Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
JULY 6-12
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | Ẹ́KÍSÓDÙ 6-7
“Ní Báyìí, Wàá Rí Ohun Tí Màá Ṣe sí Fáráò”
it-2 436 ¶3
Mósè
Èrò táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní nípa Mósè yí pa dà. Wọ́n ti kọ́kọ́ gbà pé òun ni Ọlọ́run fẹ́ lò láti gbà wọ́n sílẹ̀, àmọ́ nígbà tí Fáráò fìyà jẹ wọ́n, tó sì fi kún iṣẹ́ wọn, ṣe ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ráhùn sí Mósè débi tí Mósè fi rẹ̀wẹ̀sì tó sì ké pe Jèhófà. (Ẹk 4:29-31; 5:19-23) Jèhófà wá fún Mósè lókun, ó sọ fún un pé òun máa jẹ́ kó mọ ohun tí Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù ò mọ̀ nípa òun, ìyẹn sì ni ohun tí orúkọ náà Jèhófà túmọ̀ sí ní ti pé òun máa dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀, á sì sọ wọ́n di orílẹ̀-èdè alágbára ní Ilẹ̀ Ìlérí. (Ẹk 6:1-8) Síbẹ̀, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò fetí sí Mósè, àmọ́ lẹ́yìn ìyọnu kẹsàn-án, gbágbáágbá ni gbogbo wọn dúró tì í, wọ́n sì fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ tó fi jẹ́ pé lẹ́yìn ìyọnu kẹwàá, ó ṣètò wọn, wọ́n sì “tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́” nígbà tí wọ́n kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.—Ẹk 13:18.
it-2 436 ¶1-2
Mósè
Níwájú Fáráò ti ilẹ̀ Íjíbítì. Mósè àti Áárónì ti wá ń kó ipa pàtàkì nínú ‘ìfigẹ̀wọngẹ̀ láàárín àwọn ọlọ́run.’ Olórí àwọn àlùfáà onídán Íjíbítì ni Jánésì àti Jáńbérì. (2Ti 3:8) Fáráò wá ké pe gbogbo àwọn ọlọ́run Íjíbítì kí wọ́n lè mọ ẹni tó lágbára jù láàárín àwọn ọlọ́run yìí àti Jèhófà. Iṣẹ́ ìyanu àkọ́kọ́ tí Mósè ní kí Áárónì ṣe fi hàn pé Jèhófà lágbára ju àwọn ọlọ́run Íjíbítì lọ, síbẹ̀ Fáráò ṣagídí. (Ẹk 7:8-13) Nígbà tí ìyọnu kẹta ṣẹlẹ̀, àwọn àlùfáà onídán pàápàá gbà pé, “Ìka Ọlọ́run nìyí!” Kódà, ìyọnu eéwo náà fojú àwọn àlùfáà yẹn rí màbo débi pé wọn ò lè wá síwájú Fáráò láti ta ko Mósè nígbà ìyọnu náà.—Ẹk 8:16-19; 9:10-12.
Àwọn ìyọnu náà mú káwọn kan nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, kí ọkàn àwọn míì sì le. Mósè àti Áárónì ló kéde àwọn Ìyọnu Mẹ́wàá náà. Bí Mósè ṣe sọ, bẹ́ẹ̀ làwọn ìyọnu mẹ́wàá náà rí, ìyẹn sì jẹ́ kó hàn gbangba pé Jèhófà ni Mósè ń ṣojú fún. Orúkọ Jèhófà wá di mímọ̀ jákèjádò ilẹ̀ Íjíbítì, ìyẹn sì mú káwọn kan nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, kí ọkàn àwọn míì sì le. Ó jẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtàwọn ọmọ Íjíbítì kàn nífẹ̀ẹ́ Jèhófà; àmọ́ ọkàn Fáráò àtàwọn alátìlẹyìn rẹ̀ le. (Ẹk 9:16; 11:10; 12:29-39) Dípò káwọn ọmọ Íjíbítì tó wá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà náà ronú pé àwọn ti ṣẹ àwọn ọlọ́run wọn, wọ́n mọ̀ pé Jèhófà ló ń dá àwọn ọlọ́run yẹn lẹ́jọ́. Nígbà tí ìyọnu kẹsàn-án fi máa ṣẹlẹ̀, Mósè ti wá di “ẹni ńlá nílẹ̀ Íjíbítì lójú àwọn ìránṣẹ́ Fáráò àti àwọn èèyàn náà.”—Ẹk 11:3.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
it-1 78 ¶3-4
Olódùmarè
Jèhófà lo orúkọ oyè náà “Ọlọ́run Olódùmarè” (ʼEl Shad·daiʹ) nígbà tó ń ṣèlérí fún Ábúráhámù pé ó máa bí Ísákì, ìlérí yìí sì gba pé kí Ábúráhámù nígbàgbọ́ pé Ọlọ́run lágbára láti mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ. Bíbélì tún lo orúkọ oyè yìí nígbà tó sọ pé Ọlọ́run máa bù kún Ísákì àti Jékọ́bù, ìyẹn àwọn tó máa kó ipa pàtàkì nínú májẹ̀mú tí Jèhófà bá Ábúráhámù dá.—Jẹ 17:1; 28:3; 35:11; 48:3.
