ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • lv orí 4 ojú ìwé 36-49
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Bọ̀wọ̀ Fáwọn Aláṣẹ?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Bọ̀wọ̀ Fáwọn Aláṣẹ?
  • ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ÌDÍ TÓ FI ṢÒROÓ ṢE
  • KÍ NÌDÍ TÓ FI YẸ KÁ MÁA BỌ̀WỌ̀ FÁWỌN ALÁṢẸ?
  • BÁ A ṢE LÈ FỌ̀WỌ̀ HÀN NÍNÚ ÌDÍLÉ
  • BÁ A ṢE LÈ FỌ̀WỌ̀ HÀN NÍNÚ ÌJỌ
  • BÁ A ṢE LÈ BỌ̀WỌ̀ FÁWỌN ALÁṢẸ ÌLÚ
  • Ẹ Máa Bọlá Fún Àwọn Tó Ní Ọlá Àṣẹ Lórí Yín
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Ojú-Ìwòye Kristian Nípa Ọlá-Àṣẹ
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Máa Tẹ̀ Lé Àṣẹ Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ọ̀wọ̀ Fáwọn Aláṣẹ—Èé Ṣe Tó Fi Ṣe Kókó?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
Àwọn Míì
‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’
lv orí 4 ojú ìwé 36-49
Bàbá kan ń kọ́ ìdílé rẹ̀

ORÍ 4

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Bọ̀wọ̀ Fáwọn Aláṣẹ?

“Ẹ máa bọlá fún onírúurú ènìyàn gbogbo.”—1 PÉTÉRÙ 2:17.

1, 2. (a) Kí nìdí tó fi máa ń ṣòro fún wa láti bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ? (b) Àwọn ìbéèrè wo la fẹ́ gbé yẹ̀ wò báyìí?

ǸJẸ́ o ti ṣàkíyèsí ohun tí ọmọ kékeré kan ṣe nígbà táwọn òbí ẹ̀ ní kó ṣe ohun kan tí kò wù ú? Ó ṣeé ṣe kó o rí i pé ńṣe lọmọ náà rúnjú pọ̀. Ó gbọ́ ohùn bàbá rẹ̀, ó sì mọ̀ pé ó yẹ kóun pa àṣẹ bàbá òun mọ́. Àmọ́, pẹ̀lú bọ́rọ̀ ṣe rí lára rẹ̀ yìí, kò kàn ṣáà fẹ́ ṣe nǹkan yẹn ni. Ká sòótọ́, báwa náà ṣe máa ń ṣe nígbà míì nìyẹn.

2 Kì í fi gbogbo ìgbà rọrùn láti bọ̀wọ̀ fáwọn tó wà nípò àṣẹ. Ṣáwọn ìgbà kan wà tó máa ń ṣòro fún ẹ láti bọ̀wọ̀ fáwọn tó láṣẹ lórí ẹ dé ìwọ̀n àyè kan? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, kì í ṣèwọ nìkan lọ̀ràn náà kàn. Àkókò tí bíbọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dàwátì là ń gbé. Síbẹ̀, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé a gbọ́dọ̀ máa bọ̀wọ̀ fáwọn tó láṣẹ lé wa lórí. (Òwe 24:21) Ká sòótọ́, a ò lè sọ pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tá ò bá bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ. Ó di dandan ká bi ara wa léèrè pé: Kí nìdí tó fi máa ń ṣòro fún wa láti bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ? Kí nìdí tí Jèhófà fi ní ká máa bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ, kí ló sì lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣègbọràn sí Jèhófà? Paríparì ẹ̀ ni pé, àwọn ọ̀nà wo la lè gbà fi hàn pé à ń bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ?

ÌDÍ TÓ FI ṢÒROÓ ṢE

3, 4. Báwo ni ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé ṣe bẹ̀rẹ̀, kí sì nìdí tí àìpé fi máa ń mú kó ṣòro fún wa láti bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ?

3 Ẹ jẹ́ ká wo ìdí méjì tó fi lè ṣòro fún wa láti bọ̀wọ̀ fáwọn tó wà nípò àṣẹ. Àkọ́kọ́ ni pé, àìpé ẹ̀dá ń dà wá láàmú, èkejì sì ni pé àìpé kan náà ò yé da àwọn tó wà nípò àṣẹ láàmú. Ọjọ́ ti pẹ́ tí ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé ti bẹ̀rẹ̀, ìyẹn nígbà tí Ádámù àti Éfà ṣọ̀tẹ̀ sí àṣẹ Ọlọ́run lọ́gbà Édẹ́nì. Èyí fi hàn pé ọ̀tẹ̀ ló bí ẹ̀ṣẹ̀. Látìgbà yẹn títí di bá a ṣe ń sọ̀rọ̀ yìí, ìfẹ́ láti ṣòtẹ̀ máa ń wà lọ́kàn wa ṣáá.—Jẹ́nẹ́sísì 2:15-17; 3:1-7; Sáàmù 51:5; Róòmù 5:12.

4 Nítorí pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wá, ìgbéraga àti ẹmi àwa la wà ńbẹ̀, máa ń tètè wọ̀ wá lẹ́wù, àmọ́ tó bá di pé ká jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ekukáká la fi ń ṣèyẹn, àfi ká ṣiṣẹ́ kára ká sì gbìyànjú láti ní in. Tá a bá tiẹ̀ ti jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run láti àwọn ọdún yìí wá pàápàá, tá ò bá sọ́ra, ó ṣeé ṣe ká di alágídí ká sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbéra ga. Fi àpẹẹrẹ ti Kórà ṣe àríkọ́gbọ́n; ó fòótọ́ inu dúró ti àwọn èèyàn Jèhófà nígbà ìṣòro. Síbẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí wá ipò ńlá fún ara rẹ̀, àìnítìjú ẹ̀ sì sún un láti ṣọ̀tẹ̀ sí Mósè ẹni tó jẹ́ ọlọ́kàn-tútù jù lọ nígbà ayé ẹ̀. (Númérì 12:3; 16:1-3) Tún ronú lórí ohun tí Ùsáyà Ọba ṣe, ìgbéraga ló jẹ́ kó wọ tẹ́ńpìlì lọ láti ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ tó jẹ́ ojúṣe àwọn àlùfáà. (2 Kíróníkà 26:16-21) Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí jẹ palaba ìyà nítorí ìwà ọ̀tẹ̀ tí wọ́n hù. Síbẹ̀, ẹ̀kọ́ àti ìránnilétí ni ìwàkiwà tí wọ́n hù jẹ́ fún gbogbo wa. A ní láti borí ìgbéraga tó ń jẹ́ kó ṣòro fún wa láti bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ.

