ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Báwo La Ṣe Ń Kọ Àwọn Ìwé Wa, Tí A sì Ń Túmọ̀ Wọn?
    Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
    • Ẹ̀KỌ́ 23

      Báwo La Ṣe Ń Kọ Àwọn Ìwé Wa, Tí A sì Ń Túmọ̀ Wọn?

      Ẹnì kan tó ń ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Ìwé Kíkọ ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà

      Ẹ̀ka Ìwé Kíkọ ní Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà

      Àwọn atúmọ̀ èdè ní orílẹ̀-èdè South Korea

      Orílẹ̀-èdè South Korea

      Ọkùnrin ará ilẹ̀ Àméníà kan mú ìwé tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà túmọ̀ dání

      Orílẹ̀-èdè Àméníà

      Ọmọbìnrin ilẹ̀ Bùrúńdì yìí mú ìwé kan tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà túmọ̀ dání

      Orílẹ̀-èdè Bùrúńdì

      Obìnrin ará ilẹ̀ Sri Lanka yìí mú àwọn ìtẹ̀jáde tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà túmọ̀ dání

      Orílẹ̀-èdè Sri Lanka

      Ká lè sọ “ìhìn rere” náà fún “gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n àti èèyàn,” èdè tó lé ní ọgọ́rùn-ún méje àti àádọ́ta (750) la fi ń tẹ ìwé jáde. (Ìfihàn 14:6) Báwo la ṣe ń ṣe iṣẹ́ bàǹtàbanta yìí? À ń lo àwọn òǹkọ̀wé wa tí wọ́n wà káàkiri ayé àti àwọn atúmọ̀ èdè tó ń fi tọkàn tara ṣiṣẹ́, gbogbo wọn pátá sì jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

      Èdè Gẹ̀ẹ́sì la fi ń kọ àwọn ìwé wa ká tó tú u sí àwọn èdè míì. Ìgbìmọ̀ Olùdarí ló ń bójú tó Ẹ̀ka Ìwé Kíkọ ní orílé-iṣẹ́ wa lágbàáyé. Ẹ̀ka yìí ló ń ṣètò iṣẹ́ àwọn òǹkọ̀wé tó wà ní orílé-iṣẹ́ wa àtàwọn tó wà láwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa kan. Àwọn òǹkọ̀wé wa wá láti àwọn ibi tó yàtọ̀ síra, èyí ń jẹ́ ká lè sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹ̀kọ́ tó wúlò fún àwọn tí àṣà ìbílẹ̀ wọn yàtọ̀ síra, ó sì ń jẹ́ kí àwọn èèyàn láti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè nífẹ̀ẹ́ sí àwọn ohun tí à ń gbé jáde.

      A máa ń fi ohun tá a kọ ránṣẹ́ sí àwọn atúmọ̀ èdè. Lẹ́yìn tá a bá ṣàtúnṣe sí ohun tí àwọn òǹkọ̀wé wa kọ, tá a sì fọwọ́ sí i, a máa ń fi ránṣẹ́ lórí kọ̀ǹpútà sí àwọn atúmọ̀ èdè káàkiri ayé, kí wọ́n lè túmọ̀ rẹ̀, kí wọ́n yẹ̀ ẹ́ wò dáadáa, kí wọ́n sì rí i pé ó dùn-ún kà lédè wọn. Wọ́n máa ń rí i dájú pé àwọn lo “àwọn ọ̀rọ̀ tó péye tó sì jẹ́ òtítọ́” kí wọ́n lè gbé ìtumọ̀ ohun tí a sọ lédè Gẹ̀ẹ́sì yọ dáadáa ní èdè ìbílẹ̀ wọn.​—Oníwàásù 12:10.

      Kọ̀ǹpútà ń mú kí iṣẹ́ wọn yára kánkán. A ò lè fi kọ̀ǹpútà rọ́pò àwọn òǹkọ̀wé àtàwọn atúmọ̀ èdè. Àmọ́, iṣẹ́ wọn máa ń yá tí wọ́n bá lo àwọn ìwé atúmọ̀ èdè tó wà lórí kọ̀ǹpútà, àwọn ètò orí kọ̀ǹpútà tó wà fún èdè wọn àtàwọn ohun tí wọ́n lè fi ṣe ìwádìí. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ètò orí kọ̀ǹpútà kan tá a pè ní Multilanguage Electronic Publishing System (ìyẹn MEPS) tó máa jẹ́ ká lè tẹ ọ̀rọ̀ ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún èdè, ká fi àwòrán sí i, ká sì ṣètò rẹ̀ bó ṣe máa wà lórí ìwé.

