ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwbr18 February ojú ìwé 1-7
  • Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
  • Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé—2018
  • Ìsọ̀rí
  • FEBRUARY 5-11
  • ABẸ́ ÀBÓJÚTÓ JÉSÙ LÓ WÀ
  • FEBRUARY 12-18
  • FEBRUARY 19-25
  • FEBRUARY 26–MARCH 4
Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé—2018
mwbr18 February ojú ìwé 1-7

Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni

FEBRUARY 5-11

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | MÁTÍÙ 12-13

“Àkàwé Àlìkámà àti Èpò”

w13 7/15 9-10 ¶2-3

“Wò Ó! Mo Wà Pẹ̀lú Yín Ní Gbogbo Àwọn Ọjọ́”

2 Kókó méjì ni ohun tó ṣẹlẹ̀ ní oko afúnrúgbìn yìí jẹ́ ká mọ̀. Àkọ́kọ́ ni bí Jésù ṣe máa kó àwọn tó fi wé àlìkámà yìí jọ láàárín aráyé. Àwọn tó fi wé àlìkámà yìí ni àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó máa ṣàkóso pẹ̀lú rẹ̀ nínú Ìjọba rẹ̀. Kókó kejì ni ìgbà tó máa kó wọn jọ. Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni ló bẹ̀rẹ̀ sí í fún irúgbìn náà. Kíkó àwọn àlìkámà jọ máa parí nígbà tí àwọn ẹni àmì òróró tó ṣẹ́ kù ní òpin ètò àwọn nǹkan yìí bá gba èdìdì wọn ìkẹyìn lẹ́yìn èyí tí wọ́n á wá lọ sí ọ̀run. (Mát. 24:31; Ìṣí. 7:​1-4) Bó ṣe jẹ́ pé téèyàn bá gorí òkè téńté, ó máa rọrùn láti rí ibi tó jìnnà níwá-lẹ́yìn àti lọ́tùn-ún-lósì, bẹ́ẹ̀ ni àkàwé yìí ṣe mú ká lóye kúlẹ̀kúlẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé láàárín nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún méjì gbáko. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó tan mọ́ Ìjọba Ọlọ́run wo la ti wá lóye? Àkàwé náà sọ nípa ìgbà tá a fún irúgbìn, ìgbà tó dàgbà àti ìgbà ìkórè. Àmọ́ ìgbà ìkórè yẹn nìkan la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí.

ABẸ́ ÀBÓJÚTÓ JÉSÙ LÓ WÀ

3 Ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kejì Sànmánì Kristẹni ni “àwọn èpò fara hàn,” nígbà táwọn Kristẹni afàwọ̀rajà bẹ̀rẹ̀ sí í gbilẹ̀. (Mát. 13:26) Nígbà tó fi máa di ọ̀rúndún kẹrin, àwọn Kristẹni tá a fi wé èpò yìí ti wá pọ̀ gan-an ju àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró lọ. Ẹ rántí pé nínú àkàwé Jésù, àwọn ẹrú náà sọ pé kí ọ̀gá náà jẹ́ káwọn lọ tu èpò tó wà nínú oko yẹn dà nù. (Mát. 13:28) Kí ni ọ̀gá wọn sọ?

w13 7/15 10 ¶4

“Wò Ó! Mo Wà Pẹ̀lú Yín Ní Gbogbo Àwọn Ọjọ́”

4 Nínú àkàwé àlìkámà àti èpò, Jésù sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí àwọn méjèèjì dàgbà pa pọ̀ títí di ìkórè.” Ohun tí ọ̀gá yìí sọ fáwọn ẹrú rẹ̀ fi hàn pé kò sígbà kan tí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, tá a fi wé àlìkámà kò sí lórí ilẹ̀ ayé, láti ọ̀rúndún kìíní títí di àkókò wa yìí. Ohun tí Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tún fi hàn pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí, ó sọ pé: “Mo wà pẹ̀lú yín ní gbogbo àwọn ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Mát. 28:20) Èyí fi hàn pé Jésù máa pa àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró mọ́ títí di àkókò òpin. Àmọ́, látàrí bí àwọn Kristẹni tá a fi wé èpò ṣe pọ̀ gan-an jù wọ́n lọ, a ò lè fi ìdánilójú sọ pé ẹni báyìí wà lára àwọn ojúlówó Kristẹni tá a fi wé àlìkámà ní gbogbo àkókò tí wọ́n fi dàgbà pọ̀ yẹn. Bó ti wù kó rí, ní nǹkan bí ọgbọ̀n ọdún ṣáájú àkókò ìkórè, àwọn ojúlówó Kristẹni tá a fi wé àlìkámà wá fara hàn kedere. Ọ̀nà wo ni wọ́n gbà fara hàn kedere?

