Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
MARCH 1-7
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | NỌ́ŃBÀ 7-8
“Ohun Tá A Rí Kọ́ Látinú Bí Jèhófà Ṣe Ṣètò Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì”
it-1 497 ¶3
Ìjọ
Ní Ísírẹ́lì, wọ́n sábà máa ń yan àwọn olórí tó tóótun láti ṣojú fún wọn. (Ẹsr 10:14) Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé “àwọn ìjòyè” ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan ló mú ọrẹ wá síwájú Jèhófà lẹ́yìn tí wọ́n to àgọ́ ìjọsìn. (Nọ 7:1-11) Bákan náà, nígbà ayé Nehemáyà, táwọn èèyàn bá “wọnú àdéhùn,” àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì àtàwọn “olórí àwọn èèyàn náà” ló máa ń gbé èdìdì lé àdéhùn yẹn. (Ne 9:38–10:27) Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà láginjù, Kórà, Dátánì, Ábírámù, àti Ónì pẹ̀lú igba ó lé àádọ́ta (250) ọkùnrin lára ‘àwọn ìjòyè àpéjọ, àwọn tí a yàn nínú ìjọ àtàwọn ọkùnrin tó lókìkí’ kóra jọ láti ta ko Mósè àti Áárónì. (Nọ 16:1-3) Ìgbà kan wà tí Jèhófà sọ fún Mósè pé kó yan àádọ́rin (70) ọkùnrin nínú àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì tí wọ́n jẹ́ olórí, kí wọ́n lè bá a ru “ẹrù àwọn èèyàn náà,” torí pé kò lè dá ru ẹrù wọn. (Nọ 11:16, 17, 24, 25) Léfítíkù 4:15 sọ̀rọ̀ nípa “àwọn àgbààgbà àpéjọ,” ó jọ pé àwọn àgbààgbà yìí, àwọn olórí àtàwọn onídàájọ́ ló máa ń ṣojú fún àwọn èèyàn náà.—Nọ 1:4, 16; Joṣ 23:2; 24:1.
it-2 796 ¶1
Rúbẹ́nì
Apá gúúsù àgọ́ ìjọsìn ni ẹ̀yà Rúbẹ́nì, Síméónì àti Gádì wà nínú ibùdó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Tí wọ́n bá fẹ́ kúrò ní ibùdó, ẹ̀yà Júdà, Ísákà àti Sébúlúnì ló máa ń kọ́kọ́ gbéra. Àwọn ẹ̀yà tó wà ní apá gúúsù á wá tẹ̀ lé wọn, ẹ̀yà Rúbẹ́nì ló sì máa ń ṣáájú. (Nọ 2:10-16; 10:14-20) Lọ́jọ́ ìyàsímímọ́ àgọ́ ìjọsìn, bí wọ́n ṣe tẹ̀ léra wọn náà nìyẹn nígbà tí wọ́n mú ọrẹ wá síwájú Jèhófà.—Nọ 7:1, 2, 10-47.
Àwọn Ìṣúra Tẹ̀mí
it-1 835
Àkọ́bí
Àwọn àkọ́bí ọkùnrin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ló máa ń di olórí ìdílé kọ̀ọ̀kan, torí náà àwọn ló máa ń ṣojú fún gbogbo orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Kódà, Jèhófà pe gbogbo orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ní “àkọ́bí” òun torí májẹ̀mú tó bá Ábúráhámù dá. (Ẹk 4:22) Lẹ́yìn tí Jèhófà dáàbò bo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n ya ‘gbogbo àkọ́bí ọkùnrin nínú àwọn ọmọ wọn, àkọ́bí èèyàn lọ́kùnrin àti àkọ́bí ẹran tó jẹ́ akọ’ sí mímọ́ fún òun. (Ẹk 13:2) Torí náà, gbogbo àkọ́bí ọkùnrin ni wọ́n yà sọ́tọ̀ fún Ọlọ́run.
