Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
MARCH 5-11
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | MÁTÍÙ 20-21
“Ẹnì Yòówù Tí Ó Bá Fẹ́ Di Ẹni Ńlá Láàárín Yín Gbọ́dọ̀ Jẹ́ Òjíṣẹ́ Yín”
nwtsty àwòrán àti fídíò
Ibi Ọjà
Ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà ni àwọn ibi ọjà kan máa ń wà bí irú èyí tó wà nínú àwòrán yìí. Àwọn ọlọ́jà sábà máa ń pàtẹ ọjà wọn sójú ọ̀nà, èyí sì máa ń jẹ́ kí ọ̀nà dí. Àwọn tó ń gbé níbi tí ọjà wà máa ń rí àwọn ohun èlò ilé rà, irú bíi ìṣasùn, àwọn àwo tó wọ́n gan-an àtàwọn nǹkan oko tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde. Torí pé kò sí fìríìjì láyé ìgbà yẹn, ojoojúmọ́ làwọn èèyàn máa ń lọ sọ́jà láti ra nǹkan. Inú ọjà yìí náà làwọn tó wá rajà ti máa ń gbọ́ ìròyìn táwọn oníṣòwò míì àtàwọn àlejò mú wá, àwọn ọmọdé máa ń ṣeré kiri, àwọn tó ń wáṣẹ́ náà á dúró dé àwọn tó máa gbéṣẹ́ fún wọn. Jésù wo aláìsàn sàn ní ibi ọjà, Pọ́ọ̀lù náà wàásù níbẹ̀. (Iṣe 17:17) Àmọ́, ọ̀rọ̀ àwọn akọ̀wé òfin àtàwọn Farisí agbéraga yàtọ̀ síyẹn, wọ́n fẹ́ràn kí àwọn èèyàn máa pàfíyèsí sí wọn, kí wọ́n sì máa kí wọn láwọn ibi téèyàn pọ̀ sí.
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 20:20, 21
ìyá àwọn ọmọkùnrin Sébédè: Ìyẹn ìyá àpọ́sítélì Jákọ́bù àti Jòhánù. Gẹ́gẹ́ bí Máàkù ṣe sọ, Jákọ́bù àti Jòhánù ló lọ bá Jésù. Ẹ̀rí fi hàn pé àwọn gan-an ló fẹ́ béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ Jésù, àmọ́ wọ́n ní kí ìyà wọn, Sàlómẹ̀ tó ṣeé ṣe kó jẹ́ àǹtí Jésù bá wọn béèrè.—Mt 27:55, 56; Mk 15:40, 41; Jo 19:25.
ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ àti ọ̀kan ní òsì rẹ: Ọwọ́ ọ̀tún àti ọwọ́ òsì tí ibí yìí sọ dúró fún ipò ọlá àti ipò àṣẹ, àmọ́ ọwọ́ ọ̀tún ló ní ọlá jù nínú méjéèjì.—Sm 110:1; Iṣe 7:55, 56; Ro 8:34.
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 20:26, 28
òjíṣẹ́: Tàbí “ìránṣẹ́.” Bíbélì sábà máa ń lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà di·aʹko·nos fún ẹni tí kò jẹ́ kó sú òun láti máa jíṣẹ́ fún àwọn ẹlòmíì. Bíbélì lo ọ̀rọ̀ yìí fún Kristi (Ro 15:8), àwọn òjíṣẹ́ tàbí ìránṣẹ́ Kristi (1Kọ 3:5-7; Kol 1:23), àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ (Flp 1:1; 1Ti 3:8), títí kan àwọn tí wọ́n ń rán níṣẹ́ nínú ilé (Jo 2:5, 9) àtàwọn òṣìṣẹ́ ìjọba (Ro 13:4).
kì í ṣe kí a lè ṣe ìránṣẹ́ fún un, bí kò ṣe kí ó lè ṣe ìránṣẹ́: Tàbí “kì í ṣe kò lè máa rán àwọn èèyàn níṣẹ́, bí kò ṣe kó jíṣẹ́ fún àwọn èèyàn.”
