Bí Ìgbéyàwó Ṣe Lè Kẹ́sẹ Járí
ŃṢE ni ìgbéyàwó dà bí ìrìn-àjò, ìyẹn ìrìn-àjò gígùn tó kún fún òkè àti gegele. Òkè míì lè kani láyà bí ìgbà tí ìṣòro kíkàmàmà bá ṣàdédé dé báni. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń gúnlẹ̀ ayọ̀ nínú irú ìrìn-àjò yìí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn gbágungbàgun díẹ̀ lè wà lọ́nà. Ibi tọ́rọ̀ náà wà ni pé kì í ṣe bí ìṣòro ṣe pọ̀ tó nínú ìgbéyàwó ló jà, bí kò ṣe ọwọ́ tí tọkọtaya bá fi mú àwọn ìṣòro náà.
Kí lo rò pó lè mú kéèyàn gúnlẹ̀ ayọ̀ nínú ìrìn-àjò tá a fi ìgbéyàwó wé yìí, kí ayọ̀ onítọ̀hún má sì pẹ̀dín? Ó máa ń ṣe ọ̀pọ̀ tọkọtaya bíi kí wọ́n rí “àwòrán ojú ọ̀nà” tá máa fi wọ́n mọ̀nà. Ọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run tó dá ìgbéyàwó sílẹ̀ ni ọlá àṣẹ tó ga jù lọ, tí kì í bà á tì, tá a lè fi wé irú “àwòrán ojú ọ̀nà” bẹ́ẹ̀ ti wá. Kì í ṣì í ṣe ohun méjì yàtọ̀ sí Bíbélì Mímọ́, ìyẹn ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó mí sí. Àmọ́ wíwulẹ̀ ní Bíbélì lọ́wọ́ ò tán ìṣòro ìgbéyàwó o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó láwọn ìlànà tó gbéṣẹ́, èyí táwọn tọkọtaya gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé kí ìgbéyàwó wọn bàa lè kẹ́sẹ járí.—Sáàmù 119:105; Éfésù 5:21-33; 2 Tímótì 3:16.
Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára àwọn ìtọ́sọ́nà Ìwé Mímọ́, ìyẹn àwọn ìlànà pàtàkì látinú Bíbélì, èyí tó lè máa ṣamọ̀nà wa síbi tó yẹ nínú ìrìn-àjò tá a fi ìgbéyàwó wé yìí, ká bàa lè gúnlẹ̀ láyọ̀.
▸ Máa wo ìgbéyàwó bí ohun mímọ́. “Ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀.” (Mátíù 19:6) Ẹlẹ́dàá ló dá ètò ìgbéyàwó sílẹ̀ nígbà tó fa Éfà lé ọkùnrin àkọ́kọ́, ìyẹn Ádámù lọ́wọ́. (Jẹ́nẹ́sísì 2:21-24) Kristi Jésù, tí ìgbéyàwó náà ṣojú ẹ̀, kó tó wá sórí ilẹ̀ ayé, jẹ́rìí sí i pé ńṣe ni Ọlọ́run so Ádámù àti Éfà pọ̀ ṣọ̀kan, kí wọ́n lè máa gbé pọ̀ títí ayé. Ó sọ pé: “Ẹ kò ha kà pé ẹni tí ó dá wọn láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ṣe wọ́n ní akọ àti abo, ó sì wí pé, ‘Nítorí ìdí yìí ọkùnrin yóò fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóò sì fà mọ́ aya rẹ̀, àwọn méjèèjì yóò sì di ara kan’? Tí ó fi jẹ́ pé wọn kì í ṣe méjì mọ́, bí kò ṣe ara kan. Nítorí náà, ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀.”—Mátíù 19:4-6.
