Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
NOVEMBER 7-13
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 2 ÀWỌN ỌBA 5-6
“Àwọn Tó Wà Pẹ̀lú Wa Pọ̀ Ju Àwọn Tó Wà Pẹ̀lú Wọn”
it-1 716 ¶4
Èlíṣà
Jèhófà Gba Ísírẹ́lì Sílẹ̀ Lọ́wọ́ Síríà. Lásìkò tí Ọba Jèhórámù ń ṣàkóso ilẹ̀ Ísírẹ́lì, àwọn ọmọ ogun Síríà ṣètò bí wọ́n á ṣe gbéjà ko àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láìfura. Àmọ́ gbogbo ọgbọ́n tí Bẹni-hádádì Kejì ọba Síríà dá ò ṣiṣẹ́ torí pé Èlíṣà ń sọ gbogbo ohun táwọn ọmọ ogun Síríà fẹ́ ṣe fún Ọba Jèhórámù. Bẹni-hádádì kọ́kọ́ rò pé ọ̀dàlẹ̀ kan tó wà lára àwọn ọmọ ogun òun ló ń fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́wọ́, àmọ́ nígbà tó yá, ó rí i pé Èlíṣà ló ń tú àṣírí òun. Ó wá rán àwọn agẹṣinjagun àtàwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun lọ sí Dótánì kí wọ́n lè lọ mú Èlíṣà. Àwọn ọmọ ogun náà sì yí ìlú náà ká. (ÀWÒRÁN, Ìdìpọ̀ 1, ojú ìwé 950) Nígbà tí ìránṣẹ́ Èlíṣà rí àwọn ọmọ ogun yìí, ẹ̀rù bà á. Èlíṣà wá bẹ Ọlọ́run pé kó la ojú ìránṣẹ́ rẹ̀, ìránṣẹ́ náà sì rí i pé “àwọn ẹṣin àti àwọn kẹ̀kẹ́ ogun oníná kún agbègbè olókè náà, wọ́n sì yí Èlíṣà ká.” Bí àwọn ọmọ ogun Síríà ṣe túbọ̀ sún mọ́ ìlú náà, Èlíṣà gbàdúrà pé, “Jọ̀ọ́, bu ìfọ́jú lu orílẹ̀-èdè yìí.” Ó wá sọ fáwọn ọmọ ogun náà pé, “Ẹ tẹ̀ lé mi.” Èlíṣà ò dì wọ́n lọ́wọ́ mu, tó fi hàn pé kì í ṣe pé ojú wọn fọ́ ní tààràtà, àmọ́ ó jọ pé iyè wọn rá. Wọn ò mọ̀ pé Èlíṣà táwọn fẹ́ wá mú ló wá bá àwọn, wọn ò sì mọ ibi tó ń mú wọn lọ.—2Ọb 6:8-19.
it-1 343 ¶1
Ìfọ́jú
Bí Èlíṣà ṣe sọ pé kí Jèhófà bu ìfọ́jú lu àwọn ọmọ ogun Síríà, kì í ṣe pé ojú wọn fọ́ ní tààràtà, àmọ́ ṣe ni iyè wọn rá. Ká sọ pé ojú gbogbo wọn ló fọ́, á jẹ́ pé wọ́n á di gbogbo wọn lọ́wọ́ mu, àmọ́ àkọsílẹ̀ náà sọ pé Èlíṣà sọ fún wọn pé: “Ibí kọ́ ni ọ̀nà, ibí kọ́ sì ni ìlú náà. Ẹ tẹ̀ lé mi.” Nígbà tí William James ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí, ó sọ nínú ìwé rẹ̀ tó pè ní Principles of Psychology (1981, Ìdìpọ̀ 1, ojú ìwé 59) pé: “Àrùn ọpọlọ kan wà tí wọ́n ń pè ní cortical disorder tó máa ń mú kí iyè ẹni rá. Ẹni tó bá ní àrùn yìí máa ríran, àmọ́ ọpọlọ ẹ̀ kò ní lè lóyè tàbí kó ṣàlàyé ohun tí ojú náà rí. Lédè míì, ṣe ló dà bí ìgbà tí ohun tó ń gbé ìsọfúnni látinú ojú lọ sí ọpọlọ ò ṣiṣẹ́ mọ́. Lára ohun tó lè fa àìsan yìí ni tí nǹkan kan bá ṣẹlẹ̀ sí iṣan tó ń gbé ìsọfúnni láti ojú lọ sí ọpọlọ.” Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ ogun Síríà nìyẹn, Jèhófà sì mú ìfọ́jú yìí kúrò nígbà tí wọ́n dé Samáríà. (2Ọb 6:18-20) Bákan náà, ó lè jẹ́ pé ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ọkùnrin Sódómù náà nìyẹn nígbà táwọn áńgẹ́lì bu ìfọ́jú lù wọ́n, torí Bíbélì ò sọ pé wọn ò ríran rárá, dípò bẹ́ẹ̀ ó sọ pé ó rẹ̀ wọ́n bí wọ́n ṣe ń wá ibi tí ẹnu ọ̀nà wà.—Jẹ 19:11.