Nípa bẹ́ẹ̀, Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Mo ti máa ń fara han Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù pé èmi ni Ọlọ́run Olódùmarè [beʼElʹ Shad·daiʹ], àmọ́ ní ti orúkọ mi Jèhófà, mi ò jẹ́ kí wọ́n fi mọ̀ mí.” (Ẹk 6:3) Èyí ò túmọ̀ sí pé àwọn ọkùnrin ìgbàanì yìí ò mọ orúkọ Jèhófà, ó ṣe tán, wọ́n lo orúkọ yẹn dáadáa, àwọn míì tó wà ṣáájú wọn náà sì lò ó. (Jẹ 4:1, 26; 14:22; 27:27; 28:16) Kódà ẹ̀ẹ̀mẹfà péré ni ìwé Jẹ́nẹ́sísì tó sọ ìtàn àwọn olóòótọ́ ìgbàanì yìí lo ọ̀rọ̀ náà “Olódùmarè,” àmọ́ ìgbà méjìléláàádọ́sàn-án (172) ni orúkọ Jèhófà fara hàn níbẹ̀. Torí náà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọkùnrin olóòótọ́ yìí mọyì àjọṣe tí wọ́n ní pẹ̀lú Ọlọ́run, tí wọ́n sì gbà pé Ọlọ́run lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ orúkọ oyè náà “Olódùmarè,” síbẹ̀ wọn ò mọ ìtumọ̀ orúkọ Jèhófà lẹ́kùn ún rẹ́rẹ́ ní ti pé wọn ò láǹfààní láti rí bí Jèhófà ṣe fi agbára ńlá rẹ̀ hàn kí wọ́n lè lóye orúkọ rẹ̀ ní kíkún. Lórí kókó yìí, The Illustrated Bible Dictionary (Vol. 1, p. 572) sọ pé: “Ọlọ́run sọ àwọn ìlérí tó máa ṣẹ lọ́jọ́ iwájú fáwọn ọkùnrin olóòótọ́ yìí; ó sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òun Yahweh jẹ́ Ọlọ́run (ʼel) tó lágbára láti mú àwọn ìlérí náà ṣẹ (ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìtumọ̀ sadday). Àmọ́ Jèhófà túbọ̀ fi irú ẹni tó jẹ́ hàn nígbà tó fara han Mósè níbi igbó tó ń jò, ó sì fi agbára rẹ̀ hàn lọ́nà tí ìtumọ̀ orúkọ náà Yahweh fi ṣe kedere.”—Nípasẹ̀ J. D. Douglas, 1980.
