ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jésù Fi Igi Ọ̀pọ̀tọ́ Kan Kọ́ Wọn Lẹ́kọ̀ọ́ Nípa Ìgbàgbọ́
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
    • Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ rí i tí igi ọ̀pọ̀tọ́ kan tí kò so èso ti gbẹ

      ORÍ 105

      Jésù Fi Igi Ọ̀pọ̀tọ́ Kan Kọ́ Wọn Lẹ́kọ̀ọ́ Nípa Ìgbàgbọ́

      MÁTÍÙ 21:19-27 MÁÀKÙ 11:19-33 LÚÙKÙ 20:1-8

      • OHUN TÍ IGI Ọ̀PỌ̀TỌ́ TÓ GBẸ KỌ́ WA NÍPA ÌGBÀGBỌ́

      • ÀWỌN ÈÈYÀN BÉÈRÈ ẸNI TÓ FÚN JÉSÙ LÁṢẸ TÓ FI Ń ṢE NǸKAN

      Nígbà tí Jésù kúrò ní Jerúsálẹ́mù lọ́sàn-án ọjọ́ Monday, ó pa dà sí Bẹ́tánì tó wà ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ ìlà oòrùn Òkè Ólífì. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ilé Lásárù, Màríà àti Màtá tí wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ ló sùn mọ́jú.

      Láàárọ̀ Nísàn 11, Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tún bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò wọn. Wọ́n pa dà sí Jerúsálẹ́mù, ọjọ́ yẹn ni Jésù máa dé tẹ́ńpìlì gbẹ̀yìn. Ọjọ́ yẹn kan náà ló máa lò kẹ́yìn lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, lẹ́yìn náà wọ́n máa ṣe Ìrékọjá, ó máa dá Ìrántí Ikú rẹ̀ sílẹ̀, wọ́n máa gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀, wọ́n sì máa pa á.

      Bí wọ́n ṣe ń gba Òkè Ólífì kọjá lọ láti Bẹ́tánì sí Jerúsálẹ́mù, Pétérù rí igi tí Jésù gégùn-ún fún láàárọ̀ ọjọ́ tó ṣáájú ọjọ́ yẹn. Ó yà á lẹ́nu, ó wá sọ pé: “Rábì, wò ó! igi ọ̀pọ̀tọ́ tí o gégùn-ún fún ti gbẹ.”—Máàkù 11:21.

      Àmọ́ kí nìdí tí Jésù fi ní kí igi náà gbẹ? Ohun tó sọ lẹ́yìn náà jẹ́ ká mọ ìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀, ó ní: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, tí ẹ bá ní ìgbàgbọ́, tí ẹ ò sì ṣiyèméjì, ohun tí mo ṣe sí igi ọ̀pọ̀tọ́ náà nìkan kọ́ lẹ máa lè ṣe, àmọ́ tí ẹ bá sọ fún òkè yìí pé, ‘Dìde, wọnú òkun,’ ó máa ṣẹlẹ̀. Gbogbo ohun tí ẹ bá sì béèrè nínú àdúrà, tí ẹ bá ní ìgbàgbọ́, ẹ máa rí i gbà.” (Mátíù 21:21, 22) Ohun tó sọ yìí fi hàn pé ó fẹ́ tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ tó ti sọ tẹ́lẹ̀ nípa bí ìgbàgbọ́ ṣe lè mú kí òkè kúrò níbì kan lọ síbòmíì.—Mátíù 17:20.

      Torí náà, bí Jésù ṣe mú kí igi yẹn gbẹ fi hàn pé ó fẹ́ kí wọ́n mọ bó ti ṣe pàtàkì tó láti nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run. Ó ní: “Gbogbo ohun tí ẹ bá gbàdúrà fún, tí ẹ sì béèrè, ẹ ní ìgbàgbọ́ pé ẹ ti rí i gbà, ó sì máa jẹ́ tiyín.” (Máàkù 11:24) Ẹ̀kọ́ pàtàkì lèyí jẹ́ fún gbogbo àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù! Ní pàtàkì, fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, torí wọ́n máa tó kojú àdánwò tó lágbára. Àmọ́, ẹ̀kọ́ míì wà tá a tún lè rí kọ́ nínú bí igi yẹn ṣe rọ.

      Bíi ti igi yẹn, ó lè dà bíi pé orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì nígbàgbọ́. Torí Ọlọ́run bá wọn dá májẹ̀mú, èèyàn lè máa wò wọ́n bí ẹni tó ń pa Òfin Ọlọ́run mọ́. Àmọ́ orílẹ̀-èdè yẹn lápapọ̀ ti fi hàn pé àwọn ò nígbàgbọ́, wọn ò sì méso jáde. Kódà, wọ́n kọ̀ láti gba Ọmọ Ọlọ́run gbọ́! Torí náà, bí Jésù ṣe mú kí igi tí kò méso jáde yẹn gbẹ, ṣe ló ń ṣàpèjúwe ohun tó máa gbẹ̀yìn orílẹ̀-èdè yẹn, torí pé wọn ò méso jáde, wọn ò sì nígbàgbọ́.

      Kò pẹ́ sígbà yẹn, Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ dé Jerúsálẹ́mù. Bó ṣe máa ń ṣe, ó lọ sí tẹ́ńpìlì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn èèyàn. Àwọn olórí àlùfáà àtàwọn àgbààgbà lọ bá Jésù, ó ṣeé ṣe kí wọ́n ṣì máa ronú lórí ohun tó ṣe lọ́jọ́ kan ṣáájú ìgbà yẹn. Wọ́n bi í pé: “Àṣẹ wo lo fi ń ṣe àwọn nǹkan yìí? Àbí ta ló fún ọ ní àṣẹ yìí pé kí o máa ṣe àwọn nǹkan yìí?”—Máàkù 11:28.

      Jésù dá wọn lóhùn pé: “Èmi náà á bi yín ní ìbéèrè kan. Tí ẹ bá dá mi lóhùn, màá wá sọ àṣẹ tí mo fi ń ṣe àwọn nǹkan yìí fún yín. Ṣé láti ọ̀run ni ìrìbọmi tí Jòhánù ṣe fún àwọn èèyàn ti wá àbí látọ̀dọ̀ èèyàn? Ẹ dá mi lóhùn.” Lọ̀rọ̀ bá pèsì jẹ. Wọ́n wá forí korí kí wọ́n lè dáhùn ìbéèrè yìí, wọ́n sọ láàárín ara wọn pé: “Tí a bá sọ pé, ‘Láti ọ̀run,’ ó máa sọ pé, ‘Kí ló wá dé tí ẹ ò gbà á gbọ́?’ Àmọ́, ṣé a lè sọ pé, ‘Látọ̀dọ̀ èèyàn’?” Ẹ̀rù àwọn èèyàn tó wà lọ́dọ̀ Jésù ló ba àwọn alátakò yẹn tí wọ́n fi ń sọ bẹ́ẹ̀, “torí gbogbo àwọn yìí gbà pé wòlíì ni Jòhánù lóòótọ́.”—Máàkù 11:29-32.

      Àwọn alátakò yẹn ò rí ohunkóhun sọ sí ìbéèrè tí Jésù bi wọ́n. Ni wọ́n bá dá a lóhùn pé: “A ò mọ̀.” Jésù náà dá wọn lóhùn, ó ní: “Èmi náà ò ní sọ àṣẹ tí mo fi ń ṣe àwọn nǹkan yìí fún yín.”—Máàkù 11:33.

      • Kí ló mú kí Nísàn 11 ṣàrà ọ̀tọ̀?

      • Ẹ̀kọ́ wo ni Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bó ṣe ní kí igi ọ̀pọ̀tọ́ kan gbẹ?

      • Àwọn kan bi Jésù pé ta ló fún un láṣẹ tó fi ń ṣe àwọn nǹkan tó ń ṣe, báwo ló ṣe dá wọn lóhùn?

  • Àpèjúwe Méjì Nípa Ọgbà Àjàrà
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
    • Àwọn tó ń dáko pa ọmọ ẹni tó ni ọgbà àjàrà náà

      ORÍ 106

      Àpèjúwe Méjì Nípa Ọgbà Àjàrà

      MÁTÍÙ 21:28-46 MÁÀKÙ 12:1-12 LÚÙKÙ 20:9-19

      • ÀPÈJÚWE NÍPA ỌMỌ MÉJÌ

      • ÀPÈJÚWE NÍPA ÀWỌN TÓ BÓJÚ TÓ ỌGBÀ ÀJÀRÀ KAN

      Nígbà tí Jésù wà nínú tẹ́ńpìlì, àwọn olórí àlùfáà àtàwọn àgbààgbà béèrè ẹni tó fún un ní àṣẹ tó fi ń ṣe nǹkan. Ìdáhùn tí Jésù fún wọn mú kí ọ̀rọ̀ náà dà rú mọ́ wọn lójú. Ni wọ́n bá gbẹ́nu dákẹ́. Lẹ́yìn náà, Jésù sọ àpèjúwe kan tó jẹ́ ká túbọ̀ mọ irú ẹni tí wọ́n jẹ́ ní ti gidi.

      Jésù sọ pé: “Ọkùnrin kan ní ọmọ méjì. Ó lọ bá àkọ́kọ́, ó sọ pé, ‘Ọmọ, lọ ṣiṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà lónìí.’ Ọmọ náà fèsì pé, ‘Mi ò lọ,’ àmọ́ lẹ́yìn náà, ó pèrò dà, ó sì lọ. Ó lọ bá ìkejì, ó sọ ohun kan náà fún un. Ọmọ náà sì fèsì pé, ‘Màá lọ Sà,’ àmọ́ kò lọ. Èwo nínú àwọn méjèèjì ló ṣe ìfẹ́ bàbá rẹ̀?” (Mátíù 21:28-31) Ìdáhùn ìbéèrè yẹn ò lọ́jú pọ̀ rárá, torí pé ọmọ tí bàbá yẹn kọ́kọ́ bá sọ̀rọ̀ ló pa dà ṣe ohun tí bàbá yẹn fẹ́.

      Jésù wá sọ fáwọn alátakò rẹ̀ pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín pé, àwọn agbowó orí àti àwọn aṣẹ́wó máa ṣáájú yín lọ sínú Ìjọba Ọlọ́run.” Níbẹ̀rẹ̀ àwọn agbowó orí àtàwọn aṣẹ́wó ò sin Jèhófà. Àmọ́ nígbà tó yá, wọ́n ṣe bíi ti ọmọ àkọ́kọ́, wọ́n ronú pìwà dà, wọ́n sì ti wá ń sin Ọlọ́run báyìí. Àmọ́ ní ti àwọn aṣáájú ẹ̀sìn yẹn, ṣe lọ̀rọ̀ wọn dà bíi ti ọmọ kejì. Wọ́n ń sọ pé àwọn ń sin Ọlọ́run, àmọ́ wọn ò ṣe bẹ́ẹ̀. Jésù wá sọ pé: “Jòhánù [Arinibọmi] wá sọ́dọ̀ yín ní ọ̀nà òdodo, àmọ́ ẹ ò gbà á gbọ́. Ṣùgbọ́n àwọn agbowó orí àti àwọn aṣẹ́wó gbà á gbọ́, kódà nígbà tí ẹ rí èyí, ẹ ò pèrò dà lẹ́yìn náà kí ẹ lè gbà á gbọ́.”—Mátíù 21:31, 32.

      Jésù tún sọ àpèjúwe míì lẹ́yìn ìyẹn. Lọ́tẹ̀ yìí, Jésù fi hàn pé ohun táwọn aṣáájú ẹ̀sìn yẹn ṣe kọjá pé wọn ò sin Ọlọ́run. Ìkà burúkú ni wọ́n. Jésù sọ pé: “Ọkùnrin kan gbin àjàrà, ó sì ṣe ọgbà yí i ká, ó gbẹ́ ẹkù sí ibi tí wọ́n ti ń fún wáìnì, ó sì kọ́ ilé gogoro kan; ó wá gbé e fún àwọn tó ń dáko, ó sì rin ìrìn àjò lọ sí ilẹ̀ òkèèrè. Nígbà tí àsìkò tó, ó rán ẹrú kan lọ sọ́dọ̀ àwọn tó ń dáko náà pé kó gbà lára àwọn èso ọgbà àjàrà náà lọ́wọ́ wọn. Àmọ́ wọ́n mú un, wọ́n lù ú, wọ́n sì ní kó máa lọ lọ́wọ́ òfo. Ó tún rán ẹrú míì sí wọn àmọ́ wọ́n lù ú ní orí, wọ́n sì kàn án lábùkù. Ó rán ẹlòmíì, wọ́n sì pa á, ó tún rán ọ̀pọ̀ àwọn míì, wọ́n lu àwọn kan nínú wọn, wọ́n sì pa àwọn míì.”—Máàkù 12:1-5.

