Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
© 2023 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
SEPTEMBER 11-17
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | Ẹ́SÍTÀ 3-5
“Ran Àwọn Míì Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Túbọ̀ Máa Lo Ara Wọn Lẹ́nu Iṣẹ́ Jèhófà”
it-2 431 ¶7
Módékáì
Módékáì Ò Tẹrí Ba fún Hámánì. Kí èyí tó ṣẹlẹ̀, Ahasuérúsì fi Hámánì tó jẹ́ ọmọ Ágágì ṣe igbá kejì ẹ̀, ó sì pàṣẹ pé kí gbogbo àwọn tó wà ní ẹnubodè ọba máa wólẹ̀ fún Hámánì torí ipò tuntun tí ọba gbé e sí. Àmọ́, Módékáì kọ̀ jálẹ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀, ó sọ pé Júù ni òun. (Ẹst 3:1-4) Bí Módékáì ṣe sọ pé Júù lòun fi hàn pé ọ̀rọ̀ náà kan àjọṣe ẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run torí Júù tó ti ya ara ẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà ni. Nígbà àtijọ́, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sábà máa ń wólẹ̀ fún ẹni tó bá wà ní ipò àṣẹ láti fi hàn pé wọ́n bọ̀wọ̀ fún ẹni náà, àmọ́ Módékáì mọ̀ pé ohun tí Hámánì ń fẹ́ ju ìyẹn lọ. (2Sa 14:4; 18:28; 1Ọb 1:16) Ìdí pàtàkì kan wà tí Módékáì ò fi tẹrí ba fún Hámánì. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọmọ Ámálékì ni Hámánì, Jèhófà sì ti sọ pé òun á máa gbógun ja Ámálékì “láti ìran dé ìran.” (Ẹk 17:16; wo HÁMÁNÌ.) Èyí jẹ́ ká rí i pé torí pé Módékáì fẹ́ jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run ni kò ṣe tẹrí ba fún Hámánì kì í ṣe torí pé kò bọ́wọ́ fún ipò rẹ̀.
it-2 431 ¶9
Módékáì
Jèhófà Lò Ó Láti Gba Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Sílẹ̀. Nígbà tí ọba pàṣẹ pé kí wọ́n pa gbogbo àwọn Júù tó wà ní agbègbè abẹ́ àṣẹ rẹ̀ run, Módékáì fi hàn pé òun nígbàgbọ́, ìdí nìyẹn tó fi sọ fún Ẹ́sítà pé torí irú àkókò yìí ló fi dé ipò ayaba kó lè gba àwọn Júù sílẹ̀. Ó jẹ́ kí Ẹ́sítà mọ ojúṣe pàtàkì tó ní, ó sì sọ pé kó lọ bá ọba láti wá ojú rere rẹ̀, kó sì ní kí ọba ran òun lọ́wọ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ohun tí Ẹ́sítà fẹ́ ṣe yẹn máa fi ẹ̀mí ẹ̀ sínú ewu, ó gbà láti ṣe é.—Ẹst 4:7–5:2.
