Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Náhúmù, Hábákúkù àti Sefanáyà
ÌGBÀ kan wà tí orílẹ̀-èdè Ásíríà tó ń ṣàkóso ayé pa ìlú Samáríà tó jẹ́ olú ìlú ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì run. Àwọn ará Ásíríà sì ti ń halẹ̀ mọ́ Júdà látọjọ́ tó ti pẹ́. Àsìkò yìí ni wòlíì Náhúmù ará Júdà fẹ́ jẹ́ iṣẹ́ kan tó dá lórí ìlú Nínéfè tó jẹ́ olú ìlú Ásíríà. Inú ìwé Náhúmù ni iṣẹ́ tó jẹ́ yẹn wà, ó sì ti kọ ìwé ọ̀hún kó tó di ọdún 632 ṣáájú Sànmánì Kristẹni.
Lẹ́yìn Ásíríà, ilẹ̀ Bábílónì ni ìṣàkóso ayé bọ́ sí lọ́wọ́, àwọn ará Kálídíà sì máa ń jọba níbẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Ìwé Hábákúkù tó ṣeé ṣe kó ti parí ní nǹkan bí ọdún 628 ṣáájú Sànmánì Kristẹni sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa bí Jèhófà ṣe máa lo Bábílónì yìí láti ṣèdájọ́ àwọn èèyàn rẹ̀, ó sì tún sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí Bábílónì lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.
Wòlíì Sefanáyà tó wà ní Júdà ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ tiẹ̀ ṣáájú wòlíì Náhúmù àti Hábákúkù. Ìparun tó máa dé bá Júdà àti ìrètí tó wà fún un lẹ́yìn náà ni àsọtẹ́lẹ̀ Sefanáyà dá lé lórí. Ó ju ogójì ọdún lọ lẹ́yìn tó ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ yìí kí ìparun Jerúsálẹ́mù tó dé lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Àwọn ohun tí Jèhófà kéde lòdì sáwọn orílẹ̀-èdè míì pẹ̀lú wà nínú ìwé Sefanáyà.
“ÈGBÉ NI FÚN ÌLÚ ŃLÁ ÌTÀJẸ̀SÍLẸ̀”
Àtọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run, ẹni tó ń “lọ́ra láti bínú,” tó “sì tóbi ní agbára” ni “ọ̀rọ̀ ìkéde lòdì sí Nínéfè” ti wá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé “ibi odi agbára ní ọjọ́ wàhálà” ni Jèhófà jẹ́ fún àwọn tó sá di í, síbẹ̀ ìlú Nínéfè gbọ́dọ̀ pa run.—Náhúmù 1:1, 3, 7.
“Jèhófà yóò kó ohun ìyangàn Jékọ́bù jọ [ìyẹn ni pé yóò dá a padà] dájúdájú.” Àmọ́ Ásíríà ti kó ìpayà bá àwọn èèyàn Ọlọ́run, ó dà bíi ‘kìnnìún tó ń fa nǹkan ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ.’ Jèhófà máa “sun kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun [Nínéfè] nínú èéfín. Idà yóò sì jẹ àwọn ẹgbọrọ kìnnìún onígọ̀gọ̀ [rẹ̀] run.” (Náhúmù 2:2, 12, 13) “Ègbé ni fún ìlú ńlá ìtàjẹ̀sílẹ̀,” ìyẹn Nínéfè. ‘Gbogbo àwọn tí ń gbọ́ ìròyìn nípa rẹ̀ yóò pàtẹ́wọ́ sí i dájúdájú,’ inú wọn á sì dùn.—Náhúmù 3:1, 19.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
1:9—Àǹfààní wo ni “ìparun pátápátá” tó dé bá Nínéfè máa ṣe àwọn ará Júdà? Ó máa jẹ́ kí wọ́n bọ́ pátápátá lọ́wọ́ àwọn ará Ásíríà; “wàhálà kì yóò dìde nígbà kejì.” Náhúmù ń sọ̀rọ̀ bíi pé Nínéfè ti pa run nígbà tó kọ ọ̀rọ̀ yìí pé: “Wò ó! Lórí àwọn òkè ńlá, ẹsẹ̀ ẹni tí ń mú ìhìn rere wá, ẹni tí ń kéde àlàáfíà fáyé gbọ́. Ìwọ Júdà, ṣe ayẹyẹ àwọn àjọyọ̀ rẹ.”—Náhúmù 1:15.
