Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
© 2024 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
NOVEMBER 4-10
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN SÁÀMÙ 105
“Ó Ń Rántí Májẹ̀mú Rẹ̀ Títí Láé”
Báwo La Ṣe Lè Jẹ́ Kí Ìgbàgbọ́ Wa Túbọ̀ Lágbára Pé Ayé Tuntun Máa Dé?
11 Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára àwọn ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fáwọn èèyàn ẹ̀ nígbà àtijọ́ tó dà bíi pé kò lè ṣẹ. Ọlọ́run fi dá Ábúráhámù àti Sérà lójú pé wọ́n máa bí ọmọkùnrin kan, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti darúgbó. (Jẹ́n. 17:15-17) Ó tún sọ fún Ábúráhámù pé òun máa fún àwọn àtọmọdọ́mọ ẹ̀ ní ilẹ̀ Kénáánì. Ọ̀pọ̀ ọdún làwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù fi ṣẹrú nílẹ̀ Íjíbítì, lásìkò yẹn, ó lè dà bíi pé ìlérí tí Jèhófà ṣe ò ní ṣẹ láé. Àmọ́ ìlérí náà ṣẹ. Lẹ́yìn ìyẹn, Jèhófà sọ fún Èlísábẹ́tì pé òun náà máa bí ọmọkùnrin kan, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ti darúgbó. Ó tún sọ fún Màríà wúńdíá pé ó máa bí Ọmọ òun, ìyẹn ọmọ tí Jèhófà ṣèlérí ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn nínú ọgbà Édẹ́nì pé wọ́n máa bí. Àsọtẹ́lẹ̀ náà sì ṣẹ!—Jẹ́n. 3:15.
12 Tá a bá ń ronú nípa àwọn ìlérí tí Jèhófà ṣe tó mú ṣẹ, á jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára, á sì jẹ́ kó dá wa lójú pé ayé tuntun máa dé. (Ka Jóṣúà 23:14; Àìsáyà 55:10, 11.) Ìgbàgbọ́ tó lágbára tá a ní yìí ló ń jẹ́ ká máa sọ fáwọn èèyàn pé ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé ayé máa di tuntun kì í ṣe àlá tí ò lè ṣẹ. Kódà, nígbà tí Jèhófà ń sọ̀rọ̀ nípa ọ̀run tuntun àti ayé tuntun, ó ní: “Àwọn ọ̀rọ̀ yìí ṣeé gbára lé, òótọ́ sì ni.”—Ìfi. 21:1, 5.
it-2 1201 ¶2
Ọ̀rọ̀ Náà
Gbogbo nǹkan tí Jèhófà dá ì báà jẹ́ èyí tó lẹ́mìí tàbí èyí tí ò lẹ́mìí ló máa ń tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó sì máa ń lò wọ́n láti mú ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ. (Sm 103:20; 148:8) Ọ̀rọ̀ Jèhófà ṣeé gbára lé; kì í sì í gbàgbé àwọn ìlérí tó ṣe fáwọn èèyàn ẹ̀, gbogbo ẹ̀ ló máa ń mú ṣẹ. (Di 9:5; Sm 105:42-45) Jèhófà fúnra ẹ̀ tiẹ̀ sọ pé ọ̀rọ̀ òun “máa wà títí láé”; kò sì ní pa dà sọ́dọ̀ òun láìṣẹ.—Ais 40:8; 55:10, 11; 1Pe 1:25.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
Ǹjẹ́ O Lè Fi Kún Ohun Tó Ò Ń Ṣe Nínú Ìjọsìn Ọlọ́run
13 Jẹ́ kí Jèhófà mú kó o túbọ̀ tóótun. Kí ló yẹ kó o ṣe táwọn míì bá hùwà àìdáa sí ẹ? Á dáa kó o tètè yanjú ọ̀rọ̀ náà. Tó o bá ń wá bó o ṣe máa dá ara rẹ láre nínú ọ̀rọ̀ kan, lọ́pọ̀ ìgbà ńṣe nìyẹn tún máa dá kún ohun tó wà nílẹ̀. A lè kẹ́kọ̀ọ́ lára Jósẹ́fù. Àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ hùwà àìdáa sí i, síbẹ̀ kò dì wọ́n sínú. Nígbà tó ya, àwọn kan fẹ̀sùn èké kàn án, wọ́n sì jù ú sẹ́wọ̀n láìtọ́. Síbẹ̀, ó jẹ́ kí Jèhófà tọ́ òun sọ́nà ní gbogbo àsìkò tí nǹkan nira yẹn. Kí ló wá gbẹ̀yìn ọ̀rọ̀ náà? Bíbélì sọ pé: “Àsọjáde Jèhófà tìkára rẹ̀ yọ́ ọ mọ́.” (Sm. 105:19) Àwọn àdánwò yẹn mú kí Jósẹ́fù tóótun fún iṣẹ́ pàtàkì kan. (Jẹ́n. 41:37-44; 45:4-8) Bí ìwọ náà ṣe ń bá onírúurú ìṣòro yí, bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó sì fún ẹ ní ọgbọ́n tó o nílò. Máa hùwà tútù kó o sì máa sọ̀rọ̀ tó ń tuni lára. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú pé Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́.—Ka 1 Pétérù 5:10.
NOVEMBER 11-17
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN SÁÀMÙ 106
“Wọ́n Gbàgbé Ọlọ́run Olùgbàlà Wọn”
“Ta Ni Ó Wà ní Ìhà Ọ̀dọ̀ Jèhófà?”
13 Ẹ̀rù ba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n rí àwọsánmà dúdú tó bolẹ̀, mànàmáná tó ń bù yẹ̀rì àtàwọn nǹkan àrà míì tí Ọlọ́run ṣe. Wọ́n wá bẹ Mósè pé kó jẹ́ agbẹnusọ fáwọn lọ́dọ̀ Jèhófà lórí Òkè Sínáì. (Ẹ́kís. 20:18-21) Mósè gòkè lọ, ó sì pẹ́ gan-an lórí òkè náà. Làwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàníyàn. Ó jọ pé wọn ò mọ ohun tí wọ́n máa ṣe mọ́ torí pé wọn ò rí Mósè tó jẹ́ aṣáájú wọn. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yẹn ti gbára lé Mósè jù, tó fi jẹ́ pé tí wọ́n ò bá rí i, àtisin Jèhófà máa dìṣòro fún wọn. Wọ́n wá sọ fún Áárónì pé: “Ṣe ọlọ́run kan fún wa tí yóò máa ṣáájú wa, nítorí, ní ti Mósè yìí, ẹni tí ó mú wa gòkè kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, dájúdájú, àwa kò mọ ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí i.”—Ẹ́kís. 32:1, 2.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Kẹta àti Ìkẹrin Sáàmù
106:36, 37. Àwọn ẹsẹ Bíbélì wọ̀nyí jẹ́ ká mọ̀ pé ìbọ̀rìṣà ò yàtọ̀ sí rírúbọ sí àwọn ẹ̀mí èṣù. Èyí fi hàn pé béèyàn bá ń bọ ère, irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè di ẹni táwọn ẹ̀mí èṣù ń darí. Bíbélì rọ̀ wá pé: “Ẹ máa ṣọ́ra fún àwọn òrìṣà.”—1 Jòhánù 5:21.