      Ṣé àpèjúwe yìí máa yé àwọn èèyàn? Ó ṣeé ṣe kí wọ́n rántí ohun tí wòlíì Àìsáyà sọ nígbà tó ń dẹ́bi fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ilé Ísírẹ́lì ni ọgbà àjàrà Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun; àwọn èèyàn Júdà sì ni oko tó fẹ́ràn. Ó ń retí ìdájọ́ òdodo, àmọ́ wò ó! ìrẹ́jẹ ló wà.” (Àìsáyà 5:7) Ohun tí Àìsáyà sọ yìí jọra pẹ̀lú àpèjúwe Jésù yẹn. Jèhófà ló gbin àjàrà, orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ló dà bí ọgbà àjàrà náà, Òfin Ọlọ́run ló dà bí ọgbà tó yí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ká, tó sì ń dáàbò bò wọ́n. Jèhófà rán àwọn wòlíì sí wọn láti tọ́ wọn sọ́nà, kí wọ́n lè máa so èso tó dáa.

      Ṣùgbọ́n, “àwọn tó ń dáko” ṣe àwọn “ẹrú” tí wọ́n rán sí wọn ṣúkaṣùka, wọ́n sì pa wọ́n. Jésù wá ṣàlàyé pé: “Ẹnì kan tó ṣẹ́ kù [fún ẹni tó ni ọgbà àjàrà yẹn] ni ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n. Òun ló rán sí wọn gbẹ̀yìn, ó ní, ‘Wọ́n máa bọ̀wọ̀ fún ọmọ mi.’ Àmọ́ àwọn tó ń dáko náà sọ fún ara wọn pé, ‘Ẹni tó máa jogún rẹ̀ nìyí. Ẹ wá, ẹ jẹ́ ká pa á, ogún rẹ̀ sì máa di tiwa.’ Torí náà, wọ́n mú un, wọ́n [sí] pa á.”—Máàkù 12:6-8.

      Jésù wá bi wọ́n pé: “Kí ni ẹni tó ni ọgbà àjàrà náà máa ṣe?” (Máàkù 12:9) Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn yẹn dá a lóhùn pé: “Torí pé èèyàn burúkú ni wọ́n, ó máa mú ìparun tó lágbára wá sórí wọn, ó sì máa gbé ọgbà àjàrà náà fún àwọn míì tó ń dáko, tí wọ́n máa fún un ní èso nígbà tí àkókò bá tó.”—Mátíù 21:41.

      Láìmọ̀, ṣe ni wọ́n ń dá ara wọn lẹ́jọ́, torí wọ́n wà lára “àwọn tó ń dáko” tí Jèhófà ní kó máa bójú tó orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tó jẹ́ “ọgbà àjàrà” rẹ̀. Ọ̀kan lára èso tí Jèhófà ń retí látọ̀dọ̀ wọn ni pé kí wọ́n nígbàgbọ́ nínú Ọmọ rẹ̀, ìyẹn Mèsáyà. Jésù wá kọjú sáwọn aṣáájú ẹ̀sìn yẹn, ó sì sọ fún wọn pé: “Ṣé ẹ ò ka ìwé mímọ́ yìí rí ni, pé: ‘Òkúta tí àwọn kọ́lékọ́lé kọ̀ sílẹ̀, òun ló wá di olórí òkúta igun ilé. Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni èyí ti wá, ó sì jẹ́ ìyanu lójú wa’?” (Máàkù 12:10, 11) Lẹ́yìn náà, Jésù ṣàlàyé fún wọn pé: “Ìdí nìyí tí mo fi sọ fún yín pé, a máa gba Ìjọba Ọlọ́run kúrò lọ́wọ́ yín, a sì máa fún orílẹ̀-èdè tó ń mú èso rẹ̀ jáde.”—Mátíù 21:43.

      Àwọn akọ̀wé òfin àtàwọn olórí àlùfáà rí i pé ‘àwọn ni Jésù ń fi àpèjúwe yìí bá wí.’ (Lúùkù 20:19) Torí pé Jésù ló “máa jogún” olóko yẹn, àwọn aṣáájú ìsìn yìí túbọ̀ ń wá bí wọ́n ṣe máa pa á. Àmọ́ wọ́n ń bẹ̀rù àwọn èèyàn tó wà lọ́dọ̀ Jésù, torí àwọn èèyàn yẹn gbà pé wòlíì ni Jésù. Torí náà wọn ò lè pa á níbẹ̀.

      • Àwọn wo ni ọmọ méjì tó wà nínú àpèjúwe Jésù dúró fún?

      • Nínú àpèjúwe kejì, ta ló dúró fún; ‘ẹni tó gbin àjàrà,’ “ọgbà àjàrà,” “àwọn tó ń dáko,” “ẹrú” àti ẹni “tó máa jogún” olóko náà?

      • Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí “àwọn tó ń dáko” yẹn lọ́jọ́ iwájú?

  • Ọba Kan Pe Àwọn Èèyàn Wá Síbi Ayẹyẹ Ìgbéyàwó
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
    • Ọba ní kí wọ́n lé ọkùnrin tí ò wọ aṣọ ìgbéyàwó kúrò níbi àsè náà

      ORÍ 107

      Ọba Kan Pe Àwọn Èèyàn Wá Síbi Ayẹyẹ Ìgbéyàwó

      MÁTÍÙ 22:1-14

      • ÀPÈJÚWE NÍPA AYẸYẸ ÌGBÉYÀWÓ

      Bí iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù ṣe ń parí lọ, ó túbọ̀ ń lo àpèjúwe láti tú àṣírí àwọn akọ̀wé òfin àtàwọn olórí àlùfáà. Torí náà, wọ́n ń wá bí wọ́n ṣe máa pa á. (Lúùkù 20:19) Àmọ́, Jésù ò tíì parí ọ̀rọ̀ ẹ̀. Ó tún lo àpèjúwe míì láti tú àṣírí wọn, ó ní:

      “A lè fi Ìjọba ọ̀run wé ọba kan tó se àsè ìgbéyàwó fún ọmọkùnrin rẹ̀. Ó wá rán àwọn ẹrú rẹ̀ kí wọ́n lọ pe àwọn tí wọ́n pè síbi àsè ìgbéyàwó náà wá, àmọ́ wọn ò fẹ́ wá.” (Mátíù 22:2, 3) Ọ̀rọ̀ nípa “Ìjọba ọ̀run” ni Jésù fi bẹ̀rẹ̀ àpèjúwe yìí. Torí náà, ó bọ́gbọ́n mu láti gbà pé Jèhófà ni “ọba” yẹn. Ta wá ni ọmọ ọba àtàwọn tí wọ́n pè wá síbi ayẹyẹ ìgbéyàwó náà? Ìbéèrè yìí náà ò le, Ọmọ Jèhófà ló dúró fún ọmọ ọba, àwọn tó sì máa wà pẹ̀lú Ọmọ yìí nínú Ìjọba ọ̀run làwọn tí wọ́n pè síbi ayẹyẹ náà.

      Àwọn wo ni wọ́n kọ́kọ́ pè síbi ayẹyẹ náà? Rò ó ná! Àwọn wo ni Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ń wàásù Ìjọba Ọlọ́run fún? Àwọn Júù ni! (Mátíù 10:6, 7; 15:24) Ọdún 1513 Ṣ.S.K. ni orílẹ̀-èdè yẹn gba Májẹ̀mú Òfin, ìyẹn ló sì mú kí wọ́n di ẹni àkọ́kọ́ tó máa wà nínú “ìjọba àwọn àlùfáà.” (Ẹ́kísódù 19:5-8) Àmọ́ ìgbà wo ni wọ́n pè wọ́n síbi “àsè ìgbéyàwó náà”? Kò sí iyèméjì pé ọdún 29 S.K. ni, torí pé ìgbà yẹn ni Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù nípa Ìjọba ọ̀run.

      Kí ni ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe nígbà tí wọ́n pè wọ́n? Bí Jésù ṣe sọ, “wọn ò fẹ́ wá.” Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn èèyàn yẹn àtàwọn aṣáájú ẹ̀sìn ni ò gbà pé òun ni Mèsáyà tí Ọlọ́run yàn láti di Ọba.

      Jésù jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé àǹfààní míì ṣì wà fáwọn Júù, ó ní: “[Ọba] tún rán àwọn ẹrú míì, ó sọ pé, ‘Ẹ sọ fún àwọn tí a pè, pé: “Ẹ wò ó! Mo ti pèsè oúnjẹ alẹ́ mi sílẹ̀, mo ti pa àwọn akọ màlúù mi àtàwọn ẹran mi tó sanra, gbogbo nǹkan sì ti wà ní sẹpẹ́. Ẹ wá síbi àsè ìgbéyàwó náà.”’ Àmọ́ wọn ò kà á sí, wọ́n jáde lọ, ọ̀kan lọ sí oko rẹ̀, òmíràn lọ síbi òwò rẹ̀; àmọ́ àwọn tó kù gbá àwọn ẹrú rẹ̀ mú, wọ́n kàn wọ́n lábùkù, wọ́n sì pa wọ́n.” (Mátíù 22:4-6) Èyí jọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n bá dá ìjọ Kristẹni sílẹ̀. Nígbà yẹn, àwọn Júù tún máa láǹfààní láti wà nínú Ìjọba yẹn, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ lára wọn ò ní gba ìkésíni náà, kódà ṣe ni wọ́n máa kan ‘àwọn ẹrú ọba’ náà lábùkù.—Ìṣe 4:13-18; 7:54, 58.

      Kí ló wá ṣẹlẹ̀ sí orílẹ̀-èdè yẹn? Jésù sọ pé: “Inú bí ọba náà, ló bá rán àwọn ọmọ ogun rẹ̀ lọ pa àwọn apààyàn náà, ó sì dáná sun ìlú wọn.” (Mátíù 22:7) Ọdún 70 S.K. lohun tí Jésù sọ yìí ṣẹlẹ̀ nígbà tí àwọn ará Róòmù pa “ìlú wọn” run, ìyẹn Jerúsálẹ́mù.

      Ṣé bí wọn ò ṣe jẹ́ ìpè ọba yẹn túmọ̀ sí pé àwọn míì ò lè wá síbi àsè náà? Ohun tí Jésù sọ kọ́ nìyẹn. Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “[Ọba] wá sọ fún àwọn ẹrú rẹ̀ pé, ‘Àsè ìgbéyàwó náà ti wà ní sẹpẹ́, àmọ́ àwọn tí a pè kò yẹ. Torí náà, ẹ lọ sí àwọn ojú ọ̀nà tó jáde látinú ìlú, kí ẹ sì pe ẹnikẹ́ni tí ẹ bá rí wá síbi àsè ìgbéyàwó náà.’ Àwọn ẹrú náà ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n jáde lọ sí àwọn ojú ọ̀nà, wọ́n sì kó gbogbo àwọn tí wọ́n rí jọ, ẹni burúkú àti ẹni rere; àwọn tó ń jẹun sì kún inú yàrá tí wọ́n ti ń ṣe ayẹyẹ ìgbéyàwó náà.”—Mátíù 22:8-10.

      Ó ṣe kedere pé ohun tí Jésù sọ yìí ṣẹlẹ̀ nígbà tí àpọ́sítélì Pétérù ran àwọn Kèfèrí lọ́wọ́, ìyẹn àwọn tí kì í ṣe Júù tàbí aláwọ̀ṣe, àwọn yìí sì di Kristẹni. Nígbà tó di ọdún 36 S.K., ẹ̀mí mímọ́ bà lé Kọ̀nílíù tó jẹ́ ọmọ ogun Róòmù àti ìdílé rẹ̀, ìyẹn sì mú kí wọ́n di ọ̀kan lára àwọn tó máa wà pẹ̀lú Jésù nínú Ìjọba ọ̀run.—Ìṣe 10:1, 34-48.

      Jésù tún sọ pé kì í ṣe gbogbo àwọn tó bá wá síbi àsè náà ni inú “ọba” máa dùn sí. Ó ní: “Nígbà tí ọba náà wọlé wá wo àwọn àlejò, ó tajú kán rí ọkùnrin kan tí kò wọ aṣọ ìgbéyàwó. Ó wá bi í pé, ‘Ọ̀gbẹ́ni, báwo lo ṣe wọlé síbí láìwọ aṣọ ìgbéyàwó?’ Ọkùnrin náà ò lè sọ nǹkan kan. Ọba wá sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, ‘Ẹ dè é tọwọ́ tẹsẹ̀, kí ẹ sì jù ú sínú òkùnkùn níta. Ibẹ̀ lá ti máa sunkún, tí á sì ti máa payín keke.’ Torí ọ̀pọ̀ la pè, àmọ́ díẹ̀ la yàn.”—Mátíù 22:11-14.

      Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn yẹn lè má lóye ohun tí Jésù ń sọ, wọ́n sì lè má mọ ibi tọ́rọ̀ náà máa já sí. Síbẹ̀ inú wọn ò dùn sí Jésù, kódà ṣe ni wọ́n túbọ̀ ń wá bí wọ́n ṣe máa pa á, torí pé ó ń kàn wọ́n lábùkù.

      • Nínú àpèjúwe yìí, ta ni “ọba” náà, ta ni “ọmọkùnrin rẹ̀,” àwọn wo ló sì kọ́kọ́ pè síbi àsè ìgbéyàwó náà?

      • Ìgbà wo ni Ọlọ́run pe àwọn Júù, àwọn wo ló sì pè lẹ́yìn wọn?

      • Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé ọ̀pọ̀ la pè, àmọ́ díẹ̀ la yàn?

  • Ìdáhùn Jésù Ò Jẹ́ Káwọn Ọ̀tá Rẹ̀ Rí I Mú
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
    • Jésù mú ẹyọ owó tí wọ́n fi ń san owó orí dání bó ṣe ń dáhùn ìbéèrè táwọn Farisí fẹ́ fi dẹkùn mú un

      ORÍ 108

      Ìdáhùn Jésù Ò Jẹ́ Káwọn Ọ̀tá Rẹ̀ Rí I Mú

      MÁTÍÙ 22:15-40 MÁÀKÙ 12:13-34 LÚÙKÙ 20:20-40

      • OHUN TI KÉSÁRÌ PA DÀ FÚN KÉSÁRÌ

      • ṢÉ ÀWỌN ÈÈYÀN MÁA GBÉYÀWÓ NÍGBÀ ÀJÍǸDE?

      • ÀṢẸ TÓ TÓBI JÙ LỌ

      Inú ń bí àwọn aṣáájú ìsìn sí Jésù, torí pé ó ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ àpèjúwe tó fi tú àṣírí wọn pé ìkà ni wọ́n. Làwọn Farisí bá ń wá bí wọ́n ṣe máa mú un. Wọ́n fẹ́ kó sọ ohun kan kí wọ́n lè fẹ̀sùn kàn án, kí wọ́n sì mú un lọ sọ́dọ̀ gómìnà àwọn ará Róòmù. Wọ́n tún fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn wọn lówó kí wọ́n lè bá wọn mú un.—Lúùkù 6:7.

      Àwọn Farisí wá sọ pé: “Olùkọ́, a mọ̀ pé o máa ń sọ̀rọ̀, o sì máa ń kọ́ni lọ́nà tó tọ́, o kì í ṣe ojúsàájú rárá, àmọ́ ò ń kọ́ni ní ọ̀nà Ọlọ́run ní ìbámu pẹ̀lú òtítọ́: Ṣé ó bófin mu fún wa láti san owó orí fún Késárì àbí kò bófin mu?” (Lúùkù 20:21, 22) Jésù ò jẹ́ kí wọ́n fi ọ̀rọ̀ dídùn tan òun jẹ, torí ó mọ̀ pé alágàbàgebè àti alárèékérekè ni wọ́n. Tó bá sọ pé, ‘Rárá, kò yẹ kí wọ́n máa san owó orí yìí,’ wọ́n lè fẹ̀sùn kàn án pé ó ń dìtẹ̀ sí ìjọba Róòmù. Tó bá sì sọ pé, ‘Bẹ́ẹ̀ ni, ó yẹ kẹ́ ẹ máa san owó orí,’ wọ́n lè ṣi Jésù lóye torí pé ará ń kan wọ́n bí wọ́n ṣe wà lábẹ́ ìjọba Róòmù, ìyẹn sì lè mú káwọn èèyàn kẹ̀yìn sí i. Báwo ni Jésù ṣe dáhùn ìbéèrè yẹn?

      Jésù fèsì pé: “Ẹ̀yin alágàbàgebè, kí ló dé tí ẹ̀ ń dán mi wò? Ẹ fi ẹyọ owó tí ẹ fi ń san owó orí hàn mí.” Wọ́n fún un ní owó dínárì, ó wá bi wọ́n pé: “Àwòrán àti àkọlé ta nìyí?” Wọ́n sọ pé: “Ti Késárì ni.” Jésù wá fún wọn ní ìtọ́ni kan, ó ní: “Torí náà, ẹ san àwọn ohun ti Késárì pa dà fún Késárì, àmọ́ ẹ fi àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”—Mátíù 22:18-21.

      Èsì tí Jésù fún àwọn ọkùnrin yìí yà wọ́n lẹ́nu. Bí Jésù ṣe fọgbọ́n dá wọn lóhùn yìí ò jẹ́ kí wọ́n rí ọ̀rọ̀ sọ mọ́, ni wọ́n bá kúrò níbẹ̀. Àmọ́ kàkà kí ọ̀rọ̀ náà tán lára wọn, ṣe ló túbọ̀ ń le sí i, ìsapá wọn láti mú Jésù ò tíì tán. Lẹ́yìn tí ìsapá àwọn Farisí láti mú Jésù já sí pàbó, àwọn aṣáájú ìsìn míì tún kóra jọ, wọ́n sì lọ bá a.

      Àwọn Sadusí gbà pé kò sí àjíǹde, wọ́n wá lọ bá Jésù, wọ́n sì bi í ní ìbéèrè nípa àjíǹde àti ṣíṣú obìnrin lópó, wọ́n ní: “Olùkọ́, Mósè sọ pé: ‘Tí ọkùnrin èyíkéyìí bá kú láìní ọmọ, kí arákùnrin rẹ̀ fẹ́ ìyàwó rẹ̀, kó sì bímọ fún arákùnrin rẹ̀.’ Ó ṣẹlẹ̀ pé arákùnrin méje wà pẹ̀lú wa. Ẹni àkọ́kọ́ fẹ́ ìyàwó, ó sì kú, ó fi ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ fún arákùnrin rẹ̀, nígbà tó jẹ́ pé kò bí ọmọ kankan. Ohun kan náà ló ṣẹlẹ̀ sí ẹnì kejì àti ẹnì kẹta, títí dórí ẹnì keje. Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, obìnrin náà kú. Tí àwọn méjèèje bá wá jíǹde, èwo nínú wọn ló máa fẹ́? Torí gbogbo wọn ni wọ́n ti fi ṣe aya.”—Mátíù 22:24-28.

      Jésù mọ̀ pé àwọn Sadusí yẹn gba ọ̀rọ̀ Mósè gbọ́, torí náà ibẹ̀ ló ti fa ọ̀rọ̀ ẹ̀ yọ. Ó dá wọn lóhùn pé: “Ṣebí ìdí tí ẹ fi ṣàṣìṣe nìyẹn, torí pé ẹ ò mọ Ìwé Mímọ́, ẹ ò sì mọ agbára Ọlọ́run? Torí tí wọ́n bá jíǹde, àwọn ọkùnrin kì í gbéyàwó, a kì í sì í fa àwọn obìnrin fún ọkọ, àmọ́ wọ́n máa dà bí àwọn áńgẹ́lì ní ọ̀run. Àmọ́ ní ti àjíǹde àwọn òkú, ṣé ẹ ò tíì kà á nínú ìwé Mósè ni, nínú ìtàn igi ẹlẹ́gùn-ún, pé Ọlọ́run sọ fún un pé: ‘Èmi ni Ọlọ́run Ábúráhámù, Ọlọ́run Ísákì àti Ọlọ́run Jékọ́bù’? Kì í ṣe Ọlọ́run àwọn òkú, àmọ́ ó jẹ́ Ọlọ́run àwọn alààyè. Ẹ mà ṣàṣìṣe o.” (Máàkù 12:24-27; Ẹ́kísódù 3:1-6) Èsì tí Jésù fún wọn yìí ya gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ lẹ́nu gan-an.

      Jésù ti pa àwọn Farisí àtàwọn Sadusí lẹ́nu mọ́, ni gbogbo wọn bá gbìmọ̀ pọ̀ láti túbọ̀ dán an wò. Ọ̀kan lára àwọn akọ̀wé òfin wá bi í pé: “Olùkọ́, àṣẹ wo ló tóbi jù lọ nínú Òfin?”—Mátíù 22:36.

      Jésù fèsì pé: “Àkọ́kọ́ ni, ‘Gbọ́, ìwọ Ísírẹ́lì, Jèhófà Ọlọ́run wa, Jèhófà kan ṣoṣo ni, kí o sì fi gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara rẹ àti gbogbo èrò rẹ àti gbogbo okun rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ.’ Ìkejì ni, ‘Kí o nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ.’ Kò sí àṣẹ míì tó tóbi ju àwọn yìí lọ.”—Máàkù 12:29-31.

      Lẹ́yìn tí Jésù dáhùn, ọkùnrin náà sọ pé: “Olùkọ́, ohun tí o sọ dáa, ó sì bá òtítọ́ mu, ‘Ọ̀kan ṣoṣo ni Òun, kò sí ẹlòmíì àfi òun nìkan’; kí èèyàn fi gbogbo ọkàn, gbogbo òye àti gbogbo okun nífẹ̀ẹ́ Rẹ̀, kó sì nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ̀ bí ara rẹ̀ ṣe pàtàkì gan-an ju gbogbo odindi ẹbọ sísun àtàwọn ẹbọ.” Nígbà tí Jésù rí i pé ìdáhùn rẹ̀ mọ́gbọ́n dání, ó sọ fún un pé: “O ò jìnnà sí Ìjọba Ọlọ́run.”—Máàkù 12:32-34.

      Ó ti tó ọjọ́ mẹ́ta báyìí tí Jésù ti ń kọ́ àwọn èèyàn nínú tẹ́ńpìlì (ìyẹn Nísàn 9, Nísàn 10 àti Nísàn 11). Ọ̀pọ̀ èèyàn ló sì ń fara balẹ̀ tẹ́tí sí i, títí kan àwọn akọ̀wé òfin. Àmọ́ àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ò nífẹ̀ẹ́ sí ohun tó ń sọ, wọn ò sì “láyà láti tún bi í ní ìbéèrè mọ́.”

      • Kí làwọn Farisí ṣe láti dán Jésù wò, kí nìyẹn sì yọrí sí?

      • Nígbà táwọn Sadusí gbìyànjú láti dán Jésù wò, kí ni Jésù sọ tó fi pa wọ́n lẹ́nu mọ́?

      • Kí ni Jésù sọ pé ó ṣe pàtàkì jù nígbà tó ń dáhùn ìbéèrè akọ̀wé òfin kan?

  • Ó Dẹ́bi Fáwọn Aṣáájú Ìsìn Tó Ń Ta Kò Ó
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
    • Jésù tú àṣírí àwọn aṣáájú ìsìn tó ń ta kò ó

      ORÍ 109

      Ó Dẹ́bi Fáwọn Aṣáájú Ẹ̀sìn Tó ń ta Kò Ó

      MÁTÍÙ 22:41–23:24 MÁÀKÙ 12:35-40 LÚÙKÙ 20:41-47

      • ỌMỌ TA NI KRISTI?

      • JÉSÙ TÚ ÀṢÍRÍ ÀWỌN ALÁGÀBÀGEBÈ TÓ Ń TA KÒ Ó

      Oríṣiríṣi ọgbọ́n làwọn aṣáájú ẹ̀sìn ti dá kí wọ́n lè mú Jésù, kí wọ́n sì fà á lé àwọn ará Róòmù lọ́wọ́, àmọ́ pàbó ni gbogbo rẹ̀ ń já sí. (Lúùkù 20:20) Inú tẹ́ńpìlì ni Jésù ṣì wà ní Nísàn 11. Àwọn alátakò yẹn ti ń béèrè oríṣiríṣi ìbéèrè, Jésù náà wá bi wọ́n ní ìbéèrè kí wọ́n lè mọ ẹni tó jẹ́ gan-an. Ó ní: “Kí lèrò yín nípa Kristi? Ọmọ ta ni?” (Mátíù 22:42) Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé ìlà ìdílé Dáfídì ni Kristi tàbí Mèsáyà á ti wá. Ohun táwọn náà sọ fún Jésù nìyẹn.—Mátíù 9:27; 12:23; Jòhánù 7:42.

      Jésù béèrè pé: “Kí wá nìdí tí Dáfídì fi pè é ní Olúwa nípasẹ̀ ìmísí, tó sọ pé, ‘Jèhófà sọ fún Olúwa mi pé: “Jókòó sí ọwọ́ ọ̀tún mi, títí màá fi fi àwọn ọ̀tá rẹ sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ”’? Tí Dáfídì bá pè é ní Olúwa, báwo ló ṣe jẹ́ ọmọ rẹ̀?”—Mátíù 22:43-45.