w13 7/15 12 ¶10-12

“Wò Ó! Mo Wà Pẹ̀lú Yín Ní Gbogbo Àwọn Ọjọ́”

10 Àkọ́kọ́, kíkó àwọn èpò jọ. Jésù sọ pé: “Ní àsìkò ìkórè, ṣe ni èmi yóò sì sọ fún àwọn akárúgbìn pé, Ẹ kọ́kọ́ kó àwọn èpò jọ, kí ẹ sì dì wọ́n ní ìdìpọ̀-ìdìpọ̀.” Lẹ́yìn ọdún 1914, àwọn ańgẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí í kó àwọn Kristẹni tá a fi wé èpò jọ ní ti pé wọ́n ń yà wọ́n sọ́tọ̀ kúrò lára “àwọn ọmọ Ìjọba Ọlọ́run,” ìyẹn àwọn ẹni àmì òróró.”​—Mát. 13:​30, 38, 41.

11 Bí iṣẹ́ kíkó àwọn èpò jọ ṣe ń bá a lọ, bẹ́ẹ̀ ni ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwùjọ méjèèjì yìí túbọ̀ ń ṣe kedere. (Ìṣí. 18:​1, 4) Nígbà tó fi máa di ọdún 1919, ó ṣe kedere pé Bábílónì Ńlá ti ṣubú. Kí lohun pàtàkì tó mú kí àwọn Kristẹni tòótọ́ yàtọ̀ sí àwọn afàwọ̀rajà? Ohun náà ni iṣẹ́ ìwàásù. Àwọn tó ń múpò iwájú lára àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bẹ̀rẹ̀ sí í tẹnu mọ́ bó tí ṣe pàtàkì tó pé kí gbogbo Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì máa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, ìwé kan tí wọ́n tẹ̀ lọ́dún 1919, tí wọ́n pè ní To Whom the Work Is Entrusted, rọ gbogbo Kristẹni ẹni àmì òróró pé kí wọ́n máa wàásù láti ilé dé ilé. Ìwé náà sọ pé: “Iṣẹ́ náà lè dà bí èyí tó ń kani láyà lóòótọ́, àmọ́ iṣẹ́ Olúwa ni, òun ló sì máa fún wa lókun láti ṣe é. Àǹfààní ńlá la ní bí a ti ń ní ìpín nínú iṣẹ́ yìí.” Kí làwọn Kristẹni yẹn ṣe nígbà tí wọ́n ka ọ̀rọ̀ inú ìwé yìí? Ilé Ìṣọ́ 1922 (Gẹ̀ẹ́sì) ròyìn pé látìgbà yẹn lọ, ńṣe làwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì túbọ̀ tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù yìí. Kò pẹ́ kò jìnnà, ìwàásù ilé-dé-ilé di ohun táwọn èèyàn mọ̀ mọ àwọn Kristẹni olóòótọ́ yẹn, bó sì ṣe rí títí dòní náà nìyẹn.

12 Èkejì, kíkó àlìkámà jọ. Jésù pàṣẹ fáwọn ańgẹ́lì rẹ̀ pé: “Ẹ lọ kó àlìkámà jọ sínú ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ mi.” (Mát. 13:30) Àtọdún 1919 ni wọ́n ti ń kó àwọn ẹni àmì òróró sínú ìjọ Kristẹni tá a mú pa dà bọ̀ sípò. Ní ti àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó bá ṣì wà láàyè títí di òpin ètò àwọn nǹkan yìí, á máa kó wọn jọ nígbà tí wọ́n bá lọ sí ọ̀run.​—Dán. 7:​18, 22, 27.

Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 12:20

Òwú àtùpà: Láyé àtijọ́, amọ̀ ni wọ́n máa ń fi ṣe àtùpà, wọ́n á wá bu òróró ólífì sínú rẹ̀. Òwú àtùpà náà máa fa òróró sókè, kí iná lè máa jó. Ọ̀rọ̀ èdè Gíríìkì tí wọ́n tú sí “òwú àtùpà” lè jẹ́ òwú tó máa ń yọ èéfín tí iná orí rẹ̀ bá ti kẹ̀ bó ṣe ń jó lọ́úlọ́ú tàbí tí iná rẹ̀ bá ti kú. Aísáyà 42:3 sọ tẹ́lẹ̀ pé Jésù máa jẹ́ aláàánú, ó sọ pé kò ní fẹ́ iná ìrètí tó ṣẹ́ kù pa lára àwọn ẹni rírẹlẹ̀ àtàwọn tó sorí kọ́.

w16.10 32

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ṣé lóòótọ́ ni pé láyé àtijọ́ àwọn kan máa ń fún èpò sínú oko ẹlòmíì?

