ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Kí La Lè Ṣe Láti Máa Tọ́jú Gbọ̀ngàn Ìjọba Wa?
    Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
    • Ẹ̀KỌ́ 26

      Kí La Lè Ṣe Láti Máa Tọ́jú Gbọ̀ngàn Ìjọba Wa?

      Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tọ́jú Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn ní orílẹ̀-èdè Estonia

      Orílẹ̀-èdè Estonia

      Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tọ́jú Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn ní orílẹ̀-èdè Sìǹbábúwè

      Orílẹ̀-èdè Sìǹbábúwè

      Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan ń tún nǹkan ṣe ní Gbọ̀ngàn Ìjọba lórílẹ̀-èdè Mòǹgólíà

      Orílẹ̀-èdè Mòǹgólíà

      Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan ń kun Gbọ̀ngàn Ìjọba lórílẹ̀-èdè Puerto Rico

      Orílẹ̀-èdè Puerto Rico

      Orúkọ mímọ́ Ọlọ́run la fi ń pe gbogbo Gbọ̀ngàn Ìjọba àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nítorí náà, a gbà pé àǹfààní ló jẹ́ láti máa mú kí ilé yìí wà ní mímọ́ tónítóní, kó dùn-ún wò, ká sì máa tún un ṣe. Èyí jẹ́ apá pàtàkì lára ìjọsìn mímọ́ wa. Gbogbo wa la lè kópa nínú iṣẹ́ yìí.

      Yọ̀ǹda ara rẹ láti ṣe ìmọ́tótó lẹ́yìn ìpàdé. Àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin máa ń fayọ̀ ṣe iṣẹ́ ìmọ́tótó pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ lẹ́yìn ìpàdé, kí Gbọ̀ngàn Ìjọba lè wà ní mímọ́ tónítóní. Wọ́n sì tún máa ń ṣe ìmọ́tótó tó pọ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan ló máa ń ṣe kòkáárí iṣẹ́ náà, ó sábà máa ń wo àkọsílẹ̀ ọ̀kọ̀ọ̀kan ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe. Ẹnì kọ̀ọ̀kan máa ń yọ̀ǹda ara rẹ̀ láti ṣe àwọn iṣẹ́ tó bá wà, irú bíi gbígbálẹ̀, fífi omi tàbí ẹ̀rọ fọ ilẹ̀ tàbí nínu eruku, títo àga, fífọ ilé ìgbọ̀nsẹ̀ àti bíbu oògùn apakòkòrò sí i, fífọ fèrèsé àti dígí, kíkó pàǹtírí dà nù tàbí ṣíṣe ìmọ́tótó ara ilé àti ríro àyíká. Ó kéré tán, lẹ́ẹ̀kan lọ́dún, a máa ń ya ọjọ́ kan sọ́tọ̀ fún ṣíṣe gbogbo iṣẹ́ ìmọ́tótó Gbọ̀ngàn Ìjọba tinú tòde. A máa ń jẹ́ kí àwọn ọmọ wa lọ́wọ́ sí iṣẹ́ náà, kí wọ́n lè máa kẹ́kọ̀ọ́ láti bọ̀wọ̀ fún ibi ìjọsìn wa.​—Oníwàásù 5:1.

      Yọ̀ǹda ara rẹ láti ṣe àtúnṣe tó bá yẹ. Lọ́dọọdún, a máa ń yẹ tinú tòde Gbọ̀ngàn Ìjọba wò fínnífínní. Àyẹ̀wò yìí máa ń mú ká tún àwọn nǹkan ṣe látìgbàdégbà kí gbọ̀ngàn náà lè wà bó ṣe yẹ, èyí sì ń jẹ́ ká lè máa ṣọ́ owó ná. (2 Kíróníkà 24:13; 34:10) Gbọ̀ngàn Ìjọba tó mọ́ tónítóní tá a sì tún ṣe dáadáa ni ibi tó yẹ ká ti máa jọ́sìn Ọlọ́run wa. Tá a bá ń kópa nínú iṣẹ́ yìí, à ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, a sì mọyì ibi ìjọsìn wa. (Sáàmù 122:1) Èyí tún máa ń jẹ́ káwọn èèyàn fojú tó dára wò wá ládùúgbò.​—2 Kọ́ríńtì 6:3.

      • Kí nìdí tó fi yẹ ká máa tọ́jú ibi ìjọsìn wa?

      • Àwọn ètò wo la ṣe láti mú kí Gbọ̀ngàn Ìjọba wà ní mímọ́ tónítóní?

