Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
MARCH 14-20
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 1 SÁMÚẸ́LÌ 14-15
“Ìgbọràn Sàn Ju Ẹbọ Lọ”
it-2 521 ¶2
Ìgbọràn
A ò lè rí ojú rere Ọlọ́run tá ò bá ṣègbọràn sí i. Sámúẹ́lì sọ fún Ọba Sọ́ọ̀lù pé: “Ṣé àwọn ẹbọ sísun àti ẹbọ máa ń múnú Jèhófà dùn tó kéèyàn ṣègbọràn [ìyẹn sha·maʽʹ] sí ohùn Jèhófà? Wò ó! Ṣíṣe ìgbọràn sàn ju ẹbọ, fífi etí sílẹ̀ sì sàn ju ọ̀rá àgbò.” (1Sa 15:22) Tẹ́nì kan bá ṣàìgbọràn, ṣe lẹni náà kọ ọ̀rọ̀ Jèhófà, ìyẹn fi hàn pé kò nígbàgbọ́, kò sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà àti ọ̀rọ̀ rẹ̀. Torí náà, ẹni tó bá ń ṣàìgbọràn kò yàtọ̀ sí ẹni tó ń woṣẹ́ tàbí tó ń bọ̀rìṣà. (1Sa 15:23; fi wé Ro 6:16.) Tí wọ́n bá fún ẹnì kan ní ìtọ́ni, tẹ́ni náà sì gbà láti ṣe é àmọ́ tí kò ṣe é, irú ẹni bẹ́ẹ̀ fi hàn pé òun ò bọ̀wọ̀ fún ẹni tó fún un ní ìtọ́ni náà. (Mt 21:28-32) Tẹ́nì kan bá ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tó sì gbà nínú ọkàn rẹ̀ pé òótọ́ ni, àmọ́ tí kò ṣe ohun tí ọ̀rọ̀ náà sọ, ṣe ni irú ẹni bẹ́ẹ̀ ń fi èrò èké tan ara ẹ̀ jẹ, kò sì lè rí ìbùkún gbà. (Jem 1:22-25) Ọmọ Ọlórun jẹ́ kó ṣe kedere pé àwọn tó ń ṣe ohun tó fara jọ ohun tí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ, àmọ́ tó jẹ́ pé èrò tí kò dáa ló sún wọn ṣe é tàbí tí wọ́n ń ṣe é lọ́nà tí kò tọ́ kò ní rí ojú rere Jèhófà, wọn ò sì ní wọ Ìjọba Ọlọ́run.—Mt 7:15-23.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
it-1 493
Àánú
Téèyàn bá fàánú hàn sí ẹni tí kò yẹ kéèyàn fàánú hàn sí, àbájáde ẹ̀ kì í dáa. Èyí ṣe kedere nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ọba Sọ́ọ̀lù. Jèhófà pàṣẹ fún Sọ́ọ̀lù pé kó lọ pa àwọn ọmọ Ámálékì run, kò sì gbọ́dọ̀ fojú àánú hàn sí wọn. Àwọn ọmọ Ámálékì yìí ló kọ́kọ́ gbéjà ko àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láìnídìí lẹ́yìn tí wọ́n kúrò ní Íjíbítì. Àmọ́ Sọ́ọ̀lù ò ṣègbọràn délẹ̀délẹ̀ sí àṣẹ tí Jèhófà pa torí pé ó bẹ̀rù àwọn èèyàn ẹ̀. Torí náà, Jèhófà kọ Sọ́ọ̀lù ní ọba. (1Sa 15:2-24) Tá a bá mọyì àwọn ìlànà Jèhófà, tá a gbà pé ọ̀nà rẹ̀ ló tọ́, tá a sì jẹ́ adúróṣinṣin sí i ṣáájú ẹnikẹ́ni míì, a ò ní ṣàṣìṣe bíi ti Sọ́ọ̀lù, a ò sì ní pàdánù ojú rere Jèhófà.