      Àwọn Farisí yẹn ò rí nǹkan sọ, wọ́n gbà pé ẹnì kan máa wá láti ìran Dáfídì tó máa gbà wọ́n sílẹ̀ lábẹ́ ìṣàkóso Róòmù. Àmọ́ bí Jésù ṣe fa ọ̀rọ̀ yọ látinú ohun tí Dáfídì sọ nínú Sáàmù 110:1, 2 jẹ́ kó hàn pé Mèsáyà kì í ṣe èèyàn lásán kan, ìjọba ẹ̀ ò sì ní dà bíi tàwọn èèyàn. Olúwa ni Mèsáyà jẹ́ fún Dáfídì, lẹ́yìn tó bá sì ti jókòó sí ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run, ó máa lo agbára tó ní láti ṣàkóso. Ṣe ni ìdáhùn Jésù yìí tún pa àwọn alátakò yẹn lẹ́nu mọ́.

      Àwọn ọmọ ẹ̀yìn àtàwọn èrò tó wà níbẹ̀ náà ń gbọ́ ohun tí Jésù ń sọ. Jésù wá yíjú sí wọn kó lè kìlọ̀ fún wọn nípa ìwà àwọn akọ̀wé òfin yẹn àtàwọn Farisí. Àwọn ọkùnrin yẹn ti “fi ara wọn sí orí ìjókòó Mósè” kí wọ́n lè kọ́ àwọn èèyàn ní Òfin Ọlọ́run. Jésù sọ fáwọn tó ń gbọ́rọ̀ ẹ̀ pé: “Gbogbo ohun tí wọ́n bá sọ fún yín ni kí ẹ ṣe, kí ẹ sì máa pa mọ́, àmọ́ ẹ má ṣe ohun tí wọ́n ń ṣe, torí tí wọ́n bá sọ̀rọ̀, wọn kì í ṣe ohun tí wọ́n sọ.”—Mátíù 23:2, 3.

      Jésù sọ díẹ̀ lára ohun tí wọ́n ń ṣe tó fi hàn pé alábòsí ni wọ́n, ó ní: “Wọ́n fẹ àwọn akóló tí wọ́n ń kó ìwé mímọ́ sí, èyí tí wọ́n ń dè mọ́ra láti dáàbò bo ara wọn.” Ọ̀pọ̀ àwọn Júù ló ní akóló tí wọ́n máa ń kó ìwé mímọ́ sí, wọ́n sì máa ń dè é mọ́ ìwájú orí tàbí apá wọn. Àmọ́, àwọn Farisí jẹ́ kí akóló tiwọn tóbi dáadáa, kí wọ́n lè fi hàn pé àwọn nítara. Wọ́n tún “mú kí wajawaja etí aṣọ wọn gùn.” Lóòótọ́, Òfin Ọlọ́run ló ní káwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe wajawaja sí etí aṣọ wọn, àmọ́ ṣe làwọn Farisí yẹn mú kí wajawaja tó wà létí aṣọ wọn gùn dáadáa. (Nọ́ńbà 15:38-40) “Kí àwọn èèyàn lè rí wọn” ni wọ́n ṣe ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe yẹn.—Mátíù 23:5.

      Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù náà lè bẹ̀rẹ̀ sí í wá ipò ọlá fún ara wọn, ìdí nìyẹn tó fi gbà wọ́n nímọ̀ràn pé: “Kí wọ́n má pè yín ní Rábì, torí Olùkọ́ kan lẹ ní, arákùnrin sì ni gbogbo yín. Bákan náà, ẹ má pe ẹnikẹ́ni ní baba yín ní ayé, torí Baba kan lẹ ní, Ẹni tó wà ní ọ̀run. Kí wọ́n má sì pè yín ní aṣáájú, torí Aṣáájú kan lẹ ní, Kristi.” Ojú wo ló wá yẹ káwọn ọmọ ẹ̀yìn máa fi wo ara wọn, irú ìwà wo ló sì yẹ kí wọ́n máa hù? Jésù sọ fún wọn pé: “Kí ẹni tó tóbi jù lọ láàárín yín jẹ́ ìránṣẹ́ yín. Ẹnikẹ́ni tó bá gbé ara rẹ̀ ga, a máa rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀, ẹnikẹ́ni tó bá sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, a máa gbé e ga.”—Mátíù 23:8-12.

      Lẹ́yìn náà, Jésù kéde ègbé lé àwọn akọ̀wé òfin àtàwọn Farisí tí wọ́n jẹ́ alágàbàgebè yẹn, ó ní: “Ẹ gbé, ẹ̀yin akọ̀wé òfin àti Farisí, ẹ̀yin alágàbàgebè! torí pé ẹ ti Ìjọba ọ̀run pa mọ́ àwọn èèyàn; ẹ̀yin fúnra yín ò wọlé, ẹ ò sì jẹ́ kí àwọn tó fẹ́ wọlé ráyè wọlé.”—Mátíù 23:13.

      Jésù dẹ́bi fáwọn Farisí yẹn torí pé dípò kí wọ́n mọyì ohun tí Jèhófà kà sí pàtàkì, ohun tí ò pọn dandan ni wọ́n kà sí pàtàkì. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n sọ pé: “Tí ẹnikẹ́ni bá fi tẹ́ńpìlì búra, kò ṣe nǹkan kan; àmọ́ tí ẹnikẹ́ni bá fi wúrà tẹ́ńpìlì búra, dandan ni kó ṣe ohun tó búra.” Èyí fi hàn pé wọn ò ronú lọ́nà tó tọ́ mọ́, torí pé àwọn wúrà tó wà nínú tẹ́ńpìlì ni wọ́n kà sí pàtàkì jù, dípò kí wọ́n máa rí tẹ́ńpìlì yẹn bí ilé ìjọsìn Jèhófà àti pé ibẹ̀ làwọn èèyàn ti lè wá kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà. Wọn ò sì “ka àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣe pàtàkì jù nínú Òfin sí, ìyẹn ìdájọ́ òdodo, àánú àti òtítọ́.”—Mátíù 23:16, 23; Lúùkù 11:42.

      Jésù fi àwọn Farisí yẹn wé “afọ́jú tó ń fini mọ̀nà, tó ń sẹ́ kòkòrò tín-tìn-tín, àmọ́ tó ń gbé ràkúnmí mì káló!” (Mátíù 23:24) Wọ́n ń sẹ́ kòkòrò tín-tìn-tín kúrò nínú wáìnì wọn torí pé lábẹ́ Òfin Mósè ohun àìmọ́ ni kòkòrò yìí. Àmọ́ bí wọn ò ṣe ka àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣe pàtàkì jù nínú Òfin sí dà bí ìgbà tí wọ́n bá gbé ràkúnmí mì káló. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ohun àìmọ́ náà ni ràkúnmí lábẹ́ Òfin Mósè, ó sì tóbi ju kòkòrò tín-tìn-tín tí wọ́n ń sẹ́ kúrò lọ.—Léfítíkù 11:4, 21-24.

      • Nígbà tí Jésù béèrè ohun tí Dáfídì sọ nínú Sáàmù 110 lọ́wọ́ àwọn Farisí, kí nìdí tí wọn ò fi fèsì?

      • Kí nìdí táwọn Farisí fi mú kí akóló tí wọ́n ń kó ìwé mímọ́ sí túbọ̀ fẹ̀ sí i, tí wọ́n sì mú kí wajawaja etí aṣọ wọn gùn dáadáa?

      • Ìmọ̀ràn wo ni Jésù gba àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀?

  • Ọjọ́ Tí Jésù Wá sí Tẹ́ńpìlì Kẹ́yìn
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
    • Jésù ń wo opó aláìní kan nígbà tó ń fi ẹyọ owó kéékèèké méjì sínú àpótí ìṣúra

      ORÍ 110

      Ọjọ́ Tí Jésù Wá sí Tẹ́ńpìlì Kẹ́yìn

      MÁTÍÙ 23:25–24:2 MÁÀKÙ 12:41–13:2 LÚÙKÙ 21:1-6

      • JÉSÙ TÚBỌ̀ DẸ́BI FÁWỌN AṢÁÁJÚ Ẹ̀SÌN

      • WỌ́N MÁA PA TẸ́ŃPÌLÌ RUN

      • OPÓ ALÁÌNÍ KAN FI ẸYỌ OWÓ KÉÉKÈÈKÉ MÉJÌ SÍNÚ ÀPÓTÍ ÌṢÚRA

      Lọ́jọ́ tí Jésù wá sí tẹ́ńpìlì kẹ́yìn, ṣe ló túbọ̀ ń tú àṣírí ìwà àbòsí àwọn akọ̀wé òfin àtàwọn Farisí, ó sì ń pè wọ́n ní alágàbàgebè lójú gbogbo èèyàn. Ó lo àpèjúwe kan, ó ní: “Ẹ̀ ń fọ ẹ̀yìn ife àti abọ́ mọ́, àmọ́ wọ̀bìà àti ìkẹ́rabàjẹ́ kún inú wọn. Farisí afọ́jú, kọ́kọ́ fọ inú ife àti abọ́ mọ́, kí ẹ̀yìn rẹ̀ náà lè mọ́.” (Mátíù 23:25, 26) Tó bá dọ̀rọ̀ ká pa Òfin Mósè mọ́ lórí bóyá ohun kan mọ́ tàbí kò mọ́, àwọn Farisí ò fi ṣeré rárá. Báwọn èèyàn ṣe máa kà wọ́n séèyàn pàtàkì ló gbà wọ́n lọ́kàn. Wọ́n kọ̀ láti ṣàtúnṣe sírú ẹni tí wọ́n jẹ́, kí wọ́n sì fọ ọkàn wọn mọ́.

      Bó ṣe ń wù wọ́n láti kọ́ sàréè fún àwọn wòlíì, kí wọ́n sì ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́ fi hàn pé alágàbàgebè ni wọ́n. Jésù sọ fún wọn pé, “ọmọ àwọn tó pa àwọn wòlíì ni yín.” (Mátíù 23:31) Òótọ́ ni Jésù sọ, torí wọ́n gbìyànjú àtipa òun náà.—Jòhánù 5:18; 7:1, 25.

      Jésù wá sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sáwọn aṣáájú ẹ̀sìn yìí tí wọn ò bá ronú pìwà dà, ó sọ pé: “Ẹ̀yin ejò, ọmọ paramọ́lẹ̀, báwo lẹ ṣe máa bọ́ nínú ìdájọ́ Gẹ̀hẹ́nà?” (Mátíù 23:33) Wọ́n máa ń sun ìdọ̀tí nítòsí Àfonífojì Hínómù, torí náà àpèjúwe yìí jẹ́ ká rí irú ìparun ayérayé tó máa gbẹ̀yìn àwọn akọ̀wé òfin àtàwọn Farisí burúkú yẹn.

      Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ló máa ṣojú fún Jésù, wọ́n máa di ‘wòlíì, amòye àtàwọn tó ń kọ́ni ní gbangba.’ Báwo làwọn èèyàn ṣe máa hùwà sí wọn? Jésù sọ fáwọn aṣáájú ẹ̀sìn yẹn pé: “Ẹ máa pa àwọn kan lára [àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà], ẹ sì máa kàn wọ́n mọ́gi, ẹ máa na àwọn kan lára wọn nínú àwọn sínágọ́gù yín, ẹ sì máa ṣe inúnibíni sí wọn láti ìlú dé ìlú, kí ẹ lè jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ gbogbo àwọn olódodo tí wọ́n ta sílẹ̀ ní ayé, látorí ẹ̀jẹ̀ Ébẹ́lì olódodo dórí ẹ̀jẹ̀ Sekaráyà . . . ẹni tí ẹ pa.” Ó wá kìlọ̀ pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, gbogbo nǹkan yìí máa wá sórí ìran yìí.” (Mátíù 23:34-36) Ohun tó ṣẹlẹ̀ nìyẹn lọ́dún 70 S.K. nígbà táwọn ọmọ ogun Róòmù pa Jerúsálẹ́mù run, ọ̀pọ̀ àwọn Júù ló sì bá ogun yẹn lọ.