  • Báwo Ni Ibi Ìkówèésí Gbọ̀ngàn Ìjọba Ṣe Ń Ṣe Wá Láǹfààní?
    Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
    • Ẹ̀KỌ́ 27

      Báwo Ni Ibi Ìkówèésí Gbọ̀ngàn Ìjọba Ṣe Ń Ṣe Wá Láǹfààní?

      Arákùnrin kan ń wá ìwé níbi ìkówèésí Gbọ̀ngàn Ìjọba

      Orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì

      Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan ń ran ọ̀dọ́kùnrin yìí lọ́wọ́ kó lè mọ bá a ṣe ń ṣe ìwádìí

      Orílẹ̀-èdè Czech

      Ọmọbìnrin yìí ń kọ orúkọ rẹ̀ sínú ìwé orin rẹ̀

      Orílẹ̀-èdè Benin

      Arákùnrin kan ń ṣe ìwádìí lórí Watchtower Library

      Àwọn Erékùṣù Cayman

      Ṣé wàá fẹ́ ṣe àwọn ìwádìí kan kí ìmọ̀ rẹ nínú Bíbélì lè pọ̀ sí i? Ṣé ó wù ẹ́ pé kó o mọ̀ sí i nípa ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tàbí ẹnì kan, ibì kan tàbí ohun kan tí Bíbélì mẹ́nu bà? Àbí ò ń wò ó bóyá Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti borí ohun kan tó ò ń ṣàníyàn nípa rẹ̀? Lọ ṣèwádìí níbi ìkówèésí tó wà nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba.

      Àwọn ohun téèyàn lè fi ṣèwádìí wà níbẹ̀. O ṣeé ṣe kó o má ní gbogbo ìwé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó dá lórí Bíbélì ní èdè rẹ. Àmọ́, ọ̀pọ̀ àwọn ìwé tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ tẹ̀ jáde máa wà níbi ìkówèésí Gbọ̀ngàn Ìjọba. Àwọn ìwé tó tún lè wà níbẹ̀ ni oríṣiríṣi Bíbélì, ìwé atúmọ̀ èdè àtàwọn ìwé míì tá a lè fi ṣèwádìí. O lè lo àwọn ìwé tó wà níbi ìkówèésí yìí kí ìpàdé tó bẹ̀rẹ̀ tàbí lẹ́yìn ìpàdé. Tí kọ̀ǹpútà bá wà níbẹ̀, ó lè ní ètò Watchtower Library (ìyẹn àkójọ ìwé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà). Ètò ìṣiṣẹ́ kọ̀ǹpútà yìí ní àkójọ àwọn ìwé wa, ó sì rọrùn láti fi ṣe ìwádìí nípa ẹ̀kọ́ kan, ọ̀rọ̀ kan tàbí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan.

      Ó wúlò fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni. O lè lo ibi ìkówèésí Gbọ̀ngàn Ìjọba tó o bá ń múra iṣẹ́ rẹ sílẹ̀. Alábòójútó Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ ló ń bójú tó ibi ìkówèésí náà. Ó máa ń rí i pé àwọn ìwé tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde wà níbẹ̀ àti pé gbogbo ìwé ibẹ̀ wà létòlétò. Òun tàbí ẹni tó ń kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lè fi bó o ṣe máa rí ohun tó o nílò hàn ẹ́. Àmọ́, má ṣe mú ìwé èyíkéyìí kúrò níbi ìkówèésí Gbọ̀ngàn Ìjọba. Bákan náà, ó yẹ ká máa tọ́jú àwọn ìwé náà dáádáá ká má sì kọ nǹkan kan sínú wọn.

      Bíbélì ṣàlàyé pé tá a bá fẹ́ “rí ìmọ̀ Ọlọ́run,” a gbọ́dọ̀ máa “wá a kiri bí àwọn ìṣúra tó fara sin.” (Òwe 2:​1-5) O lè lo ibi ìkówèésí Gbọ̀ngàn Ìjọba láti bẹ̀rẹ̀ sí í wá a.

      • Kí làwọn ohun tá a lè fi ṣe ìwádìí níbi ìkówèésí Gbọ̀ngàn Ìjọba?

      • Ta ló lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti mọ bó o ṣe lè lo ibi ìkówèésí Gbọ̀ngàn Ìjọba dáadáa?

      ṢE ÌWÁDÌÍ SÍ I

      Tó o bá fẹ́ ní àkójọ ìwé ti ara rẹ, wo àwọn ohun tó wà níbi tá a ti ń gbàwé nínú ìjọ. Ẹni tó ń kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lè dábàá àwọn ìwé tó yẹ kó o kọ́kọ́ ní.