SEPTEMBER 25–OCTOBER 1
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | Ẹ́SÍTÀ 9-10
“Ó Lo Àṣẹ Tó Ní Láti Ran Àwọn Èèyàn Ọlọ́run Lọ́wọ́”
it-2 432 ¶2
Módékáì
Ní báyìí, Módékáì ti rọ́pò Hámánì, ó sì ti di igbá kejì ọba. Ọba wá fún un ni òrùka àṣẹ rẹ̀ kó lè máa gbé èdìdì lé àwọn ìwé àṣẹ ọba. Ọba fún Ẹ́sítà ní ilé Hámánì, Ẹ́sítà sì fi Módékáì ṣe olórí ilé náà. Módékáì kọ ìwé àṣẹ kan ní orúkọ ọba tó fagi lé àṣẹ àkọ́kọ́ tí ọba pa, èyí sì fún àwọn Júù ní ẹ̀tọ́ lábẹ́ òfin láti gbèjà ara wọn. Ìyẹn fi hàn pé Jèhófà máa gba àwọn Júù sílẹ̀, wọ́n sì máa láyọ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn tó wà ní ilẹ̀ ọba Páṣíà ló ti àwọn Júù lẹ́yìn, àwọn Júù sì ti múra sílẹ̀ de ọjọ́ kẹtàlá oṣù Ádárì tí òfin ọba máa ṣẹ. Torí ipò tí Módékáì wà, àwọn ìjòyè ọba tó kù nílẹ̀ Páṣíà náà tì í lẹ́yìn. Ní Ṣúṣánì, ìjà náà le débi pé ọjọ́ kejì ni wọ́n tó parí ẹ̀. Ó ju ẹgbẹ̀rún márùnléláàádọ́rin (75,000) àwọn ọ̀tá táwọn Júù pa ní ilẹ̀ ọba Páṣíà, títí kan àwọn ọmọkùnrin Hámánì mẹ́wẹ̀ẹ̀wá. (Ẹst 8:1–9:18) Lẹ́yìn náà, Módékáì fi lẹ́tà ránṣẹ́ sáwọn Júù, ó sọ fún wọn pé kí wọ́n máa pa “àwọn ọjọ́ Púrímù” náà mọ́ lọ́dọọdún ìyẹn ọjọ́ kẹrìnlá àti ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù Ádárì. Ó ní kí wọ́n máa fi àwọn ọjọ́ náà ṣe ọjọ́ àsè àti ọjọ́ ayọ̀, kí wọ́n sì máa fi oúnjẹ àti ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí ara wọn títí kan àwọn aláìní. Tayọ̀tayọ̀ ni wọ́n fi gba ohun tó sọ yìí, kódà wọ́n fi dandan lé e fún àwọn àtọmọdọ́mọ wọn àti gbogbo àwọn tó dara pọ̀ mọ́ wọn láti máa ṣe é. Àwọn Júù bọ́wọ́ fún Módékáì torí pé òun ni igbá kejì ọba, òun náà sì ń ṣiṣẹ́ fún ire àwọn èèyàn náà.—Ẹst 9:19-22, 27-32; 10:2, 3.
it-2 716 ¶5
Púrímù
Ohun tó wà fún. Àwọn kan tó ṣàlàyé nípa àjọyọ̀ Púrímù sọ pé táwọn Júù òde òní bá fẹ́ ṣe àjọyọ̀ náà, wọn kì í ṣe é láti fògo fún Ọlọ́run torí àwọn nǹkan tí kò kan ìjọsìn ni wọ́n máa ń ṣe níbẹ̀. Bákan náà, wọ́n máa ń ṣe àṣejù nídìí ẹ̀, àmọ́ bó ṣe rí kọ́ nìyẹn nígbà tí wọ́n dá àjọyọ̀ náà sílẹ̀. Jèhófà tó jẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ ni Módékáì àti Ẹ́sítà ń sìn, òun ni wọ́n sì ń fi àjọyọ̀ náà yìn. Ó ṣe kedere pé Jèhófà Ọlọ́run ló da àwọn Júù nídè nígbà yẹn ìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé Módékáì jẹ́ olóòótọ́, ó sì fọwọ́ pàtàkì mú ìjọsìn Jèhófà. Ó ṣeé ṣe kí Hámánì jẹ́ ọmọ Ámálékì, ìyẹn orílẹ̀-èdè tí Jèhófà gégùn-ún fún pé òun máa pa run. Abájọ tí Módékáì ò fi tẹrí ba fún Hámánì kó lè fi hàn pé òun fara mọ́ ìdájọ́ tí Ọlọ́run ṣe. (Ẹst 3:2, 5; Ẹk 17:14-16) Bákan náà, ọ̀rọ̀ tí Módékáì sọ fún Ẹ́sítà (Ẹst 4:14) fi hàn pé ó gbà pé alágbára gíga jù lọ ìyẹn Jèhófà ló lè gba àwọn Júù sílẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, bí Ẹ́sítà ṣe gbààwẹ̀ kó tó lọ bá ọba láti pè é wá sí ibi àsè fi hàn pé ó fẹ́ kí Ọlọ́run ran òun lọ́wọ́.—Ẹst 4:16.
