ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àwọn Ilé Ẹ̀kọ́ Tó Wà fún Àwọn Aṣáájú-Ọ̀nà
    Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
    • Ẹ̀KỌ́ 14

      Àwọn Ilé Ẹ̀kọ́ Tó Wà fún Àwọn Aṣáájú-Ọ̀nà

      Àwọn aṣáájú-ọ̀nà ń wàásù

      Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà

      Àwọn ọmọ Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì
      Àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ń múra sílẹ̀ fún iṣẹ́ míṣọ́nnárì

      Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, ní Patterson, New York

      Tọkọtaya míṣọ́nnárì kan ń wàásù lórílẹ̀-èdè Panama

      Orílẹ̀-èdè Panama

      Ọjọ́ pẹ́ tí ètò ìdálẹ́kọ̀ọ́ ti jẹ́ apá pàtàkì nínú ìjọsìn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ètò Ọlọ́run ṣètò ilé ẹ̀kọ́ lákànṣe fún àwọn tó ń fi ọ̀pọ̀ àkókò wàásù Ìjọba Ọlọ́run kí wọ́n lè ‘ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn láìkù síbì kan.’​—2 Tímótì 4:5.

      Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Aṣáájú-Ọ̀nà. Tó bá ti pé ọdún kan tí ẹnì kan bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, ó máa lọ sí ilé ẹ̀kọ́ ọlọ́jọ́ mẹ́fà tó ṣeé ṣe kó wáyé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba kan tí kò jìnnà sí agbègbè rẹ̀. Ilé ẹ̀kọ́ náà máa jẹ́ kó túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, á jẹ́ kó túbọ̀ mọ bí a ṣe ń wàásù, kó sì máa fi òtítọ́ bá iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ lọ.

      Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere. A dá ilé ẹ̀kọ́ olóṣù méjì yìí sílẹ̀ láti dá àwọn aṣáájú-ọ̀nà tó nírìírí lẹ́kọ̀ọ́, àwọn tó ṣe tán láti fi agbègbè wọn sílẹ̀, kí wọ́n lè lọ sìn ní ibikíbi tí ètò Ọlọ́run bá ti nílò wọn. Ńṣe ló dà bí ìgbà tí wọ́n ń sọ pé, “Èmi nìyí! Rán mi!” Wọ́n fìwà jọ Ajíhìnrere tó ga jù lọ tó gbé ayé rí, ìyẹn Jésù Kristi. (Àìsáyà 6:8; Jòhánù 7:29) Wọ́n lè ní láti fi àwọn nǹkan kan du ara wọn torí pé ibi tí wọ́n wà jìnnà sí ìlú wọn. Àṣà ìbílẹ̀ ibi tí wọ́n kó lọ lè yàtọ̀ pátápátá, títí kan ojú ọjọ́ àti oúnjẹ. Ó sì lè pọn dandan pé kí wọ́n kọ́ èdè tuntun. Ilé ẹ̀kọ́ yìí máa jẹ́ kí àwọn àpọ́n, àwọn obìnrin tí kò lọ́kọ àti àwọn tọkọtaya tí wọ́n jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàlélógún (23) sí márùndínláàádọ́rin (65) ní àwọn ìwà tó yẹ Kristẹni tó máa wúlò lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wọn. Wọ́n á tún kọ́ àwọn ohun táá jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ wúlò fún Jèhófà àti ètò rẹ̀.

      Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Ní èdè Hébérù, “Gílíádì” túmọ̀ sí “Òkìtì Ẹ̀rí.” Láti ọdún 1943 tí a ti dá ilé ẹ̀kọ́ yìí sílẹ̀, a ti rán àwọn míṣọ́nnárì tó ju ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ (8,000) tí wọ́n gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ láti lọ máa wàásù káàkiri “gbogbo ayé,” wọ́n sì ń ṣe àṣeyọrí lọ́pọ̀lọpọ̀. (Ìṣe 13:47) Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí àwọn míṣọ́nnárì kọ́kọ́ dé orílẹ̀-èdè Peru, kò sí ìjọ kankan níbẹ̀. Àmọ́ ní báyìí, ìjọ tó wà níbẹ̀ ti lé ní ẹgbẹ̀rún (1,000). Nígbà táwọn míṣọ́nnárì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù ní ilẹ̀ Japan, àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà níbẹ̀ kò tó mẹ́wàá. Àmọ́ ní báyìí wọ́n ti lé ní ọ̀kẹ́ mẹ́wàá (200,000). Oṣù márùn-ún ni wọ́n fi ń lọ sí Ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì, wọ́n sì máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jinlẹ̀ níbẹ̀. Àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, àwọn míṣọ́nnárì tó wà ní pápá, àwọn tó ń sìn ní ẹ̀ka ọ́fíìsì tàbí àwọn alábòójútó àyíká ló máa ń lọ sí ilé ẹ̀kọ́ yìí kí wọ́n lè gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó jinlẹ̀ táá jẹ́ kí wọ́n lè ṣèrànwọ́ láti mú kí iṣẹ́ ìwàásù fẹsẹ̀ múlẹ̀, kó sì gbòòrò sí i kárí ayé.

