ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ìlérí Tí Jẹ́fútà Ṣe
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
    • Jẹ́fútà fa aṣọ ẹ̀ ya nígbà tí ọmọbìnrin ẹ̀ jáde wá pàdé ẹ̀

      Ẹ̀KỌ́ 36

      Ìlérí Tí Jẹ́fútà Ṣe

      Nígbà tó yá, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún fi Jèhófà sílẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í bọ òrìṣà. Nígbà táwọn ọmọ Ámónì bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jà, àwọn òrìṣà yẹn ò ràn wọ́n lọ́wọ́. Ọ̀pọ̀ ọdún làwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi jìyà. Wọ́n wá sọ fún Jèhófà pé: ‘A ti dẹ́ṣẹ̀. Jọ̀ọ́ gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa.’ Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kó àwọn òrìṣà wọn dànù, wọ́n sì pa dà bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn Jèhófà. Inú Jèhófà ò dùn bí ìyà ṣe ń jẹ wọ́n.

      Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá yan jagunjagun kan tó ń jẹ́ Jẹ́fútà láti ṣáájú wọn kí wọ́n lè lọ gbógun ja àwọn ọmọ Ámónì. Jẹ́fútà sọ fún Jèhófà pé: ‘Tó o bá jẹ́ ká ṣẹ́gun, mo ṣèlérí pé tí mo bá pa dà délé, ẹnikẹ́ni tó bá kọ́kọ́ jáde wá pàdé mi ni màá yọ̀ǹda fún ẹ.’ Jèhófà gbọ́ àdúrà Jẹ́fútà, ó sì jẹ́ kó borí ogun náà.

      Nígbà tí Jẹ́fútà pa dà délé, ọmọbìnrin ẹ̀ ló kọ́kọ́ jáde wá pàdé ẹ̀, òun sì ni ọmọ kan ṣoṣo tó bí. Ó ń jó, ó sì ń lu ìlù tanboríìnì. Kí ni Jẹ́fútà máa ṣe báyìí? Ó rántí ìlérí tó ṣe, ó sì sọ pé: ‘Áà ọmọbìnrin mi! O ti bà mí lọ́kàn jẹ́. Mo ṣèlérí fún Jèhófà. Kí n lè mú ìlérí náà ṣẹ, mo gbọ́dọ̀ rán ẹ lọ sí àgọ́ ìjọsìn ní Ṣílò, kó o lè lọ sìn níbẹ̀.’ Ọmọbìnrin ẹ̀ wá sọ fún un pé: ‘Bàbá mi, tẹ́ ẹ bá ti ṣèlérí fún Jèhófà, ẹ gbọ́dọ̀ mú ìlérí yín ṣẹ. Àmọ́, ẹ fún mi lóṣù méjì, kí n lè wà pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ mi lórí àwọn òkè. Lẹ́yìn náà, màá lọ.’ Àgọ́ ìjọsìn ni ọmọbìnrin Jẹ́fútà ti sìn ní gbogbo ọjọ́ ayé ẹ̀, tọkàntọkàn ló sì fi sin Jèhófà níbẹ̀. Àwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ sì máa ń lọ kí i ní Ṣílò lọ́dọọdún.

      Àwọn ọ̀rẹ́ ọmọbìnrin Jẹ́fútà máa ń wá wò ó ní àgọ́ ìjọsìn

      ‘Ẹnikẹ́ni tó bá nífẹ̀ẹ́ ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin jù mí lọ kò yẹ fún mi.’​—Mátíù 10:37

      Ìbéèrè: Ìlérí wo ni Jẹ́fútà ṣe? Kí ni ọmọbìnrin Jẹ́fútà ṣe nígbà tó gbọ́ ìlérí tí bàbá ẹ̀ ṣe fún Jèhófà?

