Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
DECEMBER 3-9
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÌṢE 9-11
“Ẹni Tó Ń Ṣe Inúnibíni Di Ẹni Tó Ń Fìtara Wàásù”
Ìjọ “Wọnú Sáà Àlàáfíà”
ÀWỌN arìnrìn àjò náà ti ń sún mọ́ Damásíkù, níbi tí wọ́n ti fẹ́ lọ hùwà ibi tó wà lọ́kàn wọn. Wọ́n fẹ́ lọ fipá mú àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tí wọ́n kórìíra nínú ilé wọn, kí wọ́n dè wọ́n, kí wọ́n dójú tì wọ́n, kí wọ́n sì wọ́ wọn lọ sọ́dọ̀ ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn ní Jerúsálẹ́mù, kí wọ́n lè fìyà jẹ́ wọn.
2 Sọ́ọ̀lù tó jẹ́ aṣáájú àwọn ẹlẹ́hòónú yìí ti lẹ́jẹ̀ èèyàn lọ́rùn ní tiẹ̀. Kò tíì pẹ́ sígbà yẹn táwọn agbawèrèmẹ́sìn bíi tiẹ̀ sọ Sítéfánù olùfọkànsìn ọmọ ẹ̀yìn Jésù lókùúta pa níṣojú ẹ̀. (Ìṣe 7:57–8:1) Síbẹ̀, inú ẹ̀ ṣì ń ru sáwọn ọmọlẹ́yìn Jésù tó ń gbé ní Jerúsálẹ́mù, Sọ́ọ̀lù wá sọ ara rẹ̀ di irinṣẹ́ Èṣù láti tan inúnibíni kálẹ̀. Ó fẹ́ pa ìsìn tó kà sí eléwu, tí wọ́n ń pè ní “Ọ̀nà Náà” run.—Ìṣe 9:1, 2; wo àpótí náà, “Sọ́ọ̀lù Gbàṣẹ Láti Lọ Mú Àwọn Kristẹni ní Damásíkù,” lójú ìwé 61.
Mọyì Jèhófà Tó Jẹ́ Amọ̀kòkò Wa
4 Bí Jèhófà ṣe ń kíyè sí ọmọ aráyé, kì í ṣe ẹwà tàbí ìrísí wa ló ń wò. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọkàn wa ló ń wò, ìyẹn irú ẹni tá a jẹ́ gan-an. (Ka 1 Sámúẹ́lì 16:7b.) Ọ̀rọ̀ yìí túbọ̀ ṣe kedere nígbà tí Ọlọ́run dá ìjọ Kristẹni sílẹ̀. Onírúurú èèyàn tí àwọn èèyàn ò kà sí ni Jèhófà mú kó wá sọ́dọ̀ Jésù, ọmọ rẹ̀. (Jòh. 6:44) Ọ̀kan lára irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni Sọ́ọ̀lù tó jẹ́ Farisí tẹ́lẹ̀. Nígbà yẹn, ó jẹ́ “asọ̀rọ̀ òdì àti onínúnibíni àti aláfojúdi.” (1 Tím. 1:13) Àmọ́, Jèhófà tó jẹ́ ‘olùṣàyẹ̀wò ọkàn,’ mọ̀ pé amọ̀ tó ṣì máa wúlò ni Sọ́ọ̀lù. (Òwe 17:3) Ohun tí Ọlọ́run rí lára ọkùnrin yìí yàtọ̀ pátápátá, Ọlọ́run rí i pé amọ̀ táá ṣeé fi mọ ohun èlò tó fani mọ́ra ni Sọ́ọ̀lù. Àní sẹ́, “ohun èlò tí a ti yàn ni” láti jẹ́rìí fún “àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn ọba àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.” (Ìṣe 9:15) Àwọn míì tí Ọlọ́run rí i pé wọ́n máa jẹ́ ohun èlò “fún ìlò ọlọ́lá” ni àwọn tó ti fìgbà kan jẹ́ ọ̀mùtí, oníṣekúṣe àti olè. (Róòmù 9:21; 1 Kọ́r. 6:9-11) Bí wọ́n ṣe túbọ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n ń lo ìgbàgbọ́, wọ́n sì gbà kí Jèhófà mọ àwọn bí amọ̀kòkò ṣe máa ń mọ amọ̀.
Ìjọ “Wọnú Sáà Àlàáfíà”
15 Ṣé o lè fojú inú wo bí ẹnu á ṣe ya àwọn èèyàn àti bí orí wọn á ṣe gbóná tó nígbà tí wọ́n rí Sọ́ọ̀lù tó ń wàásù nípa Jésù nínú sínágọ́gù? Wọ́n sọ pé: “Èyí ha kọ́ ni ọkùnrin tí ó run àwọn tí ń bẹ ní Jerúsálẹ́mù, àwọn tí ń ké pe orúkọ yìí?” (Ìṣe 9:21) Nígbà tí Sọ́ọ̀lù ń sọ ìdí tó fi yí èrò rẹ̀ nípa Jésù pa dà, ó “fi ẹ̀rí ìdánilójú hàn lọ́nà tí ó bọ́gbọ́n mu pé èyí ni Kristi náà.” (Ìṣe 9:22) Àmọ́, Sọ́ọ̀lù nílò ju fífi ọgbọ́n ṣàlàyé Kristi lọ. Torí pé irú ọgbọ́n bẹ́ẹ̀ ò lè yí èrò àwọn tí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àti ìgbéraga ti wọ̀ lẹ́wù pa dà. Síbẹ̀, Sọ́ọ̀lù ò jẹ́ kó sú òun.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Ìjọ “Wọnú Sáà Àlàáfíà”
5 Nígbà tí Jésù dá Sọ́ọ̀lù dúró lójú ọ̀nà Damásíkù, kò béèrè pé: “Kí ló dé tó o fi ń ṣe inúnibíni sáwọn ọmọ ẹ̀yìn mi?” Gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ lókè, ohun tí Jésù sọ ni pé: “Èé ṣe tí ìwọ fi ń ṣe inúnibíni sí mi?” (Ìṣe 9:4) Bẹ́ẹ̀ ni, Jésù fúnra ẹ̀ mọ ìyà tó ń jẹ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lára.—Mát. 25:34-40, 45.