NOVEMBER 14-20
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 2 ÀWỌN ỌBA 7-8
“Jèhófà Ṣe Ohun Tó Dà Bíi Pé Kò Ṣeé Ṣe”
it-1 716-717
Èlíṣà
Nígbà tó yá, Ọba Bẹni-hádádì Kejì kó gbogbo ọmọ ogun rẹ̀ jọ, ó sì dó ti ìlú Samáríà. Nǹkan le gan-an débi pé wọ́n ròyìn fún ọba nípa obìnrin kan tó se ọmọ ẹ̀ jẹ. Ọba Jèhórámù tí Bíbélì pè ní “ọmọ apààyàn” torí pé ó jẹ́ ọmọ Áhábù wá búra pé òun á pa Èlíṣà, àmọ́ kò ṣe bẹ́ẹ̀. Jèhórámù àti olùrànlọ́wọ́ ọ̀gágun rẹ̀ lọ sílé Èlíṣà, Jèhórámù sì sọ pé òun ò rò pé Jèhófà lè ran àwọn lọ́wọ́. Èlíṣà wá fi ọba náà lọ́kàn balẹ̀ pé oúnjẹ máa pọ̀ rẹpẹtẹ lọ́jọ́ kejì. Àmọ́ olùrànlọ́wọ́ ọ̀gágun náà bẹnu àtẹ́ lu Èlíṣà, ìyẹn mú kí Èlíṣà sọ fún un pé: “Wàá fi ojú ara rẹ rí i, ṣùgbọ́n o ò ní jẹ nínú rẹ̀.” Jèhófà mú káwọn ọmọ ogun Síríà máa gbọ́ ìró àwọn kẹ̀kẹ́ ogun àtàwọn àwọn ẹṣin, ìyẹn sì mú káwọn ọmọ Síríà náà rò pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ ogun tó para pọ̀ fẹ́ gbéjà ko àwọn. Ni wọ́n bá sá kúrò ní ibùdó wọn, wọn sì fi gbogbo oúnjẹ wọn sílẹ̀ níbẹ̀. Nígbà tí Jèhórámù gbọ́ pé àwọn ọmọ ogun Síríà ti sá lọ, ó ní kí olùrànlọ́wọ́ ọ̀gágun náà máa ṣọ́ ẹnubodè ìlú Samáríà. Àmọ́ nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ebi ń pa ń rọ́ jáde nílùú lọ sí ibùdó àwọn ọmọ Síríà, ṣe ni wọ́n tẹ olùrànlọ́wọ́ ọ̀gágun náà pa ní ẹnubodè. Ó rí oúnjẹ náà, ṣùgbọ́n kò jẹ nínú rẹ̀.—2Ọb 6:24–7:20.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
it-2 195 ¶7
Fìtílà
Àwọn Ọba Tó Wá Láti Ìlà Ìdílé Dáfídì. Jèhófà yan Dáfídì láti jẹ́ ọba Ísírẹ́lì. Torí pé Dáfídì máa ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Jèhófà, ìṣàkóso ẹ̀ tu àwọn èèyàn lára, ó sì darí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́nà tó tọ́. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi pè é ní “iná Ísírẹ́lì.” (2Sa 21:17) Nígbà tí Jèhófà bá Dáfídì dá májẹ̀mú Ìjọba, ó ṣèlérí fún Dáfídì pé: ‘Ìtẹ́ rẹ á fìdí múlẹ̀ títí láé.’ (2Sa 7:11-16) Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn ọba tó wá láti ìlà ìdílé Dáfídì nípasè Sólómọ́nì jẹ́ fìtílà tàbí iná Ísírẹ́lì.—1Ọb 11:36; 15:4; 2Ọb 8:19; 2Kr 21:7.