NÍNÚ Mátíù 13:​24-26, Jésù sọ pé: “Ìjọba ọ̀run wá dà bí ọkùnrin kan tí ó fún irúgbìn àtàtà sínú pápá rẹ̀. Nígbà tí àwọn ènìyàn ń sùn, ọ̀tá rẹ̀ wá, ó sì tún fún àwọn èpò sí àárín àlìkámà náà, ó sì lọ. Nígbà tí ewé ọ̀gbìn náà rú jáde, tí ó sì mú èso jáde, nígbà náà ni àwọn èpò fara hàn pẹ̀lú.” Àwọn òǹkọ̀wé kan sọ pé bóyá nirú ohun tí Jésù sọ nínú àpèjúwe yìí máa ń ṣẹlẹ̀. Síbẹ̀, àwọn ìwé òfin ilẹ̀ Róòmù fi hàn pé irú ẹ̀ máa ń ṣẹlẹ̀.

“Ìwé kan tó ń túmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì sọ pé: ‘Òfin Róòmù sọ pé ẹ̀ṣẹ̀ ni tẹ́nì kan bá fún èpò sóko olóko torí pé ó fẹ́ gbẹ̀san. Ti pé òfin wà fún irú nǹkan báyìí fi hàn pé ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ dáadáa ni.’ Alastair Kerr tó jẹ́ onímọ̀ nípa òfin sọ pé ní ọdún 533 Sànmánì Kristẹni, Olú Ọba Róòmù tó ń jẹ́ Justinian tẹ ìwé kan tó pè ní Digest jáde. Ìwé náà jẹ́ àkópọ̀ àwọn òfin ilẹ̀ Róòmù àtàwọn àkọsílẹ̀ látinú àwọn ẹjọ́ kan tí wọ́n ti dá sẹ́yìn láàárín ọdún 100 sí 250 Sànmánì Kristẹni. Nínú ìwé náà (ìyẹn Digest, 9.2.27.14), adájọ́ kan tó ń jẹ́ Ulpian tọ́ka sí ẹjọ́ kan tí àgbà òṣèlú ilẹ̀ Róòmù kan tó ń jẹ́ Celsus dá ní ọgọ́rùn-ún ọdún kejì. Nínú ẹjọ́ yẹn, ẹnì kan fún èpò sínú oko ẹlòmíì, èpò náà sì fún àwọn irúgbìn náà pa. Ìwé Digest náà sọ ẹjọ́ tí wọ́n máa dá tí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá wáyé, èyí á sì jẹ́ kí olóko náà lè gba ìtanràn lọ́wọ́ ọ̀daràn náà.

Torí náà, ó ṣe kedere pé ìwà burúkú yìí máa ń ṣẹlẹ̀ láwọn ilẹ̀ tí Róòmù ń ṣàkóso. Èyí fi hàn pé ohun tí Jésù sọ nínú àpèjúwe rẹ̀ máa ń ṣẹlẹ̀ lóòótọ́.

FEBRUARY 12-18

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | MÁTÍÙ 14-15

“Jésù Ń Tipasẹ̀ Àwọn Èèyàn Kéréje Bọ́ Ọ̀pọ̀ Èèyàn”

w13 7/15 15 ¶2

Jésù Ń Tipasẹ̀ Àwọn Èèyàn Kéréje Bọ́ Ọ̀pọ̀ Èèyàn

2 Nígbà tí Jésù rí ogunlọ́gọ̀ yẹn, àánú wọn ṣe é, torí náà, ó mú àwọn aláìsàn tó wà láàárín wọn lára dá, ó sì kọ́ wọn ní ohun púpọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run. Nígbà tó di pé ilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣú, àwọn ọmọ ẹ̀yìn sọ fún Jésù pé kó jẹ́ káwọn èèyàn náà máa lọ, kí wọ́n lè lọ wá oúnjẹ rà láwọn abúlé tó wà nítòsí. Ṣùgbọ́n, Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin ẹ fún wọn ní nǹkan láti jẹ.” Kò sí àní-àní pé ọ̀rọ̀ yìí rú àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà lójú gan-an, torí pé oúnjẹ tí wọ́n ní lọ́wọ́ kò tó nǹkan rárá, ìyẹn búrẹ́dì márùn-ún àti ẹja wẹ́wẹ́ méjì.

