ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwbr16 September ojú ìwé 1-7
  • Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni
  • Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé—2016
  • Ìsọ̀rí
  • SEPTEMBER 5-11
  • SEPTEMBER 12-18
  • SEPTEMBER 19-25
  • SEPTEMBER 26–OCTOBER 2
Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé—2016
mwbr16 September ojú ìwé 1-7

Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni

SEPTEMBER 5-11

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | SÁÀMÙ 119

“Máa Rìn Nínú Òfin Jèhófà”

w05 4/15 ojú ìwé 10 ìpínrọ̀ 3-4

Gbẹ́kẹ̀ Lé Ọ̀rọ̀ Jèhófà

Pa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Mọ́ Kó O Lè Láyọ̀

3 Ẹni tó bá fẹ́ láyọ̀ gidi gbọ́dọ̀ máa rìn nínú òfin Ọlọ́run. (Sáàmù 119:1-8) Tá a bá ń rìn nínú òfin Ọlọ́run, Jèhófà yóò gbà pé a jẹ́ ‘aláìní-àléébù ní ọ̀nà wa.’ (Sáàmù 119:1) Tá a bá sọ pé ẹnì kan jẹ́ aláìní àléébù, kò túmọ̀ sí pé onítọ̀hún jẹ́ ẹni pípé, ńṣe ló kàn fi hàn pé ó ń sa gbogbo ipá rẹ̀ láti ṣe ìfẹ́ Jèhófà Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, Nóà “fi ara rẹ̀ hàn ní aláìní-àléébù láàárín àwọn alájọgbáyé rẹ̀” ní ti pé ó “bá Ọlọ́run tòótọ́ rìn.” Nítorí pé baba ńlá olóòótọ́ yìí gbé ìgbé ayé rẹ̀ bí Jèhófà ṣe fẹ́, òun àti ìdílé rẹ̀ ò sí lára àwọn tí Ìkún Omi pa. (Jẹ́nẹ́sísì 6:9; 1 Pétérù 3:20) Tí àwa náà yóò bá la òpin ayé yìí já, a gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tó ń ‘fi tọkàntara pa àṣẹ Ọlọ́run mọ́,’ ìyẹn ni pé ká máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.—Sáàmù 119:4.

4 Jèhófà ò ní fi wá sílẹ̀ láé tá a bá ń fi ‘ìdúróṣánṣán ọkàn-àyà gbé e lárugẹ’ tá a sì ‘ń pa àwọn ìlànà rẹ̀ mọ́.’ (Sáàmù 119:7, 8) Ọlọ́run ò fi Jóṣúà aṣáájú Ísírẹ́lì sílẹ̀, torí ó ṣe bí Ọlọ́run ṣe wí, ó ń ‘ka ìwé òfin Ọlọ́run ní ọ̀sán àti ní òru kó bàa lè ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí a kọ sínú rẹ̀.’ Ohun tó ṣe yìí jẹ́ kí ọ̀nà rẹ̀ yọrí sí rere, ó sì mú kó hùwà ọlọ́gbọ́n. (Jóṣúà 1:8) Títí tí Jóṣúà fi darúgbó kùjọ́kùjọ́ ló ṣì ń gbé Ọlọ́run ga, àní ó tiẹ̀ tún rán àwọn ọmọ Ísírẹ́lì létí pé: “Ẹ̀yin . . . mọ̀ dáadáa ní gbogbo ọkàn-àyà yín àti ní gbogbo ọkàn yín pé kò sí ọ̀rọ̀ kan tí ó kùnà nínú gbogbo ọ̀rọ̀ rere tí Jèhófà Ọlọ́run yín sọ fún yín.” (Jóṣúà 23:14) Bíi ti Jóṣúà àti ẹni tó kọ Sáàmù ìkọkàndínlọ́gọ́fà lọ̀ràn tiwa náà rí. Ká tó lè láyọ̀ kí ọ̀nà wa sì yọrí sí rere, a ní láti máa yin Jèhófà ká sì gbẹ́kẹ̀ lé ọ̀rọ̀ rẹ̀.

w05 4/15 ojú ìwé 12 ìpínrọ̀ 12

Gbẹ́kẹ̀ Lé Ọ̀rọ̀ Jèhófà

Ọ̀rọ̀ Jèhófà Ń Fún Wa Ní Ìgboyà

12 Tí a bá ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, a óò ní ìgboyà tá a ó fi lè máa fara da àwọn ìṣòro tá a bá ní. (Sáàmù 119:33-40) Tá a bá ń fi ìrẹ̀lẹ̀ wá ìtọ́ni Jèhófà, a ó lè “máa fi gbogbo ọkàn àyà” pa òfin rẹ̀ mọ́. (Sáàmù 119:33, 34) Ó yẹ ká máa bẹ Ọlọ́run bí onísáàmù náà ṣe bẹ̀ ẹ́ pé: “Tẹ ọkàn-àyà mi síhà àwọn ìránnilétí rẹ, kí ó má sì jẹ́ sí èrè” àbòsí. (Sáàmù 119:36) Ó yẹ ká tún máa ṣe bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ká máa “hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo.” (Hébérù 13:18) Bí ọ̀gá wa níbi iṣẹ́ bá fẹ́ ká hùwà àbòsí kan, kò yẹ ká gbà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yẹ ká fi ìgboyà tẹ̀ lé ìtọ́ni Ọlọ́run. Jèhófà sì máa ń bù kún àwọn tó bá ṣe bẹ́ẹ̀. Kódà tí èròkérò bá sọ sí wa lọ́kàn, Jèhófà máa ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè kápá rẹ̀. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa gbà á ládùúrà pé: “Mú kí ojú mi kọjá lọ láìrí ohun tí kò ní láárí.” (Sáàmù 119:37) Ẹ jẹ́ ká rí i dájú pé a ò ka ohun tí Jèhófà kórìíra sí ohun tó dára. (Sáàmù 97:10) Nígbà tó ti jẹ́ pé ohun tá a kì í jẹ, a kì í fi í runmú, ńṣe ló yẹ ká yàgò pátápátá fún àwòrán oníhòòhò àtohun tó bá lè fa ọkàn ẹni sí ìṣekúṣe àti àṣà bíbá ẹ̀mí lò.—1 Kọ́ríńtì 6:9, 10; Ìṣípayá 21:8.

w05 4/15 ojú ìwé 13 ìpínrọ̀ 13-14

Gbẹ́kẹ̀ Lé Ọ̀rọ̀ Jèhófà

13 Tí a bá mọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáadáa, a óò máa fi ìgboyà wàásù. (Sáàmù 119:41-48) A sì ní láti jẹ́ onígboyà láti lè ‘dá ẹni tí ń gàn wá lóhùn.’ (Sáàmù 119:42) Nígbà mìíràn, ọ̀rọ̀ wa lè dà bíi tàwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tí wọ́n gbàdúrà nígbà inúnibíni pé: “Jèhófà, . . . yọ̀ǹda fún àwọn ẹrú rẹ láti máa bá a nìṣó ní fífi àìṣojo rárá sọ ọ̀rọ̀ rẹ.” Kí ló wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn àdúrà wọn yìí? Ńṣe ni “gbogbo wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan . . . kún fún ẹ̀mí mímọ́, wọ́n sì ń fi àìṣojo sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.” Olúwa Ọba Aláṣẹ kan náà ló ń fún wa nígboyà tá a fi ń sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ láìṣojo.—Ìṣe 4:24-31.