2:6—“Àwọn ẹnubodè àwọn odò” wo ló ṣí? Àwọn ẹnubodè yìí ni ibi tí omi Odò Tígírísì bì wó lára ògiri ìlú Nínéfè. Lọ́dún 632 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, nígbà táwọn ará Bábílónì àtàwọn Mídíà para pọ̀ gbéjà ko Nínéfè, àwọn ará ìlú Nínéfè ò gbà pé mìmì kan lè mi àwọn. Nítorí pé ògiri gìrìwò-gìrìwò ló yí ìlú wọn ká, ọkàn wọn balẹ̀ pé kò sẹ́ni tó lè wọbẹ̀. Àmọ́, àrọ̀ọ̀rọ̀dá òjò mú kí Odò Tígírísì kún àkúnya. Gẹ́gẹ́ bí òpìtàn kan tó ń jẹ́ Diodorus ṣe sọ, àgbàrá òjò yìí “ya wọ apá ibì kan nínú ìlú náà, ibi tó sì wó lára ògiri rẹ̀ fẹ̀ gan-an.” Bí àwọn ẹnu ibodè odò ṣe ṣí nìyẹn, gẹ́gẹ́ bí Náhúmù sì ṣe sọ ọ́ tẹ́lẹ̀, kíá lọ́wọ́ tẹ àwọn ará Nínéfè bí ìgbà tí iná bá jó àgékù pòròpórò.—Náhúmù 1:8-10.
3:4—Lọ́nà wo ni Nínéfè gbà dà bíi kárùwà? Nínéfè tó jẹ́ olú ìlú Ásíríà tan àwọn orílẹ̀-èdè jẹ nípa ṣíṣèlérí fún wọn pé àwọn á jọ máa ṣọ̀rẹ́ àti pé òun á ràn wọ́n lọ́wọ́. Àmọ́ òun gan-an ló tún wá ki àjàgà bọ̀ wọ́n lọ́rùn. Bí àpẹẹrẹ, orílẹ̀-èdè Ásíríà ran Áhásì Ọba Jùdíà lọ́wọ́ nígbà táwọn ará Síríà àti Ísírẹ́lì gbìmọ̀ pọ̀ láti bá a jà. Àmọ́, ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, “ọba Ásíríà wá láti gbéjà [ko Áhásì], ó sì kó wàhálà bá a.”—2 Kíróníkà 28:20.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
1:2-6. Bí Jèhófà ṣe gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá rẹ̀, ìyẹn àwọn tí kò fi gbogbo ọkàn wọn sìn ín jẹ́ ká rí i pé ohun tó ń retí látọ̀dọ̀ àwọn olùjọsìn rẹ̀ ni pé kí wọ́n máa fi gbogbo ọkàn wọn pátá sin òun.—Ẹ́kísódù 20:5.
1:10. Ògiri gìrìwò-gìrìwò àti ọgọ́rọ̀ọ̀rún ilé gogoro kò ní kí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ nípa Nínéfè má ṣẹ. Kò sí báwọn ọ̀tá tí wọ́n dojú kọ àwọn èèyàn Jèhófà lóde òní ṣe lè bọ́ lọ́wọ́ ìdájọ́ Ọlọ́run nígbà tó bá dé.—Òwe 2:22; Dáníẹ́lì 2:44.
