Ṣọ́ra! Sátánì Fẹ́ Pa Ọ́ Jẹ
“Ẹ máa kíyè sára! Elénìní yín, Èṣù, ń rìn káàkiri bí kìnnìún tí ń ké ramúramù, ó ń wá ọ̀nà láti pani jẹ.”—1 PÉT. 5:8.
1. Ṣàlàyé bí áńgẹ́lì kan ṣe di Sátánì.
ÁŃGẸ́LÌ kan wà tó rí ojú rere Jèhófà nígbà kan rí. Àmọ́, nígbà tó yá ó bẹ̀rẹ̀ sí í wá bí àwọn èèyàn á ṣe máa jọ́sìn òun. Dípò tí ì bá fi gbé èrò búburú yẹn kúrò lọ́kàn, ṣe ló ń ronú nípa rẹ̀ ṣáá, títí tí èrò náà fi gbilẹ̀ lọ́kàn rẹ̀ tó sì mú un dẹ́ṣẹ̀. (Ják. 1:14, 15) Áńgẹ́lì yẹn la wá mọ̀ sí Sátánì, ẹni tí kò “dúró ṣinṣin nínú òtítọ́.” Ó ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà, ó sì wá di “baba irọ́.”—Jòh. 8:44.
2, 3. Kí làwọn orúkọ náà “Sátánì,” “Èṣù,” “ejò” àti “dírágónì” jẹ́ ká mọ̀ nípa olórí ọ̀tá Jèhófà?
2 Látìgbà tí Sátánì ti ṣọ̀tẹ̀ ló ti di olórí ọ̀tá Jèhófà, ó sì dájú pé kì í ṣe ọ̀rẹ́ àwa náà. Àwọn orúkọ tá a fi ń pe Sátánì jẹ́ ká mọ bí ìwà ìbàjẹ́ rẹ̀ ṣe jinlẹ̀ tó. Sátánì túmọ̀ sí “Alátakò,” ìyẹn fi hàn pé áńgẹ́lì búburú yìí kò ti ìṣàkóso Ọlọ́run lẹ́yìn, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ló kórìíra ìṣàkóso náà tó sì ń gbógun tì í. Olórí ohun tó wà lọ́kàn Sátánì ni bó ṣe máa fòpin sí ìṣàkóso Jèhófà.
3 Nínú ìwé Ìṣípayá 12:9, Bíbélì pe Sátánì ní Èṣù, èyí tó túmọ̀ sí “Afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́.” Orúkọ yìí rán wa létí pé Sátánì ba Jèhófà lórúkọ jẹ́, ó pe Jèhófà ní òpùrọ́. Ọ̀rọ̀ náà, “ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà” rán wa létí ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ burúkú yẹn ní ọgbà Édẹ́nì nígbà tí Sátánì lo ejò láti tan Éfà jẹ. Tá a bá gbọ́ gbólóhùn náà “dírágónì ńlá,” ohun tó máa wá síni lọ́kàn ni ẹranko abàmì kan, èyí sì bá Sátánì mu wẹ́kú torí pé ó ń jà fitafita láti dènà ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn fún aráyé, ó sì ń wá ọ̀nà láti pa àwọn èèyàn Jèhófà run.
4. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
4 Kò sí àní-àní, Sátánì ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe kó lè ba ìṣòtítọ́ wa jẹ́. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi gbà wá níyànjú pé: “Ẹ pa agbára ìmòye yín mọ́, ẹ máa kíyè sára. Elénìní yín, Èṣù, ń rìn káàkiri bí kìnnìún tí ń ké ramúramù, ó ń wá ọ̀nà láti pani jẹ.” (1 Pét. 5:8) Nítorí ìkìlọ̀ yìí, a máa jíròrò ohun mẹ́ta nípa Sátánì nínú àpilẹ̀kọ yìí, wọ́n á sì jẹ́ ká rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká ṣọ́ra fún ọ̀tá búburú tó ń ta ko Jèhófà àtàwa èèyàn rẹ̀.
SÁTÁNÌ NÍ AGBÁRA
5, 6. (a) Sọ àwọn àpẹẹrẹ tó fi hàn pé àwọn ańgẹ́lì “tóbi jọjọ nínú agbára.” (b) Kí nìdí tá a fi lè sọ pé Sátánì ní “ọ̀nà àtimú ikú wá”?