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 21:9
Gbà là, ni àwa bẹ̀bẹ̀: Ní olówuuru ó túmọ̀ sí “Hòsánà.” Ọ̀rọ̀ Gíríìkì yẹn wá látinú gbólóhùn èdè Hébérù tó túmọ̀ sí “gbà là, ni àwa gbàdúrà” tàbí “jọ̀wọ́, gbà wá là.” Bí wọ́n ṣe lo ọ̀rọ̀ yìí níbí jẹ́ ẹ̀bẹ̀ sí Ọlọ́run pé kó gbà wọ́n là tàbí kó ṣẹ́gun fún àwọn; wọ́n tún lè sọ pé “jọ̀wọ́, fún wa ní ìgbàlà.” Nígbà tó yá, ó wá di ọ̀rọ̀ àdúrà àti ọ̀rọ̀ ìyìn. Ní àwọn ìgbà àjọyọ̀ Ìrékọjá, wọ́n máa ń lo ọ̀rọ̀ Hébérù tó wà ní Sm 118:25, tó wà lára àwọn Sáàmù Hálẹ́lì nínú àwọn orin tí wọ́n máa ń kọ. Torí náà, wọ́n máa ń rántí ọ̀rọ̀ yìí làwọn àkókò àjọyọ̀ yẹn. Ọ̀nà kan tí Ọlọ́run gbà dáhùn àdúrà yìí pé kó gba Ọmọ Dáfídì là ni bó ṣe jí i dìde nígbà tó kú. Nínú Mt 21:42, Jésù fúnra ẹ̀ fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Sm 118:22, 23, ó sì fi hàn pé ó ṣẹ sí Mèsáyà lára.
Ọmọkùnrin Dáfídì: Bí wọ́n ṣe lo ọ̀rọ̀ yìí níbí jẹ́ ká mọ ìlà ìdílé tí Jésù ti wá àti ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí.
jy 244 ¶4-6
Jésù Fi Igi Ọ̀pọ̀tọ́ Kan Kọ́ Wọn Lẹ́kọ̀ọ́ Nípa Ìgbàgbọ́
Àmọ́ kí nìdí tí Jésù fi jẹ́ kí igi náà rọ? Ó sọ ìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ tó sọ pé: “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, bí ẹ bá sáà ti ní ìgbàgbọ́, tí ẹ kò sì ṣiyèméjì, kì í ṣe pé ẹ ó ṣe ohun ti mo ṣe sí igi ọ̀pọ̀tọ́ náà nìkan ni, ṣùgbọ́n bí ẹ bá sọ fún òkè ńlá yìí pẹ̀lú pé, ‘Gbéra sọ sínú òkun,’ yóò ṣẹlẹ̀. Gbogbo ohun tí ẹ bá sì béèrè nínú àdúrà, pẹ̀lú ìgbàgbọ́, ni ẹ óò rí gbà.” (Mátíù 21:21, 22) Jésù ń tipa báyìí tún kókó pàtàkì tó sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìgbàgbọ́ sọ pé ìgbàgbọ́ á jẹ́ kí wọ́n lè ṣí òkè nípò.—Mátíù 17:20.
Torí náà, Jésù jẹ́ kí igi náà rọ kó lè kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì nípa ìdí tó fi yẹ kí wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run. Ó sọ pé: “Gbogbo ohun tí ẹ bá gbàdúrà fún, tí ẹ sì béèrè, ẹ ní ìgbàgbọ́ pé ẹ kúkú ti rí wọn gbà, ẹ ó sì ní wọn.” (Máàkù 11:24) Ẹ ò rí i pé ẹ̀kọ́ pàtàkì lèyí jẹ́ fún gbogbo ọmọlẹ́yìn Jésù! Ó sì yẹ kí àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ fi ẹ̀kọ́ yìí sọ́kàn torí àwọn àdánwò tí wọ́n máa kojú láìpẹ́. Àmọ́ bí igi ọ̀pọ̀tọ́ náà ṣe rọ tún tan mọ́ bí ìgbàgbọ́ ṣe lágbára tó.