14 Láti dẹni tó ní ìgboyà láti máa wàásù láìsí pé à ń tijú, a ní láti fẹ́ràn “ọ̀rọ̀ òtítọ́” tọkàntọkàn, ká sì máa ‘pa òfin Ọlọ́run mọ́ nígbà gbogbo.’ (Sáàmù 119:43, 44) Bí a bá ń fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, a ó lè ‘sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìránnilétí rẹ̀ ní iwájú àwọn ọba.’ (Sáàmù 119:46) Àdúrà gbígbà àti ẹ̀mí Jèhófà yóò sì ràn wá lọ́wọ́ ká lè sọ ohun tó tọ́ lọ́nà tó yẹ. (Mátíù 10:16-20; Kólósè 4:6) Pọ́ọ̀lù fi ìgboyà sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìránnilétí Ọlọ́run fáwọn alákòóso ní ọ̀rúndún kìíní. Bí àpẹẹrẹ, ó wàásù fún Fẹ́líìsì ará Róòmù tó jẹ́ gómìnà, Fẹ́líìsì sì “fetí sí i lórí èrò ìgbàgbọ́ nínú Kristi Jésù.” (Ìṣe 24:24, 25) Pọ́ọ̀lù tún wàásù fún Fẹ́sítọ́ọ̀sì tó jẹ́ gómìnà àti Ágírípà Ọba. (Ìṣe 25:22–26:32) Jèhófà ń bẹ lẹ́yìn àwa náà, ìyẹn ló ń jẹ́ ká lè máa fi ìgboyà wàásù, láìsí pé à ń “tijú ìhìn rere.”—Róòmù 1:16.

Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

w06 9/1 ojú ìwé 14 ìpínrọ̀ 4

Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Kárùn-Ún Sáàmù

119:71— Àǹfààní wo la lè rí nínú Ìpọ́njú? Ìṣòro lè kọ́ wa láti túbọ̀ máa gbára lé Jèhófà, láti máa gbàdúrà sí i tọkàntara, ká túbọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gan-an, ká sì máa fi ohun tí Bíbélì sọ sílò. Ìyẹn nìkan kọ́, ohun tá a bá ṣe nígbà tá a wà nínú ìpọ́njú lè jẹ́ ká rí àwọn ibi tá a kù sí, ká sì ṣàtúnṣe. Tá a bá jẹ́ kí ìpọ́njú sọ wá dẹni rere sí i, a ò ní máa bínú tí ìpọ́njú bá dé bá wa.

w06 9/1 ojú ìwé 14 ìpínrọ̀ 5

Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Kárùn-Ún Sáàmù

119:96— Kí ni “òpin gbogbo ìjẹ́pípé” túmọ̀ sí? Ohun tí onísáàmù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ni ojú tí ẹ̀dá èèyàn fi ń wo ìjẹ́pípé. Ó lè jẹ́ pé ohun tó ní lọ́kàn ni pé ó níbi tí òye èèyàn mọ nípa ìjẹ́pípé. Àmọ́, àwọn òfin Ọlọ́run kò ní irú ààlà bẹ́ẹ̀. Gbogbo ohun tí à ń ṣe nígbèésí ayé wa pátá ni ìtọ́sọ́nà inú rẹ̀ wúlò fún.

SEPTEMBER 12-18

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | SÁÀMÙ 120-134

“Ọ̀dọ̀ Jèhófà Ni Ìrànlọ́wọ́ Mi Ti Wá”

w04 12/15 ojú ìwé 12 ìpínrọ̀ 3

Jèhófà Ni Olùrànlọ́wọ́ Wa

Orísun Ìrànwọ́ Tí Kì Í Kùnà

3 Onísáàmù náà bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ nípa jíjẹ́ ká mọ̀ pé dídá tí Jèhófà dá ohun gbogbo la fi ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ̀, ó ní: “Èmi yóò gbé ojú mi sókè sí àwọn òkè ńlá. Ibo ni ìrànlọ́wọ́ mi yóò ti wá? Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìrànlọ́wọ́ mi ti wá, Olùṣẹ̀dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.” (Sáàmù 121:1, 2) Kì í ṣe pé òkè ńlá kan ṣá ni onísáàmù yìí ń wò o. Nígbà tó kọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sílẹ̀, Jerúsálẹ́mù ni tẹ́ńpìlì Jèhófà wà. Ìlú yìí wà ní orí àwọn òkè ńlá Júdà, ibẹ̀ sì ni Jèhófà ń gbé lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. (Sáàmù 135:21) Ó ní láti jẹ́ pé àwọn òkè Jerúsálẹ́mù níbi tí wọ́n kọ́ tẹ́ńpìlì Jèhófà sí ni onísáàmù náà ń wò, ó ń fi ìgbọ́kànlé retí Jèhófà pé á ran òun lọ́wọ́. Kí ló mú kó dá onísáàmù náà lójú pé Jèhófà yóò ran òun lọ́wọ́? Ohun tó mú kó dá a lójú ni pé Jèhófà ni “Olùṣẹ̀dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.” Lẹ́nu kan, ohun tí onísáàmù náà ń sọ ni pé, ‘Dájúdájú kò sóhun tó lè dá Ẹlẹ́dàá tó jẹ́ alágbára gbogbo dúró tí kò fi ní ràn mí lọ́wọ́!’—Aísáyà 40:26.

w04 12/15 ojú ìwé 12 ìpínrọ̀ 4

Jèhófà Ni Olùrànlọ́wọ́ Wa

4 Onísáàmù náà tún ṣàlàyé pé Jèhófà kì í fọ̀rọ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣeré rárá, ó ní: “Kò ṣeé ṣe kí òun jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n. Kò ṣeé ṣe kí Ẹni tí ń ṣọ́ ọ tòògbé. Wò ó! Kì yóò tòògbé, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sùn, Ẹni tí ń ṣọ́ Ísírẹ́lì.” (Sáàmù 121:3, 4) Ọlọ́run ò lè jẹ́ káwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé e “ta gbọ̀n-ọ́ngbọ̀n-ọ́n” kò sì lè jẹ́ kí wọ́n ṣubú débi tí wọn ò ti ní lè dìde mọ́. (Òwe 24:16) Kí nìdí? Nítorí pé ńṣe ni Jèhófà dà bí olùṣọ́ àgùntàn tó wà lójúfò, tó ń ṣọ́ àwọn àgùntàn rẹ̀ lójú méjèèjì. Ǹjẹ́ ìyẹn ò tó láti fi wá lọ́kàn balẹ̀? Kò tiẹ̀ sígbà kan tí kì í wá nǹkan ṣe sí ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn rẹ̀. Tọ̀sán-tòru ló máa ń ṣọ́ wọn lójú méjèèjì.

w04 12/15 ojú ìwé 13 ìpínrọ̀ 5-7

Jèhófà Ni Olùrànlọ́wọ́ Wa

5 Ìdánilójú tí onísáàmù náà ní pé Jèhófà ń dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀ ló mú kó kọ̀wé pé: “Jèhófà ń ṣọ́ ọ. Jèhófà ni ibòji rẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ. Àní oòrùn kì yóò pa ọ́ ní ọ̀sán, tàbí òṣùpá ní òru.” (Sáàmù 121:5, 6) Ní Ìlà Oòrùn ayé, táwọn tó ń fẹsẹ̀ rìnrìn àjò nínú oòrùn tó mú janjan bá rí ibi tí wọ́n lè forí pa mọ́ sí, ńṣe ni inú wọn máa ń dùn gan-an. Jèhófà dà bíi ibòji fún àwọn èèyàn rẹ̀, ó ń dáàbò bò wọ́n kúrò nínú àjálù tó dà bí ooru gbígbóná janjan. Kíyè sí i pé “ọwọ́ ọ̀tún” ló sọ pé Jèhófà wà. Nígbà táwọn èèyàn bá ń jagun láyé ìgbàanì, apata táwọn sójà sábà máa ń gbé sọ́wọ́ òsì kì í fi bẹ́ẹ̀ dáàbò bo ọwọ́ ọ̀tún wọn. Ọ̀rẹ́ kan tó bá nífẹ̀ẹ́ sójà náà dénú lè dàábò bò ó nípa dídúró sí ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún rẹ̀ kó sì máa gbèjà rẹ̀. Bí Jèhófà ṣe ń dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn olùjọsìn rẹ̀ nìyẹn, tó sì múra tán láti ràn wọ́n lọ́wọ́ ní gbogbo ìgbà.