      Kí nìdí tá a fi ń ṣe gbogbo iṣẹ́ yìí, kódà láwọn èdè tó jẹ́ pé àwọn tó ń sọ ọ́ kò ju ẹgbẹ̀rún mélòó kan lọ? Ìdí ni pé ó jẹ́ ìfẹ́ Jèhófà pé “ká gba onírúurú èèyàn là, kí wọ́n sì ní ìmọ̀ tó péye nípa òtítọ́.”​—1 Tímótì 2:​3, 4.

      • Báwo la ṣe ń kọ àwọn ìwé wa?

      • Kí nìdí tá a fi ń túmọ̀ àwọn ìwé wa sí ọ̀pọ̀ èdè?

  • Báwo La Ṣe Ń Rí Owó fún Iṣẹ́ Wa Kárí Ayé?
    Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
    • Ẹ̀KỌ́ 24

      Báwo La Ṣe Ń Rí Owó fún Iṣẹ́ Wa Kárí Ayé?

      Ẹnì kan ń ṣe ọrẹ àtinúwá
      Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń wàásù fún ẹnì kan

      Orílẹ̀-èdè Nepal

      Àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn láti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba ní Orílẹ̀-èdè Tógò

      Orílẹ̀-èdè Tógò

      Àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn láti ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ọ́fí ìsì wa tó wà nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì

      Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì

      Ètò àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù Bíbélì àtàwọn ìwé míì lọ́dọọdún, a sì ń pín wọn fún àwọn èèyàn láì díye lé e. À ń kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba àtàwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì, a sì ń tún wọn ṣe. À ń ṣètìlẹ́yìn fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì àtàwọn míṣọ́nnárì, a sì ń ṣèrànwọ́ nígbà àjálù. Nítorí náà, o lè máa wò ó pé, ‘Ibo la ti ń rówó ṣe gbogbo àwọn nǹkan yìí?’

      A kì í san ìdámẹ́wàá, a kì í bu owó fúnni, a kì í sì í gbégbá ọrẹ. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé owó kékeré kọ́ là ń ná sórí iṣẹ́ ìwàásù wa, a kì í tọrọ owó. Ní ohun tó lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn, ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ sọ nínú ẹ̀dà kejì tó jáde pé, a gbà pé Jèhófà ni alátìlẹyìn wa àti pé a “kò ní tọrọ ohunkóhun bẹ́ẹ̀ ni [a] kò ní bẹ̀bẹ̀ láé pé káwọn èèyàn wá ṣètìlẹ́yìn,” a ò sì tíì ṣe bẹ́ẹ̀!​—Mátíù 10:8.

      Ọrẹ àtinúwá la fi ń ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ wa. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló mọyì iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí à ń ṣe, wọ́n sì máa ń fi ọrẹ ṣètìlẹ́yìn. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń dùn láti fi àkókò wọn, agbára wọn, owó wọn àtàwọn nǹkan míì ṣètìlẹ́yìn fún ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run kárí ayé. (1 Kíróníkà 29:9) Àwọn àpótí téèyàn lè fi ọrẹ sí wà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba àti àwọn àpéjọ wa, àwọn tó bá fẹ́ fi ọrẹ síbẹ̀ lè ṣe bẹ́ẹ̀. Bákan náà, èèyàn lè ṣètọrẹ lórí ìkànnì wa, jw.org/yo. Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn tó ń fi owó ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ wa ni kò fi bẹ́ẹ̀ ní lọ́wọ́, bíi ti opó aláìní tí Jésù sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa, tó fi ẹyọ owó kékeré méjì sínú àpótí ìṣúra ní tẹ́ńpìlì. (Lúùkù 21:​1-4) Nítorí náà, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè máa “ya ohun kan sọ́tọ̀” déédéé láti fi ṣètọrẹ “gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu nínú ọkàn rẹ̀.”​—1 Kọ́ríńtì 16:2; 2 Kọ́ríńtì 9:7.

      Ó dá wa lójú pé Jèhófà á máa mú kí àwọn tí wọ́n fẹ́ ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run ‘fi àwọn ohun ìní wọn tó níye lórí bọlá fún òun’ kí ìfẹ́ rẹ̀ lè ṣẹ.​—Òwe 3:9.

