ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • rr ojú ìwé 47
  • ‘Mò Ń Wo Àwọn Ẹ̀dá Alààyè Náà’

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • ‘Mò Ń Wo Àwọn Ẹ̀dá Alààyè Náà’
  • Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Wo Ni “Ẹ̀dá Alààyè Tó Ní Ojú Mẹ́rin Náà”?
    Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
  • “Ṣàlàyé Bí Tẹ́ńpìlì Náà Ṣe Rí”
    Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
  • “Fi Ọkàn-àyà Rẹ Sí” Tẹ́ńpìlì Ọlọ́run!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • ‘Mo Rí Ìran Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run’
    Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
Àwọn Míì
Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
rr ojú ìwé 47
Ère akọ màlúù tí wọ́n ṣe nígbà àtijọ́, ó ní orí èèyàn àti ìyẹ́.

ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 4A

‘Mò Ń Wo Àwọn Ẹ̀dá Alààyè Náà’

Ó dájú pé Ìsíkíẹ́lì á ti máa rí àwọn ère akọ màlúù àti ti kìnnìún tó rí gìrìwò, tó sì ní orí èèyàn àti ìyẹ́, èyí tí wọ́n máa ń gbé dúró bí ẹ̀ṣọ́ ní ẹnu ọ̀nà ààfin àtàwọn tẹ́ńpìlì. Àwọn ère yìí sábà máa ń wà káàkiri ilẹ̀ Ásíríà àti Babilóníà àtijọ́. Bíi ti àwọn ẹlòmíì tó ń rí àwọn ère yìí, àwọn ẹ̀dá tó rí fàkìàfakia yìí á ti máa ya Ìsíkíẹ́lì lẹ́nu. Àwọn míì tiẹ̀ fẹ́rẹ̀ẹ́ ga tó ogún (20) ẹsẹ̀ bàtà. Síbẹ̀, kò sí bó ṣe lè jọ pé àwọn ẹ̀dá náà lágbára tó, wọn kì í ṣe nǹkan ẹlẹ́mìí, òkúta ni wọ́n fi gbẹ́ wọn.

AKỌ MÀLÚÙ TÓ NÍ ORÍ ÈÈYÀN ÀTI ÌYẸ́

A fi bí èèyàn ṣe ga tó (nǹkan bí ẹsẹ̀ bàtà mẹ́fà) wéra pẹ̀lú bí ère akọ màlúù tó ní orí èèyàn àti ìyẹ́ ṣe ga tó (nǹkan bí ẹsẹ̀ bàtà mẹ́rìnlá àbọ̀).

Ère akọ màlúù tó ní orí èèyàn àti ìyẹ́ wà ní ẹnu ọ̀nà àbáwọlé lára ògiri ìlú Kọsábádì tó jẹ́ ìlú àwọn ara Ásíríà àtijọ́. Wọ́n gbà gbọ́ pé ère yìí ò ní jẹ́ kí nǹkan láabi wọnú ìlú náà.

Àmọ́ “ẹ̀dá alààyè” ni Ìsíkíẹ́lì pe ẹ̀dá mẹ́rin tó rí nínú ìran. Ẹ ò rí i pé wọ́n yàtọ̀ pátápátá sí ère tí wọ́n fi òkúta lásánlàsàn gbẹ́! Ohun tí Ìsíkíẹ́lì rí yìí wọ̀ ọ́ lọ́kàn débi pé ó tó ìgbà mọ́kànlá (11) tó mẹ́nu ba “ẹ̀dá alààyè” níbẹ̀rẹ̀ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀. (Ìsík. 1:​5-22) Ìran ẹ̀dá alààyè mẹ́rin tí wọ́n jọ ń gbéra lẹ́ẹ̀kan náà nísàlẹ̀ ìtẹ́ Jèhófà ti máa gbìn ín sí Ìsíkíẹ́lì lọ́kàn pé gbogbo ìṣẹ̀dá wà níkàáwọ́ Jèhófà. Bó ṣe rí lónìí náà nìyẹn, ìran yẹn máa ń gbìn ín sí wa lọ́kàn pé Jèhófà tóbi lọ́ba, agbára rẹ̀ pọ̀ gidigidi, ògo rẹ̀ ò sì láfiwé.​—1 Kíró. 29:11.

Ọ̀kan lára àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin tó ní ojú mẹ́rin, ó na ìyẹ́ rẹ̀ síta.

Pa dà sí orí 4, ìpínrọ̀ 4

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́