ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwbr24 September ojú ìwé 1-11
  • Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú “Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú “Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni”
  • Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé—2024
  • Ìsọ̀rí
  • SEPTEMBER 2-8
  • SEPTEMBER 9-15
  • SEPTEMBER 16-22
  • SEPTEMBER 23-29
  • SEPTEMBER 30–OCTOBER 6
  • OCTOBER 7-13
  • OCTOBER 14-20
  • OCTOBER 21-27
  • OCTOBER 28–NOVEMBER 3
Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé—2024
mwbr24 September ojú ìwé 1-11

Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni

© 2024 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania

SEPTEMBER 2-8

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN SÁÀMÙ 79-81

Máa Fi Hàn Pé O Nífẹ̀ẹ́ Orúkọ Jèhófà Tó Jẹ́ Ológo

w17.02 9 ¶5

Ìràpadà “Ọrẹ Pípé” Tí Baba Fún Wa

5 Báwo la ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ orúkọ Jèhófà? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ nípa ìwà wa. Jèhófà ní ká jẹ́ mímọ́. (Ka 1 Pétérù 1:15, 16.) Èyí gba pé ká jọ́sìn Jèhófà nìkan ṣoṣo, ká sì máa fi gbogbo ọkàn wa tẹ̀ lé ìlànà rẹ̀. Táwọn èèyàn bá tiẹ̀ ń ṣenúnibíni sí wa, ẹ jẹ́ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti pa àwọn òfin àti ìlànà Jèhófà mọ́. Bá a ṣe ń hùwà mímọ́, ṣe là ń jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ wa máa tàn, tá a sì ń tipa bẹ́ẹ̀ bọlá fún orúkọ Jèhófà. (Mát. 5:14-16) Torí pé a jẹ́ èèyàn Jèhófà, ọ̀nà tá a gbà ń gbé ìgbé ayé wa fi hàn pé àwọn òfin Jèhófà ṣàǹfààní àti pé irọ́ ni ẹ̀sùn tí Sátánì fi kan Jèhófà. Nítorí àìpé wa, gbogbo wa la máa ń ṣàsìṣe. Tó bá ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká ronú pìwà dà tọkàntọkàn, ká sì jáwọ́ nínú ìwà èyíkéyìí tó lè tàbùkù sórúkọ Jèhófà.​—Sm. 79:9.

ijwbv 3 ¶4-5

Róòmù 10:13​—“Pe Orúkọ Oluwa”

Nínú Bíbélì, gbólóhùn náà “ké pe orúkọ Jèhófà” ju kéèyàn kàn mọ orúkọ Ọlọ́run kó sì máa lò ó nínú ìjọsìn. (Sáàmù 116:12-14) Ó gba pé ká gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run, ká sì gbà pé ó máa ràn wá lọ́wọ́.​—Sáàmù 20:7; 99:6.

Orúkọ Ọlọ́run ṣe pàtàkì sí Jésù Kristi. Àwọn ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ nínú àdúrà àwòkọ́ṣe tó kọ́ wa ni: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di mímọ́” tàbí kí a ka orúkọ rẹ sí mímọ́. (Mátíù 6:9) Jésù tún fi hàn pé a gbọ́dọ̀ mọ ẹni tó ń jẹ́ orúkọ yìí, ká ṣègbọràn sí i, ká sì nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ ká tó lè jèrè ìyè àìnípẹ̀kun.​—Jòhánù 17:3, 6, 26.

Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

it-2 111

Jósẹ́fù

Ipò Pàtàkì Tí Jósẹ́fù Wà. Torí pé ipò pàtàkì ni Jósẹ́fù wà láàárín àwọn ọmọ Jékọ́bù, ó tọ́ bí wọ́n ṣe máa ń fi orúkọ ẹ̀ pé gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì nígbà míì. (Sm 80:1) Wọ́n sì máa ń fi orúkọ ẹ̀ pe ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì. (Sm 78:67; Emọ 5:6, 15; 6:6) Orúkọ ẹ̀ tún fara hàn nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì kan. Nínú ìràn alásọtẹ́lẹ̀ tí Ìsíkíẹ́lì rí, ìpín méjì ni ogún tí Jósẹ́fù gbà. (Isk 47:13) Bákan náà, orúkọ Jósẹ́fù ni wọ́n fi pe ọ̀kan lára àwọn ẹnubodè tó wà ní ìlú tí wọ́n pè ní “Jèhófà Wà Níbẹ̀.” (Isk 48:32, 35) Nígbà tí Bíbélì sì ń sọ̀rọ̀ nípa bí àwọn èèyàn Jèhófà ṣe máa pa dà wà níṣọ̀kan, ó pe Jósẹ́fù ní olórí apá kan orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, ó sì pe Júdà ní olórí apá kejì orílẹ̀-èdè náà. (Isk 37:15-26) Àsọtẹ́lẹ̀ Ọbadáyà jẹ́ ká mọ̀ pé “ilé Jósẹ́fù” máa pa run pẹ̀lú “ilé Ísọ̀.” (Ọbd 18) Àsọtẹ́lẹ̀ Sekaráyà sì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà máa gba “ilé Jósẹ́fù” là. (Sek 10:6) Yàtọ̀ síyẹn, orúkọ Jósẹ́fù ló wà nínú àwọn Ísírẹ́lì tẹ̀mí dípò orúkọ Éfúrémù.​—Ifi 7:8.

Ti pé orúkọ Jósẹ́fù wà lára ẹ̀yà Ísírẹ́lì tó wà nínú Ìfihàn 7:8 fi hàn pé àsọtẹ́lẹ̀ tí Jékọ́bù sọ nígbà tó fẹ́ kú ṣẹ sí Ísírẹ́lì tẹ̀mí lára. Ó gbàfiyèsí pé Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Alágbára Jékọ́bù ti fún wa ní Kristi Jésù bí Olùṣọ́ Àgùntàn Àtàtà tó fi ẹ̀mí rẹ̀ lẹ́lẹ̀ nítorí “àwọn àgùntàn.” (Jo 10:11-16) Bákan náà, Kristi Jésù ni òkúta ìpìlẹ̀ igun ilé tí Ísírẹ́lì tẹ̀mí tó wà nínú tẹ́ńpìlì Ọlọ́run dúró lé. (Ef 2:20-22; 1Pe 2:4-6) Olùṣọ́ Àgùntàn àti Òkúta yìí sì wà pẹ̀lú Ọlọ́run Olódùmarè.​—Jo 1:1-3; Iṣe 7:56; Heb 10:12; fi wé Jẹ 49:24, 25.

SEPTEMBER 9-15

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN SÁÀMÙ 82-84

Mọyì Ohunkóhun Tó O Bá Ń Ṣe Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìsìn Jèhófà

wp16.6 8 ¶2-3

Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́ Lára Àwọn Ẹyẹ Ojú Ọ̀run

Àwọn aráàlú Jerúsálẹ́mù mọ ẹyẹ alápàáǹdẹ̀dẹ̀ bí ẹni mowó. Inú òrùlé ló sábà máa ń kọ́ ìtẹ́ rẹ̀ sí. Àwọn kan tiẹ̀ kọ́ ìtẹ́ wọn sínú tẹ́ńpìlì Sólómọ́nì. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn ẹyẹ yìí fẹ́ràn láti kọ́ ìtẹ́ wọn sínú tẹ́ńpìlì lọ́dọọdún, kí wọ́n lè tọ́ àwọn ọmọ wọn láìsí ìyọlẹ́nu kankan.