6 Bí wọ́n bá ń ni ẹ́ lára torí ìgbàgbọ́ rẹ nínú Kristi, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà àti Jésù mọ bí ọ̀ràn ṣe rí lára ẹ. (Mát. 10:22, 28-31) Jèhófà lè ṣàì mú ìṣòro náà kúrò lójú ẹsẹ̀. Rántí pé Jésù rí bí Sọ́ọ̀lù ṣe lọ́wọ́ nínú ikú Sítéfánù, Ó sì tún rí bó ṣe fipá mú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ adúróṣinṣin látinú ilé wọn ní Jerúsálẹ́mù. (Ìṣe 8:3) Síbẹ̀, Jésù ò dá sí i lákòókò náà. Àmọ́, Jèhófà tipasẹ̀ Kristi fún Sítéfánù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn tó kù lókun láti jẹ́ adúróṣinṣin.
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Iṣe 10:6
Símónì kan, oníṣẹ́ awọ: Awọ ẹranko làwọn oníṣẹ́ awọ máa ń fi ṣiṣẹ́, wọ́n máa ń fi ẹfun fọ ẹran tàbí ọ̀rá tó wà lára rẹ̀ kúrò. Lẹ́yìn náà, wọ́n á fi ọtí tó le gan-an fọ awọ náà, kí wọ́n lè fi ṣe ohun tí wọ́n bá fẹ́ fi ṣe. Ibi tí wọ́n ti máa ń ṣiṣẹ́ yìí máa ń rùn gan-an, torí náà, wọ́n máa ń lo omi púpọ̀, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé torí ìdí yìí ni Símónì fi ń gbé lẹ́bàá òkun, lẹ́yìn ìlú Jópà. Níbàámu pẹ̀lú Òfin Mósè, aláìmọ́ ni ẹni tó bá fọwọ́ kan òkú ẹran. (Le 5:2; 11:39) Torí náà, ọ̀pọ̀ àwọn Júù máa ń fojú burúkú wo àwọn oníṣẹ́ awọ, wọn ò sì ní fẹ́ sùn nílé wọn. Kódà, ìwé ìsìn àwọn Júù kan tó ń jẹ́ Támọ́dì sọ pé àwọn tó ń kó ìgbẹ́ sàn ju àwọn oníṣẹ́ awọ lọ. Àmọ́, Pétérù kò jẹ́ kí ẹ̀tanú tí àwọn èèyàn ní sí àwọn oníṣẹ́ awọ dí òun lọ́wọ́ láti gbé pẹ̀lú Símónì. Bí Pétérù kò ṣe jẹ́ kí ẹ̀tanú yìí ran òun mú kó rọrùn fún un láti tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ tí Ọlọ́run fún un nígbà tó yá, pé kó lọ wàásù fún Kèfèrí nílé rẹ̀. Àwọn ọ̀mọ̀wé kan gbà pé orúkọ àpèlé Símónì ni ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n lò fún “oníṣẹ́ awọ” (byr·seusʹ).
Bíbélì Kíkà
DECEMBER 10-16
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÌṢE 12-14
“Bánábà àti Pọ́ọ̀lù Sọ Àwọn Èèyàn Tó Wà Láwọn Ọ̀nà Jíjìn Di Ọmọlẹ́yìn”
Wọ́n Kún “fún Ìdùnnú àti Ẹ̀mí Mímọ́”
4 Àmọ́ kí nìdí tí ẹ̀mí mímọ́ fi dìídì sọ pé kí wọ́n ya Bánábà àti Sọ́ọ̀lù sọ́tọ̀ “fún iṣẹ́”? (Ìṣe 13:2) Bíbélì kò sọ fún wa. Ohun tá a mọ̀ ni pé ẹ̀mí mímọ́ ló darí yíyan àwọn ọkùnrin náà. Kò sì sí ohun tó fi hàn pé àwọn wòlíì àtàwọn olùkọ́ tó wà ní Áńtíókù ta ko ìpinnu yìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni wọ́n kọ́wọ́ ti àwọn tí wọ́n yàn. Fojú inú wo bọ́rọ̀ náà á ṣe rí lára Bánábà àti Sọ́ọ̀lù báwọn arákùnrin wọn ṣe ‘gbààwẹ̀, tí wọ́n gbàdúrà, tí wọ́n gbé ọwọ́ lé wọn, tí wọ́n sì jẹ́ kí wọn lọ’ láìsí pé wọ́n ń jowú wọn. (Ìṣe 13:3) Àwa náà gbọ́dọ̀ máa ti àwọn tó rí àǹfààní iṣẹ́ ìsìn gbà nínú ìjọ Kristẹni lẹ́yìn, títí kan àwọn tá a yàn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó. Dípò tá a ó fi máa jowú àwọn tó rí irú àǹfààní iṣẹ́ ìsìn bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yẹ ká máa “fún wọn ní ìkàsí tí ó ju àrà ọ̀tọ̀ lọ nínú ìfẹ́ nítorí iṣẹ́ wọn.”—1 Tẹs. 5:13.