NOVEMBER 18-24
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN SÁÀMÙ 107-108
“Ẹ Fi Ọpẹ́ fún Jèhófà, Nítorí Ó Jẹ́ Ẹni Rere”
Kí Ìjọ Máa Yin Jèhófà
2 Ìjọ tá à ń wí yìí kì í wulẹ̀ ṣe ìpàdé ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà. Kì í ṣe ẹgbẹ́ táwọn aráàlú dá sílẹ̀ tàbí ẹgbẹ́ mìíràn láwùjọ níbi táwọn kan ti ń kóra jọ, irú bí àwọn tí iṣẹ́ tàbí òwò dà pọ̀ tàbí àwọn tó jọ nífẹ̀ẹ́ sí eré ìdárayá kan náà. Ohun tí ìjọ wà fún ní pàtàkì ni láti máa yin Jèhófà Ọlọ́run. Bó sì ti rí nìyẹn látọdúnmọdún gẹ́gẹ́ bí ìwé Sáàmù ṣe fi hàn. Sáàmù 35:18 sọ pé: “Ṣe ni èmi yóò máa gbé ọ lárugẹ nínú ìjọ ńlá; èmi yóò máa yìn ọ́ láàárín àwọn ènìyàn tí ó pọ̀ níye.” Bákan náà, Sáàmù 107:31, 32 gbà wá níyànjú pé: “Kí àwọn ènìyàn máa fi ọpẹ́ fún Jèhófà nítorí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ àti nítorí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀ fún àwọn ọmọ ènìyàn. Kí wọ́n sì máa kókìkí rẹ̀ nínú ìjọ àwọn ènìyàn.”
Fi Ọpẹ́ Fún Jèhófà Kí O sì Gba Ìbùkún
4 Ká tó lè fi hàn pé a moore a gbọ́dọ̀ máa ṣàṣàrò, ká gbà pé Jèhófà ń ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan fún wa, ká ṣàṣàrò lé wọn lórí, ká sì ronú lórí àwọn ọ̀nà tí Jèhófà ti fi inúure hàn sí wa. Nígbà tí onísáàmù kan ṣe bẹ́ẹ̀, ó yà á lẹ́nu gan-an láti rí ọ̀pọ̀ ohun àgbàyanu tí Jèhófà ti ṣe fún un.—Ka Sáàmù 40:5; 107:43.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
it-2 420 ¶4
Móábù
Nígbà tí Dáfídì fúnra ẹ̀ ń ṣàkóso, ogun ṣì wáyé láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtàwọn ọmọ Móábù. Àmọ́ Dáfídì ṣẹ́gun àwọn ará Móábù, wọ́n sì ń san ìṣákọ́lẹ̀ fún un. Nígbà tí ogun yẹn parí, ó ṣe kedere pé Dáfídì pa ìdá méjì nínú mẹ́ta àwọn ọmọ ogun Móábù. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ṣe ni Dáfídì dá àwọn ọmọ ogun Móábù yẹn dùbúlẹ̀ sórí ìlà, tó sì lo àwọn ìlà náà láti pinnu ìdá méjì tí wọ́n máa pa àti ìdá kan tí wọ́n máa dá sí. (2Sa 8:2, 11, 12; 1Kr 18:2, 11) Ó tún ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àkókò yẹn náà ni Bẹnáyà ọmọ Jèhóádà “pa àwọn ọmọkùnrin méjèèjì tí Áríélì ará Móábù bí.” (2Sa 23:20; 1Kr 11:22) Bí Dáfídì ṣe ṣẹ́gun àwọn ará Móábù yìí mú kí àsọtẹ́lẹ̀ tí Báláámù sọ ní ohun tó lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ọdún sẹ́yìn ṣẹ. Ohun tó sọ ni pé: “Ìràwọ̀ kan máa ti ọ̀dọ̀ Jékọ́bù wá, ọ̀pá àṣẹ kan sì máa dìde láti Ísírẹ́lì. Ó sì dájú pé ó máa fọ́ iwájú orí Móábù sí wẹ́wẹ́ àti agbárí gbogbo àwọn ọmọ ìdàrúdàpọ̀.” (Nọ 24:17) Bí Dáfídì ṣe ṣẹ́gun àwọn ará Móábù yìí ló mú kí onísáàmù náà sọ pé Ọlọ́run ka Móábù sí ‘bàsíà tó fi ń wẹ ẹsẹ̀.’—Sm 60:8; 108:9.
NOVEMBER 25–DECEMBER 1
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN SÁÀMÙ 109-112
Kọ́wọ́ Ti Àkóso Jésù, Ọba Wa!
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Kárùn-Ún Sáàmù
110:1, 2—Kí ni “Olúwa [Dáfídì],” ìyẹn Jésù Kristi ń ṣe ní àkókò tó fi jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún Ọlọ́run? Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó gòkè re ọ̀run ó sì ń dúró lọ́wọ́ ọ̀tún Ọlọ́run títí di ọdún 1914 tó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso. Láàárín àkókò yẹn, Jésù ń ṣàkóso lé àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tó jẹ́ ẹni àmì-òróró lórí, ó ń tọ́ wọn sọ́nà nínú iṣẹ́ ìwàásù àti iṣẹ́ sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn tí wọ́n ń ṣe, bákan náà ló sì ń múra wọn sílẹ̀ kí wọ́n lè bá a ṣàkóso nínú Ìjọba rẹ̀.—Mátíù 24:14; 28:18-20; Lúùkù 22:28-30.
Àwọn Tí Ń Bá Ọlọ́run Jà Kò Ní Borí!