6 Ǹjẹ́ ìgbà kan tiẹ̀ wà tí Jèhófà máa dáwọ́ ìrànlọ́wọ́ tó ń ṣe fáwọn èèyàn rẹ̀ dúró? Ìyẹn ò lè ṣẹlẹ̀ láé. Onísáàmù náà wá parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ báyìí pé: “Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò máa ṣọ́ ọ lọ́wọ́ gbogbo ìyọnu àjálù. Òun yóò máa ṣọ́ ọkàn rẹ. Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò máa ṣọ́ ìjáde rẹ àti ìwọlé rẹ láti ìsinsìnyí lọ àti títí dé àkókò tí ó lọ kánrin.” (Sáàmù 121:7, 8) Ṣàkíyèsí pé onísáàmù yìí ti wá ń sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ iwájú báyìí, kò sọ̀rọ̀ nípa ìsinsìnyí nìkan mọ́. Onísáàmù náà ti kọ́kọ́ sọ ṣáájú ní ẹsẹ ìkarùn-ún pé: “Jèhófà ń ṣọ́ ọ.” Àmọ́ nínú àwọn ẹsẹ yìí, onísáàmù náà sọ pé: “Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò máa ṣọ́ ọ.” Ìyẹn ló mú un dá àwọn olùjọ́sìn tòótọ́ lójú pé ìrànlọ́wọ́ Jèhófà yóò nasẹ̀ dé ọjọ́ iwájú. Ibi yòówù ti wọn ì báà lọ, àjálù èyíkéyìí tí wọn ì báà dojú kọ, kò sígbà kan tí Jèhófà ò ní ràn wọ́n lọ́wọ́.—Òwe 12:21.

7 Láìṣe àní-àní, ó dá ẹni tó kọ Sáàmù kọkànlélọ́gọ́fà yìí lójú pé, Ẹlẹ́dàá tó jẹ́ alágbára ńlá gbogbo ń ṣọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn tó bìkítà àti bí ẹ̀ṣọ́ tó wà lójúfò ṣe ń ṣọ́nà lójú méjèèjì. Kò sídìí tí ò fi yẹ káwa náà ní ìdánilójú bíi ti onísáàmù yìí, nítorí pé Jèhófà kò yí padà. (Málákì 3:6) Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé nǹkan kan ò ní ṣẹlẹ̀ sí wa ni? Rárá o, àmọ́ tá a bá gbà pé Jèhófà ni Olùrànlọ́wọ́ wa, Jèhófà yóò dáàbò bò wá lọ́wọ́ gbogbo ohun tó bá lè pa wá lára nípa tẹ̀mí. A lè béèrè pé, ‘Báwo ni Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́?’ Ẹ jẹ́ ká yẹ ọ̀nà mẹ́rin tó gbà ń ràn wá lọ́wọ́ wò. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a óò jíròrò bó ṣe ran àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ lákòókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì. Inú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e la óò ti jíròrò ọ̀nà tó gbà ń ran àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́ lóde òní.

Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

w06 9/1 ojú ìwé 15 ìpínrọ̀ 4

Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Kárùn-Ún Sáàmù

123:2—Ẹ̀kọ́ wo ni àkàwé ojú àwọn ìránṣẹ́ fi kọ́ wa? Ìdí méjì làwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin fi máa ń wo ọwọ́ ọ̀gá wọn. Èkíní, láti mọ ohun tí ọ̀gá wọn fẹ́ àti èkejì, kí wọ́n lè rí ààbò àtohun tí wọ́n nílò. Bẹ́ẹ̀ làwa náà ṣe ń wo ojú Jèhófà láti mọ ohun tó jẹ́ ìfẹ́ rẹ̀ àti láti rí ojú rere rẹ̀.

w06 9/1 ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 3

Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Kárùn-Ún Sáàmù

133:1-3. Ìṣọ̀kan àárín àwọn èèyàn Jèhófà ń fini lọ́kàn balẹ̀, ó ń gbéni ró, ó sì ń mára tuni. A ò gbọ́dọ̀ ba ìṣọ̀kan yìí jẹ́ nípa ṣíṣe àríwísí àwọn arákùnrin wa, nípa dídá aáwọ̀ sílẹ̀, tàbí nípa ríráhùn.

SEPTEMBER 19-25

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | SÁÀMÙ 135-141

“Ọlọ́run Ṣẹ̀dá Wa Tìyanu-Tìyanu”

w07 6/15 ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 1-4

Ọlọ́run ‘Ṣẹ̀dá Wa Tìyanu-tìyanu’

ÀWỌN ohun àgbàyanu pọ̀ lọ súà láyé yìí. Báwo ló ṣe di pé wọ́n wà? Àwọn kan ò gbà pé Ẹlẹ́dàá ọlọ́gbọ́n-lóye kan wà tó dá wọn. Àmọ́ àwọn míì sọ pé téèyàn bá kọ̀ jálẹ̀ pé òun ò gbà pé Ẹlẹ́dàá kankan wà, olúwarẹ̀ ò ní lè mọ gbogbo ohun tó yẹ kó mọ̀ nípa àwọn ohun àgbàyanu inú ayé yìí. Wọ́n gbà pé pẹ̀lú bí àwọn ohun tó wà láyé ṣe jẹ́ àgbàyanu tó, bí wọ́n ṣe pọ̀ lóríṣiríṣi tó àti bí wọ́n ṣe díjú tó, kò kàn lè jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n ṣàdédé wà. Ọ̀pọ̀ èèyàn, títí kan àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan, gbà pé ẹ̀rí fi hàn pé Ẹlẹ́dàá kan tó jẹ́ ọlọgbọ́n, alágbára àti ọ̀làwọ́ ló dá ọ̀run òun ayé àti gbogbo nǹkan tó wà nínú wọn.

2 Dáfídì ọba Ísírẹ́lì ayé ọjọ́un jẹ́ ẹnì kan tó gbà pé ìyìn yẹ Ẹlẹ́dàá fún dídá tó dá àwọn ohun àgbàyanu. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ayé ìgbà tí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ò tíì gbilẹ̀ ni Dáfídì gbé láyé, ó róye pé àwọn ohun tóun ń rí láyìíká òun gbogbo jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ Ọlọ́run. Kò dìgbà tí Dáfídì bá rìn jìnnà kí iṣẹ́ àrà tí Ọlọ́run ṣe nínú ìṣẹ̀dá tó lè jọ ọ́ lójú gan-an. Wíwò tó wo ara rẹ̀ lásán ti tó. Ìyẹn ló mú kó kọ̀wé pé: “Èmi yóò gbé ọ lárugẹ, nítorí pé lọ́nà amúnikún-fún-ẹ̀rù ni a ṣẹ̀dá mi tìyanu-tìyanu. Àgbàyanu ni àwọn iṣẹ́ rẹ, bí ọkàn mi ti mọ̀ dáadáa.”—Sáàmù 139:14.

3 Ohun tó mú kó dá Dáfídì lójú hán-únhán-ún pé Ẹlẹ́dàá kan ní láti wà ni pé ó ro àròjinlẹ̀. Lóde òní, àwọn ẹ̀kọ́ tí wọ́n ń kọ́ni níléèwé àtàwọn ohun tí wọ́n ń gbé jáde nínú tẹlifíṣọ̀n, rédíò àtàwọn ìwé ìròyìn kún fún onírúurú èrò táwọn èèyàn hùmọ̀ nípa bí ìran èèyàn ṣe pilẹ̀ṣẹ̀, àwọn èrò náà sì lè sọ̀ọ̀yàn dẹni tí kò gbà pé Ẹlẹ́dàá wà. Nítorí náà, ká tó lè nígbàgbọ́ bíi ti Dáfídì, a ní láti ronú jinlẹ̀ bíi tiẹ̀. Ó léwu tá a bá kàn ń gba ohun táwọn èèyàn sọ láì fúnra wa ronú, pàápàá nínú àwọn ọ̀rọ̀ pàtàkì bíi bóyá Ẹlẹ́dàá wà àti bóyá òun ló dá ohun gbogbo tàbí òun kọ́.

