Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
JULY 11-17
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 2 SÁMÚẸ́LÌ 20-21
“Ọlọ́run Onídàájọ́ Òdodo Ni Jèhófà”
it-1 932 ¶1
Gíbéónì
Àwọn ará Gíbéónì àtijọ́ ti wà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọba Sọ́ọ̀lù gbìyànjú láti pa wọ́n run. Àmọ́, àwọn ará Gíbéónì fi sùúrù dúró dìgbà tí Jèhófà dá sí ọ̀rọ̀ náà. Jèhófà sì ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tó jẹ́ kí ìyàn mú fún ọdún mẹ́ta nígbà ìṣàkóso Dáfídì. Nígbà tí Dáfídì ṣèwádìí lọ́dọ̀ Jèhófà, ó wá rí i pé ọ̀rọ̀ náà ní í ṣe pẹ̀lú ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀, torí náà ó béèrè lọ́wọ́ àwọn ará Gíbéónì nípa nǹkan tí òun lè ṣe láti yanjú ọ̀rọ̀ náà. Àwọn ará Gíbéónì wá sọ pé ọ̀rọ̀ náà kì í ṣe “ọ̀rọ̀ fàdákà tàbí wúrà,” torí ohun tí òfin sọ ni pé, a ò gbọ́dọ̀ gba ìràpadà fún ẹni tó bá pààyàn. (Nọ 35:30, 31) Wọ́n tún gbà pé àwọn ò lè pa ẹnì kan láìjẹ́ pé wọ́n gbàṣẹ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Torí náà, Dáfídì ní kí wọ́n béèrè ohun tí wọ́n bá fẹ́, àwọn ará Gíbéónì sì ní kí Dáfídì fáwọn ní méje lára “àwọn ọmọkùnrin” Sọ́ọ̀lù. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Sọ́ọ̀lù ló ṣètò láti pa àwọn ará Gíbéónì, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé “àwọn ọmọkùnrin” rẹ̀ lọ́wọ́ sí i lọ́nà kan tàbí òmíì, ìdí nìyẹn tí ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ fi wà lórí Sọ́ọ̀lù àti agbo ilé rẹ̀. (2Sa 21:1-9) Ìyẹn fi hàn pé ìdájọ́ yẹn kì í ṣe ọ̀rọ̀ pé káwọn ọmọ kú torí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn bàbá (Di 24:16) àmọ́, ó wà ní ìbámu pẹ̀lú òfin Ọlọ́run tó sọ pé “kí o gba ẹ̀mí dípò ẹ̀mí.”—Di 19:21.
JULY 25-31
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 2 SÁMÚẸ́LÌ 23-24
“Kí Lo Máa Yááfì fún Jèhófà?”
it-1 146
Áráúnà
Ó jọ pé Áráúnà fún Dáfídì ní ilẹ̀ yẹn, títí kan màlúù àtàwọn igi tó máa fi rúbọ láìgba owó lọ́wọ́ rẹ̀, àmọ́ Dáfídì sọ fún un pé òun gbọ́dọ̀ rà á lọ́wọ́ ẹ̀. Bíbélì sọ nínú 2 Sámúẹ́lì 24:24 pé Dáfídì ra ibi ìpakà náà àti màlúù náà ní àádọ́ta (50) ṣékélì fàdákà ($110). Àmọ́, ohun tí 1 Kíróníkà 21:25 sọ ni pé Dáfídì san ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) ṣékélì wúrà (c. $77,000) fún ilẹ̀ náà. Ẹni tó kọ Sámúẹ́lì Kejì kàn sọ̀rọ̀ nípa ilẹ̀ kékeré tí Dáfídì fi kọ́ pẹpẹ àtàwọn nǹkan míì tó fi rúbọ, ó sì jọ pé àwọn nǹkan yìí nìkan ni Dáfídì san owó yẹn fún. Àmọ́, ẹni tó kọ ìwé Kíróníkà Kìíní sọ̀rọ̀ nípa tẹ́ńpìlì tí wọ́n kọ́ sórí ilẹ̀ yẹn nígbà tó yá, ó sì sọ̀rọ̀ nípa owó gbogbo ilẹ̀ tí wọ́n kọ́ tẹ́ńpìlì yẹn sí. (1Kr 22:1-6; 2Kr 3:1) Ilẹ̀ tí wọ́n kọ́ tẹ́ńpìlì náà sí tóbi gan-an, torí náà ó jọ pé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) ṣékélì wúrà yẹn ni Dáfídì san fún gbogbo ilẹ̀ yẹn, dípò ilẹ̀ kékeré tó kọ́ pẹpẹ náà sí.
