Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
© 2024 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
JANUARY 6-12
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN SÁÀMÙ 127-134
Ẹ̀yin Òbí—Ẹ Máa Bójú Tó Ẹ̀bùn Iyebíye Tí Jèhófà Fún Yín
Mọyì Àǹfààní Tó O Ní Pé O Wà Nínú Ìdílé Jèhófà
9 Jèhófà dá wa lọ́nà tá a fi lè bímọ, ó sì fẹ́ ká kọ́ àwọn ọmọ náà kí wọ́n lè nífẹ̀ẹ́ òun, kí wọ́n sì sin òun. Tó o bá jẹ́ òbí, ṣé o mọyì ẹ̀bùn iyebíye tí Jèhófà fún ẹ yìí? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà dá àwọn áńgẹ́lì lọ́lá gan-an, wọ́n sì lè ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan, síbẹ̀ wọn ò láǹfààní láti bímọ. Torí náà, ó yẹ kẹ́yin òbí mọyì àǹfààní tẹ́ ẹ ní láti bímọ. Ojúṣe ńlá lẹ̀yin òbí ní láti tọ́ àwọn ọmọ yín dàgbà nínú “ìbáwí àti ìmọ̀ràn Jèhófà.” (Éfé. 6:4; Diu. 6:5-7; Sm. 127:3) Kí àwọn òbí lè ṣe iṣẹ́ yìí láṣeyanjú, ètò Ọlọ́run ti pèsè ìwé lóríṣiríṣi, fídíò, orin àtàwọn ìtẹ̀jáde orí ìkànnì. Kò sí àní-àní pé Baba wa ọ̀run àti Ọmọ rẹ̀ mọyì àwọn ọmọdé gan-an. (Lúùkù 18:15-17) Inú Jèhófà máa ń dùn táwọn òbí bá gbára lé e, tí wọ́n sì ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti bójú tó àwọn ọmọ wọn. Ńṣe ni irú àwọn òbí bẹ́ẹ̀ mú kó ṣeé ṣe fáwọn ọmọ wọn láti di ara ìdílé Jèhófà títí láé.
Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Kọ́ Àwọn Ọmọ Yín Kí Wọ́n Lè Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà
20 Ẹ mọ àwọn ọmọ yín dáadáa. Sáàmù kẹtàdínláàádóje (127) fi àwọn ọmọ wé ọfà. (Ka Sáàmù 127:4.) Bó ṣe jẹ́ pé oríṣiríṣi nǹkan ni wọ́n lè fi ṣe ọfà, tí wọ́n sì máa ń gùn jura wọn lọ, bẹ́ẹ̀ náà làwọn ọmọ yàtọ̀ síra. Fún ìdí yìí, ó yẹ káwọn òbí pinnu bí wọ́n ṣe máa tọ́ ọmọ kọ̀ọ̀kan, kí wọ́n má sì fi ọ̀kan wé èkejì. Bí àpẹẹrẹ, tọkọtaya kan lórílẹ̀-èdè Israel ní ọmọ méjì, àwọn méjèèjì ni wọ́n sì tọ́ yanjú nínú òtítọ́. Kí ló ràn wọ́n lọ́wọ́? Wọ́n ní: “A máa ń bá wọn ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ lọ́tọ̀ọ̀tọ̀.” Òótọ́ ibẹ̀ ni pé olórí ìdílé kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu bóyá wọ́n máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ àwọn ọmọ wọn lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ tàbí wọ́n máa ṣe é pa pọ̀.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
it-1 543
Àwọn Igi Tí Bíbélì Sọ̀rọ̀ Wọn
Nígbà tí onísáàmù ń sọ̀rọ̀ nípa ìlérí tí Jèhófà ṣe fáwọn tó bẹ̀rù ẹ̀, ó fi wọ́n wé bí igi ólífì ṣe máa ń yọ ẹ̀ka, ó ní: “Àwọn ọmọ rẹ yóò dà bí àwọn ẹ̀ka tó ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ lára igi ólífì, wọ́n á yí tábìlì rẹ ká.” (Sm 128:1-3) Wọ́n sábà máa ń gé ẹ̀ka tó ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ lára igi ólífì, wọ́n á gbìn ín, á sì di igi. Nígbà míì sì rèé, àwọn igi ólífì tó ti dàgbà lè yọ ẹ̀ka tuntun níbi gbòǹgbò wọn, àwọn ẹ̀ka yẹn náà á sì di igi. Bíi tàwọn ẹ̀ka tó yọ lára igi ólífì yẹn, àwọn ọmọ máa yí bàbá tó bẹ̀rù Jèhófà ká, wọ́n á sì máa ṣe ipa tiwọn kí ìdílé lè láyọ̀.
JANUARY 13-19
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN SÁÀMÙ 135-137
“Olúwa Wa Ju Gbogbo Ọlọ́run Yòókù Lọ”
it-2 661 ¶4-5
Agbára, Àwọn Iṣẹ́ Agbára
Ọlọ́run ní agbára tó ṣàrà ọ̀tọ̀ lórí àwọn ohun tó dá. Kó lè dá wa lójú pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́, ó bọ́gbọ́n mu nígbà míì tá a bá retí pé kí Jèhófà ṣe nǹkan kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ tó fi hàn pé ó lágbára lórí àwọn ohun tó dá, kó lè dá orúkọ rẹ̀ láre. (Sm 135:5, 6) Oòrùn, òṣùpá, ìràwọ̀ àtàwọn pílánẹ́ẹ̀tì yòókù máa ń tẹ̀ lé ìlànà tí Ọlọ́run ti fi lélẹ̀ fún wọn. Afẹ́fẹ́, òjò àtàwọn ohun àdáyébá míì náà ní ìlànà tí wọ́n ń tẹ̀ lé, bẹ́ẹ̀ sì làwọn eéṣú àtàwọn ẹyẹ máa ń ṣí kiri lásìkò tó yẹ kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ àwọn nǹkan yìí àtàwọn nǹkan míì nìkan ò tó láti sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ́ nígbà táwọn èèyàn bá ta ko Ọlọ́run àti ìjọsìn tòótọ́.
