Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
JANUARY 1-7
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | MÁTÍÙ 1-3
“Ìjọba Ọ̀run Ti Sún Mọ́lé”
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 3:1, 2
ìwàásù: Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n tú sí wàásù túmọ̀ sí “ìpolongo tí òjíṣẹ́ kan ṣe ní gbangba.” Ó tọ́ka sí ọ̀nà tí ẹni náà gbà polongo ọ̀rọ̀ rẹ̀, pé ó sábà máa ń jẹ́: ní gbangba, dípò ìwàásù fún àwùjọ kan.
Ìjọba: ba·si·leiʹa ni ọ̀rọ̀ Gíríìkì tó dúró fún ìjọba tàbí àkóso kan tó ń darí àwọn èèyàn. Ọ̀rọ̀ yìí fara hàn ní ọgọ́jọ ó lé méjì [162] ìgbà nínú Ìwé Mímọ́ ní èdè Gíríìkì. Ìgbà márùnléláàádọ́ta [55] ló fara hàn nínú ìwé Mátíù nìkan, èyí tó pọ̀ jù nínú rẹ̀ ni wọ́n sì lò fún ìṣàkóso Ọlọ́run ní ọ̀run. Mátíù lo ọ̀rọ̀ yìí gan-an débi pé àwọn kan pe ìwé Mátíù ní Ìhìn Rere Ìjọba náà.
Ìjọba ọ̀run: Ọ̀rọ̀ yìí fara hàn nínú Bíbélì ní ọgbọ̀n [30] ìgbà, inú ìwé Ìhìnrere Mátíù nìkan ló sì ti fara hàn Àmọ́ nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere Máàkù àti Lúùkù “ìjọba Ọlọ́run “ ló fara hàn, gbólóhùn yìí dúró fún “ìjọba Ọlọ́run” tó máa ṣàkóso láti ọ̀run tí a kò lè fojú rí.—Mt 21:43; Mk 1:15; Lu 4:43; Da 2:44; 2Ti 4:18.
ti sún mọ́lé: Ọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí pé Olùṣàkóso Ìjọba ọ̀run náà ò ní pẹ́ dé.
nwtsty àwòrán àti fídíò
Aṣọ àti Ìrísí Jòhánù Arinibọmi
Aṣọ tí wọ́n fi irun ràkúnmí ṣe ni Jòhánù máa ń wọ̀, á wá de àmùrè tí wọ́n fi awọ ṣe, tó lè fi gbé àwọn nǹkan kéékèké. Wòlíì Èlíjà náà wọ irú aṣọ yìí. (2Ọb 1:8) Àwọn òtòṣì ló sábà máa ń wọ aṣọ tí wọ́n fi irun ràkúnmí ṣe. Àwọn olówó ló sì máa ń wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ tàbí aṣọ tí wọ́n bá fi sílíìkì ṣe. (Mt 11:7-9) Torí pé Násírì ni Jòhánù látìgbà tí wọ́n ti bí i, ó ṣeé ṣe kò má gé irun rẹ̀ rí. Aṣọ àti ìrísí rẹ̀ fi hàn kedere pé ó jẹ́ kí ohun ìní díẹ̀ tẹ́ òun lọ́rùn, ó sì gbájú mọ́ ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.
Eéṣú
Bó ṣe wà nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ náà “eéṣú” lè túmọ̀ sí tata, èyíkéyìí nínú àwọn tata ló sì lè jẹ́, ì báà jẹ́ èyí tó ní imú kékeré pàápàá, lọ́pọ̀ ìgbà ó tún sábà máa ń tọ́ka sí àwọn èyí tó máa ń rìn lọ́wọ̀ọ̀wọ́. Níbàámú pẹ̀lú àlàyé kan tí wọ́n ṣe ní Jerúsálẹ́mù, èròjà purotéènì sábà máa ń pọ̀ lára àwọn eéṣú tó wà ní aṣálẹ̀. Lóde òní, ṣe làwọn kan máa ń yọ orí, ẹsẹ̀, ìyẹ́, àti ikùn rẹ̀ kúrò lára ẹ̀, kí wọ́n tó jẹ ẹ́. Apá tó ṣẹ́ kù lára rẹ̀, ìyẹn igẹ̀ ni wọ́n máa ń jẹ ní tútù tàbí kí wọ́n sè é. Ó máa ń rí lẹ́nu bí alákàn tàbí edé, ó sì ní èròjà purotéènì nínú gan-an.