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ Kórà ló kọ Sáàmù 84. Láàárín oṣù mẹ́fà, ọ̀sẹ̀ kan péré lẹni yìí fi máa ń ṣiṣẹ́ nínú tẹ́ńpìlì, ibẹ̀ ló ti kíyè sí àwọn ìtẹ́ ẹyẹ tó wà ní àyíká tẹ́ńpìlì. Ó wu òun náà kó dà bí ẹyẹ alápàáǹdẹ̀dẹ̀ tó ń gbé inú ilé Jèhófà. Ó sọ pé: “Ibùgbé rẹ lẹ́wà pupọ, OLUWA àwọn ọmọ ogun, ọkàn àgbàlá tẹmpili OLUWA ń fà mí, àárò rẹ̀ ń sọ mí. . . . Àwọn ẹyẹ ológoṣẹ́ pàápàá a máa kọ́ ilé, àwọn alápàáǹdẹ̀dẹ̀ a sì máa tẹ́ ìtẹ́ níbi tí wọ́n ń pa ọmọ sí, lẹ́bàá pẹpẹ rẹ, àní lẹ́bàá pẹpẹ rẹ, OLUWA àwọn ọmọ ogun, ọba mi, ati Ọlọrun mi.” (Sáàmù 84:1-3, Bíbélì Mímọ́) Ṣé ó máa ń wu àwa náà àtàwọn ọmọ wa láti máa wà láàárín ìjọ àwọn èèyàn Ọlọ́run déédéé?​—Sáàmù 26:8, 12.

w08 7/15 30 ¶3-4

Láti Lè Máa Láyọ̀, Ohun Tọ́wọ́ Rẹ Lè Tẹ̀ Ni Kó O Fi Ṣe Àfojúsùn Rẹ

Ọjọ́ ogbó tàbí ara tí kò jí pépé lè má jẹ́ ká lè ṣe ohun tó pọ̀ mọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Tó o bá jẹ́ òbí, ó lè máa ṣe ọ́ bíi pé o kì í fi bẹ́ẹ̀ gbádùn ìkẹ́kọ̀ọ́ ara ẹni tàbí ìpàdé ìjọ nítorí pé èyí tó pọ̀ jù nínú àkókò rẹ àti agbára rẹ ló ń lò lórí àwọn ọmọ rẹ kéékèèké. Àmọ́, ṣé kì í ṣe pé ọ̀rọ̀ ohun tọ́wọ́ rẹ ò lè tẹ̀ tó gbà ọ́ lọ́kàn yìí ti ń ṣàkóbá fún ọ nígbà míì, débi pé o kì í rí àwọn ohun tọ́wọ́ rẹ lè tẹ̀?

Ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn, ọmọ Léfì kan sọ pé nǹkan kan wu òun, àmọ́ ọwọ́ rẹ̀ kó tẹ nǹkan ọ̀hún. Ó láǹfààní àrà ọ̀tọ̀ láti máa sìn nínú tẹ́ńpìlì fún ọ̀sẹ̀ méjì méjì lọ́dọọdún. Àmọ́, ó sọ bó ṣe wu òun tó láti máa sìn títí láé lẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ, ohun tó wù ú yẹn sì dára gan-an ni. (Sm. 84:1-3) Kí ló jẹ́ kí ọkùnrin adúróṣinṣin yìí lè nítẹ̀lọ́rùn? Ó mọ̀ pé àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ ni pé kéèyàn lo kódà ọjọ́ kan péré nínú àgbàlá tẹ́ńpìlì. (Sm. 84:4, 5, 10) Bákan náà, dípò tá a ó fi wá máa ronú ṣáá lórí àwọn ohun tọ́wọ́ wa ò lè tẹ̀, ẹ jẹ́ ká gbìyànjú láti fòye mọ àwọn ohun tọ́wọ́ wa lè tẹ̀, ká sì mọrírì rẹ̀.

w20.01 17 ¶12

Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Rẹ, Ó sì Mọyì Ẹ Gan-an!

12 Tó o bá ń ṣàìsàn, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà mọ ohun tó ń ṣe ẹ́ àti bó ṣe rí lára ẹ. Bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa fojú tó tọ́ wo ìṣòro rẹ. Lẹ́yìn náà, ka Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ kó o lè rí àwọn ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ láti tù ẹ́ nínú. Ní pàtàkì, máa ronú lórí àwọn ẹsẹ tó fi hàn pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn rẹ̀, ó sì mọyì wa gan-an. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá rí i pé adúrótini nígbà ìṣòro ni Jèhófà, kì í sì í fàwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀.​—Sm. 84:11.

Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

it-1 816

Ọmọ Aláìníbaba

Torí pé ó rọrùn gan-an láti fojú pa àwọn ọmọ aláìníbaba rẹ́ torí kò sẹ́ni tó máa gbèjà wọn, Jèhófà máa ń lo ọ̀rọ̀ náà “ọmọ aláìníbaba” láti jẹ́ ká mọ báwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe jẹ́ onígbọràn àti bí wọ́n ṣe jẹ́ aláìgbọràn. Lásìkò táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá ń ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́, wọ́n máa ń bójú tó àwọn ọmọ aláìníbaba. Àmọ́ nígbà tí wọ́n bá ya aláìgbọràn, tí wọ́n sì ń yí ìdájọ́ po, ó dájú pé wọn ò ní rí táwọn ọmọ aláìníbaba rò. (Sm 82:3; 94:6; Ais 1:17, 23; Jer 7:5-7; 22:3; Isk 22:7; Sek 7:9-11; Mal 3:5) Jèhófà gégùn-ún fún àwọn tó bá ń fìyà jẹ àwọn ọmọ aláìníbaba. (Di 27:19; Ais 10:1, 2) Jèhófà jẹ́ ká mọ̀ pé òun ni Olùgbèjà (Owe 23:10, 11), Olùrànlọ́wọ́ (Sm 10:14), àti Bàbá (Sm 68:5) àwọn ọmọ aláìníbaba. Òun ló ń ṣe ìdájọ́ òdodo fún ọmọ aláìníbaba (Di 10:17, 18), tó ń ṣàánú wọn (Ho 14:3), tó ń fún wọn lókun (Sm 146:9), tó sì ń mú kí wọ́n máa wà láàyè.​—Jer 49:11.

Ọ̀kan lára ohun tá a fi ń dá àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ̀ ni bí wọ́n ṣe ń fìfẹ́ hàn sáwọn opó àtàwọn ọmọ aláìníbaba. Jémíìsì sọ fáwọn Kristẹni pé: “Ìjọsìn tó mọ́, tí kò sì ní ẹ̀gbin lójú Ọlọ́run àti Baba wa nìyí: láti máa bójú tó àwọn ọmọ aláìlóbìí àti àwọn opó nínú ìpọ́njú wọn, ká sì máa pa ara wa mọ́ láìní àbààwọ́n nínú ayé.”​—Jem 1:27.

SEPTEMBER 16-22

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN SÁÀMÙ 85-87

Àdúrà Máa Ń Jẹ́ Ká Lè Ní Ìfaradà

w12 5/15 25 ¶10

Ǹjẹ́ Ò Ń Gbé Ògo Jèhófà Yọ?

10 Ká bàa lè máa gbé ògo Ọlọ́run yọ, a tún gbọ́dọ̀ máa “ní ìforítì nínú àdúrà.” (Róòmù 12:12) Ó yẹ ká máa gbàdúrà sí Jèhófà pé kó jẹ́ ká máa sin òun lọ́nà tó tẹ́wọ́ gbà. Torí náà, ó tọ́ ká máa bẹ̀ ẹ́ pé kó fún wa ní ẹ̀mí mímọ́, kó fún wa ní ìgbàgbọ́ sí i, kó fún wa lókun ká má bàa ṣubú sínú ìdẹwò àti pé kó mú kó ṣeé ṣe fún wa láti máa “fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́.” (2 Tím. 2:15; Mát. 6:13; Lúùkù 11:13; 17:5) Bí ọmọ kan ṣe ń gbára lé bàbá rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ló ṣe yẹ kí àwa náà máa gbára lé Jèhófà, Baba wa ọ̀run. Tá a bá bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn wá lọ́wọ́ ká lè túbọ̀ máa sìn ín ní kíkún, a máa ní ìdánilójú pé ó máa ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹ má ṣe jẹ́ ká ronú pé ńṣe là ń yọ Jèhófà lẹ́nu! Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká máa yìn ín nínú àdúrà wa, ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, ká máa wá ìtọ́sọ́nà rẹ̀ ní pàtàkì nígbà tá a bá dojú kọ àdánwò, ká sì máa bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa sìn ín lọ́nà tó máa fi ògo fún orúkọ mímọ́ rẹ̀.​—Sm. 86:12; Ják. 1:5-7.

w23.05 13 ¶17-18

Báwo Ni Jèhófà Ṣe Ń Dáhùn Àdúrà Wa?