it-2 435 ¶5
Mósè
Jèhófà yan Mósè láìka pé ó ro ara ẹ̀ pin. Mósè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàwáwí, ó sọ fún Jèhófà pé òun ò mọ ọ̀rọ̀ sọ. Àbí ẹ ò rí nǹkan, Mósè tó gbìyànjú láti sọ ara ẹ̀ di olùgbàlà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní nǹkan bí ogójì (40) ọdún sẹ́yìn ló wà ń ṣàwáwí báyìí. Ó sọ pé kí Jèhófà yan ẹlòmíì fún iṣẹ́ náà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé inú bí Ọlọ́run, kò pa Mósè tì. Dípò bẹ́ẹ̀, ó yan Áárónì arákùnrin rẹ̀ láti jẹ́ agbẹnusọ fún un. Torí náà, Mósè ń ṣojú fún Ọlọ́run, ó sì wá dà bí “Ọlọ́run” fún Áárónì tó jẹ́ agbẹnusọ rẹ̀. Nígbà tí Mósè àti Áárónì lọ jíṣẹ́ Jèhófà fún àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì àti fún Fáráò, ó jọ pé Mósè gan-an ni Jèhófà fún láwọn ìtọ́ni àti àṣẹ, Mósè wá ṣàlàyé wọn fún Áárónì kí Áárónì lè jíṣẹ́ náà fún Fáráò (Fáráò yìí ló jọba lẹ́yìn Fáráò tí Mósè sá fún ní ogójì (40) ọdún sẹ́yìn). (Ẹk 2:23; 4:10-17) Nígbà tó yá, Jèhófà sọ pé Áárónì máa jẹ́ “wòlíì” fún Mósè. Ohun tí ìyẹn túmọ̀ sí ni pé bí Mósè ṣe jẹ́ wòlíì Ọlọ́run tí Ọlọ́run ń fún ní ìtọ́ni, bẹ́ẹ̀ náà ni Áárónì jẹ́ wòlíì Mósè tí Mósè á máa fún ní ìtọ́ni. Bákan náà, Jèhófà sọ pé òun máa jẹ́ kí Mósè dà bí “Ọlọ́run fún Fáráò,” ní ti pé, Ọlọ́run máa fún un lágbára àti àṣẹ lórí Fáráò, torí náà kò ní sídìí fún un láti bẹ̀rù ọba Íjíbítì.—Ẹk 7:1, 2.
Bíbélì Kíkà
Fi Ọpẹ́ Fún Jèhófà Kí O sì Gba Ìbùkún
Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rere Pọ́ọ̀lù, káwa náà lè máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún oore tó ṣe fún wa? Bíi ti Pọ́ọ̀lù, a ní láti máa ṣàṣàrò lórí àwọn ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wa. (Sm. 116:12) Báwo lo ṣe máa dáhùn tí wọ́n bá bi ẹ́ pé, ‘Àwọn nǹkan wo ni Jèhófà ti ṣe fún ẹ tó o mọrírì gan-an? Ṣé wàá dárúkọ àjọṣe tímọ́tímọ́ tó o ní pẹ̀lú Jèhófà? Àbí wàá sọ ìdáríjì tó o rí gbà torí pé o nígbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Kristi? Ṣé wàá mẹ́nu kan àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tí wọ́n dúró tì ẹ́ nígbà ìṣòro tó le koko? Ó dájú pé, o ò ní gbàgbé láti dárúkọ ọkọ tàbí aya àtàwọn ọmọ rẹ ọ̀wọ́n. Tó o bá ń ronú lórí àwọn ohun tí Jèhófà Baba rẹ onífẹ̀ẹ́ ti ṣe fún ẹ, wàá moore, wàá sì máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ lójoojúmọ́.—Ka Sáàmù 92:1, 2.
Tá ò bá gbàgbé gbogbo ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wa, ó máa rọrùn fún wa láti gbàdúrà sí Jèhófà ká sì dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. (Sm. 95:2; 100:4, 5) Ọ̀pọ̀ ló rò pé téèyàn bá fẹ́ tọrọ nǹkan lọ́wọ́ Ọlọ́run nìkan ló yẹ kéèyàn gbàdúrà. Àmọ́, àwa mọ̀ pé inú Jèhófà máa ń dùn tá a bá dúpẹ́ oore tó ṣe fún wa. Nínú Bíbélì, a máa rí oríṣiríṣi àdúrà ìdúpẹ́ tó ń múnú ẹni dùn, lára wọn ni àdúrà tí Hánà gbà àti ti Hesekáyà. (1 Sám. 2:1-10; Aísá. 38:9-20) Torí náà, tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn ìránṣẹ́ olóòótọ́ wọ̀nyẹn tí wọ́n fi hàn pé àwọn moore. Tó o bá ń gbàdúrà sí Jèhófà, máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ nítorí àwọn ìbùkún tó ò ń rí gbà. (1 Tẹs. 5:17, 18) Àǹfààní tí o máa rí tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ kò lóǹkà. Wàá máa láyọ̀, ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà á túbọ̀ jinlẹ̀ sí i, wàá sì sún mọ́ ọn pẹ́kípẹ́kí.—Ják. 4:8.