‘OLÓDODO YÓÒ MÁA WÀ LÁÀYÈ NÌṢÓ’
Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ láàárín Jèhófà Ọlọ́run àti wòlíì Hábákúkù ló wà nínú orí kìíní àti ìkejì ìwé Hábákúkù. Ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní Júdà kó ẹ̀dùn ọkàn bá wòlíì Hábákúkù, ló bá bi Ọlọ́run pé: “Èé ṣe tí ìwọ fi mú kí n rí ohun tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́, tí ìwọ sì ń wo èkìdá ìdààmú?” Èsì tí Jèhófà fún un ni pé: “Èmi yóò gbé àwọn ará Kálídíà dìde, orílẹ̀-èdè tí ó korò, tí ó sì ní inú fùfù.” Ó ya wòlíì yẹn lẹ́nu pé Ọlọ́run máa lo “àwọn tí ń ṣe àdàkàdekè” láti jẹ Júdà níyà. (Hábákúkù 1:3, 6, 13) Jèhófà mú un dá Hábákúkù lójú pé olódodo á máa wà láàyè nìṣó, àmọ́ ìdájọ́ ò lè yẹ̀ lórí àwọn ọ̀tá. Yàtọ̀ síyẹn, Hábákúkù ṣàkọsílẹ̀ àwọn ègbé márùn-ún tó máa bá àwọn ará Kálídíà tó jẹ́ ọ̀tá àwọn èèyàn Ọlọ́run.—Hábákúkù 2:4.
Nígbà tí Hábákúkù ń bẹ̀bẹ̀ fún àánú Ọlọ́run, ó “fi orin arò” gbàdúrà, ó sì sọ̀rọ̀ nípa bí Jèhófà ṣe fi agbára ńlá rẹ̀ hàn láyé àtijọ́, bí èyí tó ṣẹlẹ̀ ní Òkun Pupa, ní aginjù àti ní Jẹ́ríkò. Wòlíì yìí tún sàsọtẹ́lẹ̀ bí Jèhófà ṣe lọ tìbínú-tìbínú sí Amágẹ́dọ́nì láti pa àwọn ọ̀tá run. Gbólóhùn tó tẹ̀ lé e yìí ló fi parí àdúrà náà: “Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ ni ìmí mi; yóò sì ṣe ẹsẹ̀ mi bí ti àwọn egbin, yóò sì mú kí n rìn ní àwọn ibi gíga mi.”—Hábákúkù 3:1, 19.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
1:5, 6—Kí nìdí tó fi lè dà bíi pé ó ṣòroó gbà gbọ́ fáwọn Júù pé Jèhófà máa gbé àwọn ará Kálídíà dìde sí Jerúsálẹ́mù? Ìdí rẹ̀ ni pé nígbà tí Hábákúkù bẹ̀rẹ̀ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀, agbára tí orílẹ̀-èdè Íjíbítì ní lórí Júdà pọ̀ gan-an. (2 Àwọn Ọba 23:29, 30, 34) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé agbára Bábílónì ti ń pọ̀ sí i nígbà yẹn, àwọn ọmọ ogun Bábílónì kò tíì ṣẹ́gun Fáráò Nẹ́kò ọba Íjíbítì. (Jeremáyà 46:2) Yàtọ̀ síyẹn, tẹ́ńpìlì Jèhófà wà ní Jerúsálẹ́mù, ibẹ̀ sì làwọn ìdílé Dáfídì ti ń jọba látìrandíran láìsẹ́ni tó gbà á lọ́wọ́ wọn. Lójú àwọn Júù nígbà yẹn, “ìgbòkègbodò” Ọlọ́run láti gba àwọn ará Kálídíà láyè kí wọ́n pa Jerúsálẹ́mù run lè dà bí ohun tí kò lè ṣeé ṣe. Bó ti wù kí ọ̀rọ̀ tí Hábákúkù sọ ṣe dà bí ohun tí kò ṣeé ṣe tó lójú wọn, síbẹ̀ ìran tí Hábákúkù rí, pé àwọn ará Bábílónì máa pa Jerúsálẹ́mù run “ṣẹ láìkùnà” lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni.—Hábákúkù 2:3.