“Sísọ̀rọ̀ Pẹ̀lú Àìṣojo Nípasẹ̀ Ọlá Àṣẹ Jèhófà”
5 Pọ́ọ̀lù àti Bánábà kọ́kọ́ dúró ní Íkóníónì, ìlú kan tí kò fi àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ Gíríìkì ṣeré rárá, ó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìlú pàtàkì-pàtàkì ní ìpínlẹ̀ Gálátíà, tó wà lábẹ́ ìjọba Róòmù. Àwọn lóókọ-lóókọ tí wọ́n jẹ́ Júù àti ọ̀pọ̀ àwọn aláwọ̀ṣe tí kì í ṣe Júù ni wọ́n ń gbé ìlú yìí. Gẹ́gẹ́ bí àṣà Pọ́ọ̀lù àti Bánábà, wọ́n wọnú sínágọ́gù, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù. (Ìṣe 13:5, 14) Wọ́n “sọ̀rọ̀ ní irúfẹ́ ọ̀nà tí ó fi jẹ́ pé ògìdìgbó ńlá àwọn Júù àti Gíríìkì di onígbàgbọ́.”—Ìṣe 14:1.
Máa Sin Jèhófà Láìyẹsẹ̀ Láìka “Ọ̀pọ̀ Ìpọ́njú” Sí
4 Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà kúrò ní Débè, “wọ́n padà sí Lísírà àti Íkóníónì àti sí Áńtíókù, wọ́n ń fún ọkàn àwọn ọmọ ẹ̀yìn lókun, wọ́n ń fún wọn ní ìṣírí láti dúró nínú ìgbàgbọ́, wọ́n sì wí pé: ‘A gbọ́dọ̀ ti inú ọ̀pọ̀ ìpọ́njú wọ ìjọba Ọlọ́run.’ ” (Ìṣe 14:21, 22) Gbólóhùn yẹn lè kọ́kọ́ yani lẹ́nu. Ó ṣe tán, èrò pé èèyàn máa dojú kọ “ọ̀pọ̀ ìpọ́njú” lè mú kí nǹkan súni tàbí kí ó kó ìrẹ̀wẹ̀sì báni. Báwo ni Pọ́ọ̀lù àti Bánábà ṣe “fún ọkàn àwọn ọmọ ẹ̀yìn lókun” nígbà tí wọ́n sọ fún wọn pé wọ́n máa ní láti kojú ọ̀pọ̀ ìpọ́njú?
5 A máa rí ìdáhùn tá a bá fara balẹ̀ wo ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ. Ẹ kíyè sí i pé kò kàn sọ pé: “A gbọ́dọ̀ fara da ọ̀pọ̀ ìpọ́njú.” Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó sọ ni pé: “A gbọ́dọ̀ ti inú ọ̀pọ̀ ìpọ́njú wọ ìjọba Ọlọ́run.” Nítorí náà, Pọ́ọ̀lù fún ọkàn àwọn ọmọ ẹ̀yìn lókun bó ṣe sọ̀rọ̀ nípa ohun rere tó máa yọrí sí téèyàn bá jẹ́ olóòótọ́. Èrè tó máa tìdí rẹ̀ wá kì í ṣe ọ̀rọ̀ àlá lásán. Kódà, Jésù sọ pé: “Ẹni tí ó bá fara dà á dé òpin ni ẹni tí a ó gbà là.”—Mát. 10:22.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Ìṣe
12:21-23; 14:14-18. Hẹ́rọ́dù gba ògo tó jẹ́ ti Ọlọ́run láìjanpata. Ẹ ò rí bí ìyẹn ti yàtọ̀ tó sí bí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà ṣe yára kọ ìyìn àti ògo tí kò tọ́ sí wọn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀! Nítorí náà, a ò gbọ́dọ̀ máa wá bá a ṣe máa gbògo lórí àṣeyọrí èyíkéyìí tá a bá ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Iṣe 13:9
Sọ́ọ̀lù, ẹni tí ó tún ń jẹ́ Pọ́ọ̀lù: Láti ẹsẹ yìí lọ ni wọ́n ti ń pe Sọ́ọ̀lù ní Pọ́ọ̀lù. Hébérù làwọn tó bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, àmọ́ ọmọ ìbílẹ̀ Róòmù ni. (Iṣe 22:27, 28; Flp 3:5) Torí náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àti kékeré ló ti ní orúkọ Hébérù náà Sọ́ọ̀lù àti orúkọ Róòmù náà Pọ́ọ̀lù. Àwọn Júù kì í sábà ní orúkọ méjì, pàápàá jù lọ àwọn tí kò gbé ní Ísírẹ́lì. (Iṣe 12:12; 13:1) Àwọn ìbátan Pọ́ọ̀lù kan náà ní orúkọ Róòmù àti Gíríìkì. (Ro 16:7, 21) Wọ́n rán Pọ́ọ̀lù tó jẹ́ “àpọ́sítélì fún àwọn orílẹ̀-èdè” pé kó lọ wàásù ìhìn rere fún àwọn tí kì í ṣe Júù. (Ro 11:13) Ó ní láti jẹ́ pé ṣe ló yàn láti lo orúkọ Róòmù tó ní; ó ṣeé ṣe kó ti rò ó pé orúkọ yẹn máa tu àwọn tó ń wàásù fún lára. (Iṣe 9:15; Ga 2:7, 8) Àwọn kan sọ pé ṣe ló ń lo orúkọ Róòmù yẹn láti máa bọlá fún Sájíọ́sì Pọ́lọ́sì, èyí ò sì lè rí bẹ́ẹ̀, torí pé Pọ́ọ̀lù ṣì ń lo orúkọ yẹn kódà lẹ́yìn tó kúrò ní ìlú Kípírọ́sì. Àwọn kan tún sọ pé Pọ́ọ̀lù kì í fẹ́ lo orúkọ Hébérù rẹ̀ torí pé tí wọ́n bá pe orúkọ yẹn lédè Gíríìkì, ó máa ń fẹ́ dún bí ọ̀rọ̀ tí wọ́n máa ń lò fún èèyàn tó ń ṣakọ rìn tàbí ẹranko.—Wo àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Iṣe 7:58.