17 Ka Sáàmù 86:6, 7. Ó dá Dáfídì lójú pé Jèhófà gbọ́ àwọn àdúrà òun, ó sì dáhùn wọn. Jẹ́ kó dá ìwọ náà lójú pé Jèhófà máa dáhùn àwọn àdúrà ẹ. Àwọn àpẹẹrẹ tá a sọ nínú àpilẹ̀kọ yìí ti jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà máa fún wa ní ọgbọ́n àti okun táá jẹ́ ká fara da àwọn ìṣòro wa. Ó lè lo àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tàbí àwọn tí kì í ṣe ìránṣẹ́ ẹ̀ láti ràn wá lọ́wọ́.

18 Lóòótọ́, kì í ṣe gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń dáhùn àwọn àdúrà wa bá a ṣe fẹ́, àmọ́ a mọ̀ pé ó máa dáhùn wọn. Ó máa pèsè ohun tá a nílò gan-an lásìkò tá a nílò ẹ̀. Torí náà máa gbàdúrà, kó o sì nígbàgbọ́ pé Jèhófà máa dáhùn àdúrà ẹ àti pé ó máa bójú tó ẹ ní báyìí, ó sì máa “fún gbogbo ohun alààyè ní ohun tí wọ́n ń fẹ́” nínú ayé tuntun.​—Sm. 145:16.

Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

it-1 1058 ¶5

Ọkàn

Fi “Gbogbo Ọkàn” Sin Jèhófà. Kí ọkàn èèyàn tó lè ṣiṣẹ́ dáadáa, ó gbọ́dọ̀ wà lódindi. Àmọ́ ọkàn ìṣàpẹẹrẹ lè pínyà. Dáfídì gbàdúrà pé: “Fún mi ní ọkàn tó pa pọ̀ kí n lè máa bẹ̀rù orúkọ rẹ,” ìyẹn fi hàn pé ohun tá a nífẹ̀ẹ́ sí àti ohun tó ń kó wa lọ́kàn sókè lè mú kí ọkàn wa pínyà tàbí kó má pa pọ̀. (Sm 86:11) Irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ “aláàbọ̀-ọkàn,” ìyẹn ẹni tí kò gbóná tàbí tutù bó ṣe ń sin Ọlọ́run. (Sm 119:113; Ifi 3:16) Ẹnì kan tún lè jẹ́ “ọlọ́kàn méjì” (tó túmọ̀ lólówuuru sí ẹni tó ní ọkàn àti ọkàn), ní ti pé, ó fẹ́ máa sin ọ̀gá méjì tàbí kó jẹ́ pé ọ̀tọ̀ lohun tó ń sọ, àmọ́ ọ̀tọ̀ lohun tó wà lọ́kàn ẹ̀. (1Kr 12:33; Sm 12:2, àlàyé ìsàlẹ̀) Jésù dẹ́bi fún irú ìwà àgàbàgebè bẹ́ẹ̀.​—Mt 15:7, 8.

SEPTEMBER 23-29

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN SÁÀMÙ 88-89

Ìṣàkóso Jèhófà Ló Dáa Jù

w17.06 28 ¶5

Fara Mọ́ Ìṣàkóso Jèhófà!

5 Ìdí míì tí Jèhófà fi lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ alákòóso ayé àtọ̀run ni pé ó máa ń ṣe ìdájọ́ òdodo. Òun fúnra rẹ̀ sọ pé: “Èmi ni Jèhófà, Ẹni tí ń ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́, ìdájọ́ òdodo àti òdodo ní ilẹ̀ ayé; nítorí nǹkan wọ̀nyí ni mo ní inú dídùn sí.” (Jer. 9:24) Kì í ṣe òfin táwọn èèyàn aláìpé gbé kalẹ̀ ni Jèhófà ń wò kó tó pinnu ohun tó tọ́. Òun fúnra rẹ̀ ló máa ń pinnu ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́ torí pé onídàájọ́ òdodo ni, ìdí nìyẹn tó fi gbé òfin kalẹ̀ fáwa èèyàn. Bíbélì sọ pé: “Òdodo àti ìdájọ́ ni ibi àfìdímúlẹ̀ ìtẹ́ [rẹ̀],” torí náà ọkàn wa balẹ̀ pé gbogbo òfin àti ìlànà tó fún wa ló tọ̀nà. (Sm. 89:14; 119:128) Lọ́wọ́ kejì, pẹ̀lú gbogbo atótónu Sátánì pé ìṣàkóso Jèhófà ò dáa, títí di báyìí, àìṣòdodo ló kún inú ayé Sátánì.

w17.06 29 ¶10-11

Fara Mọ́ Ìṣàkóso Jèhófà!

10 Jèhófà kì í ni àwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀ lára, kì í sì í ṣe apàṣẹwàá. Ó fún àwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀ lómìnira, ìyẹn sì ń mú kí wọ́n láyọ̀. (2 Kọ́r. 3:17) Bí àpẹẹrẹ, Dáfídì sọ pé: “Iyì àti ọlá ńlá ń bẹ níwájú [Ọlọ́run], okun àti ìdùnnú ń bẹ ní ipò rẹ̀.” (1 Kíró. 16:7, 27) Étánì tóun náà kọ Sáàmù sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn ènìyàn tí ó mọ igbe ìdùnnú. Jèhófà, inú ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ ni wọ́n ti ń rìn. Wọ́n ń kún fún ìdùnnú láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀ ní orúkọ rẹ, a sì gbé wọn ga nínú òdodo rẹ.”​—Sm. 89:15, 16.

11 Tá a bá ń ṣàṣàrò déédéé lórí bí Jèhófà ṣe jẹ́ onínúure, á mú kó túbọ̀ dá wa lójú pé ìṣàkóso rẹ̀ ló dáa jù. Àwa náà á sọ bíi ti onísáàmù pé: “Ọjọ́ kan nínú àwọn àgbàlá rẹ sàn ju ẹgbẹ̀rún ọjọ́ níbòmíràn!” (Sm. 84:10) Ẹ ò rí i pé òótọ́ pọ́ńbélé nìyẹn! Torí pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá wa, ó mọ àwọn ohun táá jẹ́ ká láyọ̀, ó sì ń fún wa láwọn nǹkan náà lọ́pọ̀ yanturu. Kò sóhun tí Jèhófà ní ká ṣe tí kì í ṣe fún àǹfààní wa, kódà tó bá tiẹ̀ gba pé ká yááfì àwọn nǹkan kan. Tá a bá ṣe ohun tó fẹ́, á ṣe wá láǹfààní, àá sì láyọ̀.​—Ka Aísáyà 48:17.

w14 10/15 10 ¶14

Ní Ìgbàgbọ́ Tó Fẹsẹ̀ Múlẹ̀ Ṣinṣin Nínú Ìjọba Ọlọ́run

14 Ọlọ́run ṣèlérí kan fún Dáfídì Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì, ìlérí yẹn ni májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá Dáfídì dá. (Ka 2 Sámúẹ́lì 7:12, 16.) Jèhófà bá Dáfídì dá májẹ̀mú yìí nígbà tí Dáfídì ń ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Jèhófà sì ṣèlérí fún un nípasẹ̀ májẹ̀mú náà pé Mèsáyà máa wá láti ìlà ìdílé rẹ̀. (Lúùkù 1:30-33) Jèhófà tipa bẹ́ẹ̀ sọ ohun kan tó ṣe tààràtà nípa ìdílé tí irú-ọmọ náà ti máa wá. Jèhófà sọ pé ajogún Dáfídì kan ló máa ní “ẹ̀tọ́ lọ́nà òfin” sí ìtẹ́ Ìjọba Mèsáyà. (Ìsík. 21:25-27) Jèhófà máa tipasẹ̀ Jésù mú kí ìṣàkóso Dáfídì ‘fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in fún àkókò tí ó lọ kánrin.’ Àní sẹ́, irú-ọmọ Dáfídì “yóò wà . . . fún àkókò tí ó lọ kánrin àti ìtẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí oòrùn.” (Sm. 89:34-37) Ó ti wá ṣe kedere pé ìṣàkóso Mèsáyà kò ní di ìdàkudà láé, a ó sì máa jàǹfààní Ìjọba yìí títí láé!.

Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

cl 281 ¶4-5

“Ìwọ Nìkan Ni Adúróṣinṣin”

4 Ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà “ìdúróṣinṣin,” gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ṣe lò ó, ni inú rere tí ń fi tìfẹ́tìfẹ́ rọ̀ mọ́ ohun kan, tí kò sì ní dẹ̀yìn títí ó fi máa mú ìdí tó fi rọ̀ mọ́ ohun náà ṣẹ. Adúróṣinṣin máa ń fìfẹ́ hàn. Ó yẹ fún àfiyèsí pé onísáàmù náà pe òṣùpá ní “ẹlẹ́rìí aṣeégbíyèlé ní sánmà” nítorí bó ṣe ń yọ lálaalẹ́. (Sáàmù 89:37) Ìyẹn ni pé, òṣùpá jẹ́ ohun tó ṣeé gbọ́kàn lé, tí kò ní ṣàìyọ nígbà tí àkókò rẹ̀ bá tó. Àmọ́ òṣùpá kò lè jẹ́ adúróṣinṣin gẹ́gẹ́ bí èèyàn ṣe lè jẹ́ adúróṣinṣin. Kí nìdí? Nítorí pé ìfẹ́ ló ń súnni jẹ́ adúróṣinṣin, a sì mọ̀ pé ohun aláìlẹ́mìí kò lè fi ìfẹ́ hàn.

5 Gẹ́gẹ́ bá a ṣe lo ọ̀rọ̀ náà ìdúróṣinṣin nínú Ìwé Mímọ́, ó jẹ́ ànímọ́ ọlọ́yàyà. Ẹ̀rí sábà máa ń wà pé àjọṣe wà láàárín ẹni tó fi ànímọ́ yìí hàn àti ẹni tá a fi í hàn sí. Irú ìdúróṣinṣin bẹ́ẹ̀ kì í yẹ̀. Kò rí bí ìgbì òkun tí ẹ̀fúùfù ń bì síwá bì sẹ́yìn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìdúróṣinṣin, tàbí ìfẹ́ dídúróṣinṣin, máa ń dúró gbọn-in láìyẹsẹ̀, kódà lójú òkè ìṣòro.

SEPTEMBER 30–OCTOBER 6

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN SÁÀMÙ 90-91

Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà, Tó O Bá Fẹ́ Kí Ẹ̀mí Ẹ Gùn

wp19.3 5 ¶2-4

Àwọn Èèyàn Ń Wá Ẹ̀mí Gígùn

Kì í ṣe gbogbo àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ló gbà pé àwọn oògùn tí kì í jẹ́ kéèyàn darúgbó lè mú kí ẹ̀mí èèyàn gùn kọjá ọjọ́ orí téèyàn máa ń gbé. Òótọ́ ni pé láti ọgọ́rùn-ún ọdún kọkàndínlógún ni ìlera ẹ̀dá èèyàn ti ń sunwọ̀n sí i. Ìdí sì ni pé, àwọn èèyàn túbọ̀ ń fọwọ́ pàtàkì mú ọ̀rọ̀ ìmọ́tótó, wọ́n ń lo àwọn oògùn tó ń pa kòkòrò inú ara, wọ́n sì tún ń gba abẹ́rẹ́ àjẹsára. Àwọn kan tó jẹ́ onímọ̀ nípa àbùdá èèyàn gbà pé ọjọ́ orí èèyàn kò lè gùn ju bó ṣe wà náà lọ.

Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ààbọ̀ (3,500) ọdún sẹ́yìn, Mósè tó wà lára àwọn tó kọ Bíbélì sọ pé: “Àádọ́rin (70) ọdún ni gígùn ọjọ́ ayé wa, tàbí kó jẹ́ ọgọ́rin (80) ọdún tí èèyàn bá lókun tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Síbẹ̀, wàhálà àti ìbànújẹ́ ló kún inú wọn; wọ́n á kọjá lọ kíákíá, a ó sì fò lọ.” (Sáàmù 90:10) Bo tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn ti sapá láti jẹ́ kí ọjọ́ ayé wa gùn, síbẹ̀ ọjọ́ orí wa kì í ju bí Mósè ṣe sọ ọ́ náà lọ.

Àmọ́, àwọn ẹran omi kéékèèké tí wọ́n ń pè ní sea urchin tàbí irú òkòtó òkun kan tí wọ́n ń pè ní quahog clam lè gbé ohun tó ju ọgọ́rùn-ún méjì (200) ọdún láyé, bákan náà igi ńláńlá bíi sequoia lè gbé ẹgbẹ̀rún ọdún mélòó kan láyé. Tá a bá sì fi gígùn ọjọ́ ayé wa wé ti àwọn nǹkan alààyè yìí àtàwọn míì, á mú ká bi ara wa pé, ‘Ṣé àwa èèyàn ò wá lè lò ju 70 tàbí 80 ọdún láyé ni?’

wp19.1 5, àpótí

Kí Ni Orúkọ Ọlọ́run?

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti béèrè ìbéèrè yìí. Ó ṣeé ṣe kí ìwọ náà ti béèrè pé, ṣèbí ẹnì kan ló dá ayé àti ọ̀run, ta ló wá dá Ọlọ́run?

Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì gbà pé ayé àti àwọn nǹkan tó wà lójú ọ̀run ní ìbẹ̀rẹ̀. Èyí sì bá ohun tí ẹsẹ àkọ́kọ́ nínú Bíbélì sọ mu pé: “Ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀, Ọlọ́run dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.”​—Jẹ́nẹ́sísì 1:1.

Ayé àti ọ̀run kò ṣàdédé wà. Ohun tí kò sí kò ṣáà lè dá ohun kan tó wà. Tó bá jẹ́ pé kò sí ẹnì kankan ṣáájú kí ayé àti ọ̀run tó wà ni, kò ní sí ayé àti ọ̀run. Ọ̀rọ̀ yìí lè fẹ́ le díẹ̀ láti lóye, ohun tá à ń sọ ni pé ẹnì kan tí kì í ṣe apá kan ìṣẹ̀dá tí kò ní ìbẹ̀rẹ̀ àti òpin gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ wà ṣáájú. Jèhófà Ọlọ́run tí agbára rẹ̀ kò láàlà tó sì gbọ́n jù lọ sì ni ẹni tó kọ́kọ́ wà.​—Jòhánù 4:24.

Bíbélì sọ nípa Ọlọ́run pé: “Àní kí a tó bí àwọn òkè ńlá, tàbí kí o tó bẹ̀rẹ̀ sí bí ilẹ̀ ayé àti ilẹ̀ eléso gẹ́gẹ́ bí ẹni pé pẹ̀lú ìrora ìrọbí, àní láti àkókò tí ó lọ kánrin títí dé àkókò tí ó lọ kánrin, ìwọ ni Ọlọ́run.” (Sáàmù 90:2) Torí náà, Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ti kọ́kọ́ wà ṣáájú ohun gbogbo. Nígbà tó wá yá, ìyẹn “ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀,” ó dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.​—Ìṣípayá 4:11.

w22.06 18 ¶16-17

Bí Ìfẹ́ Ṣe Lè Jẹ́ Ká Borí Ìbẹ̀rù

16 Sátánì mọ̀ pé a ò fẹ́ kú. Ó sọ pé tá ò bá fẹ́ kú, gbogbo nǹkan la máa yááfì títí kan àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Jèhófà. (Jóòbù 2:4, 5) Ẹ ò rí i pé onírọ́ ni Sátánì! Síbẹ̀, torí pé Sátánì ni “ẹni tó lè fa ikú,” ó máa ń fìyẹn dẹ́rù bà wá ká lè fi Jèhófà sílẹ̀. (Héb. 2:14, 15) Nígbà míì, àwọn tí Sátánì ń lò máa ń halẹ̀ mọ́ wa pé ká sọ pé a ò sin Jèhófà mọ́, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, àwọn máa pa wá. Láwọn ìgbà míì sì rèé, Sátánì máa ń lo àìsàn tó lè la ikú lọ láti mú ká ṣe ohun tí inú Jèhófà ò dùn sí. Àwọn dókítà tàbí àwọn mọ̀lẹ́bí tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè fúngun mọ́ wa pé ká gba ẹ̀jẹ̀, ìyẹn sì máa ta ko òfin Ọlọ́run. Yàtọ̀ síyẹn, ẹnì kan lè sọ fún wa pé ká gba ìtọ́jú tó lòdì sí ohun tí Bíbélì sọ.