2:5—Ta ni “abarapá ọkùnrin,” kí sì nìdí tí kò fi ní “lé góńgó rẹ̀ bá”? Àwọn ará Bábílónì, tí wọ́n jẹ́ akọni lójú ogun, tí wọ́n sì ti ń ṣẹ́gun àwọn orílẹ̀-èdè ni “abarapá ọkùnrin” náà. Bí wọ́n ṣe ń ṣẹ́gun yẹn ń pa wọ́n bí wáìnì. Àmọ́, kò ní ṣeé ṣe fún wọn láti kó gbogbo orílẹ̀-èdè jọ sọ́dọ̀ ara wọn nítorí pé Jèhófà máa lo àwọn ará Mídíà àti Páṣíà láti bì wọ́n ṣubú. Ohun tó dúró fún “ọkùnrin” náà lóde òní ni àwọn orílẹ̀-èdè alágbára. Ohun tó ń pa àwọn orílẹ̀-èdè alágbára bí ọtí ni dídá tí wọ́n dá ara wọn lójú, jíjọ tí wọ́n jọ ara wọn lójú àti ojúkòkòrò tó ń mú kí wọ́n fẹ́ máa gbòòrò sí i. Ṣùgbọ́n kò ní ṣeé ṣe fún wọn láti kó ‘gbogbo orílẹ̀-èdè jọ sọ́dọ̀ ara wọn.’ Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló máa so aráyé pọ̀ ṣọ̀kan.—Mátíù 6:9, 10.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
1:1-4; 1:12–2:1. Hábákúkù béèrè àwọn ìbéèrè tó ń jẹ ẹ́ lọ́kàn, Jèhófà sì dá a lóhùn. Ọlọ́run tòótọ́ máa ń fetí sí àdúrà àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó ń sìn ín tọkàntọkàn.
2:1. Bíi ti Hábákúkù, àwa náà ní láti wà lójúfò ká sì máa bá iṣẹ́ ìsìn wa sí Jèhófà lọ. A ní láti múra tán láti tún èrò wa ṣe tẹ́nì kan bá ‘fi ìbáwí tọ́ wa sọ́nà’ tàbí tó fi ibi tá a ti nílò àtúnṣe hàn wá.
2:3; 3:16. Bá a ṣe ń fìgbàgbọ́ dúró de ọjọ́ Jèhófà, ẹ má ṣe jẹ́ ká dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wa.
2:4. Láti lè la ọjọ́ ìdájọ́ Jèhófà tó ń bọ̀ já, a gbọ́dọ̀ máa bá ìṣòtítọ́ nìṣó.—Hébérù 10:36-38.
2:6, 7, 9, 12, 15, 19. Ègbé ni fún ẹni tó ń fi ìwọra wá èrè tí kò tọ́ sí i, ẹni tó nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá, ẹni tó ń ṣèṣekúṣe tàbí ẹni tó ń lọ́wọ́ nínú ìbọ̀rìṣà. A ní láti ṣọ́ra ká má dẹni tó ń lọ́wọ́ nínú àwọn àṣà yìí.
2:11. Tá a bá kọ̀ tá ò tú àṣírí ìwà ibi tó kúnnú ayé yìí, “òkúta yóò fi ohùn arò ké jáde.” Ó ṣe pàtàkì pé ká máa fìgboyà wàásù Ìjọba Ọlọ́run nìṣó!
3:6. Nígbà tí Jèhófà bá ṣèdájọ́ àwọn ẹni ibi, kò sóhun tó máa dá a dúró, àwọn àjọ táwọn èèyàn gbé kalẹ̀ tó dà bíi pé wọ́n fìdí múlẹ̀ bí òkè ńláńlá àti òkè kéékèèké pàápàá kò ní lè dá a dúró.