w13 7/15 15 ¶3

Jésù Ń Tipasẹ̀ Àwọn Èèyàn Kéréje Bọ́ Ọ̀pọ̀ Èèyàn

3 Jésù gba tàwọn èèyàn náà rò, ó wá ṣe iṣẹ́ ìyanu kan. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe ló wà lákọsílẹ̀, àmọ́ èyí ni iṣẹ́ ìyanu kan ṣoṣo tí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn tó kọ ìwé ìhìn rere sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. (Máàkù 6:​35-44; Lúùkù 9:​10-17; Jòhánù 6:​1-13) Jésù ní káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ fún àwọn èèyàn náà pé kí wọ́n jókòó ní àwùjọ-àwùjọ nǹkan bí àádọ́ta àti ọgọ́rùn-ún. Lẹ́yìn tí ó gbàdúrà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í bu búrẹ́dì àti ẹja náà sí wẹ́wẹ́. Àmọ́ kàkà tí òun alára ì bá fi pín oúnjẹ fún ogunlọ́gọ̀ náà, ńṣe ló gbé e ‘fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn láti gbé e kalẹ̀ níwájú ogunlọ́gọ̀ náà.’ Bó ṣe di pé àwọn èèyàn náà jẹun ní àjẹyó àti àjẹṣẹ́kù nìyẹn o. Kò sí àní-àní pé iṣẹ́ ìyanu lèyí! Ẹ tiẹ̀ rò ó wò ná: Jésù tipasẹ̀ àwọn èèyàn kéréje, ìyẹn àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá bọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn.

nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 14:21

àtàwọn obìnrin àti àwọn ọmọ kéékèèké: Àkọ́sílẹ̀ Mátíù nìkan ló mẹ́nu kan àwọn obìnrin àti àwọn ọmọ kéékèèké nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ ìyanu Jésù yìí. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé iye àwọn tí Jésù fi iṣẹ́ ìyanu bọ́ ju ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dógún [15,000] lọ.

w13 7/15 15 ¶1

Jésù Ń tipasẹ̀ Àwọn Èèyàn Kéréje Bọ́ Ọ̀pọ̀ Èèyàn

FOJÚ inú wo ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí ná. (Ka Mátíù 14:​14-21.) Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí wáyé nígbà tí àjọyọ̀ Ìrékọjá kù díẹ̀ lọ́dún 32 Sànmánì Kristẹni. Ogunlọ́gọ̀ tí iye wọn tó ẹgbẹ̀rún márùn-ún ọkùnrin, láìka àwọn obìnrin àtàwọn ọmọdé wà pẹ̀lú Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Ìtòsí ìlú Bẹtisáídà ni ibi tí wọ́n wà, ní abúlé kan nítòsí Òkun Gálílì, àgbègbè náà sì dá páropáro.

Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 15:7

alágàbàgebè: Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà hy·po·kri·tesʹ ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ ń tọ́ka sí àwọn ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì (nígbà tó yá wọ́n lo ọ̀rọ̀ náà fún àwọn ọmọ ilẹ̀ Róòmù) tó ń ṣeré orí ìtàgé, tí wọ́n máa ń wọ ìbòjú ńlá kan tó máa ń jẹ́ kí ohùn wọn ròkè tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀. Wọ́n tún máa ń lo ọ̀rọ̀ yìí lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ láti tọ́ka sí ẹnì kan tó máa fi irú ẹni tó jẹ́ pa mọ́ táá wá máa ṣojú ayé. Nínú ẹsẹ Bíbélì yìí, Jésù pe àwọn aṣáájú ìsìn Júù ní “alágàbàgebè.”​—Mt 6:​5, 16.

nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 15:26

àwọn ọmọdé . . . àwọn ajá kéékèèké: Lábẹ́ Òfin Mósè, àwọn ajá jẹ́ aláìmọ́, ìdí nìyẹn tí Ìwé Mímọ́ fi sábà máa ń lo ọ̀rọ̀ yìí lọ́nà tó ń bu nǹkan kù. (Le 11:27; Mt 7:6; Flp 3:2; Iṣi 22:15) Àmọ́ nígbà tí Máàkù (7:27) àti Mátíù ń ṣàkọsílẹ̀ ìjíròrò tó wáyé láàárín Jésù àti obìnrin yẹn, wọn ò kàn sọ pé ajá, àmọ́ ńṣe ni wọ́n lo gbólóhùn náà “àwọn ajá kéékèèké” tàbí “ajá ilé,” èyí sì rọ àpèjúwe náà lójú. Èyí fi hàn pé ọ̀rọ̀ jèlẹ́ńkẹ́ ni Jésù lò fún àwọn ohun ọ̀sìn tó máa ń wà nílé àwọn tí kì í ṣe Júù. Nígbà tí Jésù pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní “àwọn ọmọ” tó sì pe àwọn tí kì í ṣe Júù ní “ajá kéékèèké,” ohun tó fẹ́ fà yọ ní pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ló yẹ kí òun kọ́kọ́ bójú tó. Tí ebi bá ń pa ọmọ, tí ebi sì ń pa ajá nílé kan náà, ó dájú pé ọmọ la máa kọ́kọ́ fún lóúnjẹ.

