ tó kúnjú ìwọ̀n máa ń ràn wá lọ́wọ́ láti mọ bí a ṣe lè máa fi ìlànà Bíbélì sílò ní ìgbésí ayé wa. (Diutarónómì 31:12; Nehemáyà 8:8) Gbogbo èèyàn ló lè dá sí ìjíròrò, a sì jọ máa ń kọrin, èyí ń jẹ́ ká lè sọ ìrètí tí àwa Kristẹni ní.—Hébérù 10:23.
Ìgbàgbọ́ rẹ nínú Ọlọ́run á lágbára sí i. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún ọ̀kan lára àwọn ìjọ tó wà nígbà ayé rẹ̀ pé: ‘Àárò yín ń sọ mí, ká lè jọ fún ara wa ní ìṣírí nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa, tiyín àti tèmi.’ (Róòmù 1:11, 12) Bá a ṣe ń pé jọ déédéé pẹ̀lú àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ láwọn ìpàdé wa máa ń mú kí ìgbàgbọ́ wa lágbára, ó sì ń mú ká lè máa gbé ìgbé ayé Kristẹni.
O ò ṣe wá sí ìpàdé wa tó ń bọ̀ kí ìwọ fúnra rẹ lè rí àwọn nǹkan tá a sọ yìí? A máa fi ọ̀yàyà kí ẹ káàbọ̀. Ọ̀fẹ́ ni àwọn ìpàdé wa, a kì í gbé igbá owó.
Àpẹẹrẹ àwọn wo là ń tẹ̀ lé ní àwọn ìpàdé wa?
Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń lọ sí àwọn ìpàdé ìjọ?
-
-
Àǹfààní Wo La Máa Rí Tá A Bá Ń Bá Àwọn Tá A Jọ Jẹ́ Kristẹni Ṣọ̀rẹ́?Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
-
-
Ẹ̀KỌ́ 6
Àǹfààní Wo La Máa Rí Tá A Bá Ń Bá Àwọn Tá A Jọ Jẹ́ Kristẹni Ṣọ̀rẹ́?
Orílẹ̀-èdè Madagásíkà
Orílẹ̀-èdè Norway
Orílẹ̀-èdè Lẹ́bánónì
Orílẹ̀-èdè Ítálì
A máa ń lọ sí àwọn ìpàdé ìjọ déédéé, àní tó bá tiẹ̀ gba pé ká gba àárín igbó kìjikìji kọjá tàbí ká fara da ojú ọjọ́ tí kò bára dé. Láìka àwọn ìṣòro tá a ní sí àti àárẹ̀ lẹ́yìn iṣẹ́ ojoojúmọ́, kí nìdí táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi máa ń rí i pé a wà pẹ̀lú àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́?
Ó ń gbé wa ró. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ nípa àwọn tá a jọ ń pàdé nínú ìjọ, ó sọ pé, ‘Ẹ jẹ́ ká gba ti ara wa rò.’ (Hébérù 10:24) Ọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí “ká ronú dáadáa nípa,” ìyẹn ni pé ká mọ ara wa. Torí náà, ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì yìí ń rọ̀ wá pé ká jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àwọn ẹlòmíì jẹ wá lọ́kàn. Bá a ṣe túbọ̀ ń mọ àwọn ìdílé míì tá a jọ jẹ́ Kristẹni, a máa rí i pé àwọn kan lára wọn ti borí àwọn ìṣòro tó jọ tiwa, wọ́n sì lè ràn wá lọ́wọ́ láti borí tiwa.
Ó ń jẹ́ ká ní àwọn ọ̀rẹ́ àtàtà. Ní àwọn ìpàdé wa, a máa ń pé jọ pẹ̀lú àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa, wọn kì í ṣe ẹni tá a mọ̀ lásán, ọ̀rẹ́ àtàtà ni wọ́n jẹ́. Láwọn ìgbà míì, a jọ máa ń ṣe eré ìnàjú tó dáa. Àǹfààní wo ni irú àjọṣe bẹ́ẹ̀ máa ń ṣe wá? Ó ń jẹ́ ká túbọ̀ mọyì ara wa, ó sì ń jẹ́ kí ìfẹ́ tó wà láàárín wa pọ̀ sí i. Tí àwọn ọ̀rẹ́ wa yìí bá wá níṣòro, a máa ń tètè ràn wọ́n lọ́wọ́ torí pé wọ́n ti di ọ̀rẹ́ wa àtàtà. (Òwe 17:17) Tá a bá ń fi gbogbo àwọn ará ìjọ ṣe ọ̀rẹ́, à ń fi hàn pé à ń “ṣìkẹ́ ara” wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan.—1 Kọ́ríńtì 12:25, 26.