      Nígbà tí Jésù ronú nípa gbogbo nǹkan burúkú tó máa ṣẹlẹ̀ yìí. Inú ẹ̀ bà jẹ́, ó sì sọ pé: “Jerúsálẹ́mù, Jerúsálẹ́mù, ìlú tó ń pa àwọn wòlíì, tó sì ń sọ àwọn tí a rán sí i lókùúta, wo bí mo ṣe máa ń fẹ́ kó àwọn ọmọ rẹ jọ tó lọ́pọ̀ ìgbà, bí ìgbà tí àgbébọ̀ adìyẹ ń kó àwọn ọmọ rẹ̀ jọ sábẹ́ ìyẹ́ rẹ̀! Àmọ́ ẹ ò fẹ́ bẹ́ẹ̀. Ẹ wò ó! A ti pa ilé yín tì fún yín.” (Mátíù 23:37, 38) Àwọn tó ń gbọ́rọ̀ rẹ̀ á máa rò ó pé “ilé” wo ló ń sọ. Ṣé ó lè jẹ́ tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù, tó jọ pé Ọlọ́run ń dáàbò bò ló ń sọ?

      Jésù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “Mò ń sọ fún yín pé, ó dájú pé ẹ ò ní rí mi láti ìsinsìnyí títí ẹ fi máa sọ pé, ‘Ìbùkún ni fún ẹni tó ń bọ̀ ní orúkọ Jèhófà!’” (Mátíù 23:39) Inú àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Sáàmù 118:26 ni Jésù ti fa ọ̀rọ̀ yìí yọ. Sáàmù yẹn sọ pé: “Ìbùkún ni fún ẹni tó ń bọ̀ ní orúkọ Jèhófà; à ń bù kún yín látinú ilé Jèhófà.” Ó ṣe kedere pé tí tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù bá pa run, kò sẹ́ni táá máa wá síbẹ̀ láti wá jọ́sìn Ọlọ́run mọ́.

      Jésù wá lọ sí apá ibòmíì nínú tẹ́ńpìlì, ìyẹn ibi táwọn àpótí ìṣúra máa ń wà. Àwọn àpótí ìṣúra yìí dà bíi kàkàkí, àwọn èèyàn sì máa ń fi owó sínú ẹ̀ láti ibi tó ṣí sílẹ̀ lápá òkè. Jésù wá rí ọ̀pọ̀ àwọn Júù tó ń ṣe bẹ́ẹ̀, “àwọn ọlọ́rọ̀ [náà] sì ń fi ẹyọ owó púpọ̀ síbẹ̀.” Ó tún rí opó kan tó jẹ́ aláìní nígbà tó “fi ẹyọ owó kéékèèké méjì tí ìníyelórí rẹ̀ kéré gan-an” sínú àpótí ìṣúra náà. (Máàkù 12:41, 42) Ó dájú pé Jésù mọ bínú Ọlọ́run ṣe máa dùn tó sí ẹ̀bùn tí obìnrin yẹn mú wá.

      Jésù wá pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ mọ́ra, ó sọ fún wọn pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín pé ohun tí opó aláìní yìí fi sílẹ̀ ju ti gbogbo àwọn yòókù tó fi owó sínú àwọn àpótí ìṣúra.” Lọ́nà wo? Jésù ṣàlàyé pé: “Gbogbo wọn fi síbẹ̀ látinú àjẹṣẹ́kù wọn, àmọ́ òun, láìka pé kò ní lọ́wọ́, ó fi gbogbo ohun tó ní síbẹ̀, gbogbo ohun tó ní láti gbé ẹ̀mí rẹ̀ ró.” (Máàkù 12:43, 44) Ó hàn pé irú ẹ̀mí tí obìnrin yìí ní yàtọ̀ pátápátá sí tàwọn aṣáájú ẹ̀sìn yẹn!

      Nígbà tí Nísàn 11 ń parí lọ, Jésù kúrò nínú tẹ́ńpìlì, ọjọ́ yẹn ló sì wá síbẹ̀ kẹ́yìn. Bí wọ́n ṣe ń lọ, ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ sọ pé: “Olùkọ́, wò ó! àwọn òkúta àti ilé yìí mà wuni o!” (Máàkù 13:1) Ká sòótọ́, bí ọ̀pọ̀ lára òkúta tí wọ́n fi kọ́ ògiri tẹ́ńpìlì yìí ṣe tóbi jẹ́ kó túbọ̀ lágbára, ìyẹn sì jẹ́ kó dà bíi pé títí láé ni tẹ́ńpìlì yẹn máa wà. Torí náà, ó máa yà wọ́n lẹ́nu nígbà tí Jésù sọ pé: “Ṣé o rí àwọn ilé ńlá yìí? Ó dájú pé wọn ò ní fi òkúta kan sílẹ̀ lórí òkúta míì níbí, láìwó o palẹ̀.”—Máàkù 13:2.

      Lẹ́yìn tí Jésù parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, òun àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ sọdá Àfonífojì Kídírónì, wọ́n sì lọ sí apá ibì kan lórí Òkè Ólífì. Láàárín àsìkò yìí, àwọn ọmọ ẹ̀yìn mẹ́rin kan wà nítòsí Jésù, ìyẹn Pétérù, Áńdérù, Jémíìsì àti Jòhánù. Láti ibi tí wọ́n wà, ó rọrùn fún wọn láti rí tẹ́ńpìlì, kí wọ́n sì rí bó ṣe tóbi tó.

      • Kí ni Jésù ṣe lọ́jọ́ tó wá sí tẹ́ńpìlì kẹ́yìn?

      • Kí ni Jésù sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ sí tẹ́ńpìlì yẹn lọ́jọ́ iwájú?

      • Kí nìdí tí Jésù fi sọ pé ohun tí opó yẹn fi ṣètọrẹ pọ̀ ju tàwọn ọlọ́rọ̀ lọ?

  • Àwọn Àpọ́sítélì Ní Kí Jésù Fún Àwọn Ní Àmì
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
    • Jésù dáhùn ìbéèrè tí mẹ́rin nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ bi í

      ORÍ 111

      Àwọn Àpọ́sítélì Ní Kí Jésù Fún Àwọn Ní Àmì

      MÁTÍÙ 24:3-51 MÁÀKÙ 13:3-37 LÚÙKÙ 21:7-38

      • MẸ́RIN NÍNÚ ÀWỌN ỌMỌ Ẹ̀YÌN NÍ KÍ JÉSÙ FÚN ÀWỌN NÍ ÀMÌ

      • ÀSỌTẸ́LẸ̀ JÉSÙ ṢẸ NÍ ỌGỌ́RÙN-ÚN ỌDÚN KÌÍNÍ, Ó TÚN MÁA ṢẸ LỌ́JỌ́ IWÁJÚ

      • A GBỌ́DỌ̀ WÀ LÓJÚFÒ

      Ọ̀sán ti pọ́n, ọjọ́ Tuesday Nísàn 11 ti ń parí lọ, díẹ̀ ló sì kù kí Jésù parí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ láyé. Láwọn ọjọ́ tó ṣáájú ìgbà yẹn, Jésù máa ń kọ́ àwọn èèyàn nínú tẹ́ńpìlì lọ́wọ́ ọ̀sán, ó sì máa ń sùn mọ́jú láwọn ìlú tó wà nítòsí Jerúsálẹ́mù. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló nífẹ̀ẹ́ sọ́rọ̀ Jésù, wọ́n sì máa ń “wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ní àárọ̀ kùtù kí wọ́n lè gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú tẹ́ńpìlì.” (Lúùkù 21:37, 38) Ní báyìí, Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wà lórí Òkè Ólífì, ó sì jókòó pẹ̀lú mẹ́rin lára wọn, ìyẹn Pétérù, Áńdérù, Jémíìsì àti Jòhánù.

      Ṣe làwọn ọmọ ẹ̀yìn yẹn dọ́gbọ́n wá bá Jésù lóun nìkan. Ohun tí Jésù sọ nípa tẹ́ńpìlì ló ká wọn lára, torí ó sọ pé wọn ò ní fi òkúta kan sílẹ̀ lórí òkúta míì níbẹ̀. Yàtọ̀ sí ọ̀rọ̀ tẹ́ńpìlì yẹn, àwọn nǹkan míì tún wà tí wọ́n fẹ́ bi í. Ṣáájú ìgbà yẹn, Jésù sọ fún wọn pé: “Ẹ múra sílẹ̀, torí pé wákàtí tí ẹ ò rò pé ó lè jẹ́ ni Ọmọ èèyàn ń bọ̀.” (Lúùkù 12:40) Bákan náà, Jésù sọ̀rọ̀ nípa ‘ọjọ́ tí a máa ṣí Ọmọ èèyàn payá.’ (Lúùkù 17:30) Torí náà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn yẹn lè máa rò ó pé ṣé àwọn ohun tí Jésù sọ yẹn jọra pẹ̀lú ohun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ nípa tẹ́ńpìlì yìí? Wọ́n wá bi í pé: “Sọ fún wa, ìgbà wo ni àwọn nǹkan yìí máa ṣẹlẹ̀, kí ló sì máa jẹ́ àmì pé o ti wà níhìn-ín àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan?”—Mátíù 24:3.

      Ó ṣeé ṣe kí wọ́n máa ronú nípa bí tẹ́ńpìlì tó wà níwájú wọn ṣe máa pa run. Bákan náà, bí wọ́n ṣe béèrè nípa ìgbà tí Ọmọ èèyàn máa dé, ó ṣeé ṣe kí wọ́n rántí ohun tí Jésù sọ ṣáájú ìgbà yẹn nípa “ọkùnrin kan tí wọ́n bí ní ilé ọlá” tó “rìnrìn àjò . . . kó lè lọ gba agbára láti jọba, kó sì pa dà.” (Lúùkù 19:11, 12) Ó tún ṣeé ṣe kí wọ́n máa ronú nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ ní “ìparí ètò àwọn nǹkan.”

      Nígbà tí Jésù ń dá wọn lóhùn, ó ṣàlàyé ohun tó máa ṣẹlẹ̀ nígbà tí ètò àwọn Júù bá fẹ́ wá sópin àti bí tẹ́ńpìlì tó wà níbẹ̀ ṣe máa pa run. Àmọ́, àmì tó fún wọn tún kọjá ìyẹn, torí ó wúlò fáwọn tó di Kristẹni lẹ́yìn wọn. Àmì yẹn ló máa jẹ́ kí wọ́n mọ ohun táá ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jésù bá “wà níhìn-ín,” táá sì tún jẹ́ kí wọ́n mọ̀ tí wọ́n bá ti ń sún mọ́ ìparí ètò àwọn nǹkan yìí.

      Bọ́dún ṣe ń gorí ọdún, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ń rí i bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ṣe ń ṣẹ. Ọ̀pọ̀ nǹkan tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ lójú wọn. Torí náà, ó dájú pé ọkàn àwọn Kristẹni tó wà lójúfò máa balẹ̀ nígbà tí ètò àwọn Júù àti tẹ́ńpìlì wọn bá dópin lọ́dún mẹ́tàdínlógójì (37) lẹ́yìn náà, ìyẹn lọ́dún 70 S.K. Àmọ́ o, kì í ṣe gbogbo ohun tí Jésù sọ ló ṣẹlẹ̀ ṣáájú kí Jerúsálẹ́mù tó pa run àti nígbà tó pa run lọ́dún 70 S.K. Kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jésù bá gba agbára láti ṣàkóso? Jésù jẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ mọ ìdáhùn sí ìbéèrè yìí.

      Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé wọ́n máa ‘gbọ́ nípa àwọn ogun àti ìròyìn nípa àwọn ogun,’ bákan náà “orílẹ̀-èdè máa dìde sí orílẹ̀-èdè àti ìjọba sí ìjọba.” (Mátíù 24:6, 7) Ó tún sọ pé “ìmìtìtì ilẹ̀ tó lágbára máa wáyé, àìtó oúnjẹ àti àjàkálẹ̀ àrùn sì máa wà láti ibì kan dé ibòmíì.” (Lúùkù 21:11) Jésù wá kìlọ̀ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Àwọn èèyàn máa gbé ọwọ́ wọn lé yín, wọ́n á sì ṣe inúnibíni sí yín.” (Lúùkù 21:12) Ó tún sọ pé àwọn wòlíì èké máa wà, wọ́n sì máa ṣi ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́nà. Àti pé ìwà tí kò bófin mu máa pọ̀ sí i, ìfẹ́ ọ̀pọ̀ èèyàn sì máa tutù. Jésù fi kún un pé a máa “wàásù ìhìn rere Ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé, kó lè jẹ́ ẹ̀rí fún gbogbo orílẹ̀-èdè, nígbà náà ni òpin yóò dé.”—Mátíù 24:14.

      Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ohun tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀ ló ṣẹ káwọn ará Róòmù tó pa Jerúsálẹ́mù run àti nígbà tí wọ́n pa á run, ṣé ó ṣeé ṣe káwọn ọ̀rọ̀ Jésù yẹn ṣẹ lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ lọ́jọ́ iwájú? Ṣé ìwọ náà ń rí àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Jésù sọ yẹn ń ṣẹ lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ lákòókò wa yìí?

      Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa àmì tó máa fi hàn pé ó ti wà níhìn-ín, ó tún mẹ́nu ba ohun míì. Ó sọ pé wọ́n máa rí “ohun ìríra tó ń fa ìsọdahoro.” (Mátíù 24:15) Lọ́dún 66 S.K., ohun ìríra yẹn fara hàn nígbà táwọn abọ̀rìṣà, ìyẹn àwọn “ọmọ ogun [Róòmù] pàgọ́ yí Jerúsálẹ́mù ká,” tí wọ́n sì gbé àsíá wọn wá síbẹ̀. Wọ́n yí ìlú náà ká, wọ́n sì wó apá kan lára ògiri rẹ̀. (Lúùkù 21:20) Àwọn ni “ohun ìríra” tó dúró síbi táwọn Júù gbà pé ó jẹ́ “ibi mímọ́.”

      Jésù tún sọ nǹkan míì tó máa ṣẹlẹ̀, ó ní: “Ìpọ́njú ńlá máa wà nígbà náà, irú èyí tí kò tíì ṣẹlẹ̀ rí láti ìbẹ̀rẹ̀ ayé títí di báyìí, àní, irú rẹ̀ kò ní ṣẹlẹ̀ mọ́.” Lọ́dún 70 S.K., àwọn ọmọ ogun Róòmù pa Jerúsálẹ́mù run. Ìpọ́njú ńlá ló wáyé nígbà yẹn torí ọgọ́rọ̀ọ̀rún èèyàn ló kú, wọ́n ṣẹ́gun Jerúsálẹ́mù táwọn Júù kà sí ‘ìlú mímọ́,’ wọ́n sì run tẹ́ńpìlì rẹ̀. (Mátíù 4:5; 24:21) Ìparun yẹn burú gan-an torí pé irú ẹ̀ ò ṣẹlẹ̀ rí nínú ìtàn àwọn Júù, ìyẹn ló sì fòpin sí ọ̀nà táwọn Júù ń gbà jọ́sìn Ọlọ́run fún ọ̀pọ̀ ọdún. Tí àsọtẹ́lẹ̀ Jésù bá ṣẹ lọ́nà tó lágbára nígbà yẹn, ó dájú pé bó ṣe máa ṣẹ lọ́jọ́ iwájú máa bani lẹ́rù gan-an.

      JÉSÙ FI WỌ́N LỌ́KÀN BALẸ̀ NÍPA OHUN TÓ MÁA ṢẸLẸ̀ LỌ́JỌ́ IWÁJÚ

      Jésù ò tíì parí ọ̀rọ̀ tó ń bá àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ sọ nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ nígbà tó bá gba agbára láti ṣàkóso àti bí nǹkan ṣe máa rí ní ìparí ètò àwọn nǹkan. Ó wá kìlọ̀ fún wọn pé kí wọ́n ṣọ́ra nítorí “àwọn èké Kristi àti àwọn wòlíì èké.” Jésù jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé àwọn wòlíì yẹn máa gbìyànjú “láti ṣi àwọn àyànfẹ́ pàápàá lọ́nà, tó bá ṣeé ṣe.” (Mátíù 24:24) Àmọ́ wọn ò ní lè ṣì wọ́n lọ́nà. Àwọn èké Kristi á fẹ́ káwọn èèyàn gbà pé àwọn máa rí Jésù lójúkojú. Àmọ́ ọ̀rọ̀ Jésù ò ní rí bẹ́ẹ̀, torí àwọn èèyàn ò ní rí i sójú nígbà tó bá dé.

      Nígbà tí Jésù ń ṣàlàyé bí ìpọ́njú ńlá tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú ṣe máa rí, ó sọ pé: “Oòrùn máa ṣókùnkùn, òṣùpá ò sì ní mọ́lẹ̀, àwọn ìràwọ̀ máa já bọ́ láti ọ̀run, a sì máa mi àwọn agbára ọ̀run.” (Mátíù 24:29) Ohun tí Jésù sọ fáwọn àpọ́sítélì yẹn bà wọ́n lẹ́rù, bí wọn ò tiẹ̀ lóye bí nǹkan ṣe máa rí, ó dájú pé nǹkan máa le gan-an nígbà yẹn.

      Kí làwọn èèyàn máa ṣe nígbà táwọn nǹkan yẹn bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹlẹ̀? Jésù sọ pé: “Àwọn èèyàn máa kú sára nítorí ìbẹ̀rù àti àwọn ohun tí wọ́n ń retí pé ó máa ṣẹlẹ̀ ní ilẹ̀ ayé tí à ń gbé, torí a máa mi àwọn agbára ọ̀run.” (Lúùkù 21:26) Ká sòótọ́, àsìkò yẹn ló máa ṣókùnkùn jù lọ nínú ìtàn ẹ̀dá èèyàn.

      Inú wa dùn bí Jésù ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo èèyàn láá máa kérora nígbà tí ‘ọmọ èèyàn bá ń bọ̀ pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá.’ (Mátíù 24:30) Ó sọ pé Ọlọ́run máa dá sí ọ̀rọ̀ náà “nítorí àwọn àyànfẹ́.” (Mátíù 24:22) Torí náà, kí ló yẹ káwọn ọmọ ẹ̀yìn tó bá jẹ́ olóòótọ́ ṣe nígbà tí wọ́n bá rí i tí gbogbo nǹkan yìí ń ṣẹlẹ̀? Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Tí àwọn nǹkan yìí bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹlẹ̀, ẹ nàró ṣánṣán, kí ẹ sì gbé orí yín sókè, torí ìdáǹdè yín ń sún mọ́lé.”—Lúùkù 21:28.

      Kí ló máa wá jẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn tó wà láyé nígbà yẹn mọ bí òpin ṣe sún mọ́lé tó? Jésù sọ àpèjúwe igi ọ̀pọ̀tọ́, ó ní: “Gbàrà tí ẹ̀ka rẹ̀ bá ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ ọ̀mùnú, tó sì rúwé, ẹ mọ̀ pé ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ti sún mọ́lé. Bákan náà, tí ẹ bá rí gbogbo nǹkan yìí, kí ẹ mọ̀ pé ó ti sún mọ́ ẹnu ọ̀nà. Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín pé, ó dájú pé ìran yìí ò ní kọjá lọ títí gbogbo nǹkan yìí fi máa ṣẹlẹ̀.”—Mátíù 24:32-34.

      Torí náà, táwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù bá ti ń rí oríṣiríṣi àmì tí Jésù sọ, wọ́n máa mọ̀ pé òpin ti sún mọ́lé. Jésù wá sọ ohun kan tó yẹ káwọn ọmọ ẹ̀yìn tó bá wà láyé nígbà yẹn fi sọ́kàn, ó ní:

      “Ní ti ọjọ́ àti wákàtí yẹn, kò sí ẹni tó mọ̀ ọ́n, àwọn áńgẹ́lì ọ̀run àti Ọmọ pàápàá kò mọ̀ ọ́n, àfi Baba nìkan. Torí bí àwọn ọjọ́ Nóà ṣe rí gẹ́lẹ́ ló máa rí tí Ọmọ èèyàn bá ti wà níhìn-ín. Torí bó ṣe rí ní àwọn ọjọ́ yẹn ṣáájú Ìkún Omi, wọ́n ń jẹ, wọ́n sì ń mu, àwọn ọkùnrin ń gbéyàwó, a sì ń fa àwọn obìnrin fún ọkọ, títí di ọjọ́ tí Nóà wọ ọkọ̀ áàkì, wọn ò fiyè sí i títí Ìkún Omi fi dé, tó sì gbá gbogbo wọn lọ, bẹ́ẹ̀ náà ni wíwàníhìn-ín Ọmọ èèyàn máa rí.” (Mátíù 24:36-39) Ìkún Omi tó wáyé nígbà ayé Nóà dé ibi gbogbo láyé, torí náà, Jésù fi ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà yẹn wé ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.

      Ó dájú pé àwọn àpọ́sítélì tí Jésù ń bá sọ̀rọ̀ lórí Òkè Ólífì yẹn máa rí i pé ó ṣe pàtàkì káwọn wà lójúfò. Jésù sọ pé: “Ẹ kíyè sí ara yín, kí àjẹjù, ọtí àmujù àti àníyàn ìgbésí ayé má bàa di ẹrù pa ọkàn yín, láìròtẹ́lẹ̀ kí ọjọ́ yẹn sì dé bá yín lójijì bí ìdẹkùn. Torí ó máa dé bá gbogbo àwọn tó ń gbé ní gbogbo ayé. Torí náà, ẹ máa wà lójúfò, kí ẹ máa rawọ́ ẹ̀bẹ̀ nígbà gbogbo, kí ẹ lè bọ́ nínú gbogbo nǹkan tó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ yìí, kí ẹ sì lè dúró níwájú Ọmọ èèyàn.”—Lúùkù 21:34-36.

      Ohun tí Jésù sọ yìí túbọ̀ tẹ̀ ẹ́ mọ́ wọn lọ́kàn pé ọ̀rọ̀ yẹn máa lágbára gan-an. Kì í ṣe ohun tó máa ṣẹlẹ̀ ní ọdún bíi mélòó kan sígbà yẹn nìkan ni Jésù ń sọ, ìyẹn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù tó sì máa kan àwọn Júù. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó “máa dé bá gbogbo àwọn tó ń gbé ní gbogbo ayé” ni Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.

      Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa ṣọ́nà, kí wọ́n wà lójúfò, kí wọ́n sì múra sílẹ̀. Jésù tún fi àpèjúwe míì ṣàlàyé bí ìyẹn ṣe ṣe pàtàkì tó, ó sọ pé: “Ẹ mọ ohun kan: Ká ní baálé ilé mọ ìṣọ́ tí olè ń bọ̀ ni, ì bá má sùn, kò sì ní jẹ́ kí wọ́n ráyè wọ ilé òun. Torí èyí, kí ẹ̀yin náà múra sílẹ̀, torí wákàtí tí ẹ kò ronú pé ó máa jẹ́ ni Ọmọ èèyàn ń bọ̀.”—Mátíù 24:43, 44.

      Jésù sọ ohun kan tó máa fi àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ́kàn balẹ̀. Ó jẹ́ kó dá wọn lójú pé “ẹrú” kan máa wà nígbà tí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn bá ń ṣẹ, ẹrú yẹn máa mọṣẹ́ ẹ̀ níṣẹ́, á sì wà lójúfò. Jésù lo àpèjúwe kan tó máa tètè yé wọn, ó ní: “Ní tòótọ́, ta ni ẹrú olóòótọ́ àti olóye tí ọ̀gá rẹ̀ yàn pé kó máa bójú tó àwọn ará ilé rẹ̀, kó máa fún wọn ní oúnjẹ wọn ní àkókò tó yẹ? Aláyọ̀ ni ẹrú yẹn tí ọ̀gá rẹ̀ bá dé, tó sì rí i tó ń ṣe bẹ́ẹ̀! Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ó máa yàn án pé kó máa bójú tó gbogbo ohun ìní rẹ̀.” Àmọ́ tí “ẹrú” yẹn bá lọ yíwà pa dà, tó sì ń fìyà jẹ àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ ẹrú, ọ̀gá rẹ̀ “máa fi ìyà tó le jù lọ jẹ ẹ́.”—Mátíù 24:45-51; fi wé Lúùkù 12:45, 46.

      Jésù ò sọ pé àwọn kan lára àwọn ọmọlẹ́yìn òun máa di ẹni burúkú. Kí ni Jésù wá fẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ mọ̀? Ó fẹ́ kí wọ́n wà lójúfò, kí wọ́n sì mọṣẹ́ wọn níṣẹ́. Jésù ṣàlàyé ìyẹn nínú àpèjúwe míì tó tẹ̀ lé e.

      • Kí nìdí táwọn àpọ́sítélì fi béèrè nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, àmọ́ kí ló ṣeé ṣe kó tún wà lọ́kàn wọn?

      • Ìgbà wo ni àsọtẹ́lẹ̀ Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ, báwo ló sì ṣe ṣẹ?

      • Àwọn nǹkan wo láá máa ṣẹlẹ̀ táá fi hàn pé Kristi ti wà níhìn-ín?

      • Báwo ni “ohun ìríra” náà ṣe fara hàn, kí ló sì ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tó fara hàn?

      • Kí làwọn èèyàn máa ṣe nígbà tí wọ́n bá rí i tí àsọtẹ́lẹ̀ Jésù ń ṣẹ?

      • Àpèjúwe wo ni Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ tí wọ́n á fi mọ̀ pé òpin ti sún mọ́?

      • Kí ló fi hàn pé àsọtẹ́lẹ̀ Jésù máa ṣẹ ní gbogbo ayé?

      • Ìmọ̀ràn wo ni Jésù gba àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ bí ètò àwọn nǹkan yìí ṣe ń lọ sópin?