Pọ́ọ̀lù: Nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, ìgbà mẹ́tàdínlọ́gọ́jọ [157] ni Bíbélì lo orúkọ náà Pauʹlos, lédè Latin Paulus, tó túmọ̀ sí “Kéré; Bíńtín,” nígbà tó ń tọ́ka sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ó sì lo orúkọ yẹn lẹ́ẹ̀kan fún Sájíọ́sì Pọ́lọ́sì tó jẹ́ alákòóso ìbílẹ̀ Kípírù.—Iṣe 13:7.
Bíbélì Kíkà
DECEMBER 17-23
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÌṢE 15-16
“Wọ́n Fìmọ̀ Ṣọ̀kan Láti Ṣe Ìpinnu Tó Dá Lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run”
“Awuyewuye Tí Kì Í Ṣe Kékeré Ti Wáyé”
8 Lúùkù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Nígbà tí ìyapa àti ṣíṣe awuyewuye tí kì í ṣe kékeré ti wáyé láti ọ̀dọ̀ Pọ́ọ̀lù àti Bánábà pẹ̀lú wọn [“àwọn ọkùnrin kan” yẹn], wọ́n [àwọn alàgbà] ṣètò pé kí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà àti àwọn mìíràn kan lára wọn gòkè lọ sọ́dọ̀ àwọn àpọ́sítélì àti àwọn àgbà ọkùnrin ní Jerúsálẹ́mù nípa awuyewuye yìí.” (Ìṣe 15:2) “Ìyapa àti ṣíṣe awuyewuye” náà fi hàn pé olúkúlùkù wọn fi ohùn tó le sọ̀rọ̀ bí wọ́n ti ń fi ìdánilójú ṣàlàyé bí ọ̀rọ̀ náà ṣe yé wọn sí. Ọ̀rọ̀ ọ̀hún kọjá ohun tí ìjọ tó wà ní Áńtíókù lè yanjú. Àmọ́ nítorí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan, ìjọ fọgbọ́n ṣètò pé kí wọ́n fọ̀ràn náà lọ “àwọn àpọ́sítélì àti àwọn àgbà ọkùnrin ní Jerúsálẹ́mù,” tí wọ́n jẹ́ ìgbìmọ̀ olùdarí nígbà yẹn. Kí la lè rí kọ́ lára àwọn alàgbà tó wà ní Áńtíókù?
Àwọn Kristẹni Tòótọ́ Bọ̀wọ̀ fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
6 Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n fi yanjú ọ̀ràn náà ni Ámósì 9:11, 12. Ìwé Ìṣe 15:16, 17 tọ́ka sí ohun tó wà nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà pé: “Èmi yóò padà, èmi yóò sì tún àtíbàbà Dáfídì tí ó ti wó lulẹ̀ kọ́; èmi yóò sì tún àwókù rẹ̀ kọ́, èmi yóò sì gbé e nà ró lẹ́ẹ̀kan sí i, kí àwọn tí ó ṣẹ́ kù lára àwọn ènìyàn náà lè fi taratara wá Jèhófà, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè, àwọn ènìyàn tí a fi orúkọ mi pè, ni Jèhófà wí.”
7 Àmọ́, ẹnì kan lè sọ pé, ‘ẹsẹ yẹn kò sọ pé kí àwọn Kèfèrí tó di onígbàgbọ́ má ṣe dádọ̀dọ́.’ Òótọ́ ni, á sì ti yé àwọn Júù tó di Kristẹni pé ohun tí ẹsẹ yẹn ń sọ nìyẹn. Kí nìdí? Ìdí ni pé arákùnrin ni àwọn Júù tó di Kristẹni ka àwọn Kèfèrí tó dádọ̀dọ́ sí, wọn ò kà wọ́n sí ‘àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè.’ (Ẹ́kís. 12:48, 49) Bí àpẹẹrẹ, nínú ẹ̀dà Bíbélì Septuagint tí Bagster ṣe, Ẹ́sítérì 8:17 sọ pé: “Ọ̀pọ̀ lára àwọn Kèfèrí náà dádọ̀dọ́, wọ́n sì di Júù.” Torí náà, nígbà tí Ìwé Mímọ́ sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn tó ṣẹ́ kù lára ilé Ísírẹ́lì (àwọn Júù àti àwọn aláwọ̀ṣe Júù tó dádọ̀dọ́) pa pọ̀ pẹ̀lú “àwọn ènìyàn gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè” (àwọn Kèfèrí tí kò dádọ̀dọ́) máa di èèyàn kan tá à ń fi orúkọ Ọlọ́run pè, ó wá ṣe kedere sí wọn pé ohun tí Ìwé Mímọ́ ń sọ ni pé kò pọn dandan kí àwọn Kèfèrí tó fẹ́ di Kristẹni dádọ̀dọ́.