3 Látìgbà tí ọ̀rúndún ogún ti bẹ̀rẹ̀ ni wọ́n ti ń gbéjà ko àwọn ènìyàn Jèhófà. Ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, àwọn tí ń pète ibi ti sapá láti ṣèdíwọ́ fún ìpolongo ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, àní láti dá a dúró pàápàá. Olórí Elénìní wa, Èṣù, tí ‘ń rìn káàkiri bíi kìnnìún tí ń ké ramúramù, tó ń wá ọ̀nà láti pani jẹ,’ ló ń tì wọ́n ṣe é. (1 Pétérù 5:8) Lẹ́yìn tí “àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè” dópin lọ́dún 1914, Ọlọ́run gbé Ọmọ rẹ̀ gorí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba tuntun fún ayé, ó sì pàṣẹ fún un pé: “Máa ṣẹ́gun lọ láàárín àwọn ọ̀tá rẹ.” (Lúùkù 21:24; Sáàmù 110:2) Agbára Ìjọba yẹn ni Kristi lò láti fi lé Sátánì jáde kúrò lọ́run, ó sì sé e mọ́ àgbègbè ilẹ̀ ayé. Inú wá ń bí Èṣù burúkú-burúkú sáwọn Kristẹni ẹni àmì òróró àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn, nítorí ó mọ̀ pé àkókò kúkúrú lòun ní. (Ìṣípayá 12:9, 17) Kí wá ni àtakò àwọn tó ń bá Ọlọ́run jà léraléra yìí ń yọrí sí?
Máa Tẹ̀ Síwájú
Bí a ṣe ń gbà ọ́ níyànjú pé kí o lo ẹ̀bùn rẹ, yóò gba pé kí o lo ìdánúṣe. Ǹjẹ́ o máa ń lo ìdánúṣe láti bá àwọn ará ṣiṣẹ́ pọ̀ lóde ẹ̀rí? Ǹjẹ́ o máa ń wá ọ̀nà láti ran àwọn ará ìjọ rẹ tó jẹ́ ẹni tuntun, ọ̀dọ́, tàbí ẹni tó ń ṣàìsàn lọ́wọ́? Ǹjẹ́ o máa ń yọ̀ǹda ara rẹ láti mú kí Gbọ̀ngàn Ìjọba wà ní mímọ́, tàbí kó o ṣèrànwọ́ ní onírúurú ọ̀nà ní àpéjọ àgbègbè, àpéjọ àyíká àti ti àkànṣe? Ṣé o lè máa ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ látìgbàdégbà? Ṣé o lè di aṣáájú ọ̀nà déédéé tàbí kí o lọ ṣèrànwọ́ nínú ìjọ tí wọ́n ti nílò ìrànlọ́wọ́ gidigidi? Bí o bá jẹ́ arákùnrin, ṣé ò ń nàgà láti dójú ìlà ohun tí Ìwé Mímọ́ là sílẹ̀ fún ẹni tí yóò bá di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí alàgbà? Bí o ṣe ń yọ̀ǹda ara rẹ láti ṣèrànwọ́ àti láti tẹ́wọ́ gba ẹrù iṣẹ́ sí, jẹ́ àmì tó ń fi ìlọsíwájú rẹ hàn.—Sm. 110:3.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
it-1 524 ¶2
Májẹ̀mú
Májẹ̀mú Láti Di Àlùfáà ní Ọ̀nà ti Melikisédékì. Ọ̀rọ̀ nípa májẹ̀mú yìí wà nínú Sáàmù 110:4. Nínú ìwé Hébérù 7:1-3, 15-17, Pọ́ọ̀lù sọ pé Kristi ni májẹ̀mú náà ṣẹ sí lára. Jésù Kristi nìkan sì ni Jèhófà bá dá májẹ̀mú yìí. Nígbà tí Jésù ń bá àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ dá májẹ̀mú ìjọba, ó tọ́ka sí májẹ̀mú yìí. (Lk 22:29) Májẹ̀mú tí Jèhófà bá Jésù Kristi dá yìí fi hàn pé Jésù tó jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run máa di àlùfáà lọ́nà ti Melikisédékì. Nígbà tí Melikisédékì wà láyé, ó jẹ́ ọba àti àlùfáà fún Ọlọ́run. Lọ́nà kan náà, Jésù Kristi máa di Ọba àti Àlùfáà Àgbà fún Ọlọ́run, àmọ́ ọ̀run ló máa jẹ́, kì í ṣe ayé níbí. Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde tó sì lọ sọ́run, ó di Àlùfáà Àgbà, nígbà tó sì yá, ó di Ọba. (Heb 6:20; 7:26, 28; 8:1) Torí pé Jéhòfá ló yan Jésù láti jẹ́ Ọba àti Àlùfáà Àgbà táá sì máa tọ́ ọ sọ́nà, ìdí nìyẹn tí májẹ̀mú yìí fi máa wà títí láé.—Heb 7:3.
DECEMBER 2-8
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN SÁÀMÙ 113-118
Kí La Máa San Pa Dà fún Jèhófà?
Kí Ìfẹ́ Máa Gbé Yín Ró
13 Látinú ọ̀rọ̀ Jésù, ó ṣe kedere pé, lékè gbogbo rẹ̀, a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Àmọ́ kò sẹ́ni tí wọ́n bí pẹ̀lú ògidì ìfẹ́ fún Jèhófà nínú wa. A gbọ́dọ̀ kọ́ ọ ni. Nígbà tá a kọ́kọ́ gbọ́ nípa rẹ̀, ohun tá a gbọ́ ló mú wa fà sún mọ́ ọn. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, a wá kẹ́kọ̀ọ́ nípa bó ṣe ṣètò ilẹ̀ ayé sílẹ̀ fún ẹ̀dá ènìyàn. (Jẹ́nẹ́sísì 2:5-23) A kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìṣarasíhùwà rẹ̀ sí aráyé, bí kò ti ta wá nù nígbà tí ẹ̀ṣẹ̀ kọ́kọ́ kó àìrójú-ráyè bá ọmọ aráyé, ṣùgbọ́n tó ṣètò bí a ó ṣe rà wá pa dà. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5, 15) Ó fi inú rere bá àwọn tó ṣolóòótọ́ lò, níkẹyìn ó sì pèsè Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ wa. (Jòhánù 3:16, 36) Bí a ti ń gba ìmọ̀ kún ìmọ̀ ni a túbọ̀ ń mọyì Jèhófà. (Aísáyà 25:1) Dáfídì Ọba sọ pé òun nífẹ̀ẹ́ Jèhófà nítorí àbójútó onífẹ̀ẹ́ Rẹ̀. (Sáàmù 116:1-9) Lóde òní, Jèhófà ń tọ́jú wa, ó ń ṣamọ̀nà wa, ó ń fún wa lókun, ó sì ń fún wa níṣìírí. Bí a bá ṣe túbọ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni ìfẹ́ wa yóò túbọ̀ máa jinlẹ̀ sí i.—Sáàmù 31:23; Sefanáyà 3:17; Róòmù 8:28.