Síbẹ̀, Jèhófà Ọlọ́run lè lo àwọn nǹkan tó dá láti jẹ́ ká mọ̀ pé òun ni Ọlọ́run tòótọ́. Ní àwọn àkókò kan pàtó, Jèhófà lè mú kí àwọn ìṣẹ̀dá rẹ̀ ṣe àwọn nǹkan kan tó yàtọ̀ sí ohun tí wọ́n sábà máa ń ṣe. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe nǹkan bàbàrà tí ọ̀gbẹlẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, tí atẹ́gùn fẹ́ tàbí tí òjò rọ̀, síbẹ̀ tí Jèhófà bá lo àwọn nǹkan yẹn láti mú àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ṣe, ohun àrà ọ̀tọ̀ ló máa ń jẹ́ lásìkò yẹn. (Fi wé 1Ọb 17:1; 18:1, 2, 41-45.) Lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tó máa ń mú káwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn jẹ́ ohun àrà ọ̀tọ̀ ni bí wọ́n ṣe lágbára tó (Ẹk 9:24), bí wọ́n ṣe wáyé lọ́nà tó ṣàjèjì tàbí lásìkò tírú ẹ̀ kì í ṣẹlẹ̀, táwọn èèyàn ò sì gbọ́ irú ẹ̀ rí.—Ẹk 34:10; 1Sa 12:16-18.
Báwo Ni Ìfẹ́ Jèhófà Tí Kì Í Yẹ̀ Ṣe Ń Ṣe Ọ́ Láǹfààní?
16 Tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa dáàbò bò wá, ọkàn wa máa balẹ̀. Àmọ́ láwọn ìgbà míì, ìrẹ̀wẹ̀sì lè mú wa débi tá ò fi ní lókun mọ́. Nírú àwọn àsìkò bẹ́ẹ̀, kí ni Jèhófà máa ń ṣe fún wa? (Ka Sáàmù 136:23.) Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́, ó máa rọra fi apá rẹ̀ gbé wa dìde, kò sì ní jẹ́ ká rẹ̀wẹ̀sì mọ́. (Sm. 28:9; 94:18) Àǹfààní tó ń ṣe wá: Bá a ṣe mọ̀ pé Jèhófà ń tì wá lẹ́yìn máa ń jẹ́ ká rántí pé ọ̀nà méjì ló ń gbà ràn wá lọ́wọ́. Àkọ́kọ́, ibi yòówù ká máa gbé, a mọ̀ pé Jèhófà á máa dáàbò bò wá. Ìkejì, Bàbá wa ọ̀run ń fìfẹ́ bójú tó wa..
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
it-1 1248
Jáà
Àwọn èèyàn sábà máa ń lo ọ̀rọ̀ náà Jáà tó jẹ́ ọ̀rọ̀ onísílébù kan tí wọ́n bá ń yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun, tàbí tí wọ́n rí bí Ọlọ́run ṣe fi ọwọ́ agbára ẹ̀ gbà wọ́n sílẹ̀. Èyí máa ń hàn tí wọ́n bá ń fayọ̀ kọrin ìyìn sí Jèhófà, tí wọ́n ń gbàdúrà tàbí tí wọ́n ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀. Àpẹẹrẹ irú ẹ̀ pọ̀ nínú Bíbélì. Ọ̀rọ̀ náà, “Ẹ yin Jáà!” (ìyẹn Halelúyà) jẹ́ ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ń yin Ọlọ́run nínú Sáàmù, ibi tó sì ti kọ́kọ́ fara hàn ni Sáàmù 104:35. Nínú àwọn sáàmù míì tó ti fara hàn, ìbẹ̀rẹ̀ nìkan ló máa ń wà (Sm 111; 112), nígbà míì ó máa ń wà láàárín (135:3), tàbí kó wà ní ìparí nìkan (Sm 104, 105, 115-117), àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, ó máa ń wà ní ìbẹ̀rẹ̀ àti ìparí (Sm 106, 113, 135, 146-150). Nínú ìwé Ìfihàn, léraléra làwọn áńgẹ́lì lo ọ̀rọ̀ náà, “Ẹ yin Jáà!” bí wọ́n ṣe ń yin Jèhófà.—Ifi 19:1-6.
Láwọn ibòmíì tí ọ̀rọ̀ náà “Jáà” ti fara hàn, ṣe ni wọ́n fi yin Jèhófà láwọn ìgbà tí wọ́n ń kọrin, tí wọ́n sì ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí i. Àpẹẹrẹ kan ni orin ìṣẹ́gun tí Mósè kọ. (Ẹk 15:2) Nígbà tí Àìsáyà ń sọ̀rọ̀ nípa orin yẹn, ṣe ló lo ọ̀rọ̀ méjì pa pọ̀, ìyẹn “Jáà Jèhófà” kó lè tẹnu mọ́ ọn. (Ais 12:2; 26:4) Yàtọ̀ síyẹn, Hẹsikáyà lo ọ̀rọ̀ náà Jáà léraléra nínú ewì kan tó fi yin Jèhófà nígbà tó wò ó sàn lọ́nà ìyanu, tó gbà á lọ́wọ́ ikú. (Ais 38:9, 11) Bíbélì tún jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn òkú ò lè yin Jáà, àmọ́ àwọn alààyè lè pinnu láti fi ìgbésí ayé wọn yìn ín. (Sm 115:17, 18; 118:17-19) Nínú àwọn àdúrà míì tó wà nínú sáàmù, wọ́n lo ọ̀rọ̀ náà Jáà nígbà tí wọ́n ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà bó ṣe gbà wọ́n sílẹ̀, tó dáàbò bò wọ́n, tó sì tọ́ wọn sọ́nà.—Sm 94:12; 118:5, 14.
JANUARY 20-26
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN SÁÀMÙ 138-139
Má Ṣe Jẹ́ Kí Ìbẹ̀rù Dí Ẹ Lọ́wọ́ Láti Dáhùn Nípàdé
Máa Yin Jèhófà Nínú Ìjọ
10 Ṣé àyà ẹ máa ń lù kìkì tó o bá fẹ́ nawọ́ nípàdé? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ ni irú ẹ̀ máa ń ṣẹlẹ̀ sí. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé ọ̀pọ̀ wa lẹ̀rù máa ń bà déwọ̀n àyè kan tá a bá fẹ́ dáhùn. Kó o tó lè borí ìbẹ̀rù yìí, o gbọ́dọ̀ mọ ohun tó ń fà á. Ṣé ẹ̀rù máa ń bà ẹ́ pé wàá gbàgbé ohun tó o fẹ́ sọ àbí pé o ò ní gba ìdáhùn náà? Ṣé ó máa ń ṣe ẹ́ bíi pé ìdáhùn rẹ ò ní dáa tó tàwọn míì? Ká sòótọ́, ẹ̀rù tó ń bà ẹ́ fi hàn pé o lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Ó fi hàn pé o gbà pé àwọn míì sàn jù ẹ́ lọ, Jèhófà sì fẹ́ràn àwọn tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. (Sm. 138:6; Fílí. 2:3) Àmọ́, Jèhófà fẹ́ kó o máa yin òun kó o sì máa gbé àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin rẹ ró nípàdé. (1 Tẹs. 5:11) Ó nífẹ̀ẹ́ rẹ, ó sì máa fún ẹ nígboyà láti máa dáhùn.