5 Àwọn áńgẹ́lì tá ò lè fojú rí yìí “tóbi jọjọ nínú agbára.” (Sm. 103:20) Wọ́n lágbára ju àwa èèyàn lọ fíìfíì, torí náà ọgbọ́n wọn àti okun wọn ju tiwa lọ gan-an. Ohun kan ni pé àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ máa ń fi agbára wọn ṣe ohun rere. Bí àpẹẹrẹ, nígbà kan áńgẹ́lì Jèhófà kan ṣoṣo pa ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [185,000] àwọn ọmọ ogun Ásíríà tí wọ́n jẹ́ ọ̀tá àwọn èèyàn Ọlọ́run. Kò sí ẹgbẹ́ ológun kan tó lè ṣe irú iṣẹ́ ńlá yìí, ká má tiẹ̀ wá sọ ẹ̀dá èèyàn kan ṣoṣo. (2 Ọba 19:35) Àpẹẹrẹ míì ni ańgẹ́lì kan tó lo agbára ńlá àti ọgbọ́n gíga rẹ̀ láti dá àwọn àpọ́sítélì Jésù sílẹ̀ lẹ́wọ̀n. Áńgẹ́lì náà wọnú ọgbà ẹ̀wọ̀n láìsí ìdíwọ́ kankan, ó ṣí àwọn ìlẹ̀kùn, ó mú àwọn àpọ́sítélì náà jáde, ó sì tún pa ìlẹ̀kùn dé, bẹ́ẹ̀ sì rèé, àwọn ẹ̀ṣọ́ náà dúró láìlè ta pútú!—Ìṣe 5:18-23.
6 Àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ máa ń lo agbára wọn láti ṣe ohun rere, àmọ́ Sátánì máa ń lo agbára tiẹ̀ láti ṣe ohun búburú. Ẹ wo bí agbára tó ní lórí àwọn èèyàn ṣe pọ̀ tó! Ìwé Mímọ́ pè é ní “olùṣàkóso ayé yìí” àti “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí.” (Jòh. 12:31; 2 Kọ́r. 4:4) Kódà, Sátánì Èṣù ní “ọ̀nà àtimú ikú wá.” (Héb. 2:14) Èyí kò túmọ̀ sí pé gbogbo èèyàn ló máa ń pa ní tààràtà o. Àmọ́, ìwà gbẹ̀mígbẹ̀mí rẹ̀ kúnnú ayé yìí. Síwájú sí i, torí pé Éfà gba irọ́ Sátánì gbọ́, tí Ádámù sì ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú di ohun tó ran gbogbo aráyé. (Róòmù 5:12) Lọ́nà yìí ni Èṣù gbà ní “ọ̀nà àtimú ikú wá.” Ohun tí Jésù pè é náà ló jẹ́, “apànìyàn.” (Jòh. 8:44) Ẹ ò rí i pé ọ̀tá tó lágbára gan-an ni Sátánì!
7. Báwo làwọn ẹ̀mí èṣù ṣe fi hàn pé àwọn lágbára?
7 Tá a bá kọjú ìjà sí Sátánì, kì í ṣe òun nìkan la kọjú ìjà sí, a tún kọjú ìjà sí gbogbo àwọn tó lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ láti ta ko jíjẹ́ tí Jèhófà jẹ́ ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run. Lára àwọn tó lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ ni àwọn áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ tàbí àwọn ẹ̀mí èṣù, wọ́n sì pọ̀ díẹ̀. (Ìṣí. 12:3, 4) Léraléra làwọn ẹ̀mí èṣù yìí máa ń dán agbára ńlá tí wọ́n ní wò, wọ́n máa ń fa ẹ̀dùn ọkàn fún àwọn èèyàn tí wọ́n dá lóró. (Mát. 8:28-32; Máàkù 5:1-5) Torí náà, má ṣe fojú kéré agbára táwọn áńgẹ́lì burúkú yìí ní tàbí tí “olùṣàkóso àwọn ẹ̀mí èṣù” ní. (Mát. 9:34) Láìsí ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, a ò ní lè borí Sátánì nínú ìjà náà.