Máa Fi Ìmoore Hàn Kó O sì Máa Fúnni Tọkàntọkàn
Ọ̀kan lára àwọn tó kọ ìwé Sáàmù sọ pé: “Kí ni èmi yóò san padà fún Jèhófà nítorí gbogbo àǹfààní tí mo rí gbà láti ọ̀dọ̀ rẹ̀?” (Sm. 116:12) Àwọn àǹfààní wo ni onísáàmù yìí ti rí gbà? Jèhófà dúró tì í nígbà tó wà nínú “wàhálà àti ẹ̀dùn-ọkàn.” Bákan náà, Jèhófà “gba ọkàn [rẹ̀] sílẹ̀ lọ́wọ́ ikú.” Ó wá ń wá ọ̀nà tó máa gbà ‘san án pa dà’ fún Jèhófà. Kí wá ni onísáàmù yẹn máa ṣe? Ó ní: “Àwọn ẹ̀jẹ́ mi ni èmi yóò san fún Jèhófà.” (Sm. 116:3, 4, 8, 10-14) Ó pinnu pé òun á mú gbogbo ẹ̀jẹ́ tóun ti jẹ́ fún Jèhófà ṣẹ, òun á sì máa ṣàwọn ojúṣe òun.
Ìwọ náà lè ṣe bẹ́ẹ̀. Lọ́nà wo? Nípa gbígbé ìgbé ayé rẹ lọ́nà tó bá àwọn òfin àti ìlànà Ọlọ́run mu nígbà gbogbo. Torí náà, jẹ́ kí jíjọ́sìn Jèhófà jẹ́ ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nígbèésí ayé ẹ, kó o sì jẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run máa darí ẹ nínú gbogbo nǹkan tó o bá ń ṣe. (Oníw. 12:13; Gál. 5:16-18) Ká sòótọ́, kò sí bó o ṣe lè san gbogbo ohun tí Jèhófà ti ṣe fún ẹ pa dà. Síbẹ̀, ó máa ń ‘mú ọkàn Jèhófà yọ̀’ tó bá rí i pé ò ń fi tọkàn tara ṣe iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. (Òwe 27:11) Ẹ ò rí i pé àǹfààní àgbàyanu ló jẹ́ láti múnú Jèhófà dùn lọ́nà yìí!
Àwọn Ohun Tá A Rí Kọ́ Nínú Ìwé Léfítíkù
9 Ẹ̀kọ́ kejì: À ń sin Jèhófà torí pé a mọyì ohun tó ṣe fún wa. Ká lè lóye kókó yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa ẹbọ ìrẹ́pọ̀ táwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń rú. Ìwé Léfítíkù jẹ́ ká rí i pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀ “láti fi ṣe ìdúpẹ́.” (Léf. 7:11-13, 16-18) Kò sí òfin tó sọ pé ọmọ Ísírẹ́lì kan gbọ́dọ̀ rú ẹbọ yìí, òun fúnra rẹ̀ ló pinnu láti ṣe bẹ́ẹ̀. Lédè míì, ìfẹ́ tí ọmọ Ísírẹ́lì kan ní fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ ló mú kó fínnúfíndọ̀ rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀. Ẹni tó rú ẹbọ yìí, ìdílé rẹ̀ àtàwọn àlùfáà máa jẹ lára ẹran tó fi rúbọ náà. Àmọ́, àwọn apá kan wà lára ẹran náà tó jẹ́ ti Jèhófà nìkan. Apá wo nìyẹn?
10 Ẹ̀kọ́ kẹta: Torí pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ohun tó dáa jù lọ la máa ń fún un. Ọ̀rá ni Jèhófà kà sí pàtàkì jù lára ẹran. Ó tún jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn apá míì bíi kíndìnrín ṣe pàtàkì sí òun. (Ka Léfítíkù 3:6, 12, 14-16.) Ẹ wá rídìí tí inú Jèhófà fi máa ń dùn tí ọmọ Ísírẹ́lì kan bá fínnúfíndọ̀ fi ọ̀rá àtàwọn apá pàtàkì míì rúbọ sí i. Ọmọ Ísírẹ́lì tó fi àwọn nǹkan yìí rúbọ fi hàn pé ohun tó dára jù lọ lòun fún Jèhófà. Lọ́nà kan náà, Jésù fínnúfíndọ̀ fi ohun tó dára jù lọ rúbọ sí Jèhófà ní ti pé ó sin Jèhófà tọkàntara torí ìfẹ́ tó ní fún un. (Jòh. 14:31) Inú Jésù máa ń dùn gan-an láti ṣe ìfẹ́ Jèhófà torí pé ó nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ̀ dénúdénú. (Sm. 40:8) Ẹ wo bí inú Jèhófà ṣe máa dùn tó pé Jésù sin òun tọkàntọkàn!
11 Iṣẹ́ ìsìn wa jọ ẹbọ ìrẹ́pọ̀ torí pé àwa fúnra wa la pinnu pé a máa sin Jèhófà. Torí pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tọkàntọkàn, ohun tó dáa jù là ń fún un. Ẹ wo bí inú Jèhófà ṣe máa dùn tó bó ṣe ń rí ẹgbàágbèje èèyàn tó ń jọ́sìn rẹ̀ torí ìfẹ́ tí wọ́n ní fún un! Kì í ṣe pé Jèhófà mọrírì ohun tá à ń ṣe nínú ìjọsìn rẹ̀ nìkan, ó tún mọyì ohun tó ń sún wa ṣe é, ìyẹn sì ń tù wá nínú gan-an. Bí àpẹẹrẹ, bóyá àgbàlagbà ni ẹ́ tó ò sì lè ṣe tó bó o ṣe fẹ́, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà lóye rẹ. Ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé ohun tó ò ń ṣe kò tó nǹkan, àmọ́ ohun tí Jèhófà ń wò ni ìfẹ́ àtọkànwá tó o ní, torí ìfẹ́ yẹn ló jẹ́ kó o máa ṣe gbogbo ohun tágbára rẹ gbé. Inú Jèhófà ń dùn sí ẹ torí pé ohun tó dáa jù lọ lò ń fún un.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Onísáàmù kan tí Ọlọ́run mí sí kọ ọ́ lórin pé: “Iyebíye ní ojú Jèhófà ni ikú àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀.” (Sm. 116:15) Ìwàláàyè olùjọ́sìn Jèhófà kọ̀ọ̀kan ṣe iyebíye gan-an ní ojú rẹ̀. Àmọ́, ohun tí onísáàmù náà ní lọ́kàn nínú Sáàmù 116 yìí ré kọjá ikú ẹnì kan ṣoṣo.