5. Báwo làwọn ẹ̀dá aláìpé ṣe ṣi ipò wọn lò?

5 Yàtọ̀ síyẹn, ìwà táwọn ẹ̀dá aláìpé tó wà ní ipò àṣẹ máa ń hù tún ń jẹ́ kó ṣòro fáwọn èèyàn láti bọ̀wọ̀ fún wọn. Ọ̀pọ̀ nínú wọn ló rorò bí ataare, wọ́n ṣàìdáa sáwọn èèyàn, wọn ò sì gba tẹlòmíì rò rárá. Àní, ìtàn ti fi hàn pé ọ̀pọ̀ ló ti lo agbára wọn nílòkulò. (Ka Oníwàásù 8:9) Bí àpẹẹrẹ, ẹni rere ni Sọ́ọ̀lù, onírẹ̀lẹ̀ èèyàn sì ni nígbà tí Jèhófà fi í jọba. Àmọ́, ó jẹ́ kí owú àti ìgbéraga wọ òun lẹ́wù; ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í fòòró Dáfídì, ọkùnrin olóòótọ́ yẹn. (1 Sámúẹ́lì 9:20, 21; 10:20-22; 18:7-11) Láìpẹ́ sígbà yẹn ni Dáfídì jọba, ó sì wá wà lára àwọn ọba tó ṣe dáadáa jù ní Ísírẹ́lì, àmọ́ òun náà ṣi agbára rẹ̀ lò. Ó fèrú gba ìyàwó Ùráyà ará Hítì, ó sì ní kí wọ́n fi ọkùnrin aláìmọwọ́ mẹsẹ̀ yìí síbi tí ogun tí gbóná janjan kó lè kú sójú ogun. (2 Sámúẹ́lì 11:1-17) Bó ṣe máa ń rí nìyẹn, àìpé ẹ̀dá ni kì í jẹ́ kí wọ́n ṣe ohun tó tọ́ bí wọ́n bá wà nípò. Táwọn tó wà nípò ò bá tún lọ bọ̀wọ̀ fún Jèhófà, ṣe ni nǹkan máa bà jẹ́ ráúráú. Nígbà tí àgbà òṣèlú kan nílùú Britain ń ṣàlàyé báwọn póòpù Kátólíìkì ṣe ń fìyà jẹ àwọn èèyàn nílé lóko, ó ní: “Ńṣe nipò máa ń gunni, bá a bá sì gbé èèyàn sípò, gàràgàrà nipò á máa gùn-ún.” Pẹ̀lú òótọ́ ọ̀rọ̀ yìí lọ́kàn wa, ẹ jẹ́ ká wá ṣàlàyé ìdí tó fi yẹ ká máa bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ.

KÍ NÌDÍ TÓ FI YẸ KÁ MÁA BỌ̀WỌ̀ FÁWỌN ALÁṢẸ?

6, 7. (a) Kí ni ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà ń sún wa láti ṣe, kí sì nìdí tọ́ràn fi rí bẹ́ẹ̀? (b) Kí ló túmọ̀ sí láti máa tẹrí ba, báwo la sì ṣe lè fi hàn pé à ń ṣe bẹ́ẹ̀?

6 Ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà, tá a ní sáwọn ọmọnìkejì wa àtèyí tá a ní sára wa ni olórí ìdí tó fi yẹ ká máa bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, a fẹ́ múnú Jèhófà dùn torí pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. (Ka Òwe 27:11; Máàkù 12:29, 30) A mọ̀ dájú pé látìgbà tí Sátánì ti ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà lọ́gbà Édẹ́nì, tí ọ̀pọ̀ tó ń tẹ̀ lé e sì ti pa ìṣàkóso Jèhófà tì, ni ìbéèrè ti wà nípa bóyá Jèhófà gan-an laláṣẹ àgbáyé àti pé bóyá ó tiẹ̀ lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso ayé. Àmọ́, a láyọ̀ láti kọ́wọ́ ti ipò tí Jèhófà wà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ. Tọkàntọkàn la fi máa fẹ́ ṣe ti Jèhófà tá a bá ka àwọn ọ̀rọ̀ tó fakíki tó wà nínú Ìṣípayá 4:11. Ó dá wa lójú gbangba gbàǹgbà pé Jèhófà gan-an ló lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ Olùṣàkóso àgbáyé! À ń fi hàn nínú ìwà wa ojoojúmọ́ pé a fọwọ́ sí ìṣàkoso Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ.

7 Ọ̀wọ̀ tá a ní fún Ọlọ́run yìí yẹ kó sún wa láti ṣègbọràn sí i, ká sì tún ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà ló jẹ́ kó máa yá wa lára láti gbọ́ràn sí i lẹ́nu. Síbẹ̀, àwọn ìgbà kan máa ń wà tó máa ń ṣòro fún wa láti ṣègbọràn. Bó bá wá rí bẹ́ẹ̀, bíi ti ọmọ kékeré tá a mẹ́nu kàn lẹ́ẹ̀kan, àwa náà ní láti kọ́ bá a ṣe lè máa tẹrí ba. Ẹ jẹ́ ká rántí pé Jésù pàápàá ṣe ìfẹ́ inú Baba rẹ̀ nígbà tí kò rọrùn fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ó sọ fún Baba rẹ̀ pé: “Kì í ṣe ìfẹ́ mi ni kí ó ṣẹ, bí kò ṣe tìrẹ.”—Lúùkù 22:42.