      Àwọn Onídàájọ́ 10:6–11:11; 11:29-40; 1 Sámúẹ́lì 12:10, 11

  • Jèhófà Bá Sámúẹ́lì Sọ̀rọ̀
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
    • Sámúẹ́lì ṣílẹ̀kùn àgọ́ ìjọsìn

      Ẹ̀KỌ́ 37

      Jèhófà Bá Sámúẹ́lì Sọ̀rọ̀

      Élì tó jẹ́ Àlùfáà Àgbà ní àwọn ọmọkùnrin méjì tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ àlùfáà nínú àgọ́ ìjọsìn. Hófínì àti Fíníhásì lorúkọ wọn. Wọn ò pa òfin Jèhófà mọ́ rárá, wọ́n sì ń hùwà tí kò dáa sáwọn èèyàn. Táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá mú ẹbọ wá fún Jèhófà, Hófínì àti Fíníhásì máa mú èyí tó dáa jù lára ẹran tí wọ́n fẹ́ fi rúbọ. Élì gbọ́ nípa ohun táwọn ọmọ ẹ̀ ń ṣe, àmọ́ kò ṣe nǹkan kan sí i. Ṣé Jèhófà máa gbà kírú ìwà yìí máa bá a nìṣó?

      Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Sámúẹ́lì kéré sí Hófínì àti Fíníhásì, kò hùwà búburú ní tiẹ̀. Inú Jèhófà sì ń dùn sí Sámúẹ́lì. Lálẹ́ ọjọ́ kan, nígbà tí Sámúẹ́lì ń sùn, ó gbọ́ ohùn kan tó pe orúkọ ẹ̀. Ó sáré dìde lọ bá Élì, ó sì sọ pé: ‘Èmi nìyí!’ Àmọ́ Élì sọ pé: ‘Mi ò pè ẹ́. Pa dà lọ sùn.’ Ni Sámúẹ́lì bá pa dà lọ sùn. Ó tún gbọ́ ohùn náà lẹ́ẹ̀kejì. Nígbà tí Sámúẹ́lì gbọ́ ohùn náà lẹ́ẹ̀kẹta, Élì wá rí i pé Jèhófà ló ń pe Sámúẹ́lì. Ni Élì bá sọ fún un pé tó bá tún gbọ́ ohùn náà, kó sọ pé: ‘Jèhófà, sọ̀rọ̀. Ìránṣẹ́ rẹ ń gbọ́.’

      Sámúẹ́lì sọ ohun tí Jèhófà ní kó sọ fún Élì

      Sámúẹ́lì wá pa dà lọ sùn. Lẹ́yìn náà, ó gbọ́ tí ohùn náà sọ pé: ‘Sámúẹ́lì! Sámúẹ́lì!’ Ó wá dáhùn pé: ‘Sọ̀rọ̀, nítorí ìránṣẹ́ rẹ ń gbọ́.’ Jèhófà sọ fún un pé: ‘Sọ fún Élì pé, màá fìyà jẹ òun àti ìdílé rẹ̀. Ó mọ̀ pé àwọn ọmọ òun ń hùwà tí kò dáa nínú àgọ́ ìjọsìn, àmọ́ kò ṣe nǹkan kan sí i.’ Nígbà tílẹ̀ mọ́, Sámúẹ́lì ṣílẹ̀kùn àgọ́ ìjọsìn bó ti máa ń ṣe. Ẹ̀rù ń bà á láti jíṣẹ́ tí Jèhófà rán an sí Élì àlùfáà àgbà. Àmọ́, Élì ránṣẹ́ sí i, ó sì béèrè lọ́wọ́ ẹ̀ pé: ‘Ọmọ mi, kí ni Jèhófà sọ fún ẹ? Sọ gbogbo ẹ̀ fún mi.’ Ni Sámúẹ́lì bá jíṣẹ́ fún Élì.

      Bí Sámúẹ́lì ṣe ń dàgbà, Jèhófà ò fi í sílẹ̀. Gbogbo ilẹ̀ náà làwọn èèyàn ti mọ̀ pé Jèhófà ti yan Sámúẹ́lì láti jẹ́ àlùfáà àti adájọ́.

      “Nítorí náà, rántí Ẹlẹ́dàá rẹ Atóbilọ́lá nígbà ọ̀dọ́ rẹ.”​—Oníwàásù 12:1

      Ìbéèrè: Báwo ni Sámúẹ́lì ṣe yàtọ̀ sí Hófínì àti Fíníhásì? Iṣẹ́ wo ni Jèhófà rán Sámúẹ́lì?

      1 Sámúẹ́lì 2:12-17, 22-26; 3:1-21; 7:6

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́