Bíi ti igi ọ̀pọ̀tọ́ yìí, ó fẹ́ jọ pé orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ń ṣe dáadáa. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti bá Ọlọ́run dá májẹ̀mú, wọ́n sì ń ṣe bí ẹni pé wọ́n ń pa Òfin Ọlọ́run mọ́. Àmọ́, gbogbo orílẹ̀-èdè yẹn lápapọ̀ ti fi hàn pé àwọn ò nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run àti pé wọn ò so èso rere. Wọ́n tiẹ̀ kọ Ọmọ Ọlọ́run sílẹ̀! Torí náà, bí Jésù ṣe jẹ́ kí igi ọ̀pọ̀tọ́ náà rọ ṣàpẹẹrẹ ohun tó máa gbẹ̀yìn orílẹ̀-èdè aláìléso àti aláìgbàgbọ́ yẹn.
Bíbélì Kíkà
MARCH 12-18
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | MÁTÍÙ 22-23
“Máa Tẹ̀ Lé Àwọn Àṣẹ Méjì Tó Tóbi Jù Lọ”
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 22:37
ọkàn-àyà: Tí wọ́n bá lò ó lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, ọ̀rọ̀ náà túmọ̀ sí irú ẹni tí ẹnì kan jẹ́ gan-an. Àmọ́, tí wọ́n bá lò ó pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ bíi “ọkàn” àti “èrò inú,” ó tún máa ń ní ìtumọ̀ tó ṣe pàtó, ó sì máa ń tọ́ka sí bí nǹkan ṣe máa ń rí lára ẹni àti ohun tẹ́nì kan nífẹ̀ẹ́ sí. Bí Bíbélì ṣe lo ọ̀rọ̀ mẹ́ta yìí (ọkàn-àyà, ọkàn àti èrò inú) níbí kò túmọ̀ sí pé ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn dá wà lọ́tọ̀; Bíbélì lò wọ́n lọ́nà tó fi hàn pé wọ́n so kọ́ra, ó sì fi ìtẹnumọ́ tó lágbára gan-an sọ ìdí pàtàkì tó fi yẹ ká ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀, tó sì wá látọkàn sí Ọlọ́run.
ọkàn: Tàbí “gbogbo ohun téèyàn jẹ́.”
èrò inú: Ìyẹn ni làákàyè. Ó yẹ kéèyàn fi làákàyè rẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run, kó sì túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. (Jo 17:3; Ro 12:1) Nínú Di 6:5, ọ̀rọ̀ mẹ́ta tó wá látinú èdè Hébérù tó wà nínú ẹsẹ yẹn ni, ‘ọkàn-àyà, ọkàn àti okunra.’ Àmọ́, nínú ìhìn rere Mátíù tó wà lédè Gíríìkì, ọ̀rọ̀ náà “èrò inú” ni wọ́n lò dípò “okunra.” Ó ṣeé ṣe kó láwọn ìdí tí wọ́n fi lo ọ̀rọ̀ tó yàtọ̀ síra. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò ní ọ̀rọ̀ kan pàtó fún “èrò inú” nínú èdè Hébérù àtijọ́, wọ́n sábà máa ń lo ọ̀rọ̀ náà “ọkàn” fún èrò inú. Tí wọ́n bá lo ọ̀rọ̀ yìí lọ́nà àpẹẹrẹ, ó máa ń tọ́ka sí gbogbo ohun téèyàn jẹ́ gan-an, tó fi mọ́ bí èèyàn ṣe ń ronú, bí ọ̀rọ̀ ṣe ń rí lára rẹ̀, ìwà àti ìṣe rẹ̀ àti ohun tó ń mú kó ṣe nǹkan. (Di 29:4; Sm 26:2; 64:6; wo àlàyé ọ̀rọ̀ lórí ọkàn nínú ẹsẹ yìí.) Fún ìdí yìí, níbi tí wọ́n bá ti lo ọ̀rọ̀ náà “ọkàn,” nínú Bíbélì lédè Hébérù, “èrò inú” ni Bíbélì Septuagint lédè Gíríìkì sábà máa ń lò. (Jẹ 8:21; 17:17; Owe 2:10; Ais 14:13) Ìdí míì tó ṣeé ṣe kó mú kí Mátíù lo ọ̀rọ̀ náà “èrò inú” dípò “okunra” nígbà tó ń fa ọ̀rọ̀ inú Di 6:5 yọ ni pé ọ̀rọ̀ Hébérù náà tí wọ́n tú sí “okunra” lè túmọ̀ sí okun nípa ti ara àti làákàyè. Ohun yòówù kó jẹ́, bí ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ èdè Hébérù àti Gíríìkì yìí ṣe wọnú ara jẹ́ ká lè ṣàlàyé ìdí tí àwọn tó kọ àwọn ìwé Ìhìn Rere kò fi lo ọ̀rọ̀ kan náà nígbà tí wọ́n fa ọ̀rọ̀ yọ látinú ìwé Diutarónómì.