8. (a) Kí ni títẹríba fún àṣẹ Jèhófà sábà máa ń túmọ̀ sí lóde òní, kí ló sì jẹ́ ká mọ ojú tí Jèhófà fi ń wò ó? (b) Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti fetí sí ìmọ̀ràn ká sì gba ìbáwí? (Wo “Fetí Sí Ìmọ̀ràn Kí O Sì Gba Ìbáwí.”)

8 Òótọ́ ni pé Jèhófà kì í bá wa sọ̀rọ̀ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan lónìí; Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àtàwọn èèyàn tó ń ṣojú fún un lórí ilẹ̀ ayé ló ń lò láti bá wa sọ̀rọ̀. Tọ́ràn bá rí bẹ́ẹ̀ nígbà náà, tá a bá ti ń bọ̀wọ̀ fáwọn tí Jèhófà yàn sípò tàbí àwọn tó fàyè gbà láti máa ṣàkóso wa, à ń fi hàn pé à ń tẹrí ba fún àṣẹ Jèhófà nìyẹn. Tá a bá lọ ṣọ̀tẹ̀ sáwọn èèyàn tó ń ṣojú fún Jèhófà pẹ́nrẹ́n, bóyá tá a kọ̀ láti gba ìmọ̀ràn àti ìbáwí tí wọ́n fún wa láti inú Ìwé Mímọ́, inú Ọlọ́run ò ní dùn sí wa o. Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì kùn sí Mósè tí wọ́n sì ṣọ̀tẹ̀ sí i, Jèhófa sọ pé òun gan-an ni wọ́n kùn sí, òun sì ni wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí.—Númérì 14:26, 27.

9. Kí nìdí tí ìfẹ́ tá a ní sáwọn ọmọnìkejì wa fi máa sún wa láti bọ̀wọ̀ fáwọn tó wà ní ipò àṣẹ? Ṣàkàwé.

9 Ohun tó tún ń jẹ́ ká bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ ni ìfẹ́ tá a ní sí ọmọnìkejì wa. Lọ́nà wo? Ó dáa ná, ká sọ pé o jẹ́ ọ̀kan lára ẹgbẹ́ ọmọ ogun kan. Kí ẹgbẹ́ ọmọ ogun tó o wà tó lè ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ ogun, o gbọ́dọ̀ fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn sójà tó kù, o gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sáwọn òfin ọmọ ẹgbẹ́, o sì gbọ́dọ̀ bọ̀wọ̀ fáwọn ọ̀gá ẹ. Tó o bá lọ fojú pa àwọn ètò tó ti wà nílẹ̀ rẹ́ tó o sì ṣọ̀tẹ̀ sẹ́gbẹ́, àfàìmọ̀ kó o má kó àwọn sójà tó kù sínú ewu. Òótọ́ ni pé jàǹbá táwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ayé yìí ti fà kò kéré rárá. Àmọ́, àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Jèhófà kì í yé rere ṣe. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ìgbà ni Bíbélì pé Ọlọ́run ní “Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun.” (1 Sámúẹ́lì 1:3) Òun ni Olórí ẹgbàágbèje àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára. Nígbà míì, Jèhófà máa ń pe àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé ní ẹgbẹ́ ọmọ ogun. (Sáàmù 68:11; Ìsíkíẹ́lì 37:1-10) Tá a bá lọ ń ṣọ̀tẹ̀ sáwọn èèyàn tí Jèhófà fi ṣe olórí wa, ṣe kì í ṣe pé ńṣe la fẹ́ kó àwọn tá a jọ jẹ́ ọmọ ogun Jèhófà sínú ewu báyìí? Tí Kristẹni kan bá ṣọ̀tẹ̀ sáwọn alàgbà, ó lè fi tiẹ̀ kó bá àwọn tó kù nínú ìjọ. (1 Kọ́ríńtì 12:14, 25, 26) Bẹ́ẹ̀ náà ni tí ọmọ kan bá ṣọ̀tẹ̀ nínú ìdílé, ó lè fi tiẹ̀ kó bá agbo ìdílé lápapọ̀. Nítorí náà ìfẹ́ tá a ní sáwọn ọmọnìkejì wa láá jẹ́ ká máa bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn ká sì máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú wọn.

10, 11. Báwo ni fífẹ́ láti jàǹfààní tó tọ́ sí wa ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa ṣègbọràn sáwọn aláṣẹ?

10 A tún máa ń bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ torí a mọ̀ pé tiwa náà ni wọ́n ń ṣe. Gbogbo ìgbà tí Jèhófà bá ní ká bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ ló máa ń sọ àǹfààní tó máa tìdí ẹ̀ yọ. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà ní káwọn ọmọ máa gbọ́ràn sáwọn òbí wọn lẹ́nu kí wọ́n lè pẹ́ láyé, káyé wọ́n sì lè dùn bí oyin. (Diutarónómì 5:16; Éfésù 6:2, 3) Ó ní ká máa bọ̀wọ̀ fáwọn alàgbà ìjọ torí tá ò bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó lè ba àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run jẹ́. (Hébérù 13:7, 17) Ó tún ní ká máa ṣègbọràn sáwọn aláṣẹ ìlú nítorí ààbò wa.—Róòmù 13:4.

11 Ó dájú pé bá a ṣe mọ ìdí tí Jèhófà ṣe fẹ́ ká máa ṣègbọràn á ràn wá lọ́wọ́ láti máa bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ. Ẹ jẹ́ ká wá gbé bá a ṣe lè bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ láwọn ọ̀nà pàtàkì mẹ́ta yẹ̀ wò.