AUGUST 1-7
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 1 ÀWỌN ỌBA 1-2
“Ṣé O Máa Ń Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Àṣìṣe Ẹ?”
it-2 987 ¶4
Sólómọ́nì
Nígbà tí Ádóníjà àtàwọn ọlọ̀tẹ̀ tó kù gbọ́ ohùn orin ní Gíhónì tí ò fi bẹ́ẹ̀ jìnnà sí ibi tí wọ́n wà, tí wọ́n sì gbọ́ táwọn èèyàn ń kígbe pé: “Kí ẹ̀mí Ọba Sólómọ́nì gùn o,” ṣe lẹ̀rù bà wọ́n, wọ́n sì sá lọ. Bí Sólómọ́nì ò ṣe gbẹ̀san lára Ádóníjà nígbà tó gorí ìtẹ́ fi hàn pé àlàáfíà máa wà nígbà ìṣàkóso rẹ̀. Torí ká sọ pé Ádóníjà ló di ọba, ì bá ti pa Sólómọ́nì. Ádóníjà sá lọ sí àgọ́ ìjọsìn ó sì fara pa mọ́ síbẹ̀. Torí náà Sólómọ́nì ní kí wọ́n lọ mú Ádóníjà wá sọ́dọ̀ òun, ó sì sọ fún un pé tí kò bá hùwà burúkú èyíkéyìí, òun ò ní pa á. Lẹ́yìn náà, Sólómọ́nì ní kó máa lọ sílé rẹ̀ ní àlàáfíà.—1Ọb 1:41-53.
it-1 49
Ádóníjà
Àmọ́ lẹ́yìn tí Dáfídì kú, Ádóníjà lọ bá Bátí-ṣébà ó sì sọ fún un pé kó lọ bá òun bá Sólómọ́nì pé kó jẹ́ kóun fẹ́ Ábíṣágì tó ń tọ́jú Dáfídì tó sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún un. Bí Ádóníjà ṣe sọ pé “èmi ni ọba tọ́ sí, gbogbo Ísírẹ́lì sì ń retí pé màá di ọba” fi hàn pé inú ẹ̀ ò dùn pé àǹfààní àtidi ọba bọ́ mọ́ òun lọ́wọ́, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó sọ pé Jèhófà lọ́wọ́ sí ọ̀rọ̀ náà. (1Ọb 2:13-21) Lóòótọ́, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìdí tó fi béèrè fún Ábíṣágì ni pé ó fẹ́ fi dí àǹfààní tó bọ́ mọ́ òun lọ́wọ́, àmọ́ ó tún fi hàn pé ó ṣì ń wá bó ṣe máa di ọba. Torí pé nínú òfin àwọn tó ń gbé ní Ìlà Oòrùn láyé àtijọ́, àwọn ìyàwó ọba àtàwọn wáhàrí rẹ̀ máa di ti ẹni tó bá rọ́pò ẹ̀. (Fi wé 2Sa 3:7; 16:21.) Sólómọ́nì ka ìbéèrè Ádóníjà sí àǹfààní láti gba ìjọba mọ́ òun lọ́wọ́ torí náà ó pàṣẹ pé kí wọ́n lọ pa á, Bẹnáyà sì ṣe bẹ́ẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.—1Ọb 2:22-25.