Pọ́ọ̀lù “Ń Fún Àwọn Ìjọ Lókun”
18 Pọ́ọ̀lù àti Tímótì ṣiṣẹ́ pa pọ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún. Gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ arìnrìn-àjò, wọ́n jẹ́ ọ̀pọ̀ iṣẹ́ tí ìgbìmọ̀ olùdarí rán wọn. Bíbélì sọ pé: “Bí wọ́n ti ń rin ìrìn àjò la àwọn ìlú ńlá náà já, wọn a fi àwọn àṣẹ àgbékalẹ̀ tí àwọn àpọ́sítélì àti àwọn àgbà ọkùnrin tí ń bẹ ní Jerúsálẹ́mù ti ṣe ìpinnu lé lórí jíṣẹ́ fún àwọn tí ń bẹ níbẹ̀, kí wọ́n lè máa pa wọ́n mọ́.” (Ìṣe 16:4) Ó sì dájú pé àwọn ìjọ tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà àwọn àpọ́sítélì àtàwọn àgbà ọkùnrin tó wà ní Jerúsálẹ́mù. Ohun tó jẹ́ àbájáde ìgbọ́ràn yìí ni pé, “àwọn ìjọ ń bá a lọ ní fífìdímúlẹ̀ gbọn-in nínú ìgbàgbọ́ àti ní pípọ̀ sí i ní iye láti ọjọ́ dé ọjọ́.”—Ìṣe 16:5.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Kọ́ Bó O Ṣe Lè Máa Ṣọ́nà Látinú Àpẹẹrẹ Àwọn Àpọ́sítélì Jésù
8 Kí la lè rí kọ́ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn? Kíyè sí i pé lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù gbéra ìrìn àjò lọ sí Éṣíà ni ẹ̀mí Ọlọ́run tó darí rẹ̀. Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù sì ti dé ìtòsí Bítíníà ni Jésù tó fún un ní ìtọ́ni síwájú sí i. Sì tún kíyè sí i pé lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù dé Tíróásì ni Jésù tó darí rẹ̀ pé kó lọ sí Makedóníà. Jésù tó jẹ́ Orí ìjọ Ọlọ́run lè darí àwa náà lọ́nà tó fara jọ èyí. (Kól. 1:18) Bí àpẹẹrẹ, o lè ti máa ronú pé wàá fẹ́ láti sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà tàbí kó o lọ sí àgbègbè kan tí wọ́n ti nílò àwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run púpọ̀ sí i. Àmọ́, ó lè jẹ́ pé lẹ́yìn tó o bá ti ṣe àwọn ohun tó máa mú kí ọwọ́ rẹ tẹ àfojúsùn rẹ ni Jésù máa tó fi ẹ̀mí Ọlọ́run darí rẹ. Wo àpèjúwe yìí ná: Kí awakọ̀ kan tó lè darí ọkọ̀ sọ́tùn-ún tàbí sósì, ọkọ̀ náà gbọ́dọ̀ wà lórí ìrìn. Bákan náà, Jésù lè fi ẹ̀mí Ọlọ́run darí wa láti mọ bí a ṣe lè mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa gbòòrò sí i, àmọ́, ìyẹn á jẹ́ lẹ́yìn tá a bá ti sapá gidigidi kí ọwọ́ wa lè tẹ àfojúsùn náà.
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Iṣe 16:37
a jẹ́ ará Róòmù: Ìyẹn ọmọ ìbílẹ̀ Róòmù. Ọmọ ìbílẹ̀ Róòmù ni Pọ́ọ̀lù àti Sílà. Òfin ilẹ̀ Róòmù sọ pé wọ́n gbọ́dọ̀ gbọ́ ẹjọ́ ọmọ ìbílẹ̀ bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ kí wọ́n tó dájọ́ fún un, wọn ò sì gbọ́dọ̀ fìyà jẹ ẹ́ ní gbangba láìjẹ́ pé wọ́n ti dájọ́ ẹ̀. Ẹni tó bá jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ Róòmù máa ń ní àwọn ẹ̀tọ́ àtàwọn àǹfààní kan ní ibikíbi tó bá wà ní ilẹ̀ ọba Róòmù. Ọmọ ìbílẹ̀ Róòmù wà lábẹ́ òfin Róòmù, kì í ṣe abẹ́ òfin àgbègbè ibi tó bá ń gbé. Tí wọ́n bá fẹ̀sùn kàn án, ó lè gbà kí wọ́n ṣe ẹjọ́ òun lábẹ́ òfin àgbègbè tọ́rọ̀ náà ti ṣẹlẹ̀, síbẹ̀ ó lẹ́tọ̀ọ́ láti gbé ẹjọ́ náà lọ sí ilé ẹjọ́ Róòmù. Kódà, bó bá tiẹ̀ jẹ́ ẹjọ́ ikú ló tọ́ sí i, ó ṣì lè pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sọ́dọ̀ olú ọba Róòmù. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wàásù jákèjádò Ilẹ̀ Ọba Róòmù. Ó lo àǹfààní ẹ̀tọ́ tó ní gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìbílẹ̀ Róòmù ó kéré tán lẹ́ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Àkọ́kọ́ nìgbà tó sọ fún aṣojú ìjọba ìlú Fílípì pé wọ́n ti tẹ ẹ̀tọ́ òun lójú bí wọ́n ṣe na òun lẹ́gba.—Láti mọ ìgbà méjì tó kù, wo àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Iṣe 22:25; 25:11.