Nígbà tí Jésù sọ pé “ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀,” ìyẹn ò túmọ̀ sí pé ọ̀run ni Ọlọ́run ti ń yan ọkọ àti aya fúnra wọn. Ńṣe ló wulẹ̀ ń jẹ́rìí sí i pé Ọlọ́run fúnra ẹ̀ ló fìdí ètò ìgbéyàwó múlẹ̀, torí náà, a gbọ́dọ̀ máa wo ìgbéyàwó gẹ́gẹ́ bí ohun mímọ́.a
Àmọ́ ṣá o, àwọn ọkọ àtàwọn aya ò ní fẹ́ ká ‘so àwọn pọ̀’ pẹ̀lú ọ̀dájú èèyàn tí kò nífẹ̀ẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n á fẹ́ láti gbádùn ìgbéyàwó tó máa fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀, táwọn méjèèjì á sì máa láyọ̀. Ó lè já sí pé a ‘so wọ́n pọ̀’ nínú ìgbéyàwó aláyọ̀ báwọn méjèèjì bá ń fi ìmọ̀ràn tó gbéṣẹ́ tí Ẹlẹ́dàá fi fúnni nínú Bíbélì sílò.
Nítorí pé gbogbo wa jẹ́ aláìpé, kò lè ṣe kí èdèkòyédè àti aáwọ̀ má wà. Àmọ́ ṣá o, ohun tó sábà máa ń ran àwọn tí ìgbéyàwó wọn ń kẹ́sẹ járí lọ́wọ́ ni pé wọn kì í jẹ́ kí aáwọ̀ tó bá ń yọjú dààmú àwọn, tíwọn ṣáà ni pé kí wọ́n máa yanjú aáwọ̀ náà. Nítorí náà, ọ̀kan lára ohun pàtàkì tó yẹ kéèyàn mọ̀ nípa ìgbéyàwó ni béèyàn ṣe lè fìfẹ́ yanjú èdèkòyédè, torí pé ìfẹ́ “ni ó so àwọn nǹkan ìyókù pọ̀, tí ó [sì] mú wọn pé.”—Kólósè 3:14, Ìròhìn Ayọ̀.
▸ Máa sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. “Ẹnì kan wà tí ń sọ̀rọ̀ láìronú bí ẹni pé pẹ̀lú àwọn ìgúnni idà, ṣùgbọ́n ahọ́n ọlọ́gbọ́n jẹ́ ìmúniláradá.” (Òwe 12:18) Àwọn olùwádìí ti rí i pé ọ̀nà tí ọ̀pọ̀ ìjíròrò bá gbà bẹ̀rẹ̀ ni wọ́n máa ń parí sí. Torí náà, bí ìjíròrò kan bá bẹ̀rẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, àfàìmọ̀ kó má parí tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Lódì kejì ẹ̀wẹ̀, o mọ bó ṣe máa dùn ẹ́ tó bí ẹnì kan tó sún mọ́ ẹ bá sọ̀rọ̀ kòbákùngbé sí ẹ. Nítorí náà, fi sínú àdúrà pé kí Ọlọ́run ran ìwọ pẹ̀lú lọ́wọ́ láti lè máa sọ̀rọ̀ lọ́nà tó máa pọ́n àwọn ẹlòmíì lé, tó má fọ̀wọ̀ hàn fún wọn, tó sì máa fi hàn pó o nífẹ̀ẹ́ wọn. (Éfésù 4:31) Lórílẹ̀-èdè Japan, ìyàwó ilé kan tó ń jẹ́ Haruko,b tó ti lé lọ́dún mẹ́rìnlélógójì [44] báyìí tó ti ṣègbéyàwó, sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé á máa ń rí àléébù ara wa, a máa ń sapá láti bọ̀wọ̀ fúnra wa nínú ọ̀rọ̀ àti nínú ìṣe. Ìyẹn ló sì ń mú ká kẹ́sẹ járí nínú ìgbéyàwó wa.”