JULY 13-19
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | Ẹ́KÍSÓDÙ 8-9
“Fáráò Agbéraga Ò Mò Pé Ohun Tí Jèhófà Fẹ́ Ni Òun Ń Ṣe”
it-2 1040-1041
Agídí
Nígbà míì, Jèhófà Ọlọ́run máa ń mú sùúrù fáwọn èèyàn tàbí orílẹ̀-èdè tí ikú tọ́ sí, ó sì máa ń jẹ́ kí wọ́n wà láàyè nìṣó. (Jẹ 15:16; 2Pe 3:9) Àwọn kan máa ń ronú pìwà dà, wọ́n sì máa ń rí àánú Ọlọ́run gbà (Joṣ 2:8-14; 6:22, 23; 9:3-15), àmọ́ àwọn míì máa ń mú kí ọkàn wọn le sí i, wọ́n á sì túbọ̀ máa ta ko Jèhófà àtàwọn èèyàn rẹ̀. (Di 2:30-33; Joṣ 11:19, 20) Torí pé Jèhófà kì í da ẹni kẹ́ni tó bá fẹ́ ṣagídí dúró, Bíbélì máa ń sọ ọ́ bíi pé òun ló mú kí wọ́n ‘ṣorí kunkun’ tàbí ‘kí ọkàn wọn le.’ Nígbà tó bá wá fìyà jẹ àwọn alágídí, ó máa ń fi agbára ńlá rẹ̀ hàn, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kí orúkọ ẹ̀ di mímọ̀.—Fi wé Ẹk 4:21; Jo 12:40; Ro 9:14-18.
it-2 1181 ¶3-5
Ìwà Ìkà
Bákan náà, Jèhófà lè lo ipò èyíkéyìí, kó sì mú káwọn tó ń hùwà ìkà ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ láìmọ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń ta ko Ọlọ́run, Ọlọ́run mọ bó ṣe lè dín agbára wọn kù kí wọ́n má bàa ṣe àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ ní jàǹbá, ó sì lè lo ohunkóhun táwọn ẹni ibi yìí bá ṣe láti mú ìyìn wá fún orúkọ rẹ̀. (Ro 3:3-5, 23-26; 8:35-39; Sm 76:10) Kókó yìí ló wà nínú Òwe 16:4, tó sọ pé: “Jèhófà ti mú kí gbogbo nǹkan rí bó ṣe fẹ́, kódà láti pa ẹni burúkú run ní ọjọ́ àjálù.”
Àpẹẹrẹ kan ni ti Fáráò tí Jèhófà rán Mósè àti Áárónì sí pé kó dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀. Ọlọ́run kọ́ ló sọ ọba Íjíbítì yìí di èèyàn burúkú, àmọ́ ó dá ẹ̀mí rẹ̀ sí, ó sì jẹ́ kí ọba yìí fi ara ẹ̀ hàn ní èèyàn burúkú tí ikú tọ́ sí. Ẹ́kísódù 9:16 jẹ́ ká mọ ìdí tí Jèhófà fi ṣe bẹ́ẹ̀, ó ní: “Ìdí tí mo fi dá ẹ̀mí rẹ sí ni pé: kí n lè fi agbára mi hàn ọ́, kí a sì lè ròyìn orúkọ mi ní gbogbo ayé.”
Àwọn Ìyọnu Mẹ́wàá tó dé bá àwọn ará Íjíbítì àti bí Jèhófà ṣe pa Fáráò àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ run nínú Òkun Pupa fi agbára ńlá Jèhófà hàn lọ́nà tó kàmàmà. (Ẹk 7:14–12:30; Sm 78:43-51; 136:15) Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn ìgbà yẹn, àwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká ṣì ń sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, nípa bẹ́ẹ̀, orúkọ Jèhófà di èyí tí a ròyìn rẹ̀ ní gbogbo ayé. (Joṣ 2:10, 11; 1Sa 4:8) Ká sọ pé Jèhófà ti pa Fáráò lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni, kò ní lè fi agbára rẹ̀ hàn lọ́nà tó kàmàmà láti gba àwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀, ògo rẹ̀ ò sì ní gbayé kan.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
it-1 878
Eṣinṣin Mùjẹ̀mùjẹ̀
Ní ti ìyọnu kẹrin tó dé bá ilẹ̀ Íjíbítì àmọ́ tí kò dé ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ń gbé ní Góṣénì, a ò lè sọ ní pàtó irú kòkòrò tí ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n lò nínú Ìwé Mímọ́ ń tọ́ka sí. (Ẹk 8:21, 22, 24, 29, 31; Sm 78:45; 105:31) Wọ́n ti túmọ̀ ʽA·rovʹ ní onírúurú ọ̀nà, àwọn kan pè é ní “eṣinṣin mùjẹ̀mùjẹ̀” (JB, NW, Ro), “kòkòrò” (Yg), “eṣinṣin” (AS, KJ, RS), “kòkòrò abìyẹ́” (AT), àti “eṣinṣin-ajá” (LXX).