ÌKÀ NI SÁTÁNÌ
8. (a) Kí ni Sátánì ní lọ́kàn láti ṣe? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.) (b) Kí lo kíyè sí tó jẹ́ kó o gbà pé ayé yìí níkà bíi ti Sátánì?
8 Àpọ́sítélì Pétérù fi Sátánì wé “kìnnìún tí ń ké ramúramù.” Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí “ké ramúramù” ń ṣàpèjúwe “igbe tí ẹranko máa ń ké nígbà tí ebi bá ń pa á burúkú burúkú.” Ẹ ò rí i pé àpèjúwe yìí bá Sátánì àti ìwà ìkà rẹ̀ mu gan-an! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ayé ti wà níkàáwọ́ Sátánì, ó ṣì ń wá àwọn èèyàn tó máa pa jẹ. (1 Jòh. 5:19) Lójú Sátánì, bí “ìpápánu” lásán ni àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run jẹ́. Lédè míì, àwọn tó kà sí “oúnjẹ gidi” ló ń wá kiri, ìyẹn àwọn ẹni àmì òróró àtàwọn “àgùntàn mìíràn” tó jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ wọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́. (Jòh. 10:16; Ìṣí. 12:17) Ohun tó wà lọ́kàn Sátánì ni bó ṣe máa pa àwọn èèyàn Jèhófà jẹ. Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ inúnibíni tí wọ́n ṣe sí àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù láti ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní títí di ìsinsìnyí fi hàn pé ìkà ni Sátánì.
9, 10. (a) Báwo ni Sátánì ṣe gbìyànjú láti dènà ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì? (Sọ àwọn àpẹẹrẹ kan.) (b) Kí nìdí tí Sátánì fi dójú sọ Ísírẹ́lì àtijọ́? (d) Báwo ló ṣe máa ń rí lára Èṣù nígbà tí ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà bá dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì lónìí?
9 Bí Sátánì ṣe ń gbìyànjú láti dènà ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn, ó tún máa ń fi hàn lọ́nà míì pé ìkà lòun. Kìnnìún tí ebi ń pa kì í ṣàánú ẹran tó fẹ́ pa jẹ. Kì í ṣàánú ẹran náà kó tó pa á, bẹ́ẹ̀ sì ni inú rẹ̀ kì í bà jẹ́ lẹ́yìn tó bá ti pa á. Lọ́nà kan náà, Sátánì kì í ṣàánú àwọn tó fẹ́ pa jẹ. Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa ọ̀pọ̀ ìgbà tí Sátánì Èṣù máa ń lúgọ de àwọn ọmọ Ísírẹ́lì títí wọ́n á fi dẹ́ṣẹ̀, irú bí ìwà wọ̀bìà àti ìṣekúṣe. Nígbà tó o bá kà nípa aburú tó dé bá Símírì oníṣekúṣe àti Géhásì olójúkòkòrò, ǹjẹ́ o kì í “rí” bí kìnnìún tó ń bú ramúramù yẹn ṣe ń ju ìrù tí inú rẹ̀ sì ń dùn torí pé ọwọ́ rẹ̀ ti tẹ ohun tó ń wá?—Núm. 25:6-8, 14, 15; 2 Ọba 5:20-27.
Inú Sátánì máa ń dùn nígbà tí ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà bá dẹ́ṣẹ̀ (Wo ìpínrọ̀ 10)
10 Sátánì ní ìdí pàtàkì tó fi dójú sọ Ísírẹ́lì àtijọ́. Ó ṣe tán, orílẹ̀-èdè yẹn ni Mèsáyà ti máa jáde, ẹni tó máa pa Sátánì run tó sì máa jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Jèhófà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ ọba aláṣẹ láyé àtọ̀run. (Jẹ́n. 3:15) Sátánì kò fẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣàṣeyọrí, ó sì ń sapá lójú méjèèjì kó lè mú kí wọn dẹ́ṣẹ̀ kí wọ́n lè di ẹlẹ́gbin. Má ṣe ronú pé inú Sátánì bà jẹ́ nígbà tí Dáfídì ṣe panṣágà, bẹ́ẹ̀ sì ni kò káàánú wòlíì Mósè nígbà tí Ọlọ́run sọ pé wòlíì náà kò ní wọ Ilẹ̀ Ìlérí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni inú Sátánì máa ń dùn nígbà tí ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì bá sọ ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run di ẹlẹ́gbin. Ká sòótọ́, irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí Èṣù ti rọ́wọ́ mú yìí wà lára ohun tó máa ń lò láti fi ṣáátá Jèhófà.—Òwe 27:11.