Oyin Ìgàn
Ilé tí àwọn kòkòrò oyin kọ́ rèé (1) àti afárá oyin ìgàn (2). Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ara kòkòrò oyin kan tí wọ́n máa ń pè ní Apis mellifera syriaca, ni Jòhánù ti máa ń rí oyin tó ń jẹ torí àwọn ló pọ̀ jù ní àgbègbè yẹn. Apá ibi tó gbóná tó sì gbẹ táútáú lágbègbè Jùdíà ni àwọn oyin yìí ń gbé, èèyàn ò sì lè sìn wọ́n nílé. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún mẹ́sàn-án ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àwọn tó ń gbé ní orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì máa ń tọ́jú kòkòrò oyin sínú ìkòkò amọ̀ tó rí ribiti. Wọ́n rí àwọn ilé oyin kan tó ṣẹ́ kù láàárín ìgboro ìlú kan tí wọ́n pè ní Tel Rehov lóde òní, èyí tó wà ní Àfonífojì Jọ́dánì. Láti ara àwọn kòkòrò oyin kan tí wọ́n ń kó wá láti orílẹ̀-èdè kan tá a wá mọ̀ sí Turkey nísìnyìí ni wọ́n ti rí oyin tó wà nínú ilé oyin yìí.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 1:3
Támárì: Orúkọ obìnrin àkọ́kọ́ nínú àwọn obìnrin márùn-ún, tó fara hàn láàárín àwọn ọkùnrin ìlà ìdílé Mèsáyà tó wà nínú ìwé Mátíù. Àwọn obìnrin mẹ́rin tó kù ni Ráhábù àti Rúùtù, àwọn méjèèjì yìí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì (ẹsẹ 5); Bátí-ṣébà, “aya Ùráyà” (ẹsẹ 6); àti Màríà (ẹsẹ 16). Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ torí pé àwọn nǹkan kan wà tó gbàfíyèsí nípa bí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn obìnrin yìí ṣe di ìyá ńlá Jésù ni orúkọ wọn ṣe fara hàn láàárín àwọn ọkùnrin ìlà ìdílé Jésù.
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 3:11
batisí yín: Tàbí “rì yín bọmi.” Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà ba·ptiʹzo túmọ̀ sí “kì bọ̀; rì bọ̀.” Àwọn ibòmíì nínú Bíbélì fi hàn pé batisí túmọ̀ sí kí wọ́n ri ẹnì kan bọ omi pátápátá. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí Jòhánù lọ ń batisí àwọn èèyàn ní àgbègbè kan ní Àfonífojì Jọ́dánì nítòsí Sálímù “nítorí pé omi púpọ̀ rẹpẹtẹ wà níbẹ̀.” (Joh 3:23) Nígbà tí Fílípì batisí ìwẹ̀fà ara Etiópíà, àwọn méjèèjì “sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú omi.” (Iṣe 8:38) Bí wọ́n ṣe lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì yìí náà nìyẹn nínú Bíbélì Septuagint nínú 2Ọb 5:14 nígbà tí wọ́n ń ṣàlàyé pé Náámánì “ri ara rẹ̀ bọ Jọ́dánì ní ìgbà méje.”
JANUARY 8-14
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | MÁTÍÙ 4-5
“Àwọn Ẹ̀kọ́ Tá A Lè Rí Kọ́ Nínú Ìwàásù Jésù Lórí Òkè”
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 5:3
Aláyọ̀: Ó ju pé kí ara èèyàn yá gágá, bóyá nítorí pé èèyàn ń gbádùn ara rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, tí wọ́n bá lo ọ̀rọ̀ yìí fún èèyàn, ńṣe ló ń tọká sí ìmọ̀lára ẹnì kan tí Ọlọ́run bù kún tó sì ń gbádùn inú rere rẹ̀. Bíbélì tún lo ọ̀rọ̀ yìí láti fi ṣàpèjúwe bí Ọlọ́run àti Jésù ṣe rí nínú ògo wọn lọ́run.—1Ti 1:11; 6:15.
àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn: Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà ‘àwọn tí àìní ń jẹ lọ́kàn,’ túmọ̀ sí “àwọn òtòṣì (aláìní; àwọn tí ebi ń pa; alágbe),” bí wọ́n ṣe lò ó nínú ọ̀rọ̀ yìí fi hàn pé wọ́n sọ̀rọ̀ nípa ẹni tó ṣaláìní tí òun fúnra rẹ̀ sì mọ̀ bẹ́ẹ̀. Ọ̀rọ̀ yìí kan náà ni wọ́n lò fún “alágbe” náà Lásárù nínú Lk 16:20, 22. Àwọn ìtúmọ̀ Bíbélì kan lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà “àwọn òtòṣi ní ẹ̀mí” fún àwọn tó ń dùn gan-an pé àwọn jẹ́ òtòṣì nípa tẹ̀mí tí wọ́n sì nílò ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run.
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 5:7
aláàánú: Bí Bíbélì ṣe máa ń lo ọ̀rọ̀ náà “aláàánú” àti “àánú” kò mọ sórí ìdáríjì tàbí kéèyàn fi àánú hàn tó bá ń ṣèdájọ́ nìkan. Àmọ́, ó tún jẹ́ ká mọ ìyọ́nú àti ojú àánú tó máa ń sún èèyàn láti ran aláìní lọ́wọ́.
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 5:9
ẹlẹ́mìí àlàáfíà: Kì í ṣe àwọn tí wọ́n ń wá àlàáfíà nìkan ló ń tọka sí, àmọ́ ó tún kan àwọn tó ń mú kí àlàáfíà wà níbi tí kò sí àlàáfíà.
