Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
JANUARY 10-16
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÀWỌN ONÍDÀÁJỌ́ 17-19
“Téèyàn Bá Rú Òfin Ọlọ́run, Àbájáde Ẹ̀ Kì Í Dáa”
it-2 390-391
Míkà
1. Ọkùnrin kan láti ẹ̀yà Éfúrémù. Míkà rú òfin kẹjọ nínú Òfin Mẹ́wàá náà (Ẹk 20:15), ó jí ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún (1,100) ẹyọ fàdákà nínú owó ìyá rẹ̀. Lẹ́yìn tó jẹ́wọ́, tó sì dá owó náà pa dà, ìyá rẹ̀ sọ pé: “Ó dájú pé màá ya fàdákà náà sí mímọ́ fún Jèhófà látọwọ́ mi, kí ọmọ mi lè fi ṣe ère gbígbẹ́ àti ère onírin. Mo fún ọ pa dà báyìí.” Ìyá rẹ̀ wá mú igba (200) ẹyọ fàdákà, ó sì fún alágbẹ̀dẹ fàdákà kó lè ṣe “ère gbígbẹ́ àti ère onírin,” wọ́n sì gbé e sínú ilé Míkà. Míkà ní “ilé kan tó kó àwọn ọlọ́run rẹ̀ sí,” ó ṣe éfódì kan àti àwọn ère tẹ́ráfímù, ó sì yan ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀ pé kó jẹ́ àlùfáà rẹ̀. Míkà ronú pé òun fi nǹkan tóun ṣe yìí fògo fún Jèhófà, àmọ́ ohun tó ṣe yẹn burú jáì torí pé ó lòdì sí àṣẹ tí Ọlọ́run pa nípa ìbọ̀rìṣà, (Ẹk 20:4-6) bákan náà, kò tẹ̀ lé ètò tí Jèhófà ṣe fún ìjọsìn. (Ond 17:1-6; Di 12:1-14) Nígbà tó yá, Míkà mú Jónátánì tó jẹ́ àtọmọdọ́mọ Gẹ́ṣómù ọmọ Mósè wá sínú ilé rẹ̀, ó sì ní kó máa ṣiṣẹ́ àlùfáà fún òun. (Ond 18:4, 30) Míkà ronú pé inú Jèhófà máa dùn sí òun, ó wá sọ pé: “Mo ti wá mọ̀ báyìí pé Jèhófà máa ṣe rere sí mi.” (Ond 17:7-13) Àmọ́ Jónátánì ò lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣiṣẹ́ àlùfáà torí pé kì í ṣe àtọmọdọmọ Áárónì, ìyẹn sì tún dákún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.—Nọ 3:10.
it-2 391 ¶2
Míkà
Kò pẹ́ sígbà yẹn, Míkà àtàwọn ọkùnrin ẹ̀ lé àwọn ọmọ Dánì bá. Nígbà tí wọ́n bá wọn, àwọn ọmọ Dánì bi Míkà pé kí ló ṣẹlẹ̀? Míkà sọ pé: “Ẹ ti kó àwọn ọlọ́run mi tí mo ṣe, ẹ tún mú àlùfáà lọ. Kí ló kù tí mo ní?” Àwọn ọmọ Dánì wá kìlọ̀ fún un pé tí ò bá pa dà lẹ́yìn àwọn, àwọn máa gbéjà kò ó. Nígbà tí Míkà rí i pé àwọn ọmọ Dánì lágbára ju òun lọ, ó pa dà sílé. (Ond 18:22-26) Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Dánì ṣá àwọn tó ń gbé ní Láíṣì balẹ̀, wọ́n dáná sun ìlú wọn, wọn sì kọ́ ìlú Dánì síbẹ̀. Jónátánì àtàwọn ọmọ rẹ̀ wá di àlùfáà fáwọn ọmọ Dánì, àwọn ọmọ Dánì “gbé ère gbígbẹ́ tí Míkà ṣe kalẹ̀, ó sì wà níbẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ tí ilé Ọlọ́run tòótọ́ [àgọ́ ìjọsìn] fi wà ní Ṣílò.”—Ond 18:27-31.
FEBRUARY 21-27
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 1 SÁMÚẸ́LÌ 6-8
“Ta Ni Ọba Rẹ?”
it-2 163 ¶1
Ìjọba Ọlọ́run
Wọ́n Fẹ́ Kéèyàn Máa Ṣàkóso Wọn. Ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) ọdún lẹ́yìn táwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Íjíbítì, ìyẹn ní ohun tó lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ (800) ọdún lẹ́yìn tí Ọlọ́run bá Ábúráhámù dá májẹ̀mú, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ pé àwọn fẹ́ kí ọba máa ṣàkóso àwọn bíi tàwọn orílẹ̀-èdè míì. Bí wọ́n ṣe béèrè fún ọba yẹn fi hàn pé wọ́n kọ Jèhófà ní ọba wọn. (1Sa 8:4-8) Lóòótọ́, àwọn èèyàn náà gbà pé Ọlọ́run máa gbé Ìjọba kan kalẹ̀ bó ṣe ṣèlérí fún Ábúráhámù àti Jékọ́bù. Ìlérí yìí ṣe kedere nínú àsọtẹ́lẹ̀ tí Jékọ́bù sọ nípa Júdà kó tó kú (Jẹ 49:8-10), ó tún hàn nínú ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì lẹ́yìn tí wọ́n kúrò ní Íjíbítì (Ẹk 19:3-6), àti nínú májẹ̀mú Òfin (Di 17:14, 15), kódà ó hàn nínú ọ̀rọ̀ tí Jèhófà mú kí wòlíì Báláámù sọ (Nọ 24:2-7, 17). Àdúrà tí Hánà ìyá Sámúẹ́lì gbà fi hàn pé ó nígbàgbọ́ nínú ìlérí yìí. (1Sa 2:7-10) Síbẹ̀, Jèhófà ò tíì ṣí “àṣírí mímọ́” nípa Ìjọba náà payá nígbà yẹn. Kò tíì sọ ìgbà tó máa bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso, bí Ìjọba náà ṣe máa rí àti bóyá ọ̀run tàbí ayé ni Ìjọba náà á ti máa ṣàkóso. Torí náà, ìkọjá àyè gbáà ló jẹ́ fáwọn èèyàn náà láti béèrè fún ọba.