ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • th ẹ̀kọ́ 8 ojú ìwé 11
  • Àpèjúwe Tó Ń Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àpèjúwe Tó Ń Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́
  • Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Kì Í Bá Wọn Sọ̀rọ̀ Láìsí Àpèjúwe”
    “Máa Tọ̀ Mí Lẹ́yìn”
  • “Kì í Bá Wọn Sọ̀rọ̀ Láìsí Àpèjúwe”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Máa Lo Ìjìnlẹ̀ Òye Àti Ìyíniléròpadà Nígbà Tóo Bá Ń Kọ́ni
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Máa Fara Wé Olùkọ́ Ńlá Náà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
Àwọn Míì
Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
th ẹ̀kọ́ 8 ojú ìwé 11

Ẹ̀KỌ́ 8

Àpèjúwe Tó Ń Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́

Ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí

Mátíù 13:34, 35

KÓKÓ PÀTÀKÌ: Mú kí ọ̀nà tó ò ń gbà kọ́ni dára sí i nípa lílo àwọn àpèjúwe tó rọrùn, tó máa mú kí àwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ rẹ, tó sì máa jẹ́ kí wọ́n rí ẹ̀kọ́ pàtàkì kọ́.

BÓ O ṢE LÈ ṢE É:

  • Lo àpèjúwe tó rọrùn. Tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, máa fi àwọn nǹkan kéékèèké ṣàlàyé àwọn nǹkan ńlá, kó o sì máa fi àwọn nǹkan tó rọrùn ṣàlàyé àwọn nǹkan tó le. Má ṣe àlàyé tí kò pọn dandan nínú àpèjúwe rẹ, kí àpèjúwe náà má bàa lọ́jú pọ̀. Kí àpèjúwe rẹ lè bọ́gbọ́n mu, kó sì ṣe kedere lọ́kàn àwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀, rí i dájú pé ó bá ohun tó o fẹ́ kọ́ wọn mu dáadáa.

    Àwọn àbá

    Jẹ́ ẹni tó lákìíyèsí. Máa ṣàkíyèsí àwọn nǹkan tó wà láyìíká rẹ, máa ka àwọn ìtẹ̀jáde wa, kó o sì máa fetí sí àwọn olùkọ́ tó dáńtọ́. Bó o ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀, máa kíyè sí àwọn àpèjúwe tó o lè fi kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà tó dára sí i, kó o sì tọ́jú wọn pa mọ́ síbì kan.

  • Máa ronú nípa àwọn tó o fẹ́ bá sọ̀rọ̀. Lo àwọn àpèjúwe tí kò ní ṣàjèjì sí àwọn tó o fẹ́ bá sọ̀rọ̀, tó sì bá ohun tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí mu.

  • Àwọn kókó pàtàkì ni kó o pàfíyèsí sí. Àwọn kókó pàtàkì ni kó o fi àlàyé rẹ gbé yọ, kì í ṣe àwọn tí kò pọn dandan. Fi sọ́kàn pé kò yẹ kó jẹ́ àpèjúwe rẹ nìkan ni àwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀ máa rántí, wọ́n tún gbọ́dọ̀ rántí ohun tí wọ́n kọ́ látinú rẹ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́