Kọ́ Ọmọ Rẹ Láti Jẹ́ Ẹni Àlàáfíà
Àwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni máa ń fẹ́ káwọn ọmọ wọn dẹni tó ‘máa ń wá àlàáfíà, tó sì máa ń lépa rẹ̀.’ (1 Pétérù 3:11) Ó yẹ kí ayọ̀ téèyàn máa ń ní téèyàn bá jẹ́ ẹni àlàáfíà múni sa gbogbo ipá ẹni kéèyàn lè borí ìfura, ìbínú, àti ìkórìíra.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 4:9
jọ́sìn mi lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo: Ọ̀rọ̀ ìṣe Gíríìkì náà “jọ́sìn” jẹ́ atọ́ka ọ̀rọ̀-ìṣe; ó sì tọ́ka sí ohun tó ṣẹlẹ̀ lójú ẹ̀sẹ̀. Torí náà, bí Èṣù ṣe sọ fún Jésù pé “jọ́sìn mi” fi hàn pé kì í ṣe pé ó fẹ́ kó máa jọ́sìn òun lọ, bí kò ṣe pé kó ‘jọ́sìn òun’ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo péré.
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 4:23
ó ń kọ́ni . . . ó sì ń wàásù: Kéèyàn kọ́ni yàtọ̀ sí kéèyàn wàásù, torí pé ohun tí ẹni tó ń kọ́ni máa ṣe wulẹ̀ ju kó kéde lọ; ó máa pèsè ìtọ́ni, á ṣàlàyé, ó máa lo àwọn ọ̀rọ̀ tó ń yíni lérò pa dà, á sì fi ẹ̀rí ti ọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́yìn.
Bíbélì Kíkà
JANUARY 15-21
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | MÁTÍÙ 6-7
“Máa Wá Ìjọba Náà Lákọ̀ọ́kọ́”
ún Mọ́ Ọlọ́run Nípasẹ̀ Àdúrà
12 Àwọn ohun tó kan Jèhófà ló yẹ ká fi ṣáájú nígbà tá a bá ń gbàdúrà. Dájúdájú, ó yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ nítorí gbogbo ohun rere tó ń ṣe fún wa. (1 Kíróníkà 29:10-13) Nínú àdúrà àfiṣàpẹẹrẹ tó wà nínú Mátíù 6:9-13, Jésù kọ́ wa pé ká máa gbàdúrà pé kí orúkọ Ọlọ́run di èyí tá a sọ di mímọ́, ìyẹn ni pé kó di ohun táwọn èèyàn mọ̀ sí ohun mímọ́. (Kà á.) Ohun tí Jésù mẹ́nu kàn tẹ̀ lé e ni pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé, kí ìfẹ́ rẹ̀ sì di èyí tá à ń ṣe lórí ilẹ̀ ayé bíi ti ọ̀run. Ìgbà tó sọ àwọn ohun pàtàkì wọ̀nyí tó kan Jèhófà tán ló tó ṣẹ̀ṣẹ̀ mẹ́nu kan àwọn ohun tó jẹ́ tara ẹni. Táwa náà bá fi Ọlọ́run sí ipò tó ṣe pàtàkì jù nínú àdúrà wa, a óò fi hàn pé ọ̀ràn ara wa nìkan kọ́ ló jẹ́ wa lógún.
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 6:24
sìnrú: Ọ̀rọ̀ ìṣe Gíríìkì yìí túmọ̀ sí ẹrú tó ń ṣiṣẹ́, tó fi hàn pé ọ̀gá kan ló ni onítọ̀hún. Ohun tí Jésù wá ń sọ níbi ni pé èèyàn ò lè sọ pé òun ń ṣiṣẹ́ sin Ọlọ́run lẹ́sẹ̀ kan náà kó tún máa kó nǹkan ìní tara jọ.
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 6:33
Ẹ máa bá a nìṣó . . . ní wíwá: Bí wọ́n ṣe lo ọ̀rọ̀ ìṣe Gíríìkì yìí ń fi hàn pé ohun kan téèyàn ń ṣe lọ ni, a sì tún lè pè é ní “Ẹ máa bá a nìṣó ní wíwá.” Àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù tòótọ́ ò kàn ní wá Ìjọba náà fúngbà díẹ̀, kí wọ́n sì fi í lẹ̀ kí wọ́n lọ máa wá nǹkan míì. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n gbọ́dọ̀ fi sípò àkọ́kọ́ ní ìgbésí ayé wọn.
Ìjọba náà: “Ìjọba Ọlọ́run” ló wà nínú àwọn ìwé Gíríìkì ìpilẹ̀sẹ̀ kan
rẹ̀: Ó túmọ̀ sí Ọlọ́run, ìyẹn ‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run’ tó fara hàn ní Mt 6:32.
òdodo: Àwọn tó ń wá òdodo Ọlọ́run ni àwọn tó ti ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́ tí wọ́n sì ń pa òfin rẹ̀ mọ́ nípa ojú tó fi ń wo àwọn ohun tó tọ́ àti èyí tí kò tọ́. Ẹ̀kọ́ yìí yàtọ̀ pátápátá sí ti àwọn Farisí, torí òdodo ti ara wọn ni àwọn Farisí máa ń wá.—Mt 5:20.