17 Òótọ́ ni pé a ò fẹ́ kú, ṣùgbọ́n a mọ̀ pé Jèhófà á ṣì máa nífẹ̀ẹ́ wa tá a bá tiẹ̀ kú. (Ka Róòmù 8:37-39.) Táwọn ìránṣẹ́ Jèhófà bá kú, ó ṣì máa ń rántí wọn bíi pé wọ́n wà láàyè. (Lúùkù 20:37, 38) Ó ń fojú sọ́nà fún ìgbà tó máa jí wọn dìde. (Jóòbù 14:15) Nǹkan ńlá ni Jèhófà san ká “lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòh. 3:16) A mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, ó sì ń bójú tó wa. Torí náà, dípò ká pa òfin Jèhófà tì nígbà tá a bá ṣàìsàn tó lè gbẹ̀mí wa tàbí nígbà táwọn kan bá halẹ̀ mọ́ wa pé àwọn máa pa wá, ẹ jẹ́ ká bẹ Jèhófà pé kó tù wá nínú, kó sì fún wa lọ́gbọ́n àti okun tá a nílò. Ohun tí Valérie àti ọkọ ẹ̀ ṣe gan-an nìyẹn.​—Sm. 41:3.

Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

wp17.5 5

Ṣé O Ní Áńgẹ́lì Tó Ń Dáàbò Bò Ẹ́?

Bíbélì kò kọ́ wa pé ẹnì kọ̀ọ̀kan wa la ní áńgẹ́lì tó ń dáàbò bò wá. Lóòótọ́, ìgbà kan wà tí Jésù sọ pé: “Ẹ rí i pé ẹ kò tẹ́ńbẹ́lú ọ̀kan nínú àwọn ẹni kékeré wọ̀nyí; nítorí mo sọ fún yín pé nígbà gbogbo ni àwọn áńgẹ́lì wọn ní ọ̀run ń wo ojú Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run.” (Mátíù 18:10) Àmọ́, ohun tí Jésù ní lọ́kàn ni pé àwọn áńgẹ́lì máa ń kíyè sí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọlẹ́yìn òun, kì í ṣe pé ẹnì kọ̀ọ̀kan ló ní áńgẹ́lì tó ń dáàbò bò ó. Torí náà, àwọn olùjọ́sìn tòótọ́ kì í fẹ̀mí ara wọn wewu, kí wọ́n wá máa ronú pé àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run máa dáàbò bo àwọn.

Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé àwọn áńgẹ́lì kì í ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ ni? Rárá o. (Sáàmù 91:11) Ó dá àwọn kan lójú gbangba pé Ọlọ́run ti lo áńgẹ́lì rẹ̀ láti dáàbò bo àwọn tó sì tún tọ́ wọn sọ́nà. Kenneth, tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú wà lára àwọn tó nírú èrò yìí. Àmọ́, a ò lè sọ bóyá bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sábà máa ń rí i pé àwọn áńgẹ́lì ń darí wa bí a ṣe ń ṣiṣẹ́ ìwàásù. Ṣùgbọ́n, torí pé a ò lè rí àwọn áńgẹ́lì, kò ṣeé ṣe fún wa láti mọ bí Ọlọ́run ṣe ń lò wọ́n tó láti ran ẹnì kọ̀ọ̀kan lọ́wọ́. Síbẹ̀, kì í ṣe àṣìṣe rárá tá a bá dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún ìtìlẹ́yìn èyíkéyìí tó bá ṣe fún wa.​—Kólósè 3:15; Jákọ́bù 1:17, 18.

OCTOBER 7-13

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN SÁÀMÙ 92-95

Ohun Tó Dáa Jù Téèyàn Lè Fayé Ẹ̀ Ṣe Ni Pé Kó Sin Jèhófà

w18.04 26 ¶5

Ẹ̀yin Ọ̀dọ́, Ṣé Ìjọsìn Jèhófà Ló Gbawájú ní Ìgbésí Ayé Yín?

5 Ìdí tó ṣe pàtàkì jù tó fi yẹ ká láwọn àfojúsùn tẹ̀mí ni pé a fẹ́ kí Jèhófà mọ̀ pé a mọyì ìfẹ́ rẹ̀ àtàwọn ohun tó ṣe fún wa. Onísáàmù kan sọ pé: “Ó dára láti máa fi ọpẹ́ fún Jèhófà . . . Nítorí pé ìwọ, Jèhófà, ti mú kí n máa yọ̀ nítorí ìgbòkègbodò rẹ; mo ń fi ìdùnnú ké jáde nítorí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.” (Sm. 92:1, 4) Ní báyìí tó o ṣì jẹ́ ọ̀dọ́, ronú àwọn nǹkan tí Jèhófà fún ẹ. Òun ló jẹ́ kó o wà láàyè, ó jẹ́ kó o mọ òtítọ́, ó jẹ́ kó o mọ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó jẹ́ kó o wà láàárín àwọn èèyàn rẹ̀, ó sì jẹ́ kó o ní ìrètí láti wà láàyè títí láé. Torí náà, o lè fi hàn pé o mọyì àwọn nǹkan tí Jèhófà ṣe fún ẹ tó o bá fi ìjọsìn rẹ̀ sípò àkọ́kọ́ láyé rẹ. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá túbọ̀ sún mọ́ ọn.

w18.11 20 ¶8

Ta Ló Ń Darí Èrò Rẹ?

8 Bíi ti òbí kan tó nífẹ̀ẹ́ ọmọ rẹ̀, Jèhófà náà fẹ́ káyé wa ládùn kó lóyin. (Aísá. 48:17, 18) Ìdí nìyẹn tó fi fún wa láwọn ìlànà nípa bó ṣe yẹ ká máa hùwà àti bó ṣe yẹ ká máa ṣe sáwọn míì. Ó fẹ́ ká máa fojú tóun fi ń wo nǹkan wò ó, ká sì máa fi àwọn ìlànà rẹ̀ sílò. Àwọn ìlànà yìí ò ká wa lọ́wọ́ kò rárá, kàkà bẹ́ẹ̀ wọ́n ń jẹ́ ká lè ronú jinlẹ̀, ká sì lo làákàyè wa. (Sm. 92:5; Òwe 2:1-5; Aísá. 55:9) Èyí máa jẹ́ ká ṣe àwọn ìpinnu táá fún wa láyọ̀, táá sì jẹ́ ká gbádùn ayé wa. (Sm. 1:2, 3) Ká sòótọ́, àá jàǹfààní tá a bá ń jẹ́ kí èrò Jèhófà darí wa.

w20.01 19 ¶18

Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Rẹ, Ó sì Mọyì Ẹ Gan-an!

18 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ara ti ń dara àgbà, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà mọyì rẹ àti pé ó ṣì níṣẹ́ fún ẹ láti ṣe. (Sm. 92:12-15) Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé bó ti wù kí agbára wa mọ tàbí bí ohun tá à ń ṣe nínú ìjọsìn Jèhófà ṣe kéré tó lójú wa, Jèhófà mọyì rẹ̀. (Lúùkù 21:2-4) Torí náà, ohun tí agbára rẹ ká ni kó o máa ṣe. Bí àpẹẹrẹ, o lè sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà fáwọn èèyàn, o lè gbàdúrà fáwọn ará, o sì lè fún àwọn míì níṣìírí kí wọ́n lè jẹ́ adúróṣinṣin. Jèhófà gbà pé alábàáṣiṣẹ́ òun lo jẹ́. Kì í ṣe nítorí bí agbára rẹ ṣe tó, àmọ́ torí pé ò ń ṣègbọràn sí i.​—1 Kọ́r. 3:5-9.

Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

cl 176 ¶18

‘Ìjìnlẹ̀ Ọgbọ́n Ọlọ́run Mà Pọ̀ O!’