4 Ìyẹn nìkan kọ́, tá a bá ronú jinlẹ̀ nípa iṣẹ́ ọwọ́ Jèhófà, àá túbọ̀ mọrírì àwọn ohun tó ṣe, á sì dá wa lójú pé àwọn ìlérí tó ṣe nípa ọjọ́ ọ̀la yóò ṣẹ dandan. Ìyẹn lè mú ká fẹ́ láti túbọ̀ mọ Jèhófà ká sì túbọ̀ máa sìn ín. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká wo bí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì òde òní ṣe kín ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ lẹ́yìn pé Ọlọ́run ‘ṣẹ̀dá wa tìyanu-tìyanu.’

w07 6/15 ojú ìwé 22-23 ìpínrọ̀ 7-11

Ọlọ́run ‘Ṣẹ̀dá Wa Tìyanu-tìyanu’

7 “Àwọn egungun mi kò pa mọ́ fún ọ nígbà tí a ṣẹ̀dá mi ní ìkọ̀kọ̀, nígbà tí a hun mí ní àwọn apá ìsàlẹ̀ jù lọ ní ilẹ̀ ayé.” (Sáàmù 139:15) Ohun tín-ń-tín tó bẹ̀rẹ̀ ìwàláàyè èèyàn, tá à ń pè ní sẹ́ẹ̀lì, á bẹ̀rẹ̀ sí í pín ní àpíntúnpín sí oríṣiríṣi ọ̀nà níbàámu pẹ̀lú iṣẹ́ kálukú wọn nínú ara. Wọ́n á di sẹ́ẹ̀lì inú iṣan ara, sẹ́ẹ̀lì inú ẹran ara, sẹ́ẹ̀lì inú awọ ara, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn sẹ́ẹ̀lì irú kan náà á wá para pọ̀ di ẹ̀yà ara kan. Bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹ̀yà ara yòókù á ṣe máa fara hàn. Bí àpẹẹrẹ, láàárín ọ̀sẹ̀ kẹta, àwọn egungun á bẹ̀rẹ̀ sí í fara hàn. Nígbà tó bá fi máa di ọ̀sẹ̀ keje, ọlẹ̀ náà ò lè tíì gùn ju nǹkan bí ìdajì igi ìṣáná lọ o, síbẹ̀ gbogbo igba ó lé mẹ́fà [206] egungun tó máa ń wà lára wa tá a bá dàgbà á ti bẹ̀rẹ̀ sí í dàgbà díẹ̀díẹ̀ nínú rẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ṣì rọ̀.

8 Ọmọ máa ń dàgbà lọ́nà ìyanu nínú ilé ọlẹ̀ ìyá, níbi tí ojú ẹ̀dá èèyàn kankan ò tó, àfi bíi pé ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ayé. Ká sòótọ́, ṣín-ń-ṣín lọmọ èèyàn tíì mọ̀ nípa bí ara ṣe ń dàgbà nínú ilé ọlẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, kí ló máa ń sún èròjà tó máa ń pinnu bí ara ṣe máa rí láti mú kí àwọn sẹ́ẹ̀lì inú ọlẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í pín sí oríṣiríṣi ọ̀nà níbàámu pẹ̀lú iṣẹ́ kálukú wọn nínú ara? Bóyá lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ìwádìí, ó ṣeé ṣe káwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì mọ̀ ọ́n, síbẹ̀, bí ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ tẹ̀ lé e ṣe fi hàn, gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ ẹ̀ ni Jèhófà Ẹlẹ́dàá wa ti mọ̀ láti ìpilẹ̀ṣẹ̀.

9 “Àní ojú rẹ rí ọlẹ̀ mi, inú ìwé rẹ sì ni gbogbo àwọn ẹ̀yà rẹ̀ wà ní àkọsílẹ̀, ní ti àwọn ọjọ́ tí a ṣẹ̀dá wọn, tí ìkankan lára wọn kò sì tíì sí.” (Sáàmù 139:16) Ìlànà bí ara látòkèdélẹ̀ ṣe máa rí wà nínú ohun tín-ń-tín, ìyẹn sẹ́ẹ̀lì àkọ́kọ́ tó bẹ̀rẹ̀ ìwàláàyè èèyàn. Ìlànà yìí ló máa darí bí ara ṣe máa dàgbà fún oṣù mẹ́sàn-án kí wọ́n tó bí èèyàn, òun náà ní á sì máa darí bí ara ṣe máa dàgbà fún ohun tó lé ní ogún ọdún lẹ́yìn tí wọ́n bá bí èèyàn. Láàárín àkókò yìí, ọ̀pọ̀ ìpele ni ara máa là kọjá bó ṣe ń dàgbà, ìlànà tí Ẹlẹ́dàá sì ti fi sínú ohun tín-ń-tín àkọ́kọ́ yẹn ló máa darí gbogbo èyí.

10 Dáfídì ò mọ̀ nípa àwọn nǹkan tín-tìn-tín tí wọ́n ń pè ní sẹ́ẹ̀lì, kò mọ̀ nípa èròjà tó máa ń pinnu bí ara ṣe máa rí, kódà kò ní awò amúǹkantóbi. Àmọ́ ó fòye mọ̀ pé ìlànà kan ti wà nílẹ̀ tí ara òun tẹ̀ lé bó ṣe ń dàgbà nínú ilé ọlẹ̀, èyí sì tọ̀nà. Ó sì ṣeé ṣe kí Dáfídì mọ̀ díẹ̀ nípa bí ọlẹ̀ ṣe ń dàgbà, ìdí nìyẹn tó fi lè ronú pé ó ní láti jẹ́ pé ńṣe ló ń dàgbà ní gbogbo ìpele-ìpele rẹ̀ níbàámu pẹ̀lú àkókò àti ìlànà kan tó ti wà nílẹ̀. Ó wá fi èdè ewì sọ̀rọ̀, ó ní ìlànà bí ara ṣe ń dàgbà nínú ilé ọlẹ̀ “wà ní àkọsílẹ̀” nínú “ìwé” Ọlọ́run.

11 Lóde òní, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì rí i pé èròjà inú ẹ̀jẹ̀ tó máa ń pinnu bí ara ṣe máa rí ló pinnu àwọn ohun tá a fi jọ àwọn òbí wa àtàwọn babańlá àti ìyá ńlá wa, irú bá a ṣe ga sí, bí ojú wa ṣe rí, àwọ̀ ẹyinjú wa àti irun wa, àti àìmọye àwọn nǹkan míì bẹ́ẹ̀. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn sẹ́ẹ̀lì tó wà lára wa ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún èròjà tó máa ń pinnu bí ara ṣe máa rí, àwọn èròjà yìí sì wà nínú ohun tí wọ́n ń pè ní DNA (deoxyribonucleic acid). Ìlànà bí ara á ṣe máa dàgbà ti “wà ní àkọsílẹ̀” nínú DNA yìí tó wà nínú sẹ́ẹ̀lì kálukú wa. Èròjà DNA wa ló ń mú káwọn sẹ́ẹ̀lì ara wa máa pín káwọn sẹ́ẹ̀lì mìíràn lè jẹ yọ tàbí káwọn sẹ́ẹ̀lì tuntun lè pààrọ̀ àwọn èyí tó ti gbó. Èyí ló ń jẹ́ ká lè máa wà láàyè lọ ki ìrísí wa sì máa wà bó ṣe wà. Áà, agbára àti ọgbọ́n Ẹlẹ́dàá wa tí ń bẹ lọ́run mà pọ̀ o!