      • Kí ló mú kí ètò wa yàtọ̀ sí àwọn ẹ̀sìn míì?

      • Báwo la ṣe ń lo ọrẹ àtinúwá tí àwọn èèyàn fi ń ṣètìlẹ́yìn?

  • Kí Nìdí Tá A Fi Ń Kọ́ Àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba, Báwo La sì Ṣe Ń Kọ́ Wọn?
    Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
    • Ẹ̀KỌ́ 25

      Kí Nìdí Tá A Fi Ń Kọ́ Àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba, Báwo La sì Ṣe Ń Kọ́ Wọn?

      Àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn fún iṣẹ́ ìkọ́lé ní orílẹ̀-èdè Bolivia

      Orílẹ̀-èdè Bolivia

      Gbọ̀ngàn Ìjọba kan ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà kí wọ́n tó tún un ṣe
      Gbọ̀ngàn Ìjọba kan ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nígbà tí wọ́n tún un ṣe tán

      Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, bó ṣe rí tẹ́lẹ̀ àti bó ṣe rí báyìí

      Nígbà iṣẹ́ ìkọ́lé kan ní orílẹ̀-èdè Tahiti

      Orílẹ̀-èdè Tahiti

      Bí orúkọ Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣe fi hàn, ohun tí à ń jíròrò níbẹ̀ ni ẹ̀kọ́ pàtàkì látinú Bíbélì nípa Ìjọba Ọlọ́run, èyí sì ni ẹ̀kọ́ Jésù dá lé.​—Lúùkù 8:1.

      Wọ́n jẹ́ ibi tá a ti ń jọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́ ní àdúgbò wa. A máa ń ṣètò iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run láwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wa. (Mátíù 24:14) Àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba máa ń tóbi ju ara wọn lọ, wọ́n yàtọ̀ síra, wọ́n sì máa ń mọ níwọ̀n. Ìjọ tó ń lo ọ̀pọ̀ Gbọ̀ngàn Ìjọba máa ń ju ẹyọ kan lọ. Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, a ti kọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún Gbọ̀ngàn Ìjọba (tá a bá pín in lọ́gbọọgba, márùn-ún là ń kọ́ lójúmọ́) ká lè rí àyè fún àwọn ìjọ wa tó ń pọ̀ sí i. Kí ló mú kí èyí ṣeé ṣe?​—Mátíù 19:26.

      Ọrẹ tí gbogbo wa ń mú wá la fi ń kọ́ wọn. A máa ń fi ọrẹ yìí ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa kí wọ́n lè fi owó ránṣẹ́ sí àwọn ìjọ tó fẹ́ kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí tí wọ́n fẹ́ tún un ṣe.

      Onírúurú èèyàn tó yọ̀ǹda ara wọn láìgbowó ló máa ń kọ́ ọ. Ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, a ti ṣètò Ẹgbẹ́ Àwọn Tí Ń Kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba. Àwùjọ àwọn tó ń kọ́lé àtàwọn tó yọ̀ǹda ara wọn máa ń lọ láti ìjọ kan sí òmíì, kódà wọ́n ń lọ sí àwọn ibi tó jìnnà ní orílẹ̀-èdè kan náà, kí wọ́n lè ran àwọn ìjọ lọ́wọ́ láti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn. Ní àwọn ilẹ̀ míì, àwọn arákùnrin tí wọ́n kọ́ṣẹ́ mọṣẹ́ máa ń bójú tó kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba àti ṣíṣe àtúnṣe sí àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà lágbègbè kan. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ máa ń yọ̀ǹda ara wọn láwọn ibi tá a ti ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba, àwọn ará ìjọ tó máa lo gbọ̀ngàn náà ló máa ń pọ̀ jù lára àwọn tó ń ṣiṣẹ́ náà. Ẹ̀mí Jèhófà àti iṣẹ́ àṣekára táwọn èèyàn rẹ̀ ṣe tinútinú ló ń mú kí gbogbo èyí ṣeé ṣe.​—Sáàmù 127:1; Kólósè 3:23.

      • Kí nìdí tá a fi ń pe ilé ìjọsìn wa ní Gbọ̀ngàn Ìjọba?

      • Kí ló mú kó ṣeé ṣe fún wa láti kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba káàkiri ayé?

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́