      • Kí nìdí tá a fi ṣètò Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Aṣáájú-Ọ̀nà?

      • Àwọn wo ló lè lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere?

  • Báwo Ni Àwọn Alàgbà Ṣe Ń Ran Ìjọ Lọ́wọ́?
    Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
    • Ẹ̀KỌ́ 15

      Báwo Ni Àwọn Alàgbà Ṣe Ń Ran Ìjọ Lọ́wọ́?

      Alàgbà kan ń bá àwọn ará ìjọ sọ̀rọ̀

      Orílẹ̀-èdè Finland

      Alàgbà ń kọ́ni nínú ìjọ

      Wọ́n ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́

      Àwọn alàgbà ń fún àwọn ará ìjọ níṣìírí

      Wọ́n ń ṣe olùṣọ́ àgùntàn

      Alàgbà kan ń wàásù

      Wọ́n ń wàásù

      A kò ní àwọn àlùfáà tó ń gba owó nínú ètò wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, a yan àwọn alábòójútó tó kúnjú ìwọ̀n sípò “láti ṣe olùṣọ́ àgùntàn ìjọ Ọlọ́run” bíi ti ìgbà tí ìjọ Kristẹni bẹ̀rẹ̀. (Ìṣe 20:28) Àwọn alàgbà yìí jẹ́ ẹni tó sún mọ́ Ọlọ́run gan-an, wọ́n ń mú ipò iwájú nínú ìjọ, wọ́n sì ń ṣe olùṣọ́ àgùntàn, ‘kì í ṣe tipátipá àmọ́ tinútinú níwájú Ọlọ́run; kì í ṣe nítorí èrè tí kò tọ́, àmọ́ wọ́n ń fi ìtara ṣe é látọkàn wá.’ (1 Pétérù 5:1-3) Àwọn iṣẹ́ wo ni wọ́n ń ṣe nítorí wa?

      Wọ́n ń bójú tó wa, wọ́n sì ń dáàbò bò wá. Àwọn alàgbà ń tọ́ wa sọ́nà, wọ́n sì ń mú kí ìjọ túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run. Àwọn alàgbà mọ̀ pé iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé àwọn lọ́wọ́ ṣe pàtàkì, torí náà wọn kì í jọ̀gá lé àwọn èèyàn Ọlọ́run lórí, kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ń mú kí àlàáfíà àti ayọ̀ wa pọ̀ sí i. (2 Kọ́ríńtì 1:24) Bí olùṣọ́ àgùntàn kan ṣe ń tọ́jú àwọn àgùntàn rẹ lọ́kọ̀ọ̀kan, bẹ́ẹ̀ ni àwọn alàgbà ṣe ń sapá láti mọ gbogbo ará ìjọ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan.​—Òwe 27:23.

      Wọ́n ń kọ́ wa bí a ṣe lè ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, àwọn alàgbà máa ń darí àwọn ìpàdé ìjọ láti mú kí ìgbàgbọ́ wa lágbára sí i. (Ìṣe 15:32) Àwọn ọkùnrin tó ń sin Ọlọ́run tọkàntọkàn yìí tún máa ń mú ipò iwájú nínú iṣẹ́ ìwàásù, wọ́n ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú wa lóde ẹ̀rí, wọ́n sì ń dá wa lẹ́kọ̀ọ́ nínú gbogbo ọ̀nà tí à ń gbà wàásù.

      Wọ́n ń fún wa ní ìṣírí lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Nítorí kí wọ́n lè ràn wá lọ́wọ́ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan láti túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run, àwọn alàgbà máa ń bẹ̀ wá wò ní ilé wa tàbí ní Gbọ̀ngàn Ìjọba láti fi Ìwé Mímọ́ tù wá nínú, kí wọ́n sì ràn wá lọ́wọ́.​—Jémíìsì 5:14, 15.

      Yàtọ̀ sí iṣẹ́ wọn nínú ìjọ, ọ̀pọ̀ àwọn alàgbà tún ní iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ àti ojúṣe nínú ìdílé tó ń gba àkókò àti àfiyèsí wọn. Ó yẹ ká máa bọ̀wọ̀ fún àwọn arákùnrin wa tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ kára yìí.​—1 Tẹsalóníkà 5:12, 13.

