ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ráhábù Fi Àwọn Amí Pa Mọ́
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
    • Ráhábù darí àwọn ẹ̀ṣọ́ ọba sọ́nà mí ì kó lè dáàbò bo àwọn ọkùnrin tó wá ṣe amí ìlú Jẹ́ríkò

      Ẹ̀KỌ́ 30

      Ráhábù Fi Àwọn Amí Pa Mọ́

      Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ amí dé ìlú Jẹ́ríkò, ilé obìnrin kan tó ń jẹ́ Ráhábù ni wọ́n dé sí. Nígbà tí ọba ìlú Jẹ́ríkò gbọ́, ó rán àwọn ẹ̀ṣọ́ ẹ̀ pé kí wọ́n lọ mú wọn wá nílé Ráhábù. Àmọ́, Ráhábù fi àwọn amí náà pa mọ́ sí òrùlé ilé ẹ̀. Nígbà táwọn ẹ̀ṣọ́ ọba dé, ńṣe ló júwe ibòmíì fún wọn. Ó wá sọ fáwọn amí náà pé: ‘Màá ràn yín lọ́wọ́ tórí mo mọ̀ pé Jèhófà wà pẹ̀lú yín àti pé ẹ máa ṣẹ́gun ìlú yìí. Ẹ jọ̀ọ́, ẹ ṣèlérí fún mi pé ẹ ò ní pa èmi àtàwọn mọ̀lẹ́bí mi.’

      Àwọn amí náà sọ fún Ráhábù pé: ‘A ṣèlérí pé kò sẹ́nì kankan nínú ilé rẹ tó máa fara pa.’ Wọ́n wá sọ pé: ‘So okùn pupa mọ́ ojú wíńdò ẹ kí ìdílé rẹ má bàa pa run.’

      Ilé Ráhábù tí wọ́n so okùn pupa mọ́ wíńdò rẹ̀. Ilé náà dúró nígbà tí ògiri ìlú Jẹ́ríkò wó lulẹ̀

      Ráhábù jẹ́ káwọn amí yìí fi okùn kan sọ̀ kalẹ̀ láti ojú wíńdò ẹ̀. Wọ́n sì sá lọ sórí àwọn òkè láti fara pa mọ́ fún ọjọ́ mẹ́ta kí wọ́n tó pa dà sọ́dọ̀ Jóṣúà. Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọdá Odò Jọ́dánì láti lọ gba ilẹ̀ náà. Ìlú Jẹ́ríkò ni wọ́n kọ́kọ́ ṣẹ́gun. Jèhófà ní kí wọ́n máa yan yí ìlú náà ká lẹ́ẹ̀kan lójúmọ́ fún ọjọ́ mẹ́fà. Nígbà tó wá di ọjọ́ keje, wọ́n yan yí i ká lẹ́ẹ̀méje. Lẹ́yìn náà, àwọn àlùfáà fọn kàkàkí wọn, àwọn ológun sì fi gbogbo agbára wọn pariwo. Bí ògiri ìlú Jẹ́ríkò ṣe wó lulẹ̀ nìyẹn! Àmọ́ ilé Ráhábù tí wọ́n kọ́ mọ́ ògiri ìlú náà kò wó. Ráhábù àti ìdílé rẹ̀ kò kú torí pé wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.

      “Bákan náà, ṣebí àwọn iṣẹ́ ló mú kí á ka Ráhábù . . . pẹ̀lú sí olódodo, lẹ́yìn tó gba àwọn òjíṣẹ́ lálejò, tó sì ní kí wọ́n gba ọ̀nà míì jáde?”​—Jémíìsì 2:25

      Ìbéèrè: Kí nìdí tí Ráhábù fi ran àwọn amí náà lọ́wọ́? Báwo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe gbógun ti ìlú Jẹ́ríkò? Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Ráhábù àti ìdílé rẹ̀?