Nígbà táwọn ará Bábílónì rọ Ọba Sedekáyà lóyè, tí wọ́n sì mú un lóǹdè lọ sí Bábílónì kó lè kú síbẹ̀, ṣe ló dà bíi pé wọ́n ti pa iná tàbí fìtílà Ísírẹ́lì. Àmọ́ Jèhófà ò gbàgbé májẹ̀mú tó bá Dáfídì dá. Ṣe ló mú kí ìtẹ́ yẹn ṣófo “títí ẹni tó lẹ́tọ̀ọ́ sí i lọ́nà òfin fi máa dé.” (Isk 21:27) Jésù Kristi tó jẹ́ Mèsáyà àti “ọmọ Dáfídì” ni ẹni tó lẹ́tọ̀ọ́ láti jókòó sórí ìtẹ́ náà títí láé. Nípa bẹ́ẹ̀, kò sígbà tí ọmọ Dáfídì ò ní máa ṣàkóso. Jésù ni iná tàbí fìtílà tó ń jó títí láé, òun ló sì máa jẹ́ Ọba Ìjọba náà títí lọ fáàbàdà.—Mt 1:1; Lk 1:32.
NOVEMBER 28–DECEMBER 4
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 2 ÀWỌN ỌBA 11-12
“Jèhófà Fìyà Jẹ Obìnrin Burúkú Kan”
it-1 209
Ataláyà
Bíi ti Jésíbẹ́lì ìyà rẹ̀, Ataláyà náà mú kí Jèhórámù ọkọ rẹ̀ ṣe ohun tó burú ní ojú Jèhófà ní gbogbo ọdún mẹ́jọ tó fi jọba. (1Ọb 21:25; 2Kr 21:4-6) Ataláyà tún fìwà jọ ìyá rẹ̀ ní ti pé ọ̀pọ̀ àwọn àláìmọwọ́mẹsẹ̀ tó pa. Nígbà tí Ahasáyà ọmọ rẹ̀ tó jẹ́ ọba búburú kú lẹ́yìn ọdún kan lórí àlééfà, Ataláyà pa gbogbo àwọn ọmọ ọba àyàfi Jèhóáṣì tó jẹ́ ọmọ ọwọ́. Ìdí sì ni pé àlùfáà àgbà àti ìyàwó rẹ̀ tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n Jèhóáṣì gbé e pa mọ́. Lẹ́yìn náà, Ataláyà sọ ara ẹ̀ di ọbabìnrin, ó sì ṣàkóso fún ọdún mẹ́fà láti ọdún 905 sí ọdún 899 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni (2Kr 22:11, 12) Àwọn ọmọ rẹ̀ jí àwọn ohun mímọ́ tó wà nínú tẹ́ńpìlì Jèhófà, wọ́n sì fi rúbọ sí Báálì.—2Kr 24:7.