OCTOBER 9-15
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JÓÒBÙ 4-5
“Ṣọ́ra Fáwọn Ọ̀rọ̀ tí Kì Í Ṣòótọ́”
it-1 713 ¶11
Élífásì
2. Ó jẹ́ ọ̀kan lárá àwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù mẹ́ta. (Job 2:11) Ó jẹ́ ará Témánì, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ísọ̀ tá a mẹ́nu kàn ṣáájú, ìyẹn túmọ̀ sí pé àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù ni, ó sì tún tan mọ́ Jóòbù. Àwọn ará Témánì gbà pé àwọn gbọ́n gan-an, ìyẹn sì máa ń mú kí wọ́n fọ́nnu. (Jer 49:7) Nínú àwọn mẹ́ta tó jẹ́ olùtùnú èké tó wá sọ́dọ̀ Jóòbù, Élífásì ta yọ torí ó lẹ́nu láwùjọ, òun ló sì lọ́lá jù láàárín wọn, o sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé òun ló dàgbà jù. Òun ló kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nínú àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, ọ̀rọ̀ ẹ̀ ló sì gùn jù.
OCTOBER 30–NOVEMBER 5
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JÓÒBÙ 11-12
“Ohun Mẹ́ta Táá Jẹ́ Ká Ní Ọgbọ́n, Kó sì Ṣe Wá Láǹfààní”
it-2 1190 ¶2
Ọgbọ́n
Ọgbọ́n Ọlọ́run. Jèhófà Ọlọ́run ni orísun ọgbọ́n, ọgbọ́n rẹ̀ kò láfiwé, kódà òun ni “ẹnì kan ṣoṣo tí ó gbọ́n.” (Ro 16:27; Ifi 7:12) Torí pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá, kò sí nǹkan tí kò mọ̀. Ìdí sì ni pé ó ti wà “láti ayérayé dé ayérayé.” (Sm 90:1, 2) Ó mọ ohun gbogbo nípa ayé àtọ̀run, àwọn nǹkan tó wà nínú ẹ̀ àti bó ṣe bẹ̀rẹ̀ títí di báyìí. Táwọn èèyàn bá fẹ́ ṣèwádìí tàbí gbé ohun tuntun kan jáde, wọ́n gbọ́dọ̀ gbára lé àwọn nǹkan ti Jèhófà ṣètò, bí òfin tó ń darí àgbáyé wa, àwọn ohun tó ń yí po ní ayé, àtàwọn ìlànà pàtó kan kí wọ́n tó lè ṣàṣeyọrí. (Job 38:34-38; Sm 104:24; Owe 3:19; Jer 10:12, 13) Òótọ́ kan ni pé téèyàn bá fẹ́ kí nǹkan máa lọ bó ṣe yẹ, kí ìgbésí ayé ẹ̀ sì nítumọ̀, ó ṣe pàtàkì kó máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run. (Di 32:4-6; wo JÈHÓFÀ [Àwọn ìlànà Ọlọ́run].) Òye Jèhófà kò lópin. (Ais 40:13, 14) Nígbà míì, Jèhófà lè gbà káwọn ohun tí kò bá ìlànà rẹ̀ mu ṣẹlẹ̀ tàbí kí wọ́n ṣàṣeyọrí fúngbà díè, àmọ́ òótọ́ kan ni pé òun ló máa pinnu ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, ohun tó sì fẹ́ ló máa ṣẹlẹ̀. Kódà, Bíbélì sọ pé gbogbo ohun tó bá sọ “máa yọrí sí rere.”—Ais 55:8-11; 46:9-11.