11. Kí ni Sátánì ń wá ọ̀nà àtiṣe nígbà tó dájú sọ Sárà?
11 Sátánì kórìíra ìdílé tí Mèsáyà ti máa wá. Bí àpẹẹrẹ, wo ohun tó ṣẹlẹ̀ kété lẹ́yìn tí Ọlọ́run sọ fún Ábúráhámù pé ó máa di “orílẹ̀-èdè ńlá.” (Jẹ́n. 12:1-3) Nígbà tí Ábúráhámù àti Sárà wà ní Íjíbítì, Fáráò ní kí wọ́n mú Sárà wá sí ilé òun, ó sì dájú pé ó fẹ́ fi ṣe aya rẹ̀ ni. Àmọ́, Jèhófà dá sí ọ̀ràn náà, ó sì gba Sárà lọ́wọ́ ohun tó lè mú un ṣe ìṣekúṣe. (Ka Jẹ́nẹ́sísì 12:14-20.) Ṣáájú kó tó bí Ísákì, irú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí wáyé ní Gérárì. (Jẹ́n. 20:1-7) Ṣé Sátánì ló wà lẹ́yìn gbogbo nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ yẹn? Ṣé ó retí pé ààfin rèǹtèrente Fáráò àti ti Ábímélékì máa fa Sárà lọ́kàn mọ́ra, ẹni tó jẹ́ pé ó fi Úrì ìlú ọlọ́rọ̀ sílẹ̀ tó wá ń gbé nínú àwọn àgọ́? Ṣé Sátánì rò pé Sárà máa dalẹ̀ ọkọ rẹ̀ àti Jèhófà, kó sì ṣe ìgbéyàwó onípanṣágà? Bíbélì kò sọ, àmọ́ ìdí pàtàkì wà láti gbà pé inú Èṣù máa dùn láti sọ Sárà di ẹni tí kò lè bí ọmọ tá a ṣèlérí náà. Kò ní dun Sátánì rárá pé òun máa bá àárín obìnrin rere yìí àti ọkọ rẹ̀ jẹ́, kò sì ní dùn ún pé òun máa ba orúkọ obìnrin náà àti ìwà rẹ̀ jẹ́ lọ́dọ̀ Jèhófà. Sátánì mà níkà gan-an o!
12, 13. (a) Báwo ni Sátánì ṣe fìwà ìkà rẹ̀ hàn lẹ́yìn tí wọ́n bí Jésù? (b) Kí lèrò Sátánì nípa àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tí wọ́n sì ń sapá láti sìn ín lónìí?
12 Ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún lẹ́yìn tí Ábúráhámù ti gbáyé ni wọ́n bí Jésù. Ṣé o rò pé Sátánì nífẹ̀ẹ́ sí bí ọmọ náà ti lẹ́wà tó tàbí bó ṣe ṣeyebíye tó? Rárá o, nítorí Sátánì mọ̀ pé ọmọ tuntun yẹn máa dàgbà, á sì di Mèsáyà tá a ṣèlérí. Ó dájú pé Jésù ni apá àkọ́kọ́ lára irú-ọmọ Ábúráhámù, ẹni tó máa “fọ́ àwọn iṣẹ́ Èṣù túútúú.” (1 Jòh. 3:8) Ṣé Sátánì rò pé ó burú tóun bá gba ẹ̀mí ọmọ náà? Rárá o, nítorí oníwàkiwà ni Sátánì. Nígbà tó dórí ọ̀ràn Jésù ọmọ kékeré náà, Sátánì gbógun tì í láìjáfara. Báwo ló ṣe ṣe é?