      Jóṣúà 2:1-24; 6:1-27; Hébérù 11:30, 31; Jémíìsì 2:24-26

  • Jóṣúà àti Àwọn Ará Gíbíónì
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
    • Àwọn ará Gíbíónì wá sọ́dọ̀ Jóṣúà àtàwọn ọmọ ogun ẹ̀, wọ́n sì wọ aṣọ tó ti gbó

      Ẹ̀KỌ́ 31

      Jóṣúà àti Àwọn Ará Gíbíónì

      Gbogbo ìlú tó kù ní Kénáánì ló gbọ́ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ ní Jẹ́ríkò. Àwọn ọba ìlú tó kù wá sọ pé àwọn jọ máa bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jà. Ṣùgbọ́n àwọn ará Gíbíónì ṣe ohun tó yàtọ̀ sí tàwọn tó kù. Wọ́n wọ aṣọ tó ti gbó lọ sọ́dọ̀ Jóṣúà, wọ́n ní: ‘Ọ̀nà jíjìn la ti wá. A ti gbọ́ nípa Jèhófà àti gbogbo ohun tó ṣe fún yín ní Íjíbítì àti ní Móábù. A fẹ́ kẹ́ ẹ ṣèlérí fún wa pé ẹ ò ní bá wa jagun, àá sì di ìránṣẹ́ yín.’

      Jóṣúà gba ohun tí wọ́n sọ, ó sì ṣèlérí fún wọn. Àmọ́, lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta, ó gbọ́ pé irọ́ làwọn èèyàn náà pa fóun. Àṣé ilẹ̀ Kénáánì tó wà nítòsí ni wọ́n ti wá. Jóṣúà wá béèrè lọ́wọ́ àwọn ará Gíbíónì yìí pé: ‘Kí ló dé tẹ́ ẹ fi parọ́ fún wa?’ Wọ́n dáhùn pé: ‘Ẹ̀rù ló bà wá! A mọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run yín ń jà fún yín. Ẹ jọ̀ọ́, ẹ má pa wá.’ Torí ìlérí tí Jóṣúà ti ṣe fún wọn tẹ́lẹ̀, kò pa wọ́n.

      Kò pẹ́ sígbà yẹn làwọn ọba Kénáánì márùn-ún àtàwọn ọmọ ogun wọn wá halẹ̀ mọ́ àwọn ará Gíbíónì. Jóṣúà àtàwọn ọmọ ogun ẹ̀ sì lọ dáàbò bo àwọn ará Gíbíónì. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìjà ní kùtùkùtù àárọ̀ ọjọ́ kejì. Báwọn ará Kénáánì ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í sá lọ nìyẹn. Gbogbo ibi tí wọ́n ń sá gbà ni Jèhófà ti ń rọ yìnyín tó dà bí òkúta lé wọn lórí. Lẹ́yìn ìyẹn, Jóṣúà gbàdúrà pé kí Jèhófà mú kí oòrùn dúró sójú kan. Kí nìdí tó fi ní kí Jèhófà ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tí oòrùn ò dúró sójú kan rí? Ìdí ni pé ó dá a lójú pé kò sóhun tí Jèhófà ò lè ṣe. Oòrùn sì dúró fún odindi ọjọ́ kan gbáko títí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi ṣẹ́gun àwọn ọba Kénáánì àtàwọn ọmọ ogun wọn.

      Jóṣúà gbójú sókè, ó sì bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kí oòrùn dúró sójú kan

      “Kí ọ̀rọ̀ yín, ‘Bẹ́ẹ̀ ni’ jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, kí ‘Bẹ́ẹ̀ kọ́’ yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ kọ́, torí ọ̀dọ̀ ẹni burúkú náà ni ohun tó bá ju èyí lọ ti wá.”​—Mátíù 5:37

      Ìbéèrè: Kí làwọn ará Gíbíónì ṣe láti dáàbò bo ara wọn? Báwo ni Jèhófà ṣe ran àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́wọ́?

      Jóṣúà 9:1–10:15

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́