FEBRUARY 19-25

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | MÁTÍÙ 16-17

“Èrò Ta Ni Ò Ń Rò?”

w07 2/15 16 ¶17

Ẹ̀yin Ọkọ, Ẹ Mọ Kristi Ní Orí Yín

17 Ní àkókò mìíràn, Jésù sọ fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé òun gbọ́dọ̀ lọ sí Jerúsálẹ́mù, níbi tóun yóò ti fojú winá inúnibíni látọ̀dọ̀ “àwọn àgbà ọkùnrin àti àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin, kí wọ́n sì pa òun, kí a sì gbé òun dìde ní ọjọ́ kẹta.” Látàrí èyí, Pétérù mú Jésù lọ sí ẹ̀gbẹ́ kan, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá a wí lọ́nà mímúná, pé: “Ṣàánú ara rẹ, Olúwa; ìwọ kì yóò ní ìpín yìí rárá.” Kò sí àní-àní pé ìfẹ́ tí Pétérù ní sí Jésù ti ru bò ó lójú débi pé kò mọ irú ìmọ̀ràn tó yẹ kó fún Jésù. Ìyẹn ló fi yẹ kí Jésù tọ́ ọ sọ́nà. Jésù sì sọ fún un pé: “Dẹ̀yìn lẹ́yìn mi, Sátánì! Ohun ìkọ̀sẹ̀ ni ìwọ jẹ́ fún mi, nítorí kì í ṣe àwọn ìrònú Ọlọ́run ni ìwọ ń rò, bí kò ṣe ti ènìyàn.”​—Mátíù 16:​21-23.

w06 4/1 23 ¶9

‘Ẹ Lọ, Ẹ Máa Sọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn, Ẹ Máa Batisí Wọn’

9 Kí ni títẹ̀lé àpẹẹrẹ Jésù nínú ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run gba pé ká ṣe? Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ níní ara rẹ̀, kí ó sì gbé òpó igi oró rẹ̀, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn nígbà gbogbo.” (Mátíù 16:24) Nínú ọ̀rọ̀ yìí, Jésù mẹ́nu kan ohun mẹ́ta tá a gbọ́dọ̀ ṣe. Ìkíní, a ó “sẹ́” ara wa. Ìyẹn ni pé a ó kọ ìtẹ̀sí ọkàn wa tó máa ń dá lórí ìmọtara-ẹni-nìkan àti àìpé sílẹ̀, a ó sì máa ṣègbọràn sí ìmọ̀ràn àti ìtọ́ni Ọlọ́run. Ìkejì, a ó ‘gbé òpó igi oró wa.’ Nígbà ayé Jésù, àmì ìtìjú àti ìyà ni òpó igi oró jẹ́. Nítorí pé a jẹ́ Kristẹni, a gbà pé àwa náà lè jìyà nítorí ìhìn rere nígbà míì. (2 Tímótì 1:8) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ayé lè fi wá ṣe yẹ̀yẹ́ tàbí kí wọ́n pẹ̀gàn wa, síbẹ̀ bíi ti Kristi, à ń ‘tẹ́ńbẹ́lú ìtìjú,’ inú wa sì ń dùn pé à ń múnú Ọlọ́run dùn. (Hébérù 12:2) Èyí tó kẹ́yìn ni pé, a ó máa tẹ̀ lé Jésù “nígbà gbogbo.”​—Sáàmù 73:26; 119:44; 145:2.

Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 16:18

Ìwọ ni Pétérù, orí àpáta yìí: Tí á bá lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà peʹtros fún ọkùnrin ó máa ń túmọ̀ sí “ègé òkúta.” Níbí, ó dúró fún orúkọ èèyàn (ìyẹn Pétérù), tó jẹ́ orúkọ èdè Gíríìkì tí Jésù fún Símónì. (Jo 1:42) Àmọ́ tí a bá lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà peʹtra fún obìnrin, ó máa ń túmọ̀ sí “àpáta ràbàtà.” Ọ̀rọ̀ Gíríìkì yìí tún fara hàn nínú Mt 7:​24, 25; 27:60; Lk 6:48; 8:6; Ro 9:33; 1Kọ 10:4; 1Pe 2:8. Ó hàn pé Pétérù kò ka ara rẹ̀ sí àpáta tí Jésù máa kọ́ ìjọ rẹ̀ lé, torí ó sọ ní 1 Pétérù 2: 4-8 pé Jésù ni “òkúta ìpìlẹ̀ igun ilé,” tí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yàn gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú àsọtẹ́lẹ̀. Bákan náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pe Jésù ní “ìpìlẹ̀” àti “àpáta ràbàtà ti ẹ̀mí.” (1Kọ 3:11; 10:4) Ìfọ̀rọ̀dárà ni Jésù lò níbí, bí ìgbà tó ń sọ pé: ‘Ìwọ tí mo pè ní Pétérù, (tí ó túmọ̀ sí “Òkúta Kan”) ti mọ ẹni tí Kristi jẹ́, ìyẹn “àpáta ràbàtà yìí,” ẹni tó máa jẹ́ ìpìlẹ̀ tí a óò kọ́ ìjọ Kristẹni lé.’