it-1 209
Ataláyà
Nígbà tí Jèhóáṣì pé ọmọ ọdún méje, Jèhóádà Àlùfáà Àgbà tó bẹ̀rù Ọlọ́run mú jáde káwọn èèyàn lè rí i, ó sì sọ ọ́ di ọba. Nígbà tí Ataláyà gbọ́ ariwo, ó sáré lọ sí tẹ́ńpìlì, bó sì ṣe rí ohun tó ń ṣẹlẹ̀, ó kígbe pé, “Ọ̀tẹ̀ rèé o! Ọ̀tẹ̀ rèé o!” Jèhóádà Àlùfáà Àgbà wá pàṣẹ pé kí wọ́n mú un jáde nínú tẹ́ńpìlì, kí wọ́n sì pa á ní ẹnubodè ẹṣin tó wà ní ilé ọba; ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Ataláyà lẹni tó kẹ́yìn nínú ilé Áhábù. (2Ọb 11:1-20; 2Kr 22:1–23:21) Ẹ ò rí i pé: “Kò sí ìkankan nínú ọ̀rọ̀ Jèhófà tí Jèhófà kéde sórí ilé Áhábù tí kò ní ṣẹ”!—2Ọb 10:10, 11; 1Ọb 21:20-24.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
it-1 1265-1266
Jèhóáṣì
Ní gbogbo àkókò tí Jèhóádà Àlùfáà Àgbà fi wà láàyè, nǹkan ń lọ dáadáa fún Jèhóáṣì torí pé Jèhóádà máa ń gbà á nímọ̀ràn, ó sì dà bíi bàbá fún un. Nígbà tí Jèhóáṣì fi máa pé ọmọ ọdún mọ́kànlélógún (21), ó ti níyàwó méjì, ọ̀kan lára àwọn ìyàwó rẹ̀ sì ń jẹ́ Jèhóádánì. Jèhóáṣì wá bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin. Nípa bẹ́ẹ̀, ìlà ìdílé Dáfídì tí Mèsáyà ti wá tó dà bíi pé ó ti fẹ́ pa run, tún wá lágbára lẹ́ẹ̀kan sí i.—2Ọb 12:1-3; 2Kr 24:1-3; 25:1.
DECEMBER 12-18
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 2 ÀWỌN ỌBA 16-17
“Sùúrù Jèhófà Níbi Tó Mọ”
it-2 908 ¶5
Ṣálímánésà
Ìṣàkóso Rẹ̀ Nasẹ̀ Dé Ilẹ̀ Ísírẹ́lì. Lásìkò tí Ọba Hóṣéà ń ṣàkóso ilẹ̀ Ísírẹ́lì (ọdún 758 sí 740 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni), Ṣálímánésà Karùn-ún gbógun wọ ilẹ̀ Palẹ́sínì, Hóṣéà di ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì ń san ìṣákọ́lẹ̀ fún un lọ́dọọdún. (2Ọb 17:1-3) Àmọ́ nígbà tó yá, Hóṣéà ò san ìṣákọ́lẹ̀ náà mọ́, ó sì dara pọ̀ mọ́ Sóò ọba Íjíbítì láti ṣọ̀tẹ̀. (wo SÓÒ.) Ṣálímánésà wá fi Hóṣéà sẹ́wọ̀n, ó sì dó ti ìlú Samáríà fún ọdún mẹ́ta. Nígbà tó yá, ó ṣẹ́gun ìlú náà, ó sì kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ sígbèkùn.—2Ọb 17:4-6; 18:9-12; fi wé Ho 7:11; Isk 23:4-10.
it-1 414-415
Kó Lẹ́rú
Ohun kan náà ni àwọn tó wà ní ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì àti ìjọba ẹ̀yà méjì ti Júdà ṣe tí wọ́n fi kó wọn lẹ́rú, ohun tí wọ́n ṣe ni pé wọ́n pa ìjọsìn Jèhófà tì, wọ́n sì ń bọ àwọn òrìṣà. (Di 28:15, 62-68; 2Ọb 17:7-18; 21:10-15) Léraléra ni Jèhófà rán àwọn wòlíì rẹ̀ sí wọn pé kí wọ́n yí pa dà, àmọ́ wọ́n kọtí ikún sáwọn ìkìlọ̀ náà. (2Ọb 17:13) Ìbọ̀rìṣà ni Jèróbóámù tó jẹ́ ọba àkọ́kọ́ ní ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì gbé kalẹ̀, kò sì sí ọba tó jẹ lẹ́yìn rẹ̀ tó ṣàṣeyọrí láti mú ìbọ̀rìṣà náà kúrò. Bákan náà, àwọn èèyàn Júdà kọtí ikún sí gbogbo ìkìlọ̀ Jèhófà, wọn ò sì kẹ́kọ̀ọ́ lára ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà táwọn ọ̀tá ṣẹ́gun wọn, tí wọ́n sì kó wọn lẹ́rú. (Jer 3:6-10) Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, wọ́n kó àwọn tó wà ní ìjọba méjèèjì lẹ́rú, kódà, ó ju ẹ̀ẹ̀kan lọ tí wọ́n kó wọn lẹ́rú.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