MARCH 8-14
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | NỌ́ŃBÀ 9-10
“Bí Jèhófà Ṣe Ń Darí Àwọn Èèyàn Rẹ̀”
it-1 398 ¶3
Àgọ́
Ọ̀nà tó ṣàrà-ọ̀tọ̀ ni Jèhófà gbà ṣètò àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n bá fẹ́ gbéra láti ibì kan sí ibòmíì (ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ibi ogójì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí Mósè sọ pé wọ́n pàgọ́ sí nínú Nọ́ńbà orí kẹtàlélọ́gbọ̀n [33]). Gbogbo ìgbà tí ìkùukùu bá wà lórí àgọ́ ìjọsìn làwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa wà níbi tí wọ́n pàgọ́ sí. Gbàrà tí ìkùukùu bá sì gbéra ni wọ́n máa ń gbéra. “Tí Jèhófà bá pàṣẹ pé kí wọ́n pàgọ́, wọ́n á pàgọ́. Tí Jèhófà bá sì pàṣẹ pé kí wọ́n gbéra, wọ́n á gbéra.” (Nọ 9:15-23) Kàkàkí méjì tí wọ́n fi fàdákà ṣe ni wọ́n fi máa ń kéde ohun tí Jèhófà sọ. (Nọ 10:2, 5, 6) Ìgbàkigbà tí wọ́n bá fi kàkàkí náà fun ìró tó ń lọ sókè sódò làwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń gbéra. “Ogúnjọ́ oṣù kejì, ọdún kejì” [1512 Ṣ.S.K.] ni ìgbà àkọ́kọ́ tí wọ́n lo kàkàkí yìí. Tí wọ́n bá gbéra, àwọn tó gbé àpótí májẹ̀mú ló máa ń ṣáájú, àwọn ẹ̀yà mẹ́ta àkọ́kọ́, ìyẹn Júdà, Ísákà àti Sébúlúnì á wá tẹ̀ lé e, Júdà ló sì máa ń ṣáájú wọn. Àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì àtàwọn ọmọ Mérárì á wá tẹ̀ lé wọn, wọ́n máa gbé ohun tí wọ́n yàn fún wọn lára ohun èlò àgọ́ ìjọsìn. Ẹ̀yà mẹ́ta míì máa gbéra, Rúbẹ́nì máa ṣáájú, Síméónì àti Gádì á sì tẹ̀ lé wọn. Àwọn ọmọ Kóhátì tí wọ́n ń ru ohun èlò ibi mímọ́ á wá gbéra, ẹ̀yà mẹ́ta míì á sì tẹ̀ lé wọn. Éfúrémù ló máa ṣáájú, Mánásè àti Bẹ́ńjámínì á sì tẹ̀ lé wọn. Lẹ́yìn ìyẹn, ẹ̀yà Dánì tó wà lára ẹ̀yà mẹ́ta tó gbẹ̀yìn á ṣáájú, Áṣérì àti Náfútálì á sì tẹ̀ lé wọn. Èyí fi hàn pé àwùjọ méjì tó pọ̀ jù tó sì lágbára jù ló máa ń wà ní ọwọ́ iwájú àtẹ̀yìn nígbà tí wọ́n bá ń lọ.—Nọ 10:11-28.
Àwọn Ìṣúra Tẹ̀mí
it-1 199 ¶3
Àpéjọ
Ìdí Tí Wọ́n Fi Ń Pé Jọ. Jèhófà fẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa pé jọ kí wọ́n lè máa gba ìtọ́ni látọ̀dọ̀ òun. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi gbọ́dọ̀ máa ṣe Ìrékọjá lọ́dọọdún. Kódà, tí ọkùnrin kan bá wà ní mímọ́, tí kò sì rìnrìn àjò, síbẹ̀ tó kọ̀ láti ṣètò ẹbọ Ìrékọjá, ṣe ni wọ́n máa pa á. (Nọ 9:9-14) Nígbà tí Ọba Hẹsikáyà pe àwọn èèyàn Júdà àtàwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó kù pé kí wọ́n wá ṣe Ìrékọjá ní Jerúsálẹ́mù, ó sọ pé: “Ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì, ẹ pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà . . . ẹ má ṣorí kunkun bí àwọn baba ńlá