ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jẹ́ Kí “Òfin Inú-rere-onífẹ̀ẹ́” Máa Fi Ìṣọ́ Ṣọ́ Ahọ́n Rẹ
    Ilé Ìṣọ́—2010 | August 15
    • 18, 19. Kí nìdí tí òfin inú-rere-onífẹ̀ẹ́ kò fi gbọ́dọ̀ kúrò lórí ahọ́n wa nínú àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn tá a jọ ń sin Jèhófà?

      18 Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ gbọ́dọ̀ hàn gbangba nínú gbogbo àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn tá a jọ jẹ́ olùjọ́sìn Jèhófà. Kódà, tí ipò nǹkan bá le koko, òfin inú-rere-onífẹ̀ẹ́ kò gbọ́dọ̀ kúrò lẹ́nu wa. Inú Jèhófà kò dùn sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí inú-rere-onífẹ̀ẹ́ wọn dà “gẹ́gẹ́ bí ìrì tí ń tètè lọ.” (Hós. 6:4, 6) Àmọ́, inú Jèhófà máa ń dùn sí inú-rere-onífẹ̀ẹ́ tí kò yẹ̀. Ṣàgbéyẹ̀wò bó ṣe ń bù kún àwọn tó ń lépa ànímọ́ yìí.

  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Máa Dé Lásìkò?
    Ilé Ìṣọ́—2010 | August 15
    • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Máa Dé Lásìkò?

      GBOGBO ìgbà kọ́ ló máa ń rọrùn láti dé lásìkò. Lára ohun tó máa ń ṣèdíwọ́ ni ìrìn-àjò ọ̀nà jíjìn, sún kẹẹrẹ fà kẹẹrẹ ọkọ̀ àti kí ọwọ́ èèyàn dí gan-an. Síbẹ̀ náà, ó ṣe pàtàkì kéèyàn máa dé lásìkò. Bí àpẹẹrẹ, níbi iṣẹ́ wọ́n gbà pé ẹni tó bá ń dé lásìkò jẹ́ ẹni tó ṣeé fọkàn tán, tí kì í sì í fiṣẹ́ ṣeré. Àmọ́, ẹni tó bá ń pẹ́ lẹ́yìn lè ṣàkóbá fún iṣẹ́ àwọn ẹlòmíì àti bí iṣẹ́ wọn ṣe máa dára sí. Pípẹ́ lẹ́yìn lè mú kí akẹ́kọ̀ọ́ kan pa kíláàsì jẹ, kó má sì ṣe dáadáa lẹ́nu ẹ̀kọ́ rẹ̀. Pípẹ́ dé ibi tí èèyàn ti fẹ́ lọ gba ìtọ́jú lè mú kí èèyàn máà rí ìtọ́jú tó péye gbà.

      Àmọ́ láwọn apá ibì kan, wọn ò fi bẹ́ẹ̀ ka dídé lásìkò sí pàtàkì. Ní irú àwọn ibi bẹ́ẹ̀, ó lè di àṣà wa láti máa pẹ́ lẹ́yìn. Tí ọ̀rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, ó ṣe pàtàkì pé ká sọ ọ́ di àṣà wa láti máa dé lásìkò. Tá a bá mọ bó ti ṣe pàtàkì tó láti máa dé lásìkò, ìyẹn á ràn wá lọ́wọ́ láti má ṣe jẹ́ apẹ́lẹ́yìn. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìdí tó fi yẹ ká máa dé lásìkò? Kí la lè ṣe tá ò fi ní máa pẹ́ lẹ́yìn? Kí sì ni àǹfààní tó máa ṣe wá tá a bá ń tètè dé?

      Jèhófà Kì Í Fi Àkókò Falẹ̀

      Olórí ìdí tó fi yẹ ká máa dé lásìkò ni pé a fẹ́ máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Ọlọ́run tá à ń sìn. (Éfé. 5:1) Jèhófà pèsè àpẹẹrẹ tó dára jù lọ tó bá dọ̀rọ̀ dídé lásìkò. Kò fi àkókò falẹ̀ rí. Ó máa ń mú ète rẹ̀ ṣẹ lásìkò tó yàn pé òun máa ṣe é gẹ́lẹ́.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́