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 22:39
Èkejì: Èsì tí Jésù fún Farisí yìí ló wà nínú Mt 22:37, àmọ́ ìdáhùn Jésù ju ohun tó béèrè lọ, ó tọ́ka sí òfin kejì (Le 19:18), ó jẹ́ kó mọ̀ pé òfin méjèèjì so kọ́ra gan-an àti pé orí wọn ni gbogbo Òfin àti àwọn Wòlíì dá lé.—Mt 22:40.
aládùúgbò: Ọ̀rọ̀ Gíríìkì yìí tí wọ́n lò fún “aládùúgbò” (ní olówuuru, “ẹni tó sún mọ́ni”) kọjá àwọn tó ń gbé nítòsí ẹni. Ó lè tọ́ka sí ẹnikẹ́ni tá a jọ máa ń ṣe nǹkan pọ̀.—Lk 10:29-37; Ro 13:8-10.
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 22:40
Òfin . . . àwọn Wòlíì: “Òfin” tọ́ka sí àwọn ìwé Bíbélì láti Jẹ́nẹ́sísì dé Diutarónómì. “Àwọn Wòlíì” tọ́kà sí àwọn ìwé Mímọ́ lédè Hébérù tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀. Àmọ́, tí wọ́n bá sọ pé òfin àti àwọn wòlíì, gbogbo ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ló ń tọ́ka sí.—Mt 7:12; 22:40; Lk 16:16.
so kọ́: Ọ̀rọ̀ ìṣe èdè Gíríìkì tó ní ìtumọ̀ olówuuru náà “kí nǹkan so kọ́” tí wọ́n lò níbí lọ́nà àpẹẹrẹ túmọ̀ sí pé “ó dúró lórí; ó dá lé.” Jésù tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé Òfin Mẹ́wàá àti gbogbo ọ̀rọ̀ inú ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù pátá ló dá lórí ìfẹ́.—Ro 13:9.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 22:21
àwọn ohun ti Késárì padà fún Késárì: Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ níbí àti ohun tó wà nínú àwọn ẹsẹ míì bíi Mk 12:17 àti Lk 20:25 nìkan nibi tí Jésù ti sọ̀rọ̀ nípa Olú Ọba Róòmù. “Àwọn ohun ti Késárì” kan sísan owó iṣẹ́ tí ìjọba bá ṣe fáwọn aráàlú àti bíbọ̀wọ̀ fún àwọn aláṣẹ.—Ro 13:1-7.
àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run: Èyí kan fífún Ọlọ́run ní ìjọsìn tó wá látọkàn, ká ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ sí i, ká sì máa ṣègbọràn sí i láìkù síbì kan.—Mt 4:10; 22:37, 38; Iṣe 5:29; Ro 14:8.
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 23:24
tí ń sẹ́ kòkòrò kantíkantí ṣùgbọ́n tí ń gbé ràkúnmí mì káló: Kòkòrò kantíkantí ló kéré jù nínú àwọn ẹ̀dá aláìmọ́ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ̀, ràkúnmí ló sì tóbi jù lára ẹran aláìmọ́ tí wọ́n mọ̀. (Le 11:4, 21-24) Jésù lo àbùmọ́ àti ẹ̀dà ọ̀rọ̀ bó ṣe sọ pé àwọn aṣáájú ẹ̀sìn sẹ́ kòkòrò kantíkantí kúrò nínú ọtí kó má bàa sọ wọ́n di aláìmọ́, àmọ́ wọ́n ṣàìka àwọn ọ̀rọ̀ pàtàkì inú Òfin sí, èyí tó dà bí ìgbà tí wọ́n gbé ràkúnmí mì.