      • Kí ni iṣẹ́ àwọn alàgbà ìjọ?

      • Àwọn ọ̀nà wo ni àwọn alàgbà ń gbà fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan?

      ṢE ÌWÁDÌÍ SÍ I

      Ta ló kúnjú ìwọ̀n láti sìn nínú ìjọ? O lè ka ohun tí Ìwé Mímọ́ béèrè lọ́wọ́ àwọn tó fẹ́ di alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní 1 Tímótì 3:1-10, 12 àti Títù 1:5-9.

  • Kí Ni Ojúṣe Àwọn Ìránṣẹ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́?
    Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
    • Ẹ̀KỌ́ 16

      Kí Ni Ojúṣe Àwọn Ìránṣẹ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́?

      Ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan ń bójú tó ìwé ìròyìn

      Orílẹ̀-èdè Myanmar

      Ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan ń sọ àsọyé

      Nínú ìpàdé ìjọ

      Ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan ń darí ìpàdé

      Àwùjọ àwọn tó fẹ́ lọ wàásù

      Ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan ń tún Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣe

      Wọ́n ń tún Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣe

      Bíbélì sọ pé àwùjọ méjì ni àwọn ọkùnrin tó ń bójú tó àwọn iṣẹ́ nínú ìjọ Kristẹni pín sí, ìyẹn sì ni “àwọn alábòójútó àti àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́.” (Fílípì 1:1) Àwọn alábòójútó àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó wà ní ìjọ kọ̀ọ̀kan máa ń tó bíi mélòó kan. Àwọn iṣẹ́ tó ń ṣe wá láǹfààní wo ni àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ń ṣe?

      Wọ́n ń ran ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà lọ́wọ́. Àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ jẹ́ àwọn ọkùnrin tó ń fi ọwọ́ pàtàkì mú ìjọsìn Ọlọ́run, wọ́n ṣeé fọkàn tán, wọ́n sì máa ń fara balẹ̀ ṣe nǹkan, àwọn kan lára wọn jẹ́ ọ̀dọ́, àwọn míì sì jẹ́ àgbà. Wọ́n ń bójú tó àwọn iṣẹ́ tó jẹ mọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba àti àwọn iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ míì tó ṣe pàtàkì àmọ́ tí kì í ṣe iṣẹ́ àbójútó ìjọ. Èyí jẹ́ kí àwọn alàgbà lè gbájú mọ́ iṣẹ́ kíkọ́ni àti ṣíṣe olùṣọ́ àgùntàn.

      Wọ́n ń ṣe àwọn iṣẹ́ tó ń ṣeni láǹfààní. A máa ń yan àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan pé kí wọ́n jẹ́ olùtọ́jú èrò, kí wọ́n máa kí àwọn tó bá wá sí ìpàdé káàbọ̀. Àwọn míì máa ń bójú tó ẹ̀rọ tó ń gbé ohùn sáfẹ́fẹ́, ìwé ìròyìn tàbí àkọsílẹ̀ ìnáwó ìjọ, àwọn kan sì máa ń fún àwọn ará ìjọ ní ibi tí wọ́n á ti wàásù. Wọ́n tún máa ń ṣèrànwọ́ láti tún Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣe. Àwọn alàgbà lè ní kí wọ́n ran àwọn àgbàlagbà lọ́wọ́. Iṣẹ́ èyíkéyìí tí wọ́n bá fún àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ pé kí wọ́n ṣe, wọ́n máa ń ṣe é tinútinú, èyí sì ń mú kí gbogbo èèyàn bọ̀wọ̀ fún wọn.​—1 Tímótì 3:13.

      Wọ́n ń fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni. Àwọn ìwà rere tó yẹ Kristẹni tí àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní ló mú ká yàn wọ́n sípò. Tí wọ́n bá ṣiṣẹ́ ní ìpàdé, ó máa ń mú kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára. Bí wọ́n ṣe ń mú ipò iwájú lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ń jẹ́ kí ìtara wa pọ̀ sí i. Bí wọ́n ṣe ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn alàgbà ń mú kí ayọ̀ àti ìṣọ̀kan gbilẹ̀. (Éfésù 4:16) Tó bá yá, àwọn náà lè kúnjú ìwọ̀n láti di alàgbà.

      • Àwọn wo là ń pè ní ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́?

      • Kí làwọn ìránṣẹ́ máa ń ṣe láti mú kí nǹkan máa lọ déédéé nínú ìjọ?

      ṢE ÌWÁDÌÍ SÍ I

      Ní gbogbo ìgbà tó o bá lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba, gbìyànjú láti mọ alàgbà kan tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan títí wàá fi mọ gbogbo wọn àti ìdílé wọn.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́