w07 6/15 ojú ìwé 23 ìpínrọ̀ 12-13

Ọlọ́run ‘Ṣẹ̀dá Wa Tìyanu-tìyanu’

Ọpọlọ Wa Ò Láfiwé

12 “Nítorí náà, lójú mi, àwọn ìrònú rẹ mà ṣe iyebíye o! Ọlọ́run, àròpọ̀ iye wọn pátápátá mà pọ̀ o! Ká ní mo fẹ́ gbìyànjú láti kà wọ́n ni, wọ́n pọ̀ ju àwọn egunrín iyanrìn pàápàá.” (Sáàmù 139:17, 18a) Ọ̀nà ìyanu ni Ọlọ́run gbà dá àwọn ẹranko náà. Àwọn nǹkan kan tiẹ̀ wà tí wọ́n lè ṣe táwa ò lè ṣe. Àmọ́ Ọlọ́run fún àwa èèyàn ní ọpọlọ tó ju tiwọn lọ fíìfíì. Ìwé kan tó dá lórí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn nǹkan kan wà táwa èèyàn ń ṣe táwọn ẹranko náà lè ṣe, a yàtọ̀ pátápátá sí gbogbo ẹ̀dá inú ayé nítorí pé à ń sọ èdè a sì lè ronú. Ohun mìíràn tó tún mú ká ta wọ́n yọ ni pé a máa ń ṣèwádìí gan-an láti mọ̀ nípa ara wa. Bí àpẹẹrẹ, a máa ń ronú pé: Kí ló para pọ̀ di ara wa? Báwo ni Ẹlẹ́dàá ṣe ṣẹ̀dá ara wa?” Àwọn ìbéèrè wọ̀nyí ni Dáfídì pẹ̀lú ronú nípa rẹ̀.

13 Èyí tó wá ṣe pàtàkì jù lọ nínú àwọn ọ̀nà tá a fi yàtọ̀ sí ẹranko ni pé, a lè ṣàṣàrò lórí èrò Ọlọ́run. Àkànṣe ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fún wa yìí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà dá wa “ní àwòrán rẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:27) Dáfídì lo ẹ̀bùn yìí dáadáa. Ó ronú nípa àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé Ọlọ́run wà, ó tún ronú nípa àwọn ànímọ́ rere tí àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá fi hàn pé Ọlọ́run ní. Bákan náà, ó ní àwọn ìwé inú Bíbélì tó ti wà nígbà ayé rẹ̀ lọ́wọ́. Nínú àwọn ìwé náà, Ọlọ́run jẹ́ ká mọ̀ nípa òun àti iṣẹ́ ọwọ́ òun. Àwọn ìwé tí Ọlọ́run mí sí yìí jẹ́ kí Dáfídì mọ èrò Ọlọ́run, irú ẹni tó jẹ́, àtàwọn ohun tó pinnu láti ṣe. Ṣíṣàṣàrò tí Dáfídì ṣàṣàrò lórí Ìwé Mímọ́, lórí àwọn ohun tí Ọlọ́run dá, àti lórí ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà bá òun lò, mú kó yin Ẹlẹ́dàá rẹ̀.

w06 9/1 ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 8

Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Kárùn-Ún Sáàmù

139:17, 18. Ṣé ìmọ̀ Jèhófà ń gbádùn mọ́ wa? (Òwe 2:10) Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé a ti rí orísun ìdùnnú tí kò lópin nìyẹn. Àwọn èrò Jèhófà “pọ̀ ju àwọn egunrín iyanrìn pàápàá.” Kò sígbà kankan tá ò ní rí nǹkan kọ́ nípa rẹ̀.

Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

it-1 ojú ìwé 783 ìpínrọ̀ 5

Ẹ́kísódù

Jèhófà lo agbára ńlá rẹ̀ láti gbé orúkọ rẹ̀ ga, ó sì fi dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè. Lẹ́yìn táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti sọdá Òkun Pupa, Mósè wá ṣáájú wọn nínú kíkọ orin. Míríámù ẹ̀gbọ́n Mósè tó jẹ́ wòlíì obìnrin sì mú tanboríìnì tó wà lọ́wọ́ rẹ̀, òun àti àwọn obìnrin yòókù sì ń jó, wọ́n sì ń ṣelégbè orin táwọn ọkùnrin ń kọ. (Ẹ́kís. 15:1, 20, 21) Ọlọ́run fi ìyàtọ̀ sáàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtàwọn ọ̀tá wọn. Nígbà tí wọ́n jáde kúrò nílẹ̀ Íjíbítì, Ọlọ́run kò jẹ́ kí ewu kankan wu wọ́n, lọ́wọ́ èèyàn tàbí ẹranko ẹhànnà; kódà ajá kankan kò kanra mọ́ wọn tàbí kó yọ ahọ́n rẹ̀ sí wọn. (Ẹ́kís. 11:7) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwé Ẹ́kísódù kò sọ pé Fáráò fúnra rẹ̀ pa run sínú òkun pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun rẹ̀, síbẹ̀ ìwé Sáàmù 136:15 sọ pé Jèhófà “gbọn Fáráò àti ẹgbẹ́ ológun rẹ̀ dànù sínú Òkun Pupa.”

SEPTEMBER 26–OCTOBER 2

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | SÁÀMÙ 142-150

“Jèhófà Tóbi, Ó sì Yẹ fún Ìyìn Gidigidi”

w04 1/15 ojú ìwé 10 ìpínrọ̀ 3-4

Àwámáridìí ni Títóbi Jèhófà

‘Èmi Yóò Gbé Ọlọ́run Ọba Ga’

3 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Dáfídì ni ọba tí Ọlọ́run yàn lákòókò yẹn, síbẹ̀ ó gbà pé Jèhófà gan-an ni Ọba Ísírẹ́lì. Dáfídì sọ pé: “Tìrẹ ni ìjọba, Jèhófà, ìwọ Ẹni tí ń gbé ara rẹ sókè ṣe olórí pẹ̀lú lórí ohun gbogbo.” (1 Kíróníkà 29:11) Dáfídì mà mọyì jíjẹ́ tí Ọlọ́run jẹ́ Alákòóso yìí o! Ó kọ ọ́ lórin pé: “Ṣe ni èmi yóò gbé ọ ga, ìwọ Ọlọ́run mi Ọba, ṣe ni èmi yóò máa fi ìbùkún fún orúkọ rẹ fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé. Láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀ ni èmi yóò máa fi ìbùkún fún ọ, ṣe ni èmi yóò máa yin orúkọ rẹ fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé.” (Sáàmù 145:1, 2) Ohun tó wu Dáfídì ni pé kó máa yin Jèhófà Ọlọ́run láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀, kódà títí láé pàápàá.