it-2 847
Àwọn Ará Samáríà
Ẹ̀yìn tí wọ́n ṣẹ́gun ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá ti ìlú Samáríà lọ́dún 740 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni ìgbà àkọ́kọ́ tí Bíbélì mẹ́nu kan “àwọn ará Samáríà.” Àwọn tó ń gbé láwọn ìlú tó wà lábẹ́ ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá ni Bíbélì pè bẹ́ẹ̀, kì í ṣe àwọn àjèjì tí wọ́n kó wá láti àwọn ilẹ̀ tí ìjọba Ásíríà ń ṣàkóso. (2Ọb 17:29) Ó jọ pé àwọn ará Ásíríà ò kó gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà nílẹ̀ náà kúrò torí pé ohun tó wà nínú 2 Kíróníkà 34:6-9 (fi wé 2Ọb 23:19, 20) fi hàn pé lásìkò tí Ọba Jòsáyà ń ṣàkóso, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan ṣì wà nílẹ̀ náà. Nígbà tó yá, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í pe ọmọ àwọn tó ṣẹ́ kù sí ilẹ̀ náà àtàwọn àjèjì tí àwọn ará Ásíríà kó wá ní “ará Samáríà.” Àwọn kan sì wà tó jẹ́ ọmọ àwọn àjèjì tó fẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì. Bọ́dún ṣe ń gorí ọdún, kì í ṣe àwọn ẹ̀yà kan ni wọ́n ń pè ní “ará Samáríà” bí kò ṣe àwọn kan tí ìsìn wọn yàtọ̀ sí táwọn Júù, tí wọ́n sì ń gbé láwọn agbègbè ìlú Samáríà àti Ṣékémù àtijọ́.—Jo 4:9.
DECEMBER 19-25
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 2 ÀWỌN ỌBA 18-19
“Ọgbọ́n Táwọn Alátakò Máa Ń Dá Kí Wọ́n Lè Kó Ìrẹ̀wẹ̀sì Bá Wa”
yb74 177 ¶1
Apá 2—Jámánì
Oríṣiríṣi ọgbọ́nkọ́gbọ́n làwọn ọlọ́pàá SS máa ń lò kí wọ́n lè mú kẹ́nì kan fọwọ́ síwèé pé òun kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́. Àmọ́ ó gbàfiyèsí pé lẹ́yìn tẹ́nì kan bá ti fọwọ́ síwèé náà, ṣe ni wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí í fi ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n á sì máa fìtínà ẹ̀ ju bí wọ́n ṣe ń ṣe tẹ́lẹ̀ lọ. Karl Kirscht tí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣojú ẹ̀ sọ pé: “Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n fìtínà jù nínú gbogbo àwọn èèyàn tí wọ́n kó wá sí àgọ́ ìfìyàjẹni. Wọ́n ronú pé ìyẹn ló máa mú ká fọwọ́ síwèé pé a kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́. Àìmọye ìgbà ni wọ́n wá bá wa pé ká fọwọ́ síwèé náà. Ó dunni pé àwọn kan ṣe bẹ́ẹ̀, àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ máa ń dúró fún ohun tó lé lọ́dún kan kí wọ́n tó dá wọn sílẹ̀. Ní gbogbo àsìkò yìí, àwọn ọlọ́pàá SS máa ń fi wọ́n ṣe yẹ̀yé níta gbangba, wọ́n má ń pè wọ́n ní alábòsí àti ọ̀lẹ, wọ́n sì máa ń ní kí wọ́n yan níwájú àwọn ará tó kù kí wọ́n tó gbà kí wọ́n kúro nínú àgọ́ náà.”