Bíbélì Kíkà
DECEMBER 24-30
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÌṢE 17-18
“Fara Wé Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù Bó O Ṣe Ń Wàásù Tó O sì Ń Kọ́ni”
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Iṣe 17:2, 3
fèrò-wérò: Kì í ṣe pé Pọ́ọ̀lù kàn sọ ìhìn rere lásán ni. Ó tún ṣàlàyé ẹ̀, ó sì fi ẹ̀rí hàn láti inú Ìwé Mímọ́, ìyẹn nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Yàtọ̀ sí pé ó máa ń ka Ìwé Mímọ́; ó tún máa ń ronú lé e lórí, ó sì máa ń lò ó láti ṣàtúnṣe sí ojú táwọn olùgbọ́ rẹ̀ fi ń wo nǹkan. Wọ́n ti tú ọ̀rọ̀ ìṣe Gíríìkì náà di·a·leʹgo·mai sí “láti dá sí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀; láti jọ sọ̀rọ̀; láti jọ jíròrò.” Ó ní nínú káwọn èèyàn jọ máa sọ̀rọ̀. Wọ́n tún lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì yìí nínú Iṣe 17:17; 18:4, 19; 19:8, 9; 20:7, 9.
fi ẹ̀rí ìdánilójú hàn nípasẹ̀ àwọn ìtọ́ka: Ọ̀rọ̀ Gíríìkì yìí túmọ̀ sí “mú un sẹ́gbẹ̀ẹ́ (gbé e sẹ́gbẹ̀ẹ́).” Torí náà, ó ṣeé ṣe kí èyí túmọ̀ sí pé ńṣe ni Pọ́ọ̀lù ń fara balẹ̀ gbé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù yẹ̀ wò sí àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí Jésù, láti rí bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ṣe ṣẹ sí Jésù lára.
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Iṣe 17:17
ní ibi ọjà: Apá àríwá ìwọ̀ oòrùn ilé tí wọ́n kọ́ sí téńté ìlú Áténì, ni wọ́n kọ́ ọjà ìlú náà sí, lórí ilẹ̀ tó fẹ̀ tó nǹkan bíi hẹ́kítà márùn-ún (5 ha) tàbí sarè ilẹ̀ méjìlá (12 ac). Ọjà nìkan kọ́ ni wọ́n ń ná ní ibi ọjà yìí. Ibẹ̀ ni ojúkò òwò, òṣèlú àti ojúkò àṣà ìlú náà. Àwọn ará ìlú Áténì nífẹ̀ẹ́ láti máa wá sí ojúkò yìí láti jíròrò àwọn nǹkan tuntun pẹ̀lú ara wọn.
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Iṣe 17:22, 23
Sí Ọlọ́run Àìmọ̀: Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà A·gnoʹstoi the·oiʹ wà lára àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n kọ sára pẹpẹ tó wà ní ìlú Áténì. Àwọn ará ìlú Áténì nífẹ̀ẹ́ àwọn òrìṣà, ìdí nìyẹn tí wọ́n fi kọ́ àwọn pẹpẹ àti tẹ́ńpìlì tó pọ̀ gan-an fún wọn, kódà wọ́n tún kọ́ pẹpẹ fún àwọn òrìṣà bí òrìṣà Òkìkí, Ìmẹ̀tọ́mọ̀wà, Agbára, Ìyíniléròpadà, àti òrìṣà Ojú Àánú. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n ronú pé àwọn ò fẹ́ gbójú fo ọlọ́run kankan ni wọ́n ṣe tún ya pẹpẹ kan sọ́tọ̀ fún “Ọlọ́run Àìmọ̀,” torí wọn ò fẹ́ kó bínú sí àwọn. Pẹpẹ yẹn fi hàn pé àwọn èèyàn náà gbà pé Ọlọ́run kan wà tí àwọn ò mọ nǹkan kan nípa rẹ̀. Pẹpẹ yìí ni Pọ́ọ̀lù fi dọ́gbọ́n bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ káwọn èèyàn náà lè mọ Ọlọ́run tòótọ́ náà, torí wọn ò mọ̀ ọ́n tẹ́lẹ̀.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Ìṣe
18:18—Ẹ̀jẹ́ wo ni Pọ́ọ̀lù jẹ́? Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ kan sọ pé ó ní láti jẹ́ pé ẹ̀jẹ́ Násírì ni. (Núm. 6:1-21) Àmọ́ ṣá o, Bíbélì kò sọ ohun tí ẹ̀jẹ́ náà jẹ́. Bákan náà, Ìwé Mímọ́ kò sọ bóyá Pọ́ọ̀lù ti jẹ́ ẹ̀jẹ́ náà kó tó di Kristẹni, kò sì sọ bóyá ó ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ lórí ẹ̀jẹ́ náà ni tàbí bóyá ó fẹ́ wọ́gi lé ẹ̀jẹ́ náà. Ohun yòówù kó jẹ́, kò dẹ́ṣẹ̀ kankan bó ṣe jẹ́ ẹ̀jẹ́ náà.
nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Iṣe 18:21
bí Jèhófà bá fẹ́: Ọ̀rọ̀ yìí fi hàn pé ó yẹ kéèyàn fi ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run sọ́kàn tó bá ń ṣe ohunkóhun tàbí tó bá fẹ́ ṣe ohunkóhun. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi kókó yìí sọ́kàn. (1Kọ 4:19; 16:7; Heb 6:3) Jákọ́bù tó jẹ́ ọmọlẹ́yìn náà rọ àwọn tó ń ka ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé kí wọ́n sọ pé: “Bí Jèhófà bá fẹ́, àwa yóò wà láàyè, a ó sì ṣe èyí tàbí èyíinì pẹ̀lú.” (Jak 4:15) Ọ̀rọ̀ yìí kì í ṣe ọ̀rọ̀ téèyàn á kàn sọ lásán, ẹni tó bá fi tọkàntọkàn sọ pé “bí Jèhófà bá fẹ́” gbọ́dọ̀ máa ṣe àwọn nǹkan níbàámu pẹ̀lú ohun tí Ọlọ́run fẹ́. Àwọn èèyàn sábà máa ń sọ̀rọ̀ yìí sọ́kàn torí kò di dandan kéèyàn sọ ọ́ jáde.—Wo àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Iṣe 21:14; 1Kọ 4:19; Jak 4:15.
Bíbélì Kíkà
DECEMBER 31–JANUARY 6
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÌṢE 19-20
“Ẹ Kíyè Sí Ara Yín àti Gbogbo Agbo”
“Ẹ Máa Ṣe Olùṣọ́ Àgùntàn Agbo Ọlọ́run Tí Ń bẹ Lábẹ́ Àbójútó Yín”
5 Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé kí àwọn àgbà ọkùnrin máa ‘ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run tí ń bẹ lábẹ́ àbójútó wọn.’ Ó ṣe pàtàkì kí wọ́n mọ̀ pé Jèhófà àti Jésù Kristi ló ni agbo náà. Àwọn alàgbà máa jíhìn fún Jèhófà nítorí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí àwọn àgùntàn Ọlọ́run. Ká sọ pé ọ̀rẹ́ rẹ tímọ́tímọ́ kan tó rìnrìn àjò sọ pé kó o bá òun tọ́jú àwọn ọmọ òun títí tí òun fi máa dé. Ǹjẹ́ o kò ní tọ́jú wọn dáadáa kó o sì máa fún wọn ní oúnjẹ? Bí ara ọ̀kan nínú wọn kò bá yá, ǹjẹ́ o kò ní rí i dájú pé ó gba ìtọ́jú tó yẹ? Lọ́nà kan náà, àwọn alàgbà ìjọ gbọ́dọ̀ máa “ṣe olùṣọ́ àgùntàn ìjọ Ọlọ́run, èyí tí ó fi ẹ̀jẹ̀ Ọmọ òun fúnra rẹ̀ rà.” (Ìṣe 20:28) Wọ́n máa ń fi sọ́kàn pé ẹ̀jẹ̀ Kristi Jésù tó ṣeyebíye ni Ọlọ́run fi ra àgùntàn kọ̀ọ̀kan. Torí pé àwọn alàgbà mọ̀ pé àwọn máa jíhìn fún Ọlọ́run nítorí àwọn àgùntàn wọ̀nyí wọ́n ń bọ́ wọn, wọ́n ń dáàbò bò wọ́n, wọ́n sì ń bójú tó wọn.
Àwọn Alàgbà Jẹ́ ‘Alábàáṣiṣẹ́pọ̀ Fún Ìdùnnú Wa’
15 Iṣẹ́ kékeré kọ́ làwọn alàgbà ń ṣe o! Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọn kì í sùn torí pé wọ́n ń ṣàníyàn nítorí àwọn ará. Ìgbà míì sì wà tí wọ́n lè ta jí lóru kí wọ́n lè gbàdúrà nítorí àwọn ará tàbí kí wọ́n lè ràn wọ́n lọ́wọ́. (2 Kọ́r. 11:27, 28) Àmọ́, bíi ti Pọ́ọ̀lù, inú àwọn alàgbà máa ń dùn láti ṣe ojúṣe wọn. Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn Kristẹni tó wà ní Kọ́ríńtì pé: “Èmi yóò máa fi ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ gan-an náwó, a ó sì ná mi tán pátápátá fún ọkàn yín.” (2 Kọ́r. 12:15) Nítorí pé Pọ́ọ̀lù fẹ́ràn àwọn ará, ó “ná” ara rẹ̀ nítorí wọn. Lédè mìíràn, ó lo gbogbo okun rẹ̀ kó bàa lè gbé ìgbàgbọ́ wọn ró. (Ka 2 Kọ́ríńtì 2:4; Fílí. 2:17; 1 Tẹs. 2:8) Abájọ táwọn ará fi nífẹ̀ẹ́ Pọ́ọ̀lù gan-an!—Ìṣe 20:31-38.