Bíbélì Kíkà
MARCH 19-25
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | MÁTÍÙ 24
“Máa Wà Lójúfò Nípa Tẹ̀mí ní Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn Yìí”
it-2 279 ¶6
Ìfẹ́
Ìfẹ́ Ẹni Lè Di Tútù. Nígbà tí Jésù Kristi ń sọ àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, ó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ìfẹ́ (a·gaʹpe) tí ọ̀pọ̀ àwọn tó pera wọn ní onígbàgbọ́ ní máa di tútù. (Mt 24:3, 12) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé ara àwọn àmì àkókò lílekoko tó ń bọ̀ ni pé àwọn èèyàn máa di “olùfẹ́ owó.” (2Ti 3:1, 2) Torí náà, ó ṣe kedere pé èèyàn lè má tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run mọ́, kí ìyẹn sì wá mú kí ìfẹ́ tó ní tẹ́lẹ̀ di tútù. Èyí jẹ́ ká rí ìdí pàtàkì tó fi yẹ ká máa sapá láti ṣàṣàrò nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ká sì máa jẹ́ kí àwọn ìlànà rẹ̀ máa darí ìgbésí ayé wa ká lè ní ìfẹ́, ká sì máa fi hàn.—Ef 4:15, 22-24.
Ǹjẹ́ Ò Ń ṣe Gbogbo Ojúṣe Rẹ Níwájú Ọlọ́run?
5 Jésù Kristi sọ nípa àwọn àkókò wa tó le koko pé: “Nítorí gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn ọjọ́ Nóà ti rí, bẹ́ẹ̀ náà ni wíwàníhìn-ín Ọmọ ènìyàn yóò rí. Nítorí bí wọ́n ti wà ní ọjọ́ wọnnì ṣáájú ìkún omi, wọ́n ń jẹ, wọ́n sì ń mu, àwọn ọkùnrin ń gbéyàwó, a sì ń fi àwọn obìnrin fúnni nínú ìgbéyàwó, títí di ọjọ́ tí Nóà wọ ọkọ̀ áàkì; wọn kò sì fiyè sí i títí ìkún omi fi dé, tí ó sì gbá gbogbo wọn lọ, bẹ́ẹ̀ náà ni wíwàníhìn-ín Ọmọ ènìyàn yóò rí.” (Mátíù 24:37-39) Táa bá ṣe é níwọ̀ntúnwọ̀nsì, kò sí nǹkan tó burú nínú ká jẹ, ká mu, tó bá sì jẹ́ ti ìgbéyàwó ni, Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló dá ètò yìí sílẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 2:20-24) Ṣùgbọ́n, táa bá wá rí i pé gbígbé ìgbésí ayé yọ̀tọ̀mì ti wá di olórí àníyàn wa, kí ló dé tá ò fi sínú àdúrà? Jèhófà lè ràn wá lọ́wọ́ láti fi ire Ìjọba rẹ̀ sípò kìíní, ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe ohun tó tọ́, ká sì ṣe gbogbo ojúṣe wa níwájú rẹ̀.—Mátíù 6:33; Róòmù 12:12; 2 Kọ́ríńtì 13:7.