Bí ẹnì kan bá ń sọ àsọyé ìsìnkú Kristẹni kan, kò yẹ kó lo ọ̀rọ̀ inú Sáàmù 116:15 fún onítọ̀hún, kódà bí ẹni náà bá tiẹ̀ jẹ́ olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà títí dójú ikú. Kí nìdí? Ìdí ni pé ọ̀rọ̀ inú Sáàmù yẹn ní ìtumọ̀ tó gbòòrò ju ìyẹn lọ. Ó túmọ̀ sí pé Ọlọ́run ka ikú àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀ lódindi sí àdánù ńlá tó bẹ́ẹ̀ tó fi jẹ́ pé kò ní gbà kí irú rẹ̀ wáyé.—Wo Sáàmù 72:14; 116:8.
DECEMBER 9-15
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN SÁÀMÙ 119:1-56
“Báwo Ni Ọ̀dọ́kùnrin Ṣe Lè Mú Ipa Ọ̀nà Rẹ̀ Mọ́?”
w87 11/1 18 ¶10
Ìwọ Ha Ńwá Ní Mímọ́tónítóní ní Gbogbo Ọ̀nà Bí?
10 Ní Ephesus 5:5 Paul ṣe ìkìlọ̀ pé: “Nitori ẹyin mọ̀ eyi daju pé, kò sí panṣágà, tabi aláìmọ́ eniyan, tabi olojúkòkòrò, tii ṣe olùbọ̀rìṣá, ti yoo ní ìnì kan ní ijọba Kristi ati ti Ọlọrun.” Sibẹsibẹ, ẹgbẹẹgbẹrun ní ọdún kọ̀ọ̀kan ni a ńfìbáwí-tọ́sọ́nà tabi yọlégbẹ́ nitori ìbálòpọ̀ takọtabo oníwàpálapála—‘ṣíṣẹ̀ lòdìsí ara.’ (1 Corinth 6:18) Niye igba, ó wulẹ̀ jẹ́ ìyọrísí kan ti ṣísàì “ṣọ́ ẹ̀sọ́ gẹgẹ bí ọ̀rọ̀ [Ọlọrun] ti wí.” (Psalm 119:9, NW ) Ọ̀pọ̀ awọn arakunrin, fun apẹẹrẹ, máa ńpa ẹ̀ṣọ́ wọn nipa ọ̀ná-ìwàhíhù tì sápákan ní awọn sáà àkókò-ìsinmi ráńpẹ́ kuro lẹnu iṣẹ́. Ní kíkọ̀ ìbákẹ́gbẹ́ ìṣàkóso Ọlọrun silẹ, wọn bẹrẹ ìbádọ́rèẹ́ pẹlu awọn olùlò-àkókò-ìsinmi ráńpẹ́ kuro lẹnu iṣẹ ti ayé. Ní wíwòyeronú pé awọn wọnyi jẹ́ ‘eniyan rere niti-gidi,’ awọn Kristian kan ti darapọ̀ mọ̀ wọn ninu awọn ìgbòkègbodò tí a lè gbébéèrè-dìde sí. Lọna tí ó farajọra, awọn miiran ti ṣe ọ̀rẹ́ àserékọjá-ààlà pẹlu awọn òṣìṣẹ̀ ẹlẹgbẹ wọn. Alàgbà Kristian kan ṣe wọléwọ̀de pẹlu obinrin ẹni-a-gbàsíṣẹ́ kan dé àyè pé ó pa idílè rẹ̀ tì ó sì bẹrẹsii gbé papọ́ pẹlu rẹ̀! Ìyọlẹ́gbẹ́ ni ó yọrísí. Bawo ni awọn ọ̀rọ̀ Bibeli ti jẹ́ otitọ tó pe, “Ẹgbẹ buburu ńbà ìwàrere jẹ́”!—1 Corinth 15:33.
“Àwọn Ìránnilétí Rẹ Ni Mo Ní Ìfẹ́ni Fún”
JÈHÓFÀ máa ń pèsè ìránnilétí fún àwọn èèyàn rẹ̀ kí wọ́n lè mọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe nípa àwọn ìṣòro tó wà láwọn àkókò tó le koko tí à ń gbé yìí. Ìgbà tá a bá ń ka Bíbélì tàbí tá à ń gbọ́ ọ̀rọ̀ táwọn ará wa bá ń sọ látorí pèpéle tàbí látorí ìjókòó wọn nípàdé la máa ń gbọ́ ìránnilétí wọ̀nyí. Ọ̀pọ̀ lára àwọn nǹkan wọ̀nyí ni kì í ṣe tuntun sí wa. Ó ṣeé ṣe ká ti gbọ́ tàbí ká ti kà nípa wọn nígbà kan sẹ́yìn. Àmọ́, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àwa ẹ̀dá aláìpé máa ń gbàgbé nǹkan, ìgbà gbogbo ló yẹ ká máa gbé àwọn òfin àtàwọn ìlànà Jèhófà, àtàwọn ohun tó ní lọ́kàn láti ṣe lọ́jọ́ iwájú yẹ̀ wò. Ó yẹ ká mọrírì àwọn ìránnilétí Ọlọ́run. Wọ́n ń fún wa lókun ní ti pé wọ́n ń jẹ́ ká máa rántí ìdí tá a fi pinnu láti máa gbé ìgbé ayé tí inú Ọlọ́run dùn sí. Abájọ tí onísáàmù fi kọrin sí Jèhófà pé: “Àwọn ìránnilétí rẹ ni mo ní ìfẹ́ni fún.”—Sáàmù 119:24.
Má Ṣe Máa Wo Àwọn Ohun Tí Kò Ní Láárí!