Ẹ Máa Gba Ara Yín Níyànjú Nípàdé Ìjọ
7 O lè rí àwọn ohun tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ nínú àwọn Ilé Ìṣọ́ tí ètò Ọlọ́run ti ṣe sẹ́yìn. Bí àpẹẹrẹ, múra ìdáhùn ẹ dáadáa. (Òwe 21:5) Bó o bá ṣe múra ohun tẹ́ ẹ fẹ́ kọ́ dáadáa, bẹ́ẹ̀ lọkàn ẹ máa balẹ̀ láti dáhùn. Bákan náà, jẹ́ kí ìdáhùn ẹ ṣe ṣókí. (Òwe 15:23; 17:27) Tí ìdáhùn ẹ bá ṣe ṣókí, ẹ̀rù ò ní bà ẹ́. Ìdáhùn tó ṣe ṣókí tí ò ju gbólóhùn kan tàbí méjì lọ máa ń tètè yé àwọn ará ju ìdáhùn jàn-ànràn jan-anran. Tó o bá dáhùn ṣókí lọ́rọ̀ ara ẹ, ìyẹn fi hàn pé o múra sílẹ̀ dáadáa àti pé ohun tá à ń kọ́ yé ẹ.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
it-1 862 ¶4
Ìdáríjì
Àwa Kristẹni gbọ́dọ̀ máa dárí ji àwọn tó bá ṣẹ̀ wá, láìka iye ìgbà tí wọ́n ṣẹ̀ wá sí. (Lk 17:3, 4; Ef 4:32; Kol 3:13) Ọlọ́run ò ní dárí ji àwọn tí kì í bá dárí ji àwọn tó ṣẹ̀ wọ́n. (Mt 6:14, 15) Àmọ́, tí wọ́n bá tiẹ̀ mú “ẹni burúkú” tó dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì kúrò nínú ìjọ Kristẹni, tó bá yá tẹ́ni náà bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn, ó máa rí ìdáríjì. Gbogbo àwọn ará ìjọ lè wá fìfẹ́ gbà á pa dà. (1Kọ 5:13; 2Kọ 2:6-11) Àmọ́ a ò retí pé káwa Kristẹni dárí ji àwọn tó bá ń mọ̀ọ́mọ̀ dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì, tí wọn ò sì ronú pìwà dà, torí irú ẹni bẹ́ẹ̀ ti sọ ara ẹ̀ di ọ̀tá Ọlọ́run.—Heb 10:26-31; Sm 139:21, 22.
JANUARY 27–FEBRUARY 2
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN SÁÀMÙ 140-143
Máa Ṣe Àwọn Nǹkan Tó Bá Àdúrà Ẹ Mu
‘Fetí Sí Ọ̀rọ̀ Ọlọgbọ́n’
13 Gbà pé torí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹ ló ṣe ń bá ẹ wí. Ohun tó dáa jù ni Jèhófà fẹ́ fún wa. (Òwe 4:20-22) Ó máa ń bá wa wí nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, àwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì tàbí àwọn ará tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn, ìyẹn ló sì ń fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wa. Hébérù 12:9, 10 sọ pé: ‘Torí ire wa ló ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀.’
14 Ohun tí wọ́n bá ẹ sọ ni kó o wò, má wo bí wọ́n ṣe sọ ọ́. Nígbà míì, tí wọ́n bá gbà wá nímọ̀ràn, ó lè máa ṣe wá bíi pé ọ̀nà tó yẹ kí wọ́n gbà sọ ọ́ kọ́ nìyẹn. Ká sòótọ́, ó yẹ kẹ́ni tó fẹ́ gba èèyàn nímọ̀ràn sapá láti sọ ọ́ lọ́nà tó máa rọrùn fún ẹni náà láti gbà á. (Gál. 6:1) Tó bá jẹ́ àwa ni wọ́n gbà nímọ̀ràn, ohun tí wọ́n sọ fún wa ló yẹ ká wò, kódà tó bá ń ṣe wá bíi pé ọ̀nà tí wọ́n gbà sọ ọ́ yẹn ò dáa tó. Torí náà, ó yẹ ká bi ara wa pé: ‘Tí inú mi ò bá tiẹ̀ dùn sí ohun tẹ́ni náà sọ fún mi, ṣé òótọ́ ọ̀rọ̀ wà níbẹ̀? Ṣé mo lè gbójú fo àìpé ẹni tó fún mi nímọ̀ràn kí n lè jàǹfààní látinú ohun tó sọ?’ A máa fi hàn pé a gbọ́n tá a bá ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí wọ́n fún wa.—Òwe 15:31.
Ní ‘Ọkàn-àyà Tó Mọ́’ Ní Àwọn Àkókò Líle Koko Yìí
Ìdààmú látọ̀dọ̀ àwọn tó ń ṣàtakò, ìṣòro ìgbọ́bùkátà àti àìsàn líle koko lè kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn kan lára àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run. Nígbà míì, ó lè ṣàkóbá fún ọkàn-àyà wọn. Kódà Dáfídì Ọba ní irú ìṣòro yìí, ó sọ pé: “Àárẹ̀ sì mú ẹ̀mí mi nínú mi; ọkàn-àyà mi ti kú tipiri nínú mi.” (Sm. 143:4) Kí ló ràn án lọ́wọ́ láti bọ́ nínú ìṣòro yìí? Dáfídì rántí bí Ọlọ́run ṣe ń bójú tó àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀ àti bí òun alára ṣe rí ìdáǹdè gbà. Ó ṣàṣàrò lórí ohun tí Jèhófà ti ṣe nítorí orúkọ ńlá Rẹ̀. Dáfídì jẹ́ kí àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run jẹ òun lógún. (Sm. 143:5) Lọ́nà kan náà, tá a bá ń ṣàṣàrò nípa Ẹlẹ́dàá àti gbogbo ohun tó ti ṣe àtèyí tó ń ṣe fún wa, ìyẹn á ràn wá lọ́wọ́ kódà nígbà tá a bá wà lábẹ́ àdánwò.