yín. Ẹ fi ara yín fún Jèhófà, kí ẹ wá sí ibi mímọ́ rẹ̀ tó ti yà sí mímọ́ títí láé, kí ẹ sì máa sin Jèhófà Ọlọ́run yín, kí ìbínú rẹ̀ tó ń jó fòfò lè kúrò lórí yín. . . . Jèhófà Ọlọ́run yín jẹ́ ẹni tó ń gba tẹni rò àti aláàánú, kò sì ní yí ojú rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ yín tí ẹ bá pa dà sọ́dọ̀ rẹ̀.” (2Kr 30:6-9) Tẹ́nì kan bá wá mọ̀ọ́mọ̀ pinnu pé òun ò ní wá, ìyẹn máa fi hàn pé ẹni náà ti pa Ọlọ́run tì. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwa Kristẹni kì í ṣe Ìrékọjá lónìí, síbẹ̀ Pọ́ọ̀lù rí i pé ó ṣe pàtàkì pé ká kíyè sára ká má ṣe máa kọ ìpàdé wa sílẹ̀, ó ní: “Ẹ sì jẹ́ ká gba ti ara wa rò ká lè máa fún ara wa níṣìírí láti ní ìfẹ́ àti láti ṣe àwọn iṣẹ́ rere, ká má ṣe máa kọ ìpàdé wa sílẹ̀, bí àṣà àwọn kan, àmọ́ ká máa gba ara wa níyànjú, ní pàtàkì jù lọ bí ẹ ṣe ń rí i pé ọjọ́ náà ń sún mọ́lé.”—Heb 10:24, 25; tún wo ÌJỌ.
MARCH 15-21
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | NỌ́ŃBÀ 11-12
“Kí Nìdí Tí Kò Fi Yẹ Ká Máa Ráhùn?”
it-2 719 ¶4
Ìjà
Kùn. Ṣe lẹni tó bá ń kùn máa ń mú kí nǹkan tojú súni. Kò pẹ́ rárá táwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi bẹ̀rẹ̀ sí í kùn sí Jèhófà lẹ́yìn tí wọ́n kúrò ní Íjíbítì, wọ́n sì ń ṣàríwísí nípa bí Mósè àti Áárónì ṣe ń darí wọn. (Ẹk 16:2, 7) Nígbà tó yá, ó le débi pé àròyé wọn mú kí Mósè bẹ̀bẹ̀ pé kí Jèhófà pa òun. (Nọ 11:13-15) Àkóbá tó burú jáì lẹni tó bá ń kùn máa ń fà fún ara ẹ̀. Torí nígbà táwọn èèyàn yẹn ń kùn sí Mósè, ṣe ni Jèhófà gbà pé òun gan-an ni wọ́n ń ṣọ̀tẹ̀ sí, tí wọ́n sì ń ṣàríwísí ọ̀nà tóun ń gbà darí wọn. (Nọ 14:26-30) Ọ̀pọ̀ èèyàn ló sì kú torí pé wọn ò yéé ṣàríwísí.
Àwọn Ìṣúra Tẹ̀mí
it-2 309
Mánà
Bó Ṣe Rí. Mánà “funfun bí irúgbìn kọriáńdà,” ó sì rí bí oje igi tó mọ́ rekete. Ó dùn bí “àkàrà olóyin pẹlẹbẹ” tàbí “àkàrà dídùn tí wọ́n fi òróró sí.” Lẹ́yìn tí wọ́n bá fi ọlọ lọ̀ ọ́ tàbí gún un nínú odó, wọ́n máa ń sè é tàbí kí wọ́n fi ṣe búrẹ́dì.—Ẹk 16:23, 31; Nọ 11:7, 8.
MARCH 22-28
Àwọn Ìṣúra Tẹ̀mí
it-1 740
Ilẹ̀ Tí Ọlọ́run Fún Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì
ILẸ̀ tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dáa lóòótọ́. Nígbà tí Mósè ní káwọn amí lọ wo Ilẹ̀ Ìlérí, kí wọ́n sì mú lára èso ibẹ̀ wá, wọ́n mú èso ọ̀pọ̀tọ́, pómégíránétì àti òṣùṣù èso àjàrà kan wá. Èso àjàrà yẹn tóbi débi pé ọkùnrin méjì lára wọn ló fi ọ̀pá gbọọrọ kan gbé e! Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àìnígbàgbọ́ mú kí ẹ̀rù ba èyí tó pọ̀ jù lára àwọn amí yẹn, síbẹ̀ wọ́n ròyìn pé: ‘Wàrà àti oyin ń ṣàn níbẹ̀ lóòótọ́.’—Nọ 13:23, 27.