ìjọ: Ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tí ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà ek·kle·siʹa fara hàn. Ó wá látinú ọ̀rọ̀ Gíríìkì méjì, ek, tó túmọ̀ sí “ìta,” àti ka·leʹo, tó túmọ̀ sí “láti pè.” Ó ń tọ́ka sí àwùjọ èèyàn tí wọ́n péjọ láti ṣe nǹkan kan pọ̀. (Wo àwọn àlàyé ọ̀rọ̀ inú Bíbélì.) Níbí, Jésù sọ tẹ́lẹ̀ nípa bí wọ́n á ṣe dá ìjọ Kristẹni sílẹ̀, pé ó máa ní àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí wọ́n jẹ́ “àwọn òkúta ààyè” “tí wọ́n fi kọ́ ilé tẹ̀mí.” (1Pe 2:​4, 5) Wọ́n sábà máa ń lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì yìí nínú Septuagint bí àfirọ́pò fún ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n tú sí “ìjọ,” tí ó dúró fún odindi àwọn èèyàn Ọlọ́run. (Di 23:3; 31:30) Nínú Iṣe 7:​38, Ọlọ́run pe àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde ní Íjíbítì ó sì pè wọ́n ní “ìjọ.” Bákan náà, àwọn Kristẹni tí a “pè jáde. . . kúrò nínú òkùnkùn “ tí a sì “yàn. . . kúrò nínú ayé” ló para pọ̀ di “ìjọ Ọlọ́run.”​—1Pe 2:9; Jo 15:19; 1Kọ 1:2

nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 16:19

àwọn kọ́kọ́rọ́ Ìjọba ọ̀run: Nínú Bíbélì, tí wọ́n bá sọ pé wọ́n fún ẹnì kan ní kọ́kọ́rọ́, yálà ní ti gidi tàbí lọ́nà àpèjúwe, ohun tó túmọ̀ sí ni pé wọ́n fún ẹni náà ní ọlá àṣẹ kan. (1Kr 9: 26, 27; Ais 22:​20-22) Torí náà, ọ̀rọ̀ náà “kọ́kọ́rọ́” dúró fún ọlá àṣẹ àti ojúṣe pàtàkì. Pétérù lo àwọn “kọ́kọ́rọ́” tí wọ́n fún un láti ṣí àǹfààní sílẹ̀ fún àwọn Júù (Iṣe 2:​22-41), àwọn ará Samáríà (Iṣe 8:​14-17), àti àwọn Kèfèrí (Iṣe 10:​34-38) kí wọ́n lè gba ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run káwọn náà lè ní àǹfààní láti wọ Ìjọba ọ̀run.

FEBRUARY 26–MARCH 4

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | MÁTÍÙ 18-19

“Yẹra Pátápátá fún Ohun Tó Lè Mú Ìwọ Àtàwọn Míì Kọsẹ̀”

nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 18:​6, 7

ọlọ tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ máa ń yí: Tàbí “ọlọ ńlá.” Ní olówuuru, a lè pè é ní “ọlọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.” Irú ọlọ bẹ́ẹ̀ lè fẹ̀ tó 1.2-1.5 mítà (ìyẹn 4-5 ft), ó sì máa ń wúwo débi pé àfi kéèyàn fi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yí i.

ohun ìkọ̀sẹ̀: Ní ìpilẹ̀ṣẹ̀, ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n lò fún ọ̀rọ̀ yìí ni skanʹda·lon, tí wọ́n tú sí “ohun ìkọ̀sẹ̀.” Àwọn kan gbà pé ó tọ́ka sí ìdẹkùn; ní pàtàkì pé ó dúró fún igi tí wọ́n ń fi ìjẹ há lára ìdẹkùn. Bó ti wù kó rí, ó pa dà wá jẹ́ ohun kan tó lè kọni lẹ́sẹ̀ tàbí gbéni ṣubú. Lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, ó ń tọ́ka sí ìwà kan tàbí ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó mú kí ẹnì kan ṣe ohun tí kò tọ́, kó kọsẹ̀, kó hùwàkiwà tàbí kó ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀. A tún lè rí ọ̀rọ̀ ìṣe kan tó sún mọ́ ohun tá à ń sọ yìí ní Mt 18:​8, 9, tí wọ́n pè ní skan·da·liʹzo lédè Gíríìkì tó túmọ̀ sí “mú kọsẹ̀,” èyí tó tún lè tọ́ka sí “di ìdẹkùn; mú dẹ́ṣẹ́.”