MARCH 21-27
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
it-2 871-872
Sọ́ọ̀lù
Lẹ́yìn èyí àti lẹ́yìn tí Jèhófà fòróró yan Dáfídì láti di ọba lọ́la ni ẹ̀mí Jèhófà fi Sọ́ọ̀lù sílẹ̀. Látìgbà yẹn ni ‘Jèhófà ti jẹ́ kí ẹ̀mí búburú máa dà á láàmú.’ Bí ẹ̀mí Jèhófà ṣe fi Sọ́ọ̀lù sílẹ̀, Jèhófà fàyè gbà á kí ẹ̀mí búburú máa darí ẹ̀. Ẹ̀mí búburú yẹn ò jẹ́ kí ọkàn Sọ́ọ̀lù balẹ̀ mọ́, ìyẹn mú kó máa ronú lọ́nà tí kò tọ́, kó sì máa fura òdì. Bí Sọ́ọ̀lù ṣe ṣàìgbọràn sí Jèhófà fi hàn pé èrò burúkú ló wà lọ́kàn ẹ̀, ẹ̀mí Ọlọ́run kì í sì í dáàbò bo irú ẹni bẹ́ẹ̀. Torí náà, bí Jèhófà ṣe gba ẹ̀mí rẹ̀ lára Sọ́ọ̀lù, tó sì fàyè gba kí “ẹ̀mí búburú” máa dà á láàmú, a lè sọ pé ‘Jèhófà ló jẹ́ kí ẹ̀mí búburú náà máa dà á láàmú.’ Abájọ táwọn ìránṣẹ́ Sọ́ọ̀lù fi sọ pé: “Ọlọ́run ti ń jẹ́ kí ẹ̀mí búburú máa dà ọ́ láàmú.” Ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wá dábàá pé kí Dáfídì máa kọrin fún Sọ́ọ̀lù kí ara lè tù ú nígbàkigbà tí “ẹ̀mí búburú” náà bá ń dà á láàmú, Sọ́ọ̀lù sì gbà.—1Sa 16:14-23; 17:15.
MARCH 28–APRIL 3
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
it-2 695-696
Wòlíì
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ló fi ẹ̀mí rẹ̀ yàn wọ́n, kì í ṣe gbogbo ìgbà ni Ọlọ́run máa ń mí sí wọn láti sọ̀rọ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀mí Ọlọ́run máa ń ‘bà lé wọn’ nígbàkigbà tí Jèhófà bá fẹ́ kí wọ́n lọ jíṣẹ́ òun fáwọn èèyàn. (Isk 11:4, 5; Mik 3:8) Ẹ̀mí yìí máa ń mú kí wọ́n gbé ìgbésẹ̀, kí wọ́n sì lọ jíṣẹ́ tí Ọlọ́run rán wọn. (1Sa 10:10; Jer 20:9; Emọ 3:8) Wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ohun tó ṣàrà ọ̀tọ̀, wọ́n sì lè máa fìtara sọ̀rọ̀ tàbí kí wọ́n máa hùwà lọ́nà tó máa jọ àwọn míì lójú. Èyí jẹ́ ká lóye ìdí tí Bíbélì fi sọ pé àwọn kan ń “ṣe bíi wòlíì.” (1Sa 10:6-11; 19:20-24; Jer 29:24-32; fi wé Iṣe 2:4, 12-17; 6:15; 7:55.) Bí wọ́n ṣe máa ń fìtara àti ìgboyà jẹ́ iṣẹ́ tí Ọlọ́run rán wọn máa ń ya àwọn èèyàn lẹ́nu, kódà àwọn míì máa ń ronú pé orí wọn ti yí. Ohun tí àwọn olórí ọmọ ogun rò nípa wòlíì tó fòróró yan Jéhù nìyẹn. Àmọ́, nígbà tí wọ́n rí i pé wòlíì ni ọkùnrin náà, wọ́n fọwọ́ pàtàkì mú ohun tó sọ. (2Ọb 9:1-13; fi wé Iṣe 26:24, 25.) Nígbà tí Sọ́ọ̀lù ń lépa Dáfídì, ẹ̀mí Jèhófà mú kí Ṣọ́ọ̀lù máa ‘ṣe bíi wòlíì,’ ó wá bọ́ aṣọ rẹ̀, ó sì sùn sílẹ̀ “ní ìhòòhò ní gbogbo ọjọ́ yẹn àti ní gbogbo òru yẹn,” ìyẹn jẹ́ kí Dáfídì lè ráyè sá lọ. (1Sa 19:18–20:1) Èyí ò túmọ̀ sí pé àwọn wòlíì máa ń bọ́ra sí ìhòòhò nígbà gbogbo, àkọsílẹ̀ Bíbélì sì jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀. Ó ní ìgbà méjì míì tí Bíbélì sọ pé àwọn wòlíì wà ní ìhòòhò, àmọ́ ìdí tí wọ́n fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé wọ́n ń ṣàpẹẹrẹ àsọtẹ́lẹ̀ tí Ọlọ́run gbẹnu wọn sọ. (Ais 20:2-4; Mik 1:8-11) Bíbélì ò sọ ìdí tí Jèhófà fi jẹ́ kí Sọ́ọ̀lù dùbúlẹ̀ ní ìhòòhò, bóyá torí kí Sọ́ọ̀lù lè mọ̀ pé èèyàn lásán lòun, àti pé òun ò já mọ́ nǹkan kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run tàbí torí ìdí míì, a ò lè sọ.