Gbéyàwó “Kìkì Nínú Olúwa”—Ǹjẹ́ Ó Ṣì Bọ́gbọ́n Mu?
Nígbà míì, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi ti onísáàmù náà Dáfídì, tó sọ pé: “Ṣe wéré, dá mi lóhùn, Jèhófà. Ẹ̀mí mi ti wá sí òpin. Má fi ojú rẹ pa mọ́ fún mi.” (Sm. 143: 5-7, 10) Ní àwọn ìgbà tí o bá ti ní irú èrò yìí, ńṣe ni kó o ní sùúrù, kí Baba rẹ ọ̀run lè jẹ́ kó o mọ ohun tó fẹ́ kó o ṣe. O lè mọ ohun tó fẹ́ kó o ṣe tó o bá ń ka Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó o sì ń ṣàṣàrò lórí ohun tí ò ń kà. Wàá mọ àwọn òfin Jèhófà, wàá sì rí bó ṣe ń ran àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ látẹ̀yìnwá. Tó o bá ń fetí sí Jèhófà, ọkàn rẹ á túbọ̀ balẹ̀ pé ó bọ́gbọ́n mu kéèyàn máa ṣègbọràn sí Jèhófà.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
it-2 1151
Oró
Àpèjúwe. Bíbélì sọ pé irọ́ táwọn ẹni burúkú máa ń pa mọ́ àwọn èèyàn àtàwọn ọ̀rọ̀ èké tí wọ́n fi máa ń bani lórúkọ jẹ́ dà bí oró ejò tó lè pani. (Sm 58:3, 4) Bíbélì sọ nípa àwọn abanijẹ́ pé, “Oró paramọ́lẹ̀ wà lábẹ́ ètè wọn”, bó ṣe jẹ́ pé oró ejò paramọ́lẹ̀ máa ń wà ní abẹ́ ètè àti ahọ́n rẹ̀, níbi òkè ẹnu rẹ̀. (Sm 140:3; Ro 3:13) Téèyàn bá ń lo ahọ́n ẹ̀ lọ́nà tí ò yẹ, bíi kó fi máa bani jẹ́, kó máa sọ̀rọ̀ àwọn èèyàn láìdáa tàbí kó máa kọni lẹ́kọ̀ọ́ èké, ṣe ni irú ahọ́n bẹ́ẹ̀ “kún fún májèlé tó ń pani.”—Jem 3:8.
FEBRUARY 3-9
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN SÁÀMÙ 144-146
“Aláyọ̀ Ni Àwọn Tí Jèhófà Jẹ́ Ọlọ́run Wọn!”
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
2. Àtúnṣe tá a ṣe sí ẹsẹ yìí bá àwọn ẹsẹ yòókù tó wà nínú Sáàmù yẹn mu. Ọ̀rọ̀ náà “nígbà náà” tá a lò nínú ẹsẹ kejìlá túmọ̀ sí pé àwọn olódodo ló máa gbádùn àwọn ìbùkún tó wà nínú ẹsẹ kejìlá sí kẹrìnlá. Ìyẹn àwọn tó ní kí Ọlọ́run ‘dá àwọn sílẹ̀ lómìnira, kí ó sì dá wọn nídè’ lọ́wọ́ àwọn ẹni ibi bó ṣe wà ní ẹsẹ kọkànlá. Bákan náà lọ̀rọ̀ rí tá a bá wo ẹsẹ kẹẹ̀ẹ́dógún níbi tí ọ̀rọ̀ náà “aláyọ̀” ti fara hàn lẹ́ẹ̀mejì, “àwọn ènìyàn tí Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run wọn” náà ló ń tọ́ka sí. Ẹ má sì gbàgbé pé èdè Hébérù ìpilẹ̀ṣẹ̀ ò ní àmì ìpín gbólóhùn bí àmì àyọlọ̀ (“ ” tàbí ‘ ‘). Torí náà, àwọn atúmọ̀ èdè máa ní láti wo àyíká ọ̀rọ̀ kí wọ́n tó lè mọ ohun tí àwọn ẹsẹ kan ń sọ gan-an.
3. Àtúnṣe tá a ṣe sí ọ̀rọ̀ yẹn mú kí àwọn ẹsẹ yẹn bá àwọn apá míì nínú Bíbélì mu, níbi tí Ọlọ́run ti ṣèlérí pé òun máa bù kún àwọn tó bá jẹ́ olóòótọ́. Àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú sáàmù yẹn jẹ́ ká rí ìrètí tí Dáfídì ní pé, lẹ́yìn tí Ọlọ́run bá dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn, wọ́n máa láyọ̀, wọ́n á sì rí ọ̀pọ̀ ìbùkún gbà. (Léf. 26:9, 10; Diu. 7:13; Sm. 128:1-6) Bí àpẹẹrẹ, Diutarónómì 28:4 sọ pé: “Ìbùkún ni fún èso ikùn rẹ àti èso ilẹ̀ rẹ àti èso ẹranko agbéléjẹ̀ rẹ, ọmọ ẹran ọ̀sìn rẹ àti àtọmọdọ́mọ agbo ẹran rẹ.” Abájọ tó fi jẹ́ pé nígbà ìṣàkóso Sólómọ́nì ọmọ Dáfídì, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà ní àlàáfíà, wọ́n sì rí ọ̀pọ̀ ìbùkún. Bákan náà, àlàáfíà táwọn èèyàn Ọlọ́run gbádùn nígbà ìṣàkóso Sólómọ́nì tún ń ṣàpẹẹrẹ bí àlàáfíà ṣe máa gbilẹ̀ nígbà ìṣàkóso Mèsáyà.—1 Ọba 4:20, 21; Sm. 72:1-20.