Máa Wá Ìjọba Ọlọ́run, Má Ṣe Wá Àwọn Nǹkan
18 Ka Mátíù 6:33. Àwa ọmọ ẹ̀yìn Kristi gbọ́dọ̀ máa fi Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wa. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, Jésù sọ pé, ‘gbogbo nǹkan mìíràn ni a ó fi kún un fún wa.’ Kí nìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀? Ó ní: “Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run mọ̀ pé ẹ nílò gbogbo nǹkan wọ̀nyí,” ìyẹn àwọn ohun kòṣeémáàní ìgbésí ayé. Jèhófà mọ ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa nílò, kódà kí àwa fúnra wa tó mọ̀ pé a máa nílò wọn. Jèhófà mọ̀ pé a nílò oúnjẹ, aṣọ àti ilé. (Fílí. 4:19) Ó mọ àwọn aṣọ wa tí kò ní pẹ́ gbó. Ó mọ irú oúnjẹ tá a nílò àti irú ilé tó máa tu àwa àti ìdílé wa lára. Ó dájú pé Jèhófà máa bójú tó gbogbo àwọn nǹkan tá a nílò ní ti gidi.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Máa Fi Ìlànà Pàtàkì Náà Sílò Lóde Ẹ̀rí
14 Rò ó wò ná, ká sọ pé lọ́jọ́ kan ni ẹnì kan tá ò mọ̀ rí ṣàdédé pè wá lórí fóònù. Lẹni tá ò mọ̀ rí yìí bá ń bi wá léèrè irú oúnjẹ tá a fẹ́ràn. Ńṣe ni a ó máa ronú ẹni tí onítọ̀hún lè jẹ́ àti ohun tó fẹ́ gan-an. Torí pé a bọ̀wọ̀ fún onítọ̀hún, a lè bá a sọ̀rọ̀ díẹ̀, àmọ́ ó ṣeé ṣe ká wá ọ̀nà tá a fi máa jẹ́ kó mọ̀ pé a ò ní fẹ́ máa bá ìjíròrò náà lọ. Ṣùgbọ́n, jẹ́ ká sọ pé onítọ̀hún dárúkọ ara rẹ̀, ó sọ fún wa pé ilé iṣẹ́ tó ń bójú tó ọ̀rọ̀ oúnjẹ lòun ti ń ṣiṣẹ́, tó sì rọ̀ wá pé ká tẹ́tí sí ìsọfúnni kan tó máa ṣe wá láǹfààní tí òun fẹ́ sọ fún wa. Ó ṣeé ṣe ká fara balẹ̀ tẹ́tí sí i. Ó ṣe tán, a máa ń mọyì rẹ̀ nígbà táwọn èèyàn bá sọ ẹni tí wọ́n jẹ́ àtohun tí wọ́n fẹ́, tí wọ́n sì fi ọ̀wọ̀ wọ̀ wá. Báwo làwa náà ṣe lè hu irú ìwà ọmọlúwàbí yìí nígbà tá a bá bá àwọn èèyàn pàdé lóde ẹ̀rí?
15 Ní ọ̀pọ̀ ibi láyé, ó ṣe pàtàkì ká jẹ́ kí onílé tètè mọ ìdí tá a fi wá sọ́dọ̀ rẹ̀. A gbà pé ẹni tá a fẹ́ wàásù fún lè má mọ̀ pé ohun tó máa ṣe òun láǹfààní la tìtorí rẹ̀ wá, àmọ́ ṣe kò ní kù díẹ̀ káàtó, tó bá jẹ́ pé a ò dárúkọ ara wa àti ìdí tá a fi wá, tá a sì wá ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Tó o bá lágbára láti yanjú àwọn ìṣòro tó wà láyé yìí, èwo lo máa kọ́kọ́ yanjú níbẹ̀?” A mọ̀ pé torí ká lè mọ èrò rẹ̀ la ṣe béèrè irú ìbéèrè yẹn, a sì fẹ́ kó mọ ohun tí Bíbélì sọ. Ṣùgbọ́n, ó lè máa ronú pé: ‘Ta ni àjèjì tí mi ò mọ̀ rí tó wá ń da ìbéèrè bò mí yìí? Kí ló pa èmi àtiẹ̀ pọ̀?’ Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa sọ̀rọ̀ lọ́nà táá mú kí ara tu àwọn tá à ń wàásù fún. (Fílí. 2:3, 4) Báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?