Ọ̀rọ̀ náà “eṣinṣin mùjẹ̀mùjẹ̀” lè tọ́ka sí onírúurú àwọn eṣinṣin bí irù tàbí àwọn míì. Àwọn eṣinṣin kan wà tó máa ń ta èèyàn tàbí ẹranko, tá a sì fa ẹ̀jẹ̀ wọn mu. Àwọn eṣinṣin kan lè yé ẹyin wọn sára èèyàn tàbí ẹranko, tí ẹyin náà bá di ìdin, á bẹ̀rẹ̀ sí i fa ẹ̀jẹ̀ onítọ̀hún mu; ilẹ̀ olóoru làwọn eṣinṣin yìí wà. Torí náà, àjálù ńlá ni ìyọnu àwọn eṣinṣin mùjẹ̀mùjẹ̀ tó dé bá àwọn ará Íjíbítì àtàwọn ẹran wọn, kódà àwọn eṣinṣin yìí lè fa ikú nígbà míì.
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Ẹ́kísódù
8:26, 27—Kí nìdí tí Mósè fi sọ pé ẹbọ táwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò rú á jẹ́ “ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú àwọn ará Íjíbítì”? Onírúurú ẹranko làwọn ará Íjíbítì ń bọ. Nítorí náà, dídá tí Mósè dárúkọ ẹbọ tipa bẹ́ẹ̀ mú kí ọ̀rọ̀ náà kúrò ní tàwàdà, á sì mú kí wọ́n rí ìdí tó fi ń tẹnu mọ́ ọn pé kí wọ́n yọ̀ǹda fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti lọ rúbọ sí Jèhófà.
Bíbélì Kíkà
JULY 20-26
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | Ẹ́KÍSÓDÙ 10-11
“Mósè àti Áárónì Lo Ìgboyà”
Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù Máa Fìgboyà Wàásù
Tún ronú nípa ìgboyà tí Mósè fi hàn láti bá Fáráò sọ̀rọ̀, ojú táwọn èèyàn fi ń wo aláṣẹ yìí ju pé ó ń ṣojú fún ọlọ́run wọn lọ, ọlọ́run kan ni wọ́n kà á sí, ìyẹn ọmọkùnrin ọlọ́run oòrùn tí wọ́n ń pè ní Ráà. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Fáráò yìí náà jọ́sìn ère ara ẹ̀ bíi tàwọn Fáráò tó kù. Òfin làwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀, torí pé apàṣẹwàá ni. Fáráò alágbára, tó ń ṣakọ, tó sì jẹ́ olóríkunkun yìí kì í fẹ́ kí ẹnikẹ́ni sọ ohun tó máa ṣe fún un. Níwájú ọkùnrin yìí ni Mósè, olùṣọ́ àgùntàn tó jẹ́ onínútútù ti fara hàn lọ́pọ̀ ìgbà láìjẹ́ pé ó ránṣẹ́ sí i, tí ò sì ṣe tán láti gbà á lálejò. Àsọtẹ́lẹ̀ wo sì ni Mósè sọ? Àsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn ìyọnu apanirun. Kí ni Mósè béèrè? Ó ní kó fi àwọn ẹrú ẹ̀ tí wọ́n tó mílíọ̀nù bíi mélòó kan sílẹ̀, kí wọ́n sì kúrò nílùú náà! Ǹjẹ́ Mósè nílò ìgboyà? Dájúdájú, bẹ́ẹ̀ ni!—Núm. 12:3; Héb. 11:27.