18 Ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa ọgbọ́n àrà ọ̀tọ̀ tí Jèhófà ní rèé: “Ìjìnlẹ̀ àwọn ọrọ̀ àti ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run mà pọ̀ o! Àwọn ìdájọ́ rẹ̀ ti jẹ́ àwámáridìí tó, àwọn ọ̀nà rẹ̀ sì ré kọjá àwákàn!” (Róòmù 11:33) Fífi tí Pọ́ọ̀lù fi ohùn ìyanu sọ ọ̀rọ̀ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí fi hàn pé ọ̀rọ̀ ọ̀hún wọ̀ ọ́ lákínyẹmí ara, àní ẹ̀rù Ọlọ́run bà á gidigidi. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tó lò fún ọ̀rọ̀ náà “ìjìnlẹ̀” tan mọ́ ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò fún “ọ̀gbun àìnísàlẹ̀.” Ọ̀rọ̀ rẹ̀ wá gbé àwòrán kan yọ síni lọ́kàn. Ìyẹn ni pé bí a bá ń ronú nípa ọgbọ́n Jèhófà, ṣe ni yóò dà bí ìgbà tá à ń yọjú wo ọ̀gbun jìngòdò kan tí kò nísàlẹ̀, tó jẹ́ pé, gbígbòòrò rẹ̀ lásán tayọ òye ọmọ aráyé, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti pé kí ẹnì kan fẹ́ máa wá ya ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àwòrán rẹ̀ sílẹ̀. (Sáàmù 92:5) Ǹjẹ́ èyí gan-an ò kani láyà?

OCTOBER 14-20

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN SÁÀMÙ 96-99

“Ẹ Máa Kéde Ìhìn Rere”!

w11 3/1 6 ¶1-2

Kí Ni Ìhìn Rere?

ÀWỌN Kristẹni ní láti wàásù “ìhìn rere Ìjọba yìí” fún àwọn èèyàn, kí wọ́n sọ fún wọn pé Ìjọba yìí ló máa ṣàkóso gbogbo ayé nínú òdodo lọ́jọ́ iwájú. Àmọ́, a tún lo ọ̀rọ̀ náà, “ìhìn rere” lọ́nà míì nínú Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì tọ́ka sí “ìhìn rere ìgbàlà” (Sáàmù 96:2); “ìhìn rere Ọlọ́run” (Róòmù 15:16); àti “ìhìn rere nípa Jésù Kristi.”​—Máàkù 1:1.

Ní kúkúrú, ìhìn rere ni gbogbo òtítọ́ tí Jésù sọ àtàwọn èyí tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kọ sílẹ̀. Kí Jésù tó pa dà sí ọ̀run, ó sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́, ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́.” (Mátíù 28:19, 20) Nítorí náà, yàtọ̀ sí pé, àwọn Kristẹni tòótọ́ ní láti sọ nípa Ìjọba yìí fún àwọn èèyàn, wọ́n tún gbọ́dọ̀ sapá láti sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn.

w12 9/1 16 ¶1

Kí Ni Yóò Ṣẹlẹ̀ ní Ọjọ́ Ìdájọ́?

Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń rò pé Ọjọ́ Ìdájọ́ máa rí bí wọ́n ṣe yà á sínú àwòrán tó wà lápá ọ̀tún yìí. Ìyẹn ni pé nígbà yẹn, ọ̀kẹ́ àìmọye ọkàn máa wá síwájú ìtẹ́ Ọlọ́run, kí ó lè fi iṣẹ́ ọwọ́ wọn látẹ̀yìn wá ṣe ìdájọ́ wọn. Wọ́n ní àwọn èèyàn rere yóò wá máa gbé ní ọ̀run, àwọn èèyàn burúkú yóò sì máa joró ní ọ̀run àpáàdì. Àmọ́ Bíbélì fi hàn pé ìdí tí Ọjọ́ Ìdájọ́ fi máa dé ni láti lè dá àwọn èèyàn nídè kúrò nínú ipò àìsí ìdájọ́ òdodo. (Sáàmù 96:13) Ọlọ́run ti yan Jésù gẹ́gẹ́ bí Onídàájọ́ tó máa mú kí ìdájọ́ òdodo pa dà gbilẹ̀ ní ayé.​—Ka Aísáyà 11:1-5; Ìṣe 17:31.

w12 9/15 12 ¶18-19

Àlàáfíà Yóò Wà Fún Ẹgbẹ̀rún Ọdún Àti Títí Láé!

18 Sátánì ba àjọṣe tímọ́tímọ́ yẹn jẹ́ nígbà tó lo èèyàn láti ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà tó jẹ́ ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run. Ṣùgbọ́n láti ọdún 1914, Ìjọba Mèsáyà ti ń gbé ìgbésẹ̀ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé kó lè dá ìṣọ̀kan àti ìrẹ́pọ̀ yẹn pa dà. (Éfé. 1:9, 10) Nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, àwọn ohun àgbàyanu “tí a kò rí” báyìí á wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹlẹ̀. Lẹ́yìn náà ni “òpin” yóò dé, ìyẹn òpin Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run ti fún Jésù ní “gbogbo ọlá àṣẹ . . . ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé,” kò ṣe tán láti gba ipò mọ́ Jèhófà lọ́wọ́. Ìwà ìrẹ̀lẹ̀ rẹ̀ máa mú kó “fi ìjọba lé Ọlọ́run àti Baba rẹ̀ lọ́wọ́.” Ó máa lo ipò pàtàkì àti ọlá àṣẹ rẹ̀ “fún ògo Ọlọ́run.”​—Mát. 28:18; Fílí. 2:9-11.

19 Tó bá fi máa di ìgbà yẹn, àwọn ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run á ti di pípé. Wọ́n á fìwà ìrẹ̀lẹ̀ jọ Jésù, wọ́n á sì fínnú fíndọ̀ fara mọ́ ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ. Àǹfààní á sì wà fún wọn láti fi hàn pé ohun táwọn fẹ́ ṣe nìyẹn nígbà tí wọ́n bá yege ìdánwò ìkẹyìn. (Ìṣí. 20:7-10) Lẹ́yìn náà, gbogbo èèyàn àtàwọn áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ ni Ọlọ́run máa pa run títí láé. Ẹ sì wo bí ìyẹn á ṣe jẹ́ àkókò aláyọ̀ àti ìdùnnú tó! Gbogbo ìdílé Ọlọ́run láyé àtọ̀run á wá máa fayọ̀ yin Jèhófà, ẹni tó máa jẹ́ “ohun gbogbo fún olúkúlùkù.”​—Ka Sáàmù 99:1-3.

Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

it-2 994

Orin

Kì í ṣe inú ìwé Sáàmù nìkan la ti lè rí ọ̀rọ̀ náà “orin tuntun,” a tún lè rí i nínú ìwé tí Àìsáyà àti àpọ́sítélì Jòhánù kọ. (Sm 33:3; 40:3; 96:1; 98:1; 144:9; 149:1; Ais 42:10; Ifi 5:9; 14:3) Tá a bá wo àwọn ẹsẹ tó ṣáájú àtèyí tó tẹ̀ lé àwọn ibi tí wọ́n ti lo ọ̀rọ̀ náà “orin tuntun” nínú Bíbélì, ó jẹ́ ká rí i pé ìgbà tí Jèhófà bá fẹ́ lo ipò ẹ̀ gẹ́gẹ́ Ọba aláṣẹ láyé àtọ̀run láti ṣe ohun tuntun kan ni wọ́n máa ń kọ irú orin yìí. Onísáàmù kan fi tayọ̀-tayọ̀ kéde nínú Sáàmù 96:10 pé: “Jèhófà ti di Ọba.” Ohun ti “orin tuntun” yìí dá lé ni bí Jèhófà ṣe fẹ́ mú kí ìṣàkóso ẹ̀ dé gbogbo ayé àti ohun tí èyí máa túmọ̀ sí fáwọn tó wà láyé àti lọ́run.​—Sm 96:11-13; 98:9; Ais 42:10, 13.

OCTOBER 21-27

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN SÁÀMÙ 100-102

Fi Hàn Pé O Mọyì Ìfẹ́ Jèhófà Tí Kì Í Yẹ̀

w23.03 12 ¶18-19

Àwọn Nǹkan Tó O Máa Ṣe Kó O Lè Ṣèrìbọmi

18 Ó dáa gan-an bó o ṣe nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, kódà kò sóhun tó dáa jùyẹn lọ. (Ka Òwe 3:3-6.) Ìfẹ́ tó lágbára tó o ní fún Jèhófà máa jẹ́ kó o borí ìṣòro èyíkéyìí tó bá dé bá ẹ. Bíbélì sábà máa ń sọ̀rọ̀ nípa ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí Jèhófà máa ń fi hàn sáwa ìránṣẹ́ ẹ̀. Ìyẹn ni pé kì í pa àwa ìránṣẹ́ ẹ̀ tì, ìfẹ́ tó ní sí wa kì í sì í ṣá. (Sm. 100:5) Jèhófà dá àwa èèyàn ní àwòrán ara rẹ̀. (Jẹ́n. 1:26) Torí náà, báwo la ṣe lè ní irú ìfẹ́ tí Jèhófà ní yìí?

