ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Iná Ń Jó Lára Igi Kékeré Kan
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
    • Mósè níbi tíná ti ń jó igi kan

      Ẹ̀KỌ́ 18

      Iná Ń Jó Lára Igi Kékeré Kan

      Ogójì (40) ọdún ni Mósè fi gbé nílẹ̀ Mídíánì. Ó fẹ́ ìyàwó, ó sì ní àwọn ọmọ. Lọ́jọ́ kan, ó ń tọ́jú àwọn àgùntàn ẹ̀ nítòsí Òkè Sínáì, ohun kan ṣẹlẹ̀ tó yà á lẹ́nu. Ṣàdédé ló rí i tí iná ń jó igi kékeré kan tó ní ẹ̀gún lára, síbẹ̀ igi náà ò jóná! Nígbà tí Mósè sún mọ́ tòsí ibẹ̀ kó lè mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀, ó gbọ́ ohùn kan láàárín igi náà, ohùn yẹn sọ pé: ‘Mósè! Dúró síbi tó o dé yẹn. Bọ́ bàtà ẹsẹ̀ rẹ torí pé ilẹ̀ mímọ́ ni ibi tó o wà.’ Jèhófà ló rán áńgẹ́lì kan láti bá Mósè sọ̀rọ̀.

      Ẹ̀rù ba Mósè, ó sì bo ojú rẹ̀. Ohùn náà wá sọ pé: ‘Mo ti rí ìyà tí wọ́n fi ń jẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Mo máa gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì, màá sì mú wọn lọ sí ilẹ̀ tó dáa gan-an. Ìwọ lo máa kó wọn jáde kúrò nílẹ̀ Íjíbítì.’ Ọ̀rọ̀ yẹn máa ya Mósè lẹ́nu gan-an o, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?

      Mósè béèrè pé: ‘Kí ni mo máa sọ táwọn èèyàn náà bá béèrè pé ta ló rán mi?’ Ọlọ́run dáhùn pé: ‘Sọ fún wọn pé Jèhófà, Ọlọ́run Ábúráhámù, Ọlọ́run Ísákì àti Ọlọ́run Jékọ́bù ló rán mi sí yín.’ Mósè wá sọ pé: ‘Táwọn èèyàn náà ò bá fetí sí mi ńkọ́?’ Jèhófà wá ṣe ohun kan táá jẹ́ kó mọ̀ pé òun máa ràn án lọ́wọ́. Ó ní kí Mósè sọ ọ̀pá tó wà lọ́wọ́ ẹ̀ sílẹ̀. Ǹjẹ́ o mọ ohun tó ṣẹlẹ̀? Ṣe ni ọ̀pá yẹn di ejò! Nígbà tí Mósè di ìrù ejò náà mú, ó tún pa dà di ọ̀pá. Jèhófà wá sọ pé: ‘Tí wọ́n bá rí ohun tó o ṣe yìí, wọ́n á gbà pé èmi ni mo rán ẹ.’

      Mósè wá sọ pé: ‘Àmọ́ mi ò fi bẹ́ẹ̀ mọ ọ̀rọ̀ sọ.’ Jèhófà ṣèlérí fún un pé: ‘Màá jẹ́ kó o mọ ohun tí wàá sọ, màá sì ní kí Áárónì ẹ̀gbọ́n ẹ ràn ẹ́ lọ́wọ́.’ Ọkàn Mósè wá balẹ̀ pé Jèhófà wà pẹ̀lú òun. Torí náà, òun, ìyàwó ẹ̀ àtàwọn ọmọ ẹ̀ pa dà sílẹ̀ Íjíbítì.

      “Ẹ má ṣàníyàn nípa bí ẹ ṣe máa sọ̀rọ̀ àti ohun tí ẹ máa sọ, torí a máa fún yín ní ohun tí ẹ máa sọ ní wákàtí yẹn.”​—Mátíù 10:19

      Ìbéèrè: Kí ni Mósè rí nígbà tó ń tọ́jú àwọn àgùntàn ẹ̀ nítòsí Òkè Sínáì? Iṣẹ́ wo ni Jèhófà fẹ́ rán Mósè?