4 Sáàmù 145 jẹ́ ká mọ̀ pé irọ́ gbuu ni sísọ tí Sátánì sọ pé Ọlọ́run jẹ́ alákòóso tó mọ ti ara rẹ̀ nìkan tí kò sì fún àwọn ìṣẹ̀dá rẹ̀ lómìnira. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5) Sáàmù yìí tún túdìí àṣírí irọ́ tí Sátánì pa pé àwọn tó ń ṣègbọràn sí Ọlọ́run kò nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, wọ́n kàn ń ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí ohun tí wọ́n máa rí gbà lọ́wọ́ rẹ̀ ni. (Jóòbù 1:9-11; 2:4, 5) Bíi ti Dáfídì, àwọn Kristẹni tòótọ́ òde òní náà ń fi hàn pé irọ́ gbuu làwọn ẹ̀sùn èké tí Èṣù ń fi kàn wọ́n. Ìyè àìnípẹ̀kun tí wọ́n ń retí lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba náà ṣeyebíye sí wọn gan-an, nítorí pé wọ́n fẹ́ láti máa yin Jèhófà títí ayérayé. Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló ti ń ṣe bẹ́ẹ̀ báyìí nípa lílo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù, tí ìfẹ́ sì ń mú kí wọ́n máa fi ìgbọràn sin Jèhófà gẹ́gẹ́ bí àwọn olùjọsìn tí wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́, tí wọ́n sì ti ṣe ìrìbọmi.—Róòmù 5:8; 1 Jòhánù 5:3.

w04 1/15 ojú ìwé 11 ìpínrọ̀ 7-8

Àwámáridìí ni Títóbi Jèhófà

Àwọn Àpẹẹrẹ Tó Fi Títóbi Jèhófà Hàn

7 Ìwé Sáàmù 145:3 fún wa ní ìdí pàtàkì kan tó fi yẹ ká máa yin Jèhófà. Dáfídì kọrin pé: “Jèhófà tóbi, ó sì yẹ fún ìyìn gidigidi, àwámáridìí sì ni títóbi rẹ̀.” Títóbi Jèhófà kò ní ààlà. Àwámáridìí ló jẹ́ fún àwa èèyàn, a ò lè mọ bó ṣe tóbi tó, a ò sì lè díwọ̀n rẹ̀. Àmọ́ ó dájú pé yóò ṣe wá láǹfààní tá a bá bẹ̀rẹ̀ sí wo àwọn àpẹẹrẹ títóbi Jèhófà tó jẹ́ àwámáridìí.

8 Rántí ìgbà kan tó o wà níbi tí kò ti sí iná mànàmáná tó o sì wá gbójú sókè lálẹ́ láti wo ojú ọ̀run. Ǹjẹ́ kò yà ọ́ lẹ́nu láti rí ẹgbàágbèje àwọn ìràwọ̀ tó hàn kedere lójú òfuurufú tó dúdú lọ rabidun? Ǹjẹ́ èyí kò mú ọ yin Jèhófà nítorí bó ṣe tóbi tó, tó dá gbogbo àwọn ohun tí ń bẹ lójú ọ̀run yìí? Àmọ́, bíńtín ni ohun tó o rí yìí lára iye ìràwọ̀ tó wà nínú ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ tí ayé wa yìí jẹ́ apá kan rẹ̀. Láfikún sí i, a fojú bú u pé iye ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ tó wà lé ní ọgọ́rùn-ún bílíọ̀nù, mẹ́tà péré ló sì ṣeé fojú rí lára wọn láìlo awò-awọ̀nàjíjìn. Láìsí àní-àní, àìlóǹkà àwọn ìràwọ̀ àtàwọn ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ tó para pọ̀ di àgbáálá ayé kíkàmàmà yìí jẹ́ ẹ̀rí tó fi agbára ìṣẹ̀dá Jèhófà àti àwámáridìí títóbi rẹ̀ hàn.—Aísáyà 40:26.

w04 1/15 ojú ìwé 14 ìpínrọ̀ 20-21

Àwámáridìí ni Títóbi Jèhófà

Àwọn Ànímọ́ Rere Tí Ọlọ́run Ní Mà Ga Lọ́lá O!

20 Gẹ́gẹ́ bá a ti kíyè sí i, àwọn ẹsẹ mẹ́fà àkọ́kọ́ nínú Sáàmù 145 fún wa ní ojúlówó ìdí tá a fi gbọ́dọ̀ máa yin Jèhófà fún àwọn nǹkan tó so pọ̀ mọ́ títóbi rẹ̀ tó jẹ́ àwámáridìí. Ẹsẹ keje sí ìkẹsàn-án fi títóbi Ọlọ́run hàn nípa títọ́ka sí àwọn ànímọ́ rere rẹ̀. Dáfídì kọrin pé: “Wọn yóò máa fi ọ̀yàyà sọ̀rọ̀ nígbà tí wọ́n bá ń mẹ́nu kan ọ̀pọ̀ yanturu oore rẹ, wọn yóò sì fi ìdùnnú ké jáde nítorí òdodo rẹ. Jèhófà jẹ́ olóore ọ̀fẹ́ àti aláàánú, Ó ń lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́. Jèhófà ń ṣe rere fún gbogbo gbòò, àánú rẹ̀ sì ń bẹ lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ̀.”

21 Oore àti òdodo Jèhófà ni Dáfídì kọ́kọ́ tẹnu mọ́ níhìn-ín—àwọn ànímọ́ wọ̀nyí sì ni Sátánì Èṣù sọ pé Ọlọ́run kò ní. Ipa wo làwọn ànímọ́ wọ̀nyí ní lórí gbogbo ẹni tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tó sì fara mọ́ ìṣàkóso rẹ̀? Họ́wù, ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń fi ìwà rere àti òdodo ṣàkóso ń mú ayọ̀ wá fún àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ débi pé wọn ò lè ṣe kí wọ́n má máa fi ọ̀yàyà yìn ín. Ìyẹn nìkan kọ́ o, oore Jèhófà tún nasẹ̀ dé ọ̀dọ̀ ‘gbogbo èèyàn.’ A lérò pé èyí yóò ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti ronú pìwà dà, kí wọ́n sì di olùjọsìn Ọlọ́run tòótọ́ náà kó tó pẹ́ jù.—Ìṣe 14:15-17.

w04 1/15 ojú ìwé 15 ìpínrọ̀ 2

Inú-rere-onífẹ̀ẹ́ Jèhófà Mà Pọ̀ O!

2 Jèhófà fi ìfẹ́ àrà ọ̀tọ̀ tí kò lópin hàn sáwọn olùjọsìn rẹ̀ tòótọ́. Irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ la fi ọ̀rọ̀ Hébérù tá a túmọ̀ sí “inú-rere-onífẹ̀ẹ́” tàbí “ìfẹ́ dídúróṣinṣin” ṣàpèjúwe. Dáfídì Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì mọyì inú-rere-onífẹ̀ẹ́ tí Ọlọ́run ní yìí gidigidi. Ohun tójú Dáfídì alára ti rí àti àṣàrò tó ti ṣe lórí ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ń bá àwọn èèyàn lò mú kó kọrin láìmikàn pé: “Jèhófà . . . pọ̀ ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́ [tàbí, “ìfẹ́ dídúróṣinṣin”].”—Sáàmù 145:8.

w04 1/15 ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 3-6

Inú-rere-onífẹ̀ẹ́ Jèhófà Mà Pọ̀ O!

Bá A Ṣe Lè Dá Àwọn Tó Jẹ́ Adúróṣinṣin sí Ọlọ́run Mọ̀

3 Nígbà tí Hánà, màmá wòlíì Sámúẹ́lì ń sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà Ọlọ́run, ó ní: “Ó ń fi ìṣọ́ ṣọ́ ẹsẹ̀ àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀.” (1 Sámúẹ́lì 2:9) Àwọn wo ni irú “àwọn ẹni ìdúróṣinṣin” bẹ́ẹ̀? Dáfídì Ọba dáhùn ìbéèrè náà. Lẹ́yìn tó yin àwọn ànímọ́ àgbàyanu tí Jèhófà ní wọ̀nyẹn, ó wá sọ pe: “Àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ yóò sì máa fi ìbùkún fún ọ.” (Sáàmù 145:10) O lè máa ṣe kàyéfì pé báwo làwọn èèyàn ṣe lè fi ìbùkún fún Ọlọ́run? Ọ̀nà pàtàkì tí wọ́n lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé kí wọ́n máa yìn ín tàbí kí wọ́n máa sọ ohun tó dára nípa rẹ̀.