▸ Jẹ́ onínúure àti aláàánú. “Ẹ di onínúrere sí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ní fífi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn.” (Éfésù 4:32) Bí èdèkòyédè tó le gan-an bá wáyé, kì í pẹ́ tí tọkọtaya á fi máa tutọ́ sókè tí wọ́n á sì máa fojú gbà á. Lórílẹ̀-èdè Jámánì, Annette tó ti wà nínú ìgbéyàwó aláyọ̀ láti ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n [34] báyìí, gbà pé: “Kò rọrùn láti dákẹ́ jẹ́ẹ́ béèyàn bá ń bínú, èèyàn máa ń fẹ́ sọ àwọn nǹkan tó lè mú ẹni kejì bínú, ńṣe nìyẹn sì máa ń mú kí nǹkan burú sí i.” Àmọ́ ṣá o, bó o bá ń sapá láti jẹ́ onínúure àti aláàánú, ọ̀pọ̀ nǹkan lo lè ṣe kí ìgbéyàwó rẹ bàa lè máa fún ẹ láyọ̀.
▸ Jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. “[Má ṣe] ohunkóhun láti inú ẹ̀mí asọ̀ tàbí láti inú ìgbéra-ẹni-lárugẹ, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, kí ẹ máa kà á sí pé àwọn ẹlòmíràn lọ́lá jù yín lọ.” (Fílípì 2:3) Tọkọtaya ò ní yé forí gbárí bí ìgbéraga bá ń sún àwọn méjèèjì láti máa di ẹ̀bi ru ara wọn bí ìṣòro bá dé, dípò kí wọ́n máa fìrẹ̀lẹ̀ wá ọ̀nà tí wọ́n fi lè mú káwọn nǹkan sunwọ̀n sí i. Ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, tàbí ìwà ìrẹ̀lẹ̀, lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti má ṣe máa rin kinkin pé ìwọ lo jàre bí èdèkòyédè bá wáyé.
▸ Má máa tètè bínú. “Má ṣe kánjú nínú ẹ̀mí rẹ láti fara ya.” (Oníwàásù 7:9) Má ṣe jẹ́ kó mọ́ ẹ lára láti máa ta ko ojú tí ẹnì kejì rẹ fi ń wo nǹkan, tàbí kó o máa tètè gbèjà ara ẹ bí ẹnì kejì rẹ bá yẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ wò nítorí ohun tó o sọ tàbí ohun tó o ṣe. Kàkà bẹ́ẹ̀, fetí sílẹ̀ sí ẹni kejì rẹ kó o sì jẹ́ kóhun tó ń sọ yé ẹ. Ronú dáadáa kó o tó fèsì. Ó máa ń pẹ́ kí ọ̀pọ̀ tọkọtaya tó mọ̀ pé ọ̀lẹ lẹni tí ohùn rẹ̀ bá mókè nínú àríyànjiyàn, ẹni bá yanjú aáwọ̀ tó díjà sílẹ̀ ni alágbára.
▸ Mọ ìgbà tó yẹ kó o panu mọ́. “Kí olúkúlùkù ènìyàn yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ, lọ́ra nípa ìrunú.” (Jákọ́bù 1:19) Kò sí iyè méjì níbẹ̀ pé ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ tó dára jẹ́ ọ̀kan lára àmì tó ṣe pàtàkì jù lọ, tó ń fi hàn pé ibi ayọ̀ ni ìgbéyàwó ẹni forí lé. Kí wá nìdí tí Bíbélì fi sọ pé “ìgbà dídákẹ́ jẹ́ẹ́” wà? (Oníwàásù 3:7) Àkókò tí Bíbélì ń sọ níbí lè jẹ́ ìgbà tó yẹ kéèyàn tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa kó bàa lè lóye ohun tí ẹnì kejì rẹ̀ ń bá a sọ. Apá pàtàkì lèyí jẹ́ nínú ìjùmọ̀sọ̀rọ̀, ó sì máa ń jẹ́ kéèyàn mọ bọ́ràn ṣe rí lára ẹnì kejì àti ohun tó fà á tó fi rí bẹ́ẹ̀.