  • Ẹ̀kọ́ Tí Àpèjúwe Wúńdíá Mẹ́wàá Kọ́ Wa
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
    • Àwọn wúńdíá márùn-ún tó jẹ́ olóye tan fìtílà wọn

      ORÍ 112

      Ẹ̀kọ́ Tí Àpèjúwe Wúńdíá Mẹ́wàá Kọ́ Wa

      MÁTÍÙ 25:1-13

      • JÉSÙ SỌ ÀPÈJÚWE NÍPA WÚŃDÍÁ MẸ́WÀÁ

      Jésù ti ń dáhùn ìbéèrè táwọn àpọ́sítélì ẹ̀ bi í nípa àmì tó máa fi hàn pé ó ti wà níhìn-ín àti àmì ìparí ètò àwọn nǹkan. Orí ọ̀rọ̀ yẹn náà ni wọ́n ṣì wà, ó wá sọ àpèjúwe míì fún wọn láti gbà wọ́n níyànjú. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó bá wà láyé nígbà tí Jésù bá wà níhìn-ín ló máa rí bí àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ṣe ń ṣẹ.

      Ó bẹ̀rẹ̀ àpèjúwe náà báyìí, ó ní: “A lè fi Ìjọba ọ̀run wé wúńdíá mẹ́wàá tí wọ́n mú fìtílà wọn, tí wọ́n sì jáde lọ pàdé ọkọ ìyàwó. Márùn-ún nínú wọ́n jẹ́ òmùgọ̀, márùn-ún sì jẹ́ olóye.”—Mátíù 25:1, 2.

      Kì í ṣe ohun tí Jésù ń sọ ni pé ìdajì nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó máa jogún Ìjọba ọ̀run á ya òmùgọ̀, tí ìdajì tó kù á wá jẹ́ olóye. Àmọ́ ohun tó ń sọ ni pé ọmọ ẹ̀yìn kọ̀ọ̀kan tó bá máa jogún Ìjọba náà máa ní láti pinnu bóyá òun máa wà lójúfò, àbí òun máa jẹ́ kí nǹkan míì gba òun lọ́kàn. Síbẹ̀, ọkàn Jésù balẹ̀ pé àwọn ìránṣẹ́ òun máa jẹ́ olóòótọ́ délẹ̀, Baba òun á sì bù kún wọn.

      Nínú àpèjúwe yẹn, àwọn wúńdíá mẹ́wẹ̀ẹ̀wá máa lọ pàdé ọkọ ìyàwó náà, kí wọ́n lè kí i káàbọ̀, kí wọ́n sì jọ máa bá ètò ìgbéyàwó lọ. Tí ọkọ ìyàwó náà bá dé, àwọn wúńdíá yẹn máa tan fìtílà wọn kí ojú ọ̀nà lè mọ́lẹ̀, kí wọ́n sì yẹ́ ọkọ ìyàwó sí bó ṣe ń mú ìyàwó rẹ̀ lọ sí yàrá tó ti ṣètò. Àmọ́ kí ló wá ṣẹlẹ̀?

      Jésù ṣàlàyé pé: “Àwọn òmùgọ̀ mú fìtílà wọn, àmọ́ wọn ò gbé òróró dání, ṣùgbọ́n àwọn olóye rọ òróró sínú ìgò wọn, wọ́n sì gbé fìtílà wọn dání. Nígbà tí ọkọ ìyàwó ò tètè dé, gbogbo wọn tòògbé, wọ́n sì sùn lọ.” (Mátíù 25:3-5) Ọkọ ìyàwó ò tètè dé bí wọ́n ṣe rò. Ó jọ pé ó pẹ́ gan-an kó tó dé, torí àwọn wúńdíá yẹn sùn lọ níbi tí wọ́n ti ń dúró dè é. Ó ṣeé ṣe kíyẹn rán àwọn àpọ́sítélì létí ohun tí Jésù sọ fún wọn nípa ọkùnrin kan tí wọ́n bí ní ilé ọlá, tó rìnrìn àjò tó sì “pa dà dé lẹ́yìn tó gba agbára láti jọba.”—Lúùkù 19:11-15.

      Jésù wá ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí ọkọ ìyàwó dé, ó ní: “Ni ariwo bá sọ láàárín òru pé: ‘Ọkọ ìyàwó ti dé! Ẹ jáde lọ pàdé rẹ̀.’” (Mátíù 25:6) Ṣé àwọn wúńdíá yẹn múra sílẹ̀, ṣé wọ́n sì wà lójúfò?

      Jésù ń bá ọ̀rọ̀ ẹ̀ lọ, ó ní: “Gbogbo àwọn wúńdíá náà bá dìde, wọ́n sì tún fìtílà wọn ṣe. Àwọn òmùgọ̀ sọ fún àwọn olóye pé, ‘Ẹ fún wa ní díẹ̀ nínú òróró yín, torí pé àwọn fìtílà wa ti fẹ́ kú.’ Àwọn olóye dá wọn lóhùn pé: ‘Ó ṣeé ṣe kó má tó àwa àti ẹ̀yin. Torí náà, ẹ lọ sọ́dọ̀ àwọn tó ń tà á, kí ẹ sì ra tiyín.’”—Mátíù 25:7-9.

      Àwọn wúńdíá márùn-ún tí wọ́n jẹ́ òmùgọ̀ yẹn ò wà lójúfò, wọn ò sì múra sílẹ̀ de ọkọ ìyàwó. Òróró inú fìtílà wọn ò tó, wọ́n máa ní láti lọ wá òróró sí i. Jésù wá sọ pé: “Bí wọ́n ṣe ń lọ rà á, ọkọ ìyàwó dé. Àwọn wúńdíá tí wọ́n ti ṣe tán bá a wọlé síbi àsè ìgbéyàwó náà, a sì ti ilẹ̀kùn. Lẹ́yìn náà, àwọn wúńdíá yòókù dé, wọ́n ní, ‘Ọ̀gá, Ọ̀gá, ṣílẹ̀kùn fún wa!’ Ó dá wọn lóhùn pé, ‘Kí n sọ òótọ́ fún yín, mi ò mọ̀ yín rí.’” (Mátíù 25:10-12) Ó mà ṣe o, ẹ wo ibi tọ́rọ̀ wọn já sí torí pé wọn ò múra sílẹ̀, wọn ò sì wà lójúfò!

      Ó yé àwọn àpọ́sítélì pé Jésù ni ọkọ ìyàwó inú àpèjúwe yẹn dúró fún, torí ó tiẹ̀ ti fi ara ẹ̀ wé ọkọ ìyàwó tẹ́lẹ̀. (Lúùkù 5:34, 35) Àwọn wo wá ni àwọn wúńdíá tó jẹ́ olóye yẹn? Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa “agbo kékeré” tó máa jogún Ìjọba náà, ó sọ pé: “Ẹ múra, kí ẹ sì wà ní sẹpẹ́, kí ẹ jẹ́ kí àwọn fìtílà yín máa jó.” (Lúùkù 12:32, 35) Torí náà, ó yé àwọn àpọ́sítélì pé àwọn ló dúró fún àwọn wúńdíá tí Jésù ń sọ yẹn. Àmọ́ ẹ̀kọ́ wo ni Jésù fẹ́ fi àpèjúwe yìí kọ́ wọn?

      Jésù fẹ́ kí ohun tí òun ń sọ yé wọn. Ó parí àpèjúwe tó ń sọ, ó ní: “Torí náà, ẹ máa ṣọ́nà, torí pé ẹ ò mọ ọjọ́ tàbí wákàtí náà.”—Mátíù 25:13.

      Ó hàn pé Jésù fẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ olóòótọ́ “máa ṣọ́nà” de ìgbà tí òun máa dé. Wọ́n gbọ́dọ̀ múra sílẹ̀, kí wọ́n sì wà lójúfò bíi tàwọn wúńdíá márùn-ún tó jẹ́ olóye yẹn, kó lè jẹ́ pé tí Jésù bá dé, ìbùkún tó ṣeyebíye tí wọ́n ń retí á tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́.

      • Tó bá dọ̀rọ̀ kéèyàn wà lójúfò, kó sì múra sílẹ̀, ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín àwọn wúńdíá márùn-ún tó jẹ́ olóye àtàwọn márùn-ún tó jẹ́ òmùgọ̀?

      • Ta ni ọkọ ìyàwó dúró fún, ta sì ni àwọn wúńdíá náà dúró fún?

      • Ẹ̀kọ́ wo ni Jésù fẹ́ fi àpèjúwe wúńdíá mẹ́wàá kọ́ wa?

  • Ẹ̀kọ́ Tí Àpèjúwe Tálẹ́ńtì Kọ́ Wa
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
    • Ẹrú kan ń ri àpò owó mọ́lẹ̀

      ORÍ 113

      Ẹ̀kọ́ Tí Àpèjúwe Tálẹ́ńtì Kọ́ Wa

      MÁTÍÙ 25:14-30

      • JÉSÙ SỌ ÀPÈJÚWE TÁLẸ́ŃTÌ

      Jésù àti mẹ́rin lára àwọn àpọ́sítélì ẹ̀ ṣì jọ wà lápá ibì kan náà lórí Òkè Ólífì, ó wá sọ àpèjúwe míì fún wọn. Lọ́jọ́ mélòó kan sẹ́yìn, nígbà tó ṣì wà ní Jẹ́ríkò, ó sọ àpèjúwe mínà fún wọn kí wọ́n lè rí i pé Ìjọba yẹn ṣì máa pẹ́ kó tó dé. Àpèjúwe tó sọ lọ́tẹ̀ yìí náà jọra pẹ̀lú èyí tó sọ tẹ́lẹ̀. Àpèjúwe yìí wà lára ohun tó fi dáhùn ìbéèrè táwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ bi í nípa àmì tó máa fi hàn pé ó ti wà níhìn-ín àti àmì ìparí ètò àwọn nǹkan. Ó jẹ́ kí wọ́n rí i pé wọ́n gbọ́dọ̀ fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ tóun fẹ́ gbé fún wọn.

      Jésù bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ní: “Ṣe ló dà bí ọkùnrin kan tó fẹ́ rìnrìn àjò lọ sí ilẹ̀ òkèèrè, tó wá pe àwọn ẹrú rẹ̀, tó sì fa àwọn ohun ìní rẹ̀ lé wọn lọ́wọ́.” (Mátíù 25:14) Nínú àpèjúwe tí Jésù ṣe tẹ́lẹ̀, ó fi ara ẹ̀ wé ọkùnrin tó rìnrìn àjò ọ̀nà jíjìn “kó lè lọ gba agbára láti jọba,” torí náà, ó tètè yé àwọn àpọ́sítélì ẹ̀ pé òun náà tún ni “ọkùnrin” tó ń sọ nínú àpèjúwe yìí.—Lúùkù 19:12.

      Kí ọkùnrin inú àpèjúwe yẹn tó rìnrìn àjò, ó fi àwọn ohun ìní rẹ̀ tó ṣeyebíye síkàáwọ́ àwọn ẹrú rẹ̀. Láàárín ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ tí Jésù fi ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ló gbájú mọ́, ó sì dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ láti ṣe iṣẹ́ yìí. Ní báyìí tí Jésù ti ń lọ, ọkàn ẹ̀ balẹ̀ pé wọ́n á ṣe iṣẹ́ yìí bó ṣe ní kí wọ́n ṣe é.—Mátíù 10:7; Lúùkù 10:1, 8, 9; fi wé Jòhánù 4:38; 14:12.

      Báwo ni ọkùnrin inú àpèjúwe yẹn ṣe pín àwọn ohun ìní rẹ̀? Jésù sọ pé: “Ó fún ọ̀kan ní tálẹ́ńtì márùn-ún, ó fún òmíràn ní méjì, òmíràn ní ọ̀kan, ó fún kálukú bí agbára rẹ̀ ṣe mọ, ó sì lọ sí ilẹ̀ òkèèrè.” (Mátíù 25:15) Kí làwọn ẹrú yìí máa wá fi tálẹ́ńtì náà ṣe? Ṣé wọ́n máa fọwọ́ pàtàkì mú ohun tí ọ̀gá wọn fi síkàáwọ́ wọn? Jésù sọ fáwọn àpọ́sítélì ẹ̀ pé:

      “Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ẹni tó gba tálẹ́ńtì márùn-ún lọ, ó fi ṣòwò, ó sì jèrè márùn-ún sí i. Bákan náà, ẹni tó gba méjì jèrè méjì sí i. Àmọ́ ẹrú tó gba ẹyọ kan ṣoṣo lọ, ó gbẹ́ ilẹ̀, ó sì fi owó ọ̀gá rẹ̀ pa mọ́.” (Mátíù 25:16-18) Kí ló máa ṣẹlẹ̀ tí ọ̀gá bá dé?

