ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • rr ojú ìwé 212
  • Bí Wọ́n Ṣe Pín Ilẹ̀ Náà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bí Wọ́n Ṣe Pín Ilẹ̀ Náà
  • Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àyè àti iṣẹ́ tó ṣeyebíye
  • Wọ́n pín in lọ́gbọọgba
  • “Pín Ilẹ̀ Náà Bí Ogún”
    Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
  • “Fi Ọkàn-àyà Rẹ Sí” Tẹ́ńpìlì Ọlọ́run!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • “Orúkọ Ìlú Náà Yóò Máa Jẹ́ Jèhófà Wà Níbẹ̀”
    Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
  • “Tẹ́ńpìlì Náà” Àti “Ìjòyè Náà” Lónìí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
Àwọn Míì
Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
rr ojú ìwé 212
Ọkùnrin tó ní ìrísí bàbà ń fi ilẹ̀ táwọn èèyàn Ọlọ́run máa jogún han Ìsíkíẹ́lì.

ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 20A

Bí Wọ́n Ṣe Pín Ilẹ̀ Náà

Kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé tí Ọlọ́run ṣe nípa àwọn ààlà ilẹ̀ tí ìwọ̀n rẹ̀ ṣe pàtó fi àwọn tó wà nígbèkùn lọ́kàn balẹ̀ pé wọ́n máa gba ilẹ̀ tí wọ́n fẹ́ràn pa dà. Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nínú ìran yẹn lónìí? Ẹ jẹ́ ká gbé apá méjì lára ìran náà yẹ̀ wò:

Àwòrán ilẹ̀ tí Ìsíkíẹ́lì ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀, tó jẹ́ ká rí ààlà ilẹ̀ tí wọ́n pín fún àwọn tó pa dà dé láti ìgbèkùn. Ilẹ̀ tí wọ́n pín lọ́gbọọgba fún ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan jẹ́ láti àríwá dé gúúsù bẹ̀rẹ̀ látọ̀dọ̀ Dánì, Áṣérì, Náfútálì, Mánásè, Éfúrémù, Rúbẹ́nì, Júdà, Ọrẹ (ìyẹn ibi tó wà fún iṣẹ́ àbójútó), Bẹ́ńjámínì, Síméónì, Ísákà, Sébúlúnì títí dé ti Gádì.

Àyè àti iṣẹ́ tó ṣeyebíye

Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn tó pa dà láti ìgbèkùn ló máa ní ogún tiẹ̀ nínú Ilẹ̀ Ìlérí tó pa dà bọ̀ sípò. Bákan náà ló rí lónìí, gbogbo ìránṣẹ́ Jèhófà ló ní àyè tiẹ̀ nínú párádísè tẹ̀mí. Bó ṣe wù kí ipa tá à ń kó rẹlẹ̀ tó nínú ètò Ọlọ́run, a ní àyè tó fini lọ́kàn balẹ̀, a sì ní iṣẹ́ tó ṣeyebíye láti ṣe lórí ilẹ̀ tẹ̀mí. Lójú Jèhófà, gbogbo ìránṣẹ́ rẹ̀ ló ṣeyebíye bákan náà.

Wọ́n pín in lọ́gbọọgba

Nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí, gbogbo àwọn tó ń gbé agbègbè kọ̀ọ̀kan nínú Ilẹ̀ Ìlérí tó pa dà bọ̀ sípò jọ máa nípìn-ín nínú ọ̀pọ̀ rẹ̀pẹ̀tẹ̀ ohun rere tó wà nílẹ̀ náà. Bó ṣe rí lónìí náà nìyẹn, Jèhófà ti fún gbogbo ìránṣẹ́ rẹ̀ ní ìbùkún tó dọ́gba nínú párádísè tẹ̀mí.

Pa dà sí orí 20, ìpínrọ̀ 5 sí 11

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́