A rọ̀ ẹ́ pé kó o mú àwọn tó ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run lọ́rẹ̀ẹ́. Wàá rí irú ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀ láàárín àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Jọ̀ọ́, má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun dí ẹ lọ́wọ́ láti dara pọ̀ mọ́ wa.
Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń wà pẹ̀lú àwọn ará ní àwọn ìpàdé wa?
Ìgbà wo lo máa bẹ̀rẹ̀ sí í wá sí ìpàdé ìjọ wa?
-
-
Kí Là Ń Kọ́ Láwọn Ìpàdé Wa?Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
-
-
Ẹ̀KỌ́ 7
Kí Là Ń Kọ́ Láwọn Ìpàdé Wa?
Orílẹ̀-èdè New Zealand
Orílẹ̀-èdè Japan
Orílẹ̀-èdè Uganda
Orílẹ̀-èdè Lithuania
Nígbà tí ẹ̀sìn Kristẹni bẹ̀rẹ̀, ohun tí wọ́n máa ń ṣe ní àwọn ìpàdé ìjọ ni pé wọ́n máa ń kọrin, wọ́n máa ń gbàdúrà, wọ́n ń ka Ìwé Mímọ́, wọ́n sì ń jíròrò wọn, wọn ò ní àwọn àṣà ìkọ̀kọ̀ tí wọ́n ń tẹ̀ lé nínú ìsìn wọn. (1 Kọ́ríńtì 14:26) Ohun kan náà là ń ṣe láwọn ìpàdé wa.
Ẹ̀kọ́ tó wúlò látinú Bíbélì. Láwọn òpin ọ̀sẹ̀, ìjọ kọ̀ọ̀kan máa ń pé jọ láti gbọ́ Àsọyé Bíbélì fún ọgbọ̀n (30) ìṣẹ́jú, ó máa ń dá lórí bí Ìwé Mímọ́ ṣe lè mú kí ìgbésí ayé wa dára, ó sì máa ń jẹ́ ká mọ ìtumọ̀ àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ lásìkò yìí. Wọ́n máa ń rọ gbogbo wa pé ká gbé Bíbélì wa ká sì máa fojú bá ibi tí wọ́n ń kà lọ. Lẹ́yìn àsọyé náà, a máa ń ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ “Ilé Ìṣọ́” fún wákàtí kan, a sì máa ń rọ gbogbo ará ìjọ pé kí wọ́n dá sí àpilẹ̀kọ tá à ń jíròrò lọ́sẹ̀ yẹn nínú Ilé Ìṣọ́ tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́. Ìjíròrò yìí máa ń jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì nínú ìgbé ayé wa. Àpilẹ̀kọ kan náà la máa ń kẹ́kọ̀ọ́ ní àwọn ìjọ wa tó ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́fà (110,000) lọ kárí ayé.
Wọ́n ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa kọ́ni lọ́nà tó sunwọ̀n sí i. A tún máa ń pé jọ ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan láàárín ọ̀sẹ̀ fún ìpàdé alápá mẹ́ta tí à ń pè ní Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni. Ohun tó wà nínú ìwé ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni la máa ń tẹ̀ lé. Apá àkọ́kọ́ lára ìpàdé náà ni Àwọn Ìṣúra Inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó máa ń jẹ́ ká túbọ̀ lóye apá kan nínú Bíbélì táwọn ará ti kà ṣáájú. Lẹ́yìn ìyẹn ni Máa Lo Ara Rẹ Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù níbi tí a ti máa ń rí àpẹẹrẹ bá a ṣe lè bá àwọn èèyàn jíròrò látinú Bíbélì. Agbani-nímọ̀ràn kan wà tó máa ń kíyè sí ọ̀rọ̀ wa kó lè ràn wá lọ́wọ́ láti sunwọ̀n sí i nínú bá a ṣe ń kàwé àti bá a ṣe ń sọ̀rọ̀. (1 Tímótì 4:13) Apá tó gbẹ̀yìn nínú ìpàdé náà ni Máa Hùwà Tó Yẹ Kristẹni níbi tí a ti máa ń jíròrò bá a ṣe lè fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò nínú ìgbésí ayé wa ojoojúmọ́. Ó tún máa ń ní ìbéèrè àti ìdáhùn tó máa ń jẹ́ ká túbọ̀ lóye Bíbélì.
Tó o bá wá sí àwọn ìpàdé wa, ó dájú pé àwọn ẹ̀kọ́ àtàtà tó o máa kọ́ látinú Bíbélì máa wú ẹ lórí gan-an.—Àìsáyà 54:13.
Kí lo máa kọ́ láwọn ìpàdé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
Èwo nínú àwọn ìpàdé wa ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ló wù ẹ́ láti lọ?
-