Wọ́n Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
Ọkùnrin Títóbilọ́lá Jù Lọ Ṣe Iṣẹ́ Rírẹlẹ̀
JÉSÙ mọ̀ pé àwọn wákàtí tí òun yóò lò kẹ́yìn pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì òun ṣeyebíye. Láìpẹ́ láìjìnnà, wọn yóò mú un, yóò sì fojú winá irú àdánwò ìgbàgbọ́ tí kò rí rí. Jésù tún mọ̀ pé àwọn ìbùkún ńláǹlà ń bẹ níwájú. Láìpẹ́, a óò gbé e ga sí ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run, a ó sì fún un ní “orúkọ tí ó lékè gbogbo orúkọ mìíràn, kí ó lè jẹ́ pé ní orúkọ Jésù ni kí gbogbo eékún máa tẹ̀ ba ti àwọn tí ń bẹ ní ọ̀run àti àwọn tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé àti àwọn tí ń bẹ lábẹ́ ilẹ̀.”—Fílípì 2:9, 10.
Síbẹ̀, àníyàn nípa ikú tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀ lé Jésù lórí àti ìháragàgà fún èrè táa ṣèlérí kò pín ọkàn rẹ̀ níyà tó bẹ́ẹ̀ tí kò fi ráyè bójú tó àìní àwọn àpọ́sítélì rẹ̀. Jòhánù ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ nínú Ìhìn Rere lẹ́yìn náà pé ó “nífẹ̀ẹ́ wọn dé òpin.” (Jòhánù 13:1) Ní àwọn wákàtí mánigbàgbé yìí nínú ìgbésí ayé rẹ̀ tó lò kẹ́yìn pẹ̀lú wọn gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn pípé, Jésù kọ́ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ní ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n tó ṣe pàtàkì.
Ẹ̀kọ́ Àríkọ́gbọ́n Nípa Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀
Àwọn àpọ́sítélì wà pẹ̀lú Jésù nínú yàrá òkè ní Jerúsálẹ́mù láti ṣe Ìrékọjá. Ṣáájú àkókò yìí, Jésù ti gbọ́ tí wọ́n ń jiyàn nípa ẹni tó tóbi jù lọ. (Mátíù 18:1; Máàkù 9:33, 34) Ó ti bá wọn jíròrò ọ̀rọ̀ yìí, ó sì ti sapá láti tún ojú ìwòye wọn ṣe. (Lúùkù 9:46) Ṣùgbọ́n, lọ́tẹ̀ yìí, Jésù gbé e gba ọ̀nà mìíràn. Kò fẹ́ fi mọ sórí wíwulẹ̀ bá wọn sọ̀rọ̀ nìkan, ṣùgbọ́n ó tún fẹ́ fi hàn wọ́n bí wọ́n ṣe lè ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀.
Jòhánù kọ̀wé pé Jésù “dìde nídìí oúnjẹ alẹ́, ó sì fi ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀ lélẹ̀ sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan. Àti pé, ní mímú aṣọ ìnura, ó di ara rẹ̀ lámùrè. Lẹ́yìn èyíinì, ó bu omi sínú bàsíà kan, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wẹ ẹsẹ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn, ó sì fi aṣọ ìnura tí ó fi di ara rẹ̀ lámùrè nù wọ́n gbẹ.”—Jòhánù 13:4, 5.
Nínú ipò ojú ọjọ́ olóoru ti Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn ìgbàanì, sálúbàtà làwọn èèyàn máa ń wọ̀ bí wọ́n ti ń rin lójú ọ̀nà eléruku. Nígbà tí wọ́n bá wọlé mẹ̀kúnnù, onílé á kí wọn, á sì pèsè nǹkan ìbomísí àti omi kí wọ́n fi wẹ ẹsẹ̀ wọn. Bó bá ṣe ilé olówó ni wọ́n wọ̀, ẹrú ni yóò wá wẹ ẹsẹ̀ àlejò.—Onídàájọ́ 19:21; 1 Sámúẹ́lì 25:40-42.
Nínú yàrá òkè, Jésù àti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ kò dé bá ẹnikẹ́ni lálejò. Kò sí onílé tí yóò mú nǹkan ìbomisí wá, kò sì sí ẹrú tí yóò wẹ ẹsẹ̀ àlejò. Ara ti àwọn àpọ́sítélì, nígbà tí Jésù bẹ̀rẹ̀ sí wẹ ẹsẹ̀ wọn. Ẹni tó tóbi jù lọ láàárín wọn rèé tó ń ṣe iṣẹ́ rírẹlẹ̀ jù lọ!