▸ Tẹ́tí sí i láti mọ bọ́ràn ṣe rí lára ẹ̀. “Ẹ máa yọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ń yọ̀; ẹ máa sunkún pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ń sunkún.” (Róòmù 12:15) Fífi ọ̀ràn ẹlòmíì rora ẹni wò ṣe pàtàkì kí ìjíròrò bàa lè nítumọ̀ nítorí pé ó máa jẹ́ kéèyàn mọ bọ́rọ̀ ṣe rí gan-an lára ẹnì kejì. Ìyẹn á sì mú kẹ́ ẹ lè máa gbọ́ra yín lágbọ̀ọ́yé, kẹ́ ẹ máa fọ̀wọ̀ fúnra yín, kẹ́ ẹ sì máa buyì kúnra yín. Ní orílẹ̀-èdè Brazil, Nella tí wọ́n ti gbé níyàwó láti ọdún méjìlélọ́gbọ̀n [32] sẹ́yìn sọ pé, “mo máa ń fara balẹ̀ tẹ́tí sílẹ̀ nígbà gbogbo kí n bàa lè lóye ohun tí Manuel ní lọ́kàn, kí n sì mọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ̀.” Bí ẹnì kejì rẹ bá ń sọ̀rọ̀, “ìgbà dídákẹ́ jẹ́ẹ́” nìyẹn fún ẹ láti tẹ́tí sílẹ̀ lọ́nà tó fi hàn pé ò ń fi ọ̀ràn rẹ̀ rora ẹ wò.
▸ Máa fìmọrírì hàn. “Ẹ . . . fi ara yín hàn ní ẹni tí ó kún fún ọpẹ́.” (Kólósè 3:15) Tọkọtaya tó bá ń fi hàn pé àwọn mọrírì ẹnì kejì àwọn ló máa ń gbé ilé aláyọ̀ ró. Àmọ́ ṣá o, bí tọkọtaya ṣe ń gbé pa pọ̀ láti ọjọ́ dé ọjọ́, àwọn kan lára wọn lè máa gbà gbé apá tó ṣe pàtàkì nínú ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ yìí kí wọ́n sì máa rò pé ẹnì kejì àwọn á ṣáà ti mọ̀ pé àwọn mọrírì rẹ̀ gan-an. Ọ̀mọ̀wé Ellen Wachtel sọ pé: “Èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn tọkọtaya lè mú kí ẹnì kejì wọn mọ̀ pé àwọn fẹ́ràn ẹ̀, ìyẹn bí wọ́n bá ronú pó yẹ káwọn jẹ́ kó mọ̀ bẹ́ẹ̀.”
Ó ṣe pàtàkì pé káwọn ọkọ máa mú un dá àwọn aya wọn lójú pé àwọn nífẹ̀ẹ́ wọn, kí wọ́n sì tún máa fi ìmọrírì hàn fún ohun tí wọ́n bá ṣe. Ọ̀pọ̀ nǹkan lẹ sì tún lè ṣe kí ìgbéyàwó yín lè rójú, kí aya yín máa láyọ̀, kí ọkàn ẹ̀yin pẹ̀lú sì balẹ̀, bẹ́ ẹ bá jẹ́ kó mọ́ ọn yín lára láti máa gbóríyìn fún aya yín nítorí àwọn ohun ribiribi tó ń gbé ṣe.
Fífi aya lọ́kàn balẹ̀ ṣe pàtàkì, ì báà jẹ́ nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹnu yín tàbí nípasẹ̀ ìwà tẹ́ ẹ̀ ń hù. Bí ẹ̀yin ọkọ bá fẹnu ko aya yín lẹ́nu lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́, tẹ́ ẹ rọra fọwọ́ gbá a mọ́ra, tẹ́ ẹ sì rẹ́rìn-ín músẹ́ sí i, ìyẹn gan-an ṣe ju kẹ́ ẹ wulẹ̀ sọ fún un pé “Mo fẹ́ràn rẹ.” Ó máa fi í lọ́kàn balẹ̀ pé ẹ kà á sí pàtàkì àti pé kòṣeémánìí ló jẹ́ fún yín. Pè é lórí fóònù tàbí kó o fi lẹ́tà orí kọ̀ǹpútà tàbí ti tẹlifóònù alágbèéká ránṣẹ́ sí i pé, “Àárò rẹ ń sọ mi” tàbí “Ṣé iṣẹ́ ń lọ?” Bó o bá ti gbà gbé àti máa sọ irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn tẹ́ ẹ ti fẹ́ra, ó máa dára kó o tún padà sí í ṣe bẹ́ẹ̀. Má ṣe jẹ́ kó su ẹ láti túbọ̀ máa mọ ohun tí ẹnì kejì rẹ nífẹ̀ẹ́ sí.