  • Kí Ló Wà Lórí Ìkànnì Wa?
    Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
    • Ẹ̀KỌ́ 28

      Kí Ló Wà Lórí Ìkànnì Wa?

      Obìnrin kan ń ṣèwádìí lórí kọ̀ǹpútà

      Orílẹ̀-èdè Faransé

      Bàbá àti ọmọ ń lo kọ̀ǹpútà

      Orílẹ̀-èdè Poland

      Obìnrin kan ń wo fídíò èdè àwọn adití lórí ìkànnì wa

      Orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà

      Jésù Kristi sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ yín máa tàn níwájú àwọn èèyàn, kí wọ́n lè rí àwọn iṣẹ́ rere yín, kí wọ́n sì fògo fún Baba yín tó wà ní ọ̀run.” (Mátíù 5:16) Ìdí nìyẹn tá a fi ń lo ìmọ̀ ẹ̀rọ òde òní, títí kan Íńtánẹ́ẹ̀tì fún iṣẹ́ wa. Ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, jw.org, ni ibi tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kó ìsọfúnni sí nípa ìgbàgbọ́ àti iṣẹ́ wa. Kí làwọn ohun tó wà níbẹ̀?

      Ìdáhùn Bíbélì sí àwọn ìbéèrè táwọn èèyàn sábà máa ń béèrè. O lè rí ìdáhùn sí díẹ̀ lára àwọn ìbéèrè tó ṣe pàtàkì gan-an táwọn èèyàn ti béèrè. Bí àpẹẹrẹ, ìwé àṣàrò kúkúrú tá a pè ní Ǹjẹ́ Ìyà Lè Dópin? àti Ǹjẹ́ Àwọn Òkú Lè Jíǹde? wà lórí ìkànnì wa ní èdè tó lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600). Wàá tún rí Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun níbẹ̀ ní èdè tó lé ní àádóje (130). Àwọn ìwé tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà wà níbẹ̀, títí kan ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? àtàwọn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde. O lè ka ọ̀pọ̀ lára àwọn ìwé yìí tàbí kó o tẹ́tí sí wọn lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, o sì lè wà wọ́n jáde lóríṣiríṣi ọ̀nà táwọn èèyàn ń lò, irú bíi MP3, PDF tàbí EPUB. O tiẹ̀ lè tẹ ojú ìwé mélòó kan jáde fún ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ sí ìwé náà lédè rẹ̀! Àwọn fídíò tún wà ní oríṣiríṣi èdè àwọn adití. Àwọn ohun tó o tún lè wà jáde ni Bíbélì kíkà bí ẹni ṣe eré ìtàn, àwòkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àtàwọn orin aládùn tó o lè gbádùn nígbà tó bá rọ̀ ẹ́ lọ́rùn.

      Ohun tó jóòótọ́ nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ohun míì tá a tún ń gbé sórí ìkànnì wa ni àwọn ìròyìn ohun tó ń lọ àti fídíò nípa iṣẹ́ wa kárí ayé, àwọn ohun tó ṣẹ̀lẹ̀ sí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti ìrànwọ́ tá a ṣe fún àwọn tí àjálù bá. O lè mọ̀ nípa àwọn àpéjọ tó ń bọ̀ àti ibi táwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa wà.

      Lọ́nà yìí, à ń tan ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ dé apá ibi tó jìnnà jù lọ láyé. Àwọn èèyàn láti ibi gbogbo, títí kan ilẹ̀ Antarctica, ló ń jàǹfààní rẹ̀. Àdúrà wa ni pé “kí ọ̀rọ̀ Jèhófà lè máa gbilẹ̀ kíákíá” títí dé gbogbo ayé fún ògo Ọlọ́run.​—2 Tẹsalóníkà 3:1.

      • Báwo ni ìkànnì wa, jw.org ṣe ń ran àwọn èèyàn púpọ̀ sí i lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ látinú Bíbélì?

      • Kí lo máa fẹ́ ṣèwádìí nípa rẹ̀ lórí ìkànnì wa?

      ÌKÌLỌ̀:

      Àwọn alátakò ti ṣe àwọn ìkànnì kan láti máa fi tan irọ́ kiri nípa ètò wa. Ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe ni pé kí wọ́n fa àwọn èèyàn kúrò nínú ìjọsìn Jèhófà. A ò gbọ́dọ̀ lọ sórí àwọn ìkànnì yẹn.​—Sáàmù 1:1; 26:4; Róòmù 16:17.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́