jy 259 ¶5
Àwọn Àpọ́sítélì Jésù Ní Kó Fún Àwọn ní Àmì
Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n wà lójúfò, kí wọ́n máa ṣọ́nà, kí wọ́n sì múra tán. Jésù fi àpèjúwe míì tẹnu mọ́ ìkìlọ̀ tó fún wọn, ó ní: “Ẹ mọ ohun kan, pé ká ní baálé ilé mọ ìṣọ́ tí olè ń bọ̀ ni, ì bá wà lójúfò, kì bá sì ti yọ̀ǹda kí a fọ́ ilé rẹ̀. Ní tìtorí èyí, ẹ̀yin pẹ̀lú, ẹ wà ní ìmúratán, nítorí pé ní wákàtí tí ẹ kò ronú pé yóò jẹ́, ni Ọmọ ènìyàn ń bọ.”—Mátíù 24:43, 44.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 24:8
ìroragógó wàhálà: Ní olówuuru, ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n lò níbí ń tọ́ka sí ìrora tó lágbára gan-an tí aláboyún máa ń ní tó bá ń rọbí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n lò ó nínú ẹsẹ yìí láti tọ́ka sí ìnira, ìrora àti ìyà tó ń jẹ aráyé, ó ṣeé ṣe kó fi hàn pé àwọn wàhálà àti ìyà tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ á máa le sí i, á máa ṣẹlẹ̀ lemọ́lemọ́, ó sì máa wà fún àwọn àkókò kan bí ìrora aláboyún, kí ìpọ́njú ńlá tí Mt 24:21 sọ tó bẹ̀rẹ̀.
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 24:20
ní ìgbà òtútù: Òjò àrọ̀ọ̀rọ̀dá, àkúnya omi àti òtútù máa ń mú kó ṣòro láti rìnrìn-àjò, kéèyàn wá oúnjẹ àti ibùgbé.—Ẹsr 10:9, 13.
ní ọjọ́ sábáàtì: Ní àwọn ìpínlẹ̀ bíi Jùdíà, òfin tí wọ́n ṣe nípa Sábáàtì kò lè gbà àwọn èèyàn láyè láti rìnrìn-àjò ọ̀nà jíjìn kí wọ́n sì gbé ẹrù; bákàn náà, ńṣe ni wọ́n máa ń ti ẹnu bodè ìlú pa lọ́jọ́ Sábáàtì.—Wo Iṣe 1:12 àti Apá 16 nínú ìwé Àfikún Ìsọfúnni.
Bíbélì Kíkà
MARCH 26–APRIL 1
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | MÁTÍÙ 25
“Ẹ Máa Bá A Nìṣó ní Ṣíṣọ́nà”
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Máa Fi Ìdúróṣinṣin Ti Àwọn Arákùnrin Kristi Lẹ́yìn
7 Lóde òní, a ti wá ní òye tó ṣe kedere nípa àpèjúwe àwọn àgùntàn àtàwọn ewúrẹ́. Nípa ti àwọn tá a sọ̀rọ̀ nípa wọn nínú àpèjúwe yìí, Jésù ni “Ọmọ ènìyàn,” ìyẹn Ọba náà. Àwọn tó pè ní “arákùnrin mi” ni àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn, tí wọ́n máa ṣàkóso pẹ̀lú Kristi ní ọ̀run. (Róòmù 8:16, 17) “Àwọn àgùntàn” àti “àwọn ewúrẹ́,” túmọ̀ sí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn èèyàn ní gbogbo orílẹ̀-èdè. Àwọn yìí ò sí lára àwọn tí Ọlọ́run fi ẹ̀mí yan. Àkókò wo ni ìdájọ́ náà máa wáyé? Ìdájọ́ yìí máa wáyé ní apá ìparí ìpọ́njú ńlá tó máa bẹ̀rẹ̀ láìpẹ́. Kí wá ni ìdí tí Jésù máa fi ṣèdájọ́ àwọn èèyàn gẹ́gẹ́ bí àgùntàn tàbí ewúrẹ́? Èyí sinmi lé bí wọ́n bá ṣe hùwà sí àwọn tó ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé lára àwọn arákùnrin Kristi tí Ọlọ́run fi ẹ̀mí yàn. Bí òpin ètò nǹkan yìí ṣe túbọ̀ ń sún mọ́lé, a dúpẹ́ gidigidi lọ́wọ́ Jèhófà pé ó ń tan ìmọ́lẹ̀ sí àpèjúwe yìí àtàwọn àpèjúwe tó tan mọ́ ọn tó wà ní Mátíù orí 24 àti 25!