Ńṣe ló rí bí ọ̀rọ̀ tí ìyá Ọba Lémúẹ́lì, tó jẹ ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, sọ pé: “Baale rẹ̀ pẹlu . . . fi ìyìn fun un. ‘Ọpọlọpọ awọn ọmọbinrin ni o huwa rere, ṣugbọn iwọ ta gbogbo wọn yọ!’” (Òwe 31:1, 28, 29, Bibeli Yoruba Atọ́ka) Ìgbà wo lo gbóríyìn fún ìyàwó rẹ gbẹ̀yìn? Ìwọ ìyàwó náà ńkọ́, ìgbà wo lo gbóríyìn fún ọkọ rẹ gbẹ̀yìn?
▸ Yára láti dárí jini. “Má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá yín nínú ipò ìbínú.” (Éfésù 4:26) Nínú ìgbéyàwó, kò sí ni kí ẹ̀yìn méjèèjì má ṣe àṣìṣe. Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé kẹ́ ẹ máa fínnú fíndọ̀ dárí ji ara yín. Láti orílẹ̀-èdè South Africa, Clive àti Monica, tí wọ́n ti ṣègbéyàwó láti ọdún mẹ́tàlélógójì [43] sẹ́yìn, ti rí i pé ìmọ̀ràn inú Bíbélì yìí ti ran àwọn lọ́wọ́ gidigidi. Clive ṣàlàyé pé: “A máa ń sapá láti fi ìlànà tó wà nínú Éfésù 4:26 sílò, a sì máa ń gbìyànjú láti tètè dárí ji ara wa, níwọ̀n bá a ti mọ̀ pé ohun tínú Ọlọ́run dùn sí nìyẹn. Ara wa á wá yá gágá, ẹ̀rí ọkàn tó mọ́ la máa ń gbé lọ sórí ibùsùn, a sì máa ń sun oorun àsùnwọra.”
Bí òwe ìgbàanì kan ṣe sọ gẹ́lẹ́ pé ọ̀rọ̀ á rí nìyẹn, ó ní: ‘Ẹwà ni ó jẹ́ láti gbójú fo ìrélànàkọjá.’ (Òwe 19:11) Annette, tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ tẹ́lẹ̀, gbà pé bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn, ó sì fi kún un pé: “Ìgbéyàwó ò lè kẹ́sẹ járí bí tọkọtaya kì í bá dárí ji ara wọn.” Ó ṣàlàyé ìdí tó fi máa rí bẹ́ẹ̀, ó ní: “Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ wọ́n á fàyè sílẹ̀ fún ìkórìíra àti ìfura, èyí tó máa ń da ìgbéyàwó rú. Àmọ́ bẹ́ ẹ bá ń dárí ji ara yín, ìgbéyàwó yín á túbọ̀ fìdí múlẹ̀, àjọṣe yín á sì túbọ̀ fẹsẹ̀ rinlẹ̀.”
Bó o bá ṣe ohun tó dun ẹnì kejì rẹ, má wulẹ̀ parí ẹ̀ sí pé ó máa tó gbàgbé ẹ̀. Kó o tó lè yanjú aáwọ̀, àfi kó o ṣe ọ̀kan lára ohun tó ṣòro jù lọ tó pọn dandan pé káwọn tọkọtaya máa ṣe fúnra wọn, ìyẹn ni pé kí wọ́n gbà pé àwọn ti ṣe àṣìṣe. Tàbí kẹ̀, ó lè wá ọ̀nà láti fìrẹ̀lẹ̀ sọ ohun kan bí èyí: “Máà bínú, aya mi. Àṣìṣe ni.” Bó o bá fìrẹ̀lẹ̀ tọrọ àforíjì, wàá jèrè ọ̀wọ̀ ẹnì kejì rẹ, ẹ̀yin méjèèjì á lè túbọ̀ máa fọkàn tán ara yín, àlàáfíà á sì máa bá yín gbé.