3:13. Ó dá wa lójú pé àwọn ẹni ibi nìkan ni Amágẹ́dọ́nì máa pa run. Jèhófà máa dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́.
3:17-19. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣeé ṣe kí nǹkan nira fún wa ṣáájú Amágẹ́dọ́nì àti nígbà tó bá ń lọ lọ́wọ́, ó dá wa lójú pé Jèhófà máa fún wa ní agbára tá a nílò bá a bá ṣe ń fi ayọ̀ sìn ín nìṣó.
“ỌJỌ́ JÈHÓFÀ SÚN MỌ́LÉ”
Ìjọsìn Báálì gba Júdà kan. Jèhófà tipasẹ̀ wòlíì Sefanáyà sọ pé: “Dájúdájú, èmi yóò sì na ọwọ́ mi jáde lòdì sí Júdà àti lòdì sí gbogbo àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù.” Sefanáyà kìlọ̀ pé: “Ọjọ́ Jèhófà sún mọ́lé.” (Sefanáyà 1:4, 7, 14) Kìkì àwọn tó bá ń ṣe ohun tí Ọlọ́run ní ká máa ṣe nìkan ni ‘a ó pa mọ́’ ní ọjọ́ náà.—Sefanáyà 2:3.
“Ègbé ni fún . . . ìlú ńlá tí ń nini lára,” ìyẹn Jerúsálẹ́mù! “‘Ẹ máa wà ní ìfojúsọ́nà fún mi,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘títí di ọjọ́ tí èmi yóò dìde sí ẹrù àkótogunbọ̀, nítorí ìpinnu ìdájọ́ mi ni láti kó àwọn orílẹ̀-èdè jọ . . . kí n lè da ìdálẹ́bi tí ó ti ọ̀dọ̀ mi wá jáde sórí wọn.’” Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ṣèlérí pé: “Èmi yóò ṣe yín ní orúkọ àti ìyìn láàárín gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ ayé, nígbà tí mo bá kó àwọn òǹdè yín jọ padà ní ojú yín.”—Sefanáyà 3:1, 8, 20.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
2:13, 14—Ohùn wo ni “yóò máa kọrin” ní Nínéfè tó ti pa run pátápátá? Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àwọn ẹranko ìgbẹ́ àtàwọn ẹyẹ ló kù táá máa gbé Nínéfè, ohùn tí yóò máa kọrin yẹn ní láti jẹ́ ohùn orin àwọn ẹyẹ, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ ìró ẹ̀fúùfù tó ń gba ojú fèrèsé àwọn ilé tó ti dahoro kọjá.
3:9—Kí ni “èdè mímọ́ gaara,” báwo la sì ṣe ń sọ ọ́? Òótọ́ tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run tá a rí nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni, títí kan gbogbo ẹ̀kọ́ Bíbélì tá à ń kọ́ àwọn èèyàn. À ń sọ ọ́ nípa gbígba òtítọ́ gbọ́, nípa fífi kọ́ àwọn èèyàn àti nípa mímú ìgbésí ayé wa bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
1:8. Ó dà bíi pé àwọn kan nígbà ayé Sefanáyà “ń wọ aṣọ ilẹ̀ òkèèrè” káwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká bàa lè fẹ́ràn wọn. Ẹ ò rí i pé ìwà òmùgọ̀ ló máa jẹ́ fáwọn ìránṣẹ́ Jèhófà òde òní táwọn náà bá fẹ́ máa ṣe ohun táá mú káyé fẹ́ràn wọn!
1:12; 3:5, 16. Lemọ́lemọ́ ni Jèhófà ń rán àwọn wòlíì rẹ̀ láti kìlọ̀ fáwọn èèyàn rẹ̀ nípa ìdájọ́ tó fẹ́ ṣe. Kò ro ti pé ọ̀pọ̀ nínú wọn tó ti dà bíi gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ tó dì sísàlẹ̀ wáìnì, ti pinnu lọ́kàn wọn láti má ṣe yí padà, àti pé wọn ò ní fetí sí ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń sọ fún wọn. Bí ọjọ́ Jèhófà ṣe ń sún mọ́lé yìí, dípò tá ó fi jẹ́ kí ìwà àìbìkítà àwọn èèyàn mú ‘kí ọwọ́ wa rọ jọwọrọ’ ṣe ló yẹ ká máa polongo ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run láìdáwọ́dúró.
