Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
© 2023 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
NOVEMBER 6-12
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JÓÒBÙ 13-14
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
it-1 191
Eérú
Eérú máa ń ṣàpẹẹrẹ ohun táwọn èèyàn ò kà sí, tí kò sì níye lórí. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Ábúráhámù ń sọ̀rọ̀ nípa àra rẹ̀ fún Jèhófà, ó sọ pé: “Mo jẹ́ erùpẹ̀ àti eérú.” (Jẹ 18:27; tún wo Ais 44:20; Job 30:19.) Kódà, Jóòbù fi ọ̀rọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tó jẹ́ olùtùnú èké wé “òwe tó dà bí eérú.”—Job 13:12.
NOVEMBER 20-26
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JÓÒBÙ 18-19
“Má Ṣe Pa Àwọn Tẹ́ Ẹ Jọ Ń Sin Jèhófà Tì”
w90 9/1 22 ¶20
Iwọ Ha Ńnàgà Bí?
20 Ẹgbẹ́ awọn alàgbà nilati mọ̀lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ pe ìmúkúrò ní ipò-iṣẹ́ lè ṣokùnfà másùnmáwo fun alaboojuto tabi iranṣe iṣẹ́-òjíṣẹ́ tẹ́lẹ̀rí kan, koda bí oun bá fínnúfíndọ̀ fi anfaani naa sílẹ̀. Bí a kò bá yọ ọ́ lẹ́gbẹ́, sugbọn tí awọn alàgbà ríi pe arakunrin naa ní ìsoríkọ́, ó yẹ kí wọn pèsè iranlọwọ onífẹ̀ẹ́ nipa tẹ̀mí. (1 Thessalonica 5:14) Wọn nilati ràn án lọwọ kí oun lè mọ̀lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ pe a nílò oun ninu ijọ́. Àní bí ó tilẹ beere fun ìmọ̀ràn, ó lè má gba akoko gígún kan ṣaaju kí ọkunrin onírẹ̀lẹ̀ kan ti ó kún fun imoore tó gbà afikun awọn anfaani iṣẹ́-ìsìn lẹẹkan sii ninu ijọ́ naa.
DECEMBER 11-17
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JÓÒBÙ 25-27
“Kò Dìgbà Tá A Bá Jẹ́ Ẹni Pípé Ká Tó Lè Jẹ́ Olóòótọ́”
it-1 1210 ¶4
Ìwà Títọ́
Jóòbù. Láàárín ìgbà tí Jósẹ́fù kú sí ìgbà ayé Mósè ni Jóòbù gbé láyé. Bíbélì sọ nípa rẹ̀ pé “Olódodo [Heb., tam] àti olóòótọ́ èèyàn ni; ó bẹ̀rù Ọlọ́run, ó sì kórìíra ohun tó burú.” (Job 1:1; wo JÓÒBÙ.) Ọ̀rọ̀ nípa ìwà títọ́ wà lára ohun tí Sátánì àti Jèhófà sọ nígbà tí Sátánì wá síbi ìpàdé tí Ọlọ́run ṣe pẹ̀lú àwọn áńgẹ́lì ní ọ̀run, Jèhófà béèrè bóyá ó kíyè sí Jóòbù ìránṣẹ́ òun olóòótọ́. Sátánì sọ pé ìjọsìn Jóòbù kò tọkàn wá, ó fi kún un pé torí ohun tó máa rí gbà ló ṣe ń jọ́sìn Ọlọ́run. Nípa bẹ́ẹ̀, ohun tí Sátánì ń dọ́gbọ́n sọ ni pé tọ́wọ́ ìyà bá ba Jóòbù kò ní jẹ́ olóòótọ́ mọ́. Lẹ́yìn tí Sátánì gbàṣẹ, ó mú kí Jóòbù pàdánù gbogbo ohun ìní rẹ̀ ó sì tún pa àwọn ọmọ rẹ̀, síbẹ̀ kò rí ìwà títọ́ Jóòbù bà jẹ́. (Job 1:6–2:3) Sátáni sọ pé torí Jóòbù mọ tara ẹ̀ nìkan ló jẹ́ kó lè fara da ikú àwọn ọmọ ẹ̀ àti gbogbo ohun ìní ẹ̀ tó pàdánù torí ó gbà pé tẹ́mìí bá ṣì wà ìrètí ń bẹ. (Job 2:4, 5) Lẹ́yìn náà, ó fi àìsàn tó máa ń roni lára gan-an kọlu Jóòbù, ó sì tún mú kí ìyàwó ẹ̀ sọ̀rọ̀ tó lè mú kó juwọ́ sílẹ̀. Síwájú sí i, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ kòbákùngbé ọ̀rọ̀ sí i, wọ́n tún sọ pé torí ìwà ibi pọ̀ lọ́wọ́ Jóòbù ni gbogbo wàhálà yẹn ṣe dé bá a. (Job 2:6-13; 22:1, 5-11) Èsì tí Jóòbù fún wọn jẹ́ ká mọ̀ pé kò ní jáwọ́ nínú ìwà títọ́ rẹ̀, torí ó sọ pé: “Títí màá fi kú, mi ò ní fi ìwà títọ́ mi sílẹ̀! Màá rọ̀ mọ́ òdodo mi, mi ò sì ní jẹ́ kó lọ; Ọkàn mi ò ní dá mi lẹ́bi tí mo bá ṣì wà láàyè.” (Job 27:5, 6) Bí Jóòbù ṣe pa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́ jẹ́ ká rí i pé òpùrọ́ ni Sátánì.
DECEMBER 18-24
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JÓÒBÙ 28-29
“Ṣé O Ní Orúkọ Rere Bíi Ti Jóòbù?”
it-1 655 ¶10
Aṣọ
Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Bíbélì fi aṣọ ṣàpẹẹrẹ àwọn nǹkan kan. Bó ṣe jẹ́ pé a lè fi irú aṣọ tẹ́nì kan wọ̀ mọ irú iṣẹ́ tó ń ṣe tàbí ẹgbẹ́ tó wà, bẹ́ẹ̀ náà ni Bíbélì sábà máa ń lo aṣọ láti ṣàpẹẹrẹ irú èèyàn tẹ́nì kan jẹ́, ipò tó wà àti ohun tó ń ṣe. Bí àpẹẹrẹ, Jésù sọ àpèjúwe kan nípa aṣọ ìgbéyàwó. (Mt 22:11, 12; wo ÌWÉRÍ; BÀTÁ.) Nínú Ìfihàn 16:14, 15 Jésù Kristi Olúwa kìlọ̀ pé ká má ṣe sùn nípa tẹ̀mí débi tí wọ́n á fi bọ́ aṣọ tó fi wá hàn bí ẹlẹ́rìí Ọlọ́run tòótọ́. Àdánù ńlá lèyí máa jẹ́ pàápàá tó bá ṣẹlẹ̀ kété kí “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè” tó jà.