▸ Ẹ ṣera yín lọ́kan. “Wọn [ọkọ àti ìyàwó] kì í ṣe méjì mọ́, bí kò ṣe ara kan. Nítorí náà, ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀.” (Mátíù 19:6) Ẹ̀yin méjèèjì ti jẹ́jẹ̀ẹ́ níwájú Ọlọ́run àti èèyàn fúnra yín pé ẹ máa ṣe ara yín lọ́kan, láìka ìṣòro yòówù tó lè yọjú sí.c Àmọ́, ká ṣera ẹni lọ́kan kì í ṣe ọ̀rọ̀ wíwulẹ̀ ṣe ohun tí òfin sọ o. Ìfẹ́ tòótọ́, tó tinú ọkàn wá, ló máa ń mú kéèyàn fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn ló sì ń fi hàn pé ẹ ní ọ̀wọ̀ fún ara yín àti fún Ọlọ́run, àti pé ẹ̀ ń bọlá fún ara yín, ẹ sì tún ń bọlá fún Ọlọ́run. Nítorí náà, ẹ má ṣe jin ìgbéyàwó yín tó jẹ́ ohun mímọ́ lẹ́sẹ̀ nípa níní ojú síta; ọ̀dọ̀ ẹnì kejì yín nìkan ni kí ọkàn yín máa fà sí.—Mátíù 5:28.
▸ Fífi ti ẹnì kejì yín ṣáájú máa jẹ́ kí ṣíṣe tẹ́ ẹ ṣera yín lọ́kan túbọ̀ fẹsẹ̀ múlẹ̀. “Ẹ má ṣe máa mójú tó ire ara ẹni nínú kìkì àwọn ọ̀ràn ti ara yín nìkan, ṣùgbọ́n ire ara ẹni ti àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.” (Fílípì 2:4) Ọ̀nà kan tó o lè gbà mú kí ṣíṣe tí ìwọ àti ẹnì kejì rẹ ṣe ara yín lọ́kan túbọ̀ fẹsẹ̀ múlẹ̀ ni pé kó o jẹ́ káwọn ohun tó bá nílò àtàwọn nǹkan tó bá wù ú máa jẹ ẹ́ lógún ju tara ẹ lọ. Premji, tó ti pé ogún ọdún báyìí tó ti ṣègbéyàwó, ti sọ ọ́ dàṣà láti máa ran ìyàwó rẹ̀ tó jẹ́ oníṣẹ́ oṣù lọ́wọ́ láti máa ṣe àwọn iṣẹ́ ilé. Ó sọ pé: “Mo máa ń bá Rita dáná, mo sì máa ń bá a ṣe àwọn iṣẹ́ ilé míì kó bàa lè ní àkókò àti okun tó pọ̀ tó láti ṣe àwọn nǹkan tó gbádùn àtimáa ṣe.”
Ìsapá Máa Ń Mérè Wá
Nígbà míì, iṣẹ́ ribiribi tó wà nínú kéèyàn ní ilé aláyọ̀ ti tó láti mú kó sú àwọn míì. Àmọ́, má ṣe jẹ́ kí ìbínú sún ẹ láti sá fún iṣẹ́ tó pọn dandan fún ẹ láti ṣe tàbí kó o pàdánù gbogbo wàhálà tó o ti ṣe lórí ìgbéyàwó rẹ, ìyẹn ibi tẹ́ ẹ ti jọ bá ìrìn-àjò ìgbéyàwó yín dé.