“Ọrùn Mi Mọ́ Kúrò Nínú Ẹ̀jẹ̀ Ènìyàn Gbogbo”
20 Àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù yàtọ̀ pátápátá sí tàwọn tó máa yọ́ wọnú agbo wá nígbà tó bá yá, kí wọ́n lè rẹ́ agbo jẹ. Ó ń ṣiṣẹ́ kó lè gbọ́ bùkátà ara rẹ̀ kó má bàa gbé ẹrù ìnira lé ìjọ lórí. Kì í ṣe torí àtikó àwọn ará nífà ni Pọ́ọ̀lù ṣe ń ṣe gbogbo ohun tó ń ṣe fún wọn. Ó gba àwọn alàgbà ìjọ Éfésù níyànjú pé kí wọ́n ṣe tán láti yááfì àwọn nǹkan nítorí àwọn arákùnrin wọn. Ó sọ pé: “Ẹ gbọ́dọ̀ ṣèrànwọ́ fún àwọn tí wọ́n jẹ́ aláìlera, ẹ sì gbọ́dọ̀ fi àwọn ọ̀rọ̀ Jésù Olúwa sọ́kàn, nígbà tí òun fúnra rẹ̀ wí pé, ‘Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.’ ”—Ìṣe 20:35.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
‘Ọ̀rọ̀ Jèhófà Ń Gbilẹ̀ Ó sì Ń Borí’
11 Ó jọ pé ojoojúmọ́ ni Pọ́ọ̀lù máa ń sọ̀rọ̀ nínú gbọ̀ngàn àpéjọ ilé ìwé yẹn láti nǹkan bí agogo mọ́kànlá òwúrọ̀ títí di agogo mẹ́rin ìrọ̀lẹ́. (Ìṣe 19:9) Bóyá ìgbà tó parọ́rọ́ tó sì móoru jù lọ nìyẹn, táwọn èèyàn máa ń ṣíwọ́ iṣẹ́ láti jẹun kí wọ́n sì sinmi. Ká wá sọ pé bí Pọ́ọ̀lù ṣe ń fi aápọn wàásù fún odidi ọdún méjì nìyẹn, á ti lò ju ẹgbẹ̀ẹ́dógún [3,000] wákàtí lọ láti fi kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́. Ìdí míì sì tún nìyẹn tí ọ̀rọ̀ Jèhófà fi ń bá a nìṣó láti máa gbilẹ̀. Òṣìṣẹ́ kára ni Pọ́ọ̀lù, síbẹ̀ ó mọ bó ṣe lè mú ara rẹ̀ bá ipò àwọn tó ń wàásù fún mu. Ó ṣètò ìtòlẹ́sẹẹsẹ rẹ̀ kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lè ran àwọn èèyàn tó ń gbé ní àgbègbè yẹn lọ́wọ́. Kí wá ni àbájáde rẹ̀? “Gbogbo àwọn tí ń gbé àgbègbè Éṣíà . . . gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, àti àwọn Júù àti àwọn Gíríìkì.” (Ìṣe 19:10) Ẹ̀rí kúnnákúnná gbáà ló jẹ́!
‘Ọ̀rọ̀ Jèhófà Ń Gbilẹ̀ Ó sì Ń Borí’
15 Àbùkù tó ta lé àwọn ọmọkùnrin Síkéfà mú kí ìbẹ̀rù Ọlọ́run gbilẹ̀, ó mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn di onígbàgbọ́ kí wọ́n sì jáwọ́ nínú bíbá ẹ̀mí lò. Idán pípa wọ́pọ̀ gan-an nínú àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àwọn ará Éfésù. Fífi èèdì di àwọn ẹlòmíì àti lílo ìfúnpá wọ́pọ̀ láàárín wọn, wọ́n sì tún ní ọ̀pọ̀ ìwé tí wọ́n kọ ògèdè sí. Ní báyìí, ọ̀pọ̀ àwọn ará Éfésù fọwọ́ ara wọn kó àwọn ìwé idán pípa náà jáde wọ́n sì sun wọ́n ní gbangba, bó tilẹ̀ jẹ́ pé owó àwọn ìwé náà tó ẹgbẹẹgbẹ̀rún dọ́là, lóde òní. Lúùkù ròyìn pé: “Nípa báyìí, ọ̀rọ̀ Jèhófà ń bá a nìṣó ní gbígbilẹ̀ àti ní bíborí lọ́nà tí ó ní agbára ńlá.” (Ìṣe 19:17-20) Ẹ̀rí àgbàyanu lèyí jẹ́ pé òtítọ́ ń borí èké àti ìjọsìn àwọn ẹ̀mí èṣù! Àwọn olóòótọ́ èèyàn wọ̀nyẹn fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún wa lónìí. Inú ayé tí àṣà ìbẹ́mìílò ti wọ́pọ̀ gan-an làwa náà ń gbé. Bá a bá rí i pé a ní ohun kan tó ní í ṣe pẹ̀lú ìbẹ́mìílò, ó máa dára ká ṣe bíi tàwọn ará Éfésù, ká tètè gbé e sọ nù! Ohun yòówù kó ná wa, ẹ jẹ́ ká ta kété pátápátá sírú àwọn àṣà tí ń kóni nírìíra bẹ́ẹ̀.
Bíbélì Kíkà