16 Ohun kan wà tí alábòójútó arìnrìn-àjò kan máa ń ṣe tó ń mú kí ara tu àwọn èèyàn. Ohun tó máa ń ṣe ni pé lẹ́yìn tí òun àti ẹni tó fẹ́ wàásù fún bá ti kíra, á fún un ní ẹ̀dà ìwé àṣàrò kúkúrú náà, Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Òtítọ́? Lẹ́yìn náà, á wá sọ pé: “Gbogbo èèyàn tó wà lágbègbè yìí là ń fún ní ìwé yìí lónìí. Ó jíròrò ìbéèrè mẹ́fà tí ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń béèrè. Ẹ̀dà tìrẹ rèé.” Arákùnrin yìí sọ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ni ara máa ń tù gbàrà tí òun bá ti jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tí òun bá wá. Tí ara bá ti tù wọ́n, ó sábà máa ń rọrùn láti bá wọn jíròrò. Ìbéèrè míì tí alábòójútó arìnrìn-àjò náà á bi onítọ̀hún ni pé: “Ǹjẹ́ o ti ronú nípa èyíkéyìí lára àwọn ìbéèrè yìí rí?” Tó bá yan ọ̀kan lára àwọn ìbéèrè náà, arákùnrin yìí á ṣí ìwé àṣàrò kúkúrú náà, á wá bá a jíròrò ohun tí Bíbélì sọ nípa ìbéèrè náà. Bí kò bá sì tọ́ka sí èyíkéyìí lára ìbéèrè náà, arákùnrin náà á yan ọ̀kan lára àwọn ìbéèrè náà, á sì máa bá ìjíròrò lọ láìdójú ti ẹni tó ń wàásù fún. Àmọ́ o, ọ̀pọ̀ ọ̀nà ló wà téèyàn lè gbà bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀. Láwọn ibì kan, ẹni tá à ń wàásù fún lè retí pé ká béèrè ọkọ, aya, ọmọ àtàwọn aráalé ká tó sọ ohun tá a bá wá. Kókó ibẹ̀ ni pé kéèyàn mọ ohun tí àwọn tó wà lágbègbè ibi tó ti ń wàásù fẹ́, kéèyàn sì hùwà bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́.
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 7:28, 29
háà ń ṣe ogunlọ́gọ̀: Ọ̀rọ̀ ìṣe Gíríìkì tí wọ́n lò níbí tún lè túmọ̀ sí pé “ẹnu yà wọn débi pé wọn ò mọ ohun tí wọ́n lè sọ.” Ọ̀rọ̀ ìṣe tó ń bá a lọ tí wọ́n lò fi hàn pé ọ̀rọ̀ tí wọ́n gbọ́ náà nípà lórí wọn fún àkókò gígùn.
ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀: Gbólóhùn yìí túmọ̀ sí bí Jésù ṣe máa ń kọ́ni, ọ̀nà tó ń gbà kọ́ni, ìyẹn ohun tó ń kọ́ àwọn èèyàn, bí àwọn ìtọ́ni tó pèsè nínú ìwàásù rẹ̀ lórí òkè.
kì í ṣe bí àwọn akọ̀wé òfin wọn: Ó jẹ́ àṣà àwọn akọ̀wé òfin tí wọ́n bá ń kọ́ni láti máa ṣe àyọkà ọ̀rọ̀ àwọn rábì kí wọ́n lè fìdí ẹ̀kọ́ wọn múlẹ̀, àmọ́ ńṣe ni Jésù bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ bí ẹni tó ń ṣojú fún Jèhófà àti bí ẹni tó ní ọlá àṣẹ, àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ sì dá lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.—Joh 7:16.
Bíbélì Kíkà
JANUARY 22-28
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | MÁTÍÙ 8-9
“Jésù Fẹ́ràn Àwọn Èèyàn”
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 8:3
ó fọwọ́ kàn án: Òfin Mósè sọ pé kí wọ́n ya àwọn adẹ́tẹ̀ sọ́tọ̀ kúrò láàárín àwọn aráàlú, kí wọ́n má bàa kó àìsàn ran àwọn èèyàn. (Le 13:45, 46; Nu 5:1-4) Síbẹ̀, àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù tún fi àwọn òfin míì kún un. Bí àpẹẹrẹ, téèyàn bá tiẹ̀ máa wà nítòsí adẹ́tẹ̀ kan, ó gbọ́dọ̀ jìnnà sí i ní ó kéré tán nǹkan bí ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin ìyẹn ẹsẹ̀ bàtà mẹ́fà, tó bá wá jẹ́ àsìkò tí ẹ̀fúùfù ń fẹ́, èèyàn gbọ́dọ̀ jìnnà sí i tó ọgọ́rùn-ún [100] ìgbọ̀nwọ́, ìyẹn àádọ́jọ [150] ẹsẹ̀ bàtà. Àṣà yìí mú kí nǹkan le fún àwọn adẹ́tẹ̀ torí pé ó ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún àwọn rábì tí kì í fẹ́ sí nítòsí àwọn adẹ́tẹ̀ rárá, ó sì tún ṣí àyè sílẹ̀ fún àwọn tó máa ń sọ àwọn adẹ́tẹ̀ lókùúta kí wọ́n lè lé wọn jìnnà. Àmọ́ ti Jésù yàtọ̀, ó dùn ún dọ́kàn nígbà tó rí irú ipò tí àwọn adẹ́tẹ̀ wà, débi pé ó ṣe ohun tí àwọn Júù ò gbà pé ó ṣeé ṣe, ó fọwọ́ kan ọkùnrin náà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù lè sọ ọ̀rọ̀ kan péré kí ara adẹ́tẹ̀ náà sì yá, àmọ́ ó fọwọ́ kàn án.—Mt 8:5-12.
Mo fẹ́ bẹ́ẹ̀: Jésù ò kàn ṣe ohun tí adẹ́tẹ̀ yẹn fẹ́ nìkan, àmọ́ ó tún fi hàn pé ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ òun lógún, ó sì wu òun lá ti ràn án lọ́wọ́.