APRIL 19-25
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | NỌ́ŃBÀ 22-24
“Jèhófà Sọ Ègún Di Ìbùkún”
it-2 291
Wèrè
Ìwà Tí Kò Bọ́gbọ́n Mu Lòdì sí Jèhófà. Torí kí Báláámù lè gba owó lọ́wọ́ Bálákì ọba ilẹ̀ Móábù, ó gbìyànjú láti sọ tẹ́lẹ̀ lòdì sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àmọ́ Jèhófà ò jẹ́ kó yọrí sí rere. Nígbà tí àpọ́sítélì Pétérù ń sọ̀rọ̀ nípa Báláámù, ó sọ pé “ẹran akẹ́rù tí kò lè sọ̀rọ̀ tó sọ̀rọ̀ bí èèyàn, kò jẹ́ kí wòlíì náà ṣe ohun tí kò bọ́gbọ́n mu.” Ọ̀rọ̀ èdè Gíríìkì náà pa·ra·phro·niʹa ni Pétérù lò nínú ẹsẹ Bíbélì yìí nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ìwà tí kò bọ́gbọ́n mu tí Báláámù hù, ohun tó sì túmọ̀ sí ni pé “kéèyàn ṣe bí ayírí.”—2Pe 2:15, 16; Nọ 22:26-31.
APRIL 26–MAY 2
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | NỌ́ŃBÀ 25-26
“Ẹnì Kan Lè Ṣe Ọ̀pọ̀ Èèyàn Láǹfààní”
Àwọn Ìṣúra Tẹ̀mí
it-1 359 ¶1-2
Ààlà
Torí náà, ó jọ pé ohun méjì ló ń pinnu bí wọ́n ṣe máa pín ilẹ̀ fún ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan. Àkọ́kọ́ ni ibi tí kèké bá mú, ìkejì sì ni bí ẹ̀yà kan bá ṣe tóbi tó. Wọ́n lè lo kèké láti mọ ibi tí wọ́n máa pín fún ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, bóyá àríwá tàbí gúúsù, ìlà oòrùn tàbí ìwọ̀ oòrùn, ilẹ̀ tó tẹ́jú tàbí orí òkè. Tí kèké bá mú ibì kan fún wọn, wọ́n mọ̀ pé ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìpinnu yẹn ti wá, torí náà wọn ò ní máa jowú ara wọn tàbí bá ara wọn jà. (Owe 16:33) Èyí á sì jẹ́ kí Jèhófà bójú tó bí nǹkan ṣe ń lọ nínú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, kó lè wà níbàámu pẹ̀lú àsọtẹ́lẹ̀ tí Jékọ́bù baba ńlá wọn sọ nípa wọn kó tó kú, bó ṣe wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 49:1-33.
Lẹ́yìn tí kèké bá ti jẹ́ kí wọ́n mọ apá ibi tí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan máa wà, wọ́n á wá lo ohun kejì, ìyẹn bí ẹ̀yà náà bá ṣe tóbi tó láti mọ bí ibi tí wọ́n máa pín fún wọn ṣe máa fẹ̀ tó. Bíbélì sọ pé: “Kí ẹ fi kèké pín ilẹ̀ náà bí ohun ìní láàárín àwọn ìdílé yín. Kí ẹ fi kún ogún tí ẹ máa pín fún àwùjọ tó bá pọ̀, kí ẹ sì dín ogún tí ẹ máa pín fún àwùjọ tó bá kéré kù. Ibi tí kèké kálukú bá bọ́ sí ni ohun ìní rẹ̀ máa wà.” (Nọ 33:54) Wọn ò ní yí ibi tí kèké bá mú fún ẹ̀yà kan pa dà, àmọ́ wọ́n lè dín bó ṣe tóbi tó kù tàbí kí wọ́n fi kún un. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí wọ́n rí i pé ibi tí wọ́n pín fún ẹ̀yà Júdà ti fẹ̀ jù, wọ́n dín in kù, wọ́n sì fún ẹ̀yà Síméónì ní díẹ̀ lára rẹ̀.—Joṣ 19:9.