19 Máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà. (1 Tẹs. 5:18) Lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan máa bi ara ẹ pé, ‘Kí ni Jèhófà ṣe fún mi tó fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ mi?’ Lẹ́yìn náà, rí i dájú pé o dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà tó o bá ń gbàdúrà, kó o sì sọ àwọn ohun tó ti ṣe fún ẹ. Mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹ ló ṣe ń ṣe gbogbo ohun tó ń ṣe fún ẹ, bó ṣe ṣe fún àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. (Ka Gálátíà 2:20.) Bi ara ẹ pé, ‘Ṣé ó wu èmi náà kí n fìfẹ́ hàn sí Jèhófà?’ Ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà ò ní jẹ́ kó o máa ro èròkerò, á sì jẹ́ kó o borí ìṣòro èyíkéyìí tó bá dé bá ẹ. Á jẹ́ kó o máa jọ́sìn Jèhófà nìṣó, kó o sì máa fi hàn lójoojúmọ́ pé o nífẹ̀ẹ́ ẹ̀.

w23.02 17 ¶10

“Ẹ Máa Ronú Bó Ṣe Tọ́, Ẹ Wà Lójúfò!”

10 Díẹ̀ lára àwọn nǹkan tó yẹ ká sá fún ni kéèyàn máa tage, ọtí àmujù, àjẹjù, kéèyàn máa sọ̀rọ̀ àbùkù sáwọn ẹlòmíì, kéèyàn máa wo fíìmù ìwà ipá, àwòrán ìṣekúṣe àtàwọn nǹkan míì tó jọ wọ́n. (Sm. 101:3) Gbogbo ìgbà ni Èṣù tó jẹ́ ọ̀tá wa máa ń wá bó ṣe fẹ́ ba àjọṣe àwa àti Jèhófà jẹ́. (1 Pét. 5:8) Tá ò bá kíyè sára, Sátánì lè mú ká di onílara, oníwọra, ká máa parọ́, ká kórìíra àwọn èèyàn, ká máa gbéra ga, ká sì máa di àwọn èèyàn sínú. (Gál. 5:19-21) Níbẹ̀rẹ̀, ó lè jọ pé irú àwọn ìwà yìí ò fi bẹ́ẹ̀ burú. Àmọ́ tá ò bá tètè jáwọ́, ó lè gbilẹ̀ lọ́kàn wa, kí ìwà náà sì kó wa síṣòro.​—Jém. 1:14, 15.

w11 7/15 16 ¶7-8

Ṣé Wàá Gbọ́ Ìkìlọ̀ Tó Ṣe Kedere Tí Jèhófà Ń fún wa?

7 Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà yẹra fún àwọn olùkọ́ èké? A kì í jẹ́ kí wọ́n wá sínú ilé wa, a kì í sì í kí wọn. Bákan náà, a kì í ka ìwé wọn, a kì í wo ètò orí tẹlifíṣọ̀n tó bá ń gbé wọn sáfẹ́fẹ́, a kì í ka ohun tí wọ́n kọ sínú ìkànnì wọn lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì tàbí ká fi àlàyé tiwa kún tiwọn lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Kí nìdí tá a fi pinnu láti má ṣe ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú àwọn olùkọ́ èké? Ìdí àkọ́kọ́ ni pé a nífẹ̀ẹ́ “Ọlọ́run òtítọ́,” torí náà a kò fẹ́ láti máa tẹ́tí sí àwọn ẹ̀kọ́ èké tó ta ko òtítọ́ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Sm. 31:5; Jòh. 17:17) Ìdí mìíràn ni pé a nífẹ̀ẹ́ ètò Jèhófà tó kọ́ wa ní àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó jẹ́ àgbàyanu. Ètò Ọlọ́run ló kọ́ wa ní orúkọ Jèhófà àti ìtumọ̀ rẹ̀, ìdí tí Ọlọ́run fi dá ilẹ̀ ayé, ipò tí àwọn òkú wà, ó sì tún kọ́ wa nípa ìrètí àjíǹde. Ǹjẹ́ o ṣì lè rántí bí ayọ̀ rẹ ṣe pọ̀ tó nígbà tó o kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ àwọn nǹkan wọ̀nyí àtàwọn òtítọ́ míì tó ṣeyebíye? Torí náà, kí nìdí tí wàá fi jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tó fẹ́ láti máa bu ẹnu àtẹ́ lu ètò tó kọ́ ẹ ní gbogbo òtítọ́ tó o mọ̀ yìí ba ayọ̀ rẹ jẹ́?​—Jòh. 6:66-69.

8 Ohun yòówù káwọn olùkọ́ èké sọ, a kò ní tẹ̀ lé wọn! Kí tiẹ̀ nìdí tá a fi máa lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn tó dà bíi kànga tí kò lómi nínú yẹn, nígbà tó jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n máa tàn wá jẹ tí wọ́n á sì já wa kulẹ̀? Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká pinnu láti jẹ́ adúróṣinṣin. Ká má ṣe fi Jèhófà àti ètò rẹ̀ sílẹ̀. Ètò Jèhófà kò já wa kulẹ̀ rí, ìgbà gbogbo ló máa ń fún wa ní omi òtítọ́ mímọ́ gaara tó ń tuni lára látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ní ìmísí. Omi òtítọ́ yìí la sì fi ń pòùngbẹ wa nípa tẹ̀mí.​—Aísá. 55:1-3; Mát. 24:45-47.

Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

it-2 596

Ẹyẹ Òfú

Nígbà tí ẹyẹ òfú bá jẹun yó tán, ó máa fò lọ síbi tó dá, á máa wò suu a sì wa ọrùn kì, débi pé téèyàn bá ń wò ó lọ́ọ̀ọ́kán bó ṣe dúró tí ò sì mira ṣe ló máa dà bí òkúta funfun rìbìtì kan. Ẹyẹ yìí lè wà lójú kan kó sì sorí kọ́ fún ọ̀pọ̀ wákàtí nígbà míì, ìdí nìyẹn tí onísáàmù náà ṣe fi ara ẹ̀ wé ẹyẹ yìí nígbà tó ń ṣàpèjúwe bí ìbànújẹ́ tó bá a ṣe pọ̀ tó, ó ní: “Mo dà bí ẹyẹ òfú tó wà ní aginjù.” (Sm 102:6) A ò lè fi gbogbo ẹnu sọ pé “aginjù” tí ibi yìí ń sọ túmọ̀ sí aṣálẹ̀, kàkà bẹ́ẹ̀ ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ibi tó jìnnà síbi táwọn èèyàn ń gbé, bóyá kó jẹ́ ìbi ti ẹrẹ̀ wà. Láàárín àwọn àkókò kan lọ́dún, àwọn ẹyẹ òfú máa ń gbé láwọn ibi tí ẹrẹ̀ wà ní Àfonífojì apá àríwá Jọ́dánì. Oríṣi ẹyẹ òfú mẹ́ta ló wà ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì. Èyí tó wọ́pọ̀ jù ni wọ́n ń pè ní eastern white pelican (Pelecanus onocrotalus); àwọn tí ò sì fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀ ni Dalmatian pelican (Pelecanus crispus) àti pink-backed pelican (Pelecanus rufescens).

Ẹyẹ òfú fẹ́ràn kó lọ síbi táwọn èèyàn kì í gbé, kí wọ́n má bàa dà á láàmù. Ibẹ̀ ni wọ́n ti máa yé ẹyin tí wọ́n sì ti ń pa ọmọ. Wọ́n á tún pa dà síbẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n bá wá oúnjẹ lọ. Torí pé ẹyẹ yìí fẹ́ràn láti wà níbi tó dá ni Bíbélì ṣe ń lò ó láti ṣàpèjúwe ibi tó máa di ahoro. Nígbà tí Àìsáyà ń sọ tẹ́lẹ̀ nípa bí Édómù ṣe máa dahoro, ó sọ lọ́nà àpèjúwe pé ẹyẹ òfú lá máa gbébẹ̀. (Isa 34:11) Bákan náà, Sefanáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn ẹyẹ òfú á máa gbé láàárín àwọn ọpọ́n orí òpó ìlú Nínéfè, èyí sì ń tọ́ka sí bí ìlú náà ṣe máa pa run pátápátá àti bí àwọn èèyàn ò ṣe ní gbébẹ̀ mọ́.​—Sef 2:13, 14.