BÁ A ṢE LÈ FỌ̀WỌ̀ HÀN NÍNÚ ÌDÍLÉ

12. Ojúṣe wo ni Jèhófà fún ọkọ àtàwọn bàbá nínú ìdílé, báwo sì ni ọkùnrin kan ṣe lè ṣe ojúṣe yẹn?

12 Jèhófà fúnra rẹ̀ ló dá ètò ìdílé sílẹ̀. Ó sì ṣètò rẹ̀ lọ́nà tó fi máa ṣàṣeyọrí, nítorí pé ó jẹ́ Ọlọ́run ètò. (1 Kọ́ríńtì 14:33) Ó gbé àṣẹ lé àwọn ọkọ àtàwọn bàbá lọ́wọ́ láti máa wakọ̀ ìdílé. Ọkọ gbọ́dọ̀ bọ̀wọ̀ fún Kristi Jésù tó jẹ́ Olórí rẹ̀ nípa títẹ̀lé ọ̀nà tí Jésù gbà lo ipò orí rẹ̀ lórí ìjọ. (Éfésù 5:23) Èyí fi hàn pé ọkọ gbọ́dọ̀ mọsẹ́ rẹ̀ níṣẹ́, ó sì gbọ́dọ̀ ṣe é bó ṣe yẹ; èyí ò wá sọ ọkọ di apàṣẹwàá tàbí òǹrorò ẹ̀dá, kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ló ń sọ ọ́ di ẹni tó ń fìfẹ́ báni lò, tó ń fọgbọ́n hùwà, tó sì ń gba tàwọn ẹlòmíì rò. Ọkọ gbọ́dọ̀ máa rántí pé ipò orí òun kì í ṣe ti ọ̀gá pátápátá, àmọ́ pé abẹ́ àṣẹ Jèhófà lòún wà.

Bàbá tó jẹ́ Kristẹni máa ń fara wé bí Kristi ṣe lo ipò orí rẹ̀

13. Báwo ni ìyá tàbí aya ṣe lè ṣe ojúṣe rẹ̀ nínú ìdílé lọ́nà tó máa múnú Jèhófà dùn?

13 Olùrànlọ́wọ́ ni ìyá tàbí aya jẹ́ lọ́ọ̀dẹ̀ ọkọ ẹ̀. Òun náà ní àṣẹ tiẹ̀ nínú ilé torí Bíbélì sọ nípa “òfin ìyá.” (Òwe 1:8) Àmọ́ òótọ́ ibẹ̀ ni pé, àṣẹ tiẹ̀ wulẹ̀ ń kín ti ọkọ rẹ̀ lẹ́yìn ni. Aya tó jẹ́ Kristẹni ní láti máa bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀ nípa ríràn án lọ́wọ́ láti ṣe ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olórí ìdílé. Kò gbọ́dọ̀ máa fojú tẹ́ńbẹ́lú ọkọ ẹ̀, kò gbọ́dọ̀ máa fọgbọ́n àyínìke gba tọwọ́ ọkọ ẹ̀ tàbí kó wá gba ipò orí mọ́ ọkọ lọ́wọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yẹ kó máa gbárùkù tì í, kó sì máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀. Nígbà tí ìpinnu ọkọ rẹ̀ ò bá tẹ́ ẹ lọ́rùn, ó lè fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ṣàlàyé èrò tiẹ̀, síbẹ̀ ó gbọ́dọ̀ máa tẹrí ba fún un. Tí ọkọ rẹ̀ ò bá gba Ọlọ́run gbọ́, ó lè má fi bẹ́ẹ̀ rọrùn láti máa bọ̀wọ̀ fún un, síbẹ̀ bí aya yìí bá ń tẹrí ba fọ́kọ ẹ̀, ó ṣeé ṣe kí ìwà rẹ̀ sún un láti fẹ́ mọ Jèhófà.—Ka 1 Pétérù 3:1.

Bàbá kan ń fi ìfẹ́ bá ọmọkùnrin rẹ̀ wí torí pé ọmọ náà kó ìdọ̀tí wọlé

14. Báwo làwọn ọmọ ṣe lè múnú Jèhófà àtàwọn òbí wọn dùn?

14 Táwọn ọmọ bá ń gbọ́ràn sí bàbá wọn lẹ́nu tí wọn ò sì ṣá àṣẹ màmá wọn tì, wọ́n á máa múnú Jèhófà dùn. Wọ́n á mú ìyìn wá bá àwọn òbí wọn, inú bàbá àti màmá wọn á sì máa dùn. (Òwe 10:1) Láwọn ìdílé tí òbí kan ti ń dá àwọn ọmọ tọ́, àwọn ọmọ gbọ́dọ̀ máa gbọ́ràn sí òbí wọn lẹ́nu nítorí àsìkò yìí gan-an ló nílò ìtìlẹ́yìn àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ wọn. Àwọn ìdílé tí bàbá, ìyá àtàwọn ọmọ bá ti ń ṣe ojúṣe tí Ọlọ́run fún wọn, máa ń láyọ̀, ọkàn wọn sì máa ń balẹ̀. Èyí sì máa ń buyì kún Jèhófà Ọlọ́run, ẹni tó dá ìdílé sílẹ̀.—Éfésù 3:14, 15.

BÁ A ṢE LÈ FỌ̀WỌ̀ HÀN NÍNÚ ÌJỌ

15. (a) Báwo la ṣe lè fi hàn nínú ìjọ pé à ń bọ̀wọ̀ fún àṣẹ Jèhófà? (b) Àwọn ìlànà wo ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣègbọràn sáwọn tó ń múpò iwájú? (Wo “Ẹ Jẹ́ Onígbọràn Sí Àwọn Tí Ń Mú Ipò Iwájú.”)

15 Jèhófà ti yan Ọmọ rẹ̀ ṣorí ìjọ Kristẹni. (Kólósè 1:13) Jésù náà ti wá yan “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” láti máa bójú tó ohun táwọn èèyàn Ọlọ́run tó wà lórí ilẹ̀ ayé nílò tó bá dọ̀ràn ìjọsìn. (Mátíù 24:45-47) Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń ṣojú fún ẹrú yìí. Bíi tàwọn ìjọ tó wà nígbà tí ẹ̀sìn Kristẹni kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀, lónìí àwọn alàgbà máa ń gba ìtọ́ni àti ìmọ̀ràn látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí ní tààràtà tàbí látọwọ́ àwọn aṣojú wọn, irú bí àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò. Tí gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan bá ń gbọ́ tàwọn alàgbà, Jèhófà là ń ṣègbọràn sí.—Ka 1 Tẹsalóníkà 5:12; Hébérù 13:17.

16. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ẹ̀mí mímọ́ ló ń yan àwọn alàgbà sípò?

16 Àwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kì í ṣe ẹni pípé. Aláìpé ni gbogbo wa. Síbẹ̀ “ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn” làwọn alàgbà jẹ́. Jèhófà ló fún wa láwọn ẹ̀bùn wọ̀nyí, kí wọ́n lè ran ìjọ lọ́wọ́ láti ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú rẹ̀. (Éfésù 4:8) Ẹ̀mí mímọ́ ló ń yan àwọn alàgbà sípò. (Ìṣe 20:28) Lọ́nà wo? Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ kúnjú ìwọ̀n ohun tí Ọlọ́run ń béèrè nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó mí sí. (1 Tímótì 3:1-7, 12; Títù 1:5-9) Kódà àwọn alàgbà tó gbé arákùnrin kan yẹ̀ wò bóyá ó kúnjú ìwọ̀n máa ń gbàdúrà fún ìtọ́sọ́nà ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà.

17. Kí nìdí táwọn Kristẹni obìnrin fi máa ń bo orí wọn nígbà tí wọ́n bá ń bójú tó àwọn ojúṣe kan nínú ìjọ?

17 Àwọn ìgbà kan máa ń wà tí kì í sáwọn alàgbà tàbí àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nínú ìjọ láti bójú tó àwọn ojúṣe tó yẹ kí wọ́n bójú tó, irú bíi dídarí ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá. Láwọn àkókò wọ̀nyí, àwọn arákùnrin tó ti ṣèrìbọmi lè bójú tó àwọn ojúṣe wọ̀nyẹn. Tí ò bá wá sàwọn arákùnrin tó ti ṣèrìbọmi níbẹ̀, àwọn arábìnrin tó tóótun lè bójú tó àwọn ojúṣe wọ̀nyẹn. Àmọ́, nígbà tí obìnrin bá ń bójú tó ojúṣe tó yẹ kí arákùnrin tó ti ṣèrìbọmi bójú tó, ó gbọ́dọ̀ bo orí rẹ̀.a (1 Kọ́ríńtì 11:3-10) Èyí ò wá túmọ̀ sí pé a tẹ àwọn obìnrin mẹ́rẹ̀ o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fún wọn láǹfààní láti bọ̀wọ̀ fún ètò ipò orí tí Jèhófà gbé kalẹ̀ nínú ìdílé àti nínú ìjọ pẹ̀lú.

BÁ A ṢE LÈ BỌ̀WỌ̀ FÁWỌN ALÁṢẸ ÌLÚ

18, 19. (a) Báwo lo ṣe máa ṣàlàyé àwọn ìlànà tó wà nínú Róòmù 13:1-7? (b) Báwo la ṣe ń bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ ìlú?

18 Tọkàntọkàn làwọn Kristẹni tòótọ́ fi ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà tó wà nínú Róòmù 13:1-7. (Ka.) Bó o ṣe ń ka àwọn ẹsẹ wọ̀nyí, wàá rí i pé àwọn ìjọba ìlú ni “àwọn aláṣẹ onípò gíga” tó wà nínú rẹ̀ túmọ̀ sí. Bí Jèhófà bá ṣì fàyè gba àwọn èèyàn wọ̀nyí láti máa ṣàkóso, wọ́n á ṣì máa ṣàwọn ohun tó ń fẹ́ àbójútó, wọ́n á máa rí sí i pé àwọn nǹkan wà létòletò, wọ́n á sì máa pèsè àwọn nǹkan tá a nílò dé ìwọ̀n tí agbára wọ́n mọ. À ń fi hàn pé à ń bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ ìlú tá a bá ń pa àwọn òfin ìlú mọ́. Ẹ jẹ́ ká rí i dájú pé à ń san owó orí èyíkéyìí tá a bá jẹ wọ́n, ká kọ àwọn ìsọfúnni tó bá yẹ sínú àwọn ìwé tí ìjọba bá ní ká fọwọ́ sí, ká sì máa pa àwọn òfin tí wọ́n bá gbé kalẹ̀ mọ́, pàápàá èyí tó bá kan ìdílé, iṣẹ́ tàbí àwọn ohun ìní wa. Àmọ́ ṣá o, táwọn aláṣẹ ìlú bá ní ká fi ti Ọlọ́run sílẹ̀ ká wá gbọ́ tàwọn, a ò ní ṣe bẹ́ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, bíi tàwọn àpọ́sítélì ìgbaanì la ṣe máa dáhùn, wọ́n ní: “Àwa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.”—Ìṣe 5:28, 29; wo àpótí náà “Àṣẹ Ta Ló Yẹ Kí N Tẹ̀ Lé?”

ÀṢẸ TA LÓ YẸ KÍ N TẸ̀ LÉ?

Ìlànà: “Jèhófà ni Onídàájọ́ wa, Jèhófà ni Ẹni tí ń fún wa ní ìlànà àgbékalẹ̀, Jèhófà ni Ọba wa.”—Aísáyà 33:22.

Àwọn ìbéèrè díẹ̀ tó o lè bi ara rẹ rèé:

  • Kí ni mo máa ṣe táwọn kan bá ní kí n tàpá sáwọn ìlànà Jèhófà?—Mátíù 22:37-39; 26:52; Jòhánù 18:36.

  • Kí ni mo máa ṣe tí wọ́n bá ní kí n má pa àwọn àṣẹ Jèhófà mọ́?—Ìṣe 5:27-29; Hébérù 10:24, 25.