AUGUST 15-21
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 1 ÀWỌN ỌBA 5-6
“Wọ́n Fi Gbogbo Ọkàn sí Iṣẹ́ Ilé Náà”
it-1 424
Kédárì
Torí pé àwọn igi Kédárì tí wọ́n lò pọ̀ gan-an, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn òṣìṣẹ́ ni wọ́n máa ń ní láti lò. Lára àwọn iṣẹ́ tí wọ́n máa ṣe ni pé wọ́n máa gé àwọn igi, wọ́n á fi wọ́n ránṣẹ́ sí Tírè tàbí Sídónì tó wà ní etíkun Mẹditaréníà, wọ́n á dì wọ́n pọ̀ kó lè léfòó lórí omi, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Jópà ni wọ́n á fi ránṣẹ́ sí. Àtibẹ̀ ni wọ́n á ti kó o lọ sí Jerúsálẹ́mù. Hírámù ni Sólómọ́nì sì gbéṣẹ́ yìí fún. (1Ọb 5:6-18; 2Kr 2:3-10) Lẹ́yìn ìgbà yẹn wọ́n ṣì máa ń kó àwọn igi yìí wọ Jerúsálẹ́mù nígbà ìṣàkóso Sólómọ́nì, abájọ tí Bíbélì fi sọ pé Sólómọ́nì mú kí ‘igi kédárì pọ̀ rẹpẹtẹ bí àwọn igi síkámórè.’—1Ọb 10:27; fi wé Ais 9:9, 10.
it-2 1077 ¶1
Tẹ́ńpìlì
Sólómọ́nì ní káwọn ọkùnrin ọ̀kẹ́ kan ààbọ̀ (30,000) láti gbogbo Ísírẹ́lì máa ṣiṣẹ́ fún òun, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) lára wọn ló máa ń rán lọ sí Lẹ́bánónì lóṣooṣù, wọ́n á lo oṣù kan ní Lẹ́bánónì, wọ́n á sì lo oṣù méjì ní ilé wọn. (1Ọb 5:13, 14) Sólómọ́nì yan ọ̀kẹ́ mẹ́ta ààbọ̀ (70,000) ọkùnrin lára àwọn tó jẹ́ àjèjì láti ṣe lébìrà, ó sì yan ọ̀kẹ́ mẹ́rin (80,000) láti máa gé òkúta. (1Ọb 5:15; 9:20, 21; 2Kr 2:2) Sólómọ́nì yan ọgọ́rùn-ún márùn-ún ó lé àádọ́ta (550) ọkùnrin láti máa bójú tó iṣẹ́ náà, ó sì yan ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (3,300) láti máa ran àwọn alábòójútó yìí lọ́wọ́. (1Ọb 5:16; 9:22, 23) Ó jọ pé ọgọ́rùn-ún méjì ààbọ̀ (250) lára wọn jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì, nígbà tí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (3,600) jẹ́ “àjèjì” ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì.—2Kr 2:17, 18.
g 5/12 17, àpótí
Àwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì Péye, Apá 1
ÀKỌSÍLẸ̀ TÓ PÉYE NÍPA ÌGBÀ TÍ ÌṢẸ̀LẸ̀ KAN WÁYÉ
Àpẹẹrẹ ìgbà kan tí Bíbélì ṣàkọsílẹ̀ ìgbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ kan wáyé lọ́nà tó péye wà nínú 1 Àwọn Ọba 6:1, ìyẹn ìgbà tí Ọba Sólómọ́nì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù. Ó kà pé: “Ní ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé ọgọ́rin (480) ọdún [ìyẹn 479 ọdún] lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, ní ọdún kẹrin lẹ́yìn tí Sólómọ́nì di ọba lórí Ísírẹ́lì, ní oṣù Sífì (ìyẹn, oṣù kejì), ó bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ilé Jèhófà.”
Àkọsílẹ̀ ìtàn inú Bíbélì fi hàn pé ọdún kẹrin ìṣàkóso Sólómọ́nì bọ́ sí 1034 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Tá a bá wá ka 479 ọdún láti 1034 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni pa dà sẹ́yìn, á mú wa dé ọdún 1513 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni táwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò lóko ẹrú Íjíbítì.