OCTOBER 28–NOVEMBER 3

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN SÁÀMÙ 103-104

“Ó Rántí Pé Erùpẹ̀ Ni Wá”

w23.07 21 ¶5

Máa Fòye Báni Lò Bíi Ti Jèhófà

5 Torí pé Jèhófà nírẹ̀lẹ̀, tó sì láàánú, ó máa ń fòye báni lò. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà fi hàn pé òun nírẹ̀lẹ̀ nígbà tó fẹ́ pa àwọn èèyàn búburú tó wà nílùú Sódómù run. Jèhófà rán àwọn áńgẹ́lì ẹ̀ pé kí wọ́n sọ fún Lọ́ọ̀tì ìránṣẹ́ ẹ̀ olóòótọ́ pé kó sá kúrò nílùú yẹn lọ sórí òkè ńlá kan. Àmọ́, ẹ̀rù ń ba Lọ́ọ̀tì láti sá lọ síbẹ̀. Torí náà, ó bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kóun àti ìdílé òun sá lọ sí Sóárì, ìyẹn ìlú kékeré kan tí Jèhófà ti sọ pé òun máa pa run. Jèhófà lè sọ pé dandan ni kí Lọ́ọ̀tì ṣe ohun tóun sọ fún un. Àmọ́ kò ṣe bẹ́ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó gba tiẹ̀ rò, ó sì dá ìlú Sóárì sí torí tiẹ̀. (Jẹ́n. 19:18-22) Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, Jèhófà tún fàánú hàn sáwọn ará ìlú Nínéfè. Ó ní kí wòlíì Jónà lọ sọ fáwọn ará ìlú náà pé òun máa pa àwọn àti ìlú náà run nítorí ìwà burúkú wọn. Àmọ́ nígbà táwọn ará Nínéfè ronú pìwà dà, Jèhófà ṣàánú wọn, kò sì pa ìlú náà run.​—Jónà 3:1, 10; 4:10, 11.

w23.09 6-7 ¶16-18

Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà Bíi Ti Sámúsìn

16 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Sámúsìn jìyà àbájáde àṣìṣe tó ṣe, kò ṣíwọ́ láti máa sin Jèhófà. Torí náà tá a bá ṣàṣìṣe, tí wọ́n sì bá wa wí tàbí tá a pàdánù àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tá a ní, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kó sú wa láti máa sin Jèhófà nìṣó. Máa rántí pé Jèhófà kì í jẹ́ kọ́rọ̀ wa sú òun. (Sm. 103:8-10) Torí náà, tá a bá tiẹ̀ ṣe àwọn àṣìṣe kan, Jèhófà ṣì lè lò wá bó ṣe lo Sámúsìn.

17 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ arákùnrin ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Michael. Ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti aṣáájú-ọ̀nà déédéé ni, kò sì fi ìjọsìn Jèhófà ṣeré rárá. Àmọ́, ó ṣeni láàánú pé ó ṣe àwọn àṣìṣe kan, ìyẹn sì jẹ́ kó pàdánù àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn ẹ̀ nínú ìjọ. Ó sọ pé: “Kó tó di pé mo pàdánù àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn yẹn, ọ̀pọ̀ nǹkan ni mò ń gbé ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Àmọ́ bí mo ṣe pàdánù àwọn àǹfààní yẹn lójijì dà bíi pé kò sóhun tí mo lè ṣe fún Jèhófà mọ́. Mo mọ̀ pé Jèhófà ò ní pa mí tì láé, àmọ́ mo máa ń rò ó pé bóyá ni mo tún lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú ẹ̀ àti pé bóyá ni màá tún lè sin Jèhófà tọkàntọkàn nínú ìjọ bí mo ṣe ń ṣe tẹ́lẹ̀.”

18 Inú wa dùn pé Michael ò jẹ́ kó sú òun. Ó tún sọ pé: “Mo ṣiṣẹ́ kára gan-an kí àárín èmi àti Jèhófà lè pa dà gún régé. Torí náà, mo máa ń gbàdúrà déédéé, mo máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo sì máa ń ṣàṣàrò.” Nígbà tó yá, Michael pa dà ní àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tó pàdánù. Ní báyìí, alàgbà àti aṣáájú-ọ̀nà déédéé ni. Ó sọ pé: “Àwọn ará, pàápàá àwọn alàgbà ràn mí lọ́wọ́, wọ́n sì fún mi níṣìírí, ìyẹn jẹ́ kí n rí i pé Jèhófà ṣì nífẹ̀ẹ́ mi. Inú mi dùn pé mo láǹfààní láti pa dà máa sìn nínú ìjọ, mo sì ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí mi yìí ti jẹ́ kí n rí i pé Jèhófà máa ń dárí ji ẹnikẹ́ni tó bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn.” Torí náà, ó dá wa lójú pé táwa náà bá ṣàṣìṣe, àmọ́ tá a ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti ṣàtúnṣe tó yẹ, tá a sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó máa lò wá, ó sì máa bù kún wa.​—Sm. 86:5; Òwe 28:13.

w23.05 26 ¶2

Ọwọ́ Ẹ Lè Tẹ Àwọn Àfojúsùn Ẹ

2 Tó o bá lóhun kan tó o fẹ́ ṣe nínú ìjọsìn Ọlọ́run, àmọ́ tí ọwọ́ ẹ ò tíì tẹ̀ ẹ́, má rẹ̀wẹ̀sì. Ìdí ni pé àwọn nǹkan kéékèèké téèyàn fẹ́ ṣe náà máa ń gba àkókò àti ìsapá. Bó o ṣe ń ṣiṣẹ́ kára kọ́wọ́ ẹ lè tẹ àwọn àfojúsùn ẹ fi hàn pé o mọyì àjọṣe tó o ní pẹ̀lú Jèhófà, o sì fẹ́ ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe nínú ìjọsìn ẹ̀. Jèhófà mọyì gbogbo ohun tó ò ń ṣe torí kò retí pé kó o ṣe ju agbára ẹ lọ. (Sm. 103:14; Míkà 6:8) Torí náà, má ṣe lé ohun tó kọjá agbára ẹ. Tó o bá sì ti ní àfojúsùn kan, kí lo lè ṣe kọ́wọ́ ẹ lè tẹ̀ ẹ́? Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àwọn àbá díẹ̀ tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́.

Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

cl 55 ¶18

Agbára Ìṣẹ̀dá​—“Olùṣẹ̀dá Ọ̀run àti Ilẹ̀ Ayé”

18 Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ látinú agbára ìṣẹ̀dá tí Jèhófà ní? Bí onírúurú nǹkan tí Ọlọ́run dá ṣe pọ̀ yanturu mú kí ẹ̀rù Ọlọ́run bani. Onísáàmù sọ̀rọ̀ tìyanutìyanu pé: “Àwọn iṣẹ́ rẹ mà pọ̀ o, Jèhófà! . . . Ilẹ̀ ayé kún fún àmújáde rẹ.” (Sáàmù 104:24) Òdodo ọ̀rọ̀ gan-an nìyẹn! Àwọn onímọ̀ nípa ohun alààyè sọ pé ó ju mílíọ̀nù kan oríṣiríṣi ọ̀wọ́ àwọn ohun alààyè tí àwọn mọ̀ pé ó ń bẹ nínú ayé yìí; àmọ́, ẹnu wọn kò tíì kò lórí èyí pàápàá, nítorí àwọn kan sọ pé ó ṣeé ṣe kí wọ́n tó mílíọ̀nù mẹ́wàá, òmíràn ní ọgbọ̀n mílíọ̀nù tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ni. Nígbà mìíràn ọmọ aráyé oníṣẹ́ ọnà máa ń rí i pé òun ti pa gbogbo itú tóun mọ̀ pé wọ́n ń fi ọnà pa tán pátá, òun ò tún rí nǹkan tuntun ṣe mọ́. Àmọ́ ní ti Jèhófà, agbára tirẹ̀ láti ronú kí ó sì ṣẹ̀dá onírúurú nǹkan yàtọ̀, kò lè pa itú ọwọ́ rẹ̀ tán láé ní tirẹ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́