  • Kí ló lè ràn mí lọ́wọ́ láti máa bọ̀wọ̀ fáwọn tó wà ní ipò àṣẹ?—Róòmù 13:1-4; 1 Kọ́ríńtì 11:3; Éfésù 6:1-3.

19 A tún máa ń bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ ìlú nípa bá a ṣe ń hùwà sáwọn èèyàn. Nígbà míì, ó lè jẹ́ pé àwọn aṣojú ìjọba gan-an la fẹ́ bá sọ̀rọ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù bá àwọn aṣojú ìjọba kan sọ̀rọ̀ nígbà ayé ẹ̀, àwọn bíi Hẹ́ródù Àgírípà Ọba àti Gómìnà Fẹ́sítọ́ọ̀sì. Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí kì í ṣe ọmọlúwàbí èèyàn rárá, síbẹ̀ Pọ́ọ̀lù fi ọ̀wọ̀ wọn wọ̀ wọ́n. (Ìṣe 26:2, 25) Àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù ló yẹ ká máa tẹ̀ lé tá a bá ń bá àwọn èèkàn lára àwọn aṣojú ìjọba sọ̀rọ̀ títí kan àwọn ọlọ́pàá. Àwọn Kristẹni ọ̀dọ́ pàápàá gbọ́dọ̀ máa fi irú ọ̀wọ̀ bẹ́ẹ̀ hàn sáwọn olùkọ́ wọn, àwọn ọ̀gá ilé ìwé àtàwọn òṣìṣẹ́ míì níléèwé wọn. Òótọ́ ni pé kì í ṣàwọn tó gba tiwa nìkan là ń bọ̀wọ̀ fún; a tún máa ń bọ̀wọ̀ fáwọn tó tiẹ̀ ń ṣàìdáa sáwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà pàápàá. Ó yẹ kí gbogbo àwọn aláìgbàgbọ́ máa rí i nínú ìwà wa pé a ka àwọn èèyàn sí.—Ka Róòmù 12:17, 18; 1 Pétérù 3:15.

20, 21. Àǹfààní wo la máa rí gbà tá a bá ń fi tọkàntọkàn bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ?

20 Ẹ jẹ́ ká máa bọ̀wọ̀ fún gbogbo èèyàn. Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé pé: “Ẹ máa bọlá fún onírúurú ènìyàn gbogbo.” (1 Pétérù 2:17) Inú àwọn èèyàn á máa dùn sí wa tí wọ́n bá mọ̀ pé à ń bọ̀wọ̀ fún wọn látọkàn wá. Má gbàgbé pé ànímọ́ yìí ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dàwátì. Nítorí náà, tá a bá fi ànímọ́ yìí wọ ara wa láṣọ, a jẹ́ pé ńṣe là ń ṣègbọràn sí àṣẹ tí Jésù pa; ó ní ká jẹ́ “kí ìmọ́lẹ̀ [wa] máa tàn níwájú àwọn ènìyàn, kí wọ́n lè rí àwọn iṣẹ́ àtàtà [wa], kí wọ́n sì lè fi ògo fún Baba [wa] tí ń bẹ ní ọ̀run.”—Mátíù 5:16.

21 Nínú ayé oníwà wíwọ́ yìí, àwọn tó lọ́kàn rere ń wá síbi tí ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí wà. Nítorí náà, fífi ọ̀wọ̀ hàn nínú ìdílé, nínú ìjọ, láàárín àwọn ẹlẹgbẹ́ wa níléèwé àti níbi iṣẹ́ àti fífi hàn sáwọn aláṣẹ ìlú lè sún wọn láti wá bá wa rìn nínú ìmọ́lẹ̀. Èyí á mà dáa gan-an o! Tí nǹkan ò bá tiẹ̀ wá rí bẹ́ẹ̀, ohun kan dájú. Bá a ṣe ń bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn ń dùn mọ́ Jèhófà Ọlọ́run nínú, ó sì ń jẹ́ ká dúró nínú ìfẹ́ rẹ̀. Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá gbáà lèyí!

a Àfikún tó wà “Ìgbà Wo Ló Yẹ Kí Obìnrin Máa Borí, Kí sì Nìdí?” ṣàlàyé àwọn ọ̀nà mélòó kan tá a lè gbà fi ìlànà yìí sílò.

“FETÍ SÍ ÌMỌ̀RÀN KÍ O SÌ GBA ÌBÁWÍ”

Ẹ̀mí Sátánì, ìyẹn ẹ̀mí ọ̀tẹ̀ àti ẹ̀mí ìdíje tí Sátánì ń gbé lárugẹ ti gbayé kan. Abájọ tí Bíbélì fi pe Sátánì ní “olùṣàkóso ọlá àṣẹ afẹ́fẹ́,” tó sì sọ pé “ẹ̀mí tí [Sátánì ń gbé lárugẹ] ń ṣiṣẹ́ nísinsìnyí nínú àwọn ọmọ àìgbọ́ràn.” (Éfésù 2:2) Ọ̀pọ̀ lóde òní ni ò fẹ́ dúró sábẹ́ àṣẹ ẹnikẹ́ni, tí wọ́n sì fẹ́ máa dá àṣẹ tiwọn pa. Ó ṣeni láàánú pé, ẹ̀mí yìí ti ran àwọn kan nínú ìjọ Kristẹni. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan lè kọ̀ láti gba ìmọ̀ràn onífẹ̀ẹ́ tó ṣeé ṣe kí alàgbà kan fún wọn lórí ewu tó wà nídìí wíwo àwọn eré tí wọ́n ti ń ṣèṣekúṣe tàbí ti wọ́n ti ń hùwà ipá, wọ́n tiẹ̀ lè torí ẹ̀ máa bínú pàápàá. Gbogbo wa ló yẹ ká fi àwọn ọ̀rọ̀ inú ìwé Òwe 19:20 sílò, ó sọ pé: “Fetí sí ìmọ̀ràn kí o sì gba ìbáwí, kí o lè di ọlọ́gbọ́n ní ọjọ́ ọ̀la rẹ.”

Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe èyí? Ẹ jẹ́ ká gbé ìdí mẹ́ta táwọn èèyàn fi sábà máa ń kọ ìbáwí tàbí ìmọ̀ràn yẹ̀ wò, lẹ́yìn náà ká wá wo ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ lórí ọ̀ràn náà.

  • “Mi ò rò pé irú ìmọ̀ràn yẹn tọ́ sí mi.” A lè máa rò pé irú ìmọ̀ràn náà ò tọ́ sí wa. A tiẹ̀ lè rò pé ẹni tó ń fún wa nímọ̀ràn ò mọ bọ́ràn ṣe jẹ́ kó tó máa gbà wá nímọ̀ràn. Nígbà míì, a tiẹ̀ lè bẹ̀rẹ̀ sí fojú kéré ìmọ̀ràn náà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. (Hébérù 12:5) Níwọ̀n bí gbogbo wa ti jẹ́ aláìpé, ṣé kò lè wá lọ jẹ́ pé àwa gan-an ló yẹ ká tún ojú tá a fi ń wo ọ̀ràn náà ṣe báyìí? (Òwe 19:3) Ṣé bẹ́ẹ̀ ni kò wá sídìí kankan tá a fi nílò ìmọ̀ràn yẹn ni? Ìyẹn gan-an ló yẹ ká ronú lé. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbà wá nímọ̀ràn pé: “Di ìbáwí mú; má ṣe jẹ́ kí ó lọ. Fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ, nítorí òun ni ìwàláàyè rẹ.”—Òwe 4:13.

  • “Inú mi ò dùn sí bó ṣe bá mi sọ̀rọ̀ nígbà tó ń fún mi nímọ̀ràn yẹn.” Ká sòótọ́, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti fún wa nílànà tó tó nípa bó ṣe yẹ ká máa fáwọn èèyàn nímọ̀ràn. (Gálátíà 6:1) Síbẹ̀, Bíbélì tún sọ pé: “Gbogbo ènìyàn ti ṣẹ̀, wọ́n sì ti kùnà láti kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọ́run.” (Róòmù 3:23) Nítorí náà, tá ò bá fẹ́ káwọn èèyàn máa ṣẹ̀ wá torí bí wọ́n ṣe ń bá wa sọ̀rọ̀ nígbà tí wọ́n bá ń fún wa nímọ̀ràn, àfi kó wá látẹnu ẹni pípé. (Jákọ́bù 3:2) Àwọn èèyàn aláìpé ni Jèhófà máa ń lò láti bá wa wí, nítorí náà ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé ká má máa wo bí wọ́n ṣe ń bá wa sọ̀rọ̀ nígbà tí wọ́n bá ń fún wa nímọ̀ràn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìmọ̀ràn yẹn ló yẹ ká ronú lé ká sì gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ràn wá lọ́wọ́ láti fi sílò.

  • “Irú ẹ̀ kọ́ ló yẹ kó wá gbà mí nímọ̀ràn!” Tó bá lọ jẹ́ pé torí àwọn àṣìṣe tí ẹni tó gbà wá nímọ̀ràn ti ṣe la ò fi ní gba ìmọ̀ràn tó fún wa, àfi ká máa rántí àwọn kókó tó wà lókè yìí. Tá a bá sì lọ ń rò pé a ti kọjá ìbáwí bóyá nítorí ọjọ́ orí wa, tìgbà tá a ti wà nínú ìjọ Kristẹni tàbí ti ìrírí tá a ti ní, àfi ká yáa tún èrò wa pa. Nílùú Ísírẹ́lì láyé ọjọ́un, ojúṣe ọba ò kéré rárá, síbẹ̀ ó ní láti gba ìmọ̀ràn látọ̀dọ̀ àwọn wòlíì, àwọn àlùfáà àtàwọn míì tí wọ́n jẹ́ ọmọ abẹ́ rẹ̀. (2 Sámúẹ́lì 12:1-13; 2 Kíróníkà 26:16-20) Lóde òní, àwọn èèyàn aláìpé ni ètò Jèhófà ń lò láti gbà wá nímọ̀ràn, síbẹ̀ àwọn Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn ń gba àwọn ìmọ̀ràn náà wọ́n sì fi ń ṣèwà hù. Tá a bá ń bójú tó nǹkan tó pọ̀ nínú ìjọ tá a sì ní ìrírí ju àwọn ẹlòmíì lọ, ńṣe ló yẹ ká túbọ̀ máa ṣọ́ra, ká lè máa fàpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ ní ti fífọgbọ́n hùwà àti fífi ìrẹ̀lẹ̀ gba ìmọ̀ràn ká sì fi sílò.—1 Tímótì 3:2, 3; Títù 3:2.

Ó ti wá hàn kedere pé kò sẹ́ni tó kọjá ìbáwí nínú wa. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa fi tọkàntọkàn gba ìbáwí ká sì máa fi wọ́n sílò bá a ti ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún ẹ̀bùn rẹ̀ tó ń gbẹ̀mí là yìí. Ká sòótọ́, ọ̀nà kan láti fi hàn pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa ni ìbáwí tó ń fún wa, ó sì yẹ ká dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run.—Hébérù 12:6-11.

“Ẹ JẸ́ ONÍGBỌRÀN SÍ ÀWỌN TÍ Ń MÚ IPÒ IWÁJÚ”

Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ayé ọjọ́un nílò ètò tó mọ́yán lórí. Mósè nìkan ò lè máa dá bójú tó ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn èèyàn tí wọ́n jọ ń rìnrìn àjò láginjù tó léwu yẹn. Kí ló wá ṣe? “Mósè sì bẹ̀rẹ̀ sí yan àwọn ọkùnrin dídáńgájíá nínú gbogbo Ísírẹ́lì, ó sì fún wọn ní ipò gẹ́gẹ́ bí olórí lórí àwọn ènìyàn náà, gẹ́gẹ́ bí olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún, olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún, olórí àràádọ́ta àti olórí ẹ̀wẹ̀ẹ̀wá.”—Ẹ́kísódù 18:25.