13 Inú bí Hẹ́rọ́dù Ọba gan-an nígbà táwọn awòràwọ̀ ń ṣèwádìí nípa “ẹni tí a bí ní ọba àwọn Júù,” ó sì pinnu láti pa á. (Mát. 2:1-3, 13) Kí ó bàa lè rí i pé iṣẹ́ náà di ṣíṣe, ó pàṣẹ pé kí wọ́n pa gbogbo àwọn ọmọkùnrin tí wọ́n wà ní ọmọ ọdún méjì sísàlẹ̀ tí wọ́n ń gbé ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù àti àgbègbè rẹ̀. (Ka Mátíù 2:13-18.) Jésù bọ́ lọ́wọ́ ikú nígbà ìpànìyàn tó burú jáì yẹn, àmọ́ kí ni ọ̀ràn náà jẹ́ ká mọ̀ nípa ọ̀tá wa Sátánì? Ó jẹ́ ká mọ̀ pé ẹ̀mí èèyàn kò jọ Èṣù lójú. Ó dájú pé kò láàánú àwọn ọmọdé. Kò sí àní-àní pé kìnnìún tó “ń ké ramúramù” ni Sátánì. Ẹ má ṣe jẹ́ ká fojú kéré ìwà ìkà rẹ̀ láé!
ẸLẸ́TÀN NI SÁTÁNÌ
14, 15. Báwo ni Sátánì ṣe “fọ́ èrò inú àwọn aláìgbàgbọ́ lójú”?
14 Àfi tí Sátánì bá lò ẹ̀tàn ló tó lè mú kí àwọn èèyàn kẹ̀yìn sí Jèhófà, Ọlọ́run ìfẹ́. (1 Jòh. 4:8) Sátánì má ń fẹ̀tàn mú àwọn èèyàn kí “àìní wọn nípa ti ẹ̀mí” má bàa jẹ wọ́n lọ́kàn. (Mát. 5:3) Nípa bẹ́ẹ̀, ó ń “fọ́ èrò inú àwọn aláìgbàgbọ́ lójú, kí ìmọ́lẹ̀ ìhìn rere ológo nípa Kristi, ẹni tí ó jẹ́ àwòrán Ọlọ́run, má bàa mọ́lẹ̀ wọlé.”—2 Kọ́r. 4:4
15 Ìsìn èké jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀nà tó lágbára jù lọ tí Sátánì ń gbà tan àwọn èèyàn jẹ. Ẹ wo bí inú rẹ̀ ṣe máa ń dùn, tó bá rí i táwọn èèyàn ń jọ́sìn baba ńlá wọn tàbí àwọn òkè, omi, ẹranko, ẹyẹ, èèyàn tàbí ohunkóhun míì tó yàtọ̀ sí Jèhófà tó ń fẹ́ “ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe”! (Ẹ́kís. 20:5) Kódà, ọ̀pọ̀ èèyàn tí wọ́n rò pé àwọn ń jọ́sìn Ọlọ́run ni ẹ̀kọ́ èké àtàwọn ààtò ìsìn tí kò wúlò ti mú lẹ́rú. Ipò tí wọ́n wà máa ń ṣeni láàánú, ńṣe ni wọ́n dà bí àwọn tí Jèhófà pàrọwà fún pé: “Èé ṣe tí ẹ fi ń san owó fún ohun tí kì í ṣe oúnjẹ, èé sì ti ṣe tí làálàá yín jẹ́ fún ohun tí kì í yọrí sí ìtẹ́lọ́rùn? Ẹ fetí sí mi dáadáa, kí ẹ sì máa jẹ ohun tí ó dára, kí ọkàn yín sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀rá.”—Aísá. 55:2.
16, 17. (a) Kí nìdí tí Jésù fi sọ fún Pétérù pé: “Dẹ̀yìn lẹ́yìn mi, Sátánì”? (b) Ọ̀nà wo ni Sátánì lè gbà tàn wá jẹ tí a ò fi ní wà lójúfò mọ́?