      Jésù ń bá ọ̀rọ̀ ẹ̀ lọ, ó ní: “Lẹ́yìn tó ti pẹ́ gan-an, ọ̀gá àwọn ẹrú yẹn dé, wọ́n sì jọ yanjú ọ̀rọ̀ owó.” (Mátíù 25:19) Àwọn ẹrú méjì àkọ́kọ́ ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe, ‘bí agbára wọn ṣe mọ.’ Wọ́n ṣiṣẹ́ kára, wọn ò sì ṣọ̀lẹ, kódà wọ́n tún jèrè kún ohun tí ọ̀gá wọn fún wọn. Ẹni tó gba tálẹ́ńtì márùn-ún jèrè márùn-ún sí i, ẹni tó sì gba méjì náà jèrè méjì sí i. (Láyé ìgbà yẹn, nǹkan bí ọdún mọ́kàndínlógún (19) lẹnì kan máa fi ṣiṣẹ́ kó tó lè rí owó tó máa tó tálẹ́ńtì kan.) Ohun kan náà ni ọ̀gá wọn sọ nígbà tó ń yin àwọn méjèèjì, ó ní: “O káre láé, ẹrú rere àti olóòótọ́! O jẹ́ olóòótọ́ lórí ohun díẹ̀. Màá fi ohun tó pọ̀ síkàáwọ́ rẹ. Bọ́ sínú ayọ̀ ọ̀gá rẹ.”—Mátíù 25:21.

      1. Ẹrú kan ń ri àpò owó mọ́lẹ̀; 2. Wọ́n ju ẹrú yìí kan náà síta nínú òkùnkùn

      Àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ fún ẹrú tó gba tálẹ́ńtì kan. Ó sọ fún ọ̀gá rẹ̀ pé: “Ọ̀gá, ẹni tó ṣòroó tẹ́ lọ́rùn ni mo mọ̀ ọ́ sí, o máa ń kárúgbìn níbi tí o ò fúnrúgbìn sí, o sì máa ń kó ọkà jọ níbi tí o ò ti fẹ́ ọkà. Torí náà, ẹ̀rù bà mí, mo sì lọ fi tálẹ́ńtì rẹ pa mọ́ sínú ilẹ̀. Wò ó, gba nǹkan rẹ.” (Mátíù 25:24, 25) Kò tọ́jú owó náà pa mọ́ sí báǹkì kí ọ̀gá ẹ̀ tiẹ̀ lè rí èrè díẹ̀ jẹ lórí ẹ̀. Torí náà, kò wá ire ọ̀gá ẹ̀.

      Abájọ tí ọ̀gá ẹ̀ fi pè é ní “ẹrú burúkú tó ń lọ́ra.” Ṣe ni wọ́n gba ohun tó wà lọ́wọ́ rẹ̀, wọ́n sì fún ẹrú míì tó ṣe tán láti fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́. Ọ̀gá náà wá fi ìlànà kan lélẹ̀, ó ní: “Gbogbo ẹni tó bá ní, a máa fi kún èyí tó ní, ó sì máa ní ọ̀pọ̀ yanturu. Àmọ́ ẹni tí kò bá ní, a máa gba èyí tó ní pàápàá kúrò lọ́wọ́ rẹ̀.”—Mátíù 25:26, 29.

      Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ń wàásù

      Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ ló wà fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù nínú àpèjúwe kan ṣoṣo tó sọ yìí. Wọ́n rí i pé nǹkan kékeré kọ́ ni àǹfààní tó ṣeyebíye tí Jésù fi síkàáwọ́ wọn, ìyẹn pé kí wọ́n sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. Ó sì retí pé kí wọ́n fọwọ́ pàtàkì mú àǹfààní yìí. Jésù ò retí pé ohun kan náà ni gbogbo wọn máa ṣe bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́ ìwàásù tó ní kí wọ́n ṣe. Bó ṣe sọ nínú àpèjúwe tó ṣe, kálukú máa ṣe “bí agbára rẹ̀ ṣe mọ.” Àmọ́ èyí ò túmọ̀ sí pé inú Jésù máa dùn sí èyí tó bá ń “lọ́ra” nínú wọn, tí ò sì ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti wá ire Ọ̀gá rẹ̀.

      Ẹ wo bínú àwọn àpọ́sítélì ṣe máa dùn tó nígbà tí Jésù fi dá wọn lójú pé: “Gbogbo ẹni tó bá ní, a máa fi kún èyí tó ní”!

      • Nínú àpèjúwe tálẹ́ńtì, ta ni ọ̀gá náà dúró fún, ta sì ni àwọn ẹrú dúró fún?

      • Ẹ̀kọ́ wo ni Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀?

  • Kristi Ṣèdájọ́ Àgùntàn àti Ewúrẹ́
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
    • Àwọn èèyàn láti gbogbo orílẹ̀-èdè ń wòkè, wọ́n ń retí ìdájọ́ tí Jésù máa ṣe

      ORÍ 114

      Kristi Máa Ṣèdájọ́ Àgùntàn Àti Ewúrẹ́

      MÁTÍÙ 25:31-46

      • JÉSÙ SỌ ÀPÈJÚWE NÍPA ÀGÙNTÀN ÀTI EWÚRẸ́

      Orí Òkè Ólífì ni Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣì wà. Jésù ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ àpèjúwe wúńdíá mẹ́wàá àti tálẹ́ńtì láti dáhùn ìbéèrè táwọn àpọ́sítélì rẹ̀ bi í nípa àmì tó máa fi hàn pé ó ti wà níhìn-ín àti àmì ìparí ètò àwọn nǹkan. Báwo ló ṣe wá parí ọ̀rọ̀ rẹ̀? Ó sọ àpèjúwe kan sí i, ìyẹn nípa àgùntàn àti ewúrẹ́.

      Jésù kọ́kọ́ ṣàlàyé ohun tó fẹ́ mẹ́nu bà nínú àpèjúwe náà, ó ní: “Tí Ọmọ èèyàn bá dé nínú ògo rẹ̀, tòun ti gbogbo áńgẹ́lì pẹ̀lú rẹ̀, nígbà náà, ó máa jókòó sórí ìtẹ́ ògo rẹ̀.” (Mátíù 25:31) Jésù jẹ́ kó ṣe kedere pé òun gan-an ni àpèjúwe yìí dá lé, torí ó sábà máa ń pe ara rẹ̀ ní “Ọmọ èèyàn.”—Mátíù 8:20; 9:6; 20:18, 28.

      Jésù jókòó sórí ìtẹ́ ògo rẹ̀, ó sì ya àwọn olódodo tó fi wé àgùntàn sọ́tọ̀

      Ìgbà wo ni àpèjúwe yìí máa ṣẹ? Ó máa ṣẹ nígbà tí Jésù “bá dé nínú ògo rẹ̀” tòun ti àwọn áńgẹ́lì, tó sì jókòó “sórí ìtẹ́ ògo rẹ̀.” Ó ti sọ̀rọ̀ tẹ́lẹ̀ nípa “Ọmọ èèyàn tó ń bọ̀ lórí àwọsánmà ojú ọ̀run pẹ̀lú agbára àti ògo ńlá” tóun ti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀. Ìgbà wo nìyẹn máa ṣẹlẹ̀? “Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ lẹ́yìn ìpọ́njú” ni. (Mátíù 24:29-31; Máàkù 13:26, 27; Lúùkù 21:27) Torí náà, ìgbà tí Jésù bá dé nínú ògo rẹ̀ lọ́jọ́ iwájú ni àpèjúwe yìí máa ṣẹ. Kí ni Jésù máa wá ṣe nígbà yẹn?

      Jésù ṣàlàyé pé: “Tí Ọmọ èèyàn bá dé . . . , a máa kó gbogbo orílẹ̀-èdè jọ síwájú rẹ̀, ó sì máa ya àwọn èèyàn sọ́tọ̀ọ̀tọ̀, bí olùṣọ́ àgùntàn ṣe ń ya àgùntàn sọ́tọ̀ kúrò lára ewúrẹ́. Ó máa kó àwọn àgùntàn sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, àmọ́ ó máa kó àwọn ewúrẹ́ sí òsì rẹ̀.”—Mátíù 25:31-33.

      Jésù wá sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sáwọn àgùntàn tó yà sọ́tọ̀, tó sì ṣojúure sí, ó ní: “Ọba máa wá sọ fún àwọn tó wà ní ọ̀tún rẹ̀ pé: ‘Ẹ wá, ẹ̀yin tí Baba mi ti bù kún, ẹ jogún Ìjọba tí a ti pèsè sílẹ̀ fún yín látìgbà ìpìlẹ̀ ayé.’” (Mátíù 25:34) Kí nìdí táwọn àgùntàn fi rí ojúure Ọba yẹn?

      Ọba náà ṣàlàyé pé: “Ebi pa mí, ẹ sì fún mi ní oúnjẹ; òùngbẹ gbẹ mí, ẹ sì fún mi ní nǹkan mu. Mo jẹ́ àjèjì, ẹ sì gbà mí lálejò; mo wà ní ìhòòhò, ẹ sì fi aṣọ wọ̀ mí. Mo ṣàìsàn, ẹ sì tọ́jú mi. Mo wà lẹ́wọ̀n, ẹ sì wá wò mí.” Nígbà táwọn àgùntàn yẹn, ìyẹn “àwọn olódodo” béèrè pé ìgbà wo làwọn ṣe àwọn nǹkan rere yìí, ó dáhùn pé: “Torí pé ẹ ti ṣe é fún ọ̀kan lára àwọn arákùnrin mi tó kéré jù lọ yìí, ẹ ti ṣe é fún mi.” (Mátíù 25:35, 36, 40, 46) Ọ̀run kọ́ ni wọ́n ti ṣe àwọn nǹkan rere yìí, torí kò sí aláìsàn lọ́run, ebi kì í sì í pa wọ́n lọ́run. Ó dájú pé àwọn arákùnrin Kristi tó wà láyé ni wọ́n ṣe ohun rere yìí fún.

      Ó fi àwọn aláìṣòdodo wé ewúrẹ́

      Kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ sáwọn ewúrẹ́ tó wà lápá òsì? Jésù sọ pé: “[Ọba náà] máa wá sọ fún àwọn tó wà ní òsì rẹ̀ pé: ‘Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin tí a ti gégùn-ún fún, ẹ lọ sínú iná àìnípẹ̀kun tí a ṣètò sílẹ̀ fún Èṣù àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀. Nítorí ebi pa mí, àmọ́ ẹ ò fún mi ní oúnjẹ; òùngbẹ gbẹ mí, àmọ́ ẹ ò fún mi ní nǹkan kan mu. Mo jẹ́ àjèjì, àmọ́ ẹ ò gbà mí lálejò; mo wà ní ìhòòhò, àmọ́ ẹ ò fi aṣọ wọ̀ mí; mo ṣàìsàn, mo sì wà lẹ́wọ̀n, àmọ́ ẹ ò tọ́jú mi.’” (Mátíù 25:41-43) Ìdájọ́ tó tọ́ sí àwọn ewúrẹ́ yẹn nìyẹn torí pé wọn ò ṣe ohun rere sáwọn arákùnrin Kristi tó wà láyé, bó ṣe yẹ kí wọ́n ṣe.

      Àwọn àpọ́sítélì rí i pé kò sóhun tó lè yí ìdájọ́ ọjọ́ iwájú yìí pa dà. Jésù wá sọ fún wọn pé: “[Ọba] máa [sọ pé]: ‘Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, torí pé ẹ ò ṣe é fún ọ̀kan nínú àwọn tó kéré jù lọ yìí, ẹ ò ṣe é fún mi.’ Àwọn yìí máa lọ sínú ìparun àìnípẹ̀kun, ṣùgbọ́n àwọn olódodo sínú ìyè àìnípẹ̀kun.”—Mátíù 25:45, 46.

      Ìdáhùn tí Jésù fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ yìí máa jẹ́ kí wọ́n lè ronú jinlẹ̀ nípa bí wọ́n ṣe ń hùwà àti bí wọ́n ṣe ń ṣe nǹkan.

      • Nínú àpèjúwe tí Jésù sọ nípa àgùntàn àti ewúrẹ́, ta ni “Ọba náà” dúró fún, ìgbà wo sì ni àpèjúwe yẹn máa ṣẹ?

      • Kí nìdí tí Jésù fi máa ṣojúure sáwọn àgùntàn?

      • Kí ló máa mú kí Jésù ka àwọn kan sí ewúrẹ́, kí ló sì máa ṣẹlẹ̀ sáwọn àgùntàn àtàwọn ewúrẹ́?

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́