Sid, tó ti gbéyàwó láti ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n [33] sẹ́yìn sọ pé: “Bó o bá sapá tọkàntọkàn, tó o sì fi hàn pé o fẹ́ kí ìgbéyàwó rẹ kẹ́sẹ járí, ó dájú pé Jèhófà á bù kún ìsapá rẹ.” Ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn tẹ́ ẹ ní síra yín àti bẹ́ ẹ ṣe ń tira yín lẹ́yìn la onírúurú ìṣòro kọjá, tẹ́ ẹ sì jọ ń gbádùn ara yín nígbà tí nǹkan bá ń lọ déédéé, á ràn yín lọ́wọ́ láti gúnlẹ̀ ayọ̀ kí ìgbéyàwó yín sì kẹ́sẹ járí.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Jésù sọ pé ìdí kan ṣoṣo tí tọkọtaya fi lè kọra wọn sílẹ̀ kí wọ́n sì fẹ́ ẹlòmíì ni bí ọ̀kan lára wọn bá ṣe àgbèrè, ìyẹn ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹni tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya ẹni.—Mátíù 19:9.
b A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà nínú àpilẹ̀kọ yìí.
c Bíbélì yọ̀ọ̀da pé kí ọkọ tàbí aya tí ẹnì kejì rẹ̀ ṣe panṣágà pinnu yálà òun máa kọ̀ ọ́ sílẹ̀ tàbí òun ò ní kọ̀ ọ́ sílẹ̀. (Mátíù 19:9) Wo àpilẹ̀kọ náà “Ojú Ìwòye Bíbélì: Panṣágà—Ṣé Kí N Dáríjì Í Tàbí Kí N Má Ṣe Dáríjì Í?” nínú Jí! August 8, 1995.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]
Bíbélì dà bí àwòrán ojú ọ̀nà tí ń tọ́ni sọ́nà nínú ìgbéyàwó
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Bẹ́ Ẹ Bá Fẹ́ Jíròrò Ìṣòro Èyíkéyìí
◼ Ẹ wá àkókò tí kò rẹ èyíkéyìí nínú yín.
◼ Ẹ má ṣe lámèyítọ́, ńṣe ni kẹ́ ẹ sọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí gan-an.
◼ Ẹ fún ara yín lọ́rọ̀ sọ; kí ọkọ gbọ́ ohun tí aya ní í sọ, kí aya náà sì gbọ́ ohun tí ọkọ ní í sọ.
◼ Ẹ fi hàn pẹ́ ẹ mọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹnì kejì yín.
◼ Ẹ máa fi ọ̀ràn ẹnì kejì rora yín wò, àní tẹ́ ò bá gbà pẹ̀lú ara yín pàápàá.
◼ Ẹ máa lo òye, ẹ má sì ṣe máa rin kinkin.
◼ Ẹ máa fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ tọrọ àforíjì tẹ́ ẹ bá ṣẹra yín.
◼ Ẹ máa fi ìfẹ́ àti ìmọrírì hàn.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Kí Ìgbéyàwó Yín Bàa Lè Kẹ́sẹ Járí
◼ Ẹ máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì tó máa ń fìdí ìgbéyàwó múlẹ̀.
◼ Ẹ má ṣe jẹ́ kọ́wọ́ yín máa dí jù láti gbọ́ tẹnì kejì yín.
◼ Ẹ jẹ́ kí ọ̀yàyà àti ìfẹ́ gbilẹ̀.
◼ Ẹ jẹ́ ẹni tó ṣeé gbára lé, tó sì mọṣẹ́ rẹ̀ níṣẹ́.
◼ Ẹ jẹ́ onínúure, kẹ́ ẹ sì máa bọ̀wọ̀ fúnra yín.
◼ Ẹ jọ máa pín iṣẹ́ ilé ṣe.
◼ Ẹ má ṣe jẹ́ kọ́rọ̀ máa dìjà, ńṣe ni kẹ́ ẹ máa bára yín sọ̀rọ̀ bí ọ̀rẹ́.
◼ Ẹ máa bára yín ṣàwàdà kẹ́ ẹ sì máa najú pa pọ̀.
◼ Ẹ máa wá ọ̀nà tí àárín ẹ̀yìn méjèèjì á fi túbọ̀ máa gún.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Àwọn Ìbéèrè Tí Wàá Máa Bí Ara Rẹ
◼ Kí ló yẹ kí n máa ṣiṣẹ́ lé lórí jù lọ nínú ìgbéyàwó mi?
◼ Ọ̀nà wo ni mo sì lè gbà máa ṣiṣẹ́ lé wọn lórí?