2 Àmọ́ ṣá o, àwọn ohun tá à ń fojú rí tún lè ṣàkóbá fún wa. Àwòrán tí ojú bá gbé lọ sínú ọpọlọ máa ń lágbára débi pé ó lè mú kí àwọn èrò kan sọ sí wa lọ́kàn tàbí kó túbọ̀ máa wù wá láti ṣe àwọn ohun kan. Àti pé, nítorí pé à ń gbé nínú ayé bíbàjẹ́ bàlùmọ̀ tí Sátánì Èṣù ń ṣàkóso, táwọn èèyàn ti máa ń fẹ́ tẹ́ ìfẹ́ ara wọn lọ́rùn, ọ̀pọ̀ àwòrán àti àwọn ìpolongo èké tó ń rọ́ wọlé tọ̀ wá wá lè kóni ṣìnà, kódà kó jẹ́ pé ńṣe la wò wọ́n fìrí. (1 Jòh. 5:19) Abájọ tí onísáàmù náà fi bẹ Ọlọ́run pé: “Mú kí ojú mi kọjá lọ láìrí ohun tí kò ní láárí; pa mí mọ́ láàyè ní ọ̀nà tìrẹ.”—Sm. 119:37.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
Gbẹ́kẹ̀ Lé Ọ̀rọ̀ Jèhófà
2 Kókó inú Sáàmù ìkọkàndínlọ́gọ́fà ni pé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe pàtàkì gan-an. Nínú Bíbélì èdè Hébérù ìpilẹ̀ṣẹ̀, ńṣe lẹni tó kọ orin yìí pín orin náà sí ìsọ̀rí-ìsọ̀rí, álífábẹ́ẹ̀tì èdè Hébérù ló sì fi to orin náà bóyá torí kó bàa lè rọrùn láti rántí. Àwọn lẹ́tà a, b, d, èdè Hébérù yìí ló fi bẹ̀rẹ̀ ọ̀kọ̀ọ̀kan ẹsẹ mẹ́rìndínlọ́gọ́sàn-án [176] tí orin yìí ní. Ìsọ̀rí méjìlélógún ló pín orin náà sí. Ẹsẹ mẹ́jọ ló wà nínú ìsọ̀rí kọ̀ọ̀kan, lẹ́tà kan náà ló sì fi bẹ̀rẹ̀ ẹsẹ mẹ́jẹ̀ẹ̀jọ. Sáàmù yìí mẹ́nu kan àwọn nǹkan bí ọ̀rọ̀, òfin, ìránnilétí, ọ̀nà, àṣẹ ìtọ́ni, ìlànà, àṣẹ, ìpinnu ìdájọ́, àsọjáde àti ìlànà àgbékalẹ̀ Ọlọ́run. A ó fi àpilẹ̀kọ yìí àtèyí tó tẹ̀ lé e ṣàlàyé Sáàmù ìkọkàndínlọ́gọ́fà, Bíbélì tá a sì túmọ̀ lọ́nà tó péye látinú Bíbélì lédè Hébérù la ó fi ṣe àlàyé yìí. Tá a bá ṣàṣàrò lórí àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ìránṣẹ́ Jèhófà láyé àtijọ́ àti lóde òní, á jẹ́ ká túbọ̀ mọyì orin tí Ọlọ́run mí sí yìí, á sì tún jẹ́ ká túbọ̀ mọrírì Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
DECEMBER 16-22
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN SÁÀMÙ 119:57-120
Ohun Táá Jẹ́ Kó O Lè Fara Da Ìṣòro Ẹ
“Mo Mà Nífẹ̀ẹ́ Òfin Rẹ O!”
2 O lè máa ronú pé, “Báwo ni òfin Ọlọ́run ṣe lè tu onísáàmù yìí nínú?” Dídá tó dá a lójú pé ọ̀rọ̀ òun jẹ Jèhófà lógún ló fún un lókun. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀tá rẹ̀ ti fayé sú u, inú onísáàmù yìí dùn torí pé ó mọ àwọn àǹfààní tó wà nínú pípa òfin Ọlọ́run mọ́. Ó mọ̀ pé ọ̀nà tó tọ́ ni Jèhófà gbà ń bá òun lò. Ìyẹn nìkan kọ́ o, ìtọ́sọ́nà tó wà nínú òfin Ọlọ́run tí onísáàmù yìí ń tẹ̀ lé mú kó gbọ́n ju àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ, kódà ó tún dáàbò bò ó. Pípa tó ń pa òfin náà mọ́ sì jẹ́ kó ní àlàáfíà àti ìbàlẹ̀ ọkàn.—Sáàmù 119:1, 9, 65, 93, 98, 165.
Ǹjẹ́ O Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Ìránnilétí Jèhófà Lọ́nà Tó Kọyọyọ?
3 Àwọn ìránnilétí Ọlọ́run ṣeyebíye sí onísáàmù náà, ẹni tó kọ ọ́ lórin pé: “Mo ṣe wéré, n kò sì jáfara láti pa àwọn àṣẹ rẹ mọ́. Àní ìjàrá àwọn ẹni burúkú yí mi ká. Òfin rẹ ni èmi kò gbàgbé.” (Sáàmù 119:60, 61) Àwọn ìránnilétí Jèhófà ń ràn wá lọ́wọ́ láti fara da inúnibíni, nítorí a ní ìgbọ́kànlé pé Baba wa ọ̀run lè gé okùn ìdíwọ́ táwọn ọ̀tá ta yí wa ká. Nígbà tí àkókò bá sì tó lójú rẹ̀, ó ń yọ wá kúrò nínú àwọn ìṣòro yẹn, kí ó lè ṣeé ṣe fún wa láti ṣe iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà.—Máàkù 13:10.
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Kárùn-Ún Sáàmù
119:71—Àǹfààní wo la lè rí nínú Ìpọ́njú? Ìṣòro lè kọ́ wa láti túbọ̀ máa gbára lé Jèhófà, láti máa gbàdúrà sí i tọkàntara, ká túbọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gan-an, ká sì máa fi ohun tí Bíbélì sọ sílò. Ìyẹn nìkan kọ́, ohun tá a bá ṣe nígbà tá a wà nínú ìpọ́njú lè jẹ́ ká rí àwọn ibi tá a kù sí, ká sì ṣàtúnṣe. Tá a bá jẹ́ kí ìpọ́njú sọ wá dẹni rere sí i, a ò ní máa bínú tí ìpọ́njú bá dé bá wa.
‘Ẹ Máa Sunkún Pẹ̀lú Àwọn Tí Ń Sunkún’
3 Tó bá di pé ká tu èèyàn nínú, kò sẹ́ni tó lè tuni nínú bíi Jèhófà Baba wa ọ̀run tó jẹ́ Ọlọ́run àánú. (Ka 2 Kọ́ríńtì 1:3, 4.) Jèhófà ò lẹ́gbẹ́ tó bá di pé ká gba tèèyàn rò, ó sì fi dá àwa èèyàn rẹ̀ lójú pé: “Èmi fúnra mi ni Ẹni tí ń tù yín nínú.”—Aísá. 51:12; Sm. 119:50, 52, 76.
5 Ọkàn wa balẹ̀ pé Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́. Torí náà, ká sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn wa fún Jèhófà, ká sì jẹ́ kó mọ bí ẹ̀dùn ọkàn tá a ní ṣe rí lára wa. A mà dúpẹ́ o, pé Jèhófà lóye wa, ó mọ ẹ̀dùn ọkàn wa, ó sì ń pèsè ìtùnú tá a nílò gan-an! Àmọ́ báwo ló ṣe ń tù wá nínú?