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
it-1 155 ¶4
Ìwalẹ̀pìtàn
Àkọsílẹ̀ Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ọmọ Ọba Senakérúbù ilẹ̀ Ásíríà, ìyẹn Adiramélékì àti Ṣárésà ló pa á, ọmọ ẹ̀ míì tó ń jẹ́ Esari-hádónì ló sì rọ́pò rẹ̀. (2Ọb 19:36, 37) Àmọ́, àkọsílẹ̀ àwọn ará Bábílónì kan sọ pé ní ogúnjọ́ oṣù Tébétì, ọmọ Senakérúbù kan ṣọ̀tẹ̀, ó sì pa Senakérúbù. Berossus tó jẹ́ àlùfáà Bábílónì ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹta Ṣáájú Sànmánì Kristẹni àti Nabonidus tó jẹ́ ọba Bábílónì ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹfà Ṣáájú Sànmánì Kristẹni náà sọ pé ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Senakérúbù ló pa á. Àmọ́ lẹ́nu àìpẹ́ yìí, wọ́n rí àfọ́kù Wàláà Esari-hádónì ìyẹn ọmọ Senakérúbù tó jọba lẹ́yìn rẹ̀. Nínú wàláà náà, ó sọ ní kedere pé àwọn ẹ̀gbọ́n òun pa Bàbá òun, wọ́n sì sá lọ. Nínú ìwé Universal Jewish History (1948, Ìdìpọ̀ I, ojú ìwé 27) Philip Biberfeld sọ pé: “Ohun tí Nabonid àti Berossus sọ títí kan ohun tó wà nínú àkọsílẹ̀ àwọn ará Bábílónì yẹn kì í ṣòótọ́; ohun tó wà nínú Bíbélì nìkan ló jóòótọ́. Ohun tó wà nínú Wàláà Esari-hádónì fi hàn pé àkọsílẹ̀ Bíbélì péye, kódà ohun tó sọ nípa ìtàn àwọn ará Bábílónì àti Ásíríà péye ju ohun táwọn ará Bábílónì fúnra wọn sọ. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí jẹ́ ká rí i pé ó ṣe pàtàkì ká gbé ohun táwọn awalẹ̀pìtàn bá ṣàwárí yẹ̀ wò dáadáa, pàápàá tí kò bá ti bá ohun tí Bíbélì sọ mu.”
DECEMBER 26–JANUARY 1
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 2 ÀWỌN ỌBA 20-21
“Àdúrà Mú Kí Jèhófà Gbé Ìgbésẹ̀”
it-2 240 ¶1
Irinṣẹ́ Tí A Fi Ń Mú Nǹkan Tẹ́jú
Wọ́n máa ń fi irinṣẹ́ yìí mú kí ilé kan dúró dáadáa tàbí kí wọ́n fi mọ bó ṣe máa lálòpẹ́ sí. Jèhófà sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Màá na okùn ìdíwọ̀n tí a lò fún Samáríà sórí Jerúsálẹ́mù àti irinṣẹ́ tí a fi ń mú nǹkan tẹ́jú tí a lò fún ilé Áhábù.” Ọlọ́run ti díwọ̀n Samáríà àti ilé Ọba Áhábù, ó sì rí i pé ìwà burúkú ló kún ọwọ́ wọn, ìyẹn mú kó pa wọ́n run. Lọ́nà kan náà, Ọlọ́run máa dá Jerúsálẹ́mù àtàwọn ọba rẹ̀ lẹ́jọ́, ó máa tú àṣírí ìwà burúkú wọn, ó sì máa pa ìlú náà run. Àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣẹ lọ́dún 607 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni. (2Ọb 21:10-13; 10:11) Jèhófà tipasẹ̀ Àìsáyà kìlọ̀ fáwọn èèyàn burúkú àtàwọn aṣaájú tó ń gbé ní Jerúsálẹ́mù nípa ìparun tó ń bọ̀ lórí wọn. Ó ní: “Màá fi ìdájọ́ òdodo ṣe okùn ìdíwọ̀n, màá sì fi òdodo ṣe irinṣẹ́ tí a fi ń mú nǹkan tẹ́jú.” Ìlànà òdodo Jèhófà máa jẹ́ kí wọ́n mọ àwọn tó ń fòótọ́ inú sìn ín àtàwọn tí kò ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn tó bá ń ṣèfẹ́ Jèhófà máa là á já, àwọn tí kò sì ṣe bẹ́ẹ̀ máa pa run.—Ais 28:14-19.