“Ọ̀rẹ́ Mi Ni Yín”
16 Tó o bá nírètí àtigbé lórí ilẹ̀ ayé lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, ọ̀nà wo lo máa gbà fi hàn pé ó jẹ́ ọ̀rẹ́ àwọn arákùnrin Kristi? Jẹ́ ká gbé ọ̀nà mẹ́ta yẹ̀ wò. Àkọ́kọ́ ni pé ká máa kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù tọkàntọkàn. Kristi pàṣẹ fáwọn arákùnrin rẹ̀ pé kí wọ́n wàásù ìhìn rere náà kárí ayé. (Mát. 24:14) Àmọ́, iṣẹ́ náà yóò nira fún àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn arákùnrin Kristi lórí ilẹ̀ ayé tí kò bá sí ìrànlọ́wọ́ látọ̀dọ̀ àwọn àgùntàn mìíràn tó jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ wọn. Ká sòótọ́, gbogbo ìgbà tí ẹnì kan lára àwọn àgùntàn mìíràn bá ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù, àwọn arákùnrin Kristi ló ń ràn lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ mímọ́ tí Jésù gbé fún wọn. Ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye mọrírì irú ìbádọ́rẹ̀ẹ́ yìí, Kristi pàápàá mọrírì rẹ̀.
17 Ọ̀nà kejì táwọn tó jẹ́ ara àgùntàn mìíràn gbà ń ran àwọn arákùnrin Kristi lọ́wọ́ ni fifi owó ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ ìwàásù. Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n yan ọ̀rẹ́ fún ara wọn nípasẹ̀ “ọrọ̀ àìṣòdodo.” (Lúùkù 16:9) Èyí ò túmọ̀ sí pé a lè fowó fa ojú Jèhófà àti Jésù mọ́ra o. Kàkà bẹ́ẹ̀, tá a bá ń lo ohun ìní wa láti mú kí iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run máa tẹ̀ síwájú, ńṣe là ń fi hàn pé ọ̀rẹ́ wọn la jẹ́ àti pé a nífẹ̀ẹ́ wọn, kì í ṣe lọ́rọ̀ ẹnu lásán àmọ́ “ní ìṣe àti òtítọ́.” (1 Jòh. 3:16-18) A máa ń ṣe irú ìtìlẹ́yìn bẹ́ẹ̀ nígbà tá a bá wà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, nígbà tá a bá dáwó fún iṣẹ́ ìkọ́lé àti fún títọ́jú àwọn ibi tá a ti ń pé jọ àti nígbà tá a bá fi owó ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé. Bóyá owó tá a dá kéré tàbí ó pọ̀, ó dájú pé Jèhófà àti Jésù mọrírì bá a ṣe jẹ́ olùfúnni ọlọ́yàyà.—2 Kọ́r. 9:7.
18 Ọ̀nà kẹta tí gbogbo wa lè gbà fi hàn pé a jẹ́ ọ̀rẹ́ Kristi ni pé ká máa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà àwọn alàgbà ìjọ. Ẹ̀mí mímọ́ ló yan àwọn ọkùnrin wọ̀nyí lábẹ́ ìdarí Kristi. (Éfé. 5:23) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn tí ń mú ipò iwájú láàárín yín, kí ẹ sì jẹ́ ẹni tí ń tẹrí ba.” (Héb. 13:17) Nígbà míì, ó lè ṣòro fún wa láti tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà táwọn alàgbà ìjọ fún wa látinú Bíbélì. Ó ṣeé ṣe ká máa rí ibi tí àìpé ẹ̀dá ti máa ń mú kí wọ́n ṣàṣìṣe, èyí sì lè mú ká máa fojú tí kò tọ́ wo àwọn ìmọ̀ràn tí wọ́n bá fún wa. Síbẹ̀, ó tẹ́ Kristi Orí ìjọ lọ́rùn láti lo àwọn èèyàn aláìpé wọ̀nyí. Torí náà, ọ̀nà tá a ń gbà tẹ̀ lé ìtọ́ni wọn yóò nípa lórí ìbádọ́rẹ̀ẹ́ àwa àti Kristi. Nígbà tá a bá gbójú fo kùdìẹ̀-kudiẹ àwọn alàgbà tá a sì ń fàyọ tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà wọn, a ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Kristi.
Bíbélì Kíkà