Irú Orúkọ Wo Lo Ní?
NÍNÚ Bíbélì, ọ̀rọ̀ náà, “orúkọ” máa ń tọ́ka sí ìfùsì ẹni nígbà mìíràn. Fún àpẹẹrẹ, ọlọ́gbọ́n Ọba náà, Sólómọ́nì, kọ̀wé pé: “Orúkọ sàn ju òróró dáradára, ọjọ́ ikú sì sàn ju ọjọ́ tí a bíni lọ.” (Oníwàásù 7:1; fi wé Òwe 22:1.) Gẹ́gẹ́ bí Sólómọ́nì ti sọ ọ́, a kò bí orúkọ rere mọ́ni. Àmọ́, nígbà ayé ẹni ni a ń ní ìfùsì kan tí ó já mọ́ nǹkan. Orúkọ ẹnì kan ń sọ irú ìwà tó ní, yálà ó lawọ́ tàbí ó ya ahun, oníyọ̀ọ́nú tàbí ẹni tí kì í túra ká, onírẹ̀lẹ̀ ọkàn tàbí agbéraga, ẹni rere tàbí ẹni burúkú.
Gbé ọ̀ràn Dáfídì yẹ̀ wò. Nígbà tí ó wà lórí oyè, ó jẹ́ alágbára àti adúróṣinṣin. Lákòókò kan náà, Dáfídì fi ìrẹ̀lẹ̀ ọkàn gbà pé òun ṣe àṣìṣe, ó sì ronú pìwà dà nínú ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo tó dá. Wòlíì Jèhófà ní ìdí rere tí ó fi tọ́ka pé Dáfídì jẹ́ “ọkùnrin kan tí ó tẹ́ ọkàn-àyà [Ọlọ́run] lọ́rùn.” (1 Sámúẹ́lì 13:14) Nígbà tí Dáfídì ti wà ní ọ̀dọ́ ló ti ní orúkọ rere lọ́dọ̀ Ọlọ́run.
Lódì kejì ẹ̀wẹ̀, Ọba Jèhórámù ti Jùdíà ṣe orúkọ búburú fún ara rẹ̀. Ó mú kí àwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀ má jọ́sìn Jèhófà mọ́, ó sì pa mẹ́fà lára àwọn arákùnrin rẹ̀ àti díẹ̀ lára àwọn ọmọba Júdà. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, Jèhófà fi àrùn burúkú kan kọ lu Jèhórámù, àrùn náà ló sì pa á. Bíbélì sọ pé, Jèhórámù “lọ láìdunni,” tàbí bí ìtumọ̀ Today’s English Version ṣe sọ ọ́, “ikú rẹ̀ kò dun ẹnikẹ́ni.”—2 Kíróníkà 21:20.
Irú ìgbésí ayé tí Dáfídì àti Jèhórámù gbé ṣàlàyé bí òwe Bíbélì ti jẹ́ òtítọ́ pé: “Ìrántí olódodo ni a ó bù kún, ṣùgbọ́n orúkọ àwọn ẹni burúkú yóò jẹrà.” (Òwe 10:7) Ìdí nìyẹn tí ó fi yẹ kí gbogbo wa gbé jẹ́ẹ́, kí a sì ronú lórí ìbéèrè náà, ‘Irú orúkọ wo ni mo ń ṣe fún ara mi lọ́dọ̀ Ọlọ́run àti ẹ̀dá ẹlẹ́gbẹ́ mi?’