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Kárùn-Ún Sáàmù
119:96—Kí ni “òpin gbogbo ìjẹ́pípé” túmọ̀ sí? Ohun tí onísáàmù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ni ojú tí ẹ̀dá èèyàn fi ń wo ìjẹ́pípé. Ó lè jẹ́ pé ohun tó ní lọ́kàn ni pé ó níbi tí òye èèyàn mọ nípa ìjẹ́pípé. Àmọ́, àwọn òfin Ọlọ́run kò ní irú ààlà bẹ́ẹ̀. Gbogbo ohun tí à ń ṣe nígbèésí ayé wa pátá ni ìtọ́sọ́nà inú rẹ̀ wúlò fún.”
DECEMBER 23-29
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN SÁÀMÙ 119:121-176
Má Ṣe Kó Ẹ̀dùn Ọkàn Tí Ò Pọn Dandan Bá Ara Ẹ
Máa Fi Àwọn Òfin àti Ìlànà Jèhófà Kọ́ Ẹ̀rí Ọkàn Rẹ
5 Kí àwọn òfin Jèhófà tó lè ṣe wá láǹfààní, ó yẹ ká máa kà wọ́n, ká sì lóye wọn. Ìyẹn nìkan kọ́ o, a tún gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ àwọn òfin Jèhófà, ká sì mọyì wọn. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Ẹ kórìíra ohun búburú, kí ẹ sì nífẹ̀ẹ́ ohun rere.” (Ámósì 5:15) Báwo la ṣe lè ṣe é? Ọ̀nà kan tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká kọ́ bá a ṣe lè máa fi ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan wò ó. Bí àpẹẹrẹ: Ká sọ pé o kì í rí oorun sùn dáadáa, o wá lọ rí dókítà. Dókítà wá ka àwọn oúnjẹ aṣaralóore tó yẹ kó o máa jẹ, ó ní kó o máa ṣe eré ìdárayá, kó o sì ṣe àwọn àyípadà kan. Nígbà tó o ṣe àwọn nǹkan yẹn, o bẹ̀rẹ̀ sí í rí oorun sùn. Ó dájú pé inú rẹ máa dùn gan-an, wàá sì mọyì ohun tí dókítà náà ṣe fún ẹ.
6 Lọ́nà kan náà, àwọn òfin tí Ẹlẹ́dàá fún wa máa ń jẹ́ kí ìgbésí ayé wa nítumọ̀, ó sì ń dáàbò bò wá ká má bàa kó sí páńpẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ ká sì jìyà àbájáde rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ẹ ronú nípa àǹfààní tó wà nínú pípa òfin Ọlọ́run mọ́ tó bá dọ̀rọ̀ kéèyàn máa gbèrò ibi, irọ́ pípa, olè jíjà, ìṣekúṣe, ìwà ipá àti ìbẹ́mìílò. (Ka Òwe 6:16-19; Ìṣí. 21:8) Nígbà táwa náà bá ń rí àǹfààní tó wà nínú pípa òfin Ọlọ́run mọ́, ìyẹn á jẹ́ ká túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ká sì mọyì àwọn òfin tó fún wa.
Ẹyin Èwe—Ki Ni Ẹyin Ń Lépa?
12 Ju gbogbo rẹ̀ lọ, o gbọdọ kẹkọọ lati koriira, ṣe họ́ọ̀ si, ki o sì kẹgan ohun ti o buru. (Orin Dafidi 97:10) Bawo ni o ṣe lè koriira ohun ti o lè dabi amuniloriya tabi igbadun lakọọkọ? Nipa rironu nipa awọn abajade rẹ̀! “Ki a má ṣe tàn yin jẹ; a kò lè gan Ọlọrun: nitori ohunkohun ti eniyan bá funrugbin, ohun ni yoo sì ká. Nitori ẹni ti o bá ń funrugbin sipa ti ara, nipa ti araarẹ ni yoo ká idibajẹ.” (Galatia 6:7, 8) Nigba ti a bá dán ọ wò lati juwọsilẹ fun ifẹ-ainijaanu, ronu nipa abajade ti ó ga julọ—bi eyi yoo ṣe dun Jehofa Ọlọrun (Fiwe Orin Dafidi 78:41.) Ronu, pẹlu, nipa ṣiṣeeṣe oyún ti a kò fẹ́ tabi kíkó àrùn kan, iru bi AIDS. Ṣagbeyẹwo iparun niti ero-imọlara ati ipadanu ọ̀wọ̀ ara-ẹni ti iwọ yoo jiya rẹ̀. Awọn abajade ọlọjọ pipẹ lè wà pẹlu. Kristian obinrin kan jẹwọ pe: “Emi ati ọkọ mi ní ibalopọ takọtabo pẹlu awọn ẹlomiran ṣaaju ki a tó ri araawa. Bi o tilẹ jẹ pe a jẹ́ Kristian lonii, igbesi-aye wa nipa ti ibalopọ takọtabo jẹ́ orisun ìjà ati owú ninu igbeyawo wa.” Eyi ti kò tun yẹ lati gbojufoda, bi o ti wu ki o ri, ni ipadanu awọn anfaani iṣakoso Ọlọrun rẹ tabi ṣiṣeeṣe naa lati di ẹni ti a lé kuro ninu ijọ Kristian! (1 Korinti 5:9-13) Ǹjẹ́ igbadun onigba kukuru kan ha yẹ fun iru owó giga bẹẹ bi?
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
“Jẹ́ Kó Túbọ̀ Dá Ẹ Lójú Pé Òtítọ́ Ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run”
2 Àwa ìránṣẹ́ Jèhófà gbà pé òun ni “Ọlọ́run òtítọ́” àti pé ohun tó dáa jù ló fẹ́ fún wa. (Sm. 31:5; Àìsá. 48:17) A fọkàn tán ohun tá a kà nínú Bíbélì pé “òtítọ́ ni kókó inú ọ̀rọ̀ [Ọlọ́run].” (Ka Sáàmù 119:160.) A gbà pé òótọ́ lohun tí ọ̀mọ̀wé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì sọ pé: “Kò sí irọ́ kankan nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, gbogbo nǹkan tó bá sì sọ ló máa ń ṣẹ. Àwọn èèyàn Ọlọ́run máa ń gba ohun tó sọ gbọ́ torí pé wọ́n fọkàn tán Ọlọ́run.”