Jẹ́ Kí Ìrètí Tó O Ní Dá Ẹ Lójú
16 Ẹ̀bùn pàtàkì ni ìyè àìnípẹ̀kun tá à ń retí látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Gbogbo wa là ń retí ọjọ́ iwájú aláyọ̀ yẹn, ó sì dájú pé a máa rí i. Ìrètí yẹn dà bí ìdákọ̀ró, ó ń mú ká jẹ́ olóòótọ́ nígbà ìṣòro, ó tún ń jẹ́ ká lè fara da inúnibíni, kì í sì í jẹ́ ká bẹ̀rù ikú. Ó dà bí akoto tó máa ń dáàbò bo èrò wa ká má bàa ṣe ohun tí kò tọ́, ká sì máa ṣe ohun rere. Àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ṣèlérí nínú Bíbélì ti jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ ọn, ó sì ń jẹ́ ká mọ bó ṣe nífẹ̀ẹ́ wa tó. Torí náà, tá a bá jẹ́ kí ìrètí tá a ní túbọ̀ dá wa lójú, a máa jàǹfààní gan-an.
17 Nínú lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Róòmù, ó ní: “Ẹ jẹ́ kí ìrètí tí ẹ ní máa fún yín láyọ̀.” (Róòmù 12:12) Pọ́ọ̀lù ń láyọ̀ torí ó dá a lójú pé tóun bá jẹ́ olóòótọ́, òun máa ní ìyè àìnípẹ̀kun lọ́run. Ó yẹ káwa náà jẹ́ kí ìrètí tá a ní máa fún wa láyọ̀ torí ó dá wa lójú pé Jèhófà máa mú àwọn ìlérí ẹ̀ ṣẹ. Onísáàmù kan sọ pé: “Aláyọ̀ ni ẹni . . . tó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀, . . . Ẹni tó jẹ́ olóòótọ́ nígbà gbogbo.”—Sm. 146:5, 6.
Ìfẹ́ Wo Ló Ń Mú Kéèyàn Ní Ojúlówó Ayọ̀?
19 Ó ti lé ní ẹgbẹ̀rún ọdún mẹ́fà [6,000] tí ayé Èṣù yìí ti ń fojú pọ́n aráyé, àmọ́ ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dópin báyìí. Àwọn èèyàn tó nífẹ̀ẹ́ ara wọn nìkan, olùfẹ́ owó àtàwọn olùfẹ́ adùn ló kúnnú ayé yìí. Bọ́wọ́ wọn ṣe máa tẹ ohun tí wọ́n fẹ́ ló gbawájú nígbèésí ayé wọn, wọn kì í ro tàwọn míì mọ́ tiwọn. Irú àwọn bẹ́ẹ̀ kò lè ní ojúlówó ayọ̀. Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, Onísáàmù kan sọ béèyàn ṣe lè ní ojúlówó ayọ̀, ó ní: “Aláyọ̀ ni ẹni tí ó ní Ọlọ́run Jékọ́bù fún ìrànlọ́wọ́ rẹ̀, ẹni tí ìrètí rẹ̀ ń bẹ nínú Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀.”—Sm. 146:5.
20 Ṣe ni ìfẹ́ Ọlọ́run túbọ̀ ń jinlẹ̀ lọ́kàn àwa èèyàn Jèhófà, bẹ́ẹ̀ sì ni iye wa túbọ̀ ń pọ̀ sí i lọ́dọọdún. Ẹ̀rí nìyẹn jẹ́ pé Ìjọba Ọlọ́run ti ń ṣàkóso àti pé ó máa tó rọ̀jò ìbùkún sórí ilẹ̀ ayé. Àá ní ojúlówó ayọ̀ tá a bá ń ṣe ohun tí Baba wa ọ̀run fẹ́, àá sì múnú rẹ̀ dùn. Yàtọ̀ síyẹn, títí ayé làwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà á máa láyọ̀! Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, àá jíròrò ìwà táwọn onímọtara-ẹni-nìkan máa ń hù àti bíyẹn ṣe yàtọ̀ sáwọn ànímọ́ rere táwa èèyàn Jèhófà ní.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
it-1 111 ¶9
Àwọn Ẹranko
Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ó yẹ ká máa fàánú hàn sáwọn ẹranko, ká má sì hùwà ìkà sí wọn. Kódà Jèhófà sọ pé òun ń pèsè fáwọn ẹranko, òun sì ń dáàbò bò wọ́n. (Owe 12:10; Sm 145:15, 16) Nínú òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó sọ bó ṣe yẹ kí wọ́n máa bójú tó àwọn ẹran ọ̀sìn. Tí ẹran ọ̀sìn kan bá ṣìnà, wọ́n gbọ́dọ̀ dá a pa dà fún ẹni tó ni ín. Tí ẹran ọ̀sìn kan bá ṣubú, tí kò lè dìde torí ẹrù tó gbé, wọ́n gbọ́dọ̀ bá a gbé ẹrù náà kúrò. (Ẹk 23:4, 5) Yàtọ̀ síyẹn, wọn ò gbọ́dọ̀ fi ẹran ọ̀sìn ṣe iṣẹ́ tó ju agbára ẹ̀ lọ. (Di 22:10; 25:4) Kódà, àti èèyàn àti ẹran ọ̀sìn ló gbọ́dọ̀ sinmi lọ́jọ́ Sábáàtì. (Ẹk 20:10; 23:12; Di 5:14) Tó bá sì ti di pé ẹran ọ̀sìn kan ń ṣe àwọn èèyàn léṣe, wọ́n gbọ́dọ̀ so ó mọ́lẹ̀ tàbí kí wọ́n pa á. (Jẹ 9:5; Ẹk 21:28, 29) Bákan náà, Òfin Ọlọ́run sọ pé wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí oríṣi ẹran ọ̀sìn méjì bá ara wọn lò pọ̀.—Le 19:19.
FEBRUARY 10-16
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN SÁÀMÙ 147-150
Máa Yin Jèhófà Torí Ọ̀pọ̀ Nǹkan Tó Ń Ṣe
Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Yin Jèhófà?
5 Bí Jèhófà ṣe ń tu àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nínú lápapọ̀, bẹ́ẹ̀ náà ló ń tù wọ́n nínú lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Ohun kan náà ló ń ṣe lónìí. Bí àpẹẹrẹ, onísáàmù náà sọ nípa Ọlọ́run pé: “Ó ń mú àwọn oníròbìnújẹ́-ọkàn lára dá, ó sì ń di àwọn ojú ibi tí ń ro wọ́n.” (Sm. 147:3) Ó ṣe kedere pé Jèhófà máa ń ran àwọn tó níṣòro lọ́wọ́, yálà ẹ̀dùn ọkàn ni wọ́n ní tàbí ìṣòro míì. Lónìí, ó máa ń wu Jèhófà láti tù wá nínú, pàápàá nígbà tá a bá ní ẹ̀dùn ọkàn. (Sm. 34:18; Aísá. 57:15) Ó sì máa ń fún wa ní ọgbọ́n àti okun tá a nílò ká lè fara da àwọn ìṣòro wa.—Ják. 1:5.