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 9:10
rọ̀gbọ̀kú nídìí tábìlì: tàbí “jókòó sídìí tábìlì.” Tí èèyàn bá jókòó ti ẹnìkan nídìí tábìlì. Ó fi hàn pé èèyàn sún mọ́ onítọ̀hún nìyẹn. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, nígbà ayé Jésù, àwọn Júù ò jẹ́ jókòó sídìí tábìlì tàbí jẹun pọ̀ pẹ̀lú àwọn tí kì í ṣe Júù.
àwọn agbowó orí: Ọ̀pọ̀ àwọn Júù ló máa ń bá àwọn aláṣẹ ìjọba Róòmù gba owó orí. Àwọn èèyàn kórìíra irú àwọn Júù bẹ́ẹ̀ gan-an torí pé yàtọ̀ sí pé wọ́n ń lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú àwọn aláṣẹ ilẹ̀ òkèèrè tí wọ́n kò nífẹ̀ẹ́ sí, wọ́n tún máa ń gbà ju iye owó orí tó yẹ kí wọ́n gbà lọ. Àwọn Júù ẹgbẹ́ wọn ò gba ti àwọn agbowó orí yìí, ojú kan náà ni wọ́n fi ń wò wọ́n pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ àtàwọn aṣẹ́wó.—Mt 11:19; 21:32.
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 9:36
àánú wọn ṣe é: Ọ̀rọ̀ ìṣe Gíríìkì náà splag·khniʹzo·mai tí wọ́n lò fún ọ̀rọ̀ yìí tan mọ́ ọ̀rọ̀ tí wọ́n máa ń lò fún “ìfun” (splagʹkhna) láti fi bí ọ̀rọ̀ ṣe rí hàn nínú èèyàn lọ́hùn-ún, ìmọ̀lára àtinúwá. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀rọ̀ Gíríìkì tó lágbára jù lọ tí wọ́n máa ń lò fún àánú.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
“Mo Fi Àwòṣe Lélẹ̀ Fun Yín”
16 Bákan náà, nígbà tí ọ̀gá ẹgbẹ́ ọmọ ogun kan—tó ṣeé ṣe kó jẹ́ Kèfèrí, ará Róòmù—wá sọ́dọ̀ Jésù, tó ń bẹ̀ ẹ́ pé kó mú ẹrú òun tó ń ṣàìsàn lára dá. Jésù mọ̀ pé sójà náà ní àwọn ìkùdíẹ̀-káàtó tirẹ̀. Ó ṣeé ṣe kí ẹnì kan tó jẹ́ ọ̀gá ẹgbẹ́ ọmọ ogun ayé ìgbà yẹn ti lọ́wọ́ nínú onírúurú ìwà ipá, kó ti tàjẹ̀ sílẹ̀, kó tiẹ̀ ti jọ́sìn ọlọ́run èké pàápàá. Síbẹ̀, ànímọ́ rere tó ní ni Jésù darí àfiyèsí sí—ìyẹn ìgbàgbọ́ àrà ọ̀tọ̀ tí ọkùnrin náà ní. (Mátíù 8:5-13) Lẹ́yìn ìyẹn, nígbà tí Jésù ń bá aṣebi tí wọ́n gbé kọ́gi lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀, kò bá ọkùnrin náà wí nítorí jíjẹ́ tí ó jẹ́ arúfin tẹ́lẹ̀, àmọ́ ó lo ìrètí ọjọ́ iwájú láti fún un níṣìírí. (Lúùkù 23:43) Jésù mọ̀ pé níní èrò òdì nípa àwọn ẹlòmíràn, ká máa ṣe lámèyítọ́ wọn yóò wulẹ̀ kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wọn ni. Kò sí àní-àní pé bó ṣe ń sapá láti wo ànímọ́ rere tó wà lára àwọn èèyàn yóò ran ọ̀pọ̀ lọ́wọ́ láti túbọ̀ sunwọ̀n sí i.
jy 70 ¶6
Kí Nìdí Tí Àwọn Ọmọ Ẹ̀yìn Jésù Kì í Fi Gbààwẹ̀?
Jésù ń ran àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jòhánù Arinibọmi lọ́wọ́ láti rí i pé kò yẹ káwọn èèyàn máa retí pé kí àwọn ọmọlẹ́yìn òun tún pa dà máa ṣe ohun tí wọ́n ti fi sílẹ̀ nínú ìsìn àwọn Júù, bí ààtò ààwẹ̀. Jésù kò wá láti wá mú ìjọsìn yẹn sunwọ̀n sí i, torí pé ọ̀nà ìjọsìn yẹn ti díbàjẹ́ pátápátá kọjá àtúnṣe. Jésù kò gba ẹnikẹ́ni nímọ̀ràn láti máa tẹ̀ lé ìjọsìn àwọn Júù àti àṣà wọn. Torí pé ńṣe ni ìyẹn á dà bí ìgbà tí èèyàn rán aṣọ tuntun mọ́ aṣọ tó ti gbó tàbí tí èèyàn bu wáìnì tuntun sínú awọ wáìnì tó ti gbó.