AUGUST 22-28
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 1 ÀWỌN ỌBA 7
“Ohun Tá A Rí Kọ́ Lára Òpó Méjì”
it-1 348
Bóásì, II
Bóásì ni orúkọ èyí tó kángun sápá àríwá lára òpó bàbà ńlá méjì tí wọ́n gbé sí ibi àbáwọlé tẹ́ńpìlì tí Sólómọ́nì kọ́. Ó ṣeé ṣe kí orúkọ náà túmọ̀ sí “Nínú Okun.” Jákínì lorúkọ èyí tó wà ní apá gúúsù. Orúkọ náà túmọ̀ sí “Kí [Jèhófà] Fìdí Rẹ̀ Múlẹ̀ Gbọn-in.” Torí náà, tá a bá ka ohun tí òpó méjèèjì túmọ̀ sí láti apá gúúsù sí apá àríwá, èrò tó máa gbé síni lọ́kàn ni ‘Kí [Jèhófà] Fìdí [tẹ́ńpìlì náà] Múlẹ̀ Gbọn-in Nínú Okun.’—1Ọb 7:15-21; wo ỌPỌ́N.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
it-1 263
Ìwẹ̀
Ó ṣe pàtàkì kí àwọn tó ń jọ́sìn Jèhófà wà ní mímọ́ nípa tara. Èyí hàn gbangba nínú ètò tí wọ́n ṣe fún àwọn àlùfáà àtàwọn ọmọ léfì nínú àgọ́ ìjọsìn àti nínú tẹ́ńpìlì. Nígbà tí wọ́n yan Áárónì àlùfáà àgbà àtàwọn ọmọ rẹ̀, ṣe ni wọ́n kọ́kọ́ wẹ̀ wọ́n kí wọ́n tó wọ ẹ̀wù àlùfáà fún wọn. (Ẹk 29:4-9; 40:12-15; Le 8:6, 7) Omi tó wà nínú bàsíà tí wọ́n fi bàbà ṣe nínú àgbàlá àgọ́ ìjọsìn ni àwọn àlùfáà fi máa ń fọ ọwọ́ àti ẹsẹ̀ wọn. Nígbà tó yá, omi tó wà nínú Òkun tí wọ́n fi irin ṣe nínú tẹ́ńpìlì Sólómọ́nì ni wọ́n máa ń lò. (Ẹk 30:18-21; 40:30-32; 2Kr 4:2-6) Ẹ̀ẹ̀mejì ni àlùfáà àgbà máa wẹ̀ lọ́jọ́ tí wọ́n bá yàn án sípò. (Le 16:4, 23, 24) Àwọn tó bá rán ewúrẹ́ lọ fún Ásásélì àtàwọn tó kó ìdọ̀tí ẹran tí wọ́n fi rúbọ títí kan ti màlúù tí wọ́n fi rúbọ ní ẹ̀yìn ibùdó gbọ́dọ̀ wẹ ara wọn, kí wọ́n sì fọ aṣọ wọn kí wọ́n tó pa dà sínú ibùdó.—Le 16:26-28; Nọ 19:2-10.
AUGUST 29–SEPTEMBER 4
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 1 ÀWỌN ỌBA 8
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
it-1 1060 ¶4
Ọ̀run
Sólómọ́nì tó kọ́ tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù sọ pé “ọ̀run, àní, ọ̀run àwọn ọ̀run” kò lè gba Ọlọ́run. (1Ọb 8:27) Jèhófà ló dá ọ̀run, torí náà, ipò rẹ̀ ga fíofío ju gbogbo ọ̀run lọ, kódà “orúkọ rẹ̀ nìkan ṣoṣo ló ga kọjá ibi tó ṣeé dé. Iyì rẹ̀ ga ju ayé àti ọ̀run lọ.” (Sm 148:13) Jèhófà fi ìbú àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ wọn ọ̀run. Lójú rẹ̀, gbogbo ọ̀run ò ju àlàfo tó wà láàárín orí àtàǹpàkò àti ìka tó kéré jù téèyàn bá yàka. (Ais 40:12) Ohun tí Sólómọ́nì sọ kò túmọ̀ sí pé Ọlọ́run kò níbi pàtó kan tó ń gbé, kò sì túmọ̀ sí pé ibi gbogbo ni Ọlọ́run wà. Èyí ṣe kedere nínú ọ̀rọ̀ tí Sólómọ́nì tún sọ pé kí Jèhófà gbọ́ àdúrà wọn ‘láti ọ̀run, ibi tó ń gbé,’ ìyẹn ọ̀run níbi táwọn ẹ̀mí wà.—1Ọb 8:30, 39.