6 Ẹ̀yìn ìyẹn ni onísáàmù náà wá sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìràwọ̀ tí Jèhófà dá sójú ọ̀run, ó sì sọ pé Jèhófà “ka iye àwọn ìràwọ̀” àti pé “gbogbo wọn ni ó ń fi orúkọ wọn pè.” (Sm. 147:4) Kí nìdí tí onísáàmù náà fi yí àfíyèsí wa sójú ọ̀run? Jẹ́ ká wò ó báyìí ná: Onísáàmù náà máa ń rí àwọn ìràwọ̀ tó pọ̀ lọ súà, àmọ́ kò mọ iye wọn. Lásìkò tiwa yìí, ó ti ṣeé ṣe fún wa láti rí àwọn ìràwọ̀ tó pọ̀ ju èyí tí onísáàmù náà rí lọ. Àwọn kan sọ pé ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù ìràwọ̀ ló wà nínú ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ Milky Way nìkan. Tá a bá sì ní ká máa ka iye ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ tó wà, wọn ò lóǹkà! Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, kò sẹ́ni tó mọ iye ìràwọ̀ tó wà lójú ọ̀run! Àmọ́, ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ pé Ọlọ́run fún gbogbo wọn pátá ní orúkọ. Èyí túmọ̀ sí pé Jèhófà mọ àwọn ìràwọ̀ náà lọ́kọ̀ọ̀kan. (1 Kọ́r. 15:41) Tí Jèhófà bá mọ ìràwọ̀ kọ̀ọ̀kan, àwa èèyàn tó dá sáyé ńkọ́? Ó ṣe kedere pé Ọlọ́run mọ ibi tí ìràwọ̀ kọ̀ọ̀kan wà. Torí náà, ó mọ àwa náà lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, ó mọ ibi tí kálukú wa wà, ó mọ bí nǹkan ṣe ń rí lára wa gan-an, ó sì mọ ohun tẹ́nì kọ̀ọ̀kan wa nílò nígbàkigbà!
Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Yin Jèhófà?
7 Yàtọ̀ sí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, ó tún mọ bí ọ̀rọ̀ ṣe máa ń rí lára wa, ó sì lágbára láti ràn wá lọ́wọ́ tá a bá wà nínú ìṣòro. (Ka Sáàmù 147:5.) Ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé ìṣòro rẹ ti wọ̀ ẹ́ lọ́rùn, tàbí pé àwọn ìṣòro náà kọjá agbára rẹ. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Ọlọ́run mọ ibi tágbára rẹ mọ, ‘ó rántí pé ekuru ni ẹ́.’ (Sm. 103:14) Torí pé a jẹ́ aláìpé, a lè máa ṣe àṣìṣe kan náà léraléra. Ẹ wo bó ṣe máa ń dùn wá tó tá a bá ṣi ọ̀rọ̀ sọ tàbí tá a gbaná jẹ lórí ohun tí kò tó nǹkan, ó sì lè jẹ́ pé ṣe la máa ń jowú àwọn míì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà kì í ṣàṣìṣe, síbẹ̀ ó mọ bó ṣe máa ń rí lára wa tá a bá ṣàṣìṣe, òye tó ní kò ṣeé díwọ̀n, kódà kò sí àwárí òye rẹ̀!—Aísá. 40:28.
Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Yin Jèhófà?
18 Onísáàmù náà mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn rẹ̀ ìgbàanì gan-an. Àwọn nìkan ni Ọlọ́run fún ní “ọ̀rọ̀” rẹ̀ àtàwọn “ìlànà rẹ̀ àti àwọn ìpinnu ìdájọ́ rẹ̀.” (Ka Sáàmù 147:19, 20.) Lóde òní, Jèhófà dá wa lọ́lá ní ti pé àwa nìkan là ń jẹ́ orúkọ mọ́ ọn. Torí pé a mọ Jèhófà, a sì ń jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tọ́ wa sọ́nà, a ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀. Bíi ti ẹni tó kọ Sáàmù 147, ǹjẹ́ àwa náà ní ìdí tó pọ̀ láti máa “yin Jáà,” ká sì máa rọ àwọn míì pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀?
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
Ìṣẹ̀dá Ń polongo Ògo Ọlọ́run!
Sáàmù 148:10 sọ pé: “Ẹ̀yin ẹranko ìgbẹ́ àti gbogbo ẹ̀yin ẹran agbéléjẹ̀, ẹ̀yin ohun tí ń rákò àti ẹ̀yin ẹyẹ abìyẹ́lápá.” Ọ̀pọ̀ àwọn ẹranko orí ilẹ̀ àtàwọn ẹyẹ ojú ọ̀run ló ń pitú lọ́nà tó yani lẹ́nu. Ẹyẹ Laysan albatross lè fo ọ̀nà jíjìn gan-an (ìgbà kan wà tí ẹyẹ yìí fo ọ̀kẹ́ méjì kìlómítà láàárín àádọ́rùn-ún ọjọ́ péré). Ẹyẹ ìbákà olórí dúdú fò láti ìhà Àríwá Amẹ́ríkà dé ìhà Gúúsù Amẹ́ríkà, tó ń fi ọgọ́rin wákàtí fò láìdúró rárá. Ràkúnmí máa ń tọ́jú omi pa mọ́, kì í ṣe sínú iké ẹ̀yìn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ èèyàn ti rò, àmọ́ ó máa ń tọ́jú omi pa mọ́ sí ibi tí oúnjẹ rẹ̀ ti ń dà, èyí sì máa ń jẹ́ kó máa rìn lọ fún àkókò gígùn gan-an tí òùngbẹ kò sì ní í gbẹ ẹ́. Abájọ táwọn onímọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ máa ń fara balẹ̀ wo àwọn ẹranko dáadáa nígbà tí wọ́n bá fẹ́ ṣe ẹ̀rọ àti nǹkan tuntun mìíràn jáde. Òǹkọ̀wé Gail Cleere sọ pé: “Tó o bá fẹ́ ṣe ohun kan tó o fẹ́ kó ṣiṣẹ́ dáadáa . . . kó má sì ṣe ìpalára fún àyíká rẹ̀, ó ṣeé ṣe kó o rí àpẹẹrẹ rere kan tó o lè tẹ̀ lé nínú àwọn ohun tí Ọlọ́run dá.”