Bíbélì Kíkà
JANUARY 29–FEBRUARY 4
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | MÁTÍÙ 10-11
“Jésù Mú Kí Ara Tù Wá”
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 10:29, 30
ológoṣẹ́: Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà strou·thiʹon túmọ̀ sí ẹyẹ tó kére gan-an, àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà ológoṣẹ́ ni wọ́n sábà máa fi ń tọ́ka sí, òun ni owó rẹ̀ sì kére jù lọ nínú gbogbo ẹyẹ táwọn èèyàn ń rà jẹ.
ní ẹyọ owó kan tí ìníyelórí rẹ̀ kéré: Ní olówuuru ó túmọ̀ sí ẹyọ owó “assarion,” ìyẹn iye owó téèyàn máa gba tó bá ṣe iṣẹ́ fún iṣẹ́jú márùn-dín-láàádọ́ta [45]. (Wo App. B14.) Ní àkókò yìí tí Jésù ń rin ìrìn àjò rẹ̀ lọ sí Gálílì ní ẹ̀ẹ̀kẹta, Jésù sọ pé owó assarion kan ni wọ́n fi máa ń ra ológoṣẹ́ méjì. Ní àkókò míì, ìyẹn nǹkan bí ọdún kan lẹ́yìn tó ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ní Jùdíà, Jésù sọ pé èèyàn lè fi ìlọ́po méjì owó yìí ra ológoṣẹ́ márùn-ún. (Lk 12:6) Tá a bá gbé àwọn ohun tó sọ yìí yẹ̀ wò síra, àá kíyèsí pé àwọn ológoṣẹ́ yìí ò níye lórí rárá, débi pé ńṣe ni àwọn tó ń tà á máa ń fi ẹyọ kan ṣe èènì fún àwọn tó bá fẹ́ rà á ní owó assarion méjì.
gbogbo irun orí yín gan-an ni a ti kà: Tá a bá fojú bù ú, iye irun orí èèyàn á tó ọgọ́rùn-ún lọ́nà ẹgbẹ̀rún kan [100,000]. Bí Jèhófà ṣe mọ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn bí wọ́n ṣe kéré tó yẹn fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé ọ̀rọ̀ àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi kọ̀ọ̀kan jẹ ẹ́ lógún.
nwtsty àwòrán àti fídíò
Ológoṣẹ́
Ológoṣẹ́ ni ẹyẹ́ tí ìníyelórí rẹ̀ kéré jù lọ nínú gbogbo ẹyẹ táwọn èèyàn ń rà jẹ. Èèyàn lè fi owó iṣẹ́ iṣẹ́jú márùn-dín-láàádọ́ta [45] ra méjì. Wọ́n tún máa ń lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n ń lò fún un fún àwọn ẹyẹ kéékèèké mìíràn tó fi mọ́ àwọn ẹyẹ ológoṣẹ́ tó ṣe é sìn nílé (Passer domesticus biblicus) àti ẹyẹ ológoṣẹ́ ti ilẹ̀ Sípáníìṣì (Passer hispaniolensis), ìyẹn sì pọ̀ ní Ísírẹ́lì títí dòní.
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 11:28
di ẹrù wọ̀ lọ́rùn: Àwọn tí Jésù rọ̀ pé kí wọ́n wá sọ́dọ̀ òun ni àwọn tí àníyàn àti làálàá ti “di ẹrù wọ̀ lọ́rùn.” Ìjọsìn wọn sí Jèhófà ti di ẹrù ìnira torí àwọn òfin àtọwọ́dọ́wọ́ tí wọ́n ti fi kún Òfin Mósè. (Mt 23:4) Kódà, Sábáàtì tó yẹ kó jẹ́ àsìkò ìtura ti di ìnira.—Ek 23:12; Mk 2:23-28; Lk 6:1-11.
èmi yóò sì tù yín lára: Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n lò fún ‘tura’ lè dúró fún sinmi (Mt 26:45; Mk 6:31) àti ìtura téèyàn ní kúrò nínú làálàá tó ṣe kó lè kọ́fẹ́ tàbí jèrè okun pa dà (2Kọ 7:13; Flm 7). Àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ lẹ́yìn ìgbà yẹn fi hàn pé ẹni tó bá máa gba “àjàgà” Jésù máa ṣiṣẹ́ kì í ṣe pé á kàn máa sinmi (Mt 11:29). Ọ̀rọ̀ ìṣe Gíríìkì yìí tó ń sọ̀rọ̀ nípa Jésù fi hàn pé Jésù máa mú kí àwọn tó ti rẹ̀ kọ́fẹ pa dà kí wọ́n sì rí okun gbà pa dà kí wọ́n bàa lè gba àjàgà rẹ̀ tó fúyẹ́ tó sì jẹ́ ti inú rere.