4 Àwọn tá a lè gbà pè ó jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà ni àwọn tó ń fi ẹnu wọn sọ ohun tó dára nípa rẹ̀. Kí ni ohun tí wọ́n sábà máa ń sọ níbi àpèjẹ ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà àti láwọn ìpàdé Kristẹni? Ó dájú pé ọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Jèhófà ni! Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó jẹ́ adúróṣinṣin wọ̀nyí ní èrò kan náà tí Dáfídì ní, èyí tó kọ lórin pé: “Wọn yóò máa sọ̀rọ̀ nípa ògo ipò ọba rẹ [Jèhófà], wọn yóò sì máa sọ̀rọ̀ nípa agbára ńlá rẹ.”—Sáàmù 145:11.

5 Ǹjẹ́ Jèhófà máa ń fetí sílẹ̀ nígbà táwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin sí i bá ń yìn ín? Dájúdájú, ó máa ń fetí sí ohun tí wọ́n ń sọ. Nígbà tí Málákì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ kan tó ní í ṣe pẹ̀lú ìjọsìn tòótọ́ ní ọjọ́ wa, ó sọ pé: “Ní àkókò yẹn, àwọn tí ó bẹ̀rù Jèhófà bá ara wọn sọ̀rọ̀ lẹ́nì kìíní-kejì, olúkúlùkù pẹ̀lú alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀, Jèhófà sì ń fiyè sí i, ó sì ń fetí sílẹ̀. Ìwé ìrántí kan ni a sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ sílẹ̀ níwájú rẹ̀ fún àwọn tí ó bẹ̀rù Jèhófà àti fún àwọn tí ń ronú lórí orúkọ rẹ̀.” (Málákì 3:16) Inú Jèhófà máa ń dùn gan-an nígbà táwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin sí i bá ń sọ ohun tó dáa nípa rẹ̀, ó sì máa ń rántí wọn.

6 Ohun tá a tún lè fi dá àwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà mọ̀ ni bí wọ́n ṣe máa ń fìgboyà bá àwọn tí kì í ṣe olùjọsìn Ọlọ́run tòótọ́ sọ̀rọ̀ níbi gbogbo. Ká sòótọ́, àwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run máa ń “sọ àwọn ìṣe agbára ńlá rẹ̀ di mímọ̀ fún àwọn ọmọ ènìyàn àti ògo ọlá ńlá ipò ọba rẹ̀.” (Sáàmù 145:12) Ǹjẹ́ o máa ń lo gbogbo àǹfààní tó o bá ní láti bá àwọn aláìgbàgbọ́ sọ̀rọ̀ nípa ipò ọba Jèhófà? Láìdàbí ìjọba ènìyàn tó máa kọjá lọ láìpẹ́, ńṣe ni ipò ọba tirẹ̀ yóò wà títí láé. (1 Tímótì 1:17) Ó jẹ́ ọ̀ràn kánjúkánjú pé káwọn èèyàn kẹ́kọ̀ọ́ nípa ipò ọba Jèhófà tí yóò wà títí lọ fáàbàdà, kí wọ́n sì múra tán láti tì í lẹ́yìn. Dáfídì kọ ọ́ lórin pé: “Ipò ọba rẹ jẹ́ ipò ọba tí ó wà fún gbogbo àkókò tí ó lọ kánrin, àgbègbè ìṣàkóso rẹ sì jẹ́ jálẹ̀ gbogbo ìran-ìran tí ń dìde ní ṣísẹ̀-ń-tẹ̀lé.”—Sáàmù 145:13.

w04 1/15 ojú ìwé 17-18 ìpínrọ̀ 10-14

Inú-rere-onífẹ̀ẹ́ Jèhófà Mà Pọ̀ O!

10 Àmọ́ ṣá o, lóòtọ́ làwọn alákòóso kan máa ń ṣàníyàn nípa ire àwọn tó wà lábẹ́ ìṣàkóso wọn. Síbẹ̀ àwọn tó ṣèèyàn jù lọ láàárín wọn ò mọ àwọn ọmọ abẹ́ wọn dunjú. Nítorí náà, a lè béèrè pé: Ǹjẹ́ alákòóso èyíkéyìí tiẹ̀ wà tó bìkítà nípa gbogbo àwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀ débi pé kíá ló máa ń dìde ìrànlọ́wọ́ nígbà tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn bá wà nínú ìṣòro? Bẹ́ẹ̀ ni, ó wà. Dáfídì kọ̀wé pé: “Jèhófà ń fún gbogbo àwọn tí ó ṣubú ní ìtìlẹyìn, ó sì ń gbé gbogbo àwọn tí a tẹ̀ lórí ba dìde.”—Sáàmù 145:14.

11 Ọ̀pọ̀ àdánwò àti àjálù ló ń dé bá àwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà Ọlọ́run nítorí àìpé tiwọn fúnra wọn àti nítorí pé wọ́n ń gbé nínú ayé kan tó wà lábẹ́ agbára Sátánì, “ẹni burúkú náà.” (1 Jòhánù 5:19; Sáàmù 34:19) Àwọn èèyàn máa ń ṣenúnibíni sáwọn Kristẹni. Àìsàn ọlọ́jọ́ pípẹ́ tàbí ikú èèyàn ẹni ni ìṣòro táwọn kan ní. Àwọn ìgbà mìíràn wà tí àṣìṣe táwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà bá ṣe máa ń jẹ́ kí ìbànújẹ́ ‘dorí wọn kodò.’ Àmọ́ ṣá o, gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń múra tán láti tu ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn nínú kó sì fún wọn lókun nípa tẹ̀mí nígbàkigbà tí wọ́n bá bá ara wọn nínú àdánwò. Irú ìfẹ́ àtọkànwá kan náà yìí ni Jésù Kristi Ọba ní sí àwọn adúróṣinṣin tó ń ṣàkóso lé lórí.—Sáàmù 72:12-14.

Oúnjẹ Tó Tẹ́ni Lọ́rùn Lákòókò Tó Yẹ

12 Inú-rere-onífẹ̀ẹ́ tí Jèhófà ní ló ń mú kó fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní gbogbo ohun tí wọ́n nílò. Oúnjẹ afúnnilókun tó fi ń tẹ́ wọn lọ́rùn wà lára èyí. Dáfídì Ọba kọ̀wé pé: “Ìwọ [Jèhófà] ni ojú gbogbo gbòò ń wò tìrètí-tìrètí, ìwọ sì ń fún wọn ní oúnjẹ wọn ní àsìkò rẹ̀. Ìwọ ṣí ọwọ́ rẹ, ìwọ sì ń tẹ́ ìfẹ́-ọkàn gbogbo ohun alààyè lọ́rùn.” (Sáàmù 145:15, 16) Kódà láwọn àkókò àjálù, Jèhófà lè bójú tó àwọn ọ̀ràn lọ́nà tí àwọn ẹnì tó jẹ́ adúróṣinṣin sí i yóò fi rí ‘oúnjẹ òòjọ́ wọn.’—Lúùkù 11:3; 12:29, 30.

13 Dáfídì sọ pé “gbogbo ohun alààyè” là ń tẹ́ lọ́rùn. Ìyẹn sì kan àwọn ẹranko pẹ̀lú. Tí kì í bá ṣe pé àwọn ohun ọ̀gbìn pọ̀ rẹpẹtẹ lórí ilẹ̀, tí àwọn ewéko sì pọ̀ nínú òkun, àwọn ẹ̀dá inú omi, àwọn ẹyẹ, àtàwọn ẹranko tó ń rìn lórí ilẹ̀ ì bá má rí afẹ́fẹ́ ọ́síjìn tí wọ́n máa mí sínú tàbí oúnjẹ tí wọ́n máa jẹ́. (Sáàmù 104:14) Síbẹ̀, Jèhófà rí i pé gbogbo ohun tí wọ́n nílò ni òun fi ń tẹ́ wọn lọ́rùn.