FEBRUARY 17-23
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN ÒWE 1
Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Ta Lẹ Máa Fetí Sí?
Má Ṣe Jẹ́ Kí Ohunkóhun Mú Kó O Pàdánù Èrè Ọjọ́ Iwájú
16 Tó o bá jẹ́ ọ̀dọ́, tó sì ń ṣe ẹ́ bíi pé àwọn òbí rẹ kò mọ bí nǹkan ṣe rí lára rẹ tàbí pé wọ́n ti le koko jù, kí ni wàá ṣe? Inú lè bẹ̀rẹ̀ sí í bí ẹ, kó o sì máa ṣiyèméjì bóyá kó o sin Jèhófà tàbí kó o má sìn ín. Àmọ́ tó o bá bínú fi Jèhófà sílẹ̀, bópẹ́bóyá wàá rí i pé kò sẹ́ni tó nífẹ̀ẹ́ rẹ tó àwọn òbí rẹ àtàwọn tẹ́ ẹ jọ ń sin Jèhófà.
17 Tó bá jẹ́ pé àwọn òbí rẹ kì í bá ẹ wí rárá, ǹjẹ́ o ò ní bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyèméjì bóyá wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ? (Héb. 12:8) Ó lè jẹ́ pé ọ̀nà tí àwọn òbí rẹ ń gbà bá ẹ wí ló máa ń bí ẹ nínú. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, dípò kó o máa bínú torí ọ̀nà tí wọ́n gbà bá ẹ wí, á dáa kó o ronú nípa ìdí tí wọ́n fi bá ẹ wí. Torí náà, ṣe sùúrù, má ṣe máa fapá jánú tí wọ́n bá ń bá ẹ wí. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó bá fawọ́ àwọn àsọjáde rẹ̀ sẹ́yìn kún fún ìmọ̀, ènìyàn tí ó ní ìfòyemọ̀ sì tutù ní ẹ̀mí.” (Òwe 17:27) Torí náà, sapá kó o lè máa hùwà àgbà, tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá mọ bó o ṣe lè fi sùúrù gba ìbáwí àti bó o ṣe lè jàǹfààní nínú ìbáwí náà láìbínú sí ọ̀nà tí wọ́n gbà bá ẹ wí. (Òwe 1:8) Ìbùkún ńlá ni téèyàn bá láwọn òbí tó ń fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà, ó sì dájú pé wọ́n á ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti gba èrè tá à ń fojú sọ́nà fún.
Má Ṣe Sọ Ìwà Kristẹni Nù
11 Ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ní kó o máa ṣe kì í ṣe ohun táwọn èèyàn fẹ́. Kò sẹ́ni tó fẹ́ kí wọ́n fojú pa òun rẹ́. Gbogbo wa la fẹ́ ká ní ọ̀rẹ́, inú wa sì máa ń dùn táwọn èèyàn bá kà wá sí. Ìfẹ́ láti ṣe ohun táwọn ẹgbẹ́ ẹni ń ṣe máa ń lágbára gan-an nígbà téèyàn bá wà lọ́dọ̀ọ́, àti nígbà téèyàn bá dàgbà pàápàá. Èyí ló máa ń mú kéèyàn fẹ́ máa fara wé àwọn ẹlòmíì tàbí kó fẹ́ ṣe ohun tí wọ́n fẹ́. Àmọ́ kì í ṣe ìgbà gbogbo ni ire wa máa ń jẹ àwọn ọ̀rẹ́ tàbí ojúgbà wa lógún. Ìgbà mìíràn wà tó jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n kàn ń fẹ́ ẹni tó máa dara pọ̀ mọ́ wọn láti hùwà burúkú. (Òwe 1:11-19) Nígbà táwọn ojúgbà Kristẹni kan bá sún un ṣe ohun kan tí kò bójú mu, Kristẹni bẹ́ẹ̀ á fẹ́ máa fojú pa mọ́ káwọn èèyàn má bàa mọ irú ẹni tóun jẹ́. (Sáàmù 26:4) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ pé “Má ṣe mú ara rẹ bá àṣà ayé tí ó yí ọ ká mu.” (Róòmù 12:2, The Jerusalem Bible) Jèhófà ń fún wa lágbára tá a fi lè dènà ohunkóhun tó lè mú ká hùwà bíi táwọn èèyàn ayé.—Hébérù 13:6.
12 Nígbà táwọn èèyàn bá fẹ́ mú wa ṣe ohun tó lòdì sí òfin Ọlọ́run, ó yẹ ká rántí pé jíjẹ́ onígbọràn sí Jèhófà ṣe pàtàkì ju èrò táwọn èèyàn ní lọ. Ìlànà kan tá a lè máa tẹ̀ lé ni èyí tó wà nínú Ẹ́kísódù 23:2 tó sọ pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé ogunlọ́gọ̀ fún ète ibi.” Nígbà tí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń ṣiyèméjì pé bóyá ni Jèhófà máa mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ, Kálébù ò fara mọ́ àwọn èèyàn náà rárá àti rárá. Ó dá a lójú pé Ọlọ́run máa mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ, Ọlọ́run sì bù kún un lọ́pọ̀lọpọ̀ nítorí èyí. (Númérì 13:30; Jóṣúà 14:6-11) Ǹjẹ́ ìwọ náà fẹ́ láti dènà ẹ̀mí ṣe-ohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe kí àjọṣe rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run má bàa bà jẹ́?
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
it-1 846
Òmùgọ̀
Lọ́pọ̀ ìgbà, tí Bíbélì bá lo ọ̀rọ̀ náà “òmùgọ̀,” kì í ṣe ẹni tí kò gbọ́n ló ń tọ́ka sí, kàkà bẹ́ẹ̀ ó sábà máa ń tọ́ka sí ẹni tí kì í gba ìmọ̀ràn, tó sì máa ń hùwà tí kò bá ìlànà òdodo Ọlọ́run mu. Lára àwọn ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n lò fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni kesilʹ (‘aláìmọ̀kan; Owe 1:22), ʼewilʹ (“òmùgọ”; Owe 12:15), na·valʹ (‘òmùgọ; Owe 17:7), àti lets (“ẹlẹ́gàn”; Owe 13:1). Nínú èdè Gíríìkì, wọ́n lo àwọn ọ̀rọ̀ bí aʹphron tó túmọ̀ sí “aláìlóye” (Lk 12:20), a·noʹe·tos tó túmọ̀ sí “aláìnírònú” (Ga 3:1), àti mo·rosʹ tó túmọ̀ sí “òmùgọ̀.” (Mt 23:17; 25:2).