A nílò irú ètò bẹ́ẹ̀ náà nínú ìjọ Kristẹni lóde òní. Ìdí nìyẹn tí alábòójútó ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ fi wà ní ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ kọ̀ọ̀kan, tá a ní àwọn alàgbà nínú ìjọ, táwọn ìjọ mélòó kan ní alábòójútó àyíká, táwọn àyíká mélòó kan ní alábòójútó àgbègbè, tí orílẹ̀-èdè sì ní Ìgbìmọ̀ Orílẹ̀-Èdè tàbí Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka. Bá a ṣe ṣètò wa yìí ló jẹ́ kí olùṣọ́ àgùntàn kọ̀ọ̀kan máa bójú tó àwọn àgùntàn Jèhófà tó wà níkàáwọ́ rẹ̀ dáadáa. Àwọn olùṣọ́ àgùntàn wọ̀nyí máa jíhìn fún Jèhófà àti Kristi.—Ìṣe 20:28.

Bá a ṣe ṣètò wa yìí fi hàn pé a gbọ́dọ̀ máa gbọ́ràn sáwọn tó ń darí wa lẹ́nu ká sì máa tẹrí ba fún wọn. Ó dájú pé a ò ní fẹ́ dà bí Dìótíréfè tí ò bọ̀wọ̀ fáwọn tó wà nípò àbójútó nígbà ayé ẹ̀. (3 Jòhánù 9, 10) Kàkà bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù la fẹ́ máa tẹ̀ lé, ó kọ̀wé pé: “Ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn tí ń mú ipò iwájú láàárín yín, kí ẹ sì jẹ́ ẹni tí ń tẹrí ba, nítorí wọ́n ń ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí ọkàn yín bí àwọn tí yóò ṣe ìjíhìn; kí wọ́n lè ṣe èyí pẹ̀lú ìdùnnú, kì í sì í ṣe pẹ̀lú ìmí ẹ̀dùn, nítorí èyí yóò ṣe ìpalára fún yín.” (Hébérù 13:17) Ìtọ́ni táwọn kan bá fara mọ́ lára èyí táwọn tó ń darí wa bá gbé kalẹ̀ nìkan ni wọ́n máa ń ṣègbọràn sí, àmọ́ wọn kì í tẹrí ba fún èyí tó bá rú wọn lójú tàbí tí wọn ò fara mọ́. Ẹ jẹ́ ká máa rántí pé ọ̀kan lára ohun tí títẹrí ba túmọ̀ sí ni pé ká máa ṣègbọràn, tí ò bá tiẹ̀ wù wá ṣe pàápàá. Ó yẹ ká wá bi ara wa léèrè pé, ‘Ṣé mò ń gbọ́ràn sáwọn tó ń darí wa lẹ́nu, ṣé mo sì ń tẹrí ba fún wọn?’

Òótọ́ ni pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ò to gbogbo nǹkan tá a gbọ́dọ̀ ṣe láti kọ́wọ́ ti àwọn ètò tó wà nínú ìjọ lẹ́yìn. Síbẹ̀ Bíbélì sọ pé: “Kí ohun gbogbo máa ṣẹlẹ̀ lọ́nà tí ó bójú mu àti nípa ìṣètò.” (1 Kọ́ríńtì 14:40) Ohun tí Ìgbìmọ̀ Olùdarí ń ṣe gan-an nìyẹn, ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ṣe àwọn ètò àtàwọn ìtọ́ni tó máa ràn wá lọ́wọ́ láti máa ṣàwọn nǹkan lọ́nà tó bójú mu nínú ìjọ. Àwọn Kristẹni ọkùnrin tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn náà ń ṣe ipa tiwọn nípa fífi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ torí pé wọ́n jẹ́ onígbọràn, bí wọ́n ṣe ń tẹ̀ lé àwọn ètò wọ̀nyí. Wọ́n “ń fòye báni lò,” wọ́n sì “múra tán láti ṣègbọràn” sáwọn tó ń ṣàbójútó. (Jákọ́bù 3:17) Nígbà náà a lè sọ pé ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ kọ̀ọ̀kan, ìjọ, àyíká, àgbègbè àti orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan ló ní àwọn onígbàgbọ́ tó wà níṣọ̀kan tí wọ́n jùmọ̀ ń ṣe ti Ọlọ́run aláyọ̀.—1 Kọ́ríńtì 14:33; 1 Tímótì 1:11.

Yàtọ̀ síwọ̀nyí, ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó wà ní Hébérù 13:17 tún ṣàlàyé ìdí tí ṣíṣàìgbọràn fi léwu; ìyẹn ni pé ó lè jẹ́ káwọn tó ń darí wa máa fi “ìmí ẹ̀dùn” ṣiṣẹ́ wọn. Ohun tó yẹ kó jẹ́ àǹfààní iṣẹ́ ìsìn mímọ́ lè wá dà bí ẹrù ìnira nígbà tá ò bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú wọn, táwọn kan sì tún ń ṣọ̀tẹ̀ láàárín agbo. Àbárèbábọ̀ ẹ̀ ni pé, á pa “yín” lára, ìyẹn ìjọ lápapọ̀. Kíkọ̀ láti tẹrí ba fáwọn àṣẹ tí ètò Ọlọ́run gbé kalẹ̀ tún lè ṣèpalára fúnni lọ́nà mìíràn. Tí ìgbéraga bá lọ wọ̀ọ̀yàn lẹ́wù débi tí kò fi fẹ́ láti máa tẹrí ba fáwọn tó ń darí wa, ìyẹn lè ba àjọṣe tó dán mọ́rán tó wà láàárín òun àti Baba rẹ̀ ọ̀run jẹ́. (Sáàmù 138:6) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu láti máa gbọ́ràn sáwọn tó ń darí wa lẹ́nu, ká sì máa tẹrí ba fún wọn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́