      Ẹ́kísódù 3:1–4:20; Ìṣe 7:30-36

  • Àwọn Ìyọnu Mẹ́ta Àkọ́kọ́
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
    • Mósè àti Áárónì dúró níwájú Fáráò

      Ẹ̀KỌ́ 19

      Ìyọnu Mẹ́ta Àkọ́kọ́

      Àwọn ọmọ Íjíbítì fi dandan sọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì di ẹrú, wọ́n sì fún wọn ní iṣẹ́ tó le gan-an. Jèhófà wá rán Mósè àti Áárónì lọ sọ́dọ̀ Fáráò, ó sì ní kí wọ́n sọ fún un pé: ‘Jẹ́ kí àwọn èèyàn mi lọ, kí wọ́n lè jọ́sìn mi nínú aginjù.’ Àmọ́ Fáráò dá wọn lóhùn pé: ‘Kò sí èyí tó kàn mí pẹ̀lú ohun tí Jèhófà sọ, mi ò sì ní jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ.’ Torí ìyẹn, Fáráò fi kún iṣẹ́ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń ṣe. Jèhófà wá kọ́ Fáráò lọ́gbọ́n. Ǹjẹ́ o mọ ohun tí Jèhófà ṣe? Jèhófà mú kí Ìyọnu Mẹ́wàá ṣẹlẹ̀ sáwọn ará Íjíbítì. Jèhófà sọ fún Mósè pé: ‘Fáráò ò ṣe ohun tí mo sọ. Tí ilẹ̀ bá mọ́, lọ bá a ní Odò Náílì, kó o sì sọ fún un pé, torí pé kò jẹ́ káwọn èèyàn mi lọ, gbogbo omi Odò Náílì máa di ẹ̀jẹ̀.’ Mósè ṣègbọràn sí Jèhófà, ó sì lọ bá Fáráò. Áárónì wá fi ọ̀pá ẹ̀ lu Odò Náílì níṣojú Fáráò, gbogbo omi náà sì di ẹ̀jẹ̀. Odò náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í rùn, àwọn ẹja inú ẹ̀ sì kú. Ó wá di pé omi odò náà kò ṣeé mu mọ́. Síbẹ̀, Fáráò ò jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ.

      Lẹ́yìn ọjọ́ méje, Jèhófà rán Mósè pa dà lọ sọ́dọ̀ Fáráò, ó ní kó sọ fún un pé: ‘Tó ò bá jẹ́ káwọn èèyàn mi lọ, àkèré máa kún gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì.’ Áárónì wá na ọ̀pá ẹ̀, àkèré sì kún ilẹ̀ náà. Ṣe làwọn àkèré yẹn kún gbogbo inú ilé, wọ́n wà lórí bẹ́ẹ̀dì, kódà wọ́n tún kó sínú abọ́ oúnjẹ wọn. Gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì wá kún fún àkèré! Fáráò wá pe Mósè, ó sì ní kó bẹ Jèhófà pé kó dáwọ́ ìyọnu yẹn dúró. Fáráò tiẹ̀ sọ pé òun máa jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ. Torí náà, Jèhófà dáwọ́ ìyọnu yẹn dúró. Báwọn ará Íjíbítì ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í kó òkú àkèré jọ rẹpẹtẹ síbi gbogbo nìyẹn. Gbogbo ìlú náà sì wá ń rùn gan-an. Síbẹ̀, Fáráò ò gbọ́, kò jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ.

      Jèhófà ní kí Mósè sọ fún Áárónì pé kó fi ọ̀pá ẹ̀ lu ilẹ̀, iyẹ̀pẹ̀ sì máa di kòkòrò abìyẹ́, ìyẹn àwọn kòkòrò kéékèèké tó ń mùjẹ̀. Nígbà tí Áárónì ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn kòkòrò náà kún gbogbo ìlú. Àwọn ọmọ Íjíbítì kan tiẹ̀ sọ fún Fáráò pé: ‘Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ìyọnu yìí ti wá.’ Síbẹ̀, Fáráò ta kú, kò sì jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ.

      Mẹ́ta nínú àwọn ìyọnu mẹ́wàá tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ará Íjíbítì: odò Náílì di ẹ̀jẹ̀, àwọn ọ̀pọ̀lọ́ àtàwọn kòkòrò abìyẹ́ tó ń mùjẹ̀

      “Màá jẹ́ kí wọ́n mọ agbára àti okun mi, wọ́n á sì gbà pé Jèhófà ni orúkọ mi.”​—Jeremáyà 16:21

      Ìbéèrè: Àwọn ìyọnu mẹ́ta wo ló kọ́kọ́ dé bá àwọn ọmọ Íjíbítì? Kí nìdí tí Jèhófà fi mú àwọn ìyọnu yìí wá?

      Ẹ́kísódù 5:1-18; 7:8–8:19; Nehemáyà 9:9, 10

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́