16 Sátánì lè tan ìránṣẹ́ Jèhófà tó jẹ́ onítara jẹ. Bí àpẹẹrẹ, wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé wọn ò ní pẹ́ pa òun. Ó dájú pé èrò rere ni àpọ́sítélì Pétérù ní lọ́kàn nígbà tó mú Jésù lọ sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, tó sì sọ pé: “Ṣàánú ara rẹ, Olúwa; ìwọ kì yóò ní ìpín yìí rárá.” Jésù dá Pétérù lóhùn lọ́nà tó ṣe kedere pé: “Dẹ̀yìn lẹ́yìn mi, Sátánì!” (Mát. 16:22, 23) Kí nìdí tí Jésù fi pe Pétérù ní “Sátánì”? Ìdí ni pé Jésù mọ ohun tó fẹ́ ṣẹlẹ̀. Kò ní pẹ́ tí Jésù máa kú ikú ìrúbọ láti ṣe ìràpadà, táá sì fi hàn pé òpùrọ́ ni Èṣù. Àkókò pàtàkì yẹn nínú ìtàn aráyé kì í ṣe ìgbà tó yẹ kí Jésù “ṣàánú ara rẹ̀.” Ohun tí Sátánì fẹ́ ni pé kí Jésù dẹra nù nírú àkókò bẹ́ẹ̀.
17 Bí a ti ń sún mọ́ òpin ètò àwọn nǹkan yìí, àwa náà ń gbé ní àkókò tó le. Sátánì ń fẹ́ kí àwa náà dẹra nù, “kí á ṣàánú” ara wa kí á máa wá ibi tó tutù nínú ayé yìí láti fara pa mọ́ sí, tá ò sì ní lè wà lójúfò mọ́. Má ṣe jẹ́ kí ìyẹn ṣẹlẹ̀ sí ẹ láé! Kàkà bẹ́ẹ̀, ‘máa ṣọ́nà.’ (Mát. 24:42) Má ṣe gba ìpolongo ẹ̀tàn Sátánì gbọ́ pé òpin ayé ò tíì lè dé báyìí tàbí pé kò tiẹ̀ ní dé rárá.
18, 19. (a) Ọ̀nà wo ni Sátánì lè gbà tàn wá jẹ ká lè ní èrò òdì nípa ara wa? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè wà lójú fò ká sì máa ṣọ́nà?
18 Ọ̀nà míì wà tí Sátánì fi ń gbìyànjú láti tàn wá jẹ. Ó ń mú ká rò pé Ọlọ́run ò lè nífẹ̀ẹ́ wa àti pé ẹ̀ṣẹ̀ wa ò ní ìdáríjì. Gbogbo ìyẹn jẹ́ ara ìpolongo ẹ̀tàn látọ̀dọ̀ Sátánì. Ó ṣe tán, ta lẹni náà gan-an tí Jèhófà ò lè nífẹ̀ẹ́? Sátánì ni. Ta lẹni náà gan-an tí ò lè rí ìdáríjì? Sátánì náà ni. Àmọ́, Bíbélì fi dá wa lójú pé: “Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀.” (Héb. 6:10) Jèhófà mọrírì ìsapá wa bi á ti ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀, iṣẹ́ ìsìn wa kò sì já sásán. (Ka 1 Kọ́ríńtì 15:58.) Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ kí ìpolongo Sátánì tàn wá jẹ.
19 Gẹ́gẹ́ bá a ṣe rí i nínú àpilẹ̀kọ yìí, Sátánì lágbára, ó níkà, ó sì jẹ́ ẹlẹ́tàn. Báwo la ṣe máa borí àkòtagìrì ọ̀tá yìí? Jèhófà ò fi wá sílẹ̀ láìdáàbò bò wá. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ń kọ́ wa bá a ṣe lè yẹra fun ètekéte rẹ̀ nítorí a “kò ṣe aláìmọ àwọn ète-ọkàn rẹ̀.” (2 Kọ́r. 2:11) Tá a bá ti mọ ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ Sátánì, àá lè mọ ọ̀nà tó dára láti wà lójúfò ká sì máa ṣọ́nà. Àmọ́, mímọ̀ tá a mọ ète ọkàn Sátánì nìkan kò tó. Bíbélì sọ pé: “Ẹ kọ ojú ìjà sí Èṣù, yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ yín.” (Ják. 4:7) Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa jíròrò ọ̀nà mẹ́ta tá a lè gbà bá Sátánì jà ká sì borí.