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 11:29
Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín: Jésù lo “àjàgà” láti fi ṣàpèjúwe ìgbà tí èèyàn bá gba ẹnìkan ní aláṣẹ tàbí tó gba ìtọ́sọ́nà rẹ̀. Tó bá jẹ́ pé àjàgà méjì irú èyí tí Ọlọ́run gbé lé Jésù ni ó ní lọ́kàn, á jẹ́ pé ṣe ló ń pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n wá ran òun lọ́wọ́ kí òun àtiwọn lè jọ gbé àjàgà yẹn. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, ohun tí gbólóhùn yẹn ì bá jẹ́ rèé: “Ẹ jẹ́ ká jọ wà lábẹ́ àjàgà mi.” Àmọ́ tó bá jẹ́ àjàgà tí Jésù ń gbè fún àwọn èèyàn ni, á jẹ́ pé ohun tí ìyẹn túmọ̀ sí ni pé gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹ̀yìn Kristi, a gbà á ní aláṣẹ, a sì máa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà rẹ̀.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
jy 96 ¶2-3
Jòhánù Fẹ́ Gbọ́ Láti Ẹnu Jésù
Ṣé ìbéèrè yẹn ò ṣàjèjì? Ẹni tó ń fi tọkàntọkàn sin Ọlọ́run ni Jòhánú, nígbà tó ń ṣèrìbọmi fún Jésù ní nǹkan bí ọdún méjì sẹ́yìn, ó rí bí ẹ̀mí mímọ́ ṣe bà lé Jésù, ó sì tún gbọ́ tí Ọlọ́run sọ pé òun ti tẹ́wọ́ gbà á. Kò sídìí fún wa láti ronú pé ìgbàgbọ́ jòhánù ti jó rẹ̀yìn. Tí ọ̀rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀ lóòótọ́, Jésù ò ní sọ àwọn ọ̀rọ̀ amóríyá nípa Jòhánù irú èyí tó sọ nígbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí wáyé. Síbẹ̀ nígbà tí Jòhánù ò ṣiyèméjì, kí ló wá fà á tó fi fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ láti ẹnu Jésù.
Jòhánù lè fẹ́ kí Jésù fi ẹnu ara rẹ̀ sọ fún òun pé, òun ni Mèsáyà. Èyí máa fún Jòhánù lókun bó ṣe ń jìyà nínú ẹ̀wọ̀n. Ìbéèrè tí Jòhánù sì béèrè mọ́gbọ́n dání lóòótọ́. Ó mọ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó sọ pé Ẹni Àmì-Òróró Ọlọrun máa jẹ́ ọba àti olùgbàlà. Àmọ́, lẹ́yìn ọ̀pọ̀ oṣù tí Jésù ṣèrìbọmi ni wọ́n fi Jòhánù sẹ́wọ̀n. Torí náà, Jòhánù ń béèrè bóyá ẹlòmíì máa wà tó ń bọ̀ lẹ́yìn Jésù tí gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ tó ti wà nílẹ̀ nípa Mèsáyà máa ṣẹ sí lára.
jy 98 ¶1-2
Ó Ké Ègbé fún Ìran Burúkú Kan
Èèyàn pàtàkì ni Jésù ka Jòhánù arinibọmi sí, àmọ́ irú ojú wo ni ọ̀pọ̀ fi ń wo Jòhánù? Jésù sọ pé: “Ìran yìí dà bí àwọn ọmọ kéékèèké tí wọ́n jókòó ní àwọn ibi ọjà, tí wọ́n ń ké jáde sí àwọn alájùmọ̀-ṣeré wọn, pé, ‘Àwa fọn fèrè fún yín, ṣùgbọ́n ẹ kò jó; àwa pohùn réré ẹkún, ṣùgbọ́n ẹ kò lu ara yín nínú ẹ̀dùn-ọkàn.’ ”—Mátíù 11:16, 17.
Kí ni jésù ní lọ́kàn? Ó ṣàlàyé ohun tó ní lọ́kàn pé: “Jòhánù wá, kò jẹ bẹ́ẹ̀ ni kò mu, síbẹ̀ àwọn ènìyàn sọ pé, ‘Ó ní ẹ̀mí èṣù’; Ọmọ ènìyàn sì wá, ó ń jẹ, ó sì ń mu, síbẹ̀ àwọn ènìyàn sọ pé, ‘Wò ó! Ọkùnrin kan tí ó jẹ́ alájẹkì, tí ó sì fi ara rẹ̀ fún mímu wáìnì, ọ̀rẹ́ àwọn agbowó orí àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.’ ” (Mátíù 11:18, 19) Ìyẹn ni pé gẹ́gẹ́ bíi Násírì, Jòhánù jẹ́ kí ohun ìní díẹ̀ tẹ́ ẹ lọ́rùn, kì í mu wáínì, síbẹ̀ ìran yìí sọ pé ó ní ẹ̀mí èṣù. (Númérì 6:2, 3; Lúùkù 1:15) Lẹ́sẹ̀ kan náà, Jésù gbé ìgbé ayé rẹ̀ bíi tàwọn èèyàn tó kù. Ó ń jẹ ó sì ń mu níwọ̀ntúnwọ̀nsì síbẹ̀ àwọn èèyàn fẹ̀sùn kàn án pé alájẹkì ni. Ṣe ló dà bíi pé àwọn èèyàn náà kò ṣeé tẹ́ lọ́rùn.