DECEMBER 30–JANUARY 5
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN SÁÀMÙ 120-126
Wọ́n Fi Omijé Fúnrúgbìn, Àmọ́ Wọ́n Fi Ayọ̀ Kórè
Ìbùkún Ni Fún Àwọn Tó Ń fi Ògo Fún Ọlọ́run
10 Nígbà tá a bá gba àjàgà dídi ọmọ ẹ̀yìn Jésù sọ́rùn, ńṣe là ń kọjú ìjà sí Sátánì. Ìwé Jákọ́bù 4:7 ṣèlérí pé: “Ẹ kọ ojú ìjà sí Èṣù, yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ yín.” Àmọ́, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé ó rọrùn láti ṣe bẹ́ẹ̀ o. Sísin Ọlọ́run gba pé ká sapá dé àyè kan. (Lúùkù 13:24) Àmọ́ Bíbélì ṣe ìlérí yìí nínú Sáàmù 126:5 pé: “Àwọn tí ń fi omijé fúnrúgbìn yóò fi igbe ìdùnnú ká a.” Bẹ́ẹ̀ ni o, Ọlọ́run tá a ń sin kì í ṣe aláìmoore. Ó jẹ́ “olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a,” ó sì ń bù kún àwọn tó ń fi ògo fún un.—Hébérù 11:6.
Ṣé O Ní Ìgbàgbọ́ Tó Lágbára Tó?
17 Ṣé o ní ẹ̀dùn ọkàn torí èèyàn ẹ kan tó kú? O lè jẹ́ kí ìgbàgbọ́ ẹ túbọ̀ lágbára nínú ìrètí àjíǹde tó o bá ń kà nípa àwọn tá a jí dìde nínú Bíbélì. Àbí kẹ̀, ṣé ẹnì kan tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́ nínú ìdílé ẹ ló ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá ẹ? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ṣèwádìí kó lè dá ẹ lójú pé ọ̀nà tó dáa jù ni Jèhófà máa ń gbà bá wa wí. Ìṣòro yòówù kó o máa kojú, jẹ́ kó mú kí ìgbàgbọ́ ẹ túbọ̀ lágbára. Sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn ẹ fún Jèhófà, má ya ara ẹ sọ́tọ̀, ṣe ni kó o túbọ̀ sún mọ́ àwọn ará. (Òwe 18:1) Tó o bá ń rántí àwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ, tíyẹn sì ń jẹ́ kó o máa sunkún, máa ṣe àwọn nǹkan tó máa jẹ́ kó o fara dà á. (Sm. 126:5, 6) Máa lọ sí ìpàdé àti òde ẹ̀rí déédéé, kó o sì máa ka Bíbélì lójoojúmọ́. Yàtọ̀ síyẹn, máa ronú nípa àwọn ohun rere tí Jèhófà máa ṣe fún ẹ lọ́jọ́ iwájú. Bó o sì ṣe ń rí bí Jèhófà ṣe ń ràn ẹ́ lọ́wọ́, ṣe ni ìgbàgbọ́ ẹ á túbọ̀ máa lágbára.
Ẹ Máa Bá Iṣẹ́ Ìkórè Náà Lọ Ní Rabidun!
13 Ìtùnú ńláǹlà ni ọ̀rọ̀ inú Sáàmù 126:5, 6 jẹ́ fáwọn olùkórè tí ń ṣiṣẹ́ fún Ọlọ́run, pàápàá jù lọ àwọn tó ń fojú winá inúnibíni. Ibẹ̀ kà pé: “Àwọn tí ń fi omijé fúnrúgbìn yóò fi igbe ìdùnnú ká a. Láìkùnà, ẹni tí ń jáde lọ, àní tí ó ń sunkún, bí ó ti gbé irúgbìn ẹ̀kún àpò dání, láìkùnà, yóò fi igbe ìdùnnú wọlé wá, bí ó ti gbé àwọn ìtí rẹ̀ dání.” Ọ̀rọ̀ onísáàmù nípa gbígbìn àti kíkárúgbìn ṣàpèjúwe àbójútó àti ìbùkún Jèhófà lórí àwọn àṣẹ́kù tó padà wá láti oko ẹrú Bábílónì ìgbàanì. Inú wọ́n dùn gan-an nígbà táa tú wọn sílẹ̀, ṣùgbọ́n ó ṣeé ṣe kí wọ́n ti sunkún nígbà tí wọ́n ń fúnrúgbìn sórí ilẹ̀ ahoro tí ẹnikẹ́ni ò dáko sí fún àádọ́rin ọdún tí wọ́n fi wà ní ìgbèkùn. Àmọ́ o, àwọn tó ń fúnrúgbìn nìṣó, tí wọ́n sì ń bá iṣẹ́ ìkọ́lé lọ, jèrè iṣẹ́ ọwọ́ wọn, wọ́n sì rí ìtẹ́lọ́rùn nínú òógùn ojú wọn.
14 Omijé lè máa dà lójú wa nígbà tí ìdánwò bá dé bá wa tàbí nígbà tí àwa tàbí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa bá ń jìyà nítorí òdodo. (1 Pétérù 3:14) Nígbà tá a bá kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìkórè náà, ó lè nira gan-an lójú wa, bóyá nítorí ó jọ pé asán ni gbogbo akitiyan wa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà. Ṣùgbọ́n bí a bá ń fúnrúgbìn tá a sì ń bomi rin nìṣó, Ọlọ́run yóò jẹ́ kó dàgbà, àní ré kọjá ibi tá a fojú sí. (1 Kọ́ríńtì 3:6) Èyí hàn kedere nínú iye Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde tá a gbé ka Ìwé Mímọ́, tá a ti pín kiri.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
Agbára Ìdáàbòboni—‘Ọlọ́run Jẹ́ Ibi Ìsádi fún Wa’
15 Kọ́kọ́ wo ọ̀ràn ààbò nípa ti ara ná. Lápapọ̀, àwa olùjọsìn Jèhófà lè retí ààbò nípa ti ara gẹ́gẹ́ bí àwùjọ kan. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ńṣe ni Sátánì yóò máa he wa bí ẹní he ìgbín. Òótọ́ ọ̀rọ̀ kan nìyí: Kó sóhun tí ì bá dùn mọ́ Sátánì “olùṣàkóso ayé yìí” bíi pé kó rí i kí ìsìn tòótọ́ pa rẹ́. (Jòhánù 12:31; Ìṣípayá 12:17) Ọ̀pọ̀ àwọn ìjọba tó lágbára jù lọ láyé ló ti fòfin de iṣẹ́ ìwàásù wa tí wọ́n sì ti gbìyànjú láti pa wá rẹ́ pátápátá. Síbẹ̀síbẹ̀, mìmì kan ò mi àwọn èèyàn Jèhófà, wọ́n ṣì ń bá iṣẹ́ ìwàásù wọn lọ láìfọ̀tápè! Kí nìdí tí àwọn orílẹ̀-èdè alágbára ò fi lè fòpin sí ìgbòkègbodò àwùjọ àwọn Kristẹni tí ò tó nǹkan kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn, tí wọ́n sì tún dà bí èyí tí kò láàbò kankan yìí? Ìdí ni pé Jèhófà ti fi ìyẹ́ apá rẹ̀ alágbára dáàbò bò wá!—Sáàmù 17:7, 8.