2:3. Jèhófà nìkan ló lè pa wá mọ́ ní ọjọ́ ìbínú rẹ̀. Tá a bá fẹ́ rí ojú rere rẹ̀, a ní láti máa “wá Jèhófà” nípa fífarabalẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ìyẹn Bíbélì; ká máa fi sínú àdúrà pé kó máa tọ́ wa sọ́nà; ká sì máa sún mọ́ ọn. A gbọ́dọ̀ máa “wá òdodo” nípa gbígbé ìgbésí ayé oníwà mímọ́. A sì tún ní láti máa “wá ọkàn-tútù” nípa kíkọ́ ìwà tútù àti ìtẹríba.
2:4-15; 3:1-5. Lọ́jọ́ tí Jèhófà bá ṣèdájọ́ àwọn èèyàn búburú, ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jerúsálẹ́mù àtàwọn ìlú tó yí i ká látijọ́ náà ló máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì àti gbogbo orílẹ̀-èdè tó ń ni àwọn èèyàn Ọlọ́run lára. (Ìṣípayá 16:14, 16; 18:4-8) A ní láti máa kéde ìdájọ́ Ọlọ́run nìṣó láìbẹ̀rù.
3:8, 9. Bá a ṣe ń dúró de Jèhófà, à ń retí ìgbàlà nípa kíkọ́ “èdè mímọ́ gaara” àti nípa pípè tá à ń ‘pe orúkọ Ọlọ́run,’ èyí tá a sì ń ṣe nípa yíyà tẹ́nì kọ̀ọ̀kan ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún un. A tún ń sin Jèhófà “ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́” pẹ̀lú àwọn èèyàn rẹ̀, a sì ń “rú ẹbọ ìyìn” gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn tá à ń mú wá fún Ọlọ́run.—Hébérù 13:15.
‘Ìyára Kánkán Rẹ̀ Pọ̀ Gidigidi’
Ọ̀kan lára àwọn tó kọ Sáàmù kọ ọ́ lórin pé: “Ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹni burúkú kì yóò sì sí mọ́; dájúdájú, ìwọ yóò sì fiyè sí ipò rẹ̀, òun kì yóò sì sí.” (Sáàmù 37:10) Tá a bá ronú jinlẹ̀ lórí àsọtẹ́lẹ̀ tí ìwé Náhúmù sọ nípa Nínéfè àtèyí tí ìwé Hábákúkù sọ nípa Júdà tó ti di apẹ̀yìndà àti nípa Bábílónì, ó máa dá wa lójú ṣáká pé ọ̀rọ̀ tí onísáàmù sọ yẹn á ṣẹ. Àmọ́, báwo ló ṣe máa pẹ́ tó tá a ó fi dúró?
Sefanáyà 1:14 sọ pé: “Ọjọ́ ńlá Jèhófà sún mọ́lé. Ó sún mọ́lé, ìyára kánkán rẹ̀ sì pọ̀ gidigidi.” Ìwé Sefanáyà tún sọ ohun tá a ní láti ṣe tá a bá fẹ́ kí Jèhófà pa wá mọ́ lọ́jọ́ yẹn àtohun tá a ní láti máa ṣe báyìí ká lè rí ìgbàlà. Lóòótọ́, “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ń sa agbára.”—Hébérù 4:12.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Àwọn ògiri gìrìwò-gìrìwò Nínéfè kò dí àsọtẹ́lẹ̀ Náhúmù lọ́wọ́ kó má ṣe nímùúṣẹ
[Credit Line]
Randy Olson/National Geographic Image Collection