14 Láìdàbí àwọn ẹranko, ohun tẹ̀mí tún máa ń jẹ àwọn èèyàn lọ́kàn. (Mátíù 5:3) Ẹ wo ọ̀nà àgbàyanu tí Jèhófà gbà ń fi ohun tẹ̀mí tẹ́ àwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin sí i lọ́rùn! Kí Jésù tó kú, ó ṣèlérí pé “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” yóò pèsè “oúnjẹ . . . ní àkókò tó bẹ́tọ̀ọ́ mu” nípa tẹ̀mí fún àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù. (Mátíù 24:45) Ìyókù àwọn ẹni àmì òróró tí iye wọ́n jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì ló para pọ̀ jẹ́ ẹgbẹ́ ẹrú náà lónìí. Jèhófà sì ti tipasẹ̀ wọn pèsè oúnjẹ tẹ̀mí lọ́pọ̀ yanturu lóde òní.

Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

w10 1/15 ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 1-2

Jẹ́ Kí Ìgbé Ayé Rẹ Ojoojúmọ́ Máa Fi Ògo Fún Ọlọ́run

ONÍSÁÀMÙ náà Dáfídì, sọ pé: “Mú kí n gbọ́ inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ ní òwúrọ̀, . . . mú mi mọ ọ̀nà tí ó yẹ kí n máa rìn.” (Sm. 143:8) Nígbà tó o bá ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó jí ẹ̀ láyọ̀ àti àlàáfíà, ǹjẹ́ o máa ń bẹ Jèhófà bíi ti Dáfídì, pé kó tọ́ ẹ sọ́nà láti ṣe ìpinnu, kó o lè fọjọ́ yẹn ṣohun tó dára jù? Ó dájú pé ò ń ṣe bẹ́ẹ̀.

Gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jèhófà tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́, ‘yálà a ń jẹ tàbí a ń mu tàbí a ń ṣe ohunkóhun mìíràn, ó yẹ ká máa ṣe ohun gbogbo fún ògo Ọlọ́run.’ (1 Kọ́r. 10:31) A mọ̀ pé ọ̀nà tá a bá ń gbà gbé ìgbé ayé wa lè bọlá fún Jèhófà tàbí kó tàbùkù sí i. A tún rántí pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé Sátánì ń fẹ̀sùn kan àwọn arákùnrin Kristi “tọ̀sán-tòru,” tó sì dájú pé ohun tó ń ṣe nípa gbogbo àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run tá a wà lórí ilẹ̀ ayé náà nìyẹn. (Ìṣí. 12:10) Torí náà, a ti pinnu láti fi hàn pé èké làwọn ẹ̀sùn Sátánì, ká sì mú ọkàn Jèhófà yọ̀ nípa ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún Baba wa ọ̀run “tọ̀sán-tòru.”—Ìṣí. 7:15; Òwe 27:11.

it-2 ojú ìwé 448

Ẹnu

Ẹnu jẹ́ ẹ̀yà ara kan tí Ọlọ́run dá láti máa gbé oúnjẹ lọ sí ikùn, àwa èèyàn sì tún máa fi ń sọ̀rọ̀. Gbogbo ọ̀rọ̀ tó ń tẹnu wa jáde gbọ́dọ̀ máa fi ìyìn fún Ọlọ́run. (Sm 34:1; 51:15; 71:8; 145:21) Onísáàmù kan sọ pé kí gbogbo ohun eléèémí máa yin Jèhófà; torí náà àwa èèyàn gbọ́dọ̀ máa yin Ọlọ́run tá a bá fẹ́ wà láàyè. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé a gbọ́dọ̀ nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀ látọkànwá, àmọ́ ìyẹn nìkan kò tó. A tún gbọ́dọ̀ ṣe ìpolongo ni gbangba ká lè rí ìgbàlà.—Sm 150:6; Ro 10:10.

Torí pé Jèhófà ni ẹlẹ́dàá, ó sì lágbára, ó lè fi ọ̀rọ̀ tó tọ́ sẹ́nu àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Ó ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́nà ìyanu fún àwọn wòlíì nípasẹ̀ agbára ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. (Ẹk 4:11, 12, 15; Jer 1:9) Ìgbà kan tiẹ̀ wà tó mú kí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan sọ̀rọ̀. (Nu 22:28, 30; 2Pe 2:15, 16) Lóde òní, Ọlọ́run kì í gba ẹnu àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀, àmọ́ wọ́n lè ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni ẹnu wọn nípasẹ̀ Bíbélì tí ó fi ẹ̀mí rẹ̀ mí sí, èyí tó ń múni gbára dì fún iṣẹ́ rere gbogbo. (2Ti 3:16, 17) Wọn ò ní láti dúró de Kristi mọ́ kó lè wá sọ ìhìn rere fún wọn, bákan náà ni wọn kì í wá ohun tí wọ́n máa wàásù káàkiri. Ohun tí wọ́n máa sọ wà ní àrọ́wọ́tó wọn, torí Bíbélì sọ fún wa pé: “Ọ̀rọ̀ náà wà nítòsí rẹ, ní ẹnu ìwọ alára àti ní ọkàn-àyà ìwọ alára.”—Ro 10:6-9; Di 30:11-14.

Ẹnu Wa Lè Pa Wá Ó Sì Lè Gbà Wá. Ó ṣe pàtàkì pé ká máa lo ẹnu wa lọ́nà tó dáa, ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi sọ nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ẹnu olódodo jẹ́ orísun ìyè.” (Owe 10:11) Torí náà, ó yẹ ká máa ṣọ́ ẹnu wa dáadáa (Sm 141:3; Owe 13:3; 21:23), torí tá a bá lò ó lọ́nà tí kò tọ́, ó lè fa wàhálà bá wa. (Owe 10:14; 18:7) Ọlọ́run máa dá kálukú lẹ́jọ́ fún ohun tó ń fi ẹnu rẹ̀ sọ. (Mt 12:36, 37) Èèyàn lè fi ìkánjú sọ̀rọ̀, kó jẹ́jẹ̀ẹ́ láìronú. (Onw 5:4-6) Ó lè máa pọ́n ẹnì kan lé ju bó ṣe yẹ lọ, ìyẹn sì lè fa ìṣubú fún onítọ̀hún. (Owe 26:28) Ó tún ṣe pàtàkì ká máa pa ẹnu wa mọ́ tá a bá wà lọ́dọ̀ ẹni burúkú, torí pé tá a bá sọ ohun tó yàtọ̀ sí ohun tí ọgbọ́n Ọlọ́run darí wa láti sọ, ó lè kó ẹ̀gàn bá orúkọ Ọlọ́run, èyí sì lè yọrí sí ikú onítọ̀hún. (Sm 39:1) Jésù fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ nípa bó ṣe yẹ ká tẹrí bá fún Ọlọ́run láìṣe àròyé kankan, ká má sì kẹ́gàn àwọn ẹni ibi tó ń ta ko Ọlọ́run.—Ais 53:7; Iṣe 8:32; 1Pe 2:23.

Àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ máa ṣọ́ra ní gbogbo ìgbà, torí pé aláìpé ṣì ni wá. Fún ìdí yìí, ó yẹ ká máa kíyè sí ohun tó wà lọ́kàn wa. Jésù sọ pé kì í ṣe ohun tó gba ẹnu wọlé ló ń sọni di ẹlẹ́gbin, bí kò ṣe ohun tó ń ti ẹnu jáde, torí pé “ọ̀pọ̀ yanturu tí ń bẹ nínú ọkàn-àyà ni ẹnu ń sọ.” (Mt 12:34; 15:11) Torí náà, a gbọ́dọ̀ máa ro ohun tá a fẹ́ sọ dáadáa, ká tó sọ ọ́ jáde, ká sì ro ohun tó máa jẹ́ àbájáde rẹ̀. Èyí gba pé ká máa fi àwọn ohun rere tí à ń kọ́ látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ́kàn.—Owe 13:3; 21:23.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́