nwtsty àwòrán àti fídíò

Ọlọ

Wọ́n sábà máa ń lo ọlọ láti lọ ọkà tàbí láti fún òróro jáde lára àwọn èso ólífì. Àwọn míì kéré, èèyàn sì lè fi ọwọ́ gbé e, àmọ́ àwọn míì tóbi débi pé ẹranko ni wón lè fi yí i. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ irú ọlọ ńlá bẹ́ẹ̀ ni àwọn Filísínì fipá mú kí Sámúsìnì yí. (Ond 16:21) Kì í ṣe ilẹ̀ Ísírẹ́lì nìkan ni irú ọlọ ńlá yìí tí àwọn ẹranko máa ń yí ti wọ́pọ̀, ó tún wà káàkiri Ilẹ̀ Ọba Róòmù.

Ọmọ Ọlọ àti Ìya Ọlọ

Ọlọ ńlá bí irú èyí tó wà nínú àwòrán yìí ni wọ́n sábà máa ń lo àwọn ẹran bí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ láti yí, tí wọ́n bá fẹ́ lọ ọkà tàbí tí wọ́n bá fẹ́ fọ́ àwọn èso ólífì. Ọmọ ọlọ lè tóbi tó 1.5 mítà (5 ft) ní ìbú, tí wọ́n á sí máa yí i lórí ìyá ọlọ tó tóbi gan-an.

nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 18:9

Gẹ̀hẹ́nà: Inú ọ̀rọ̀ Hébérù náà geh hin·nomʹ, ni wọ́n ti tú ọ̀rọ̀ Gíríìkì yìí, ìtumọ̀ rẹ̀ sì ni “àfonífojì Hínómù,” tí ó wà ní apá Ìwọ̀ Oòrùn àti Gúúsù ìlú Jerúsálẹ́mù àtijọ́. (Wo App. B12, àwòrán ilẹ̀ “Jerúsálẹ́mù àti Àgbègbè Rẹ̀.”) Nígbà tó máa fi di ìgbà ayé Jésù, afonífojì yẹn ti di ibi tí wọ́n ti ń sun ìdọ̀tí, torí náà ọ̀rọ̀ náà “Gẹ̀hẹ́nà” bá a mu wẹ́kú bí wọ́n ṣe lò ó fún ìparun pátápátá.

nwtstg Àwọn àlàyé ọ̀rọ̀ inú Bíbélì

Gẹ̀hẹ́nà

Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n lò fún Àfonífojì Hínómù, tí ó wà ní apá ìwọ̀ oòrùn àti gúúsù ìlú Jerúsálẹ́mù àtijọ́. (Jer 7:31) Nínú àsọtẹ́lẹ̀ kan, wọ́n pè é ní ibi tí wọ́n ń ju òkú sí. (Jer 7:32; 19:6) Kò sí ẹ̀rí tó fi hàn pé wọ́n ń sọ ẹranko tàbí èèyàn sí Gẹ̀hẹ́nà kí wọ́n lè sun wọ́n láàyè tàbí kí wọ́n fi iná dá wọn lóró. Torí náà, ibẹ̀ kò lè dúró fún ibi ìṣàpẹẹrẹ tí kò ṣeé fojú rí tí wọ́n ti ń dá àwọn ẹ̀mí àwọn èèyàn lóró títí ayérayé nínú iná. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lo Gẹ̀hẹ́nà láti ṣàpẹẹrẹ ohun tá a lè pé ní ìyà àyerayé, ìyẹn “ikú kejì,” tó dúro fún ìparun ayérayé, ìparun pátápátá.​—Iṣi 20:14; Mt 5:22; 10:28.

nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 18:10

wo ojú Baba mi: Tàbí “rí Baba mi.” Àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí nìkan ló lè rí ojú Ọlọ́run torí pé wọ́n láǹfààní láti wọlé wá síwájú Ọlọ́run.​—Ek 33:20.

w10 11/1 16

Ipa Wo Làwọn Áńgẹ́lì Ń Ní Lórí Wa

Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé, ara iṣẹ́ àwọn áńgẹ́lì ni láti ṣèrànwọ́ fún àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run kí àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run má bàa bà jẹ́. Nítorí náà, nígbà tí Jésù ń kìlọ̀ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé wọn kò gbọ́dọ̀ fa ìkọ̀sẹ̀ fún àwọn ẹlòmíì, ó sọ pé: “Ẹ rí i pé ẹ kò tẹ́ńbẹ́lú ọ̀kan nínú àwọn ẹni kékeré wọ̀nyí; nítorí mo sọ fún yín pé nígbà gbogbo ni àwọn áńgẹ́lì wọn ní ọ̀run ń wo ojú Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run.” (Mátíù 18:10) Ohun tí Jésù ń sọ níbí yìí kì í ṣe pé Ọlọ́run yan áńgẹ́lì kọ̀ọ̀kan fún àwọn ọmọlẹ́yìn kọ̀ọ̀kan láti máa dáàbò bò wọ́n. Ohun tí Jésù ń sọ ni pé, àwọn áńgẹ́lì tó ń bá Ọlọ́run ṣiṣẹ́ ń wá ire àwọn Kristẹni tòótọ́.

Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 18:22

Ìgbà 77: ní olówuuru, “ìgbà àádọ́rin lé méje.” Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n lò lé túmọ̀ sí “70 àti 7” (ìyẹn 77 ìgbà) tàbí “70 lọ́nà 7” (tó jẹ́ 490 ìgbà). Ọ̀rọ̀ kan náà fara hàn nínú Septuagint ní Je 4:​24, wọ́n sì tú ọ̀rọ̀ Hébérù náà sí “77 ìgbà,” tó bá ohun tá a kọ́kọ́ sọ mu pé ó jẹ́ “77 ìgbà.” Ọ̀nà yòówù ká gbà lóye rẹ̀, bí wọ́n ṣe pe nọ́ńbà náà ní ẹ̀ẹ̀mejì ń tọ́ka sí “títí gbére” tàbí “láìní iye.” Nígbà tí Jésù sọ fún Pétérù pé kì í ṣe ìgbà méje, bí kò ṣe ìgbà àádọ́rin lé méje, ohun tó ń sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ni pé kí wọ́n má ṣe gbé òfin kalẹ̀ fún ara wọn lórí iye ìgbà tó yẹ kí wọ́n máa dárí jini. Àmọ́ ohun tí Ìwé Támọ́dì àwọn ará Bábílónì (Yoma 86b) sọ yàtọ̀ pátápátá, ó ní: “Bí ẹnì kan bá dẹ́ṣẹ̀ kan lákọ̀ọ́kọ́, lẹ́ẹ̀kejì àti lẹ́ẹ̀kẹta èèyàn lè dárí jì í, àmọ́ a ò gbọ́dọ̀ dárí jì í lẹ́ẹ̀kẹrin.”

nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 19:7

ìwé ẹ̀rí ìlélọ: Tàbí “ìwé ìkọ̀sílẹ̀.” Bí òfin ṣe béèrè pé kí ọkùnrin kan tó fẹ́ pinnu láti kọ aya rẹ̀ sílẹ̀ kọ́kọ́ ṣe ìwé lábẹ́ òfin, kó sì kàn sí àwọn àgbààgbà, ńṣe ni òfin ń fún irú ọkùnrin bẹ́ẹ̀ láyè láti tún inú rò kó tó ṣe irú ìpinnu ńlá bẹ́ẹ̀. Pàtàkì ibẹ̀ ni pé, Òfin kò fàyè gba ìkọ̀sílẹ̀ lórí àwọn ẹ̀sùn tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, òfin yìí sì dáàbò bo ẹ̀tọ́ àwọn obìnrin dé ìwọ̀n àyè kan. (Di 24:1) Àmọ́ láyé ìgbà Jésù, ńṣe làwọn aṣáájú ẹ̀sìn mú kí ìkọ̀sílẹ̀ rọrùn fáwọn èèyàn láti ṣe. Josephus tó jẹ́ Farisí àti òpìtàn ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, tí òun fúnra rẹ̀ ti kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn èèyàn lè kọ ara wọn sílẹ̀ “fún ìdí èyíkéyìí (ọkùnrin ló sì pọ̀ jù nínú àwọn tó ń ṣe bẹ́ẹ̀).”

nwtsty àwòrán àti fídíò

Ìwé Ìkọ̀sílẹ̀

Ìwé ìkọ̀sílẹ̀ yìí ti wà láti ọdún 71 tàbí 72 Sànmánì Kristẹni, ní èdè Árámáíkì. Wọ́n rí i lápá àríwá àgbègbè tí wọ́n ń pè ní Wadi Murabbaat, tó jẹ́ ojú odò kan tó ti gbẹ ní aṣálẹ̀ ilẹ̀ Júdà. Ìwé ẹ̀rí náà sọ pé ní ọdún kẹfà táwọn Júù ti wà lẹ́nu ìdìtẹ̀ sí ìjọba Róòmù, Jósẹ́fù ọmọ Naqsan tó ń gbé ìlú Màsádà kọ ìyàwó rẹ̀ Míríámù ọmọ Jónátánì láti ìlú Hanablata sílẹ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́