it-2 436 ¶4
Mósè
Ó gba ìgboyà àti ìgbàgbọ́ láti kojú Fáráò. Ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà ló mú kó ṣeé ṣe fún Mósè àti Áárónì láti ṣiṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún wọn. Fojú inú wo bí ààfin Fáráò ṣe máa rí, Fáráò fúnra ẹ̀ ni ọba aláyélúwà tó lágbára jù lọ láyé ìgbà yẹn. Ó máa ń gbéra ga torí pé ó lọ́lá, ó lẹ́nu, ó sì lágbára, kódà wọ́n kà á sí ọlọ́run kan. Yàtọ̀ síyẹn, ó ní ọ̀pọ̀ àwọn agbaninímọ̀ràn, ọ̀gágun, ẹ̀ṣọ́ àti ẹrú. Ó tún láwọn àlùfáà onídán tó ń ta ko Mósè lójú méjèèjì. Lẹ́yìn Fáráò, àwọn ọkùnrin yìí ló tún lágbára jù ní gbogbo agbègbè yẹn. Gbogbo àwọn tá a mẹ́nu kàn yìí ló wà lẹ́yìn Fáráò àtàwọn ọlọ́run ilẹ̀ Íjíbítì. Kì í ṣe ẹ̀ẹ̀kan, kì í ṣe ẹ̀ẹ̀mejì ni Mósè àti Áárónì wá jíṣẹ́ Jèhófà fún Fáráò. Bí wọ́n ṣe ń wá, bẹ́ẹ̀ lọkàn Fáráò túbọ̀ ń le sí i, torí pé kò ṣe tán láti yọ̀ǹda àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ ẹrú rẹ̀. Kódà, lẹ́yìn tí Mósè àti Áárónì kéde ìyọnu kẹjọ, wọ́n lé wọn kúrò níwájú Fáráò. Lẹ́yìn tí ìyọnu kẹsàn-án sì wáyé, Fáráò pàṣẹ fún Mósè àti Áárónì pé wọn ò gbọ́dọ̀ tún fojú kan òun mọ́, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, wọ́n máa kú.—Ẹk 10:11, 28.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Àwọn Ẹlẹ́rìí Ní Ìlòdìsí Àwọn Ọlọ́run Èké
Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣì wà ní Íjíbítì, Jèhófà rán Mósè sí Fáráò, ó sì wí pé: “Wọlé tọ Farao lọ: nítorí tí mo mú àyà rẹ le, àti àyà àwọn ìránṣẹ́ rẹ, kí èmi kí ó lè fi iṣẹ́-àmì mi wọ̀nyí hàn níwájú rẹ: àti kí ìwọ kí ó lè wí ní etí ọmọ rẹ, àti ti ọmọ ọmọ rẹ, ohun tí mo ṣe ní Egipti, àti iṣẹ́-àmì mi tí mo ṣe nínú wọn; kí ẹ̀yin kí ó lè mọ̀ pé èmi ni OLUWA.” (Eksodu 10:1, 2) Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì onígbọràn yóò ròyìn àwọn ìṣe alágbára-ńlá ti Jèhófà fún àwọn ọmọ wọn. Àwọn ọmọ wọn náà pẹ̀lú, yóò ròyìn fún àwọn ọmọ wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò sì máa ṣe é láti ìran dé ìran. Nípa báyìí, a óò máa rántí àwọn iṣẹ́-àrà tí ó lágbára tí Jèhófà ṣe. Bákan náà lónìí, àwọn òbí ní ẹrù iṣẹ́ jíjẹ́rìí fún àwọn ọmọ wọn.—Deuteronomi 6:4-7; Owe 22:6.
it-1 783 ¶5
Jíjáde Lọ
Jèhófà fi ọwọ́ agbára ńlá rẹ̀ hàn lọ́nà àrà, ó dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè, ó sì gbé orúkọ rẹ̀ ga. Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọdá Òkun Pupa, tí wọ́n sì wà ní apá Ìlà Oòrùn òkun náà, Mósè ṣáájú wọn nínú orin, Míríámù ẹ̀gbọ́n rẹ̀ wá mú ìlù tanboríìnì, ó sì ṣáájú gbogbo àwọn obìnrin nínú ijó bí wọ́n ṣe ń kọrin tẹ̀ lé àwọn ọkùnrin. (Ẹk 15:1, 20, 21) Wọ́n ń yọ̀ torí pé Jèhófà ti pa àwọn ọ̀tá wọn run pátápátá. Nígbà tí wọ́n jáde kúrò ní Íjíbítì, Jèhófà ò jẹ́ kí ẹni kẹ́ni tàbí àwọn ẹranko wu wọ́n léwu; kódà ajá ò gbó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. (Ẹk 11:7) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìwé Ẹ́kísódù ò sọ pé Fáráò fúnra ẹ̀ kú pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ nínú Òkun Pupa, Sáàmù 136:15 sọ pé Jèhófà “gbọn Fáráò àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sínú Òkun Pupa.”