FEBRUARY 24–MARCH 2
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì ÒWE 2
Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Fọwọ́ Pàtàkì Mú Ìdákẹ́kọ̀ọ́?
‘Ẹ Máa Rìn Nínú Òtítọ́’
16 Gbogbo wa kọ́ ló máa ń wù pé ká kàwé tàbí ká dá kẹ́kọ̀ọ́. Àmọ́ Jèhófà rọ̀ wá pé ká máa “wá” òtítọ́ kiri ká lè mọ òtítọ́. (Ka Òwe 2:4-6.) Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a máa jàǹfààní gan-an. Arákùnrin Corey sọ pé tóun bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ẹsẹ Bíbélì kan lòun máa ń gbájú mọ́. Ó ṣàlàyé pé: “Mo máa ń ka àlàyé ìsàlẹ̀ ẹsẹ Bíbélì náà, màá wo àwọn ẹsẹ Bíbélì míì tá a tọ́ka sí, màá sì ṣèwádìí ẹ̀. . . . Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ ni mo máa ń rí kọ́ torí pé mò ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́nà yìí!” Tá a bá ń lo okun àti àkókò wa láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ lọ́nà yìí tàbí láwọn ọ̀nà míì, á fi hàn pé a mọyì òtítọ́ gan-an.—Sm. 1:1-3.
Jèhófà Fẹ́ Kó O Ní Ọgbọ́n Tòótọ́
3 Ẹni tó bá gbọ́n máa ń lo ìmọ̀ tó ní láti ṣe ìpinnu tó dáa. Àmọ́ ká tó lè ní ọgbọ́n tòótọ́, àwọn nǹkan míì wà tá a gbọ́dọ̀ ṣe. Bíbélì sọ pé: “Ìbẹ̀rù Jèhófà ni ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ́n, ìmọ̀ Ẹni Mímọ́ Jù Lọ sì ni òye.” (Òwe 9:10) Torí náà, tá a bá fẹ́ ṣe ìpinnu pàtàkì, ó yẹ ká lo ìmọ̀ Jèhófà, ìyẹn “ìmọ̀ Ẹni Mímọ́ Jù Lọ” láti ṣe ìpinnu náà. A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń ka Bíbélì tá a sì ń ṣèwádìí nínú àwọn ìwé ètò Ọlọ́run. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, á fi hàn pé a ní ọgbọ́n tòótọ́.—Òwe 2:5-7.
4 Jèhófà nìkan ló lè fún wa ní ọgbọ́n tòótọ́. (Róòmù 16:27) Kí nìdí tó fi jẹ́ pé òun ni Orísun ọgbọ́n? Ìdí àkọ́kọ́ ni pé òun ni Ẹlẹ́dàá wa, ó sì ní ìmọ̀ àti òye nípa gbogbo nǹkan tó dá. (Sm. 104:24) Ìkejì, gbogbo nǹkan tí Jèhófà ń ṣe ló fi hàn pé ọlọ́gbọ́n ni. (Róòmù 11:33) Ìkẹta, gbogbo àwọn tó bá ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tí Jèhófà ń fún wa máa ń jàǹfààní. (Òwe 2:10-12) Torí náà, tá a bá fẹ́ ní ọgbọ́n tòótọ́, a gbọ́dọ̀ gbà pé òótọ́ làwọn nǹkan mẹ́ta tá a sọ yẹn, ká sì jẹ́ kí wọ́n máa darí wa tá a bá fẹ́ ṣèpinnu.
Ẹ̀yin Ọ̀dọ́, Ẹ Mú Kí Ìgbàgbọ́ Yín Túbọ̀ Lágbára
2 Ṣé bọ́rọ̀ ṣe rí pẹ̀lú ẹ̀yin ọmọ wa àtẹ̀yin ọ̀dọ́ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà nìyẹn? Ṣé àwọn ọmọ iléèwé rẹ náà máa ń fẹ́ kó o tẹ̀ síbi táyé tẹ̀ sí, kó o gbà pé ẹfolúṣọ̀n ló mú káwọn nǹkan wà dípò Ẹlẹ́dàá? Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, àwọn nǹkan kan wà tó o lè ṣe táá mú kí ìgbàgbọ́ rẹ nínú Ẹlẹ́dàá túbọ̀ lágbára. Ohun àkọ́kọ́ ni pé kó o lo làákàyè rẹ torí pé ó “máa fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ.” Kò ní jẹ́ kí wọ́n fi ẹ̀kọ́ ayé yìí ba ìgbàgbọ́ rẹ jẹ́.—Ka Òwe 2:10-12.
3 Kó o tó lè nígbàgbọ́ tó fẹsẹ̀ múlẹ̀, o gbọ́dọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run. (1 Tím. 2:4) Torí náà, tó o bá ń ka Bíbélì tàbí àwọn ìwé wa, má kàn máa wò wọ́n gààràgà, ṣe ni kó o fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ wọn. Máa ronú lé ohun tó ò ń kà, kó o lè lóye rẹ̀. (Mát. 13:23) Tó o bá ń fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́, wàá túbọ̀ rí àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé Ọlọ́run ló dá gbogbo nǹkan àti pé Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni Bíbélì. Ní báyìí, a máa jíròrò bó o ṣe lè máa fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà bẹ́ẹ̀.—Héb. 11:1.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
Dúró Sọ́dọ̀ Jèhófà
Kí lo lè ṣe láti di ọ̀rẹ́ Jèhófà? Ẹ̀kọ́ tó o kọ́ nínú Bíbélì ti jẹ kó o túbọ̀ mọ Jèhófà dáadáa, ó sì ti jẹ́ kó o di ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ńṣe ló dà bí iná téèyàn dá, tó fẹ́ kó máa jó lala. Bí iná tó ń jó ṣe nílò igi kó lè máa jó nìṣó, bẹ́ẹ̀ ló ṣe yẹ kó o máa kẹ́kọ̀ọ́ sí i kí ọ̀rẹ́ ìwọ àti Jèhófà lè máa lágbára sí i.—Òwe 2:1-5.