Lákọ̀ọ́kọ́, Pétérù kọ̀ jálẹ̀, ó ní Jésù ò ní wẹ ẹsẹ̀ tòun. Àmọ́ Jésù sọ fún un pé: “Láìjẹ́ pé mo wẹ ẹsẹ̀ rẹ, ìwọ kò ní ipa kankan lọ́dọ̀ mi.” Nígbà tí Jésù wẹ ẹsẹ̀ gbogbo àwọn àpọ́sítélì tán, ó sọ pé: “Ǹjẹ́ ẹ mọ ohun tí mo ṣe fún yín? Ẹ ń pè mí ní, ‘Olùkọ́,’ àti ‘Olúwa,’ ẹ sì sọ̀rọ̀ lọ́nà títọ́, nítorí bẹ́ẹ̀ ni mo jẹ́. Nítorí náà, bí èmi, tí ó tilẹ̀ jẹ́ Olúwa àti Olùkọ́, bá wẹ ẹsẹ̀ yín, ó yẹ kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa wẹ ẹsẹ̀ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì. Nítorí mo fi àwòṣe lélẹ̀ fún yín, pé, gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe fún yín, ni kí ẹ máa ṣe pẹ̀lú.”—Jòhánù 13:6-15.
Kì í ṣe pé Jésù ń dá ààtò ẹsẹ̀ fífọ̀ sílẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ń ran àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ lọ́wọ́ láti ní ojú ìwòye tuntun—ti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìfẹ́ láti ṣe iṣẹ́ rírẹlẹ̀ jù lọ fún àwọn arákùnrin wọn. Ó ṣe kedere pé òye kókó náà yé wọn. Gbé ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà yẹ̀ wò, nígbà tí ìbéèrè nípa ìdádọ̀dọ́ dìde. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé “awuyewuye púpọ̀” wáyé, síbẹ̀ kò sẹ́ni tó da ọ̀rọ̀ rú, wọ́n fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ fetí sí ojú ìwòye ẹnì kìíní kejì. Síwájú sí i, ó jọ pé Jákọ́bù ni alága ìpàdé yẹn—ẹni tí kì í ṣe ọ̀kan lára àwọn àpọ́sítélì, ọ̀kan lára wọn ni à bá sì retí pé kó jẹ́ alága, níwọ̀n bí wọ́n ti wà níbẹ̀. Kúlẹ̀kúlẹ̀ yìí nínú àkọsílẹ̀ ìwé Ìṣe fi hàn pé àwọn àpọ́sítélì ti tẹ̀ síwájú gidigidi nínú fífi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ hàn.—Ìṣe 15:6-29.
Ẹ̀kọ́ Táa Rí Kọ́
Nípa wíwẹ ẹsẹ̀ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, Jésù pèsè ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n tó lágbára nípa ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀. Ní tòótọ́, kò yẹ kí àwọn Kristẹni máa ronú pé àwọn ṣe pàtàkì dépò pé ṣe ló yẹ kí àwọn ẹlòmíràn máa sìn wọ́n nígbà gbogbo, bẹ́ẹ̀ sì ni kò yẹ kí wọ́n máa jà kìràkìtà torí àtidé ipò ọlá àti iyì. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló yẹ kí wọ́n tẹ̀ lé àpẹẹrẹ tí Jésù fi lélẹ̀, ẹni tó “wá, kì í ṣe kí a lè ṣe ìránṣẹ́ fún un, bí kò ṣe kí ó lè ṣe ìránṣẹ́, kí ó sì fi ọkàn rẹ̀ fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.” (Mátíù 20:28) Bẹ́ẹ̀ ni, ó yẹ kí àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù múra tán láti ṣe àwọn iṣẹ́ rírẹlẹ̀ jù lọ fún ara wọn lẹ́nì kìíní kejì.
Abájọ tí Pétérù fi kọ̀wé pé: “Ẹ fi ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú di ara yín lámùrè sí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, nítorí Ọlọ́run kọ ojú ìjà sí àwọn onírera, ṣùgbọ́n ó ń fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí fún àwọn onírẹ̀lẹ̀.” (1 Pétérù 5:5) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí a tú sí ‘dì lámùrè’ wá láti inú ọ̀rọ̀ tó túmọ̀ sí “aṣọ àlàbọrùn ẹrú,” aṣọ àlàbọrùn yìí sì ni a fi ń di ẹ̀wù tí ń tú yagba. Ó ha lè jẹ́ pé fífi tí Jésù fi aṣọ ìnura dàmùrè, tó sì wẹ ẹsẹ̀ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ni Pétérù ń tọ́ka sí bí? A kò lè sọ dájú. Síbẹ̀síbẹ̀, iṣẹ́ ìsìn onírẹ̀lẹ̀ tí Jésù ṣe wọ Pétérù lọ́kàn ṣinṣin, bẹ́ẹ̀ náà sì ló yẹ kó wọ gbogbo àwọn tó bá fẹ́ di ọmọlẹ́yìn Kristi lọ́kàn ṣinṣin.—Kólósè 3:12-14.