Bíbélì Kíkà
JULY 27–AUGUST 2
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | Ẹ́KÍSÓDÙ 12
“Ohun Tí Ìrékọjá Túmọ̀ sí fún Àwa Kristẹni”
‘Ẹ Kún Fún Ìdùnnú’
Jésù kú ní Nísàn 14, ọdún 33 Sànmánì Kristẹni. Lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, ọjọ́ àjọ̀dún Ìrékọjá ni Nísàn 14 jẹ́, ọjọ́ ìdùnnú sì ni. Ní àyájọ́ ọjọ́ yẹn lọ́dọọdún, àwọn ìdílé máa ń jẹun pa pọ̀, oúnjẹ yìí sì máa ń ní ọ̀dọ́ àgùntàn tí kò lábàwọ́n nínú. Èyí ń rán wọn létí ipa tí ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́ àgùntàn kó nínú dídá àkọ́bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sí nígbà tí áńgẹ́lì aṣekúpani pa àkọ́bí àwọn ará Íjíbítì ní Nísàn 14 ọdún 1513 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. (Ẹ́kísódù 12:1-14) Jésù ni ọ̀dọ́ àgùntàn Ìrékọjá náà dúró fún, ẹni tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa rẹ̀ pé: “A ti fi Kristi ìrékọjá wa rúbọ.” (1 Kọ́ríńtì 5:7) Bíi ti ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́ àgùntàn Ìrékọjá yẹn, ẹ̀jẹ̀ Jésù táwọn èèyàn ta sílẹ̀ jẹ́ kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ní ìdáǹdè.—Jòhánù 3:16, 36.
it-2 583 ¶6
Ìrékọjá
Àwọn apá kan nínú àjọyọ̀ Ìrékọjá táwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń ṣe ṣẹ sára Jésù. Bí àpẹẹrẹ, ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n wọ́n sára àwọn ilé ní Íjíbítì gba àwọn àkọ́bí sílẹ̀ lọ́wọ́ áńgẹ́lì tó ń pani run. Lọ́nà kan náà, Pọ́ọ̀lù pe àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ní ìjọ àwọn àkọ́bí (Heb 12:23), ó sì sọ pé Kristi rà wọ́n pa dà nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. (1Tẹ 1:10; Ef 1:7) Òmíì ni pé wọn ò gbọ́dọ̀ kán egungun ọ̀dọ́ àgùntàn tí wọ́n máa lò nígbà Ìrékọjá. Bíbélì sì sọ tẹ́lẹ̀ pé kò ní sí ìkankan nínú egungun Jésù tí a máa ṣẹ́, èyí sì ṣẹ nígbà tó kú. (Sm 34:20; Jo 19:36) Torí náà, Ìrékọjá táwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń ṣe wà lára Òfin tó jẹ́ òjìji àwọn nǹkan rere tó ń bọ̀, èyí tó tọ́ka sí Jésù Kristi, ìyẹn “Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run.”—Heb 10:1; Jo 1:29.
‘Èyí Yóò Jẹ́ Ìrántí Fún Yín’
Láti ìran dé ìran ni àwọn baba á máa ṣàlàyé àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì tó wà nínú ayẹyẹ náà fún àwọn ọmọ wọn. Ọ̀kan lára irú àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì bẹ́ẹ̀ ni pé Jèhófà lè dáàbò bo àwọn tó ń sìn ín. Àwọn ọmọ á wá mọ̀ pé ẹni gidi ni Ọlọ́run àti pé kì í ṣe ọlọ́run kan tí kò ṣeé lóye. Ọlọ́run alààyè ni Jèhófà, ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn rẹ̀ jẹ ẹ́ lógún, ó sì máa ń gbèjà wọn. Ó fi ẹ̀rí èyí hàn nígbà tó “mú ìyọnu àjàkálẹ̀ bá àwọn ará Íjíbítì” tó sì dáàbò bo àkọ́bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ó dá ẹ̀mí àwọn àkọ́bí wọn sí.
Àwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni kì í ṣàlàyé ohun tí Ìrékọjá yẹn túmọ̀ sí fún àwọn ọmọ wọn lọ́dọọdún. Àmọ́, ṣé o máa ń kọ́ àwọn ọmọ rẹ ní ẹ̀kọ́ pàtàkì kan náà pé Ọlọ́run máa ń dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀? Ṣé o máa ń jẹ́ kí wọ́n mọ bó ṣe dá ọ lójú tó pé Jèhófà ṣì ni Aláàbò àwọn èèyàn rẹ̀ lóòótọ́? (Sm. 27:11; Aísá. 12:2) Ṣé o kàn máa ń sọ ìtàn náà fún àwọn ọmọ rẹ lọ́nà tí kò ta wọ́n jí ni àbí ńṣe lẹ jọ máa ń jíròrò rẹ̀ lọ́nà tó gbádùn mọ́ wọn? Rí i pé ẹ̀kọ́ yìí wà lára àwọn nǹkan tẹ́ ẹ jọ ń jíròrò kí ìdílé rẹ bàa lè túbọ̀ ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
it-2 582 ¶2
Ìrékọjá
Jèhófà fi àwọn Ìyọnu Mẹ́wàá ní pàtàkì jù lọ ìyọnu kẹwàá, ìyẹn ikú àwọn àkọ́bí ọmọ Íjíbítì dá àwọn ọlọ́run èké wọn lẹ́jọ́. (Ẹk 12:12) Àgbò jẹ́ ẹran mímọ́ fáwọn tó ń jọ́sìn ọlọ́run tí wọ́n ń pè ní Ra, torí náà ìwà burúkú gbáà ló máa jẹ́ lójú àwọn ará Íjíbítì bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ń wọ́n ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́ àgùntàn sára ilẹ̀kùn wọn. Bákan náà, ẹran mímọ́ ni àwọn ará Íjíbítì ka akọ màlúù sí, torí náà ẹ̀tẹ́ ńlá gbáà ló dé bá ọlọ́run tí wọ́n ń pè ní Osiris nígbà tí àkọ́bí àwọn akọ màlúù wọn kú. Wọ́n tún máa ń gbé Fáráò gẹ̀gẹ̀, wọ́n sì máa ń pè é ní ọmọ Ra. Torí náà, bí àkọ́bí Fáráò fúnra ẹ̀ ṣe kú fi hàn pé Ra àti Fáráò ò lágbára kankan.
it-1 504 ¶1
Àpéjọ
Ohun kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nípa àwọn “àpéjọ mímọ́” yìí ni pé, lásìkò yẹn, àwọn èèyàn náà kì í ṣe iṣẹ́ àṣekára kankan. Bí àpẹẹrẹ, ọjọ́ kìíní àti ọjọ́ keje Àjọyọ̀ Búrẹ́dì Aláìwú jẹ́ “àpéjọ mímọ́,” Jèhófà sì sọ nípa rẹ̀ pé: “Ẹ má ṣe iṣẹ́ kankan ní àwọn ọjọ́ yìí. Ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan máa jẹ nìkan ni kí wọ́n sè.” (Ẹk 12:15, 16) Àmọ́, lásìkò àwọn “àpéjọ mímọ́” yìí, ọwọ́ àwọn àlùfáà máa ń dí bí wọ́n ṣe ń rúbọ sí Jèhófà (Le 23:37, 38), ìyẹn ò sì fi hàn pé wọ́n rú òfin Ọlọ́run pé kí wọ́n má ṣiṣẹ́ lọ́jọ́ náà. Yàtọ̀ síyẹn, ti pé àwọn èèyàn náà ò ṣiṣẹ́ kò túmọ̀ sí pé wọ́n á máa sùn látàárọ̀ ṣúlẹ̀, kàkà bẹ́ẹ̀ wọ́n máa ń lo àkókò yẹn láti túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Ní àwọn Sábáàtì tí wọ́n máa ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, àwọn èèyàn náà máa ń kóra jọ láti jọ́sìn àti láti gbá ìtọ́ni Jèhófà. Lẹ́yìn náà, wọ́n máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún wọn, wọ́n sì máa ṣàlàyé ẹ̀ lẹ́kùn ún rẹ́rẹ́ bí wọ́n ṣe máa ń ṣe nínú àwọn sínágọ́gù nígbà tó yá. (Iṣe 15:21) Torí náà, bí àwọn èèyàn náà kì í ṣe ṣiṣẹ́ kankan láwọn ọjọ́ Sábáàtì àti láwọn ọjọ́ “àpéjọ mímọ́” máa ń jẹ́ kí wọ́n lè ráyè gbàdúrà, kí wọ́n sì ronú jinlẹ̀ lórí ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kí wọ́n máa ṣe.
Bíbélì Kíkà